ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 7/02 ojú ìwé 1
  • Kíkó Àwọn Èèyàn Jọ Látinú Gbogbo Èdè

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kíkó Àwọn Èèyàn Jọ Látinú Gbogbo Èdè
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Èèyàn “Láti Inú Gbogbo Èdè” Ń Gbọ́ Ìhìn Rere Náà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Bó O Ṣe Lè Jẹ́rìí fún Àwọn Tó Ń Sọ Èdè Míì
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2015
  • Fífi Ìwé Ìkẹ́kọ̀ọ́ Lọni ní Ìpínlẹ̀ Tí Wọ́n Ti Ń Sọ Onírúurú Èdè
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • Ètò Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Tó Kárí Ayé
    Jí!—2001
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
km 7/02 ojú ìwé 1

Kíkó Àwọn Èèyàn Jọ Látinú Gbogbo Èdè

1 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń nímùúṣẹ nísinsìnyí! Àwọn èèyàn “láti inú gbogbo èdè àwọn orílẹ̀-èdè” ń tẹ́wọ́ gba ìjọsìn tòótọ́. (Sek. 8:23) Báwo làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń ran àwọn èèyàn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan látinú gbogbo ‘ẹ̀yà, ènìyàn àti ahọ́n’ lọ́wọ́, kí wọ́n bàa lè wà ní ipò mímọ́ lójú Jèhófà, kí wọ́n sì ní ìrètí àtila “ìpọ́njú ńlá” náà já?—Ìṣí. 7:9, 14.

2 Bí Ètò Àjọ Ọlọ́run Ṣe Ń Ṣèrànwọ́: Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti ṣètò láti máa pèsè àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní àwọn èdè tí ó tó okòó-dín-nírínwó [380], kó bàa lè ṣeé ṣe fún àwọn èèyàn ní gbogbo ilẹ̀ ayé láti mọ ìjẹ́pàtàkì ìhìn rere náà dáadáa. Kíkọ àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ní oríṣiríṣi èdè àti títẹ̀ wọ́n jáde jẹ́ iṣẹ́ bàǹtàbanta. Iṣẹ́ yìí ń béèrè pé ká kó àwọn olùtumọ̀ èdè tó pegedé jọ, ká sì fún wọn ní ìtìlẹyìn tí wọ́n nílò kí wọ́n lè tú àwọn ìtẹ̀jáde wa sí onírúurú èdè wọ̀nyí. Bákan náà, ó tún pọn dandan pé ká tẹ̀wé, ká sì kó wọn ránṣẹ́. Àmọ́ ṣá o, akéde Ìjọba kọ̀ọ̀kan tó ń mú ìhìn agbẹ̀mílà tó wà nínú Bíbélì lọ sọ́dọ̀ àwọn èèyàn, ló ń ṣe lájorí iṣẹ́ ọ̀hún.

3 Kíkojú Ìpèníjà Náà: Ní Nàìjíríà, ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ló jẹ́ pé kì í ṣe àgbègbè ìbílẹ̀ wọn ni wọ́n ń gbé. Torí àtilè wàásù ìhìn rere fún àwọn èèyàn wọ̀nyí, àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run kan ń sapá láti kọ́ àwọn èdè tuntun tó wọ́pọ̀ ní àgbègbè tí wọ́n ń gbé. Ọ̀pọ̀ ń kọ́ Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Amẹ́ríkà láti lè wàásù fún àwọn tó jẹ́ adití. A ti ní àwọn àwùjọ tó ń sọ èdè àwọn adití bíi mélòó kan ní orílẹ̀-èdè wa. Yàtọ̀ sí èdè Gẹ̀ẹ́sì, a tún ń mú àwọn ìtẹ̀jáde wa wà lárọ̀ọ́wọ́tó àwọn èèyàn ní àwọn èdè tó lé ní mẹ́wàá nínú àwọn èdè Nàìjíríà. Àwọn èèyàn kan tí kò gbọ́ nípa Jèhófà rí tàbí tí kò mọ ohunkóhun nípa Bíbélì ti ń kẹ́kọ̀ọ́, wọ́n sì ń tẹ́wọ́ gba òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.—Róòmù 15:21.

4 Ǹjẹ́ a lè túbọ̀ sa gbogbo agbára wa láti polongo ìhìn rere náà fún àwọn èèyàn tí àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ wọn yàtọ̀ sí tiwa, tí wọ́n wà ní ìpínlẹ̀ wa? (Kól. 1:25) Àwọn ìjọ kan ṣètò láti máa lọ ṣe iṣẹ́ ìwàásù láwọn àdúgbò táwọn èèyàn ti ń sọ èdè ilẹ̀ òkèèrè. Àwọn akéde yóò kọ́kọ́ kọ́ èdè ọ̀hún níwọ̀nba, débi tí yóò fi ṣeé ṣe fún wọn láti gbọ́rọ̀ kalẹ̀ lọ́nà rírọrùn, irú bí: “Ẹ ǹ lẹ́ ńbí o. A mú ìhìn rere wá fún un yín ni o. [Lẹ́yìn náà, fi ìwé àṣàrò kúkúrú tàbí ìwé pẹlẹbẹ kan tó wà ní èdè náà lọ̀ ọ́.] Ó dìgbà.” Ní tòótọ́, Jèhófà máa ń bù kún irú àwọn ìsapá tá a bá bẹ̀rẹ̀ lọ́nà wẹ́rẹ́ bẹ́ẹ̀!

5 Ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà máa ń fa àwọn èèyàn tí wọ́n wá láti onírúurú ipò ìgbésí ayé àti èdè mọ́ra. Ẹ jẹ́ ká lo àǹfààní tá a ní láti ṣàjọpín rẹ̀ pẹ̀lú wọn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́