Ta Lo Lè Sọ Pé Ayé Ẹ̀ Dára?
ÀWỌN kan gbà pé ọ̀gbẹ́ni kan tó ń jẹ́ Jesse Livermore ni oníṣòwò tó rọ́wọ́ mú jù lọ nínú gbogbo àwọn oníṣòwò tó wà ní àdúgbò kan tó ń jẹ́ Wall Street ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà, nítorí pé ó mọ béèyàn ṣe ń ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání gan-an nídìí iṣẹ́ òwò. Nípa bẹ́ẹ̀, ó ní ọrọ̀ tó pọ̀ gan-an. Aṣọ tó dára jù lọ ló máa ń wọ̀, inú ilé olówó ńlá kan tó ní yàrá mọ́kàndínlọ́gbọ̀n ló sì ń gbé. Ó tún ń lo ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tó gbayì jù lọ.
Bí ọ̀rọ̀ ti Davida náà ṣe fẹ́ rí nìyẹn. Òun ni igbákejì ọ̀gá àgbà ilé iṣẹ́ ńlá kan tí wọ́n ti ń ya àwòrán, ó sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ di ọ̀gá àgbà ọ̀kan lára àwọn ẹ̀ka ilé iṣẹ́ náà. Ó ti dájú pé ó máa di ọlọ́rọ̀, á sì lókìkí. Àmọ́, David dórí ìpinnu kan tó mú kó kọ̀wé fiṣẹ́ ọ̀hún sílẹ̀. Ó sọ pé: “Mo mọ̀ pé mi ò tún lè rí iṣẹ́ tó ń mówó ńlá wọlé bẹ́ẹ̀ mọ́.” Ṣé o rò pé àṣìṣe lohun tí David ṣe yìí?
Ọ̀pọ̀ ló gbà pé ẹni táyé rẹ̀ dára gbọ́dọ̀ lọ́rọ̀ kó sì gbajúmọ̀. Síbẹ̀, àwọn tó lọ́rọ̀ gan-an lè máà láyọ̀, ìgbésí ayé wọn sì lè máà nítumọ̀. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Ọ̀gbẹ́ni Livermore gan-an nìyẹn. Pẹ̀lú gbogbo ọrọ̀ tó ní, ìgbà gbogbo ló máa ń ní ìdààmú ọkàn, tí àjálù máa ń bá a, tínú rẹ̀ sì máa ń bà jẹ́. Ńṣe ló máa ń ro àròdùn ṣáá, gbogbo ìgbéyàwó tó ṣe ló forí ṣánpọ́n, àárín òun àtàwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin ò sì gún. Níkẹyìn, lẹ́yìn tó ti pàdánù èyí tó pọ̀ jù lọ nínú ọrọ̀ rẹ̀, ọjọ́ kan ló jókòó síbi tí wọ́n ti máa ń mutí ní òtẹ́ẹ̀lì olówó ńlá kan tó sì bẹ̀rẹ̀ sí í dárò gbogbo ohun tó ti pàdánù. Ló bá béèrè ìgò ọtí kan, ó fa ìwé kékeré kan tí wọ́n fi awọ ṣe ẹ̀yìn rẹ̀ yọ, ó sì kọ ọ̀rọ̀ ìdágbére sí ìyàwó rẹ̀. Bó ṣe mu ọtí rẹ̀ tán ló bọ́ sínú yàrá kan tí wọ́n ń kó nǹkan sí tí iná ibẹ̀ ò sì mọ́lẹ̀ dáadáa, ibẹ̀ ló ti yìnbọn pa ara rẹ̀.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé oríṣiríṣi nǹkan ló máa ń fà á táwọn èèyàn fi máa ń pa ara wọn, síbẹ̀ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọkùnrin yìí jẹ́ ká rí i pé òótọ́ lohun tí Bíbélì sọ pé: “Àwọn tí ó pinnu láti di ọlọ́rọ̀ . . . ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrora gún ara wọn káàkiri.”—1 Tímótì 6:9, 10.
Àfàìmọ̀ ni kó má ṣe pé àṣìṣe làwọn kan ń ṣe pé kéèyàn lówó bíi ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀, kó nípò láwùjọ, tàbí kéèyàn jẹ́ gbajúmọ̀ ló ń fi hàn pé ayé ẹnì kan dáa. Ǹjẹ́ o gbà pé ayé tiẹ̀ dáa? Kí ló mú ọ rò bẹ́ẹ̀? Kí ló mú kó dá ọ lójú pé ayé ẹ dáa? Kí lo fi ń pinnu ẹni táyé ẹ dáa? Nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí, a óò jíròrò ìmọ̀ràn tó ṣeé gbára lé tó ti mú ki ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ní ìbàlẹ̀ ọkàn. Ẹ jẹ́ ká wo ọ̀nà tí ayé tiẹ̀ náà fi le dáa.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí orúkọ rẹ̀ padà.