ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • lfb ẹ̀kọ́ 64 ojú ìwé 152-ojú ìwé 153 ìpínrọ̀ 4
  • Wọ́n Ju Dáníẹ́lì Sínú Ihò Kìnnìún

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wọ́n Ju Dáníẹ́lì Sínú Ihò Kìnnìún
  • Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Dáníẹ́lì Nínú Ihò Kìnnìún
    Ìwé Ìtàn Bíbélì
  • A Gbà Á Sílẹ̀ Lẹ́nu Àwọn Kìnnìún!
    Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì
  • Dáníẹ́lì Fi Ìdúró Gbọn-in Ṣiṣẹ́ Sin Ọlọ́run
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Dáríúsì—Ọba Onídàájọ́ Òdodo
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
Àwọn Míì
Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
lfb ẹ̀kọ́ 64 ojú ìwé 152-ojú ìwé 153 ìpínrọ̀ 4
Àwọn ọkùnrin tó ń jowú Dáníẹ́lì mú un níbi tó ti ń gbàdúrà

Ẹ̀KỌ́ 64

Wọ́n Ju Dáníẹ́lì Sínú Ihò Kìnnìún

Ọba míì tó jẹ ní Bábílónì ni Dáríúsì ará Mídíà. Dáríúsì rí i pé èèyàn tó dáa ni Dáníẹ́lì. Ó sì fi Dáníẹ́lì ṣe olórí àwọn èèyàn pàtàkì tó wà nílùú. Àwọn èèyàn pàtàkì yìí wá bẹ̀rẹ̀ sí í jowú Dáníẹ́lì, wọ́n sì ń wá ọ̀nà láti pa á. Wọ́n mọ̀ pé Dáníẹ́lì máa ń gbàdúrà sí Jèhófà lẹ́ẹ̀mẹ́ta lójúmọ́, wọ́n wá lọ sọ fún Dáríúsì pé: ‘Kábíyèsí, ó yẹ kẹ́ ẹ ṣe òfin pé ẹ̀yin nìkan ni gbogbo èèyàn gbọ́dọ̀ máa gbàdúrà sí. Ẹnikẹ́ni tó bá ṣàìgbọràn sí òfin yìí, kí wọ́n jù ú sínú ihò kìnnìún.’ Ohun tí wọ́n sọ yìí dáa lójú Dáríúsì, ó sì fàṣẹ sí i.

Bí Dáníẹ́lì ṣe gbọ́ nípa òfin tuntun náà, ó lọ sílé. Ó kúnlẹ̀ síbi wíńdò tó wà ní ṣíṣí sílẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà sí Jèhófà. Àwọn ọkùnrin tí wọ́n ń jowú ẹ̀ já wọnú ilé ẹ̀, wọ́n sì ká a mọ́ ibi tó ti ń gbàdúrà. Wọ́n sáré lọ bá Dáríúsì, wọ́n ní: ‘Dáníẹ́lì ti ṣàìgbọràn sí ẹ. Bó ṣe máa ń gbàdúrà sí Ọlọ́run ẹ̀ ní ìgbà mẹ́ta lójúmọ́ nìyẹn.’ Dáríúsì fẹ́ràn Dáníẹ́lì, kò sì fẹ́ kó kú. Ńṣe ló ń ronú bó ṣe máa yọ Dáníẹ́lì kúrò nínú wàhálà yìí. Àmọ́, ìṣòro ibẹ̀ ni pé ọba ò lásẹ láti yí òfin tí wọ́n ti fi òǹtẹ̀ lù pa dà, ì báà jẹ́ òfin tóun fúnra ẹ̀ ṣe. Ló bá pàṣẹ pé kí wọ́n lọ ju Dáníẹ́lì sínú ihò kìnnìún.

Lálẹ́ ọjọ́ yẹn, Dáríúsì kò lè sùn torí pé ọkàn ẹ̀ ò balẹ̀ rárá. Nígbà tílẹ̀ mọ́, ó sáré lọ síbi ihò náà, ó sì pe Dáníẹ́lì, ó ní: ‘Ṣé Ọlọ́run rẹ̀ gbà ẹ́ là?’

Dáríúsì gbọ́ ohùn kan. Ohùn Dáníẹ́lì ni! Ó dá Dáríúsì lóhùn pé: ‘Áńgẹ́lì Jèhófà pa ẹnu àwọn kìnnìún náà dé. Wọn ò ṣe mí léṣe.’ Inú Dáríúsì dùn gàn-an! Ó pàṣẹ pé kí wọ́n fa Dáníẹ́lì jáde nínú ihò náà. Kò sí àpá kankan lára Dáníẹ́lì. Ọba wá pàṣẹ pé: ‘Ẹ ju àwọn ọkùnrin tó fẹ́ pa Dáníẹ́lì sínú ihò náà.’ Nígbà tí wọ́n jù wọ́n sínú ihò yẹn, ńṣe ni àwọn kìnnìún náà fà wọ́n ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ.

Dáríúsì wá pàṣẹ fún gbogbo èèyàn pé: ‘Kí gbogbo yín máa bẹ̀rù Ọlọ́run tí Dáníẹ́lì ń sìn. Ó gba Dáníẹ́lì lọ́wọ́ àwọn kìnnìún.’

Ṣé o máa ń gbàdúrà sí Jèhófà lójoojúmọ́ bíi Dáníẹ́lì?

Dáníẹ́lì nínú ihò kìnnìún

“Jèhófà mọ bó ṣe ń gba àwọn èèyàn tó ń sìn ín tọkàntọkàn sílẹ̀ lọ́wọ́ àdánwò.”​—2 Pétérù 2:9

Ìbéèrè: Kí ni Dáníẹ́lì máa ń ṣe lẹ́ẹ̀mẹ́ta lójúmọ́? Báwo ni Jèhófà ṣe gba Dáníẹ́lì là?

Dáníẹ́lì 6:1-28

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́