Ọkùnrin Kan Tó Mọyì Ìwàláàyè Tó sì Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn
ARÁKÙNRIN Daniel Sydlik, tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fún àkókò pípẹ́ parí iṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé lọ́jọ́ Tuesday, ọjọ́ kejìdínlógún, oṣù April, ọdún 2006. Ẹni ọdún mẹ́tàdínláàádọ́rùn-ún [87] ni, ó sì jẹ́ ọ̀kan lára ìdílé Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Brooklyn, ní ìpínlẹ̀ New York, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, fún ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgọ́ta ọdún.
Arákùnrin Dan, gẹ́gẹ́ báwọn tó sún mọ́ ọn ṣe máa ń pè é, wá sí Bẹ́tẹ́lì lọ́dún 1946. Ṣáájú ìgbà yẹn, ó ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe nílùú California, ó tún lo àkókò díẹ̀ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n nígbà Ogun Àgbáyé Kejì nítorí pé kò bá wọn jagun. Gbogbo ohun tójú rẹ̀ rí nígbà yẹn wà nínú ìtàn ìgbésí ayé rẹ̀ tó wà nínú Ile-Iṣọ Naa ti December 1, 1985. Àkòrí rẹ̀ ni “Wo Bi Ibadọrẹ Rẹ Ti Ṣe Iyebiye Tó, Óò Ọlọrun!”
Gbogbo èèyàn ló mọ Arákùnrin Sydlik sí èèyàn dáadáa tára rẹ̀ yá mọ́ọ̀yàn. Nígbà tó bá ń darí ẹ̀kọ́ ojoojúmọ́ tí ìdílé Bẹ́tẹ́lì máa ń ṣe láràárọ̀, ẹ̀mí rere tó ní àti bó ṣe mọrírì ìwàláàyè sábà máa ń hàn nínú ọ̀rọ̀ tó máa ń kọ́kọ́ sọ, á ní: “A dúpẹ́ pé a wà láàyè, a sì ń sin Ọlọ́run òtítọ́ àti alààyè.” Nínú àwọn àsọyé tó máa ń sọ, ó máa ń fáwọn èèyàn níṣìírí láti ní irú èrò tó ní yìí. Ó sọ àwọn àsọyé tó láwọn àkòrí bí “Aláyọ̀ ni Àwọn Èèyàn Tí Jèhófà Jẹ́ Ọlọ́run Wọn,” “Ẹ Máa Gbé Ayọ̀ Jèhófà Yọ,” “Ẹ Má Ṣe Pa Iná Ẹ̀mí,” àti “Ohun Tó Dára Jù Lọ Ṣì Ń Bọ̀.”
Lọ́dún 1970, Arákùnrin Sydlik fẹ́ Marina Hodson tó wá láti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ó sì pe ìyàwó rẹ̀ yìí ní “alátìlẹyìn tí Ọlọ́run fi ta mí lọ́rẹ.” Ó lé ní ọdún márùnlélọ́gbọ̀n táwọn méjèèjì fi jọ sin Jèhófà pa pọ̀.
Lákòókò tí Arákùnrin Sydlik wà ní Bẹ́tẹ́lì, ó sìn ní onírúurú ẹ̀ka, títí kan ẹ̀ka ìtẹ̀wé àti Ẹ̀ka Ìwé Kíkọ. Ó tún ṣiṣẹ́ ní iléeṣẹ́ rédíò ti Watchtower tá à ń pè ní WBBR. Nígbà tó di oṣù November, ọdún 1974, wọ́n yàn án sínú Ìgbìmọ̀ Olùdarí, ó sì bá ìgbìmọ̀ tó ń bójú tó Ọ̀ràn Òṣìṣẹ́ àti èyí tó ń bójú tó Ìwé Kíkọ ṣiṣẹ́ pọ̀.
Fún ohun tó lé lọ́gbọ̀n ọdún tí Arákùnrin Sydlik fi wà nínú Ìgbìmọ̀ Tó Ń Bójú Tó Ọ̀ràn Òṣìṣẹ́, ó hàn kedere pé ó nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn gan-an. Ó fi ohùn rẹ̀ tó máa ń bú gan-an gba ọ̀pọ̀ èèyàn níyànjú, gbogbo ìgbà ló sì máa ń sọ̀rọ̀ nípa àǹfààní ńláǹlà tá a ní pé à ń sin Jèhófà. Ó máa ń tẹnu mọ́ ọn pé kì í ṣe àwọn ohun téèyàn lè fojú rí ló máa ń fúnni ni ojúlówó ayọ̀, bí kò ṣe àjọṣe àárín àwa àti Jèhófà àti èrò wa nípa ìgbésí ayé.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ikú Arákùnrin Sydlik dun ìdílé Bẹ́tẹ́lì gan-an, àpẹẹrẹ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹni tó mọrírì ìwàláàyè tó sì nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn yóò máa ṣe wọ́n láǹfààní títí lọ. Ó dá wa lójú pé ó wà lára àwọn tí ìwé Ìṣípayá 14:13 sọ nípa wọn pé: “Aláyọ̀ ni àwọn òkú tí ó kú ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Olúwa láti àkókò yìí lọ. Bẹ́ẹ̀ ni, ni ẹ̀mí wí, kí wọ́n sinmi kúrò nínú àwọn òpò wọn, nítorí àwọn ohun tí wọ́n ṣe ń bá wọn lọ ní tààràtà.”