Ṣé Ó Ṣeé Ṣe Kí Ayọ̀ Jọba Nínú Ìdílé?
Léṣìí, abiyamọ kan tí kò tí ì dàgbà púpọ̀ kọ̀wé sí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Mẹ́síkò, ó lóun fẹ́ ìrànlọ́wọ́ lórí bí ayọ̀ á ṣe jọba nínú ìdílé òun. Ó ṣàlàyé pé òun máa ń gbádùn nǹkan tóun ń kà nínú ìwé ìròyìn Jí!, ó sì fi kún un pé:
“Ó ti tọ́dún mẹ́ta báyìí tí mo ti wọlé ọkọ, mo sì ń fẹ́ ìmọ̀ràn àti àbá lórí ohun tí mo lè ṣe tí ìdílé mi á fi máa dùn yùngbà. Èmi àtọkọ mi bí ọmọkùnrin làǹtìlanti kan lọ́dún méjì sẹ́yìn, mo sì fẹ́ kọ́ ọ débi tó fi máa wúlò tó bá dàgbà.”
Ìyá àbúrò yìí ti gbọ́ nípa ìwé Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé ó sì kọ̀wé pé òun fẹ́ ẹ̀dà kan. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ló ti sọ bákan náà. Ọ̀pọ̀ ló ti ròyìn bí ìwé náà ṣe ran àwọn lọ́wọ́ tó lẹ́yìn tí wọ́n kà á. Lára àwọn àkórí téèyàn á rí ẹ̀kọ́ àtàtà kọ́ nínú wọn níbẹ̀ ni “Kọ́ Ọmọ Rẹ Láti Ìgbà Ọmọdé Jòjòló,” “Dáàbò Bo Ìdílé Rẹ Lọ́wọ́ Agbára Ìdarí Apanirun,” àti “Jẹ́ Kí Àlàáfíà Jọba Nínú Agbo Ilé Rẹ.”
Bó o bá fẹ́ gba ẹ̀dà kan ìwé Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé, o lè kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ládùúgbò rẹ. Bó o bá fẹ́ kí ẹnì kan wá ọ wá, jọ̀wọ́ kọ̀wé sínú fọ́ọ̀mù tó wà lójú ewé yìí kó o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tá a kọ síbẹ̀ tàbí sí àdírẹ́sì tó bá yẹ lára èyí tá a tò sójú ewé 5 nínú ìwé ìròyìn yìí.
□ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ wá máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.