Ojú Ìwé Tí Wọ́n Kọ Àkọlé Sí/Ojú Ìwé Tí Wọ́n Kọ Orúkọ Òǹṣèwé Sí
Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo
Sí Àwọn Òǹkàwé Wa
Ìyè àìnípẹ̀kun, nínú Párádísè ilẹ̀ ayé! Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ló jẹ́ ká mọ̀ nípa ìrètí àgbàyanu yìí. Àmọ́ ṣá o, ìbẹ̀rẹ̀ lásán ni èyí àtàwọn lájorí ẹ̀kọ́ mìíràn tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́. Bíbélì rọ gbogbo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run láti fi “èrò orí mòye . . . ohun tí . . . gíga àti jíjìn” àwọn òtítọ́ Ọlọ́run tó ṣeyebíye jẹ́. (Éfésù 3:18) Ìdí yìí gan-an la fi ṣe ìwé yìí. Ìrètí wa ni pé yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti dàgbà nípa tẹ̀mí, tí wàá sì túbọ̀ di ẹni tá a mú gbára dì láti rìn lójú ọ̀nà tóóró náà tó lọ sí ìyè nínú ayé tuntun òdodo Ọlọ́run.
—Àwa Òǹṣèwé
A Tẹ̀ Ẹ́ ní Ọdún 2006
A tẹ ìwé yìí gẹ́gẹ́ bí ara iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kárí ayé tí à ń fi ọrẹ àtinúwá ṣètìlẹ́yìn fún.
Bá ò bá fi hàn pé ó yàtọ̀, gbogbo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wá láti inú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tí a fi àkọtọ́ tó bóde mu kọ. Níbi tí NW bá ti tẹ̀ lé àyọlò, ó fi hàn pé ìtumọ̀ náà wá láti inú Bíbélì New World Translation of the Holy Scriptures—With References
Ibi Tá A Ti Mú Àwọn Àwòrán:
▪ Ẹ̀yìn Ìwé: Fọ́tò U.S. Navy
▪ Ojú ìwé 180: Àwọn Ọmọdé: UNITED NATIONS/J. FRANK