Kẹ́sẹ Járí Nínú Ìgbésí Ayé Rẹ!
“Aláyọ̀ ni ènìyàn tí kò rìn nínú ìmọ̀ràn àwọn ẹni burúkú . . . Gbogbo nǹkan tí ó bá ń ṣe ni yóò sì máa kẹ́sẹ járí.”—SÁÀMÙ 1:1, 3.
1. (a) Ojú wo ni ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ nínú ayé fi ń wo ìkẹ́sẹjárí? (b) Báwo ni Bíbélì ṣe ṣàpèjúwe ẹni tó kẹ́sẹ járí?
ÌKẸ́SẸJÁRÍ—kí ni ọ̀rọ̀ yẹn túmọ̀ sí lọ́kàn rẹ? Ọ̀dọ́mọkùnrin kan wí pé: “Góńgó tó wà lórí ẹ̀mí mí ni pé kí n di oníṣòwò tó rí towó ṣe.” Ọ̀dọ́mọbìnrin kan wí pé: “Pàtàkì ohun tó wù mí ni pé kí n ní ìdílé aláyọ̀.” Ṣùgbọ́n ọ̀dọ́mọbìnrin mìíràn wí pé: “Ohun tó wù mí jù lọ ni pé kí n ní ilé tèmi, kí n ní ọkọ̀ afẹ́ kan . . . Kí nǹkan ṣáà ti máa dán fún mi.” Àmọ́, ìṣòro náà ni pé kì í ṣe owó, ìdílé, tàbí iṣẹ́ tó dáa la fi ń mọ ẹni tó kẹ́sẹ járí. Nínú Sáàmù 1:1-3, a kà pé: “Aláyọ̀ ni ènìyàn tí kò rìn nínú ìmọ̀ràn àwọn ẹni burúkú . . . Inú dídùn rẹ̀ wà nínú òfin Jèhófà . . . Gbogbo nǹkan tí ó bá ń ṣe ni yóò sì máa kẹ́sẹ járí.”
2. Ibo la ti lè rí ojúlówó ìkẹ́sẹjárí, ọ̀nà kan ṣoṣo wo la sì lè gbà rí i?
2 Níhìn-ín, Bíbélì ṣèlérí ohun kan tí èèyàn kankan kò lè ṣe fúnni—ojúlówó ìkẹ́sẹjárí! Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe ọ̀ràn níní owó rẹpẹtẹ ló ń sọ. Bíbélì fúnra rẹ̀ kìlọ̀ pé: “Ìfẹ́ owó ni gbòǹgbò onírúurú ohun aṣeniléṣe gbogbo.” (1 Tímótì 6:10) Ojúlówó ìkẹ́sẹjárí máa ń wá nígbà táa bá ṣe ohun tí inú Ọlọ́run dùn sí—títí kan títẹ̀ lé òfin Jèhófà. Èyí nìkan ló le mú ìtẹ́lọ́rùn tòótọ́ àti ojúlówó ayọ̀ wá! Bóyá èrò wíwà lábẹ́ òfin Jèhófà àti sísọ ohun tí a óò máa ṣe fún wa kò dà bí èyí tó wù wá. Síbẹ̀, Jésù wí pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn.” (Mátíù 5:3) Bóyá o mọ̀ bẹ́ẹ̀ tàbí o kò mọ̀ bẹ́ẹ̀, a dá àwọn àìní tẹ̀mí mọ́ ọ—títí kan àìní tó gbópọn láti mọ Ọlọ́run àti láti lóye ète rẹ̀. Nítorí náà, o lè ní ayọ̀ tòótọ́ kìkì bí o bá wá àwọn ohun tí o ṣaláìní wọ̀nyẹn, tí o sì tẹ̀ lé “òfin Jèhófà.”
Ìdí Tí A Fi Nílò Òfin Ọlọ́run
3. Èé ṣe tí inú wa fi lè dùn láti jẹ́ kí Jèhófà ‘darí àwọn ìṣísẹ̀ wa’?
3 Wòlíì Jeremáyà kọ̀wé pé: “Mo mọ̀ dáadáa, Jèhófà, pé ọ̀nà ará ayé kì í ṣe tirẹ̀. Kì í ṣe ti ènìyàn tí ń rìn àní láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” (Jeremáyà 10:23) Bí ọ̀ràn ṣe rí fún gbogbo ènìyàn nìyẹn, àtọmọdé àtàgbà. Kì í ṣe pé a kò ní ọgbọ́n, ìrírí, àti ìmọ̀ láti darí ìgbésẹ̀ wa nìkan ni; àní a ò tiẹ̀ ní ẹ̀tọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Nínú Ìṣípayá 4:11, Bíbélì sọ pé: “Jèhófà, àní Ọlọ́run wa, ìwọ ni ó yẹ láti gba ògo àti ọlá àti agbára, nítorí pé ìwọ ni ó dá ohun gbogbo, àti nítorí ìfẹ́ rẹ ni wọ́n ṣe wà, tí a sì dá wọn.” Gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́dàá wa, Jèhófà ni “orísun ìyè wa.” (Sáàmù 36:9) Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ bẹ́ẹ̀, ó mọ bó ṣe yẹ ká gbé ìgbésí ayé wa, ju bí ẹnikẹ́ni mìíràn ti lè mọ̀ ọ́n. Nítorí náà ó ṣe òfin, kì í ṣe láti dí ìgbádùn wa lọ́wọ́, ṣùgbọ́n láti ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe ara wa láǹfààní. (Aísáyà 48:17) Tóo bá pa òfin Ọlọ́run tì, o ti fọwọ́ ara rẹ̀ ti ilẹ̀kùn àṣeyọrí rẹ nìyẹn.
4. Èé ṣe tí ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ fi ń ba ayé ara wọn jẹ́?
4 Fún àpẹẹrẹ, ǹjẹ́ o ti ṣe kàyéfì nípa ìdí tí ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ fi ń fọwọ́ ara wọn ba ìgbésí ayé ara wọn jẹ́ nípa lílo oògùn olóró, ṣíṣèṣekúṣe, àti híhu onírúurú ìwà réderède mìíràn? Sáàmù 36:1, 2 ṣàlàyé pé: “Àsọjáde ti ìrélànàkọjá sí ẹni burúkú ń bẹ nínú ọkàn-àyà rẹ̀; kò sí ìbẹ̀rùbojo fún Ọlọ́run ní iwájú rẹ̀. Nítorí pé ó ti gbé ìgbésẹ̀ fún ara rẹ̀ lọ́nà tí ó ṣe féfé jù ní ojú ara rẹ̀ tí yóò fi rí ìṣìnà ara rẹ̀, kí ó bàa lè kórìíra rẹ̀.” Nítorí wọn kò ní “ìbẹ̀rùbojo” tí ó gbámúṣé “fún Ọlọ́run,” ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ló ń tanra wọn jẹ́ nípa rírò pé, kò sí láburú kankan tí yóò ṣẹlẹ̀ báwọn bá hùwà àìtọ́. Ṣùgbọ́n o, nígbẹ̀yìn, ìlànà tí kò ṣeé yí padà yìí ti jẹ́ kó já jó irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lójú pé: “Nítorí ohun yòówù tí ènìyàn bá ń fúnrúgbìn, èyí ni yóò ká pẹ̀lú; nítorí ẹni tí ń fúnrúgbìn pẹ̀lú níní ẹran ara rẹ̀ lọ́kàn yóò ká ìdíbàjẹ́ láti inú ẹran ara rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ń fúnrúgbìn pẹ̀lú níní ẹ̀mí lọ́kàn yóò ká ìyè àìnípẹ̀kun láti inú ẹ̀mí.”—Gálátíà 6:7, 8.
‘Kíka Ọjọ́ Wa’
5, 6. (a) Èé ṣe tó fi yẹ kí àwọn ọ̀dọ́ ‘ka ọjọ́ wọn,’ kí ló sì túmọ̀ sí láti ṣe bẹ́ẹ̀? (b) Kí ló túmọ̀ sí láti ‘rántí Atóbilọ́lá Ẹlẹ́dàá wa’?
5 Báwo lo ṣe lè kẹ́sẹ járí nínú ìgbésí ayé rẹ, kí o sì “ká ìyè àìnípẹ̀kun”? Mósè kọ̀wé pé: “Ọjọ́ àwọn ọdún wa jẹ́ àádọ́rin ọdún; bí wọ́n bá sì jẹ́ ọgọ́rin ọdún nítorí àkànṣe agbára ńlá . . . Kíákíá ni yóò kọjá lọ, àwa yóò sì fò lọ.” (Sáàmù 90:10) Bóyá lo tiẹ̀ gbà pé o lè kú lọ́jọ́ kan. Ká sòdodo, ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ló ń hùwà bí ẹni pé kò sí nǹkan tíkú lè fi wọ́n ṣe. Ṣùgbọ́n, Mósè jẹ́ ká mọ òótọ́ náà tó dájú ṣáká pé, ìgbésí ayé ẹ̀dá kúrú jọjọ. Àní kò tiẹ̀ sí ìdánilójú kankan pé a lè lo àádọ́rin tàbí ọgọ́rin ọdún láyé. “Ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀” lè dá ẹ̀mí àwọn tó ṣì jẹ́ ọ̀dọ́, tí ara wọn sì le pàápàá, légbodò. (Oníwàásù 9:11) Tó bá wá rí bẹ́ẹ̀, báwo ni wàá ṣe lo ìgbésí ayé rẹ tó ṣeyebíye tóo ní nísinsìnyí? Mósè gbàdúrà pé: “Fi hàn wá, àní bí àwa yóò ṣe máa ka àwọn ọjọ́ wa ní irú ọ̀nà tí a ó fi lè jèrè ọkàn-àyà ọgbọ́n.”—Sáàmù 90:12.
6 Kí ló túmọ̀ sí pé kí o máa ka ọjọ́ rẹ? Ìyẹn kò túmọ̀ sí pé kí o máa ronú ṣáá lórí iye ọdún tóo lè lò lókè eèpẹ̀. Mósè ń gbàdúrà pé kí Jèhófà kọ́ àwọn ènìyàn Rẹ̀ ni bí wọn yóò ṣe lo àwọn ọjọ́ wọn tó ṣẹ́ kù lọ́nà tí yóò fi mú ọlá wá fún Ún. Ǹjẹ́ ò ń ka ọjọ́ ìwàláàyè rẹ—ìyẹn ni pé ṣé ò ń wo ọjọ́ kọ̀ọ̀kan bíi dúkìá ṣíṣeyebíye tí o lè lò láti mú ìyìn wá fún Ọlọ́run? Bíbélì fún àwọn ọ̀dọ́ ènìyàn ní ìṣírí yìí: “Mú pákáǹleke kúrò ní ọkàn-àyà rẹ, kí o sì taari ìyọnu àjálù kúrò ní ẹran ara rẹ; nítorí pé asán ni ìgbà èwe àti ìgbà ọ̀ṣìngín nínú ìgbésí ayé. Rántí Ẹlẹ́dàá rẹ Atóbilọ́lá nísinsìnyí, ní àwọn ọjọ́ tí o wà ní ọ̀dọ́kùnrin.” (Oníwàásù 11:10–12:1) Rírántí Ẹlẹ́dàá wa ju ká má kàn gbàgbé pé ó wà lọ. Nígbà tí ọ̀daràn kan níjelòó bẹ Jésù pé, “Rántí mi nígbà tí o bá dé inú ìjọba rẹ,” ó fẹ́ kí Jésù ṣe ju wíwulẹ̀ rántí orúkọ òun lásán. Ó fẹ́ kí Jésù gbégbèésẹ̀, ó fẹ́ kó jí òun dìde! (Lúùkù 23:42; fi wé Jẹ́nẹ́sísì 40:14, 23; Jóòbù 14:13.) Bákan náà, láti rántí Jèhófà ń béèrè ìgbésẹ̀, ó ń béèrè ṣíṣe ohun tí ó fẹ́. Ǹjẹ́ o lè fi gbogbo ẹnu sọ pé ò ń rántí Jèhófà?
Yẹra fún Ṣíṣe Ìlara Àwọn Oníwà Àìtọ́
7. Èé ṣe táwọn ọ̀dọ́ kan fi ń mọ̀ọ́mọ̀ gbàgbé Ẹlẹ́dàá wọn? Fúnni lápẹẹrẹ kan.
7 Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ló yàn láti gbàgbé Jèhófà nítorí wọ́n rò pé jíjẹ́ tí àwọn jẹ́ Ẹlẹ́rìí ti ká àwọn lọ́wọ́ kò jù. Arákùnrin kan ní Sípéènì rántí ìrònú tó ní nígbà tó wà ní ọ̀dọ́langba, ó wí pé: “Ayé fà mí mọ́ra gan-an nítorí ó dà bíi pé òtítọ́ nira jù, ó sì le koko jù. Ó béèrè jíjókòó, kíkẹ́kọ̀ọ́, lílọ sípàdé, síso táì mọ́rùn, gbogbo nǹkan wọ̀nyẹn kò sì bá mi lára mu.” Nígbà mìíràn, ǹjẹ́ o máa ń ronú pé ò ń pàdánù ohun kan nítorí tí ò ń sin Ọlọ́run? Bóyá yóò yà ọ́ lẹ́nu láti mọ̀ pé ọ̀kan lára àwọn tó kọ Bíbélì ní irú èrò bẹ́ẹ̀. Jọ̀wọ́, ṣí Bíbélì rẹ, kóo ka Sáàmù ìkẹtàléláàádọ́rin.
8. Èé ṣe tí Ásáfù fi “ṣe ìlara àwọn aṣògo”?
8 Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò sáàmù náà fínnífínní. Ẹsẹ kejì àtìkẹta sọ pé: “Ní tèmi, ẹsẹ̀ mi fẹ́rẹ̀ẹ́ yà kúrò lọ́nà, díẹ̀ ló kù kí a mú ìṣísẹ̀ mi yọ̀ tẹ̀rẹ́. Nítorí ti èmi ṣe ìlara àwọn aṣògo, nígbà tí mo rí àlàáfíà àwọn ènìyàn burúkú.” Gẹ́gẹ́ bí àkọlé rẹ̀ ti fi hàn, Ásáfù ló kọ sáàmù yìí. Akọrin, ọmọ Léfì lòún í ṣe, ó sì jẹ́ alájọgbáyé Dáfídì Ọba. (1 Kíróníkà 25:1, 2; 2 Kíróníkà 29:30) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ní àǹfààní àtàtà láti máa sin Ọlọ́run nínú tẹ́ńpìlì, ó “ṣe ìlara” àwọn ọkùnrin tí ń fi ìwà ta-ni-yóò-mú-mi tí wọ́n ń hù ṣògo. Ó dà bíi pé nǹkan gún régé fún wọn; ó sì jọ pé wọ́n lálàáfíà, ọkàn wọn sì balẹ̀. Lóòótọ́, àṣeyọrí tó jọ pé wọ́n ní ‘ré kọjá ohun tí ọkàn-àyà wọn lè rò!’ (Ẹsẹ 5, 7) Wọ́n a máa sọ̀rọ̀ “lọ́nà ìfẹgẹ̀” nípa itú tí wọ́n pa, ìyẹn ni pé, wọ́n a máa fi ṣakọ. (Ẹsẹ 8) ‘Wọ́n a gbé ẹnu wọn sí ọ̀run, ahọ́n wọn á sì máa rìn káàkiri ní ilẹ̀ ayé,’ láìka ẹnikẹ́ni sí—yálà ẹni tó wà lọ́run tàbí lórí ilẹ̀ ayé.—Ẹsẹ 9.
9. Báwo làwọn ọ̀dọ́ Kristẹni kan lóde òní ṣe lè ní irú èrò tí Ásáfù ní?
9 Bóyá a lè sọ irú ohun kan náà nípa àwọn ojúgbà rẹ nílé ẹ̀kọ́. O lè gbọ́ tí wọ́n ń fi ìṣekúṣe tí wọ́n fi ń dánra wò ṣògo, tí wọ́n ń sọ nípa àríyá oníwà ẹhànnà tí wọ́n lọ, tí wọ́n sì ń sọ nípa bí wọ́n ti fi ọtí àti oògùn kẹ́ra wọn bà jẹ́ tó. Nígbà tóo bá fi ìgbésí ayé onífàájì tí wọ́n sọ pé àwọn ń gbé wéra pẹ̀lú ọ̀nà tóóró tí o ní láti tọ̀ gẹ́gẹ́ bí Kristẹni, nígbà mìíràn o lè máa “ṣe ìlara àwọn aṣògo.” (Mátíù 7:13, 14) Ásáfù fúnra rẹ̀ dórí kókó kan tó fi polongo pé: “Dájúdájú lásán ni mo wẹ ọkàn-àyà mi mọ́, tí mo sì wẹ ọwọ́ mi ní àìmọwọ́mẹsẹ̀. Ìyọnu sì ń bá mi láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀.” (Ẹsẹ 13, 14) Bẹ́ẹ̀ ni, ó bẹ̀rẹ̀ sí bi ara rẹ̀ pé, kí làǹfààní sísin Ọlọ́run àti gbígbé ìgbésí ayé adúróṣinṣin.
10, 11. (a) Kí ló fà á tí Ásáfù fi yí èrò rẹ̀ padà? (b) Báwo ni àwọn oníwà àìtọ́ ṣe wà ní “orí ilẹ̀ yíyọ̀bọ̀rọ́”? Fúnni lápẹẹrẹ kan.
10 Ọpẹ́ ni fólúwa pé, Ásáfù kò wà ní ipò yìí fún ìgbà pípẹ́. Kò pẹ́ kó tó yé e pé ohun tó jọ àlàáfíà tí àwọn ènìyàn burúkú sọ pé àwọn ni, kì í ṣe àlàáfíà, ìtànjẹ lásán ni—àláfíafìa ni! Ó polongo pé: “Orí ilẹ̀ yíyọ̀bọ̀rọ́ ni ibi tí ìwọ gbé wọn kà. Ìwọ ti mú kí wọ́n ṣubú ní rírún wómúwómú. Ẹ wo bí wọ́n ti di ohun ìyàlẹ́nu bí ẹni pé ní ìṣẹ́jú kan! Ẹ wo bí wọ́n ti dé òpin wọn, tí a mú wọn wá sí òpin wọn nípasẹ̀ ìpayà òjijì!” (Ẹsẹ 18, 19) Ọ̀pọ̀ àwọn ojúgbà rẹ ló jẹ́ pé “orí ilẹ̀ yíyọ̀bọ̀rọ́” làwọn náà wà. Bó pẹ́, bó yá, wọn ó jèrè ìwà tí inú Ọlọ́run ò dùn sí tí wọ́n ń hù, èyí tó lè wá yọrí sí oyún ẹ̀sín, àìsàn tí ìṣekúṣe ń tàtaré rẹ̀, àní wọ́n lè fẹ̀wọ̀n jura tàbí kí wọ́n pàdánù ẹ̀mí wọn! Èyí tí yóò wá burú jù lọ ni pé, kí wọ́n di ọ̀tá Ọlọ́run.—Jákọ́bù 4:4.
11 Ọ̀dọ́ kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí ní Sípéènì rí i pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí. Nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́, ó gbé ìgbésí ayé méjì, ó kó wọnú ẹgbẹ́ àwọn ọ̀dọ́ tí kò ka òfin Ọlọ́run sí. Kò pẹ́ púpọ̀ tí ìfẹ́ ọ̀kan nínú wọn fi kó sí i lórí—ajoògùnyó sì lọ̀gbẹ́ni náà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀dọ́mọbìnrin náà kì í lo oògùn olóró, ṣùgbọ́n ó máa ń bá ọ̀rẹ́ rẹ̀ rà á. Ó tilẹ̀ sọ pé: “Èmi ni mo tilẹ̀ máa ń bá a gún abẹ́rẹ́ oògùn náà.” Ọpẹ́ ni fólúwá pé, ó ṣeé ṣe láti pe orí ọmọbìnrin yìí wálé, tí ó sì padà ní ìlera tẹ̀mí. Ṣùgbọ́n ẹ wo bí jìnnìjìnnì ti bò ó tó ní ọdún díẹ̀ lẹ́yìn ìgbà náà, nígbà tó wá gbọ́ pé àrùn éèdì ti pa ọ̀rẹ́kùnrin òun ọjọ́sí, tó jẹ́ ajoògùnyó. Òótọ́ ni, gẹ́gẹ́ bí onísáàmù náà ti sọ gan-an ló rí, “orí ilẹ̀ yíyọ̀bọ̀rọ́” làwọn tí kò ka òfin Ọlọ́run sí wà. Àwọn kan lè kú ní rèwerèwe nítorí ìgbésí ayé oníwà àìmọ́ tí wọ́n ń gbé. Ní tàwọn yòókù, àfi tí wọ́n bá yí padà, láìpẹ́ láìjìnnà wọn yóò dojú kọ “ìṣípayá Jésù Olúwa láti ọ̀run tòun ti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ alágbára nínú iná tí ń jó fòfò, bí ó ti ń mú ẹ̀san wá sórí àwọn tí kò mọ Ọlọ́run àti àwọn tí kò ṣègbọràn sí ìhìn rere nípa Jésù Olúwa wa.”—2 Tẹsalóníkà 1:7, 8.
12. Báwo ni ọ̀dọ́ kan ní Japan ṣe wá rí ìwà òmùgọ̀ tó wà nínú ṣíṣe ìlara àwọn oníwà àìtọ́?
12 Nígbà náà, ẹ wo bó ti jẹ́ ìwà òmùgọ̀ tó láti ṣe ìlara “àwọn tí kò mọ Ọlọ́run”! Ká sòótọ́, àwọn tí wọ́n mọ Jèhófà, tí wọ́n ní ìrètí wíwà láàyè títí láé ló yẹ ká jowú. Ọ̀dọ́ arákùnrin kan ní Japan wá mọ èyí. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́, òun pẹ̀lú “fẹ́ òmìnira sí i.” Ó ṣàlàyé pé: “Mo rò pé mò ń pàdánù nǹkan kan. Lẹ́yìn náà ni mo wá ronú nípa bí ayé mi ì bá ṣe rí bí n kò bá mọ òtítọ́. Mo ń ri ara mi bí ẹni tó wulẹ̀ gbé ayé fún àádọ́rin tàbí ọgọ́rin ọdún, lẹ́yìn náà tí ikú fòpin sí gbogbo rẹ̀. Ṣùgbọ́n Jèhófà nawọ́ ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun sí mi! Mímọ èyí ràn mí lọ́wọ́ láti mọrírì ohun tó wà níkàáwọ́ mi.” Àmọ́ ṣáá o, jíjẹ́ olóòótọ́ nígbà tí a bá wà láàárín àwọn tí kì í tẹ̀ lé òfin Ọlọ́run kò rọrùn. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ohun tí o lè ṣe láti dènà àwọn pákáǹleke yìí?
Ṣọ́ra fún Àwọn Tí Ò Ń Bá Rìn!
13, 14. Èé ṣe tó fi ṣe pàtàkì láti ṣe àṣàyàn tó bá dọ̀ràn àwọn tí ò ń bá rìn?
13 Lẹ́ẹ̀kan sí i, ẹ jẹ́ ká tún ṣàyẹ̀wò ọkùnrin tó kẹ́sẹ járí, tí a sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú Sáàmù 1:1-3: “Aláyọ̀ ni ènìyàn tí kò rìn nínú ìmọ̀ràn àwọn ẹni burúkú, tí kò sì dúró ní ọ̀nà àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, tí kò sì jókòó ní ìjókòó àwọn olùyọṣùtì. Ṣùgbọ́n inú dídùn rẹ̀ wà nínú òfin Jèhófà, ó sì ń fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ ka òfin rẹ̀ tọ̀sán-tòru. Dájúdájú, òun yóò dà bí igi tí a gbìn sẹ́bàá àwọn ìṣàn omi, tí ń pèsè èso tirẹ̀ ní àsìkò rẹ̀ èyí tí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ eléwé kì í sì í rọ, gbogbo nǹkan tí ó bá ń ṣe ni yóò sì máa kẹ́sẹ járí.”
14 Kọ́kọ́ ṣàkíyèsí pé, àwọn tí ò ń bá rìn ń kó ipa pàtàkì nínú ìgbésí ayé rẹ. Òwe 13:20 sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ní ìbálò pẹ̀lú àwọn arìndìn yóò rí láburú.” Èyí kò túmọ̀ sí pé o kò ní túra ká sí àwọn ọ̀dọ́ tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tàbí pé kóo mú wọn lọ́tàá, tàbí kóo máa fojú àbùkù wò wọ́n. Bíbélì rọ̀ wá láti nífẹ̀ẹ́ àwọn aládùúgbò wa, kí a sì “jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn.” (Róòmù 12:18; Mátíù 22:39) Àmọ́ ṣáá o, bíwọ náà bá wá ń ṣe wọléwọ̀de pẹ̀lú wọn jù, o lè wá rí i pé ìwọ pẹ̀lú “ń rìn ní ìmọ̀ràn” àwọn tí kì í tẹ̀ lé ọ̀pá ìdiwọ̀n Bíbélì.
Àǹfààní Kíka Bíbélì
15. Báwo ni àwọn ọ̀dọ́ ṣe lè mú ẹ̀mí ìyánhànhàn dàgbà fún kíka Bíbélì?
15 Onísáàmù náà tún ṣàkíyèsí pé ọkùnrin tó kẹ́sẹ́ járí náà ń ní inú dídùn sí kíka òfin Ọlọ́run ‘ní ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ tọ̀sán-tòru.’ (Sáàmù 1:1, 2) Lóòótọ́, Bíbélì kì í ṣe ìwé kan tó rọrùn láti kà, “àwọn ohun kan tí ó nira láti lóye” ń bẹ nínú rẹ̀. (2 Pétérù 3:16) Ṣùgbọ́n kò yẹ kí kíka Bíbélì di ohun tí à ń fagbára múni ká tó ṣe. Ó ṣeé ṣe láti “ní ìyánhànhàn fún wàrà aláìlábùlà” ìyẹn ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (1 Pétérù 2:2) Gbìyànjú láti ka díẹ̀ níbẹ̀ lóòjọ́. Báwọn kókó kan bá wà tí kò yé ọ, ṣe ìwádìí nípa rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ronú nípa ohun tóo kà. (Sáàmù 77:11, 12) Bó bá jẹ́ pé ìṣòro rẹ ni pé o kò lè pọkàn pọ̀, gbìyànjú láti kà á sókè “ní ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́.” Nígbà tó bá yá, ó dájú pé, ìfẹ́ rẹ fún kíka Bíbélì yóò pọ̀ sí i. Ọ̀dọ́ arábìnrin kan ní Brazil rántí pé: “Ó sábà máa ń jọ pé Jèhófà jìnnà sí mi. Ṣùgbọ́n lẹ́nu oṣù díẹ̀ sẹ́yìn, mo ti tẹ̀ síwájú sí i nínú ìdákẹ́kọ̀ọ́ mi àti kíka Bíbélì. Ní báyìí, mo gbà pé ìbátan mi pẹ̀lú Jèhófà ti lágbára sí i. Ó ti túbọ̀ wá jẹ́ ẹni gidi sí mi.”
16. Báwo la ṣe lè túbọ̀ máa gbádùn àwọn ìpàdé ìjọ?
16 Lílọ sí àwọn ìpàdé ìjọ tún ṣe pàtàkì fún ìdàgbàsókè rẹ nípa tẹ̀mí. Bóo bá “fiyè sí bí ẹ ṣe ń fetí sílẹ̀,” o lè túbọ̀ rí ọ̀pọ̀ ìṣírí gbà. (Lúùkù 8:18) Nígbà mìíràn, o ha máa ń ṣe ọ́ bíi pé ìpàdé kò dùn? Ó dáa, bi ara rẹ léèrè pé, ‘Kí ni mo ṣe láti mú kí ìpàdé dùn? Ǹjẹ́ mo fetí sílẹ̀? Ǹjẹ́ mo múra sílẹ̀? Ǹjẹ́ mo dáhùn?’ Ó ṣe tán, Bíbélì sọ fún wa pé kí a “ru ara wa sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà, . . . kí a máa fún ara wa ní ìṣírí lẹ́nì kìíní-kejì.” (Hébérù 10:24, 25) Láti ṣe èyí, o gbọ́dọ̀ lóhùn sí i! Àmọ́ ṣáá o, láti lè lóhùn sí ìpàdé o gbọ́dọ̀ ti múra rẹ̀ sílẹ̀. Ọ̀dọ́ arábìnrin kan sọ pé: “Ó máa ń rọrùn gidigidi láti lóhùn sí ìpàdé bóo bá ti múra sílẹ̀.”
Títọ Ọ̀nà Ọlọ́run Ló Ń Múni Kẹ́sẹ Járí
17. Báwo ni ẹni tó n fi aápọn ka Bíbélì ṣe “dà bí igi tí a gbìn sẹ́bàá àwọn ìṣàn omi”?
17 Síwájú sí i, onísáàmù náà ṣàpèjúwe ọkùnrin tó kẹ́sẹ járí gẹ́gẹ́ bí “igi tí a gbìn sẹ́bàá àwọn ìṣàn omi.” Àwọn ìṣàn omi náà ti lè máa tọ́ka sí àwọn kòtò ìbomirinlẹ̀ tí a ń lò láti bomi rin igi nínú ọgbà. (Aísáyà 44:4) Kíka Bíbélì lójoojúmọ́ dà bí dídi ẹni tí ara rẹ̀ kò ní lélẹ̀, bí kò bá rí irú orísun okun àti ìtura tí kì í yẹ̀ bẹ́ẹ̀. (Jeremáyà 17:8) Ojoojúmọ́ ni ìwọ yóò máa gba okun tóo nílò láti kojú àdánwò àti ìṣòro. Níwọ̀n ìgbà tóo sì ti kọ́ ìrònú Jèhófà, wàá ní ọgbọ́n tí o nílò láti ṣe ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu.
18. Kí ló lè mú kó dájú pé ọ̀dọ́ kan yóò kẹ́sẹ járí nínú sísin Jèhófà?
18 Nígbà mìíràn, sísin Jèhófà lè dà bí ohun tó ṣòro. Ṣùgbọ́n má ṣe rò pé ohun tó ṣòro, tí apá ẹni kò lè ká ló jẹ́. (Diutarónómì 30:11) Bíbélì ṣèlérí fún ọ pé ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀ ‘gbogbo nǹkan tí o bá ń ṣe ni yóò máa kẹ́sẹ járí’ níwọ̀n ìgbà tí olórí ète rẹ bá ti jẹ́ láti ṣe ìfẹ́ Jèhófà, kí o sì mú inú rẹ̀ dùn! (Òwe 27:11) Sì rántí o, kì í ṣe agbára rẹ nìkan lo fi ń ṣe é. Jèhófà àti Jésù Kristi ń tì ọ́ lẹ́yìn. (Mátíù 28:20; Hébérù 13:5) Wọ́n mọ pákáǹleke tí ò ń dojú kọ, wọn kò sì jẹ́ fi ọ́ sílẹ̀ láé. (Sáàmù 55:22) Ìtìlẹ́yìn látọ̀dọ̀ “gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ará” tún wà níbẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni ìtìlẹ́yìn àwọn òbí rẹ, ìyẹn bí wọ́n bá jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run. (1 Pétérù 2:17) Pẹ̀lú irú ìtìlẹ́yìn bẹ́ẹ̀, àti ìpinnu òun ìsapá rẹ, ìwọ yóò gbádùn ìgbésí ayé tó kẹ́sẹ járí, kì í ṣe nísinsìnyí nìkan, ṣùgbọ́n títí láéláé!
Ìbéèrè fún Àtúnyẹ̀wò
◻ Kí ni ojúlówó ìkẹ́sẹjárí?
◻ Èé ṣe táa fi nílò kí Jèhófà darí ìṣísẹ̀ wa?
◻ Báwo làwọn ọ̀dọ́ ṣe lè ‘ka ọjọ́ wọn’?
◻ Èé ṣe tó fi jẹ́ ìwà òmùgọ̀ láti máa ṣe ìlara àwọn oníwà àìtọ́?
◻ Báwo ni kíka Bíbélì déédéé àti wíwá sí ìpàdé déédéé ṣe lè ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ láti gbádùn ìgbésí ayé tó kẹ́sẹ járí?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Nítorí tí ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ kò ní “ìbẹ̀rùbojo” tí ó gbámúṣé “fún Ọlọ́run,” òun ló fà á tí wọ́n fi ń hùwà tó lè bayé wọn jẹ́
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
Àwọn ọ̀dọ́ kì í sábà rántí pé gbogbo ohun táwọn bá ṣe làwọn ó jèrè rẹ
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Kọ́ báa ṣe ń nífẹ̀ẹ́ kíka Bíbélì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Bóo bá ń lóhùn sí ìpàdé wàá lè gbádùn rẹ̀ dáadáa