ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g16 No. 3 ojú ìwé 3
  • Bá A Ṣe Borí Ìṣòro Àtayébáyé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bá A Ṣe Borí Ìṣòro Àtayébáyé
  • Jí!—2016
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀
    Jí!—2016
  • Ìhìn Rere Ní Ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta Èdè
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Ìwé Kan Tí “Ń Sọ” Àwọn Èdè Tí Ó Bóde Mu
    Ìwé kan tí ó Wà fún Gbogbo Ènìyàn
  • Kíkó Àwọn Èèyàn Jọ Látinú Gbogbo Èdè
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
Àwọn Míì
Jí!—2016
g16 No. 3 ojú ìwé 3
Àwọn èèyàn tó wá láti ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ láyé

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | BÁ A ṢE BORÍ ÌṢÒRO ÈDÈ

Bá A Ṣe Borí Ìṣòro Àtayébáyé

ORÍṢIRÍṢI èdè ló wà kárí ayé, kódà ó tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méje [7,000] èdè tàwọn èèyàn ń sọ báyìí. Àmọ́, bí èdè ṣe díjú kì í sábà mú kí nǹkan rọrùn nínú káràkátà, nínú ìmọ̀ ẹ̀kọ́, nínú ìjọba tàbí lẹ́nu ìrìn àjò. Bó sì ṣe rí nìyẹn látọdúnmọ́dún. Bí àpẹẹrẹ, ní nǹkan bí ọdún 475 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, nígbà ìṣàkóso Ọba Ahasuwérúsì (tó ṣeé ṣe kó jẹ́ Atasásítà I), àwọn ará Páṣíà máa ń fi àṣẹ ọba ránṣẹ́ jákèjádò ilẹ̀ wọn, “láti Íńdíà títí dé Etiópíà, ẹ̀tà-dín-láàádóje [127] àgbègbè abẹ́ àṣẹ, sí àgbègbè abẹ́ àṣẹ kọ̀ọ̀kan ní ọ̀nà-ìgbàkọ̀wé tirẹ̀ àti sí olúkúlùkù ènìyàn ní ahọ́n tirẹ̀.”a

Lóde òní, ọ̀pọ̀ àjọ tàbí ìjọba kì í sapá láti túmọ̀ èdè fún àwọn èèyàn wọn. Àmọ́, ètò kan wà tó ti ṣe èyí láṣeyọrí. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe ìwé ìròyìn, ìtẹ̀jáde tá a gbóhùn rẹ̀ sílẹ̀, fídíò àti ọ̀pọ̀ ìwé míì títí kan Bíbélì, ní èdè tó lé ní ọgọ́rùn-ún méje àti àádọ́ta [750]. Nǹkan bí ọgọ́rin [80] èdè àwọn adití wà lára wọn. Ìyẹn nìkan kọ́ o, a tún ń ṣe onírúurú ìwé tó wà fáwọn afọ́jú, ìyẹn Braille.

Pabanbarì rẹ̀ ni pé, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò ṣe gbogbo àwọn nǹkan yìí nítorí owó. Kódà, àwọn tó ń bá wa ṣe iṣẹ́ ìtúmọ̀ èdè àtàwọn míì tó ń bá wa ṣiṣẹ́ kì í gba owó. Kí nìdí tá a fi ń ṣiṣẹ́ kára láti túmọ̀ àwọn ìtẹ̀jáde wa sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èdè, báwo la sì ṣe ń ṣe é?

a Wo Ẹ́sítérì 8:9 nínú Bíbélì.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́