Ẹ̀KỌ́ 45
Ìjọba Ísírẹ́lì Pín sí Méjì
Àlàáfíà wà nílẹ̀ Ísírẹ́lì ní gbogbo ìgbà tí Sólómọ́nì ń sin Jèhófà tọkàntọkàn. Àmọ́ nígbà tó yá, Sólómọ́nì lọ fẹ́ ọ̀pọ̀ obìnrin àjèjì, òrìṣà làwọn obìnrin náà sì ń bọ. Bó ṣe di pé Sólómọ́nì náà bẹ̀rẹ̀ sí í jọ́sìn àwọn òrìṣà ilẹ̀ àjèjì nìyẹn. Inú bí Jèhófà gan-an. Jèhófà wá sọ fún Sólómọ́nì pé: ‘Màá gba ilẹ̀ Ísírẹ́lì lọ́wọ́ ìdílé ẹ, màá sì pín in sí méjì. Màá fún ìránṣẹ́ ẹ ní apá tó tóbi jù lára ẹ̀, ìdílé ẹ á sì máa jọba ní apá kékeré tó ṣẹ́ kù.’
Jèhófà ṣe ohun kan tó mú kí ìpinnu ẹ̀ ṣe kedere. Lọ́jọ́ kan, ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ Sólómọ́nì tó ń jẹ́ Jèróbóámù ń rìnrìn àjò, ló bá pàdé wòlíì kan tó ń jẹ́ Áhíjà. Nígbà tí wọ́n pàdé, Áhíjà fa aṣọ ara ẹ̀ ya, ó sì pín in sọ́nà méjìlá, ó wá sọ fún Jèróbóámù pé: ‘Jèhófà máa gba ilẹ̀ Ísírẹ́lì kúrò lọ́wọ́ ìdílé Sólómọ́nì, ó sì máa pín in sí méjì. Torí náà, mú ẹ̀wù mẹ́wàá lára méjìlá náà, torí pé ìwọ lo máa jọba lórí ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì.’ Nígbà tí Ọba Sólómọ́nì gbọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí, ó bẹ̀rẹ̀ sí í wá bó ṣe máa pa Jèróbóámù. Ni Jèróbóámù bá sá lọ sí Íjíbítì. Nígbà tó yá, Sólómọ́nì kú, ọmọ ẹ̀ tó ń jẹ́ Rèhóbóámù sì di ọba. Ìgbà yẹn ni Jèróbóámù tó pa dà sí Ísírẹ́lì.
Àwọn àgbààgbà tó wà ní Ísírẹ́lì sọ fún Rèhóbóámù pé: ‘Tó o bá ń ṣe dáadáa sáwọn ará ìlú, wọn ò ní fi ẹ́ sílẹ̀.’ Àmọ́, àwọn ọ̀rẹ́ Rèhóbóámù tí wọ́n jọ jẹ́ ẹgbẹ́ sọ fún un pé: ‘Ṣe ni kó o túbọ̀ fìyà jẹ wọ́n dáadáa. Kó o tún fi iṣẹ́ kún iṣẹ́ wọn.’ Kàkà kí Rèhóbóámù tẹ̀ lé ìmọ̀ràn táwọn àgbààgbà fún un, ohun táwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ sọ ló ṣe. Rèhóbóámù wá bẹ̀rẹ̀ sí í fìyà jẹ àwọn ará ìlú, àwọn èèyàn náà sì pa dà lẹ́yìn ẹ̀. Wọ́n fi Jèróbóámù jọba ẹ̀yà mẹ́wàá, ẹ̀yà mẹ́wàá yìí la wá mọ̀ sí ìjọba Ísírẹ́lì. Ẹ̀yà méjì tó kù la mọ̀ sí ìjọba Júdà, àwọn ará Júdà ò sì pa dà lẹ́yìn Rèhóbóámù. Bí ẹ̀yà méjìlá Ísírẹ́lì ṣe pín sí méjì nìyẹn.
Jèróbóámù ò fẹ́ káwọn èèyàn òun lọ máa jọ́sìn ní Jerúsálẹ́mù torí pé abẹ́ ìjọba Rèhóbóámù nibẹ̀ wà. Ṣé o mọ ìdí? Ìdí ni pé ẹ̀rù ń ba Jèróbóámù pé tí wọ́n bá ń lọ síbẹ̀, wọ́n máa pa òun tì, wọ́n á sì pa dà sọ́dọ̀ Rèhóbóámù. Ó wá gbẹ́ ère ọmọ màlúù wúrà méjì fún wọn, ó sì sọ fún wọn pé: ‘Jerúsálẹ́mù ti jìnnà jù. Ẹ máa ṣe ìjọsìn yín níbí. Báwọn èèyàn náà ṣe gbàgbé Jèhófà nìyẹn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í jọ́sìn àwọn ère ọmọ màlúù náà.
“Ẹ má fi àìdọ́gba so pọ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́. Nítorí àjọṣe wo ni òdodo àti ìwà tí kò bófin mu ní? . . . Àbí kí ló pa onígbàgbọ́ àti aláìgbàgbọ́ pọ̀?”—2 Kọ́ríńtì 6:14, 15