Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀
Kò dìgbà téèyàn bá ka tìfuntẹ̀dọ̀ ìwé kó tó mọ̀ pé ayé yìí ti bà jẹ́ kọjá àlà. Bí àpẹẹrẹ, kò fi bẹ́ẹ̀ sí omi tó ṣeé mu mọ́, àwọn èèyàn ti ba omi òkun jẹ́, wọ́n ti fẹ́rẹ̀ẹ́ gé gbogbo igi tán nígbó, afẹ́fẹ́ tá à ń mí sínú pàápàá ti bà jẹ́. Ṣé àwọn èèyàn ò ní ba ayé yìí jẹ́ kọjá àtúnṣe báyìí? Ka ìwé yìí kó o lè mọ̀ bóyá ọ̀nà àbáyọ wà.