ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • lfb ẹ̀kọ́ 63 ojú ìwé 150-ojú ìwé 151 ìpínrọ̀ 1
  • Ọ̀rọ̀ Tó Hàn Lára Ògiri

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọ̀rọ̀ Tó Hàn Lára Ògiri
  • Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìkọ̀wé Lára Ògiri
    Ìwé Ìtàn Bíbélì
  • Àwọn Èèyàn Ọlọ́run Kúrò Ní Bábílónì
    Ìwé Ìtàn Bíbélì
  • Ọ̀rọ̀ Mẹ́rin tí Ó yí Ayé Padà
    Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì
  • Onígbèéraga Adelé Ọba Kan Pàdánù Ilẹ̀ Ọba Kan
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
lfb ẹ̀kọ́ 63 ojú ìwé 150-ojú ìwé 151 ìpínrọ̀ 1
Ọwọ́ kan ń kọ ọ̀rọ̀ sára ògiri

Ẹ̀KỌ́ 63

Ọ̀rọ̀ Tó Hàn Lára Ògiri

Nígbà tó yá, Bẹliṣásárì di ọba Bábílónì. Lálẹ́ ọjọ́ kan, ó pe ẹgbẹ̀rún kan (1,000) lára àwọn èèyàn pàtàkì ìlú láti wá ṣe àríyá. Ó sì pàṣẹ fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé kí wọ́n kó àwọn kọ́ọ̀bù tí wọ́n fi wúrà ṣe wá, èyí tí Nebukadinésárì kó nínú tẹ́ńpìlì Jèhófà. Bẹliṣásárì àtàwọn àlejò ẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í fi àwọn kọ́ọ̀bù náà mu ọtí, wọ́n sì ń júbà òrìṣà wọn. Lójijì, wọ́n rí ọwọ́ kan tó ń kọ àwọn ọ̀rọ̀ tí wọn ò mọ̀ sára ògiri.

Ẹ̀rù ba Bẹliṣásárì gan-an. Ó pe àwọn pidánpidán rẹ̀, ó sì ṣèlérí fún wọn pé: ‘Màá sọ ẹni tó bá lè ṣàlàyé àwọn ọ̀rọ̀ yìí fún mi di igbá kẹta mi.’ Gbogbo wọn gbìyànjú, àmọ́ kò sẹ́ni tó lè ṣàlàyé àwọn ọ̀rọ̀ náà. Ayaba wá sọ pé: ‘Ọkùnrin kan wà tó ń jẹ́ Dáníẹ́lì, òun ló máa ń ṣàlàyé nǹkan fún Nebukadinésárì. Ó lè sọ ìtumọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ yìí fún yín.’

Nígbà tí Dáníẹ́lì dé ọ̀dọ̀ Ọba Bẹliṣásárì, ọba sọ fún Dáníẹ́lì pé: ‘Tó o bá lè ka ọ̀rọ̀ yìí tó o sì ṣàlàyé ẹ̀, màá fún ẹ ní ìlẹ̀kẹ̀ wúrà kan, màá sì sọ ẹ́ di igbá kẹta mi.’ Dáníẹ́lì sọ pé: ‘Mi ò fẹ́ ẹ̀bùn ẹ, àmọ́ màá sọ ohun táwọn ọ̀rọ̀ yìí túmọ̀ sí. Nebukadinésárì tó jẹ́ bàbá rẹ jẹ́ agbéraga, Jèhófà sì rẹ̀ ẹ́ wálẹ̀. Ìwọ náà mọ gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i nígbà yẹn, síbẹ̀ o rí Jèhófà fín, torí pé ò ń fi kọ́ọ̀bù tí wọ́n kó látinú tẹ́ńpìlì rẹ̀ mu wáìnì. Nítorí náà, ohun tí Ọlọ́run kọ rèé: Ménè, Ménè, Tékélì àti Párásínì. Ohun tí ọ̀rọ̀ yìí sì túmọ̀ sí ni pé àwọn ará Mídíà àti Páṣíà máa ṣẹ́gun Bábílónì, wọ́n sì máa gba ìjọba lọ́wọ́ rẹ.’

Àwọn ọmọ ogun Kírúsì gba inú odò kọjá, títí dé ẹnu géètì Bábílónì

Ògiri ìlú Bábílónì lágbára gan-an, omi ńlá ló sì yí ìlú náà ká. Ńṣe ló dà bíi pé kò sẹ́ni tó lè ṣẹ́gun wọn. Ṣùgbọ́n òru ọjọ́ yẹn gangan làwọn ará Mídíà àti Páṣíà gbógun jà wọ́n. Kírúsì ọba Páṣíà ní káwọn ọmọ ogun ẹ̀ gbẹ́ ibi tí omi tó yí ìlú náà ká máà gbà, kómi náà lè ṣàn lọ. Wọ́n wá fẹsẹ̀ rìn dé ẹnu géètì ìlú náà. Nígbà tí wọ́n dé ẹnu géètì, ńṣe ni wọ́n ṣí i sílẹ̀ gbayawu! Làwọn ọmọ ogun bá ya wọlé, wọ́n ṣẹ́gun ìlú Bábílónì, wọ́n sì pa Bẹliṣásárì. Kírúsì wá di ọba Bábílónì.

Láàárín ọdún kan sígbà yẹn, Kírúsì kéde pé: ‘Jèhófà ti sọ fún mi pé kí n lọ tún tẹ́ńpìlì ẹ̀ tó wà ní Jerúsálẹ́mù kọ́. Ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ láti ṣèrànwọ́ lè lọ ṣe bẹ́ẹ̀.’ Torí náà, gẹ́gẹ́ bí ìlérí tí Jèhófà ṣe, ọ̀pọ̀ lára àwọn Júù pa dà sí Jerúsálẹ́mù lẹ́yìn àádọ́rin (70) ọdún tó ti pa run. Kírúsì dá gbogbo kọ́ọ̀bù wúrà àti fàdákà àtàwọn ohun èlò tí Nebukadinésárì kó nínú tẹ́ńpìlì Jèhófà pa dà. Ṣé o rí bí Jèhófà ṣe lo Kírúsì láti ran àwọn èèyàn ẹ̀ lọ́wọ́?

“Ó ti ṣubú! Bábílónì Ńlá ti ṣubú, ó sì ti di ibi tí àwọn ẹ̀mí èṣù ń gbé.”​—Ìfihàn 18:2

Ìbéèrè: Kí ni ọ̀rọ̀ tó hàn lára ògiri, kí ló sì túmọ̀ sí? Kí ni Jèhófà ní kí Kírúsì ṣe?

Ẹ́sírà 1:1-11; Dáníẹ́lì 5:1-30; Àìsáyà 44:27–45:2; Jeremáyà 25:11, 12

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́