ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w07 1/1 ojú ìwé 4-7
  • Bí Ayé Rẹ Ṣe Lè Dára

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bí Ayé Rẹ Ṣe Lè Dára
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Ìmọ̀ràn Àwọn Ẹni Burúkú”
  • Má Ṣe Jẹ́ Kí Ayé Darí Rẹ
  • Fífi Ìmọ̀ràn Ọlọ́run Sílò Máa Ń Jẹ́ Káyé Ẹni Dára
  • Bí Ayé Rẹ Ṣe Lè Dára
  • Kí Ló Ń Mú Káyé Yẹni
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Kẹ́sẹ Járí Nínú Ìgbésí Ayé Rẹ!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ǹjẹ́ O Ní Inú Dídùn Sí “Òfin Jèhófà”?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ó Fẹ́ Ká Ṣàṣeyọrí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
w07 1/1 ojú ìwé 4-7

Bí Ayé Rẹ Ṣe Lè Dára

BÁWỌN òbí ṣe ń bójú tó àwọn ọmọ wọn tí wọ́n sì fẹ́ káyé wọn dára náà ni Bàbá wa ọ̀run ṣe ń bójú tó wa tó sì fẹ́ káyé wa dára. Kò fọ̀rọ̀ wa ṣeré rárá, ìdí nìyẹn tó fi ń jẹ́ ká mọ ohun tó lè mú ká kẹ́sẹ járí àtohun tó lè mú ká kùnà. Kódà, nígbà tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa ẹni tó bá ń tẹ́tí sóhun tí Ọlọ́run ń sọ, ó sọ ọ́ ni kedere pé: “Gbogbo nǹkan tí ó bá ń ṣe ni yóò sì máa kẹ́sẹ járí.”—Sáàmù 1:3.

Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí, kí wá nìdí tí ọ̀pọ̀ èèyàn ò fi láyọ̀, tí wọn ò sì ní ìfọ̀kànbalẹ̀ nígbèésí ayé wọn? Tá a bá wo sáàmù yìí dáadáa, a ó mọ ìdáhùn sí ìbéèrè yìí, a ó sì tún mọ ọ̀nà táyé àwa náà fi lè dára.

“Ìmọ̀ràn Àwọn Ẹni Burúkú”

Onísáàmù kìlọ̀ fún wa nípa ewu tó wà nínú kéèyàn máa rìn nínú “ìmọ̀ràn àwọn ẹni burúkú.” (Sáàmù 1:1) Sátánì Èṣù ni olórí àwọn “ẹni burúkú.” (Mátíù 6:13) Ìwé Mímọ́ sọ fún wa pé òun ni “olùṣàkóso ayé yìí” àti pé “gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.” (Jòhánù 16:11; 1 Jòhánù 5:19) Abájọ tó fi jẹ́ pé èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn ìmọ̀ràn tá à ń gbọ́ nínú ayé lónìí ló ń gbé èrò ẹni burúkú yẹn yọ.

Irú ìmọ̀ràn wo làwọn ẹni burúkú máa ń gbani? Lápapọ̀, àwọn ẹni burúkú kì í bọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run. (Sáàmù 10:13) Ibi gbogbo la ti máa ń gbọ́ ìmọ̀ràn wọn tí kò bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu. Ohun táwọn èèyàn òde òní ń gbé lárugẹ ni “ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú àti fífi àlùmọ́ọ́nì ìgbésí ayé ẹni hàn sóde lọ́nà ṣekárími.” (1 Jòhánù 2:16) Àwọn ohun tá à ń gbọ́ lórí rédíò àti tẹlifíṣọ̀n nígbà gbogbo ni, “jayé orí ẹ.” Àwọn ilé iṣẹ́ jákèjádò ayé ń ná ohun tó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] bílíọ̀nù owó dọ́là lórí ìpolówó ọjà wọn lọ́dọọdún káwọn èèyàn lè máa ra ohun tí wọ́n ń ṣe jáde, yálà àwọn tó ń rà wọ́n nílò wọn tàbí wọ́n ò nílò wọn. Kì í ṣe pé ìpolówó ọjà yìí túbọ̀ ń mú káwọn èèyàn máa ra nǹkan sí i nìkan ni, àmọ́ ó tún ti mú káráyé yí èrò wọn padà nípa ẹni tí wọ́n kà sí ẹni táyé ẹ̀ dára.

Nítorí ìdí èyí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti wá ní àwọn ohun tó jẹ́ pé wọn ò lálàá rẹ̀ láwọn ọdún díẹ̀ sẹ́yìn, síbẹ̀ gbogbo ìgbà ló máa ń wù wọ́n láti túbọ̀ ní sí ohun tí wọ́n ti ní. Èrò wọn ni pé téèyàn ò bá làwọn nǹkan wọ̀nyí, kò lè láyọ̀, ayé rẹ̀ kò sì nítumọ̀. Irọ́ gbuu ni irú èrò yìí jẹ́, kò sì “pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Baba, ṣùgbọ́n ó pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ ayé.”—1 Jòhánù 2:16.

Ẹlẹ́dàá wa mọ ohun tó máa jẹ́ káyé wa nítumọ̀ gan-an. Ìmọ̀ràn rẹ̀ yàtọ̀ pátápátá sí “ìmọ̀ràn àwọn ẹni burúkú.” Nítorí náà, kéèyàn máa retí àtirí ìbùkún Ọlọ́run kó sì tún fẹ́ tọ ọ̀nà táyé ń tọ̀ láti ṣàṣeyọrí dà bíi kéèyàn máa gbìyànjú láti rìn ní ọ̀nà méjì tí kò bára mu. Ìyẹn ò tiẹ̀ lè ṣeé ṣe rárá ni. Abájọ tí Bíbélì fi kìlọ̀ fúnni pé: “Má ṣe mú ara rẹ bá àṣà ayé tí ó yí ọ ká mu.”—Róòmù 12:2,Today’s English Version.

Má Ṣe Jẹ́ Kí Ayé Darí Rẹ

Àwọn èèyàn inú ayé tí Sátánì ń darí máa ń gbìyànjú láti ṣe bíi pé àwọn fẹ́ kó dára fún wa. Àmọ́, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra. Rántí pé Sátánì fi ìmọtara-ẹni-nìkan tan obìnrin àkọ́kọ́, ìyẹn Éfà jẹ, kí ọwọ́ rẹ̀ lè tẹ ohun tó ń wá. Ó tún lo Éfà láti mú kí Ádámù pẹ̀lú dẹ́ṣẹ̀. Bákan náà ni Sátánì ń lo àwọn èèyàn lóde òní láti fúnni ní ìmọ̀ràn burúkú.

Bí àpẹẹrẹ, David, tá a mẹ́nu kàn nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, ní láti máa ṣiṣẹ́ sí i lẹ́yìn àkókò iṣẹ́, yóò sì máa rìnrìn àjò lọ́pọ̀ ìgbà nítorí iṣẹ́. David sọ pé: “Màá kúrò nílé láàárọ̀ Monday, màá sì padà dé lálẹ́ Thursday.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọ̀rẹ́ David, àwọn ẹbí rẹ̀, àtàwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ mọ̀ pé gbogbo wàhálà yìí ló ní láti ṣe kó tó lè dẹni ńlá láyé, síbẹ̀ wọ́n sọ fún un pé kó máa bá iṣẹ́ náà lọ fún àǹfààní ìdílé rẹ̀. Wọ́n ronú pé ìwọ̀nba ọdún díẹ̀ ló máa fi ṣe gbogbo wàhálà yẹn, tó bá sì yá, á dá iṣẹ́ ti ara rẹ̀ sílẹ̀. David ṣàlàyé pé: “Èrò wọn ni pé èyí á ṣe ìdílé mi láǹfààní gan-an nítorí pé owó táá máa wọlé fún mi á túbọ̀ pọ̀ sí i, nǹkan á túbọ̀ ṣẹnuure fún mi. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò ráyè dúró ti ìdílé mi, síbẹ̀ àwọn ọ̀rẹ́ mi sọ fún mi pé ohun tí mò ń ṣe fún ìdílé mi ò kéré.” Bíi ti David, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń ṣiṣẹ́ àṣekúdórógbó kí wọ́n lè máa fáwọn èèyàn wọn ní gbogbo ohun tí wọ́n lérò pé wọ́n nílò. Àmọ́, ǹjẹ́ títẹ̀lé irú ìmọ̀ràn yìí lè máyọ̀ wá? Kí ni ìdílé nílò ní ti gidi?

Ìgbà kan tí David rìnrìn àjò nítorí iṣẹ́ ló wá mọ ohun tí ìdílé rẹ̀ nílò. David sọ pé: “Mo bá ọmọ mi obìnrin tó ń jẹ́ Angelica sọ̀rọ̀ lórí tẹlifóònù, ohun tó sì sọ ni pé: ‘Dádì, kí ló dé tá a kì í fi í rí yín nílé?’ Ọ̀rọ̀ yẹn wọ̀ mí lára gan-an.” Ọ̀rọ̀ tí ọmọ rẹ̀ sọ yìí gan-an ló wá jẹ́ kó túbọ̀ dúró lórí ìpinnu rẹ̀ láti kọ̀wé fiṣẹ́ sílẹ̀. David pinnu láti fún ìdílé rẹ̀ lóhun tí wọ́n nílò jù lọ, ìyẹn òun fúnra rẹ̀.

Fífi Ìmọ̀ràn Ọlọ́run Sílò Máa Ń Jẹ́ Káyé Ẹni Dára

Kí la lè ṣe nípa àwọn ìlànà tó ń ṣini lọ́nà, tó wọ́pọ̀ gan-an nínú ayé yìí? Onísáàmù sọ fún wa pé ẹni tó kẹ́sẹ járí tó sì láyọ̀ ni ẹni tí ‘inú dídùn rẹ̀ wà nínú òfin Jèhófà, tó sì ń fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ ka òfin rẹ̀ tọ̀sán-tòru.’—Sáàmù 1:2.

Nígbà tí Ọlọ́run yan Jóṣúà ṣe olórí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, ó sọ fún un pé: “Máa fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ kà láti inú [Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run] ní ọ̀sán àti ní òru.” Bẹ́ẹ̀ ni o, kí Jóṣúà máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kò sì máa ṣe àṣàrò nínú rẹ̀ ṣe pàtàkì gan-an, àmọ́ ó tún ní láti “kíyè sára láti máa ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí a kọ sínú rẹ̀.” Àmọ́, kì í ṣe pé Bíbélì kíkà máa ṣàdédé mú kó dára fúnni o. Èèyàn gbọ́dọ̀ fi ohun tó ń kà níbẹ̀ sílò. Ọlọ́run sọ fún Jóṣúà pé: “Nígbà náà ni ìwọ yóò mú kí ọ̀nà rẹ yọrí sí rere, nígbà náà ni ìwọ yóò sì hùwà ọgbọ́n.”—Jóṣúà 1:8.

Fojú inú wo ọmọ kékeré kan tó ń rẹ́rìn-ín nígbà tí òbí rẹ̀ gbé e létan táwọn méjèèjì sì jọ ń ka ìtàn kan tí ọmọ náà fẹ́ràn dáadáa. Bí wọ́n tiẹ̀ ti ka ìtàn yìí lọ́pọ̀ ìgbà, síbẹ̀ gbogbo ìgbà tí wọ́n bá ń kà á ló máa ń dùn mọ́ wọn. Bákan náà, ẹni tó bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run á rí i pé Bíbélì kíkà lójoojúmọ́ máa ń dùn mọ́ni gan-an, nítorí pé àkókò téèyàn fi ń kà á jẹ́ àkókò rere téèyàn ń lò pẹ̀lú Bàbá rẹ̀ ọ̀run. Nípa títẹ̀lé ìmọ̀ràn àti ìtọ́sọ́nà Jèhófà, irú ẹni bẹ́ẹ̀ á “dà bí igi tí a gbìn sẹ́bàá àwọn ìṣàn omi, tí ń pèsè èso tirẹ̀ ní àsìkò rẹ̀ èyí tí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ eléwé kì í sì í rọ, gbogbo nǹkan tí ó bá ń ṣe ni yóò sì máa kẹ́sẹ járí.”—Sáàmù 1:3.

Kì í ṣe pé igi tí onísáàmù sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí ṣàdédé hù lójijì o. Ńṣe ni àgbẹ̀ kan rọra gbìn ín sẹ́bàá ìṣàn omi tó sì ń bójú tó o. Bákan náà ni Bàbá wa ọ̀run ṣe ń tún èrò wa ṣe tó sì ń tọ́ ọ síbi tó yẹ nípasẹ̀ ìmọ̀ràn tó wà nínú Ìwé Mímọ́. Ìyẹn ló máa jẹ́ káyé wa tòrò, tá a ó sì láwọn ànímọ́ tí Ọlọ́run fẹ́.

Àmọ́, “àwọn ẹni burúkú kò rí bẹ́ẹ̀.” Lóòótọ́, ó lè dà bíi pé nǹkan ṣẹnuure fún wọn fúngbà díẹ̀, àmọ́ ibi ló máa gbẹ̀yìn wọn. Wọn kò ní “dìde dúró nínú ìdájọ́.” Kàkà bẹ́ẹ̀, “ọ̀nà tí í ṣe ti àwọn ẹni burúkú yóò ṣègbé.”—Sáàmù 1:4-6.

Nítorí náà, má ṣe jẹ́ káyé darí rẹ, má sì ṣe fara wé ayé. Bó o bá tiẹ̀ mọ iṣẹ́ kan gan-an, tó o sì rí i pé o lè rọ́wọ́ mú nínú ayé, ṣọ́ra nípa bó o ṣe ń lo ẹ̀bùn tó o ní àti nípa bó o ṣe máa jẹ́ kí ayé lo àwọn ẹ̀bùn náà. Kéèyàn máa lé ọrọ̀ tó jẹ́ asán àti ìmúlẹ̀mófo lè jẹ́ kéèyàn “rọ” bí igi tí kò rómi mu. Àmọ́, àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run ló lè mú káyé ẹni nítumọ̀ kéèyàn sì láyọ̀.

Bí Ayé Rẹ Ṣe Lè Dára

Kí nìdí tó fi jẹ́ pé téèyàn bá tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Ọlọ́run, gbogbo ohun tó bá ń ṣe ni yóò yọrí sí rere? Àṣeyọrí nínú ayé yìí kọ́ ni onísáàmù ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ o. Àṣeyọrí ti èèyàn Ọlọ́run ní í ṣe pẹ̀lú ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, ohun tó bá sì jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run máa ń yọrí sí rere ṣáá ni. Jẹ́ ká wo bí títẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì ṣe lè mú káyé rẹ dára.

Ìdílé: Ìwé Mímọ́ gba àwọn ọkọ níyànjú pé kí wọ́n “máa nífẹ̀ẹ́ àwọn aya wọn gẹ́gẹ́ bí ara àwọn fúnra wọn,” ó sì sọ fún aya tó jẹ́ Kristẹni pé kó “ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún ọkọ rẹ̀.” (Éfésù 5:28, 33) Ó gba àwọn òbí níyànjú pé kí wọ́n máa wà pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn, kí wọ́n jọ máa rẹ́rìn-ín, kí wọ́n sì kọ́ wọn làwọn ohun tó ṣe pàtàkì nígbèésí ayé. (Diutarónómì 6:6, 7; Oníwàásù 3:4) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tún gba àwọn òbí níyànjú pé kí wọ́n “má ṣe máa sún àwọn ọmọ [wọn] bínú.” Táwọn òbí bá tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yìí, yóò rọrùn fáwọn ọmọ láti “jẹ́ onígbọràn sí àwọn òbí [wọn]” àti láti “bọlá fún baba àti ìyá [wọn].” (Éfésù 6:1-4) Tó o bá ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Ọlọ́run yìí, ayọ̀ á wà nínú ìdílé rẹ.

Àwọn ọ̀rẹ́: Ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ló máa ń wù láti lọ́rẹ̀ẹ́. Ọlọ́run dá wa lọ́nà tá a fi lè nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn káwọn náà sì nífẹ̀ẹ́ wa. Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé wọ́n gbọ́dọ̀ “nífẹ̀ẹ́ ara [wọn] lẹ́nì kìíní-kejì.” (Jòhánù 13:34, 35) Àwọn tá a lè fẹ́ràn ká sì fọkàn tán wà lára àwọn ọ̀rẹ́ wọ̀nyí, kódà àwọn tá a lè sọ ohun to wà nísàlẹ̀ ikùn wa fún wà lára wọn. (Òwe 18:24) Lékè gbogbo rẹ̀, tá a bá ń fi ìlànà Bíbélì sílò, a ó “sún mọ́ Ọlọ́run,” kódà àwa náà lè di “ọ̀rẹ́ Jèhófà” bíi ti Ábúráhámù.—Jákọ́bù 2:23; 4:8.

Ìgbésí Tó Nítumọ̀: Àwọn tó ń fayé wọn gbọ́ ti Ọlọ́run, tí wọn ò lé nǹkan tayé kiri làwọn táyé wọn nítumọ̀ lóòótọ́. Ìgbésí ayé wọn kò dá lórí ètò nǹkan ìsinsìnyí tí kò ṣeé gbára lé. Ohun tí wọ́n ń lé máa ń yọrí sí ojúlówó ayọ̀ tí kì í ṣá, nítorí pé ìdí téèyàn fi wà láàyè gan-an ni wọ́n gbé ohun tí wọ́n ń lé kà. Kí ló ń jẹ́ káyé ẹni nítumọ̀? “Bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́, kí o sì pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́. Nítorí èyí ni gbogbo iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe ti ènìyàn.”—Oníwàásù 12:13.

Ìrètí: Fífi Ọlọ́run ṣe Ọ̀rẹ́ yóò tún jẹ́ ká nírètí pé ọjọ́ ọ̀la á dára. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni níyànjú pé “kí wọ́n má ṣe gbé ìrètí wọn lé ọrọ̀ àìdánilójú, bí kò ṣe lé Ọlọ́run.” Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n óò “máa fi àìséwu to ìṣúra ìpìlẹ̀ tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ jọ fún ara wọn de ẹ̀yìn ọ̀la, kí wọ́n lè di ìyè tòótọ́ mú gírígírí.” (Tímótì 6:17-19) Ìyè tòótọ́ yìí yóò dé láìpẹ́, nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run bá mú Párádísè padà wá sórí ilẹ̀ ayé yìí.—Lúùkù 23:43.

Tó o bá ń fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò, kò túmọ̀ sí pé o ò ní níṣòro kankan o, àmọ́ wàá bọ́ lọ́wọ́ ọ̀pọ̀ ìdààmú ọkàn àti ìbànújẹ́ táwọn ẹni ibi máa ń fi ọwọ́ ara wọn fà. David tá a mẹ́nu kàn níṣàájú, àti ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn mìíràn ti wá rí i bí fífi àwọn ìlànà Bíbélì sílò ti ṣe pàtàkì tó. Lẹ́yìn tí David wá rí iṣẹ́ tí kò gba gbogbo àkókò rẹ̀ mọ́, ó sọ pé: “Mo dúpẹ́ pé àjọṣe àárín èmi àti aya mi àtàwọn ọmọ mi ti túbọ̀ dára sí i báyìí, mo tún dúpẹ́ pé ó ṣeé ṣe fún mi láti máa sin Jèhófà Ọlọ́run, tí mo sì tún jẹ́ alàgbà nínú ìjọ.” Abájọ tí ìwé sáàmù fi sọ nípa ẹni tó bá ń tẹ́tí sí ìmọ̀ràn Ọlọ́run pé: “Gbogbo nǹkan tí ó bá ń ṣe ni yóò sì máa kẹ́sẹ járí”!

[Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 6]

OHUN MÁRÙN-ÚN TÓ LÈ JẸ́ KÁYÉ RẸ DÁRA

1 Má ṣe jẹ́ káyé darí rẹ.

Sáàmù 1:1; Róòmù 12:2

2 Máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́ kó o sì máa ṣàṣàrò lórí rẹ̀.

Sáàmù 1:2, 3

3 Máa fi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò nígbèésí ayé rẹ.

Jóṣúà 1:7-9.

4 Di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run.

Jákọ́bù 2:23; 4:8

5 Bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́, kó o sì máa pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.

Oníwàásù 12:13

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Ǹjẹ́ ò ń ṣe àwọn ohun tó máa mú káyé rẹ dára?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́