“Àpéjọ Àgbègbè “Máa Tọ Kristi Lẹ́yìn!” Ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà
Ọ̀wọ́ àwọn àpéjọ àgbègbè ọlọ́jọ́ mẹ́ta yìí ti bẹ̀rẹ̀ lóṣù May, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, yóò sì máa bá a nìṣó títí di ọdún 2008 ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún orílẹ̀-èdè kárí ayé. Lọ́pọ̀ ibi tí àpéjọ náà ti máa wáyé, orin la ó fi bẹ̀rẹ̀ ní agogo mẹ́sàn-án géérégé ní òwúrọ̀ Friday. Ńṣe ni ọjọ́ àpéjọ kọ̀ọ̀kan á dá lórí Jésù.
Ẹṣin ọ̀rọ̀ ti ọjọ́ Friday ni “Tẹjú Mọ́ Olórí Aṣojú àti Aláṣepé Ìgbàgbọ́ Wa, Jésù.” (Hébérù 12:2) Kókó ọ̀rọ̀ tá a ó fi kíni káàbọ̀ sípàdé ni “Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Máa Tọ ‘Kristi’ Lẹ́yìn?” Àpínsọ àsọyé alápá mẹ́ta tá a máa gbọ́ ni “Bó O Bá Fẹ́ Túbọ̀ Lóye Ohun Tí Jésù Ṣe—Kẹ́kọ̀ọ́ Nípa Mósè, Dáfídì, àti Sólómọ́nì.” Lájorí àsọyé náà, “Ohun Àrà Ọ̀tọ̀ Tí Jésù Ṣe Láti Mú Ohun Tí Jèhófà Ní Lọ́kàn Ṣẹ,” la ó fi kádìí ìpàdé òwúrọ̀.
Lọ́sàn-án Friday, àsọyé tá a kọ́kọ́ máa gbọ́ ni “‘Àwa Ti Rí Mèsáyà’!” Èyí tá a máa gbọ́ tẹ̀ lé e ni “Wíwá Ìṣúra ‘Tá A Rọra Fi Pa Mọ́ Sínú Rẹ̀.’” A tún máa fi wákàtí kan gbádùn àpínsọ àsọyé alápá márùn-ún náà, “Ẹ Fìwà Jọ Kristi” àtàwọn ẹṣin-ọ̀rọ̀ míì tó rọ̀ mọ́ ọn, bí “Ó ‘Fi Inú Rere Gbà Wọ́n,’” “Ó ‘Di Onígbọràn Títí Dé Ikú,’” àti “Ó Nífẹ̀ẹ́ Wọn Dé Òpin.” Àsọyé tá a máa fi parí ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọ̀sán Friday ni “Wọ́n ‘Ń Tọ Ọ̀dọ́ Àgùntàn Náà Lẹ́yìn Ṣáá Níbikíbi Tí Ó Bá Ń Lọ.’”
Ẹṣin ọ̀rọ̀ ọjọ́ Saturday ni “Àwọn Àgùntàn Mi Ń Fetí sí Ohùn Mi, . . . Wọ́n sì Ń Tẹ̀ Lé Mi.” (Jòhánù 10:27) Nínú àpínsọ àsọyé náà “Máa Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jésù Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ” tó máa gba wákàtí kan gbáko, la ti máa gbádùn ọ̀pọ̀ ìmọ̀ràn tó wúlò tá a fi lè mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa sunwọ̀n sí i. Lẹ́yìn tá a bá ti gbọ́ àwọn àsọyé náà “Ó ‘Nífẹ̀ẹ́ Òdodo, Ó sì Kórìíra Ìwà Àìlófin’—Ìwọ Ńkọ́?” àti “‘Kọ Ojú Ìjà sí Èṣù’ bí Jésù Ti Ṣe,” ọ̀rọ̀ lórí ìrìbọmi lá óò wá fi parí ìpàdé ti òwúrọ̀, lẹ́yìn ẹ̀ sì làwọn tó bá tóótun á ṣèrìbọmi.
Àpínsọ àsọyé la máa fi bẹ̀rẹ̀ ìpàdé lọ́sàn-án Saturday. Ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni “Má Ṣe Tẹ̀ Lé . . . ” Apá mẹ́fà tó pín sí ni “Ogunlọ́gọ̀,” ‘Ọkàn Àyà Rẹ àti Ojú Rẹ,” “Òtúbáńtẹ́,” “Àwọn Olùkọ́ Èké,” “Àwọn Ìtàn Èké,” àti “Sátánì.” Lára àwọn àsọyé tó máa tẹ̀ lé e ni “Kò Sóhun Tó Dà bí ‘Ẹ̀kọ́ Tí Jèhófà Ń Kọ́’ Wa” àti “Ẹ Ràn Wọ́n Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Padà Sínú Agbo.” Àsọyé náà “Máa Tọ̀ Mí Lẹ́yìn,” la máa gbọ́ kẹ́yìn lọ́sàn-án Saturday.
Ẹṣin ọ̀rọ̀ ti ọjọ́ Sunday ni “Máa Bá A Lọ ní Títọ̀ Mí Lẹ́yìn.” (Jòhánù 21:19) Lẹ́yìn àsọyé náà, “Tọ Kristi Lẹ́yìn, Má Ṣe Ṣàwáwí,” a óò gbọ́ àpínsọ àsọyé alápá mẹ́fà náà “Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó Fakíki Látinú Ìwàásù Lórí Òkè,” èyí tó máa dá lórí àwọn ọ̀rọ̀ Jésù bí “Aláyọ̀ Ni Àwọn Tí Àìní Wọn Nípa Ti Ẹ̀mí Ń Jẹ Lọ́kàn,” “Kọ́kọ́ Wá Àlàáfíà, Ìwọ Pẹ̀lú Arákùnrin Rẹ,” àti “Ẹ Sọ Fífúnni Dàṣà, Àwọn Ènìyàn Yóò sì Fi fún Yín.” Àsọyé tá a fi máa mú ìpàdé ti òwúrọ̀ wá sí ìparí ni, “Àwọn Wo Ni Ojúlówó Ọmọlẹ́yìn Kristi?” Ọ̀kan pàtàkì lára ohun tá a máa gbádùn ní ọ̀sán Sunday yìí ni àwòkẹ́kọ̀ọ́ táwọn èèyàn á ti múra bí àwọn ará ìgbàanì, èyí tó dá lórí ìtàn Bíbélì nípa Géhásì oníwọra tó jẹ́ ìránṣẹ́ Èlíjà, wòlíì Ọlọ́run. Àsọyé tá a máa gbọ́ kẹ́yìn ní àpéjọ náà ni “Máa Tọ Kristi, Ọ̀gá Wa Ajagunṣẹ́gun Lẹ́yìn!”
Máa gbára dì báyìí kó o bàa lọ síbẹ̀. Bó o bá fẹ́ mọ ibi tó sún mọ́ ẹ jù lọ tí àpéjọ náà á ti wáyé, kàn sí Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tàbí kó o kọ̀wé sí àwọn tó tẹ ìwé ìròyìn yìí.