Ẹ̀KỌ́ 81
Ìwàásù Orí Òkè
Lẹ́yìn tí Jésù yan àwọn àpọ́sítélì méjìlá náà, ó sọ̀ kalẹ̀ látorí òkè, ó sì lọ síbi táwọn èrò rẹpẹtẹ jókòó sí. Àwọn èèyàn náà wá láti Gálílì, Jùdíà, Tírè, Sídónì, Síríà àtàwọn ìlú míì tó wà ní ìsọdá Odò Jọ́dánì. Wọ́n gbé àwọn tó ní oríṣiríṣi àìsàn wá sọ́dọ̀ Jésù àtàwọn tí ẹ̀mí èṣù ń yọ lẹ́nu, ó sì wo gbogbo wọn sàn. Lẹ́yìn ìyẹn, Jésù jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ òkè náà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀. Ó sọ àwọn nǹkan tá a gbọ́dọ̀ máa ṣe tá a bá fẹ́ di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. A gbọ́dọ̀ jẹ́ kí Jèhófà máa tọ́ wa sọ́nà, ká sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Àmọ́, a ò lè nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tá ò bá nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn. A gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ gbogbo èèyàn, ká sì máa ṣe dáadáa sí wọn títí kan àwọn tó kórìíra wa pàápàá.
Jésù sọ pé: ‘Kì í ṣe àwọn ọ̀rẹ́ rẹ nìkan ló yẹ kó o nífẹ̀ẹ́, ó yẹ kó o nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá ẹ náà, kó o sì máa dárí jì wọ́n. Tẹ́nì kan bá sọ pé o ṣẹ òun, tètè lọ bá a, kó o sì bẹ̀ ẹ́ pé kó má bínú. Ohun tó o bá sì fẹ́ káwọn èèyàn ṣe sí ẹ ni kíwọ náà máa ṣe sí wọn.’
Jésù tún sọ pé ká má ṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ owó ká wa lára jù. Ó sọ pé: ‘Ó dáa kéèyàn jẹ́ ọ̀rẹ́ Jèhófà ju kéèyàn jẹ́ olówó lọ. Torí pé àwọn olè lè jí owó èèyàn lọ, àmọ́ kò sẹ́ni tó lè jí àwọn ìbùkún tá à ń rí látinú àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà. Ẹ má dààmú jù nípa ohun tẹ́ ẹ máa jẹ, ohun tẹ́ ẹ máa mu tàbí ohun tẹ́ ẹ máa wọ̀. Ẹ wo àwọn ẹyẹ, wọn ò ṣiṣẹ́, àmọ́ Jèhófà máa ń rí i pé wọ́n ní oúnjẹ tó pọ̀ láti jẹ. Tẹ́ ẹ bá ń da ara yín láàmú jù, ìyẹn ò ní fi ọjọ́ kan kún ọjọ́ ayé yín. Ẹ rántí pé Jèhófà mọ gbogbo ohun tẹ́ ẹ nílò.’
Àwọn èèyàn yẹn ò rẹ́ni tó sọ̀rọ̀ bíi Jésù rí. Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn wọn ò kọ́ wọn láwọn ohun tí Jésù kọ́ wọn. Àmọ́, kí ló mú kí Jésù mọ èèyàn kọ́ dáadáa? Ìdí ni pé ohun tí Jèhófà sọ ló ń kọ́ àwọn èèyàn.
“Ẹ gba àjàgà mi sọ́rùn yín, kí ẹ sì kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi, torí oníwà tútù àti ẹni tó rẹlẹ̀ ní ọkàn ni mí, ara sì máa tù yín.”—Mátíù 11:29