ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 7/22 ojú ìwé 25-27
  • Èé Ṣe Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Mìíràn Ń Gbádùn Gbogbo Ìmóríyá Náà?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Èé Ṣe Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Mìíràn Ń Gbádùn Gbogbo Ìmóríyá Náà?
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bí Ìmóríyá Bá Kọjá Àkóso
  • Nígbà Tí Àwọn Òbí Bá Kọ̀ Jálẹ̀
  • ‘Mo Ń Pàdánù!’
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Ní Àkókò Ìṣefàájì?
    Jí!—1996
  • Kẹ́sẹ Járí Nínú Ìgbésí Ayé Rẹ!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ẹ̀yin Ọ̀dọ́—Ẹ Dènà Ẹ̀mí Ayé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Dáàbò Bo Ìdílé Rẹ Lọ́wọ́ Agbára Ìdarí Apanirun
    Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 7/22 ojú ìwé 25-27

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Èé Ṣe Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Mìíràn Ń Gbádùn Gbogbo Ìmóríyá Náà?

Jason, ọmọ ọdún 15, ṣàròyé pé: “A wulẹ̀ fẹ́ẹ́ ní ìmóríyá ni, ṣùgbọ́n ó ṣòro gan-an.”

OHUN tí ó wulẹ̀ bá ìwà ẹ̀dá mu ni láti fẹ́ẹ́ ní ìmóríyá—ní pàtàkì, nígbà ọ̀dọ́! Fún ọ̀pọ̀ jù lọ èwe, níní ìmóríyá ṣe pàtàkì gan-an bíi jíjẹun àti sísùn. Pẹ̀lú àwọn ojúgbà àti ilé iṣẹ́ ìròyìn tí ń sún wọn sí i, àwọn èwe ń fìhára gàgà lépa onírúurú ìgbòkègbodò eré ìtura. Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí kan ṣe fi hàn, bíbẹ àwọn ọ̀rẹ́ wò, wíwo tẹlifíṣọ̀n, lílọ wo sinimá, ṣíṣe àríyá, àti jíjó gbawájú nínú àwọn ìgbòkègbodò àfipawọ́ nírọ̀lẹ́ láàárín àwọn ọ̀dọ́langba. Kíkàwé, títayò àti eré ìdárayá, àti títẹ́tí sí orín tún wọ́pọ̀ pẹ̀lú.

Pẹ̀lú onírúurú ìgbòkègbodò amóríyá lárọ̀ọ́wọ́tó, ó lè ṣòro fún àwọn àgbàlagbà láti lóye ìdí tí àwọn èwe kan, bíi Jason, fi ń nímọ̀lára pé àwọn kì í ní ìmóríyá tó. Ṣùgbọ́n ìyẹn gẹ́lẹ́ ni ohun tí àwọn ọ̀dọ Kristẹni kan ti sọ! Casey ọ̀dọ́, ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, sọ ọ́ báyìí: “O ń rí gbogbo àwọn ẹgbẹ́ rẹ nílé ìwé, tí wọ́n ń ṣàríyá, tí wọ́n sì ń ṣe àwọn nǹkan, o sì ń nímọ̀lára pé a yọ ọ́ sílẹ̀.” Ṣùgbọ́n ipò náà ha burú tó bẹ́ẹ̀ ní ti gidi bí?

Ǹjẹ́ Bíbélì ka ìgbafàájì léèwọ̀ ni bí? Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Bíbélì pe Jèhófà ní “Ọlọ́run aláyọ̀.” (Tímótì Kìíní 1:11) Kò gbọdọ̀ yà ọ́ lẹ́nu nígbà náà pé Ọba Sólómọ́nì wí pé: “Olúkúlùkù ohun ni àkókò wà fún, . . . ìgba sísọkún àti ìgba rírẹ́rìn-ín; ìgba ṣíṣọ̀fọ̀ àti ìgba jíjó.” (Oníwàásù 3:1, 4) Ọ̀rọ̀ ède Hébérù nípìlẹ̀ fún “rírẹ́rìn-ín” àti àwọn ọ̀rọ̀ tí ó tan mọ́ ọn tún lè túmọ̀ sí “ṣayẹyẹ,” “ṣeré,” ‘ṣeré ìdárayá,’ “dáni lára yá,” àti “gba fàájì.”—Sámúẹ́lì Kejì 6:21; Jóòbù 41:5; Àwọn Onídàájọ́ 16:25; Ẹ́kísódù 32:6; Jẹ́nẹ́sísì 26:8.

Nígbà náà lọ́hùn-ún tí a ń kọ Bíbélì, àwọn ènìyàn Ọlọ́run ń jẹ̀gbádùn onírúurú ìgbòkègbodò gbígbámúṣé, irú bíi lílo àwọn ohun èèlò orin, kíkọrin, jíjó, fífọ̀rọ̀wérọ̀, àti títayò. Wọ́n tún máa ń ní àwọn àkókò àkànṣe fún ṣíṣàríyá àti ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ onídùnnú. (Jeremáyà 7:34; 16:9; 25:30; Lúùkù 15:25) Kódà, Jésù Kristi pàápàá lọ síbi ayẹyẹ ìgbéyàwó kan!—Jòhánù 2:1-10.

Nítorí náà, a kò ka ìmóríyá gbígbámúṣé léèwọ̀ láàárín àwọn èwe Kristẹni lónìí. Ní tòótọ́, Bíbélì wí pé: “Máa yọ̀, ìwọ ọ̀dọ́mọdé, nínú èwe rẹ; kí o sì jẹ́ kí ọkàn rẹ kí ó mú ọ lára yá ní ọjọ́ èwe rẹ.” Bí ó ti wù kí ó rí, Sólómọ́nì fi ọ̀rọ̀ ìṣọ́ra kan gbe ọ̀rọ̀ wọ̀nyí lẹ́sẹ̀ pé: “Ṣùgbọ́n, ìwọ, mọ èyí pé, nítorí nǹkan wọ̀nyí, Ọlọ́run yóò mú ọ wá sí ìdájọ́.” (Oníwàásù 11:9) Bẹ́ẹ̀ ni, ìwọ yóò jíhìn níwájú Ọlọ́run fún àwọn yíyàn tí o bá ṣe. Nítorí náà, ẹ gbọ́dọ̀ “máa ṣọ́ra láìgbagbẹ̀rẹ́ pé bí ẹ ṣe ń rìn kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí aláìlọ́gbọ́n ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ọlọ́gbọ́n” nígbà tí ó bá kan ọ̀ràn eré ìtura. (Éfésù 5:15, 16) Kí ni èrèdi rẹ̀? Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ máa ń ṣe yíyàn tí kò jíire ní ìhà yìí.

Bí Ìmóríyá Bá Kọjá Àkóso

Gbé ohun tí ó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn lọ́hùn-ún ní àkókò kíkọ Bíbélì yẹ̀ wò. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kán pàdánù gbogbo ìmọ̀lára ìwọ̀ntúnwọ̀nsì nígbà tí ó di ọ̀ràn eré ìtura, tí wọ́n ń ṣe àríyá aláriwo ní gbogbo òru! Wòlíì Aísáyà sọ pé: “Ègbé ni fún àwọn tí í máa ń dìde ní kùtùkùtù, kí wọ́n lè máa lépa ọtí líle; tí wọ́n ń wà nínú rẹ̀ títí di alẹ́, títí ọtí wáìnì ń mú ara wọn gbóná! Àti dùrù, àti fíólì, tábúrétì, fèrè, àti ọtí wáìní wà nínú àse wọn.” Kì í ṣe pé ó burú láti kóra jọ pọ̀ kí a sì jọ gbádùn oúnjẹ, orin, àti ijó. Ṣùgbọ́n Aísáyà sọ nípa àwọn alárìíyá aláriwo wọ̀nyí pé: “Wọn kò ka iṣẹ́ Olúwa sí.”—Aísáyà 5:11, 12.

Ọ̀pọ̀ èwe lónìí ń ṣe ohun kan náà—wọn kì í ka ti Ọlọ́run sí, nígbà tí wọ́n bá ń fẹ́ eré ìtura. Àwọn kan ń fi ògbójú tàpá sí àwọn ìlànà ìwà bí Ọlọ́run, wọ́n ń lọ́wọ́ nínú ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó, ìmọ̀ọ́mọ̀ ba ohun ìní jẹ́, ìjoògùnyó, àti àwọn ìwà àìníjàánu mìíràn nítorí “ìmóríyá.” Nínú àwọn ọ̀ràn mìíràn ṣáá, kì í ṣe pé àwọn ọ̀dọ́ náà ń mọ̀ọ́mọ̀ gbìyànjú láti hùwà ibi. Ṣùgbọ́n wọ́n ń kùnà láti ṣe àwọn nǹkan ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì, kí wọ́n sì yẹra fún àṣejù. (Òwe 23:20; Tímótì Kìíní 3:11) Nítorí náà, nígbà tí wọ́n bá kóra jọ pọ̀ láti ṣe fàájì, nǹkán máa ń di èyí tí apá kò ká.—Fi wé Kọ́ríńtì Kìíní 10:6-8.

Láìpẹ́ yìí, Jí! bi àwọn èwe kan léèrè pé, “Kí ní ń ṣẹlẹ̀ níbi àwọn àríyá ayé lónìí?” Ọmọbìnrin ọ̀dọ́langba kán dáhùn pé: “Lílo oògùn líle, ọtí àmujù. Ó ń ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀ gan-an.” Andrew ọ̀dọ́ sọ nípa àwọn ọmọkùnrin tí ń lọ síbi àríyá nílé ẹ̀kọ rẹ̀ pé: “Gbogbo ohun tí wọ́n máa ń ṣe kò ju kí wọ́n máa fọ́nnu lórí bí wọ́n ṣe mutí tó.” Jason tilẹ̀ tẹ̀ síwájú débi sísọ pé: “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ nígbà gbogbo ni àwọn nǹkan búburú máa ń ṣẹlẹ̀ níbi àríyá ayé.” Níwọ̀n bí a ti dẹ́bi fún “àríyá ẹhànnà” tàbí “àríyá aláriwo” nínú Bíbélì, àwọn èwe tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run máa ń yẹra fún ìkórajọ ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà tí ó ń ṣàgbéyọ irú àwọn ìwà bẹ́ẹ̀.—Gálátíà 5:21; Byington.

Àwọn oríṣi eré ìtura tí wọ́n dà bí aláìlèpanilára tilẹ̀ lè léwu nínú. Fún àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ jù lọ sinimá gbígbajúmọ̀ jù lọ lóde òní ń gbé ìwàníhòòhò, àwòrán ìbálòpọ̀, àti ìwà ipá arínilára jáde. Àwọn orin gbígbajúmọ̀ sábà ń ní ìsọkúsọ nínú. Àwọn agbo ijó rọ́ọ̀kì sábà ń jẹ́ ibi ìran ìjoògùnyó, ìdàrúdàpọ̀, àti ìwà ipá.a

Nígbà Tí Àwọn Òbí Bá Kọ̀ Jálẹ̀

Kí ni kókó ìpìlẹ̀ ọ̀ràn yìí? Bí ìwọ́ bá jẹ́ Kristẹni kan, o kò wulẹ̀ lè máa ṣe gbogbo ohun tí àwọn ojúgbà rẹ ń gbádùn ní ṣíṣe. Ó ṣe tán, Jésù sọ pé, àwọn ọmọlẹ́yìn òun ‘kì yóò jẹ́ apá kan ayé,’ ìyẹ́n sì túmọ̀ sí yíyàtọ̀ sí àwọn ènìyàn míràn. (Jòhánù 15:19) Bí àwọn òbí rẹ bá jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run, wọ́n mọ kókó yìí dájú ṣáká. Nítorí náà, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, nítorí ìfẹ́ ọkàn wọn láti dáàbò bò ọ́, àwọn òbí rẹ lè fi dandan ṣàìfún àwọn nǹkan kan—àwọn ohun tí a ń yọ̀ǹda fún àwọn ọ̀dọ́ mìíràn láti ṣe—níṣìírí tàbí kí wọ́n tilẹ̀ kà wọ́n léèwọ̀ fún ọ. Èyí kì í fìgbà gbogbo rọrùn láti fara mọ́. Ọmọbìnrin ọ̀dọ́langba kán rin kinkin mọ́ ọn pé: “Àwọn ènìyàn ń fẹ́ láti gbádùn ìmóríyá! Àwọn òbi wá gbádùn ìmóríyá nígbà èwe wọn, ṣùgbọ́n lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ó máa ń jọ pé, wọ́n ń fẹ́ẹ́ máa há wa mọ́.”

Títẹ̀ lé ìmọ̀ràn àwọn òbí rẹ nínú irú ọ̀ràn bẹ́ẹ̀ lè ṣàìrọrùn, àní nígbà tí o bá ní ojú ìwòye kan náà pẹ̀lu wọn. Èwe onírìísí òṣèré ìdárayá kan tí a óò pè ní Jared rántí pé: “Mo fẹ́ láti máa gbá bọ́ọ̀lù alápẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù alápẹ̀rẹ̀ ilé ẹ̀kọ́. Ọ̀pọ̀ ènìyàn ní ń fún mi níṣìírí láti ṣe bẹ́ẹ̀, ó sì ń dà mí lọ́kàn rú. Ṣùgbọ́n mo bá àwọn òbí mi sọ̀rọ̀.” Àwọn òbi Jared tọ́ka sí àwọn ewu “ẹgbẹ́ búburú,” wọ́n sì rán an létí bí àwọn ìgbòkègbodò eré ìdárayá ṣe lè gba àkókò tó. (Kọ́ríńtì Kìíní 15:33) Jared sọ pẹ̀lú ìbànújẹ́ pé: “Ibi tí ó parí sí nìyẹn.” Ó fara mọ́ ìmọ̀ràn àwọn òbi rẹ̀, ṣùgbọ́n ó ṣì ń dùn ún pé kò lè máa gbá bọ́ọ̀lù.

‘Mo Ń Pàdánù!’

Ohun yòó wù kí ipò rẹ́ jẹ́, o lè rẹ̀wẹ̀sì lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan tí o bá ń gbọ́ tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹ́gbẹ́ rẹ ń dánnu nípa àkókò ìgbafàájì wọn. O lè béèrè pé, ‘Èé ṣe tí àwọn ọ̀dọ́ mìíràn fi ń gbádùn gbogbo ìmóríyá náà?’ Bẹ́ẹ̀ ni, báwo ni o ṣe lè borí ìmọ̀lára pé o ń pàdánù?

Kíka Orin Dáfídì 73 àti ṣíṣàṣàrò lórí ìrírí òǹkọ̀wé Bíbélì náà, Ásáfù, lè ṣèrànwọ́ fún ọ. Ní Sm 73 ẹsẹ 2 àti 3, ó jẹ́wọ́ pé: “Bí ó ṣe ti èmi ni, ẹsẹ̀ mí fẹ́rẹ̀ẹ́ yẹ̀ tán; ìrìn mí fẹ́rẹ̀ẹ́ yọ̀ tán. Nítorí tí èmí ṣe ìlara sí àwọn aṣeféfé.” Bẹ́ẹ̀ ni, nígbà tí Ásáfù ń gbé ìgbésí ayé aláàlà, àwọn kan ń ṣe féfé pé àwọ́n lè ṣe ohunkóhun tí àwọ́n bá fẹ́—tí ó ṣe kedere pé búburú kan kì yóò tẹ̀yin rẹ̀ yọ. Ó jọ pé wọ́n ní ọ̀pọ̀ ohun ìní, wọ́n sì ń ní púpọ̀ sí i. (Sm 73 Ẹsẹ 12) Ásáfù tipa bẹ́ẹ̀ rẹ̀wẹ̀sì tó bẹ́ẹ̀ tí ó sì ké jáde pé: “Ó ha jẹ́ lórí asán ni mo wẹ àyà mi mọ́, tí n kò sì dẹ́ṣẹ̀ bí?”—Orin Dáfídì 73:13, Today’s English Version.

Ó dùn mọ́ni nínú pé Ásáfù pe orí ara rẹ̀ wálé kí ó tóó ṣe ohun ìkùgbù kankan. Ó ṣe ìbẹ̀wò kan sí “ibi mímọ́ Ọlọ́run,” nínú àyíká tí ń gbéni ró yẹn ni ó sì ti túbọ̀ ronú jinlẹ̀ lórí ọ̀ràn náà. Láìpẹ́, Ásáfù ti dórí ìpinnu pípàfiyèsí kan nípa àwọn aláìlọ́lọ́run, olùfẹ́ fàájì wọ̀nyẹn, pé: “Ní tòótọ́, ìwọ́ gbé wọn ka ibi yíyọ̀: ìwọ́ tì wọ́n ṣubú sínú ìparun.”—Orin Dáfídì 73:17, 18.

A lè sọ ohun kan náà nípa púpọ̀ lára àwọn ojúgbà rẹ tí ń wá fàájì. Wọ́n lè rò pé àwọ́n ń ṣe fàájì nísinsìnyí. Ṣùgbọ́n fàájì ẹ̀ṣẹ́ jẹ́ onígbà kúkúrú! (Hébérù 11:25) Nítorí pé wọn kò tẹ̀ lé àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n Bíbélì, wọ́n dúró lórí “ibi yíyọ̀,” wọ́n sì fìgbà gbogbo wà nínú ewu ìṣubú tí ń bani lẹ́rù—lójijì, láìsí ìkìlọ̀. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run polongo pé: “Ohun yòó wù tí ènìyán bá ń fúnrúgbìn, èyí ni òun yóò ká pẹ̀lú.” (Gálátíà 6:7) Dájúdájú, o ti gbọ́ nípa àwọn ọ̀dọ́ ojúgbà rẹ tí wọ́n ti kú ní rèwerèwe, àwọn àrùn tí ìbálòpọ̀ ń ta látaré, oyún tí a kò fẹ́, tàbí ẹ̀wọ̀n nítorí àwọn ojúmìító aláìṣètẹ́wọ́gbà fún “ìmóríyá.” Nígbà náà, kò ha ń ṣe ọ́ láǹfààní láti má ṣe lọ́wọ́ sí irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ bí?—Aísáyà 48:17.

Sólómọ́nì fúnni nímọ̀ràn rere nígbà tí ó wí pé: “Má ṣe jẹ́ kí àyà rẹ kí ó ṣe ìlara sí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, ṣùgbọ́n kí ìwọ kí ó wà ní ìbẹ̀rù Jèhófà ní gbogbo ọjọ́. Nítorí nípa ìyẹn ni ọjọ́ ọ̀la kan ń bẹ, a kì yóò sì ké ìrètí rẹ kúrò.” (Òwe 23:17, 18) Bẹ́ẹ̀ ni, kò sí àkókò “fàájì” kankan tí ó tọ́ kí a tìtorí rẹ̀ pàdánù ìrètí ẹni láti wà láàyè títí láé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé.

Ní báyìí ná, báwo ni o ṣe lè tẹ́ ìfẹ́ àtọkànwá àdánidá rẹ láti máa ní àkókò ìgbafàájì tòótọ́ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan lọ́rùn? Àwọn ọ̀nà aláìléwu, tí ó gbámúṣé ha wà láti ṣe bẹ́ẹ̀ bí? Bí owó àti àwọn ohun ìlò míràn kò bá sí tó ńkọ́? Jí! béèrè fún àwọn àbá àti èrò díẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn èwe káàkiri àgbáyé. A óò jíròrò èyí nínú àpilẹ̀kọ kan nínú ọ̀wọ́ yìí lọ́jọ́ iwájú.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Ó Ha Yẹ Kí N Máa Lọ sí Agbo Ijó Rọ́ọ̀kì Bí?” nínú ìtẹ̀jáde wa ti December 22, 1995.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Ó ha yẹ kí o rò pé o ń pàdánù nítorí o kò lè lọ́wọ́ nínú ohun tí ayé ń pè ní ìmóríyá bí?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́