Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀
Ǹjẹ́ o mọ̀ pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe àwọn ìwé tí à ń túmọ̀ sí èdè tó lé ní ọgọ́rùn-ún méje ó lé àádọ́ta [750]?
Kí nìdí tá a fi ń ṣe bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé a fẹ́ kí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dé ọ̀dọ̀ “gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ahọ́n àti ènìyàn.”—Ìṣípayá 14:6.
Ìwé ìròyìn “Jí!” yìí ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa bá a ṣe ń túmọ̀ àwọn ìwé wa sí onírúurú èdè.