Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
May 8, 2005
Ibo Lọ̀rọ̀ Fíìmù Ń Lọ?
Ìṣekúṣe àti ìwà ipá rẹpẹtẹ tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń wò nínú fíìmù kò bá wọn lára mu. Báwo lo ṣe lè fọgbọ́n yan irú fíìmù tí ìdílé rẹ á wò, ìyẹn bẹ́ ẹ bá máa wò ó rárá?
3 Fíìmù Wo Ni Wọ́n Máa Gbé Jáde Lọ́tẹ̀ Yìí?
4 Bí Wọ́n Ṣe Ń sọ Ìtàn Di Fíìmù
10 Irú Fíìmù Wo Ni Wàá Máa Wò?
17 Ta Ni “Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà”?
20 “Àwọn Tí A Ń Pè Ní ‘Ọlọ́run’”
22 Ohun Tí “Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà” Ṣèlérí
26 Bí Àpárá Ṣe Lè Ran Aláìsàn Lọ́wọ́
31 Ṣé Ó Yẹ Ká Máa LO Orúkọ Ọlọ́run?
32 Àwọn Ọ̀dọ́ Ń wá Ìdáhùn Sí Ìbéèrè Wọn
Ṣó Yẹ Kéèyàn Máa Lo Ère Nínú Ìjọsìn? 24
Lílo oríṣiríṣi àwòrán àti ère nínú ìjọsìn wọ́pọ̀ gan-an nínú ọ̀pọ̀ ẹ̀sìn. Kí ni Bíbélì sọ nípa lílo ère tàbí àwòrán nínú ìjọsìn?
“Ṣé Mo Lè Rẹ́ni Fẹ́ Lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì?” 28
Ọ̀pọ̀ olólùfẹ́ ló jẹ́ pé orí Íńtánẹ́ẹ̀tì ni wọ́n ti kọ́kọ́ pàdé ara wọn. Kí ló mú kó máa wu àwọn èèyàn kan láti máa wá olólùfẹ́ lọ sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì? Àwọn ewu wo ló wà nídìí ẹ̀?
[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 2]
Àwòrán tí Boris Subacic/AFP/Getty Images yà