Ǹjẹ́ Ètè Rẹ Jẹ́ “Ohun Èlò Tí ó Ṣeyebíye”?
● Sólómọ́nì Ọba kọ̀wé pé: “Wúrà wà, àti ọ̀pọ̀ yanturu iyùn pẹ̀lú; ṣùgbọ́n ètè ìmọ̀ jẹ́ ohun èlò tí ó ṣeyebíye.” (Òwe 20:15) Ọjọ́ pẹ́ táwọn èèyàn ti ka wúrà sí nǹkan iyebíye, bákan náà nígbà ayé Sólómọ́nì àwọn èèyàn mọyì iyùn gan-an ni. Àmọ́, ètè wa tún lè ṣeyebíye ju àwọn nǹkan yìí lọ. Lọ́nà wo? Kì í ṣe bí ètè wa ṣe fani mọ́ra tó ló máa jẹ́ kó ṣeyebíye, ṣùgbọ́n ohun tó ń ti ẹnu wa jáde ló máa fi hàn bẹ́ẹ̀.
Àwọn nǹkan tí ètè tó ṣeyebíye máa ń mú jáde ni, ohun rere, inú rere àti ìfẹ́. Bákan náà, “ètè ìmọ̀” máa ń sọ òótọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó wà nínú Bíbélì. Ìwé àtọdúnmọ́dún yìí kún fún ọgbọ́n àti òtítọ́ nípa Ẹlẹ́dàá wa àti ìmọ̀ràn tí kò láfiwé nípa bá a ṣe máa gbé ìgbésí ayé wa.—Jòhánù 17:17.
Ó bani nínú jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń lo ètè wọn lọ́nà tí kò dáa nípa sísọ àwọn nǹkan tí kì í ṣe òótọ́ nípa Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan máa ń dá Ọlọ́run lẹ́bi nítorí ìwà ìrẹ́jẹ àti ìjìyà tó ń ṣẹlẹ̀ nínú, bẹ́ẹ̀ sì rèé, àfọwọ́fà ọmọ aráyé ni èyí tó pọ̀ jù nínú wọn. Lórí èyí, Òwe 19:3 sọ pé: “Àwọn kan ń ba ayé ara wọn jẹ́ nípasẹ̀ ìwà òmùgọ̀ wọn, lẹ́yìn náà, wọ́n wá ń dá Olúwa lẹ́bi.”—Today’s English Version.
Àwọn kan máa ń sọ ètè wọn di ohun tí kò ṣeyebíye nípa sísọ ọ̀rọ̀ tí kì í ṣòótọ́, ṣíṣe òfófó apanilára àti sísọ̀rọ̀ àwọn míì láìdáa. Lórí èyí, Òwe 26:23 lo àfiwé tó lágbára kan, ó sọ pé: “Bí fàdákà fẹ́ẹ́rẹ́ tí a fi bo àpáàdì ni ètè tí ń jó belebele pa pọ̀ pẹ̀lú ọkàn-àyà búburú.” Bíi “fàdákà fẹ́ẹ́rẹ́” tí ó bo àpáàdì, “ètè tí ń jó belebele” lè máa sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìmọ̀lára tó lágbára, kó sì dà bíi pé òótọ́ ló ń sọ, nígbà tó jẹ́ pé látinú “ọkàn-àyà búburú” ló ti ń sọ̀rọ̀.—Òwe 26:24-26.
Ó dájú pé, irú ìwà búburú bẹ́ẹ̀ kò pa mọ́ lọ́jú Ọlọ́run. Ó mọ irú èèyàn tá a jẹ́ gan-an! Ìdí nìyẹn tí Jésù Kristi fi sọ pé: “Kọ́kọ́ fọ inú ife àti àwopọ̀kọ́ mọ́, kí òde rẹ̀ pẹ̀lú le di èyí tí ó mọ́.” (Mátíù 23:26) Òótọ́ pọ́ńbélé lọ̀rọ̀ yìí o! Bákan náà, bí inú wa bá mọ́, tí òtítọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sì wà nínú ọkàn wa, ó máa hàn nínú ọ̀rọ̀ wa. Kí nìyẹn máa wá yọrí sí? Ètè wa á di “ohun èlò tí ó ṣeyebíye,” ní pàtàkì jù lọ lójú Ọlọ́run.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Ètè àwọn ọlọ́gbọ́n jẹ́ “ohun èlò tí ó ṣeyebíye”