Ǹjẹ́ O Ní Inú Dídùn Sí “Òfin Jèhófà”?
“Aláyọ̀ ni ènìyàn tí . . . inú dídùn rẹ̀ wà nínú òfin Jèhófà.”—SÁÀMÙ 1:1, 2.
1. Kí nìdí tí inú àwa ìránṣẹ́ Jèhófà fi máa ń dùn?
JÈHÓFÀ ń tì wá lẹ́yìn, ó sì ń bù kún àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́. Lóòótọ́ la máa ń dojú kọ ọ̀pọ̀ àdánwò. Àmọ́, a tún máa ń ní ojúlówó ayọ̀. Èyí kò yà wá lẹ́nu o, torí pé “Ọlọ́run aláyọ̀” là ń sìn, ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ló sì ń mú kí ọkàn wa láyọ̀. (1 Tímótì 1:11; Gálátíà 5:22) Ìdùnnú jẹ́ ayọ̀ tòótọ́ téèyàn máa ń ní nígbà tó bá ń retí ohun rere kan tàbí nígbà tí ohun rere kan bá tẹ èèyàn lọ́wọ́. Ó sì dájú pé ẹ̀bùn rere ni Bàbá wa ọ̀rún máa ń fún wa. (Jákọ́bù 1:17) Abájọ tínú wa fi máa ń dùn!
2. Àwọn sáàmù wo la óò jíròrò?
2 Léraléra ní ìwé Sáàmù sọ̀rọ̀ nípa ayọ̀. Bí àpẹẹrẹ, Sáàmù kìíní àti ìkejì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ gan-an. Àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù Kristi ní àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ gbà pé Dáfídì Ọba Ísírẹ́lì ló kọ sáàmù kejì. (Ìṣe 4:25, 26) Òǹkọ̀wé tí a kò dárúkọ rẹ̀ tó kọ sáàmù kìíní bẹ̀rẹ̀ orin rẹ̀ onímìísí pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ tó sọ pé: “Aláyọ̀ ni ènìyàn tí kò rìn nínú ìmọ̀ràn àwọn ẹni burúkú.” (Sáàmù 1:1) Nínú àpilẹ̀kọ yìí àti èyí tó tẹ̀ lé e, ẹ jẹ́ ká wo ọ̀nà tí Sáàmù kìíní àti ìkejì gbà sọ àwọn ìdí tó fi yẹ ká máa láyọ̀.
Ohun Tó Ń Mú Kéèyàn Láyọ̀
3. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Sáàmù 1:1 sọ, kí làwọn ìdí bíi mélòó kan téèyàn Ọlọ́run fi jẹ́ aláyọ̀?
3 Sáàmù kìíní sọ ohun tó ń mú kéèyàn Ọlọ́run jẹ́ aláyọ̀. Bí onísáàmù náà ṣe ń kọrin, ó mẹ́nu kan ìdí bíi mélòó kan tó ń mú irú ayọ̀ bẹ́ẹ̀ wá nípa sísọ pé: “Aláyọ̀ ni ènìyàn tí kò rìn nínú ìmọ̀ràn àwọn ẹni burúkú, tí kò sì dúró ní ọ̀nà àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, tí kò sì jókòó ní ìjókòó àwọn olùyọṣùtì.”—Sáàmù 1:1.
4. Ipa ọ̀nà tó jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ wo ni Sekaráyà àti Èlísábẹ́tì tọ̀?
4 Tá a bá fẹ́ jẹ́ aláyọ̀ ní ti gidi, a gbọ́dọ̀ máa pa àwọn àṣẹ òdodo Jèhófà mọ́. Sekaráyà àti Èlísábẹ́tì, tí wọ́n ní àǹfààní aláyọ̀ láti di òbí Jòhánù Olùbatisí, “jẹ́ olódodo níwájú Ọlọ́run nítorí rírìn láìlẹ́bi ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo àṣẹ àti àwọn ohun tí òfin Jèhófà béèrè.” (Lúùkù 1:5, 6) A lè jẹ́ aláyọ̀ tá a bá tẹ̀ lé irú ipa ọ̀nà kan náà tá a sì kọ̀ jálẹ̀ láti “rìn nínú ìmọ̀ràn àwọn ẹni burúkú” tá ò sì jẹ́ kí ìmọ̀ràn búburú wọn darí wa.
5. Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún “ọ̀nà àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀”?
5 Tá a bá kọ èrò àwọn ẹni burúkú sílẹ̀, a ò ní máa “dúró ní ọ̀nà àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.” Ká sòótọ́, a ò tiẹ̀ ní máa lọ sáwọn ibi tí wọ́n sábà máa ń wà rárá, ìyẹn láwọn ibi tí wọ́n ti máa ń ṣe àwọn eré ìnàjú oníṣekúṣe tàbí láwọn ibi tí wọ́n ti máa ń hu ìwàkiwà. Bó bá ń ṣe wá bíi pé ká dara pọ̀ mọ́ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ nínú ìwà wọn tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu ńkọ́? Ẹ jẹ́ ká yáa gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ràn wá lọ́wọ́ ká lè ṣe ohun tó wà níbàámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ má ṣe fi àìdọ́gba so pọ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́. Nítorí àjọṣe wo ni òdodo àti ìwà àìlófin ní? Tàbí àjọpín wo ni ìmọ́lẹ̀ ní pẹ̀lú òkùnkùn?” (2 Kọ́ríńtì 6:14) Tá a bá gbára lé Ọlọ́run tá a sì jẹ́ “ẹni mímọ́ gaara ní ọkàn-àyà,” a ó kọ irú ẹ̀mí tí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ní àti ọ̀nà ìgbésí ayé wọn sílẹ̀, a ó sì ní èrò àti ìfẹ́ ọkàn mímọ́ gaara pẹ̀lú “ìgbàgbọ́ láìsí àgàbàgebè.”—Mátíù 5:8; 1 Tímótì 1:5.
6. Kí nìdí tá a fi ní láti ṣọ́ra fún àwọn olùyọṣùtì?
6 Tá a bá fẹ́ múnú Jèhófà dùn, ó dájú pé ‘a ò gbọ́dọ̀ jókòó ní ìjókòó àwọn olùyọṣùtì.’ Àwọn kan tiẹ̀ máa ń yọ ṣùtì sí pípa òfin Ọlọ́run mọ́ pàápàá, kódà láwọn “ọjọ́ ìkẹyìn” yìí, àwọn tó jẹ́ Kristẹni tẹ́lẹ̀ tí wọ́n ti di apẹ̀yìndà báyìí ti wá ń fi ẹ̀sín kún ìyọṣùtì wọn. Àpọ́sítélì Pétérù kìlọ̀ fún àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ pé: “Ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, . . . ẹ mọ èyí lákọ̀ọ́kọ́, pé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn olùyọṣùtì yóò wá pẹ̀lú ìyọṣùtì wọn, wọn yóò máa rìn ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́-ọkàn ti ara wọn wọn yóò sì máa wí pé: ‘Wíwàníhìn-ín rẹ̀ yìí tí a ti ṣèlérí dà? Họ́wù, láti ọjọ́ tí àwọn baba ńlá wa ti sùn nínú ikú, ohun gbogbo ń bá a lọ gẹ́gẹ́ bí ó ti rí láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìṣẹ̀dá.’” (2 Pétérù 3:1-4) Tí a kò bá ‘jókòó sí ìjókòó àwọn olùyọṣùtì,’ jàǹbá tó dájú pé ó máa bá wọn kò ní kàn wá.—Òwe 1:22-27.
7. Kí nìdí tó fi yẹ ká fi ọ̀rọ̀ inú Sáàmù 1:1 sọ́kàn?
7 Tí a kò bá kọbi ara sí àwọn ọ̀rọ̀ tó wà níbẹ̀rẹ̀ Sáàmù kìíní, ipò tẹ̀mí wa tí a ti ní nípasẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ lè di aláìlágbára mọ́. Kódà, a lè pàdánù rẹ̀ pátápátá. Ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ tó lè mú ká pàdánù ipò tẹ̀mí wa lè jẹ́ nípa títẹ̀lé ìmọ̀ràn àwọn ẹni burúkú. Lẹ́yìn náà ka bẹ̀rẹ̀ sí bá wọn kẹ́gbẹ́ déédéé. Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, a lè wá di aláìnígbàgbọ́ apẹ̀yìndà tó ń yọ ṣùtì. Láìsí àní-àní, bíbá àwọn ẹni burúkú dọ́rẹ̀ẹ́ lè gbin ẹ̀mí tí kò dára sí wa lọ́kàn, ó sì lè ba àjọṣe àárín àwa àti Jèhófà Ọlọ́run jẹ́. (1 Kọ́ríńtì 15:33; Jákọ́bù 4:4) Ẹ má ṣe jẹ́ ká fàyè gba ìyẹn láti ṣẹlẹ̀ sí wa láé!
8. Kí ni yóò ràn wá lọ́wọ́ láti pọkàn pọ̀ sórí àwọn nǹkan tẹ̀mí?
8 Àdúrà yóò ràn wá lọ́wọ́ láti pọkàn pọ̀ sórí àwọn nǹkan tẹ̀mí ká sì yẹra fún bíbá àwọn ẹni burúkú kẹ́gbẹ́. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun, ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́ kí ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run; àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà yín àti agbára èrò orí yín nípasẹ̀ Kristi Jésù.” Àpọ́sítélì náà gbà wá níyànjú pé ká máa ṣàyẹ̀wò àwọn nǹkan tó jẹ́ òótọ́, èyí tó jẹ́ ìdàníyàn ṣíṣe pàtàkì, èyí tó jẹ́ òdodo, èyí tó mọ́ níwà, èyí tó dára ní fífẹ́, èyí tí a sọ̀rọ̀ rẹ̀ dáadáa, èyí tó jẹ́ ti ìwà funfun, àti èyí tí ó yẹ fún ìyìn. (Fílípì 4:6-8) Ẹ jẹ́ ká ṣe ohun tí Pọ́ọ̀lù gbà wá nímọ̀ràn rẹ̀, ká máà jó àjórẹ̀yìn kí á má bàa dà bí àwọn ẹni burúkú yẹn.
9. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé à ń yẹra fún àwọn ìwà búburú, báwo la ṣe ń gbìyànjú láti ran onírúurú èèyàn lọ́wọ́?
9 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò fara mọ́ àwọn ìwà búburú, síbẹ̀ a máa ń fọgbọ́n wàásù fún àwọn èèyàn, bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe bá Fẹ́líìsì, Gómìnà Róòmù nì sọ̀rọ̀ “nípa òdodo àti ìkóra-ẹni-níjàánu àti ìdájọ́ tí ń bọ̀.” (Ìṣe 24:24, 25; Kólósè 4:6) A ń wàásù ìhìn rere Ìjọba náà fún onírúurú èèyàn, a sì ń bá wọn lò lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́. Ó dá wa lójú pé àwọn “tí wọ́n sì ní ìtẹ̀sí-ọkàn títọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun” yóò di onígbàgbọ́, wọ́n á sì ní inú dídún sí òfin Ọlọ́run.—Ìṣe 13:48.
Ó Ní Inú Dídùn sí Òfin Jèhófà
10. Kí ni yóò ràn wá lọ́wọ́ láti gbin èrò tí a kò ní gbàgbé sínú ọkàn wa láwọn ìgbà tá a bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́?
10 Ohun tí onísáàmù náà tún sọ nípa ẹni tí ó jẹ́ aláyọ̀ ni pé: “Inú dídùn rẹ̀ wà nínú òfin Jèhófà, ó sì ń fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ ka òfin rẹ̀ tọ̀sán-tòru.” (Sáàmù 1:2) Gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Ọlọ́run, a ní ‘inú dídùn sí òfin Jèhófà.’ Tó bá ṣeé ṣe, láwọn ìgbà tá a bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́ tá a sì ń ṣe àṣàrò, a lè “fi ohun jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́” kàwé, ká máa kàwé ọ̀hún síta. Ṣíṣe èyí nígbà tá a bá ń ka ibikíbi nínú Ìwé Mímọ́ yóò ràn wá lọ́wọ́ láti gbin èrò tí a kò ní gbàgbé sínú ọkàn wa.
11. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ka Bíbélì “tọ̀sán-tòru”?
11 “Ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ti gbà wá níyànjú láti máa ka Bíbélì lójoojúmọ́. (Mátíù 24:45) Nítorí fífẹ́ tá a fẹ́ túbọ̀ mọ̀ nípa ìsọfúnni tí Jèhófà ní fún aráyé, á dára ká máa ka Bíbélì “tọ̀sán-tòru,” àní, ká tiẹ̀ máa ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tá ò bá rí oorun sun lóru nítorí àwọn ìdí kan. Pétérù rọ̀ wá pé: “Gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ jòjòló tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ bí, ẹ ní ìyánhànhàn fún wàrà aláìlábùlà tí ó jẹ́ ti ọ̀rọ̀ náà, pé nípasẹ̀ rẹ̀ kí ẹ lè dàgbà dé ìgbàlà.” (1 Pétérù 2:1, 2) Ǹjẹ́ inú rẹ máa ń dùn sí Bíbélì kíkà lójoojúmọ́ kó o sì máa ṣe àṣàrò ní òru lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àtàwọn ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe? Ohun tí onísáàmù náà máa ń ṣe nìyẹn.—Sáàmù 63:6.
12. Kí la ó máa ṣe tá a bá ní inú dídùn sí òfin Jèhófà?
12 A kò lè ní ayọ̀ ayérayé tá ò bá ní inú dídùn sí òfin Ọlọ́run. Òfin náà jẹ́ pípé àti òdodo, a ó sì rí èrè ńlá tá a bá ń pa á mọ́. (Sáàmù 19:7-11) Jákọ́bù tó jẹ ọmọ ẹ̀yìn Jésù kọ̀wé pé: “Ẹni tí ó bá ń wo inú òfin pípé tí í ṣe ti òmìnira ní àwòfín, tí ó sì tẹpẹlẹ mọ́ ọn, ẹni yìí, nítorí tí kò di olùgbọ́ tí ń gbàgbé, bí kò ṣe olùṣe iṣẹ́ náà, yóò láyọ̀ nínú ṣíṣe é.” (Jákọ́bù 1:25) Tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ la ní inú dídùn sí òfin Jèhófà, ọjọ́ kan ò ní kọjá láìgbé àwọn nǹkan tẹ̀mí yẹ̀ wò. Láìsí àní-àní, a óò fẹ́ láti ‘wá inú àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run,’ a ó sì fi ire Ìjọba Ọlọ́run ṣáájú nínú ìgbésí ayé wa.—1 Kọ́ríńtì 2:10-13; Mátíù 6:33.
Ó Dà Bí Igi
13-15. Ọ̀nà wo la fi lè dà bí igi tá a gbìn sẹ́bàá orísun tí omi ti pọ̀?
13 Onísáàmù náà tún ṣàlàyé ẹni ìdúróṣánṣán náà síwájú sí i, ó ní: “Dájúdájú, òun yóò dà bí igi tí a gbìn sẹ́bàá àwọn ìṣàn omi, tí ń pèsè èso tirẹ̀ ní àsìkò rẹ̀ èyí tí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ eléwé kì í sì í rọ, gbogbo nǹkan tí ó bá ń ṣe ni yóò sì máa kẹ́sẹ járí.” (Sáàmù 1:3) Bíi ti gbogbo ẹ̀dá aláìpé yòókù, àwa tá à ń sin Jèhófà náà máa ń dojú kọ ìṣòro nínú ìgbésí ayé wa. (Jóòbù 14:1) Wọ́n lè ṣe inúnibíni sí wa, a sì lè dojú kọ àwọn àdánwò mìíràn tó ní í ṣe pẹ̀lú ìgbàgbọ́ wa. (Mátíù 5:10-12) Àmọ́, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run, ó ṣeé ṣe fún wa láti fara da àwọn àdánwò wọ̀nyí, gẹ́gẹ́ bí igi tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá ṣe lè dúró gbọn-in nígbà tí ẹ̀fúùfù líle bá ń fẹ́.
14 Igi tá a gbìn sẹ́bàá orísun omi kì í gbẹ dà nù nígbà ọ̀gbẹlẹ̀ tàbí nígbà ọ̀dá. Tá a bá jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run, okun wa yóò máa wá látinú Orísun kan tí kì í kùnà, ìyẹn ni Jèhófà Ọlọ́run. Ojú Ọlọ́run ni Pọ́ọ̀lù ń wò fún ìrànlọ́wọ́, ìyẹn ló mú kó sọ pé: “Mo ní okun fún ohun gbogbo nípasẹ̀ agbára ìtóye [Jèhófà] ẹni tí ń fi agbára fún mi.” (Fílípì 4:13) Nígbà tí ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà bá ń tọ́ wa sọ́nà, tó sì mẹ́sẹ̀ wa dúró nípa tẹ̀mí, a ò ní rẹ̀ dà nù láé, ká wá di aláìléso tàbí òkú nípa tẹ̀mí. A ń so èso rere nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, a sì ń fi àwọn èso ti ẹ̀mí Ọlọ́run hàn nínú ìgbésí ayé wa.—Jeremáyà 17:7, 8; Gálátíà 5:22, 23.
15 Nípa lílo ọ̀rọ̀ Hébérù tá a túmọ̀ sí “dà bí,” ńṣe ni onísáàmù náà ń ṣe àfiwé. Ó ń fi àwọn ohun méjì tó yàtọ̀ síra wọn wéra, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n jọ ní ànímọ́ pàtó kan. Èèyàn yàtọ̀ sí igi, àmọ́ ó hàn gbangba pé bí igi tá a gbìn sẹ́bàá orísun tí omi ti pọ̀ ṣe máa ń gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ ló rán onísáàmù náà létí aásìkí tẹ̀mí tí àwọn tí ‘inú dídùn wọn wà nínú òfin Jèhófà’ máa ń ní. Tá a bá ní inú dídùn sí òfin Ọlọ́run, a lè lo ọjọ́ púpọ̀ láyé bíi ti igi. Kódà, a lè wà láàyè títí láé.—Jòhánù 17:3.
16. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé ‘gbogbo ohun tá à ń ṣe ló ń kẹ́sẹ járí,’ báwo ló sì ṣe rí bẹ́ẹ̀?
16 Bá a ṣe ń tẹ̀ lé ipa ọ̀nà títọ́ ni Jèhófà ń ràn wá lọ́wọ́ láti fara da àwọn àdánwò àti ìṣòro tó ń yọjú. Inú wa ń dùn, a sì ń so èso rere nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. (Mátíù 13:23; Lúùkù 8:15) ‘Gbogbo nǹkan tá à ń ṣe ló ń kẹ́sẹ járí,’ nítorí pé ohun tó wà lórí ẹ̀mí wa jù lọ ni pé ká ṣe ìfẹ́ Jèhófà. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé gbogbo ète rẹ̀ ló máa ń kẹ́sẹ járí, tá a sì ní inú dídùn sí àwọn àṣẹ rẹ̀, à ń láásìkí nípa tẹ̀mí. (Jẹ́nẹ́sísì 39:23; Jóṣúà 1:7, 8; Aísáyà 55:11) Èyí máa ń rí bẹ́ẹ̀ àní nígbà tá a bá wà nínú ìpọ́njú pàápàá.—Sáàmù 112:1-3; 3 Jòhánù 2.
Ó Dà Bíi Pé Àwọn Ẹni Burúkú Ń Láásìkí
17, 18. (a) Kí ni onísáàmù náà fi àwọn ẹni burúkú wé? (b) Bí àwọn ẹni burúkú tiẹ̀ láásìkí nípa tara, kí nìdí tí wọn ò fi ni ààbò tó wà pẹ́ títí?
17 Ẹ ò ri pé ìgbésí ayé àwọn ẹni burúkú yàtọ̀ pátápátá sí ti àwọn olódodo! Ó lè dà bíi pé àwọn ẹni burúkú ń láásìkí nípa tara fúngbà díẹ̀, àmọ́ ẹdun arinlẹ̀ ni wọ́n nípa tẹ̀mí. Èyí hàn kedere nínú ohun tí onísáàmù náà tún sọ pé: “Àwọn ẹni burúkú kò rí bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n wọ́n dà bí ìyàngbò tí ẹ̀fúùfù ń gbá lọ. Ìdí nìyẹn tí àwọn ẹni burúkú kì yóò fi dìde dúró nínú ìdájọ́, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ kì yóò dìde dúró ní àpéjọ àwọn olódodo.” (Sáàmù 1:4, 5) Kíyè sí i pé onísáàmù náà sọ pé, “àwọn ẹni burúkú kò rí bẹ́ẹ̀.” Ohun tó ní lọ́kàn ni pé wọn ò dà bí àwọn èèyàn Ọlọ́run, tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ fi wé igi eléso tó máa wà títí lọ.
18 Bí àwọn ẹni burúkú tiẹ̀ ń láásìkí nípa tara, kò sí ààbò tó máa wà pẹ́ títí fún wọn. (Sáàmù 37:16; 73:3, 12) Wọ́n dà bí ọkùnrin ọlọ́rọ̀ tí kò lọ́gbọ́n nínú, èyí tí Jésù mẹ́nu kan nínú àpèjúwe kan nígbà tí wọ́n wá bá a pé kò bá wọn dá sí ọ̀ràn ogún. Jésù sọ fún àwọn tó wà níbẹ̀ pé: “Ẹ la ojú yín sílẹ̀, kí ẹ sì máa ṣọ́ra fún gbogbo onírúurú ojúkòkòrò, nítorí pé nígbà tí ẹnì kan bá tilẹ̀ ní ọ̀pọ̀ yanturu pàápàá, ìwàláàyè rẹ̀ kò wá láti inú àwọn ohun tí ó ní.” Jésù ṣàlàyé kókó yìí nípa sísọ pé oko ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan mú èso púpọ̀ jáde débi pé ó pinnu láti ya àwọn ilé tó máa ń tọ́jú nǹkan pa mọ́ sí lulẹ̀, kí ó sì kọ́ èyí tí ó tóbi tí yóò kó gbogbo ohun rere tó ní sí. Ọkùnrin náà wá fẹ́ máa jẹ, kó máa mu, kó sì máa gbádùn ara rẹ̀. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run sọ fún un pé: “Aláìlọ́gbọ́n-nínú, òru òní ni wọn yóò fi dandan béèrè ọkàn rẹ lọ́wọ́ rẹ. Ta ni yóò wá ni àwọn ohun tí ìwọ tò jọ pa mọ́?” Kí kókó yìí lè túbọ̀ ṣe kedere, Jésù wá fi kún un pé: “Bẹ́ẹ̀ ni ó máa ń rí fún ẹni tí ó bá ń to ìṣúra jọ pa mọ́ fún ara rẹ̀ ṣùgbọ́n tí kò ní ọrọ̀ síhà ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.”—Lúùkù 12:13-21.
19, 20. (a) Ṣàpèjúwe bí wọ́n ṣe ń pa ọkà láyé ọjọ́hun àti bí wọ́n ṣe ń fẹ́ ẹ. (b) Kí nìdí tá a fi fi àwọn ẹni burúkú wé èèpo ọkà?
19 Àwọn ẹni burúkú kò ní “ọrọ̀ síhà ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.” Nítorí èyí, ààbò tí wọ́n ní kò ju ti ìyàngbò lọ, ìyẹn èèpo ọkà. Nígbà tí wọ́n bá kórè ọkà láyé ọjọ́hun, wọ́n á gbé e lọ sí ilẹ̀ ìpakà, ìyẹn ibi pẹrẹsẹ tó sábà máa ń wà níbi òkè. Ibẹ̀ ni wọ́n á ti gbé òkúta tàbí irin tó ní eyín lé e lórí tí ẹranko kan á sì máa wọ́ ọ síwá sẹ́yìn láti pa ọkà náà, kí hóró inú rẹ̀ lè yọ kúrò nínú èèpo ẹ̀yìn rẹ̀. Lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n á fi ṣọ́bìrì ìfẹ́kà bù ú, kí afẹ́fẹ́ lè fẹ́ ẹ. (Aísáyà 30:24) Hóró náà á máa já bọ́ sórí ilẹ̀ ìpakà náà, atẹ́gùn á wá gbé pòròpórò ọkà náà sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan á sì fẹ́ èèpo rẹ̀ dà nù. (Rúùtù 3:2) Lẹ́yìn tí wọ́n bá kó ọkà náà sínú asẹ́ láti yọ àwọn òkúta kéékèèké àtàwọn ìdọ̀tí mìíràn kúrò, wọ́n á kó o pa mọ́ tàbí kí wọ́n lọ̀ ọ́. (Lúùkù 22:31) Àmọ́ èèpo rẹ̀ ti bá afẹ́fẹ́ lọ.
20 Gẹ́gẹ́ bí hóró ọkà ṣe máa ń já bọ́ sórí ilẹ̀ tí wọ́n á sì tọ́jú rẹ̀ pa mọ́ lẹ́yìn tí wọ́n bá ti fẹ́ èèpo rẹ̀ dà nù bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni àwọn olódodo yóò dúró nígbà tí a óò gbá àwọn ẹni burúkú dà nù. Láìsí àní-àní, inú wa dùn pé a ò ní gbúròó irú àwọn ẹni burúkú bẹ́ẹ̀ mọ́ láéláé. Lẹ́yìn tí àwọn ẹni burúkú wọ̀nyí bá ti kọjá lọ, àwọn tó ní inú dídùn sí òfin Jèhófà yóò wá rí ọ̀pọ̀ ìbùkún. Ní tòótọ́, àwọn tó jẹ́ onígbọràn èèyàn yóò rí ẹ̀bùn ìyè àìnípẹ̀kun gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀.—Mátíù 25:34-46; Róòmù 6:23.
A Bù Kún “Ọ̀nà Àwọn Olódodo”
21. Lọ́nà wo ni Jèhófà fi ‘mọ àwọn olódodo’?
21 Àwọn ọ̀rọ̀ tó kẹ́yìn Sáàmù kìíní sọ pé: “Jèhófà mọ ọ̀nà àwọn olódodo, ṣùgbọ́n ọ̀nà tí í ṣe ti àwọn ẹni burúkú yóò ṣègbé.” (Sáàmù 1:6) Báwo ni Ọlọ́run ṣe ń ‘mọ àwọn olódodo’? Tá a bá ń tọ ipa ọ̀nà títọ́, a lè ní ìdánilójú pé Baba wa ọ̀run ń wo bí a ṣe ń pa àwọn òfin òun mọ́, ó sì kà wá sí ìránṣẹ́ rẹ̀ tó tẹ́wọ́ gbà. Nígbà náà, a lè kó gbogbo àníyàn wa lé e, pẹ̀lú ìdánilójú pé ó bìkítà fún wa.—Ìsíkíẹ́lì 34:11; 1 Pétérù 5:6, 7.
22, 23. Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí àwọn ẹni burúkú àti àwọn olódodo?
22 “Ọ̀nà àwọn olódodo” yóò wà títí láé, àmọ́ àwọn ẹni burúkú tó kọ̀ láti gba ìbáwí yóò pa run nítorí ìdájọ́ tí Jèhófà yóò ṣe fún wọn. “Ọ̀nà” tàbí ipa ọ̀nà ìgbésí ayé wọn yóò sì pa run pẹ̀lú wọn. A lè ní ìfọ̀kànbalẹ̀ pé àwọn ọ̀rọ̀ Dáfídì yóò ṣẹ, ó sọ pé: “Ní ìgbà díẹ̀ sí i, ẹni burúkú kì yóò sì sí mọ́; dájúdájú, ìwọ yóò sì fiyè sí ipò rẹ̀, òun kì yóò sì sí. Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà. Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.”—Sáàmù 37:10, 11, 29.
23 Ayọ̀ wa á mà pọ̀ gan-an o, tá a bá fún wa láǹfààní àtigbé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé nígbà tí àwọn ẹni burúkú kò ní sí mọ́! Àwọn ọlọ́kàntútù àti olódodo yóò wá gbádùn àlàáfíà tòótọ́ nítorí pé wọn á máa ní inú dídùn nínú “òfin Jèhófà” ní gbogbo ìgbà. Àmọ́ kó tó dìgbà yẹn, a gbọ́dọ̀ pa “àṣẹ àgbékalẹ̀ Jèhófà” mọ́. (Sáàmù 2:7a) Àpilẹ̀kọ tí ó tẹ̀ lé e yóò ràn wá lọ́wọ́ láti rí ohun tí àṣẹ àgbékalẹ̀ yẹn jẹ́ àti ohun tó túmọ̀ sí fún wa àti fún gbogbo ìdílé aráyé.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Kí nìdí tí èèyàn Ọlọ́run fi ń láyọ̀?
• Kí ló ń fi hàn pé a ní inú dídùn sí òfin Jèhófà?
• Báwo ni ẹnì kan ṣe lè dà bí igi tí a bomi rin dáadáa?
• Báwo ni ọ̀nà olódodo ṣe yàtọ̀ sí ti ẹni burúkú?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]
Àdúrà yóò ràn wá lọ́wọ́ láti má ṣe máa bá àwọn ẹni burúkú kẹ́gbẹ́
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Kí nìdí tí olódodo fi dà bí igi?