January
Sunday, January 1
Àwọn nǹkan tí ìwọ sì ti gbọ́ lọ́dọ̀ mi . . . ni kí o fi lé àwọn olùṣòtítọ́ lọ́wọ́, tí àwọn, ẹ̀wẹ̀, yóò tóótun tẹ́rùntẹ́rùn láti kọ́ àwọn ẹlòmíràn.—2 Tím. 2:2.
Kárí ayé, àwọn alábòójútó àyíká ti kíyè sí i pé ó yẹ kí ọ̀pọ̀ ìjọ ṣe púpọ̀ sí i láti dá àwọn ọ̀dọ́ àtàwọn àgbàlagbà ọkùnrin lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè bójú tó agbo Ọlọ́run. Lóòótọ́, èyí lè má rọrùn. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? Tó o bá jẹ́ alàgbà ìjọ, o mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì kó o máa dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́. O mọ̀ pé a nílò àwọn arákùnrin púpọ̀ sí i kí ìjọ lè máa lágbára nípa tẹ̀mí, kí a sì lè dá àwọn ìjọ tuntun sílẹ̀. (Aísá. 60:22) O tún mọ̀ pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbà wá níyànjú pé kí a “kọ́ àwọn ẹlòmíràn.” Síbẹ̀, ó lè má rọrùn fún ẹ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Lẹ́yìn tó o bá bójú tó ìdílé rẹ, tó o ṣiṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́, tó o ṣe ojúṣe rẹ nínú ìjọ, tó o sì tún bójú tó àwọn ọ̀ràn míì tó jẹ́ kánjúkánjú, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé kò sí àyèláti dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́ nínú ìjọ. Síbẹ̀, wọ́n nílò ìdálẹ́kọ̀ọ́ kí wọn bàa lè ṣèrànwọ́ láti bójú tó iṣẹ́ nínú ìjọ. Ìdálẹ́kọ̀ọ́ yìí sì máa wá ṣe gbogbo èèyàn láǹfààní. w15 4/15 1:2, 3
Monday, January 2
Tímótì . . . jẹ́ ọmọ mi olùfẹ́ ọ̀wọ́n àti olùṣòtítọ́ nínú Olúwa; yóò sì rán yín létí àwọn ọ̀nà tí mo gbà ń ṣe nǹkan.—1 Kọ́r. 4:17.
Kí arákùnrin tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn sípò má ṣe ronú pé gbàrà tí wọ́n bá ti fún òun láwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn kan nínú ìjọ, òun gbọ́dọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í lò ó láti fi yí nǹkan pa dà, kó wá máa ṣe nǹkan lọ́nà tó yàtọ̀ pátápátá sí bí wọ́n ṣe ń ṣe é tẹ́lẹ̀. Ẹnì kan kọ́ lo máa pinnu ìgbà tó yẹ kí nǹkan yí pa dà. Ohun tí ìjọ nílò àti ìtọ́ni tá a bá rí gbà látọ̀dọ̀ ètò Jèhófà ló máa jẹ́ ká mọ ìgbà tó yẹ kí ìyípadà wáyé. Torí náà, tí wọ́n bá yàn ẹ́ sípò, jẹ́ kí ọkàn àwọn tẹ́ ẹ jọ jẹ́ onígbàgbọ́ balẹ̀, kó o sì bọ̀wọ̀ fún àwọn alàgbà onírìírí nípa ṣíṣe nǹkan lọ́nà tí wọ́n gbà ń ṣe é tí kò sì ta ko ìlànà Bíbélì. Àmọ́, bí o ṣe ń ní ìrírí sí i, ó dájú pé ìwọ̀ náà á wà lára àwọn tó ń ran ìjọ lọ́wọ́ láti ṣe àwọn àyípadà táá jẹ́ kí wọ́n lè máa bá ètò Jèhófà tó ń tẹ̀ síwájú rìn. Kódà, Jèhófà ṣì lè lo gbogbo ẹ̀yin akẹ́kọ̀ọ́ tẹ́ ẹ jẹ́ olóòótọ́ láti ṣe àwọn iṣẹ́ tó pọ̀ ju èyí tí àwọn olùkọ́ yín ṣe lọ.—Jòh. 14:12. w15 4/15 2:17
Tuesday, January 3
Èmi yóò mú kí o ní ìjìnlẹ̀ òye, èmi yóò sì fún ọ ní ìtọ́ni nípa ọ̀nà tí ìwọ yóò máa tọ̀. Dájúdájú, èmi yóò fún ọ ní ìmọ̀ràn pẹ̀lú ojú mi lára rẹ.—Sm. 32:8.
Bíi ti Pọ́ọ̀lù, nígbà tí nǹkan bá nira gan-an fún ẹ, ó lè ṣe ẹ́ bíi pé o ti sún mọ́ ẹnu kìnnìún tàbí pé o tiẹ̀ wà “lẹ́nu kìnnìún.” (2 Tím. 4:17) Irú àwọn àkókò yìí ló ṣòro jù lọ láti gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, síbẹ̀ àkókò yìí ló ṣe pàtàkì jù lọ pé kó o gbẹ́kẹ̀ lé e. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé ò ń tọ́jú mọ̀lẹ́bí rẹ kan tó ń ṣàìsàn tó le koko. Bóyá o tiẹ̀ ti gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún ẹ ní ọgbọ́n àti okun. Lẹ́yìn tó o ti ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe, ǹjẹ́ ọkàn rẹ̀ ò ní balẹ̀ torí o mọ̀ pé ojú Jèhófà ń bẹ lára rẹ àti pé ó máa jẹ́ kó o lè fi ìṣòtítọ́ fara da ìṣòro náà? Àmọ́ nígbà míì, ohun tó ṣẹlẹ̀ lè mú kó jọ pé Jèhófà kò ràn ẹ́ lọ́wọ́. Ẹnu àwọn dókítà lè má kò lórí ọ̀nà tó yẹ kí wọ́n gbà tọ́jú àìsàn náà. Tàbí kí àwọn mọ̀lẹ́bí tó o rò pé wọ́n máa tù ẹ́ nínú mú kí nǹkan túbọ̀ nira fún ẹ. Máa wojú Jèhófà pé kó fún ẹ lókun. Túbọ̀ sún mọ́ ọn. (1 Sám. 30:3, 6) Nígbà tí ìtura bá dé wàá rí i pé àjọṣe ìwọ àti Jèhófà á lágbára sí i. w15 4/15 4:10, 11
Wednesday, January 4
Ẹ mú ìdúró yín lòdì sí [Èṣù]. —1 Pét. 5:9.
Ní ti àwa ìránṣẹ́ Jèhófà, a kò sí lára àwọn tí a tàn jẹ, tí wọ́n gbà pé kò sí Sátánì. Àwá mọ̀ pé Sátánì Èṣù wà, torí pé òun ló lo ejò láti bá Éfà sọ̀rọ̀. (Jẹ́n. 3:1-5) Sátánì fẹ̀sùn kan Jèhófà nípa Jóòbù. (Jóòbù 1:9-12) Sátánì kan náà yìí ló dẹ Jésù wò. (Mát. 4:1-10) Nígbà tá a sì bí Ìjọba Ọlọ́run lọ́dún 1914, Sátánì lẹni tó bẹ̀rẹ̀ sí í bá àṣẹ́kù àwọn ẹni àmì òróró “ja ogun.” (Ìṣí. 12:17) Sátánì kò tíì dáwọ́ ogun yìí dúró torí pé ó ṣì ń wá bó ṣe máa pa iná ìgbàgbọ́ àṣẹ́kù ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] àtàwọn àgùntàn mìíràn. Tá a bá máa borí nínú ogun yìí, a gbọ́dọ̀ kọjú ìjà sí Sátánì ká sì rí i pé a di ìgbàgbọ́ wa mú. Sátánì kò lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ rárá àti rárá. Ká sòótọ́, ìgbéraga àti ìkọjá-àyè gbáà ló máa jẹ́ bí áńgẹ́lì kan bá lè gbójúgbóyà sọ pé Jèhófà kò lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso, tí irú áńgẹ́lì bẹ́ẹ̀ sì wá sọ ara rẹ̀ di ọlọ́run níbi tí Jèhófà Ọlọ́run wà. Torí náà, ọ̀nà kan tá a lè gbà kọjú ìjà sí Sátánì ni pé ká má ṣe máa gbéra ga, kàkà bẹ́ẹ̀, ká jẹ́ ẹlẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀.—1 Pét. 5:5. w15 5/15 2:3, 4
Thursday, January 5
Jèhófà yóò nu omijé kúrò ní ojú gbogbo ènìyàn.—Aísá. 25:8.
Ní ti àwa Kristẹni, ó máa ń fún wa níṣìírí bá a ṣe ń fọkàn yàwòrán ìrètí wa, yálà à ń retí láti gbé lókè ọ̀run tàbí lórí ilẹ̀ ayé. Ǹjẹ́ ò ń fọkàn yàwòrán ara ẹ bíi pé ò ń gbádùn àwọn nǹkan tí Ọlọ́run ti ṣèlérí? Ó dájú pé bó o ṣe ń fọkàn yàwòrán àwọn ohun tó o máa ṣe tí Ọlọ́run bá mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ máa jẹ́ kó o láyọ̀ gan-an. Ó ṣeé ṣe kó o máa “rí” ara rẹ pé o ti ń gbé lórí ilẹ̀ ayé títí láé. Ronú lórí bó o ṣe ń pawọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn míì láti sọ gbogbo ayé yìí di Párádísè. Bó o ṣe nífẹ̀ẹ́ Jèhófà náà ni gbogbo èèyàn tẹ́ ẹ jọ wà láyé ṣe nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Koko lara rẹ á máa le, ojú ẹ á sì máa dán gbinrin. Àwọn tó máa ṣe kòkárí bí ayé á ṣe di Párádísè kò mú nǹkan nira rárá torí pé ire rẹ jẹ wọ́n lógún. O sì ń fi tayọ̀tayọ̀ lo ìmọ̀ tó o ní àti ohun tó o mọ̀ ọ́n ṣe, torí pé gbogbo nǹkan tó ò ń ṣe ń ṣàǹfààní fáwọn míì, ó sì ń bọlá fún Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, ò ń ran àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jíǹde lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ Jèhófà. (Jòh. 17:3; Ìṣe 24:15) Èyí kì í ṣe àlá lásán o. Ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa ọjọ́ iwájú lò ń fọkàn yàwòrán rẹ̀ yẹn.—Aísá. 11:9; 33:24; 35:5-7; 65:22. w15 5/15 3:15
Friday, January 6
Olùdarí àsè tọ́ omi tí a ti sọ di wáìnì wò.—Jòh. 2:9.
Jésù pèsè wáìnì àtàtà tó pọ̀ tó fún àwọn tó wá síbi àsè náà lọ́nà ìyanu. (Jòh. 2:6-11) Ó wúni lórí láti mọ̀ pé nígbà tí Èṣù dẹ Jésù wò pé kó sọ àwọn òkúta di àwọn ìṣù búrẹ́dì, Kristi kọ̀ jálẹ̀ láti lo agbára tó ní láti fi tẹ́ ìfẹ́ ọkàn ara rẹ̀ lọ́rùn. (Mát. 4:2-4) Àmọ́, Jésù lo agbára rẹ̀ láti fi ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù nínú bó ṣe jẹ́ kí ọ̀ràn àwọn èèyàn jẹ òun lógún? Ó gba àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run níyànjú pé kí wọ́n “sọ fífúnni dàṣà.” (Lúùkù 6:38) Ǹjẹ́ a lè fi ọ̀làwọ́ tó jẹ́ ànímọ́ tó ṣe pàtàkì yìí hàn sáwọn èèyàn, ká pè wọ́n wá jẹun nílé wa, ká sì tún jọ gbádùn ara wa nípa tẹ̀mí? Ǹjẹ́ ẹ̀mí ọ̀làwọ́ lè mú ká yọ̀ǹda àkókò wa lẹ́yìn ìpàdé láti ran ẹnì kan lọ́wọ́, bíi ká tẹ́tí sí arákùnrin kan tó fẹ́ fi bó ṣe máa ṣe iṣẹ́ rẹ̀ nípàdé hàn wá? Ǹjẹ́ a lè ṣèrànwọ́ fún àwọn tó nílò rẹ̀ lóde ẹ̀rí? Tá a bá ń fi ìwà ọ̀làwọ́ ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí, tá a sì ń fún wọn ní nǹkan ìní bí agbára wa bá ṣe gbé e tó, ńṣe là ń fi hàn pé a ti kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ Jésù. w15 6/15 1:3, 4, 6
Saturday, January 7
Kò sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: “Àìsàn ń ṣe mí.”—Aísá. 33:24.
Tá a bá ń pa ìwà títọ́ wa mọ́ nìṣó, ọ̀kan lára iṣẹ́ ìyanu tó kàmàmà jù lọ lè ṣojú wa, ìyẹn sì ni bá a ṣe máa la ìpọ́njú ńlá já. Láìpẹ́ lẹ́yìn ogun Amágẹ́dọ́nì, ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu ló ṣì máa wáyé, lára rẹ̀ ni bí ẹ̀dá èèyàn ṣe máa ní ìlera pípé. (Aísá. 35:5, 6; Ìṣí. 21:4) Ẹ fojú inú wò ó pé kò sẹ́ni tó ń lo ìgò mọ́, wọn ò lo igi tàbí ọ̀pá mọ́, kò sẹ́ni tó ń lo kẹ̀kẹ́ arọ, ohun tí wọ́n ń kì sétí kí wọ́n tó lè gbọ́ràn àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àwọn tó bá la ogun Amágẹ́dọ́nì já máa ní iṣẹ́ tó pọ̀ láti ṣe. Torí náà, wọ́n máa fi ìdùnnú sọ gbogbo ayé wa yìí tó jẹ́ ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run di Párádísè. (Sm. 115:16) Bí Jésù ṣe wo àwọn èèyàn sàn nígbà kan sẹ́yìn ń fún àwọn “ogunlọ́gọ̀ ńlá” níṣìírí lóde òní, ó túbọ̀ jẹ́ kí ọkàn wọn balẹ̀ bí wọ́n ṣe ń fayọ̀ retí ìgbà tí àìsàn èyíkéyìí kò ní ṣe wọ́n mọ́. (Ìṣí. 7:9) Àwọn iṣẹ́ ìwòsàn náà fi bí ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn ṣe rí lára rẹ̀ hàn, ó sì tún jẹ́ ká mọ̀ pé àkọ́bí Ọmọ Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn gan-an. (Jòh. 10:11; 15:12, 13) Bí Jésù ṣe jẹ́ oníyọ̀ọ́nú jẹ́ àmì pé ọ̀rọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lẹ́nì kọ̀ọ̀kan jẹ ẹ́ lógún.—Jòh. 5:19. w15 6/15 2:16, 17
Sunday, January 8
Ègbé ni fún ilẹ̀ ayé àti fún òkun, nítorí Èṣù ti sọ̀ kalẹ̀ wá bá yín, ó ní ìbínú ńlá, ó mọ̀ pé sáà àkókò kúkúrú ni òun ní.—Ìṣí. 12:12.
Lọ́dún 1914, àwọn orílẹ̀-èdè kan nílẹ̀ Yúróòpù bẹ̀rẹ̀ sí í bá ara wọn jagun, ogun yẹn sì tàn kárí ayé. Ìgbà tó fi máa kásẹ̀ nílẹ̀ lọ́dún 1918, oúnjẹ ti di góòlù, àrùn gágá sì tún fẹ̀mí àwọn èèyàn ṣòfò débi pé iye tí àìsàn náà pa ju iye àwọn tí ogun pa lọ. Torí náà, “àmì” tí Jésù sọ pé ó máa jẹ́ ẹ̀rí wíwàníhìn-ín òun tí a kò lè fojú rí gẹ́gẹ́ bí Ọba tuntun, èyí tí yóò ṣàkóso lórí ayé ti bẹ̀rẹ̀ sí í nímùúṣẹ. (Mát. 24:3-8; Lúùkù 21:10, 11) Ọ̀pọ̀ ẹ̀rí ló fi hàn pé ọdún 1914 ni ìgbà tí Ọlọ́run “fún” Jésù Kristi Olúwa “ní adé.” Torí náà, ó “jáde lọ ní ṣíṣẹ́gun àti láti parí ìṣẹ́gun rẹ̀.” (Ìṣí. 6:2) Kó lè fọ ọ̀run mọ́, ó bá Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ jagun, ó sì lé wọn dà nù sí orí ilẹ̀ ayé. Látìgbà yẹn, àwọn ẹ̀dá èèyàn ti gbà pẹ̀lú ohun tí ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí tó wà nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tòní sọ. w15 6/15 4:13
Monday, January 9
Èmi yóò kọjá lọ sínú àwọn ìran tí ó ju ti ẹ̀dá lọ àti àwọn ìṣípayá ti Olúwa.—2 Kọ́r. 12:1.
Kò tíì pé ọgọ́rùn-ún ọdún lẹ́yìn tí a dá ìjọ Kristẹni sílẹ̀ tí ìpẹ̀yìndà tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ fi bẹ̀rẹ̀. (Ìṣe 20:28-30; 2 Tẹs. 2:3, 4) Èyí wá jẹ́ kó ṣòro gan-an láti mọ àwọn tó ń sin Ọlọ́run tọkàntọkàn nínú tẹ́ńpìlì tẹ̀mí rẹ̀. Ṣùgbọ́n ní ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún lẹ́yìn náà, àkókò tó fún Jèhófà láti mú kí àwọn nǹkan ṣe kedere nípasẹ̀ Ọba tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé gorí ìtẹ́, ìyẹn Jésù Kristi. Ní ọdún 1919, àwọn tí Jèhófà fọwọ́ sí, tí wọ́n ń sìn nínú tẹ́ńpìlì tẹ̀mí rẹ̀ ti fara hàn kedere. A ti yọ́ wọn mọ́ nípa tẹ̀mí kí ìjọsìn wọn lè túbọ̀ ṣètẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run. (Aísá. 4:2, 3; Mál. 3:1-4) Lára ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rí nínú ìran ní ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún ṣáájú ìgbà yẹn wá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ. Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé ìran tó rí nínú 2 Kọ́ríńtì 12:2-4. Ó pe ohun tó rí nínú ìran tó ju ti ẹ̀dá lọ náà ní ìṣípayá. Ìṣípayá náà ò ní í ṣe pẹ̀lú ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà ayé rẹ̀, ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú ni. w15 7/15 1:6-8
Tuesday, January 10
Ní àkókò yẹn, àwọn olódodo yóò máa tàn yòò bí oòrùn nínú ìjọba Baba wọn.—Mát. 13:43.
Ṣé ohun tí èyí wá túmọ̀ sí ni pé a máa “gba” àwọn ẹni àmì òróró “lọ” sí ọ̀run? Bí ọ̀rọ̀ tí Bíbélì lò yìí ṣe yé ọ̀pọ̀ àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì sí nìyẹn. Wọ́n gbà pé a máa gba àwọn Kristẹni lọ sọ́run nínú ẹran ara. Àti pé lẹ́yìn náà, wọ́n á fi ojúyòójú rí Jésù nígbà ìpadàbọ̀ rẹ̀ láti wá máa ṣàkóso ayé. Àmọ́, Bíbélì jẹ́ kó ṣe kedere pé “àmì Ọmọ ènìyàn” máa fara hàn ní ọ̀run, Jésù yóò sì máa bọ̀ “lórí àwọsánmà ọ̀run.” (Mát. 24:30) Ohun tí gbólóhùn méjèèjì yìí túmọ̀ sí ni pé a kò ní lè fi ojúyòójú rí Jésù. Ní àfikún sí ìyẹn, “ẹran ara àti ẹ̀jẹ̀ kò lè jogún ìjọba Ọlọ́run.” Torí náà, a gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ “yí” àwọn tá a máa mú lọ sọ́run “padà, ní ìṣẹ́jú kan, ní ìpajúpẹ́, nígbà kàkàkí ìkẹyìn.” (1 Kọ́r. 15:50-53) Àwọn olóòótọ́ ẹni àmì òróró tó ṣẹ́ kù ni a óò sì kó jọpọ̀ lójú ẹsẹ̀. w15 7/15 2:14, 15
Wednesday, January 11
Èmi yóò máa yìn ọ́ ní àárín ìjọ.—Sm. 22:22.
Gbọ̀ngàn Ìjọba jẹ́ ibi tá à ń pé jọ sí láti ṣe ìjọsìn mímọ́ ní àgbègbè ibi tí à ń gbé. Àwọn ìpàdé tí à ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ ní Gbọ̀ngàn Ìjọba wà lára àwọn ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà fi oúnjẹ tẹ̀mí bọ́ wa. Ibẹ̀ la ti ń rí ìtura tá a nílò nípa tẹ̀mí àti ìtọ́sọ́nà gbà nípasẹ̀ ètò rẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ti pè wá láti wá jẹun lórí ‘tábìlì rẹ̀,’ a kò gbọ́dọ̀ fojú kéré irú ìkésíni bẹ́ẹ̀ láé. (1 Kọ́r. 10:21) Jèhófà ka àkókò tí a fi ń jọ́sìn rẹ̀, tí a sì fi ń fún ara wa níṣìírí sí pàtàkì. Ó mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti rọ̀ wá pé ká má ṣe máa kọ ìpéjọpọ̀ ara wa sílẹ̀. (Héb. 10:24, 25) Tí a bá ń pa àwọn ìpàdé jẹ torí àwọn ìdí tí kò pọn dandan, ǹjẹ́ ìyẹn á fi hàn pé à ń fi ọ̀wọ̀ hàn fún Jèhófà? A lè fi hàn ní ti gidi pé a mọrírì àwọn ìpèsè Jèhófà tá a bá ń múra àwọn ìpàdé sílẹ̀ tá a sì ń lóhùn sí àwọn ìpàdé náà tọkàntọkàn. w15 7/15 4:3, 4
Thursday, January 12
Ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà.—Mát. 24:42.
Jésù sọ pé ká máa ṣọ́nà, ìyẹn sì jẹ́ ìdí pàtàkì tó fi yẹ ká máa ṣe bẹ́ẹ̀. Nípa báyìí, ètò Jèhófà ń jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè máa ṣọ́nà. Ìgbà gbogbo ni àwọn ìtẹ̀jáde ètò Ọlọ́run ń gbà wá níyànjú pé ká máa ‘dúró de wíwàníhìn-ín ọjọ́ Jèhófà,’ ká máa ‘fi í sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí,’ ká sì máa gbé ìrètí wa karí ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí. (2 Pét. 3:11-13) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣe pàtàkì pé kí àwọn Kristẹni tí wọ́n gbé ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní máa sọ́nà, ó pọn dandan pé kí àwa náà máa ṣọ́nà lóde òní. Kí nìdí? Ìdí ni pé à ń gbé ní àkókò wíwàníhìn-ín Kristi. Láti ọdún 1914 la ti ń rí àmì wíwàníhìn-ín rẹ̀. Lára àmì alápá púpọ̀ yìí ni ipò ayé tó ń burú sí i àti ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run tá à ń wàásù rẹ̀ kárí ayé, èyí sì ń fi hàn pé à ń gbé ní “ìparí ètò àwọn nǹkan.” (Mát. 24:3, 7-14) Jésù ò sọ bí àkókò náà ṣe máa pẹ́ tó kí òpin tó dé, torí náà, ó yẹ ká túbọ̀ máa wà lójúfò, ká sì máa ṣọ́nà. w15 8/15 2:4, 5
Friday, January 13
Máa ní inú dídùn kíkọyọyọ nínú Jèhófà.—Sm. 37:4.
Àwọn ìpèsè tẹ̀mí tí Ọlọ́run máa fún wa nínú ayé tuntun ló máa mú ká láyọ̀ jù lọ. (Mát. 5:3) Àwọn nǹkan tó ní í ṣe pẹ̀lú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run ló máa gbawájú, àá sì máa fi hàn pé à ń ní inú dídùn kíkọyọyọ nínú Jèhófà. Tá a bá ń jẹ́ kí àwọn nǹkan tẹ̀mí gbawájú nínú ìgbésí ayé wa nísinsìnyí, à ń múra sílẹ̀ fún gbígbé nínú ayé tuntun nìyẹn. (Mát. 6:19-21) Báwo la ṣe lè jẹ́ kí ayọ̀ tá à ń rí nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run máa pọ̀ sí i? Ọ̀nà kan tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká ní àwọn àfojúsùn tẹ̀mí. Tó o bá jẹ́ ọ̀dọ́, tó o sì ń ronú jinlẹ̀ nípa bó o ṣe lè fi ìgbésí ayé rẹ ṣe iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, o ò ṣe ka àwọn ìtẹ̀jáde kan tó sọ̀rọ̀ nípa onírúurú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún kó o sì fi ọ̀kan lára wọn ṣe àfojúsùn rẹ? O tún lè bá àwọn tó ti lo ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún sọ̀rọ̀. Tó bá jẹ́ iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run lo pinnu láti fi ìgbésí ayé rẹ ṣe, ò ń múra sílẹ̀ láti máa ṣe iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run nìṣó nínú ayé tuntun nìyẹn. Àwọn ìrírí àti ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó o ti rí gbà á sì wúlò fún ẹ gan-an. w15 8/15 3:13, 14
Saturday, January 14
Èso ti ẹ̀mí ni ìfẹ́.—Gál. 5:22.
Àwọn apá míì lára èso tẹ̀mí irú bí, ìwà tútù, ìkóra-ẹni-níjàánu àti ìpamọ́ra tún ṣe pàtàkì. (Gál. 5:23) Wọ́n á mú kí Kristẹni kan tó dàgbà dénú máa fẹ̀sọ̀ yanjú àwọn ìṣòro tó bá jẹ yọ kó sì máa fara da àwọn ìjákulẹ̀ tó ń bani nínú jẹ́ láìsọ ìrètí nù. Gbogbo ìgbà tó bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́ ló máa ń ṣèwádìí lórí àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ tó lè ràn án lọ́wọ́ láti fìyàtọ̀ sáàárín ohun tó tọ́ àtèyí tí kò tọ́. Á wá hàn nínú àwọn ìpinnu tó bá ṣe lẹ́yìn náà pé ó dàgbà dénú. Bí àpẹẹrẹ, ohun tí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ tó ti fi Bíbélì kọ́ bá sọ fún un ló máa ń ṣe. Kristẹni kan tó dàgbà dénú á tún jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ torí ó mọ̀ pé ìgbà gbogbo ni ọ̀nà Jèhófà àtàwọn ìlànà rẹ̀ máa ń dára ju tòun lọ. Ó máa ń fìtara wàásù ìhìn rere, ó sì máa ń pa kún ìṣọ̀kan tó wà nínú ìjọ. Láìka bó ti pẹ́ tó tá a ti ń sin Jèhófà, ó yẹ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa bi ara rẹ̀ pé, ‘Ǹjẹ́ àwọn ìyípadà kan ṣì wà tó yẹ kí n ṣe kí n lè máa tẹ̀ lé ìṣísẹ̀ Jésù pẹ́kípẹ́kí, kí n sì tipa bẹ́ẹ̀ mú kí àjọṣe mi pẹ̀lú Jèhófà sunwọ̀n sí i?’ w15 9/15 1:6, 7
Sunday, January 15
Ìwọ tí o ní ìgbàgbọ́ kíkéré, èé ṣe tí ìwọ fi bẹ̀rẹ̀ sí ṣe iyèméjì?—Mát. 14:31.
Àwọn ọmọ ẹ̀yìn rí Jésù tó ń rìn lórí Òkun Gálílì. Pétérù béèrè lọ́wọ́ Jésù tó jẹ́ Ọ̀gá rẹ̀ bóyá òun lè máa tọ̀ ọ́ bọ̀. Nígbà tí Jésù sọ fún Pétérù pé kó máa bọ̀, ó kúrò nínú ọkọ̀ náà, ó sì rìn tọ Jésù lọ lórí omi tó ń ru gùdù náà. Àmọ́, kò pẹ́ lẹ́yìn yẹn tí Pétérù fi bẹ̀rẹ̀ sí í rì. Kí ló fà á? Ó wo ìjì ẹlẹ́fùúùfù náà, ẹ̀rù sì bà á. Pétérù lọgun pé kí Jésù gba òun, Jésù yára gbá a mú ó sì sọ ọ̀rọ̀ tó wà lókè yìí. (Mát. 14:24-32) Ìgbàgbọ́ tí Pétérù ní ló mú kó kúrò nínú ọkọ̀ náà, kó lè rìn lórí omi. Jésù ló ní kí Pétérù máa bọ̀, Pétérù sì nígbàgbọ́ pé Ọlọ́run á fún òun lágbára láti rìn lórí omi bíi ti Jésù. Bí ọ̀rọ̀ tiwa náà ṣe rí nìyẹn nígbà tá a ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà tá a sì ṣèrìbọmi. Ìgbàgbọ́ tá a ní nínú Ọlọ́run ló mú ká ṣe bẹ́ẹ̀. Jésù ní ká wá di ọmọlẹ́yìn òun, ká sì máa tẹ̀ lé ìṣísẹ̀ òun. A gbọ́dọ̀ lo ìgbàgbọ́ nínú Jésù àti Ọlọ́run, kó sì dá wa lójú pé wọ́n á máa tì wá lẹ́yìn ní gbogbo ọ̀nà.—Jòh. 14:1; 1 Pét. 2:21. w15 9/15 3:1, 3
Monday, January 16
Ó ń ṣọ́ ọkàn àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀; ó ń dá wọn nídè kúrò lọ́wọ́ àwọn ẹni burúkú.—Sm. 97:10.
Ó dájú pé ọ̀kan lára ohun tí bàbá onífẹ̀ẹ́ kan máa ń kà sí pàtàkì ni bó ṣe máa dáàbò bo ìdílé rẹ̀ kó sì pa wọ́n mọ́ lọ́wọ́ ewu tàbí ohun tó lè ṣèpalára fún wọn. Ohun tí Jèhófà, Baba wa ọ̀run náà máa ń ṣe nìyẹn. Jẹ́ ká wò ó báyìí ná: O ka ojú rẹ sí ohun tó ṣeyebíye, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Bí Jèhófà náà ṣe ka àwọn èèyàn rẹ̀ sí iyebíye nìyẹn. (Sek. 2:8) Ẹ sì wo bí àwọn èèyàn Ọlọ́run ṣe ṣeyebíye tó lójú rẹ̀! Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Sítéfánù jẹ́ ká rí i pé nígbà míì Jèhófà lè yọ̀ǹda pé kí àwọn ọ̀tá gba ẹ̀mí ẹnì kan tó jẹ́ olóòótọ́. Síbẹ̀, Ọlọ́run máa ń dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀ lápapọ̀ nípa fífún wọn ní àwọn ìkìlọ̀ tó bágbà mu nípa àwọn ètekéte Sátánì. (Éfé. 6:10-12) Nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àtàwọn ìtẹ̀jáde tó ń ṣàlàyé Bíbélì tí ètò Ọlọ́run ń mú jáde, à ń mọ ewu tó wà nínú eré ìnàjú tó ń gbé ìṣekúṣe àti ìwà ipá lárugẹ, lílo Íńtánẹ́ẹ̀tì lọ́nà tí kò tọ́, agbára ẹ̀tàn tí ọrọ̀ ní àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ó wá ṣe kedere pé Bàbá onífẹ̀ẹ́ ni Jèhófà, ó ń dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀, kò sì fẹ́ kí ohunkóhun wu wọ́n léwu. w15 9/15 4:15, 17
Tuesday, January 17
Ọwọ́ Jèhófà kò kúrú jù tí kò fi lè gbani là.—Aísá. 59:1.
Bí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń ‘gbèjà ìhìn rere tá a sì ń fìdí rẹ̀ múlẹ̀ lọ́nà òfin’ tún fi hàn pé Jèhófà ló ń fi agbára ńlá rẹ̀ ti iṣẹ́ náà lẹ́yìn. (Fílí. 1:7) Àwọn ìjọba orílẹ̀-èdè kan ti gbìyànjú láti dá iṣẹ́ ìwàásù àwa èèyàn Ọlọ́run dúró pátápátá. Láti ọdún 2000 títí di báyìí, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti jàre ẹjọ́ tó tó igba àti méjìdínláàádọ́rin [268] láwọn ilé ẹjọ́ gíga, mẹ́rìnlélógún [24] lára rẹ̀ sì jẹ́ ní Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù. Gbogbo àṣeyọrí yìí mú kó ṣe kedere pé kò sẹ́ni tó lè dá iṣẹ́ Ọlọ́run dúró. (Aísá. 54:17) Ọlọ́run ló ń jẹ́ kí ìhìn rere tá à ń wàásù kárí ayé kẹ́sẹ járí. (Mát. 24:14; Ìṣe 1:8) Ní àfikún síyẹn, ìṣọ̀kan tó wà láàárín ẹgbẹ́ àwọn ará wa láti ibi gbogbo kárí ayé, èyí tí kò sí níbòmíràn, máa ń ya àwọn èèyàn lẹ́nu, ìdí nìyẹn tí àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi gbà pé: “Ọlọ́run wà láàárín [wa] ní ti tòótọ́.” (1 Kọ́r. 14:25) Lápapọ̀, a ní ẹ̀rí tó pọ̀ tá a fi lè gbà pé Ọlọ́run ń ti àwọn èèyàn rẹ̀ lẹ́yìn.—Aísá. 66:14. w15 10/15 1:13, 14
Wednesday, January 18
Ẹ má ṣe máa nífẹ̀ẹ́ . . . àwọn ohun tí ń bẹ nínú ayé.—1 Jòh. 2:15.
Ewu wà nínú kéèyàn máa lo ayé dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. (1 Kọ́r. 7:29-31) Ó rọrùn fún Kristẹni kan láti máa lo àkókò tó pọ̀ jù lórí àwọn nǹkan bíi ṣíṣe eré ìgbà ọwọ́ dilẹ̀ tó nífẹ̀ẹ́ sí, kó máa kàwé najú, kó máa wo tẹlifíṣọ̀n, kó máa gbafẹ́ kiri kó lè mọ ìlú ká, kó máa lọ sí àwọn ibi ìtajà ńláńlá láti fójú lóúnjẹ, kó máa fẹ́ mọ̀ nípa àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé àtàwọn nǹkan míì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn nǹkan yìí ò burú, tí Kristẹni kan ò bá fura, wọ́n lè gba àkókò rẹ̀ pátápátá. Tá a bá ń lo ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì, tá à ń fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ lórí fóònù tàbí kọ̀ǹpútà, tá à ń ka àwọn ìròyìn lọ́ọ́lọ́ọ́ àti ìròyìn eré ìdárayá ní ìṣẹ́jú ìṣẹ́jú, ìyẹn náà tún lè fi àkókò wa ṣòfò, ó sì lè gbà wá lọ́kàn ju bó ṣe yẹ lọ. (Oníw. 3:1, 6) Tá a bá ń lo àkókò tó pọ̀ jù lórí àwọn nǹkan tí ò fi bẹ́ẹ̀ pọn dandan, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í fọwọ́ yẹpẹrẹ mú ohun tó ṣe pàtàkì jù nínú ìgbésí ayé, ìyẹn ìjọsìn Jèhófà. (Éfé. 5:15-17) Sátánì ń ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe káwọn ohun tó wà nínú ayé lè fà wá mọ́ra kí wọ́n sì fa ìpínyà ọkàn fún wa. Ohun tó ṣe ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní nìyẹn, ó sì túbọ̀ ń ṣe bẹ́ẹ̀ lónìí. (2 Tím. 4:10) Torí náà, ó yẹ ká fi ìmọ̀ràn tó wà nínú ẹsẹ ojúmọ́ wa tòní sílò. w15 10/15 3:7, 8
Thursday, January 19
Fún wa ní ìtọ́ni ní ti ohun tí ó yẹ kí a ṣe.—Oníd. 13:8.
Mánóà àti ìyàwó rẹ̀ máa di ọlọ́mọ! Ó dájú pé inú Mánóà dùn, àmọ́ ó tún gbà pé iṣẹ́ ńlá ló já lé òun léjìká. Báwo làwọn méjèèjì ṣe máa kọ́ ọmọ wọn kó lè sin Jèhófà lórílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì tí ọ̀pọ̀ èèyàn ti ń hùwà burúkú? Mánóà ‘bẹ Jèhófà’ pé: “Èmi bẹ̀ ọ, jẹ́ kí ènìyàn Ọlọ́run [áńgẹ́lì], tí ìwọ ràn tún tọ̀ wá wá, kí ó lè kọ́ wa ní ohun tí àwa ó ṣe sí ọmọ náà tí a ó bí.” (Oníd. 13:1-8, Bíbélì Mímọ́) Tó o bá jẹ́ òbí, ohun tí Mánóà bẹ̀bẹ̀ fún yẹn ò lè ṣàjèjì sí ẹ. Iṣẹ́ ńlá ló já lé ìwọ náà léjìká, ìyẹn bó o ṣe máa kọ́ ọmọ rẹ kó lè mọ Jèhófà kó sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. (Òwe 1:8) Kíyẹn lè ṣeé ṣe, àwọn òbí máa ń ṣètò Ìjọsìn Ìdílé tó ń lọ déédéé tọ́mọ kọ̀ọ̀kan sì máa rí ẹ̀kọ́ kọ́ nínú rẹ̀. Ká sòótọ́, Ìjọsìn Ìdílé ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ nìkan ò tó láti kọ́ ọmọ kan lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Bíbélì kó sì wọ̀ ọ́ lọ́kàn. (Diu. 6:6-9) Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe fún ẹ̀yin òbí láti kọ́ ọmọ yín kó lè mọ Jèhófà kó sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀? w15 11/15 1:1,2
Friday, January 20
Wò ó, ọmọ Ísírẹ́lì kan dájúdájú, nínú ẹni tí ẹ̀tàn kankan kò sí.—Jòh. 1:47.
A kì í ṣe arínúróde bíi ti Jésù, àmọ́ Jèhófà lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè máa lo òye. Ṣé wàá máa lo òye tó o ní láti máa wá ibi tọ́mọ rẹ dáa sí? Kò sẹ́ni tó fẹ́ kí wọ́n sọ òun lórúkọ burúkú. Torí náà, má ṣe máa pe ọmọ rẹ ní “ọlọ̀tẹ̀” tàbí “ọmọkọ́mọ.” Tọ́mọ rẹ ò bá tiẹ̀ tíì máa ṣe tó bó o ṣe fẹ́, jẹ́ kó mọ̀ pé o rí gbogbo ìsapá ẹ̀ àti pé o mọ̀ pé ó wù ú láti máa ṣe ohun tó tọ́. Tó bá ṣe ohun tó dáa tàbí tó o rí i pé ó ti ń gbìyànjú ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, gbóríyìn fún un. Nígbà tó bá yẹ, máa fún un lómìnira láti ṣe púpọ̀ sí i kó lè túbọ̀ ní àwọn ànímọ́ rere. Ọwọ́ tí Jésù fi mú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ náà nìyẹn. Ní nǹkan bí ọdún kan ààbọ̀ lẹ́yìn tó pàdé Nàtáníẹ́lì, Jésù sọ ọ́ di ọ̀kan lára àwọn àpọ́sítélì rẹ̀, Nàtáníẹ́lì sì wá di Kristẹni tó nítara. (Lúùkù 6:13, 14; Ìṣe 1:13, 14) Bó o ṣe ń gbóríyìn fọ́mọ rẹ tó o sì ń fún un níṣìírí, ọkàn rẹ̀ á balẹ̀ pé òun kì í ṣe ẹni tí kò lè dá nǹkan kan ṣe àmọ́ òun lè lo ẹ̀bùn tóun ní láti sin Jèhófà. w15 11/15 2:15, 16
Saturday, January 21
Wọ́n sì ń ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún [Ọlọ́run] tọ̀sán-tòru.—Ìṣí. 7:15.
Nígbà tí àwọn ọjọ́ ìkẹyìn bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1914, iye àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tó wà jákèjádò ayé ò ju ẹgbẹ̀rún mélòó kan lọ. Torí ìfẹ́ tí wọ́n ní sáwọn èèyàn àti pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run, àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run láìka àtakò sí. Ní báyìí, wọ́n ń kó ogunlọ́gọ̀ ńlá tó nírètí láti gbé lórí ilẹ̀ ayé jọ. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní àwọn ìjọ tó lé ní ẹgbẹ̀rún márùndínlọ́gọ́fà ó lé irínwó [115,400] sì ti tó mílíọ̀nù mẹ́jọ [8,000,000] jákèjádò ayé. A sì ń pọ̀ sí i lójoojúmọ́. Bí àpẹẹrẹ, àwọn tó ṣèrìbọmi lọ́dún iṣẹ́ ìsìn 2014 lé ní ọ̀kẹ́ mẹ́tàlá ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàájọ àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [275,500], tó túmọ̀ sí pé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, ẹgbẹ̀rún márùn ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́ta [5,300] èèyàn ló ń ṣèrìbọmi. Ètò Ọlọ́run ń gbèrú sí i nítorí pé a ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, a sì gba Bíbélì gẹ́gẹ́ bí Ọ̀rọ̀ rẹ̀ onímìísí. (1 Tẹs. 2:13) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Sátánì “ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí” kórìíra wa tó sì ń ta kò wá, síbẹ̀ Jèhófà ń bù kún wa.—2 Kọ́r. 4:4. w15 11/15 4:12, 14, 16
Sunday, January 22
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wa, yóò wà fún àkókò tí ó lọ kánrin.—Aísá. 40:8.
Àwọn ọ̀mọ̀wé tó kẹ́kọ̀ọ́ nípa Bíbélì ti fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò ọ̀pọ̀ àwọn àjákù Bíbélì tí wọ́n rí àtàwọn tí wọ́n fọwọ́ kọ ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ títí kan àwọn ìtumọ̀ Bíbélì kan tó ti pẹ́ gan-an, wọ́n fara balẹ̀ yẹ̀ wọ́n wò síra, wọ́n sì ti rí i pé Ìwé Mímọ́ lódindi ṣeé gbára lé torí pé àṣìṣe táwọn adàwékọ ṣe ò tó nǹkan. Àwọn ẹsẹ díẹ̀ tí ohun tó sọ ò fi bẹ́ẹ̀ yé wọn pàápàá ò yí àwọn ohun tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pa dà. Ìwádìí fínnífínní táwọn ọ̀mọ̀wé tó kẹ́kọ̀ọ́ nípa Bíbélì ṣe nínú àwọn ìwé àfọwọ́kọ́ àtijọ́ ti jẹ́ kó dá àwọn tó ń ka Bíbélì lójú pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni gbogbo ohun tó wà nínú Bíbélì. Láìka bí àwọn ọ̀tá ṣe jà fitafita tó láti pa Bíbélì run, òun ni ìwé tí wọ́n tíì túmọ̀ sí èdè tó pọ̀ jù lọ nínú ìtàn. Kódà nígbà táwọn èèyàn ò fi bẹ́ẹ̀ nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run tàbí tí wọn ò gbà pé Ọlọ́run wà, Bíbélì ni ìwé tó tà jù lọ, odindi tàbí apá kan rẹ̀ sì ti wá wà ní èdè tó lé ní ẹgbẹ̀rún méjì àti ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ [2,800] báyìí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọ̀rọ̀ inú ìtumọ̀ Bíbélì kan lè má fi bẹ́ẹ̀ yéni tàbí kí wọ́n má tọ̀nà, síbẹ̀, a ṣì lè rí àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì tó ń fúnni nírètí tó sì lè jẹ́ kéèyàn rí ìgbàlà kọ́ nínú wọn. w15 12/15 1:13, 14
Monday, January 23
Ẹnì kan wà tí ń sọ̀rọ̀ láìronú bí ẹni pé pẹ̀lú àwọn ìgúnni idà.—Òwe 12:18.
Ọ̀rọ̀ wa lè gbéni ró tàbí kó fa ìrẹ̀wẹ̀sì. Àwọn èèyàn máa ń fi ọ̀rọ̀ gún ara wọn lára nínú ayé Sátánì yìí. Àwọn olórin àtàwọn òṣèré ń kọ́ àwọn èèyàn láti máa “pọ́n ahọ́n wọn bí idà” kí wọ́n sì máa “sọ̀kò ọ̀rọ̀ burúkú bí ẹni ta ọfà.” (Sm. 64:3, Bibeli Ìròyìn Ayọ̀) Kò yẹ kí àwa Kristẹni máa bá wọn dá irú àṣà burúkú yìí. Àpẹẹrẹ irú àwọn “ọ̀rọ̀ burúkú” bẹ́ẹ̀ ni kéèyàn máa dọ́gbọ́n fọ̀rọ̀ kanni lábùkù tàbí kéèyàn máa fèèyàn ṣe yẹ̀yẹ́. Ńṣe làwọn èèyàn máa ń fi irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ pa àwọn èèyàn lẹ́rìn-ín, àmọ́ irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ máa ń yọrí sí àbùkù tàbí àrífín. Irú àwọn ẹ̀fẹ̀ yìí wà lára àwọn ọ̀rọ̀ èébú tó yẹ káwa Kristẹni ‘mú kúrò lọ́dọ̀’ wa. Lóòótọ́, àwàdà máa ń mú kọ́rọ̀ wa dùn, àmọ́ kò yẹ ká máa sọ̀rọ̀ tó máa bí àwọn ẹlòmíì nínú tàbí ọ̀rọ̀ tó máa dójú tì wọ́n. Bíbélì kìlọ̀ fún wa pé: “Kí àsọjáde jíjẹrà má ti ẹnu yín jáde, bí kò ṣe àsọjáde yòówù tí ó dára fún gbígbéniró bí àìní bá ṣe wà, kí ó lè fi ohun tí ó ṣeni lóore fún àwọn olùgbọ́.”—Éfé. 4:29, 31. w15 12/15 3:10
Tuesday, January 24
Bí ẹ bá fi tìṣọ́ra-tìṣọ́ra pa ara yín mọ́ kúrò nínú nǹkan wọ̀nyí, ẹ óò láásìkí. Kí ara yín ó le o!—Ìṣe 15:29.
Ọ̀rọ̀ tó parí lẹ́tà tí ìgbìmọ̀ olùdarí tó wà ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní kọ ránṣẹ́ sáwọn ìjọ yìí tún lè túmọ̀ sí ‘ká lókun’. Ó sì dájú pé gbogbo wa la fẹ́ ‘kí ara wa le’ ká sì lókun láti sin Jèhófà, Ọlọ́run wa. Níwọ̀n bá a ti ń gbé nínú ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí tá a sì tún jẹ́ aláìpé, kò sí bá ò ṣe ní máa ṣàìsàn. A ò sì lè retí pé kí Jèhófà wò wá sàn lọ́nà ìyanu báyìí. Àmọ́, ìwé Ìṣípayá 22:1, 2 jẹ́ ká mọ̀ pé ìgbà kan ń bọ̀ tí gbogbo wa ò ní ṣàìsàn mọ́. Nínú ìran, àpọ́sítélì Jòhánù rí “odò omi ìyè kan” àti “àwọn igi ìyè” tó ní àwọn ewé tó “wà fún wíwo àwọn orílẹ̀-èdè sàn.” Kì í ṣe egbòogi kan tó máa wo àwọn àrùn sàn nísinsìnyí tàbí lọ́jọ́ iwájú ni ibi yìí ń sọ o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí Jèhófà máa ṣe fún aráyé onígbọràn nípasẹ̀ Jésù ká lè wà láàyè títí láé ni ibí yìí ń sọ. Ohun tó sì yẹ kí gbogbo wa máa retí nìyẹn.—Aísá. 35:5, 6. w15 12/15 4:17, 18
Wednesday, January 25
Àwa yóò bá yín lọ, nítorí a ti gbọ́ pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú yín.—Sek. 8:23.
Jèhófà sọ pé ní àkókò wa yìí, “ọkùnrin mẹ́wàá láti inú gbogbo èdè àwọn orílẹ̀-èdè yóò dì í mú, bẹ́ẹ̀ ni, ní ti tòótọ́, wọn yóò di ibi gbígbárìyẹ̀ lára aṣọ ọkùnrin kan tí ó jẹ́ Júù mú, pé: ‘Àwa yóò bá yín lọ, nítorí a ti gbọ́ pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú yín.’ ” (Sek. 8:23) “Júù” náà dúró fún àwọn tí Ọlọ́run ti fi ẹ̀mí mímọ́ yàn. Àwọn ni Bíbélì tún pè ní “Ísírẹ́lì Ọlọ́run.” (Gál. 6:16) “Ọkùnrin mẹ́wàá” náà dúró fún àwọn tó nírètí láti gbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé. Wọ́n mọ̀ pé Jèhófà ti bù kún àwùjọ àwọn ẹni àmì òróró yìí, wọ́n sì gbà pé àǹfààní ńlá ni báwọn àtàwọn ẹni àmì òróró yìí ṣe jọ ń sin Jèhófà. Bíi ti wòlíì Sekaráyà, Jésù náà sọ pé àwọn èèyàn Jèhófà máa wà níṣọ̀kan. Ó pe àwọn tó nírètí láti gbé lọ́run ní “agbo kékeré,” ó sì pe àwọn tó nírètí láti gbé lórí ilẹ̀ ayé ní “àwọn àgùntàn mìíràn.” Àmọ́ Jésù sọ pé gbogbo wọn á jẹ́ “agbo kan,” wọ́n á sì máa tẹ̀ lé òun tóun jẹ́ “olùṣọ́ àgùntàn kan” ṣoṣo tí wọ́n ní.—Lúùkù 12:32; Jòh. 10:16. w16.01 4:1, 2
Thursday, January 26
Ẹ máa bá a lọ ní gbígba nǹkan wọ̀nyí rò.—Fílí. 4:8.
Ó ṣe pàtàkì ká dáàbò bo àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Jèhófà. Torí pé ayé tí Sátánì ń darí là ń gbé àti pé àwa fúnra wa ṣì jẹ́ aláìpé, ó rọrùn kéèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í ronú báyé ṣe ń ronú kéèyàn sì bẹ̀rẹ̀ sí í hùwà bí wọ́n ṣe ń hùwà. Ńṣe lọ̀rọ̀ yìí dà bí ìgbà téèyàn ń lúwẹ̀ẹ́ nínú odò àmọ́ tí omi ọ̀hún ń gbìyànjú láti gbé wa lọ síbi tá ò fẹ́ lúwẹ̀ẹ́ gbà. Àfi ká yáa fi gbogbo agbára wa lúwẹ̀ẹ́ gba ibi tá a fẹ́ gbà kí omi má bàá gbé wa lọ. Lọ́nà kan náà, àfi ká yáa ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe káyé Sátánì má bàá sọ wá dà bó ṣe dà. Báwo wá ni iṣẹ́ ìwàásù ṣe ń dáàbò bò wá? Bá a ṣe ń fi Bíbélì kọ́ àwọn èèyàn nípa Jèhófà, bẹ́ẹ̀ làwa náà á máa pọkàn pọ̀ sorí àwọn ohun tó dára tó sì ṣe pàtàkì, a ò sì ní máa gbọ́kàn wa sórí àwọn ohun tó lè ba ìgbàgbọ́ wa jẹ́. Iṣẹ́ ìwàásù máa ń mú kí ìgbàgbọ́ wa lágbára sí i torí ó máa ń rán wa létí àwọn ìlérí tí Ọlọ́run ṣe fún wa àtàwọn ìlànà tó fìfẹ́ fún wa. Ó tún máa ń jẹ́ ká ní àwọn ànímọ́ tá a lè fi dáàbò bo ara wa kúrò lọ́wọ́ Sátánì àti ayé tó ń darí, ká sì máa fi wọ́n ṣèwà hù nígbà gbogbo. (Éfé. 6:14-17) Tá a bá ń fi àkókò tó pọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tá a sì ń ṣe àwọn ohun táá ran àwọn ará ìjọ lọ́wọ́, ààbò lèyí máa jẹ́ fún wa torí kò ní jẹ́ ká ráyè tá ó fi máa ronú nípa àwọn ìṣòro wa ṣáá débi táwọn ìṣòro yẹn á fi gbà wá lọ́kàn. w16.01 5:12, 13
Friday, January 27
Àwọn ènìyàn rẹ ni yóò jẹ́ ènìyàn mi, Ọlọ́run rẹ ni yóò sì jẹ́ Ọlọ́run mi.—Rúùtù 1:16.
Kíyè sí i pé Rúùtù nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Ó wú Bóásì náà lórí débi tó fi wá yin Rúùtù fún bó ṣe ‘wá ibi ìsádi lábẹ́ ìyẹ́ apá Jèhófà.’ (Rúùtù 2:12) Ọ̀rọ̀ tí Bóásì lò yìí mú wa rántí bí òròmọdìyẹ ṣe máa ń sá sábẹ́ ìyẹ́ apá ìyá rẹ̀, kó lè dáàbò bò ó. (Sm. 36:7; 91:1-4) Lọ́nà kan náà, Jèhófà dáàbò bo Rúùtù, ó sì san án lẹ́san torí ìgbàgbọ́ tó ní. Rúùtù ò kábàámọ̀ ìpinnu tó ṣe yìí láé. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà lónìí, àmọ́ tí wọn ò sá di í. Wọn ò tíì fẹ́ ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà kí wọ́n sì ṣèrìbọmi. Tó bá jẹ́ bọ́rọ̀ tìẹ náà ṣe rí nìyẹn, á dáa kó o ronú lórí ìdí tó ò fi tíì ṣèrìbọmi. Kò sẹ́ni tí kò ní ọlọ́run tó ń sìn. (Jóṣ. 24:15) Àmọ́, ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé kéèyàn sin Ọlọ́run tòótọ́. Tó o bá ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà, ńṣe lò ń fi hàn pé o nígbàgbọ́ pé Jèhófà á jẹ́ ibi ìsádi fún ẹ. Á sì ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè máa sìn ín nìṣó láìka ìṣòro èyíkéyìí tó o lè ní sí. Ohun tí Ọlọ́run ṣe fún Rúùtù nìyẹn. w16.02 2:6, 7
Saturday, January 28
Jẹ́ kí n fi ọ̀kọ̀ gún un mọ́lẹ̀ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo péré, èmi kì yóò sì ṣe é sí i lẹ́ẹ̀mejì.—1 Sám. 26:8.
Ńṣe ni Ábíṣáì ń fi hàn pé ti Dáfídì lòun ń ṣe nígbà tó fẹ́ pa Sọ́ọ̀lù. Àmọ́ torí pé Dáfídì mọ̀ pé kò tọ́ kí òun pa “ẹni àmì òróró Jèhófà,” kò jẹ́ kí Ábíṣáì pa Sọ́ọ̀lù Ọba. (1 Sám. 26:9-11) Ẹ̀kọ́ pàtàkì lèyí kọ́ wa, ìyẹn ni pé tó bá di pé ká pinnu ẹni tá a máa kọ́kọ́ jẹ́ adúróṣinṣin sí, ó yẹ ká ronú lórí àwọn ìlànà Bíbélì tó lè ràn wá lọ́wọ́. A máa ń fẹ́ jẹ́ adúróṣinṣin sí àwọn tó sún mọ́ wa, bí àwọn ọ̀rẹ́ wa tàbí àwọn mẹ́ńbà ìdílé wa. Àmọ́, torí pé aláìpé ni wá, a máa ń ronú lọ́nà tí kò tọ́ nígbà míì. (Jer. 17:9) Torí náà, bí ẹnì kan tó sún mọ́ wa bá ń ṣàìtọ́, tó sì fi ètò Ọlọ́run sílẹ̀, ó yẹ ká rántí pé ó ṣe pàtàkì ká jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà ju ká jẹ́ adúróṣinṣin sí ẹnikẹ́ni míì.—Mát. 22:37. w16.02 4:5, 6
Sunday, January 29
Ẹ lè ṣàwárí fúnra yín ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó dára, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí ó sì pé.—Róòmù 12:2.
Kí nìdí táwọn Kristẹni tó wà nílùú Róòmù fi ní láti ṣàwárí ohun tí wọ́n ti gbà gbọ́? Àpẹẹrẹ Tímótì lè ràn ẹ́ lọ́wọ́. Ó mọ Ìwé Mímọ́ dáadáa torí pé màmá rẹ̀ àti màmá rẹ̀ àgbà ti fi Ìwé Mímọ́ kọ́ ọ. Síbẹ̀, Pọ́ọ̀lù sọ fún Tímótì pé: “Máa bá a lọ nínú àwọn ohun tí o ti kọ́, tí a sì ti yí ọ lérò padà láti gbà gbọ́.” (2 Tím. 3:14, 15) ‘Yí lérò pa dà’ tó wà nínú ẹsẹ Bíbélì yìí túmọ̀ sí pé “kí ohun kan dáni lójú kéèyàn sì gbà gbọ́ pé òótọ́ ni.” Torí náà, ó gbọ́dọ̀ dá Tímótì lójú pé inú Ìwé Mímọ́ lèèyàn ti lè rí òtítọ́. Ó sì gba ohun tó rí nínú Ìwé Mímọ́ gbọ́, kì í ṣe torí pé màmá rẹ̀ àti màmá rẹ̀ àgbà sọ pé kó ṣe bẹ́ẹ̀, bí kò ṣe torí pé òun fúnra rẹ̀ ronú lórí ohun tó kọ́, ohun tó kọ́ sì yí i lérò pa dà. (Róòmù 12:1) Bákan náà, tó o bá ń fara balẹ̀ dá kẹ́kọ̀ọ́, wàá lè dáhùn àwọn ìbéèrè tí wọ́n bá bi ẹ́, o ò ní máa ṣiyè méjì, àwọn ohun tó o gbà gbọ́ á sì túbọ̀ dá ẹ lójú.—Ìṣe 17:11. w16.03 2:3, 4, 7
Monday, January 30
[Wọ́n máa ń] lọ sí Jerúsálẹ́mù láti ọdún dé ọdún fún àjọyọ̀ ìrékọjá.—Lúùkù 2:41.
Táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá ń lọ síbi àjọyọ̀ ọdọọdún tí wọ́n máa ń ṣe ní Jerúsálẹ́mù, wọ́n máa ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ara wọn. Wọ́n á kó gbogbo ohun tí wọ́n nílò dání, wọ́n á jọ gbéra ìrìn-àjò, wọ́n sì máa ń ran ara wọn lọ́wọ́ títí tí wọ́n á fi débẹ̀. Tí wọ́n bá sì dé tẹ́ńpìlì, wọ́n á jọ sin Jèhófà, wọ́n á sì jùmọ̀ fìyìn fún un. Bí àwa náà ṣe ń retí àtigbé nínú ayé tuntun, a gbọ́dọ̀ ṣera wa lọ́kan ká sì fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ara wa. Èrò àwọn èèyàn ò ṣọ̀kan láyé tá a wà yìí, àwọn ohun tí ò tó nǹkan ló sì máa ń dá ìjà sílẹ̀ láàárín wọn. Àmọ́ à ń dúpẹ́ pé Jèhófà ti jẹ́ kí àlàáfíà jọba láàárín wa, ó sì tún jẹ́ ká lóye Ọ̀rọ̀ rẹ̀! Àwọn èèyàn rẹ̀ jákèjádò ayé ń sìn ín lọ́nà tó fẹ́. Pàápàá láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, àwọn èèyàn Jèhófà ti wá wà níṣọ̀kan ju ti ìgbàkigbà rí lọ. Bí Aísáyà àti Míkà ṣe sọ tẹ́lẹ̀ lọ̀rọ̀ náà rí, a jùmọ̀ ń gòkè lọ sí “òkè ńlá Jèhófà.” (Aísá. 2:2-4; Míkà 4:2-4) Ẹ sì wo bí inú wa ṣe máa dùn tó nígbà tí gbogbo àwọn táá máa gbé lórí ilẹ̀ ayé á ‘so pọ̀ ní ìṣọ̀kan,’ tí gbogbo wọn á sì jọ máa sin Jèhófà! w16.03 3:16, 17
Tuesday, January 31
Ohun gbogbo ni ìgbà tí a yàn kalẹ̀ wà fún.—Oníw 3:1.
Ó lè ṣòro fún àwọn alàgbà kan láti wáyè kí wọ́n lè dá àwọn ẹlòmíì lẹ́kọ̀ọ́. Wọ́n lè ronú pé: ‘Ìdálẹ́kọ̀ọ́ ṣe pàtàkì lóòótọ́, àmọ́ àwọn ọ̀ràn míì wà nínú ìjọ tá a gbọ́dọ̀ bójú tó ní kánjúkánjú. Bó bá tiẹ̀ ṣì pẹ́ díẹ̀ kí n tó dá àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́, ìyẹn ò sọ pé kí nǹkan má lọ bó ṣe yẹ nínú ìjọ.’ Òótọ́ ni pé ọ̀pọ̀ nǹkan ló yẹ kí alàgbà kan bójú tó lójú ẹsẹ̀, àmọ́ tó o bá ń fi ìdánilẹ́kọ̀ọ́ falẹ̀ ó lè ṣe ìpalára fún ìjọ nípa tẹ̀mí. Àwọn alàgbà ní ọ̀pọ̀ iṣẹ́ pàtàkì tí wọ́n gbọ́dọ̀ bójú tó ní kánjúkánjú. Àmọ́, tí àwọn alàgbà bá ń fòní dónìí fọ̀la dọ́la lórí ọ̀rọ̀ ìdálẹ́kọ̀ọ́, bó pẹ́ bó yá àwọn arákùnrin tó kúnjú ìwọ̀n kò ní pọ̀ tó láti bójú tó àwọn iṣẹ́ tó yẹ ká ṣe nínú ìjọ. A ti wá rí i báyìí pé, kò yẹ kí àwọn alàgbà máa rò pé dídá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́ kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì. Àwọn alàgbà tó bá ń ronú nípa ohun tó máa ṣe ìjọ láǹfààní lọ́jọ́ iwájú, tí wọ́n sì ń wáyè láti dá àwọn arákùnrin tí wọn ò fi bẹ́ẹ̀ ní ìrírí lẹ́kọ̀ọ́ jẹ́ ọlọ́gbọ́n ìríjú, ìbùkún gidi ni wọ́n sì jẹ́ fún gbogbo ìjọ.—1 Pét. 4:10. w15 4/15 1:4, 6, 7