Òdòdó Tẹ̀mí Hù ní Àfonífojì Ìpọntí
NÍ ỌDÚN gbọ́nhan sẹ́yìn, ìgbòkègbodò ayọnáyèéfín yọ́ bàbà, fàdákà, àti wúrà nísàlẹ̀ ilẹ̀ jíjìn lọ́hùn-ún. Ooru abẹ́lẹ̀ fipá ti ọ̀pọ̀ lára àwọn kùsà wọ̀nyí la àárín àwọn èésán ilẹ̀ já, ó sì gbá wọn jọ sí ibi tí a ń pè ní Àwọn Òkè Ńlá Mule nísinsìnyí ní ìhà àríwá Arizona, U.S.A. Ní 1877, Jack Dunn, alamí ọmọ ogun kan tí a gbà síṣẹ́ ní Fort Huachuca tí ń bẹ nítòsí, ń wá omi kiri, ó sì ṣàwárí ẹ̀rí nípa kùsà àmúṣọrọ̀ rẹpẹtẹ yìí. Ó mú oníṣòwò ìdáwọ́lé ìwakùsà kan, George Warren, wọnú àdéhùn àjọṣòwò, kí ó lè kófà ilẹ̀ kùsà náà.
George Warren gba ẹ̀tọ́ onílẹ̀ lórí ọ̀pọ̀ ibi tí ó gbà gbọ́ pé kùsà náà wà, ṣùgbọ́n pẹ̀lú àbòsí, kò jẹ́ kí alájọṣiṣẹ́ rẹ̀, Jack Dunn, mọ̀ nípa rẹ̀. Àwọn ẹ̀tọ́ onílẹ̀ wọ̀nyí ti lè mú kí Warren là, kí ó lu, ṣùgbọ́n, lábẹ́ ìdarí àpọ̀jù wisikí tí ó mu, pẹ̀lú ìwà òmùgọ̀, ó fi àwárí tí ó ti ṣe náà ta tẹ́tẹ́ lórí ìdíje kan, pé òún lè sáré ya ẹṣin kan sílẹ̀. Àmọ́ ṣáá, ó pàdánù gbogbo rẹ̀. Gbogbo àwọn ẹ̀tọ́ onílẹ̀ wọ̀nyí sì di ti Ibi Ìwakùsà Queen. La àwọn ọdún wọ̀nyẹn já, iṣẹ́ ìwakùsà rẹpẹtẹ́ ṣẹlẹ̀, tí ó mú ohun tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó igba ọ̀kẹ tọ́ọ̀nu bàbà pẹ̀lú àìmọye ìwọn wúrà àti fàdákà jáde wá láti Àwọn Òkè Ńlá Mule, ṣáájú kí ibi ìwakùsà náà tóó kógbá sílé ní 1975.
Wíwa kùsà nínú àpáta líle nílò àwọn awakùsà nínú àpáta líle. A kó àwọn wọ̀nyí wá láti England, Germany, Ireland, Ítálì, àti Serbia. Nítorí àwọn ìṣètò amóríyá tí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ibi ìwakùsà ń pèsè, àwọn awakùsà nínú àpáta líle tún jẹ́ àwọn òṣìṣẹ́kára awakùsà. Nítorí pé àwọn awakùsà wọ̀nyí jìnnà sí àwọn ìdílé wọn ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún ibùsọ̀, wọ́n tún di alámupiyè awakùsà—nítorí náà, olùdáwọ́lé ará Germany kán kọ́ ilé ìpọntí kan sítòsí ibi ìwakùsà náà. Àwọn ilé ìpọntí máa ń pọn ọtí tí kò gba wàhálà púpọ̀ ṣáájú mímu. Ọ̀pọ́ máa ń fẹ́ láti mu ún ní tútù nini, nínú àyíká títura, àti pẹ̀lú eré ìnàjú díẹ̀. Nítorí náà, wọ́n kọ́ ọ̀pọ̀ ilé ọtí sí òpópó kan nítòsí ilé ìpọntí náà. Àwọn òṣìṣẹ́kára, alámupiyè, awakùsà nínú àpáta líle ló kún inú wọn. Ìpèsè eré ìnàjú wà, ìyẹn ìṣe kárùwà àti tẹ́tẹ́ títa, pa pọ̀ pẹ̀lú ọtí líle—àdàlù tó lè tanná ran ìjọ̀ngbọ̀n. Òpópó yìí ni a wáá mọ̀ sí Àfonífojì Ìpọntí, ó sì lókìkí pé ó léwu ju ìlú Tombstone oníwà ipá, tí ó wà ní 40 kìlómítà péré, lápá ìsàlẹ̀ ọ̀nà náà, lọ.
Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn awakùsà náà ṣègbéyàwó, wọ́n sì kọ́lé tí ìdílé wọn yóò máa gbé. Àwọn awakùsà láti England kọ́ irú ilé tí àwọn awakùsà ọ̀rúndún kọkàndínlógún tí wọ́n jẹ́ ará England lè gbé inú rẹ̀; àwọn tí wọ́n wá láti Serbia, kọ́ ilé awakùsà ará Serbia; àwọn ti Germany kọ́ ti ará Germany; àwọn ti Ítálì kọ́ ti ará Ítálì; àwọn ti Ireland sì kọ́ ti ará Ireland. Wọ́n tẹ ìlú ìpìlẹ̀ náà, ògbólógbòó ìlu Bisbee, dó sí ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ ara òkè àfonífojì olómi kan, níbikíbi tí ó bá ṣeé ṣe láti gbẹ́ ara ilẹ̀ alápàáta náà. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, àgbájọ ilé aláìlẹ́gbẹ́ yìí wáá di ibùgbé àwọn ènìyàn tí ó lé ní 20,000, tí ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọ́n jẹ́ awakùsà àti ìdílé wọn, ó sì ń fa àwọn arìnrìn àjò afẹ́ jákèjádò ayé mọ́ra nísinsìnyí. Wọ́n sọ ìlú náà ní Bisbee tí ó jẹ́ orúkọ ọkùnrin kan tí ó fi owó ńlá dókòwò lórí ìwakùsà náà, ṣùgbọ́n tí kò yọjú sí ìlú tí ń jẹ́ orúkọ rẹ̀ ní gidi rí.
Bí ìlú náà ti ń gbilẹ̀ sí i ni iye ilé ọtí ń pọ̀ sí i ní Àfonífojì Ìpọntí. Nígbà kan, àdúgbò òró ilé méjì kán ní ilé ọtí tí ó lé ní 30, agbègbè ńlá kan tí àwọn kárùwà ti ń ṣiṣẹ́ sì tún gbalẹ̀ lápá òkè àfonífojì náà.
Àwọn ìdílé Ẹlẹ́rìí mélòó kan kó lọ sí Bisbee ní nǹkan bí ọdún 1950. Ìwàásù wọ́n ṣamọ̀nà sí ìdásílẹ̀ ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan, tí ó pọ̀ débi tí ó fi ní mẹ́ḿbà 12 ní 1957. Wọ́n nílò ibì kan láti máa pàdé, nítorí náà, wọ́n háyà ọ̀kan tí apá wọ́n ká—iwájú ilé ìtajà kan ní Àfonífojì Ìpọntí, lódì kejì òpópó tí ó wá láti ilé ọtí St. Elmo. Wọ́n ní àwọn ìṣòro mélòó kan pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ń lọ sí àwọn ilé iṣẹ́ oníwà pálapàla tí ó yí wọn ká. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ọ̀mùtí kan ń fẹsẹ̀ palẹ̀ wọlé nígbà tí ìpàdé ìrọ̀lẹ́ náà ń lọ lọ́wọ́, ṣùgbọ́n tí yóò wulẹ jókòó sọ́wọ́ ẹ̀yìn, tí yóò sì máa tẹ́tí sílẹ̀—àwọn kán tilẹ̀ máa ń ṣètọrẹ owó kí wọ́n tóó lọ.
Bí àkókò ṣe ń lọ, ìjọ náà ra ilẹ̀ fún Gbọ̀ngàn Ìjọba kan—ní kìlómítà 11 sí Àfonífojì Ìpọntí àti àyíká oníwà pálapàla rẹ̀. Wọ́n kọ́ gbọ̀ngàn náà, wọ́n sì yà á sí mímọ́ ní 1958. Wọ́n ti ṣe àtúnṣe àti ìmúgbòòrò ilé náà nígbà mẹ́ta, ó sì ń kájú àìní ìjọ náà dáradára síbẹ̀.
Nígbà tí àwọn ibi ìwakùsà náà kógbá sílé ní 1975, ìlú náà fẹ́rẹ̀ẹ́ tú. Àwọn awakùsà àti ìdílé wọ́n kó lọ sí àwọn ìlú tí ibi ìwakùsà wọ́n ṣì ń báṣẹ́ lọ. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn olùgbé tí ó kù jẹ́ àwọn awakùsà tí ó ti fẹ̀yìn tì àti ìdílé wọn.
Àfonífojì Ìpọntí olókìkí wulẹ̀ jẹ́ ibi ìbẹ̀wò fún àwọn arìnrìn àjò afẹ́ nísinsìnyí ni. Ilé ọtí kan ṣoṣo ló wà níbẹ̀, ilé ìpọntí náà sì ti di ilé àrójẹ ìdílé báyìí. Wọ́n ti wó agbègbè ìṣiṣẹ́ àwọn kárùwà náà palẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, a ṣì lè rí àpẹẹrẹ rẹ̀ lára àwọn ọgbà tí wọ́n fi yí àwọn ilé kan ní agbègbè náà ká. Àwọn irin bẹ́ẹ̀dì tó ti dógùn-ún ni wọ́n fi ṣe wọ́n. Àfonífojì Ìpọntí tí ó kún fún ìwà pálapàla nígbà kan rí náà wulẹ̀ jẹ́ ibi àràmàǹdà kan tí ń fa ọkàn ìfẹ́ àwọn ọlọ́finntó mọ́ra nísinsìnyí ni.
Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, ìjọ náà ní akéde 48, ó sì ń gbèrú sí i. Ìwàásù láti ilé dé ilé ń gbádùn mọ́ni gan-an. A ń ṣalábàápàdé àwọn awakùsà tí ó ti fẹ̀yìn tì, tí wọ́n wá láti England, Germany, Ireland, Ítálì, àti Serbia níbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, àti ọ̀pọ̀ oníṣẹ́ ọnà, tí díẹ̀ lára wọn ń ṣàfihàn iṣẹ́ wọn níwájú ẹnu ọ̀nà àbáwọlé olórùle wọn.
Apá kan ìdàgbàsókè náà jẹ́ nítorí pé obìnrin kan tí ó ti máa ń lọ sí ilé ọtí St. Elmo, ilé ọtí aláriwo kan ṣoṣo tó kù ní Àfonífojì Ìpọntí, kò lọ síbẹ̀ mọ́. Julie ló ń jẹ́. Julie kò wulẹ̀ ń lọ síbẹ̀ ṣáá, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn oníbàárà aláriwo jù lọ níbẹ̀. Ó máa ń lọ́wọ́ sí gbogbo onírúurú eré ìnàjú oníwà pálapàla tí wọ́n ń ṣe níbẹ̀, pa pọ̀ pẹ̀lú ìjà àtìgbàdégbà, nígbà míràn, ó máa ń jẹ́ pẹ̀lú àwọn ọkùnrin. Ìhìn iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fa Julie mọ́ra nítorí ìyàtọ̀ híhàn gbangba tí ó ń rí lára àwọn ènìyàn tí ń wá sẹ́nu ọ̀na rẹ̀. Julie ní láti ṣe àwọn ìyípadà pípabambarì, èyí sì gba ọ̀pọ̀ ọdún, ṣùgbọ́n nísinsìnyí, òún jẹ́ ògbóṣáṣá, Ẹlẹ́rìí tí a ti batisí. Ọkọ rẹ̀ àti àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́ta pẹ̀lú ń wá sí àwọn ìpàdé déédéé, wọ́n sì ń tẹ̀ síwájú.
Bisbee di ìlú nítorí àwọn ohun àmúṣọrọ̀ tí ó kóra jọ síbẹ̀ ní ọdún gbọ́nhan sẹ́yìn. Àwọn ènìyàn kò wá ìyẹn mọ́, ṣùgbọ́n ọ̀pọ wọn ń wá ohun àmúṣọrọ̀ tòótọ́, ìmọ̀ Ọlọ́run tòótọ́ náà, Jèhófà, àti Ìjọba rẹ̀. Ipò tí ó yí ògbólógbòó Gbọ̀ngàn Ìjọba tí ó wà ní Àfonífojì Ìpọntí ká jẹ́ ti ìwà pálapàla tí ó díbàjẹ́ gan-an, ṣùgbọ́n òdòdo tẹ̀mí gbèrú nínú gbọ̀ngàn yẹn. Lára àwọn akéde 12 tí ó pàdé pọ̀ nínú ògbólógbòó gbọ̀ngàn náà níbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, 7 jẹ́ aṣáájú ọ̀nà déédéé. Àwọn ọmọdé méje wà níbẹ̀ pẹ̀lú. Yóò jọ pé àyíká tẹ̀mí rere tí àwùjọ kékeré onítara yìí ní nínú gbọ̀ngàn náà lágbára ju àyíká oníwà pálapàla tí ó wà lóde lọ.
Mẹ́fà lára àwọn ọmọ wọ̀nyí kó wọnú onírúurú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún gẹ́gẹ́ bí àwọn òjíṣẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà. John Griffin lọ sí Watchtower Bible School of Gilead. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí lẹ́nu iṣẹ́ ìsin míṣọ́nnárì mọ́, ó ṣì ń ṣiṣẹ́ sin Jèhófà gẹ́gẹ́ bí alàgbà kan ní orílẹ̀-èdè tí a pínṣẹ́ yàn án sí, Costa Rica. Ẹ̀gbọn rẹ̀ obìnrin, Carolyn (tí ń jẹ́ Jasso nísinsìnyí), jẹ́ aṣáájú ọ̀nà déédéé ní Sierra Vista, Arizona. Nancy Pugh pẹ̀lú lọ sí Gilead, ó sì ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì ní Chile, ó sì wà níbẹ̀ síbẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe míṣọ́nnárì mọ́. Ẹ̀gbọn rẹ̀ ọkùnrin, Peter, ṣe aṣáájú ọ̀nà, ó sì lọ sí Sípéènì láti ṣiṣẹ́ sìn níbi tí àìní wà. Susan àti Bethany Smith ti jẹ́ aṣáájú ọ̀nà déédéé ní Bisbee fún àpapọ̀ 50 ọdún fún àwọn méjèèjì, wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ sìn níbẹ̀ síbẹ̀.
Ní tòótọ́, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run “ń sa agbára,” àní títí dé mímú òdòdo tẹ̀mí gbèrú ní Àfonífojì Ìpọntí. (Hébérù 4:12)—A kọ ọ́ ránṣẹ́.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Gbọ̀ngàn Ìjọba náà wà ní àgbékà òkè ilé yìí tẹ́lẹ̀