Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú fún Apá 14
Àwọn tó kọ́kọ́ di Kristẹni wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run dé àwọn ibi tó jìnnà jù láyé. Jésù ló pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n wàásù, ó sì ṣe iṣẹ́ ìyanu tó jẹ́ kí wọ́n lè máa fi oríṣiríṣi èdè kọ́ àwọn èèyàn. Jèhófà tún jẹ́ kí wọ́n nígboyà, ó sì fún wọn lágbára kí wọ́n lè borí àtakò tó le.
Jésù fi ìran kan han àpọ́sítélì Jòhánù, ó sì jẹ́ kó rí ògo Jèhófà. Nínú ìran míì, Jòhánù rí bí Jésù àtàwọn áńgẹ́lì ẹ̀ ṣe ṣẹ́gun Sátánì, tí wọn ò sì jé kó máa ṣiṣẹ́ ibi mọ́ títí láé. Jòhánù rí i tí Jésù di Ọba, ó sì rí àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) tó ń jọba pẹ̀lú ẹ̀. Jòhánù tún rí bí gbogbo ayé ṣe di Párádísè, tí gbogbo èèyàn wà ní àlàáfíà, tí wọ́n sì ń jọ́sìn Jèhófà níṣọ̀kan.