Jèhófà Kì Yóò Fi Àwọn Ẹni Ìdúróṣinṣin Rẹ̀ Sílẹ̀
“[Jèhófà] kì yóò sì fi àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀ sílẹ̀. Fún àkókò tí ó lọ kánrin ni a óò máa ṣọ́ wọn dájúdájú.”—SM. 37:28.
1, 2. (a) Àwọn nǹkan wo ló ṣẹlẹ̀ ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún ṣáájú kí Jésù tó wá sáyé tó dán ìdúróṣinṣin àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run wò? (b) Inú ipò mẹ́ta wo ni Jèhófà kò ti fi àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀ sílẹ̀?
OHUN tá a fẹ́ sọ yìí ṣẹlẹ̀ ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún ṣáájú kí Jésù tó wá sáyé, ní àkókò kan táwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ní láti ṣèpinnu pàtàkì kan. Ogun abẹ́lé ì bá ṣẹlẹ̀ ká ní wọn ò gbà káwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wà níhà àríwá ní ọba tiwọn, torí pé ìjọba tó wà lórí àlééfà nígbà yẹn kò tẹ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yẹn lọ́rùn mọ́. Jèróbóámù ọba wọn tuntun tètè bẹ̀rẹ̀ sí í gbé àwọn ìgbésẹ̀ kan tó máa mú kí ìjọba rẹ̀ fìdí múlẹ̀. Ó dá ìjọsìn kan tó fẹ́ kí gbogbo àwọn tó wà lórílẹ̀-èdè yẹn máa fi tọkàntọkàn ṣe sílẹ̀. Kí làwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà máa ṣe báyìí? Ǹjẹ́ wọ́n á ṣì máa jẹ́ adúróṣinṣin nìṣó sí Ọlọ́run tí wọ́n ń sìn? Ẹgbẹẹgbẹ̀rún wọn ló dúró ṣinṣin, Jèhófà sì ń ṣọ́ wọn bí wọ́n ṣe ń fi ìṣòtítọ́ sìn ín nìṣó.—1 Ọba 12:1-33; 2 Kíró. 11:13, 14.
2 Àwọn ohun kan wà tó ń dán ìdúróṣinṣin àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run wò lóde òní pẹ̀lú. Bíbélì kìlọ̀ fún wa pé: “Ẹ pa agbára ìmòye yín mọ́, ẹ máa kíyè sára. Elénìní yín, Èṣù, ń rìn káàkiri bí kìnnìún tí ń ké ramúramù, ó ń wá ọ̀nà láti pani jẹ.” Ǹjẹ́ ó lè ṣeé ṣe fún wa láti “mú ìdúró [wa] lòdì sí i, ní dídúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́”? (1 Pét. 5:8, 9) Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ tó mú kí Jèróbóámù di ọba lọ́dún 997 ṣáájú Sànmánì Kristẹni àtàwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tó gorí ìtẹ́, ká sì wo ohun tá a lè rí kọ́ nínú wọn. Láwọn ọdún tí nǹkan le koko yẹn, ìjọba ìgbà yẹn ń ni àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà lára. Àwọn apẹ̀yìndà ò tún jẹ́ kí wọ́n rímú mí bí wọ́n ṣe ń jẹ́ iṣẹ́ tí Ọlọ́run rán wọn, iṣẹ́ yẹn sì ṣòroó jẹ́. Nínú àwọn ipò tí àwọn ẹni ìdúróṣinṣin bá ara wọn yìí, Jèhófà ò fi wọ́n sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni kò ní fi wọ́n sílẹ̀ lóde òní pẹ̀lú.—Sm. 37:28.
Nígbà Ìnilára
3. Kí nìdí tí ìṣàkóso Dáfídì Ọba kò fi ni àwọn èèyàn lára?
3 Ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ ṣàyẹ̀wò àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ tó mú kí Jèróbóámù di ọba. Òwe orí kọkàndínlọ́gbọ̀n ẹsẹ kejì sọ pé: “Nígbà tí ẹni burúkú bá ń ṣàkóso, àwọn ènìyàn a máa mí ìmí ẹ̀dùn.” Nígbà tí Dáfídì Ọba ń ṣàkóso lórí Ísírẹ́lì ìgbàanì, àwọn èèyàn ò mí ìmí ẹ̀dùn. Dáfídì kì í ṣe ẹni pípé o, ṣùgbọ́n ó jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run, ó sì gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run. Ìṣàkóso Dáfídì kò ni àwọn èèyàn lára. Jèhófà bá Dáfídì dá májẹ̀mú kan, ó ní: “Ilé rẹ àti ìjọba rẹ yóò sì fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin dájúdájú fún àkókò tí ó lọ kánrin níwájú rẹ; ìtẹ́ rẹ pàápàá yóò di èyí tí a fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in fún àkókò tí ó lọ kánrin.”—2 Sám. 7:16.
4. Orí kí ni ìbùkún táwọn èèyàn ń gbádùn nígbà ìṣàkóso Sólómọ́nì sinmi lé?
4 Nígbà tí Sólómọ́nì ọmọ Dáfídì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso, gbogbo nǹkan ń lọ ní mẹ̀lọmẹ̀lọ, nǹkan sì rọ̀ṣọ̀mù fáwọn èèyàn débi pé a lè fi ìṣàkóso yẹn ṣàpẹẹrẹ Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi Jésù tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú. (Sm. 72:1, 17) Lákòókò yẹn, kò sídìí fún èyíkéyìí lára ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjìlá láti yapa. Àmọ́ o, ìbùkún tí Sólómọ́nì àtàwọn tó wà lábẹ́ ìṣàkóso rẹ̀ ń gbádùn sinmi lórí nǹkan kan. Jèhófà ti sọ fún Sólómọ́nì tẹ́lẹ̀ pé: “Bí ìwọ yóò bá rìn nínú àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ mi, tí ìwọ yóò sì ṣe àwọn ìpinnu ìdájọ́ mi, tí ìwọ yóò sì pa gbogbo àṣẹ mi mọ́ ní ti tòótọ́ nípa rírìn nínú wọn, dájúdájú, èmi pẹ̀lú yóò mú ọ̀rọ̀ mi nípa rẹ èyí tí mo sọ fún Dáfídì baba rẹ ṣẹ; èmi yóò sì máa gbé ní àárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ti tòótọ́, èmi kì yóò sì fi àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì sílẹ̀.”—1 Ọba 6:11-13.
5, 6. Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí Sólómọ́nì di aláìṣòótọ́ sí Ọlọ́run?
5 Nígbà tí Sólómọ́nì darúgbó, ó di aláìṣòótọ́ sí Jèhófà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í lọ́wọ́ nínú ìjọsìn èké. (1 Ọba 11:4-6) Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, Sólómọ́nì ò tẹ̀ lé òfin Jèhófà mọ́, ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í ni àwọn èèyàn lára. Ó ni wọ́n lára débi pé lẹ́yìn tó kú, àwọn èèyàn ráhùn lọ bá Rèhóbóámù ọmọ rẹ̀ tó bọ́ sórí ìtẹ́, wọ́n ní kó sọ̀gbà dẹ̀rọ̀ fáwọn. (1 Ọba 12:4) Kí ni Jèhófà ṣe nígbà tí Sólómọ́nì di aláìṣòótọ́?
6 Bíbélì sọ fún wa pé: “Ìbínú Jèhófà sì wá ru sí Sólómọ́nì, nítorí pé ọkàn-àyà rẹ̀ ti tẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ . . . Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ẹni tí ó fara hàn án lẹ́ẹ̀mejì.” Jèhófà sọ fún Sólómọ́nì pé: ‘Nítorí ìdí náà pé ìwọ kò pa májẹ̀mú mi mọ́ àti ìlànà àgbékalẹ̀ mi tí mo gbé kalẹ̀ ní àṣẹ fún ọ, láìkùnà, èmi yóò fa ìjọba náà ya kúrò lọ́wọ́ rẹ, dájúdájú, èmi yóò sì fi í fún ìránṣẹ́ rẹ.’—1 Ọba 11:9-11.
7. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà kọ Sólómọ́nì, báwo ló ṣe bójú tó àwọn ẹni ìdúróṣinṣin Rẹ̀?
7 Jèhófà wá rán wòlíì Áhíjà láti lọ yan ẹni tó máa dá àwọn èèyàn nídè. Ẹni náà ni Jèróbóámù, ọkùnrin kan tó tó gbangba sùn lọ́yẹ́, tó ń ṣiṣẹ́ lábẹ́ ìjọba Sólómọ́nì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ṣì dúró lórí májẹ̀mú tó bá Dáfídì dá, Ó gbà kí ẹ̀yà méjìlá Ísírẹ́lì pín sábẹ́ ìjọba méjì. Jèróbóámù yóò máa ṣàkóso lórí ẹ̀yà mẹ́wàá, Rèhóbóámù Ọba tó wà lórí ìtẹ̀ báyìí látinú ìran Dáfídì yóò sì máa ṣàkóso lórí ẹ̀yà méjì tó kù. (1 Ọba 11:29-37; 12:16, 17, 21) Jèhófà sọ fún Jèróbóámù pé: “Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, bí ìwọ bá ṣègbọràn sí gbogbo èyí tí èmi yóò pa láṣẹ fún ọ, tí o sì rìn ní àwọn ọ̀nà mi, tí o sì ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú mi ní ti tòótọ́, nípa pípa àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ mi mọ́ àti àwọn àṣẹ mi, gan-an gẹ́gẹ́ bí Dáfídì ìránṣẹ́ mi ti ṣe, dájúdájú, èmi pẹ̀lú yóò wà pẹ̀lú rẹ, èmi yóò sì kọ́ ilé wíwà pẹ́ títí fún ọ, gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti kọ́ fún Dáfídì, èmi yóò sì fi Ísírẹ́lì fún ọ.” (1 Ọba 11:38) Jèhófà gbégbèésẹ̀ torí àwọn èèyàn rẹ̀, ó ṣe ọ̀nà àbáyọ lọ́wọ́ ìnilára.
8. Àwọn àdánwò wo ló ń kó ìnira bá àwọn èèyàn Ọlọ́run lónìí?
8 Ìwà àìṣòdodo àti ìnilára pọ̀ gan-an nínú ayé lónìí. Ìwé Oníwàásù orí kẹjọ ẹsẹ kẹsàn-án sọ pé: “Ènìyàn ti jọba lórí ènìyàn sí ìṣeléṣe rẹ̀.” Àwọn tó ti ki ojúkòkòrò bọ ọ̀ràn ìṣòwò àtàwọn jẹgúdújẹrá alákòóso lè mú kí ètò ọrọ̀ ajé má fara rọ. Àpẹẹrẹ burúkú ni àwọn aṣáájú nínú ìjọba, okòwò àti ìsìn ń fi lélẹ̀. Ìdí nìyẹn tí ọ̀rọ̀ àwọn tó jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run lónìí náà fi rí bíi ti Lọ́ọ̀tì olódodo, “ẹni tí ìkẹ́ra-ẹni-bàjẹ́ nínú ìwà àìníjàánu àwọn aṣàyàgbàǹgbà pe òfin níjà kó wàhálà-ọkàn bá gidigidi.” (2 Pét. 2:7) Bákan náà, láìwo ti pé à ń sapá láti pa àwọn ìlànà Ọlọ́run mọ́ láìdí ẹnikẹ́ni lọ́wọ́, àwọn agbéraga alákòóso máa ń ṣenúnibíni sí wa lọ́pọ̀ ìgbà.—2 Tím. 3:1-5, 12.
9. (a) Kí ni Jèhófà ti ṣe láti dá àwọn èèyàn rẹ̀ nídè? (b) Kí nìdí tó fi dá wa lójú pé Jésù á máa jẹ́ adúróṣinṣin nìṣó sí Ọlọ́run?
9 Bó ti wù kó rí, òtítọ́ pọ́ńbélé kan wà tó dá wa lójú, òun ni pé Jèhófà kò ní fi àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀ sílẹ̀! Tiẹ̀ ronú ná lórí àwọn ohun tí Ọlọ́run ti ṣe láti pààrọ̀ àwọn ìjọba jẹgúdújẹrá ayé yìí. Ọlọ́run ti gbé Ìjọba kan tí yóò gba aráyé là lé Kristi Jésù lọ́wọ́. Ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgọ́rùn-ún ọdún báyìí tí Jésù Kristi ti ń ṣàkóso lọ́run. Láìpẹ́ yóò mú ìtura tí yóò wà títí láé bá àwọn tó ń bẹ̀rù orúkọ Ọlọ́run. (Ka Ìṣípayá 11:15-18.) Jésù ti fi hàn pé òun jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run títí dójú ikú. Kò ní ṣe bíi ti Sólómọ́nì, kò ní já àwọn èèyàn rẹ̀ kulẹ̀ láé.—Héb. 7:26; 1 Pét. 2:6.
10. (a) Kí ló yẹ ká ṣe láti lè fi hàn pé a mọyì Ìjọba Ọlọ́run? (b) Nígbà tá a bá dojú kọ àdánwò, kí lohun tó yẹ kó fi wá lọ́kàn balẹ̀?
10 Ìṣàkóso gidi ni Ìjọba Ọlọ́run, ó sì máa fòpin sí gbogbo ìnilára. Jèhófà Ọlọ́run àti Ìjọba rẹ̀ ló yẹ ká dúró tì gbágbáágbá. Nítorí ìgbàgbọ́ kíkún tá a ní nínú Ìjọba náà, a kọ àìṣèfẹ́ Ọlọ́run tó wà nínú ayé yìí sílẹ̀, a sì ń fìtara ṣe àwọn iṣẹ́ àtàtà. (Títù 2:12-14) À ń gbìyànjú ká lè máa wà láìní àbàwọ́n nínú ayé yìí. (2 Pét. 3:14) Àdánwò yòówù tó lè dojú kọ wá nísinsìnyí, ọkàn wa balẹ̀ pé Jèhófà máa dáàbò bò wá lọ́wọ́ ohunkóhun tó lè ba ìgbàgbọ́ wa jẹ́. (Ka Sáàmù 97:10.) Ìyẹn nìkan kọ́, Sáàmù 116:15 mú un dá wa lójú pé: “Iyebíye ní ojú Jèhófà ni ikú àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀.” Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ṣeyebíye lójú rẹ̀ débi pé kò ní gbà kí wọ́n pa run gẹ́gẹ́ bí odindi àwùjọ kan.
Nígbà Táwọn Apẹ̀yìndà Ò Jẹ́ Kí Wọ́n Rímú Mí
11. Báwo ni Jèróbóámù ṣe di aláìdúróṣinṣin?
11 Dípò kí Jèróbóámù Ọba fi ìṣàkóso rẹ̀ tu àwọn èèyàn Ọlọ́run lára, ńṣe ló ń ṣe àwọn ohun tó túbọ̀ ń dán ìdúróṣinṣin wọn sí Ọlọ́run wò. Ipò ọlá tí Jèróbóámù wà àti àǹfààní tó ní gẹ́gẹ́ bí ọba kò tẹ́ ẹ lọ́rùn, ṣe ló tún ń wá bó ṣe máa fìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ dáadáa. Ó ń sọ nínú ọkàn rẹ̀ pé: “Bí àwọn ènìyàn yìí bá ń bá a lọ láti gòkè lọ rú ẹbọ ní ilé Jèhófà ní Jerúsálẹ́mù, dájúdájú, ọkàn-àyà àwọn ènìyàn yìí yóò padà sọ́dọ̀ olúwa wọn, Rèhóbóámù ọba Júdà; dájúdájú, wọn yóò sì pa mí, wọn yóò sì padà sọ́dọ̀ Rèhóbóámù ọba Júdà.” Jèróbóámù wá gbé ìjọsìn kan kalẹ̀ níbi tí wọ́n á ti máa jọ́sìn ère ọmọ màlúù wúrà méjì. “Nígbà náà, ó gbé ọ̀kan sí Bẹ́tẹ́lì, ó sì gbé ìkejì sí Dánì. Nǹkan yìí sì wá di okùnfà ẹ̀ṣẹ̀, àwọn ènìyàn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí lọ sí iwájú èyí tí ó wà ní Dánì lọ́hùn-ún lọ́hùn-ún. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ilé àwọn ibi gíga, ó sì ṣe àwọn àlùfáà láti inú àwọn ènìyàn náà ní gbogbo gbòò, tí kì í ṣe ara àwọn ọmọ Léfì.” Kódà, Jèróbóámù fúnra rẹ̀ yan ọjọ́ kan tó pè ní ọjọ́ “àjọyọ̀ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì,” ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í “rú àwọn ẹbọ lórí pẹpẹ náà láti rú èéfín ẹbọ.”—1 Ọba 12:26-33.
12. Kí làwọn ẹni ìdúróṣinṣin Ọlọ́run tí wọ́n wà lábẹ́ ìjọba ìhà àríwá ṣe nígbà tí Jèróbóámù gbé ìjọsìn ère ọmọ màlúù kalẹ̀ nílẹ̀ Ísírẹ́lì?
12 Kí làwọn ẹni ìdúróṣinṣin Ọlọ́run tí wọ́n wà lábẹ́ ìjọba ìhà àríwá máa wá ṣe báyìí? Àwọn ọmọ Léfì tí wọ́n ń gbé ní àwọn ìlú tí wọ́n fún wọn láwọn ìpínlẹ̀ tó wà lábẹ́ ìjọba ìhà àríwá ṣe bíi tàwọn baba ńlá wọn tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́, wọ́n gbégbèésẹ̀ lẹ́yẹ-ò-sọkà. (Ẹ́kís. 32:26-28; Núm. 35:6-8; Diu. 33:8, 9) Wọ́n fàwọn ohun ìní wọn sílẹ̀, wọ́n sì kó àwọn ìdílé wọn lọ sí ìhà gúúsù nílẹ̀ Júdà níbi tí wọ́n á ti lè máa jọ́sìn Jèhófà láìsí ìdílọ́wọ́. (2 Kíró. 11:13, 14) Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì míì tí wọ́n ti lọ gbé ní ilẹ̀ Júdà fúngbà díẹ̀ kúkú pinnu láti fibẹ̀ ṣelé dípò kí wọ́n padà sílẹ̀ ìbílẹ̀ wọn. (2 Kíró. 10:17) Jèhófà rí i dájú pé ọ̀nà àtipadà sínú ìjọsìn tòótọ́ ṣí sílẹ̀ káwọn ìràn tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú nínú ìjọba ìhà àríwá lè pa ìjọsìn ère ọmọ màlúù tì, tí wọ́n á sì lè padà sí ilẹ̀ Júdà.—2 Kíró. 15:9-15.
13. Báwo lohun táwọn apẹ̀yìndà ń ṣe ṣe jẹ́ àdánwò fáwa èèyàn Ọlọ́run lónìí?
13 Àwọn apẹ̀yìndà ń dún mọ̀huru-mọ̀huru mọ́ àwa èèyàn Ọlọ́run lónìí. Àwọn aláṣẹ kan ti gbìyànjú láti gbé ìjọsìn kan kalẹ̀, èyí tí wọ́n fẹ́ kí gbogbo àwọn tí wọ́n ń ṣàkóso lé lórí máa ṣe. Àwọn àlùfáà Ṣọ́ọ̀ṣì, àtàwọn míì tí wọn mọ̀wọ̀n kò ara wọn ti gbìyànjú láti gbé ara wọn sípò “ẹgbẹ́ àlùfáà aládé” tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀. Àmọ́ ṣá o, àárín àwa Kristẹni tòótọ́ nìkan la ti rí àwọn tí wọ́n jẹ́ ojúlówó ẹni àmì òróró, tí wọ́n para pọ̀ di “ẹgbẹ́ àlùfáà aládé.”—1 Pét. 2:9; Ìṣí. 14:1-5.
14. Kí ló yẹ ká ṣe sí èrò táwọn apẹ̀yìndà bá gbé wá?
14 Ẹ̀kọ́ èké àwọn apẹ̀yìndà ò tan àwọn ẹni ìdúróṣinṣin Ọlọ́run jẹ lónìí, bí kò ṣe tan àwọn ọmọ Léfì olóòótọ́ jẹ ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún ṣáájú kí Jésù tó wá sáyé. Àwọn ẹni àmì òróró àtàwọn Kristẹni alábàákẹ́gbẹ́ wọn máa ń tètè mọ èrò táwọn apẹ̀yìndà bá gbé dé, kíá ni wọ́n sì máa ń kọ̀ ọ́ sílẹ̀. (Ka Róòmù 16:17.) Ìjọba Ọlọ́run la dúró ṣinṣin tì. Síbẹ̀, à ń fi tinútinú tẹrí ba fáwọn tí wọ́n wà nípò àṣẹ lórí àwọn ọ̀ràn tí kò bá jẹ mọ́ ti ìjọsìn, a kì í sì í lọ́wọ́ nínú dída ìlú rú. (Jòh. 18:36; Róòmù 13:1-8) A kò tẹ́wọ́ gba àwọn tí wọ́n fẹnu lásán sọ pé àwọn ń sin Ọlọ́run, lẹ́sẹ̀ kan náà tí wọ́n tàbùkù sí Ọlọ́run nípa ìwà wọn.—Títù 1:16.
15. Kí nìdí tó fi yẹ́ ká dúró ṣinṣin ti “ẹrú olóòótọ́ àti olóye”?
15 Tiẹ̀ tún ro ti pé Jèhófà ti jẹ́ kó ṣeé ṣe fáwọn olóòótọ́ ọkàn láti jáde kúrò nínú ayé búburú yìí lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, ó sì ti mú wọn lọ sínú Párádísè tẹ̀mí tó ti dá. (2 Kọ́r. 12:1-4) Pẹ̀lú ìmọrírì nínú ọkàn wa, a dúró ṣinṣin ti “ẹrú olóòótọ́ àti olóye tí ọ̀gá rẹ̀ yàn sípò lórí àwọn ará ilé rẹ̀, láti fún wọn ní oúnjẹ wọn ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu.” Kristi ti yan ẹrú yìí “lórí gbogbo àwọn nǹkan ìní rẹ̀.” (Mát. 24:45-47) Nítorí náà, ká tiẹ̀ wá sọ pé àwa gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan ò lóye àlàyé tí ẹgbẹ́ ẹrú náà ṣe lórí kókó kan dáadáa, ìyẹn ò sọ pé ká tìtorí ìyẹn kọ̀ ọ́ sílẹ̀ tàbí ká padà sínú ayé Sátánì. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìdúróṣinṣin máa jẹ́ ká hùwà ìrẹ̀lẹ̀, ká sì dúró kí Jèhófà là wá lóye.
Nígbà Tí Wọ́n Ń Ṣiṣẹ́ Tí Ọlọ́run Rán Wọn
16. Iṣẹ́ wo ni Jèhófà rán wòlíì kan láti ilẹ̀ Júdà?
16 Jèhófà dẹ́bi fún Jèróbóámù torí ìwà apẹ̀yìndà tó hù. Ó rán wòlíì kan láti ilẹ̀ Júdà pé kó rìnrìn àjò lọ sí ìlú Bẹ́tẹ́lì níhà àríwá kó lọ rí Jèróbóámù níbi tó ti ń rúbọ lórí pẹpẹ tó ṣe fún ara rẹ̀. Ìdájọ́ tó múná ni wòlíì yẹn fẹ́ lọ jẹ́ fún Jèróbóámù. Dájúdájú, iṣẹ́ yẹn á ṣòroó jẹ́.—1 Ọba 13:1-3.
17. Báwo ni Jèhófà ṣe dáàbò bo ìránṣẹ́ rẹ̀?
17 Ńṣe ni Jèróbóámù tutọ́ sókè tó fojú gbà á nígbà tó gbọ́ pé Jèhófà dẹ́bi fóun. Ló bá nawọ́ sí wòlíì tí Ọlọ́run rán sí i, ó sì ké rara sáwọn ọkùnrin tó wà nítòsí pé: “Ẹ gbá a mú!” Ṣùgbọ́n lójú ẹsẹ̀, kí ẹnikẹ́ni nínú wọn tó gbéra ńlẹ̀, “ọwọ́ rẹ̀ tí ó nà sí i . . . gbẹ, kò sì lè fà á padà sọ́dọ̀ ara rẹ̀. Pẹpẹ náà sì là sọ́tọ̀ọ̀tọ̀, tí ó fi jẹ́ pé eérú ọlọ́ràá náà dà kúrò lórí pẹpẹ.” Jèróbóámù ò mọ ojú tó fi bẹ wòlíì yìí pé kó bá òun tu Jèhófà lójú, kó sì bá òun gbàdúrà pé kọ́wọ́ òun tó ti gbẹ lè padà sí bó ṣe wà tẹ́lẹ̀. Wòlíì náà gbàdúrà sí Jèhófà, ọwọ́ náà sì padà bọ̀ sípò. Jèhófà tipa báyìí dáàbò bo ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ ewu.—1 Ọba 13:4-6.
18. Báwo ni Jèhófà ṣe ń ṣọ́ wa bá a ṣe ń fi ìgboyà ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún un?
18 Láwọn ìgbà míì, bá a ṣe ń bá iṣẹ́ wíwàásù àti sísọni-dọmọ ẹ̀yìn lọ, a máa ń pàdé àwọn tí wọn kò fẹ́ gbọ́rọ̀ wa tàbí tí wọn kò tiẹ̀ fẹ́ rí wa sójú. (Mát. 24:14; 28:19, 20) Àmọ́, ẹ má ṣe jẹ́ ká gbà kí ìbẹ̀rù pé àwọn èèyàn ò fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ wa paná ìtara tá a ní fún iṣẹ́ ìwàásù. Bíi ti wòlíì tí Ìwé Mímọ́ ò dárúkọ rẹ̀, tó lọ jíṣẹ́ fún Jèróbóámù yẹn, a ní “àǹfààní ṣíṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún [Jèhófà] láìbẹ̀rù pẹ̀lú ìdúróṣinṣin.”a (Lúùkù 1:74, 75) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò retí pé kí Jèhófà dá sí ọ̀ràn wa lọ́nà àrà lónìí, síbẹ̀ ó ṣì ń fi ẹ̀mí mímọ́ àtàwọn áńgẹ́lì rẹ̀ ṣọ́ àwa tá a jẹ́ Ẹlẹ́rìí rẹ̀, ó sì ń tì wá lẹ́yìn. (Ka Jòhánù 14:15-17; Ìṣípayá 14:6.) Láé, Ọlọ́run ò ní fi àwọn tí wọ́n ń fìgboyà sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ nìṣó sílẹ̀.—Fílí. 1:14, 28.
Jèhófà Yóò Máa Ṣọ́ Àwọn Ẹni Ìdúróṣinṣin Rẹ̀
19, 20. (a) Kí nìdí tó fi dá wa lójú pé Jèhófà kò ní fi wá sílẹ̀ láéláé? (b) Àwọn ìbéèrè wo la óò jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí?
19 Adúróṣinṣin ni Jèhófà Ọlọ́run wa. (Ìṣí. 15:4; 16:5) Ó jẹ́ “adúróṣinṣin nínú gbogbo iṣẹ́ rẹ̀.” (Sm. 145:17) Bíbélì sì mú un dá wa lójú pé: “Yóò . . . máa ṣọ́ ọ̀nà àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀.” (Òwe 2:8) Nígbà tí wọ́n bá dojú kọ àdánwò tàbí èrò àwọn apẹ̀yìndà tàbí nígbà tí wọ́n bá ń jẹ́ iṣẹ́ kan tó ṣòroó jẹ́, àwọn ẹni ìdúróṣinṣin Ọlọ́run mọ̀ dájú pé Jèhófà yóò máa ṣọ́ àwọn, yóò sì máa tì àwọn lẹ́yìn.
20 Ìbéèrè tó yẹ́ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ronú lé lórí rèé: Kí ló máa jẹ́ kí n lé máa bá a nìṣó láti jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà láìka àwọn àdánwò tí mo lè bá pàdé sí? Tàbí ká bi ara wa pé, báwo ni mo ṣe lè túbọ̀ fẹsẹ̀ múlẹ̀ lórí ìdúróṣinṣin mi sí Ọlọ́run?
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e, a ó mọ̀ bóyá wòlíì yìí ń bá a lọ láti máa ṣègbọràn sí Jèhófà tàbí kò ṣe bẹ́ẹ̀, a sì tún máa mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Báwo ni Jèhófà ṣe fi hàn pé òun kì í fi àwọn ẹni ìdúróṣinṣin òun sílẹ̀ nígbà tí wọ́n bá dojú kọ ìnilára?
• Kí ló yẹ ká ṣe sí èrò táwọn apẹ̀yìndà bá gbé wá?
• Báwo ni Jèhófà ṣe ń ṣọ́ àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀ bí wọ́n ṣe ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni?
[Àwòrán ilẹ̀/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
ÌJỌBA ÌHÀ ÀRÍWÁ (Jèróbóámù)
Dánì
ṢÉKÉMÙ
Bẹ́tẹ́lì
ÌJỌBA ÌHÀ GÚÚSÙ (Rèhóbóámù)
JERÚSÁLẸ́MÙ
[Àwòrán]
Jèhófà ò pa àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀ tì nígbà tí Jèróbóámù gbé ìjọsìn ère ọmọ màlúù kalẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]
Ìbùkún tí Sólómọ́nì àtàwọn tó wà lábẹ́ ìṣàkóso rẹ̀ ń gbádùn sinmi lórí nǹkan kan