December
Sunday, December 1
Ẹ ní ẹ̀mí aájò àlejò fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì láìsí ìráhùn.—1 Pét. 4:9.
Láyé àtijọ́, ọ̀nà míì tí wọ́n máa ń gbà ṣàlejò ni pé kí wọ́n ṣètò ibi tí àlejò kan máa dé sí. (Jẹ́n. 18:1-8; Onid. 13:15; Lúùkù 24:28-30) Tá a bá pe ẹnì kan wá jẹun, ṣe là ń fi hàn pé a fẹ́ kẹ́ni náà di ọ̀rẹ́ wa, ká sì jọ wà ní àlàáfíà. Àwọn wo ló yẹ ká máa pè wá sílé wa jù? Àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin nínú ìjọ ni. Ó ṣe tán, tíṣòro bá dé, ṣebí àwọn ará yìí náà ló máa dúró tì wá? Ká sòótọ́, gbogbo àwọn ará ló yẹ kó jẹ́ ọ̀rẹ́ wa, ká sì wà ní àlàáfíà pẹ̀lú wọn. Àwọn alábòójútó àyíká, àwọn tó bá wá fún àwọn ilé ẹ̀kọ́ ètò Ọlọ́run àtàwọn tó ń ṣiṣẹ́ ìkọ́lé máa ń nílò ibi tí wọ́n máa dé sí. Nígbà míì sì rèé, àjálù lè ba ilé àwọn ará wa kan jẹ́, kí wọ́n sì nílò ibi tí wọ́n lè forí pamọ́ sí títí wọ́n á fi tún ilé wọn ṣe. Kò yẹ ká máa ronú pé àwọn tí ilé wọn tóbi nìkan ló lè gba irú àwọn bẹ́ẹ̀ sílé, ohun kan ni pé, wọ́n lè ti ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà. Ṣé ìwọ náà lè gbà wọ́n sílé kódà tó bá jẹ́ pé ilé rẹ ò tóbi? w18.03 15 ¶6; 16 ¶9
Monday, December 2
Olódodo lè ṣubú ní ìgbà méje pàápàá, yóò sì dìde dájúdájú.—Òwe 24:16.
Kí ló máa jẹ́ kí ẹni tó ṣubú dìde pa dà? Ẹ̀mí Ọlọ́run nìkan ló lè ràn án lọ́wọ́, kò lè dá a ṣe. (Fílí. 4:13) Apá kan èso ti ẹ̀mí ni ìkóra-ẹni-níjàánu.Téèyàn bá fẹ́ ní ìkóra-ẹni-níjàánu, ó tún ṣe pàtàkì pé kó máa gbàdúrà, kó máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kó sì máa ṣàṣàrò. Àmọ́, tó bá ṣòro fún ẹ láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ńkọ́? Bóyá o ò tiẹ̀ nífẹ̀ẹ́ àtimáa kàwé rárá. Rántí pé Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ tó o bá jẹ́ kó ṣe bẹ́ẹ̀. Ó lè jẹ́ kó máa wù ẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ rẹ̀. (1 Pét. 2:2) Ohun àkọ́kọ́ tó o máa ṣe ni pé kó o bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kó o lè ṣètò ara rẹ láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lẹ́yìn náà, ṣe ohun tó bá àdúrà rẹ mu, má jẹ́ kí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà gùn jù. Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, á túbọ̀ rọrùn fún ẹ láti máa kẹ́kọ̀ọ́ á sì tún máa dùn mọ́ ẹ. Inú ẹ máa dùn pé ò ń lo àkókò rẹ láti ronú nípa àwọn òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ṣeyebíye.—1 Tím. 4:15. w18.03 29 ¶5-6
Tuesday, December 3
Èyí ni ó ń gbà yín là nísinsìnyí pẹ̀lú, èyíinì ni, ìbatisí.—1 Pét. 3:21.
Kí ẹnì kan tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó lè ṣèrìbọmi, ó gbọ́dọ̀ gbé àwọn ìgbésẹ̀ pàtàkì kan. Ó gbọ́dọ̀ ní ìmọ̀ tó péye nípa Ọlọ́run, ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe fún aráyé àtohun tí Ọlọ́run ti ṣe láti gba aráyé là, ìmọ̀ tó ní yìí ló máa jẹ́ kó ní ìgbàgbọ́. (1 Tím. 2:3-6) Ìgbàgbọ́ tó ní máa jẹ́ kó jáwọ́ nínú àwọn ìwà tí inú Ọlọ́run ò dùn sí, á sì máa ṣe àwọn nǹkan tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu. (Ìṣe 3:19) Ó ṣe kedere pé bí ẹnì kan bá ṣì ń lọ́wọ́ sáwọn ìwà tó lè mú kéèyàn pàdánù Ìjọba Ọlọ́run, kò lè sọ pé òun ti ya ara òun sí mímọ́. (1 Kọ́r. 6:9, 10) Yàtọ̀ sí pé kéèyàn jáwọ́ nínú àwọn nǹkan tí inú Jèhófà ò dùn sí, ó tún yẹ kẹ́ni tó fẹ́ ṣèrìbọmi máa wá sípàdé déédéé, kó máa wàásù, kó sì máa sọ àwọn èèyàn di ọmọlẹ́yìn. (Ìṣe 1:8) Ẹ̀yìn ìgbà yẹn ló tó lè ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà nínú àdúrà, kó sì wá ṣèrìbọmi. w18.03 6 ¶12
Wednesday, December 4
[Màríà] pa gbogbo àsọjáde wọ̀nyí mọ́ nínú ọkàn-àyà rẹ̀.—Lúùkù 2:51.
Kí nìdí tó fi jẹ́ pé Màríà ni Jèhófà yàn láti jẹ́ ìyá Jésù? Kò sí àní-àní, torí pé ó jẹ́ ẹni tẹ̀mí ni Jèhófà fi yàn án. Ohun tó sọ nígbà tó lọ sílé Sekaráyà àti Èlísábẹ́tì tí wọ́n jẹ́ mọ̀lẹ́bí rẹ̀ fi hàn pé ẹni tẹ̀mí ni. (Lúùkù 1:46-55) Àwọn ọ̀rọ̀ tí Màríà sọ fi hàn pé ó mọ Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù dáadáa, ó sì fẹ́ràn rẹ̀. (Jẹ́n. 30:13; 1 Sám. 2:1-10; Mál. 3:12) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé òun àti Jósẹ́fù ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó, wọn ò ní ìbálòpọ̀ títí tí Màríà fi bí Jésù. Kí nìyẹn fi hàn? Èyí fi hàn pé ìfẹ́ Ọlọ́run ló gbawájú ní ìgbésí ayé àwọn méjèèjì, ó sì ṣe pàtàkì sí wọn ju ìfẹ́ tara wọn lọ. (Mát. 1:25) Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, Màríà ń kíyè sí àwọn nǹkan tí Jésù ń ṣe, ó sì ń tẹ́tí sí àwọn ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n tó ń sọ. Bí ìfẹ́ Ọlọ́run ṣe máa ṣẹ nípasẹ̀ Mèsáyà ló jẹ ẹ́ lógún. Ǹjẹ́ àwa náà lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Màríà, ká sì jẹ́ kí ìfẹ́ Ọlọ́run gbawájú ní ìgbésí ayé wa? w18.02 21 ¶11
Thursday, December 5
[Jóòbù] ọkùnrin aláìlẹ́bi àti adúróṣánṣán.—Jóòbù 1:8.
Báwo la ṣe lè jẹ́ onígbọràn ká sì tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ Jóòbù? Láìka àwọn ìṣòro tá a lè máa kojú sí, ẹ jẹ́ ká rí i pé Jèhófà lẹni tó ṣe pàtàkì jù nígbèésí ayé wa, ká gbẹ́kẹ̀ lé e, ká sì máa ṣègbọràn tọkàntọkàn. Kẹ́ ẹ sì máa wò ó, ọ̀pọ̀ ìdí ló fi yẹ ká túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, a ti wá mọ àwọn nǹkan tí Jóòbù ò mọ̀. A ti mọ àwọn ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ tí Sátánì ń lò. (2 Kọ́r. 2:11) A ti mọ ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìyà bó ṣe wà lákọọ́lẹ̀ nínú ìwé Jóòbù àtàwọn ìwé míì. Bákan náà, àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì tún jẹ́ ká mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run ló máa ṣàkóso ayé yìí lábẹ́ ìdarí Jésù Kristi. (Dán. 7:13, 14) Ìjọba yìí ló sì máa fòpin sí gbogbo ìyà tó ń jẹ aráyé. Àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jóòbù jẹ́ ká rí ìdí tó fi yẹ ká máa fàánú hàn sáwọn ará wa tó ń fara da ìṣòro. Bíi ti Jóòbù, àwọn míì nínú wọn lè sọ̀rọ̀ tí kò tọ́ nígbà míì. (Oníw. 7:7) Dípò ká máa dá wọn lẹ́jọ́, ẹ jẹ́ ká máa fàánú hàn sí wọn ká sì máa fòye bá wọn lò. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe là ń fìwà jọ Jèhófà, Baba wa onífẹ̀ẹ́ àti aláàánú.—Sm. 103:8. w18.02 6 ¶16; 7 ¶19-20
Friday, December 6
Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ rẹ sì ni yóò sọ mí di ńlá.—Sm. 18:35.
Àwọn kan ń gbéra ga torí pé wọ́n lẹ́wà, wọ́n gbayì, wọ́n morin kọ, wọ́n lágbára tàbí torí pé wọ́n wà nípò gíga. Gbogbo nǹkan yìí ni Dáfídì ní, síbẹ̀ ó fẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ hàn jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀. Lẹ́yìn tó pa Gòláyátì, Ọba Sọ́ọ̀lù ní kó fi ọmọ òun ṣaya, àmọ́ Dáfídì sọ pé: “Ta ni mí, tí èmi yóò fi di ọkọ ọmọ ọba?” (1 Sám. 18:18) Bíi ti Dáfídì, àwa èèyàn Jèhófà náà ń sapá ká lè máa fẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ hàn. Ó jọ wá lójú gan-an pé Jèhófà tó jẹ́ Ẹni gíga jù lọ láyé àti lọ́run ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀. A máa ń fi ìmọ̀ràn Bíbélì sọ́kàn pé: “Ẹ fi ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti ìyọ́nú, inú rere, ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, ìwà tútù, àti ìpamọ́ra wọ ara yín láṣọ.” (Kól. 3:12) A tún mọ̀ pé ìfẹ́ “kì í fọ́nnu, kì í wú fùkẹ̀.” (1 Kọ́r. 13:4) Tá a bá lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, á mú káwọn èèyàn wá sin Jèhófà. w18.01 28 ¶6-7
Saturday, December 7
Wọ́n . . . ń bẹ̀ wá ṣáá pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ìpàrọwà fún àǹfààní ìfúnni onínúrere.—2 Kọ́r. 8:4.
Wọ́n lè sọ fún wa pé káwa náà ṣe ọrẹ fáwọn iṣẹ́ pàtó kan. (Ìṣe 4:34, 35; 1 Kọ́r. 16:2) Bí àpẹẹrẹ, ó ṣeé ṣe kí ìjọ yín nílò Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun. Wọ́n sì lè ní ká ṣètìlẹ́yìn torí àpéjọ àgbègbè tá a fẹ́ ṣe tàbí torí àwọn ará wa tí àjálù dé bá. A tún máa ń fowó ṣètìlẹ́yìn kí ètò Ọlọ́run lè bójú tó iṣẹ́ tó ń lọ ní oríléeṣẹ́ wa àti ní àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì gbogbo. Ọrẹ tá à ń ṣe náà ni wọ́n fi ń ṣètìlẹ́yìn fáwọn míṣọ́nnárì, àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe àtàwọn alábòójútó àyíká. Gbogbo wa pátá la lè ṣètìlẹ́yìn kí àwọn nǹkan ribiribi tí Jèhófà ń gbé ṣe láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí lè máa lọ geerege. Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ọrẹ tá à ń ṣe la ò mọ ẹni tó ṣe é. Inú àwọn àpótí ọrẹ tó wà ní Gbọ̀ngàn Ìjọba la sábà máa ń fi ọrẹ náà sí, ó sì lè jẹ́ látorí ìkànnì jw.org/yo. Àwọn ọrẹ tá à ń ṣe lè má jọ àwa fúnra wa lójú. Síbẹ̀ àwọn ọrẹ tá a rò pé ó kéré yẹn àmọ́ tá à ń ṣe ní gbogbo ìgbà ló ń mú kí iṣẹ́ Ọlọ́run máa tẹ̀ síwájú. w18.01 19 ¶10-11
Sunday, December 8
Èyí ni ó ń gbà yín là nísinsìnyí pẹ̀lú, èyíinì ni, ìbatisí.—1 Pét. 3:21.
Èèyàn gbọ́dọ̀ ṣèrìbọmi kó tó lè di Kristẹni àti pé ìgbésẹ̀ pàtàkì ló jẹ́ téèyàn bá máa rí ìgbàlà. (Mát. 28:19, 20) Ìrìbọmi tó o ṣe fi hàn pé o ti ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà. O tipa bẹ́ẹ̀ ṣèlérí fún Jèhófà pé wàá nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ àti pé ìfẹ́ rẹ̀ ló máa gbawájú láyé rẹ. Bó o ṣe fayé rẹ fún Jèhófà kì í ṣe àṣìṣe rárá. Ẹ gbọ́ ná, ta lèèyàn ò bá fayé ẹ̀ fún bí kò ṣe Jèhófà? Abẹ́ Sátánì lẹni tí kò bá fayé rẹ̀ fún Jèhófà wà. Sátánì ò láàánú èèyàn lójú, kò sì fẹ́ kó o rí ìgbàlà. Kódà, inú rẹ̀ máa dùn tó o bá pàdánù ìyè àìnípẹ̀kun, torí pé ohun tó fẹ́ ni pé kó o wà lọ́dọ̀ òun dípò kó o fara rẹ sábẹ́ àkóso Ọlọ́run. Ọ̀pọ̀ ìbùkún ni wàá rí tó o bá kọjú ìjà sí Èṣù, tó o yara rẹ sí mímọ́ tó o sì ṣèrìbọmi. Ní báyìí tó o ti fayé rẹ fún Jèhófà, ìwọ náà lè fi ìdánilójú sọ pé: “Jèhófà ń bẹ ní ìhà ọ̀dọ̀ mi; èmi kì yóò bẹ̀rù. Kí ni ará ayé lè fi mí ṣe?” (Sm. 118:6) Kò sóhun tó dáa tó pé kó o fayé rẹ sin Jèhófà kó o sì ní ìtẹ́wọ́gbà rẹ̀. w17.12 23-24 ¶1-3
Monday, December 9
Má ṣe gbaná jẹ kìkì láti ṣe ibi.—Sm. 37:8.
Èdèkòyédè máa ń wáyé láàárín àwa Kristẹni torí pé aláìpé ni wá. Torí náà, ọ̀rọ̀ tàbí ìṣe ẹnì kan lè múnú bí wa, ọ̀rọ̀ àti ìṣe tiwa náà sì lè múnú bí ẹlòmíì. Ká sòótọ́, ìyẹn lè dán ìgbàgbọ́ wa wò. Àmọ́, á jẹ́ ká lè fi hàn pé a jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà. Lọ́nà wo? A lè fi hàn pé a jẹ́ adúróṣinṣin tá a bá ń fìfẹ́ bá àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa lò tá a sì ń rántí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wọn bó tilẹ̀ jẹ́ pé aláìpé ni wọ́n. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jósẹ́fù mú kó ṣe kedere pé Jèhófà máa ń fàyè gba pé káwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ kojú àdánwò nígbà míì. Ìgbà tí Jósẹ́fù wà lọ́dọ̀ọ́ làwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ tà á sóko ẹrú torí pé wọ́n ń jowú rẹ̀, bó ṣe dèrò Íjíbítì nìyẹn. (Jẹ́n. 37:28) Jèhófà rí ohun tó ṣẹlẹ̀, ó sì dájú pé inú rẹ̀ ò dùn bí wọ́n ṣe ń fojú pọ́n Jósẹ́fù ọ̀rẹ́ rẹ̀. Síbẹ̀, Jèhófà kò dá a nídè. Nígbà tó yá, wọ́n fẹ̀sùn kan Jósẹ́fù pé ó fẹ́ fipá bá ìyàwó Pọ́tífárì sùn, wọ́n sì jù ú sẹ́wọ̀n. Síbẹ̀, Jèhófà ò dá sí i. Àmọ́ ṣéyẹn wá túmọ̀ sí pé Jèhófà gbàgbé Jósẹ́fù? Rárá, kò rí bẹ́ẹ̀ torí Bíbélì sọ pé: ‘Jèhófà ń mú kí ohun tí Jósẹ́fù ń ṣe yọrí sí rere.’—Jẹ́n. 39:21-23. w18.01 9-10 ¶12-14
Tuesday, December 10
Ní tòótọ́, bí kò bá sí àjíǹde àwọn òkú, a jẹ́ pé a kò tíì gbé Kristi dìde.—1 Kọ́r. 15:13.
Kí làwọn ohun pàtàkì tẹ́ ẹ gbà gbọ́ nínú ẹ̀sìn yín? Ó dájú pé wàá sọ fún onítọ̀hún pé o gbà gbọ́ pé Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá àti Olùfúnni-ní-Ìyè. Ó ṣeé ṣe kó o tún sọ pé o gbà gbọ́ nínú Jésù Kristi tó kú fún wa kó lè rà wá pa dà. Kò sí àní-àní pé tayọ̀tayọ̀ ni wàá fi sọ fún un pé ayé yìí máa di Párádísè níbi táwọn èèyàn Ọlọ́run máa gbé títí láé. Àmọ́, ṣé wàá mẹ́nu kan ìrètí àjíǹde gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára ohun tó o gbà gbọ́, tó o sì ń fojú sọ́nà fún? Ìdí púpọ̀ ló wà tó fi yẹ ká máa fi ọ̀rọ̀ àjíǹde kún àwọn ohun pàtàkì tá a gbà gbọ́, ká tiẹ̀ sọ pé ó wù wá pé ká la ìpọ́njú ńlá já, ká sì gbé títí láé nínú ayé tuntun. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ bí ìrètí àjíǹde ṣe jẹ́ apá pàtàkì lára ohun tá a gbà gbọ́. Ká ní Kristi kò jíǹde, kò ní lè jẹ́ Ọba tó ń ṣàkóso lọ́run báyìí, á sì túmọ̀ sí pé asán ni ìwàásù wa nípa Ìjọba Kristi. (1 Kọ́r. 15:12-19) Àmọ́, ó dá wa lójú pé Jésù ti jíǹde, ó sì dá wa lójú pé àwọn òkú máa jíǹde.—Máàkù 12:18; Ìṣe 4:2, 3; 17:32; 23:6-8. w17.12 8 ¶1-2
Wednesday, December 11
Ẹ ṣàìka àwọn ọ̀ràn wíwúwo jù lọ nínú Òfin sí, èyíinì ni, ìdájọ́ òdodo àti àánú.—Mát. 23:23.
Ìwà àìtọ́ tí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan hù làwọn Farisí máa ń gbájú mọ́, kì í ṣe irú ẹni tí ẹlẹ́ṣẹ̀ náà jẹ́. Nígbà táwọn Farisí rí Jésù níbi ìkórajọ kan nílé Mátíù, wọ́n bi àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Èé ṣe tí ó fi jẹ́ pé olùkọ́ yín ń jẹun pẹ̀lú àwọn agbowó orí àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀?” Jésù fèsì pé: “Àwọn ẹni tí ó ní ìlera kò nílò oníṣègùn, ṣùgbọ́n àwọn tí ń ṣòjòjò nílò rẹ̀. Ẹ lọ, nígbà náà, kí ẹ sì kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí èyí túmọ̀ sí, ‘Àánú ni èmi fẹ́, kì í sì í ṣe ẹbọ.’ Nítorí èmi kò wá láti pe àwọn olódodo, bí kò ṣe àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.” (Mát. 9:9-13) Ṣéyẹn wá túmọ̀ sí pé Jésù gba ìwàkíwà láyè? Kì í ṣe bẹ́ẹ̀. Kódà, apá pàtàkì lára ìwàásù Jésù ni pé káwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ronú pìwà dà. (Mát. 4:17) Jésù fòye mọ̀ pé àwọn kan lára “àwọn agbowó orí àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀” máa yí pa dà. Kì í ṣe torí oúnjẹ nìkan ni wọ́n ṣe wá sílé Mátíù, kàkà bẹ́ẹ̀, Bíbélì sọ pé, ‘ọ̀pọ̀ wọn bẹ̀rẹ̀ sí í tọ Jésù lẹ́yìn.’ (Máàkù 2:15) Àmọ́, àwọn Farisí kò rí ohun tí Jésù rí nípa àwọn èèyàn náà. w17.11 13 ¶2; 16 ¶15
Thursday, December 12
Ẹ fi ìfẹ́ wọ ara yín láṣọ, nítorí ó jẹ́ ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé.—Kól. 3:14.
Gbogbo wa la gbà pé ìbùkún ńlá ló jẹ́ bá a ṣe wà nínú ìjọ Kristẹni. Bá a ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nípàdé àti bá a ṣe ń ran ara wa lọ́wọ́ máa ń jẹ́ ká lè pọkàn pọ̀ sórí èrè náà. Àmọ́ nígbà míì, èdèkòyédè lè wáyé láàárín wa kó sì fa àìgbọ́ra-ẹni-yé. Tá ò bá tètè yanjú irú èdèkòyédè bẹ́ẹ̀, ó lè mú ká bẹ̀rẹ̀ sí í di ara wa sínú. (1 Pét. 3:8, 9) Kí la lè ṣe tí èdèkòyédè kò fi ní jẹ́ ká pàdánù èrè tá à ń wọ̀nà fún? Pọ́ọ̀lù gba àwọn ará Kólósè níyànjú pé: “Gẹ́gẹ́ bí àyànfẹ́ Ọlọ́run, mímọ́ àti olùfẹ́, ẹ fi ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti ìyọ́nú, inú rere, ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, ìwà tútù, àti ìpamọ́ra wọ ara yín láṣọ. Ẹ máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà lẹ́nì kìíní-kejì bí ẹnikẹ́ni bá ní ìdí fún ẹjọ́ lòdì sí ẹlòmíràn. Àní gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti dárí jì yín ní fàlàlà, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe.”—Kól. 3:12, 13. w17.11 27 ¶7-8
Friday, December 13
Kí ó sì sá lọ sí ọ̀kan nínú àwọn ìlú ńlá wọ̀nyí.—Jóṣ. 20:4.
Lẹ́yìn tẹ́nì kan bá ṣèèṣì pààyàn, ó gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ “sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní etí-ìgbọ́ àwọn àgbà ọkùnrin” tó wà ní ẹnubodè ìlú ààbò tó sá lọ, àwọn yẹn á sì gbà á tọwọ́tẹsẹ̀. Lẹ́yìn àsìkò díẹ̀, wọ́n á rán an pa dà sọ́dọ̀ àwọn àgbà ọkùnrin ìlú tí ọ̀rọ̀ náà ti ṣẹlẹ̀, kí wọ́n lè bójú tó ẹjọ́ náà. (Núm. 35:24, 25) Báwọn àgbà ọkùnrin náà bá dá ẹni náà láre pé kò mọ̀ọ́mọ̀ pa onítọ̀hún, wọ́n á dá a pa dà sí ìlú ààbò. Kí nìdí táwọn àgbà ọkùnrin fi ní láti dá sọ́rọ̀ náà? Ìdí ni pé àwọn ló ń mú káwọn èèyàn Ọlọ́run wà ní mímọ́, wọ́n sì tún ń ṣèrànwọ́ fún ẹni tó ṣèèṣì pààyàn náà kó lè rí àánú Jèhófà gbà. Ọ̀mọ̀wé Bíbélì kan sọ pé tẹ́ni tó ṣèèṣì pààyàn náà kò bá lọ bá àwọn àgbà ọkùnrin, ṣe ló ń “fi ẹ̀mí ara rẹ̀ wewu.” Ó wá fi kún un pé: “Ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ máa wà lọ́rùn rẹ̀ torí pé kò sá lọ síbi ààbò tí Ọlọ́run ṣètò fún un.” Tí kò bá sá lọ sí ọ̀kan lára àwọn ìlú ààbò tí Jèhófà pèsè, ìbátan ẹni tó pa lè gbẹ̀mí rẹ̀. w17.11 9 ¶6-7
Saturday, December 14
Gbogbo wọn kì í ha ṣe ẹ̀mí fún iṣẹ́ ìsìn gbogbo ènìyàn, tí a rán jáde láti ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn tí yóò jogún ìgbàlà?—Héb. 1:14.
Jèhófà ṣì ń lo àwọn áńgẹ́lì láti dáàbò bo àwa èèyàn rẹ̀, kí wọ́n sì fún wa lókun. (Mál. 3:6; Héb. 1:7) Látìgbà tí Ísírẹ́lì tẹ̀mí ti kúrò nígbèkùn Bábílónì Ńlá lọ́dún 1919, ìjọsìn mímọ́ túbọ̀ ń gbèrú láìka àtakò gbígbóná janjan táwọn ọ̀tá ń ṣe. (Ìṣí. 18:4) Torí pé àwọn áńgẹ́lì ń dáàbò bò wá, a mọ̀ pé Bábílónì Ńlá ò ní lágbára lórí wa mọ́. (Sm. 34:7) Kàkà bẹ́ẹ̀, ọkàn wa balẹ̀ pé àwa èèyàn Ọlọ́run á túbọ̀ máa gbèrú nípa tẹ̀mí. Àwọn ọmọ ogun ọ̀run wà lẹ́yìn wa. Nígbà táwọn alákòóso ayé Sátánì bá gbéjà kò wá nígbà ìpọ́njú ńlá, àwọn áńgẹ́lì tó jẹ́ ọmọ ogun Jèhófà máa kóra jọ, wọ́n á dáàbò bo àwa èèyàn Ọlọ́run, wọ́n á sì pa gbogbo àwọn tó ń ta ko ìṣàkóso Jèhófà. (2 Tẹs. 1:7, 8) Ọjọ́ ńlá lọjọ́ yẹn máa jẹ́! w17.10 28 ¶10-11
Sunday, December 15
[Ẹ máa gbé] ara yín ró lórí ìgbàgbọ́ yín mímọ́ jù lọ, [kí ẹ sì máa gbàdúrà] pẹ̀lú ẹ̀mí mímọ́.—Júúdà 20.
Ọgbẹ́ ọkàn téèyàn máa ń ní kì í ṣe kékeré tí ẹnì kan nínú ìdílé bá fi ètò Jèhófà sílẹ̀ tàbí tí wọ́n bá yọ ọ́ lẹ́gbẹ́. Kí lo lè ṣe tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀ sí ẹ? Máa ṣe ohun táá fún ìgbàgbọ́ rẹ lókun. Bí àpẹẹrẹ, máa ka Bíbélì déédéé, máa múra ìpàdé sílẹ̀ kó o sì máa pésẹ̀ déédéé. Bákan náà, máa wàásù déédéé, kó o sì máa gbàdúrà pé kí Jèhófà fún ẹ lókun tí wàá fi lè fara dà á. (Júúdà 21) Àmọ́, tó bá dà bíi pé ọkàn rẹ ò sí nínú àwọn nǹkan tó ò ń ṣe, kí lo lè ṣe? Má jẹ́ kó sú ẹ! Tó o bá tẹra mọ́ ṣíṣe àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run, wàá lè pọkàn pọ̀, ọ̀rọ̀ náà ò sì ní ká ẹ lára ju bó ṣe yẹ lọ. O lè kẹ́kọ̀ọ́ lára ẹni tó kọ Sáàmù kẹtàléláàádọ́rin [73]. Ìgbà kan wà tó ṣinú rò tíyẹn sì dà á lọ́kàn rú. Àmọ́ nígbà tó lọ síbi ìjọsìn Jèhófà, èrò tó ní yí pa dà, ọkàn rẹ̀ sì balẹ̀. (Sm. 73:16, 17) Nǹkan lè yí pa dà fún ìwọ náà bíi ti onísáàmù yẹn tó o bá ń fòótọ́ ọkàn sin Jèhófà nìṣó. w17.10 16 ¶17-18
Monday, December 16
Ẹ jẹ́ kí ìfẹ́ yín wà láìsí àgàbàgebè.—Róòmù 12:9.
Nínú ọgbà Édẹ́nì, Sátánì ṣe bí ẹni pé ire Éfà lòun ń wá, àmọ́ ohun tó ṣe fi hàn pé onímọtara-ẹni-nìkan àti alágàbàgebè ni. (Jẹ́n. 3:4, 5) Nígbà ayé Dáfídì, Áhítófẹ́lì fi hàn pé ọ̀rẹ́ ojú lásán lòun ń bá Dáfídì ṣe. Àmọ́ torí ohun tó máa rí gbà, ó kẹ̀yìn sí Dáfídì nígbà tí Ábúsálómù gba ìjọba. (2 Sám. 15:31) Bó ṣe rí lónìí náà nìyẹn, àwọn apẹ̀yìndà àtàwọn tó ń dá ìyapa sílẹ̀ nínú ìjọ máa ń lo “ọ̀rọ̀ dídùn mọ̀ràn-ìn mọran-in àti ọ̀rọ̀ ìyinni” bí ẹni pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn ará, àmọ́ ọ̀tọ̀ lohun tó wà lọ́kàn wọn. (Róòmù 16:17, 18) Ìfẹ́ àgàbàgebè tàbí ìfẹ́ ẹ̀tàn kò dáa torí pé ó yàtọ̀ pátápátá sí ìfẹ́ tòótọ́ tí ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà ń jẹ́ ká ní. Irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ lè tan àwọn èèyàn jẹ, àmọ́ a ò lè fi tan Jèhófà jẹ láé. Kódà, Jésù sọ pé “ìyà mímúná jù lọ” ló máa jẹ àwọn alágàbàgebè. (Mát. 24:51) Torí náà, ó yẹ ká bi ara wa pé, ‘Ṣé ìfẹ́ tí mo ní sáwọn èèyàn dénú, àbí ojú ayé ni mò ń ṣe? Ṣé kì í ṣe torí nǹkan tí màá rí gbà ni mo ṣe ń ṣe bíi pé mo nífẹ̀ẹ́ wọn?’ w17.10 8 ¶6-8
Tuesday, December 17
Wọ́n ní ìtara fún Ọlọ́run, ṣùgbọ́n kì í ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ pípéye.—Róòmù 10:2.
Tá a bá ń ka Bíbélì ní tààràtà lóde ẹ̀rí, ńṣe là ń jẹ́ kí Jèhófà bá onílé sọ̀rọ̀. Tá a bá ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tá a sì ṣàlàyé rẹ̀ lọ́nà tó gbéṣẹ́, ó máa wọ onílé lọ́kàn ju ọ̀rọ̀ èyíkéyìí tá a lè sọ. (1 Tẹs. 2:13) Torí náà, bi ara rẹ pé, ‘Ṣé mo máa ń sapá láti ka ẹsẹ Bíbélì kan, ó kéré tán pẹ̀lú àwọn tí mò ń wàásù fún?’ Tá a bá fẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wọ àwọn èèyàn lọ́kàn, kì í wulẹ̀ ṣe pé ká kàn ka Bíbélì fún wọn. Kí nìdí? Ìdí ni pé ọ̀pọ̀ ni kò lóye Bíbélì rárá tàbí kó jẹ́ pé nǹkan díẹ̀ ni wọ́n mọ̀ nípa rẹ̀. Bí nǹkan ṣe rí ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní náà nìyẹn. Torí náà, kò yẹ ká ronú pé tá a bá ṣáà ti ka Bíbélì fún ẹnì kan, á lóye rẹ̀. Ṣe ló yẹ ká tẹnu mọ́ àwọn apá tá a fẹ́ fún láfiyèsí, a tiẹ̀ lè tún un kà, ká sì fara balẹ̀ ṣàlàyé rẹ̀. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run á túbọ̀ wọ àwọn tá à ń wàásù fún lọ́kàn.—Lúùkù 24:32. w17.09 25 ¶7-8
Wednesday, December 18
Ẹ máa fi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn.—1 Pét. 3:8.
Lára ohun táwa Kristẹni gbọ́dọ̀ máa ṣe ni pé ká máa fàánú hàn sáwọn aládùúgbò wa àti sáwọn ará wa. (Jòh. 13:34,35) Ọ̀nà kan tá a lè gbà fàánú hàn ni pé ká “máa bá àwọn èèyàn kẹ́dùn.” Aláàánú èèyàn máa wá bó ṣe lè ran ẹni tó wà nínú ìṣòro lọ́wọ́. Torí náà, máa kíyè sí àwọn tó nílò ìrànlọ́wọ́. Wọ́n máa ń sọ pé ojú ló ń rójú ṣàánú. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé àwa èèyàn Jèhófà máa ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ nígbà tí àjálù bá ṣẹlẹ̀. (1 Pét. 2:17) Bí àpẹẹrẹ, ìmìtìtì ilẹ̀ àti àkúnya omi tó wáyé lórílẹ̀-èdè Japan lọ́dún 2011 ba nǹkan jẹ́ gan-an. Nígbà tí arábìnrin kan tó ń gbé lágbègbè yẹn rí ipa ribiribi táwọn ará sà láti ṣàtúnṣe àwọn ibi tó bà jẹ́, ó sọ pé “orí òun wú, inú òun sì dùn.” Kódà àwọn ará wá láti àwọn orílẹ̀-èdè míì láti ṣèrànwọ́. Ó wá sọ pé: “Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí jẹ́ kí n túbọ̀ rí i pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an àti pé a nífẹ̀ẹ́ ara wa lẹ́nì kìíní-kejì, kárí ayé làwọn ará sì ń gbàdúrà fún wa.” w17.09 11 ¶12-13
Thursday, December 19
Èso ti ẹ̀mí ni . . . ìkóra-ẹni-níjàánu.—Gál. 5:22, 23.
Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa kó ara wa níjàánu? Ẹ jẹ́ ká wo ìdí pàtàkì méjì. Àkọ́kọ́, ìwádìí ti fi hàn pé àwọn tó lè kó ara wọn níjàánu kì í sábà kó sí ìṣòro. Ara wọn máa ń balẹ̀, àwọn èèyàn máa ń mú irú wọn lọ́rẹ̀ẹ́, wọn kì í tètè bínú, wọn kì í sì í ní ìdààmú ọkàn bíi tàwọn tí kò lè kóra wọn níjàánu. Ìkejì, a gbọ́dọ̀ máa kó ara wa níjàánu tá a bá fẹ́ borí ìdẹwò àti èròkerò, ká sì máa jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run nìṣó. Èyí ṣe pàtàkì gan-an, torí pé Ádámù àti Éfà kò kó ara wọn níjàánu ni wọ́n ṣe pàdánù ojúure Jèhófà. (Jẹ́n. 3:6) Àìsí ìkóra-ẹni-níjàánu náà ló sì ń kó ọ̀pọ̀ èèyàn sí ìṣòro lónìí. Kò sí báwa èèyàn aláìpé ṣe lè kó ara wa níjàánu tá ò ní ṣàṣìṣe. Jèhófà náà mọ̀ bẹ́ẹ̀, ìdí sì nìyẹn tó fi ń ran àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ ká lè borí àìpé ẹ̀dá tá a jogún.—1 Ọba 8:46-50. w17.09 3-4 ¶3-4
Friday, December 20
Ẹ sì fi àkópọ̀ ìwà tuntun wọ ara yín láṣọ.—Kól. 3:10.
Ìgbà kan wà tí àwọn Ẹlẹ́rìí tó jẹ́ aláwọ̀ funfun ò lè péjọ pẹ̀lú àwọn tó jẹ́ aláwọ̀ dúdú lórílẹ̀-èdè South Africa. Síbẹ̀, lọ́jọ́ Sunday, December 18, 2011, àwọn Ẹlẹ́rìí tó ju ẹgbẹ̀rún lọ́nà méjìdínlọ́gọ́rin [78,000] lọ péjọ pọ̀ láti gbádùn àpéjọ kan. Orílẹ̀-èdè South Africa àtàwọn orílẹ̀-èdè míì tó wà nítòsí ni awọn tó pé jọ ti wá. Pápá ìṣeré tó tóbi jù nílùú Johannesburg ni wọ́n sì lò fún àpéjọ náà. Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ torí pé àti aláwọ̀ funfun àti aláwọ̀ dúdú ló péjọ síbẹ̀. Ọ̀kan lára àwọn tó ń bójú tó pápá ìṣeré náà sọ pé: “Mi ò rí àwọn èèyàn tó níwà tó dáa bíi tiyín rí ní pápá ìṣeré yìí. Gbogbo yín lẹ múra dáadáa. Ẹ tún mú kí pápá ìṣeré yìí mọ́ tónítóní nígbà tẹ́ ẹ ṣe tán. Àmọ́ ohun tó wú mi lórí jù ni pé ẹ wà níṣọ̀kan bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọ̀ yín yàtọ̀ síra.” Ohun táwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ yìí fi hàn pé ẹgbẹ́ ará wa ṣàrà ọ̀tọ̀ lóòótọ́. (1 Pét. 5:9) Àmọ́ kí ló mú ká yàtọ̀ sáwọn míì? Ohun tó mú ká yàtọ̀ ni pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ẹ̀mí mímọ́ ń mú ká “bọ́ ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà sílẹ̀,” ká sì fi “àkópọ̀ ìwà tuntun wọ ara [wa] láṣọ.”—Kól. 3:9. w17.08 17-18 ¶2-3
Saturday, December 21
Ẹ̀yin pẹ̀lú, ẹ mú sùúrù.—Ják. 5:8.
Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ìpamọ́ra tàbí sùúrù wà lára àwọn ànímọ́ tí ẹ̀mí mímọ́ máa ń jẹ́ kéèyàn ní. Láìjẹ́ pé Ọlọ́run ràn wá lọ́wọ́, àwa èèyàn aláìpé ò lè ní sùúrù débi tó yẹ. Ẹ̀mí Ọlọ́run ló ń jẹ́ ká ní sùúrù, tá a bá sì ní sùúrù, ṣe là ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run. Yàtọ̀ síyẹn, tá a bá ń ṣe sùúrù, a tún ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, ìfẹ́ yìí á sì máa lágbára sí i. Àmọ́ tá ò bá kí í ní sùúrù, ṣe ni ìfẹ́ yẹn á máa jó rẹ̀yìn. (1 Kọ́r. 13:4; Gál. 5:22) Ẹni bá ní sùúrù máa ní àwọn ànímọ́ dáadáa míì. Bí àpẹẹrẹ, ẹni tó ní sùúrù á ní ìfaradà. Ìfaradà máa ń mú ká ní àmúmọ́ra kódà bí nǹkan bá tiẹ̀ nira, á sì dá wa lójú pé nǹkan ṣì máa dáa. (Kól. 1:11; Ják. 1:3, 4) Ẹni tó ní sùúrù kì í gbẹ̀san, ó máa ń rọ́jú, kì í sì í bọ́hùn bó ti wù kí ìṣòro náà le tó. Bákan náà, Bíbélì rọ̀ wá pé ká ní ẹ̀mí ìdúródeni. Kókó yìí ni Jákọ́bù tẹnu mọ́ nínú Jákọ́bù 5:7, 8. w17.08 4 ¶4
Sunday, December 22
Má wò yí ká, nítorí èmi ni Ọlọ́run rẹ. Dájúdájú, èmi yóò fi okun fún ọ. Èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ ní ti tòótọ́.—Aísá. 41:10.
Ó dájú pé ẹ̀yin ọ̀dọ́ mọ̀ pé kéèyàn tó bẹ̀rẹ̀ ìrìn-àjò kan, ó gbọ́dọ̀ pinnu ibi tó ń lọ. Ìgbésí ayé dà bí ìgbà téèyàn ń rìnrìn-àjò, ìgbà tó o sì wà lọ́dọ̀ọ́ ló yẹ kó o pinnu ibi tó o fẹ́ forí lé. Lóòótọ́, kì í rọrùn láti pinnu ohun téèyàn máa fayé rẹ̀ ṣe. Àmọ́, má jẹ́ kẹ́rù bà ẹ́. Kíyè sí ohun tí Jèhófà sọ nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tòní. Jèhófà ń rọ̀ ẹ́ pé kó o fọgbọ́n pinnu ohun tó máa jẹ́ kó o gbádùn ọjọ́ ọ̀la rẹ. (Oníw. 12:1; Mát. 6:20) Ó fẹ́ kó o láyọ̀. Àwọn ohun tó dá fún ìgbádùn rẹ fi hàn pé lóòótọ́ ló fẹ́ kó o láyọ̀. Tún ronú nípa bí Jèhófà ṣe ń fìfẹ́ bójú tó ẹ tó sì ń kọ́ ẹ bó o ṣe máa lo ìgbésí ayé rẹ. Jèhófà sọ fáwọn tó fọwọ́ rọ́ ìlànà rẹ̀ sẹ́yìn pé: “Ohun tí èmi kò sì ní inú dídùn sí ni ẹ yàn. . . . Wò ó! Àwọn ìránṣẹ́ tèmi yóò yọ̀, ṣùgbọ́n ojú yóò ti ẹ̀yin. Wò ó! Àwọn ìránṣẹ́ tèmi yóò fi ìdùnnú ké jáde nítorí ipò rere ọkàn-àyà.” (Aísá. 65:12-14) Ó ṣe kedere pé inú Jèhófà máa ń dùn táwọn èèyàn rẹ̀ bá ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání.—Òwe 27:11. w17.07 22 ¶1-2
Monday, December 23
Gbogbo [àwọn ìràwọ̀] ni [Jèhófà] ń fi orúkọ wọn pè.—Sm. 147:4.
Ó ṣe kedere pé Ọlọ́run mọ ibi tí ìràwọ̀ kọ̀ọ̀kan wà. Torí náà, ó mọ àwa náà lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, ó mọ ibi tí kálukú wa wà, ó mọ bí nǹkan ṣe ń rí lára wa gan-an, ó sì mọ ohun tẹ́nì kọ̀ọ̀kan wa nílò nígbàkigbà! Yàtọ̀ sí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, ó tún mọ bí ọ̀rọ̀ ṣe máa ń rí lára wa, ó sì lágbára láti ràn wá lọ́wọ́ tá a bá wà nínú ìṣòro. (Sm. 147:5) Ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé ìṣòro rẹ ti wọ̀ ẹ́ lọ́rùn, tàbí pé àwọn ìṣòro náà kọjá agbára rẹ. Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Ọlọ́run mọ ibi tágbára rẹ mọ, ‘ó rántí pé ekuru ni ẹ́.’ (Sm. 103:14) Torí pé a jẹ́ aláìpé, a lè máa ṣe àṣìṣe kan náà léraléra. Ẹ wo bó ṣe máa ń dùn wá tó tá a bá ṣi ọ̀rọ̀ sọ tàbí tá a gbaná jẹ lórí ohun tí kò tó nǹkan, ó sì lè jẹ́ pé ṣe la máa ń jowú àwọn míì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà kì í ṣàṣìṣe, síbẹ̀ ó mọ bó ṣe máa ń rí lára wa tá a bá ṣàṣìṣe, òye tó ní kò ṣeé díwọ̀n, kódà kò sí àwárí òye rẹ̀! (Aísá. 40:28) Ó ṣeé ṣe kó o rántí ìgbà tí Jèhófà fi ọwọ́ agbára rẹ̀ ràn ẹ́ lọ́wọ́ nígbà tó o wà nínú ìṣòro.—Aísá. 41:10, 13. w17.07 18-19 ¶6-8
Tuesday, December 24
Ẹni tí ó bá jẹ́ olójú àánú ni a ó bù kún.—Òwe 22:9.
Arákùnrin kan wà tó jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ Sri Lanka àmọ́ tó ti kó lọ sórílẹ̀-èdè míì. Ó ní ilé àti ilẹ̀ ní Sri Lanka, ó sì yọ̀ǹda ẹ̀ fáwọn ará kí wọ́n lè máa ṣèpàdé àtàwọn àpéjọ níbẹ̀, ó tún gbà káwọn tó ń ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún máa gbébẹ̀. Arákùnrin náà lè máa fi ilé àti ilẹ̀ náà pawó, àmọ́ bó ṣe yọ̀ǹda rẹ̀ fáwọn ará tí kò fi bẹ́ẹ̀ lówó mú kí nǹkan rọrùn fún wọn gan-an. Yàtọ̀ síyẹn, ní ilẹ̀ kan tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ wa, àwọn ará máa ń yọ̀ǹda ilé wọn fún ìpàdé, èyí sì ti jẹ́ kó rọrùn fáwọn aṣáájú-ọ̀nà àtàwọn míì tí ò fi bẹ́ẹ̀ lówó láti máa ríbi ṣe ìpàdé láìsan owó kankan. Arábìnrin kan tó máa ń fowó ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ ìwàásù déédéé sọ àwọn ìbùkún tó ti rí, ó ní: “Bí mo ṣe máa ń fowó ṣètìlẹ́yìn ti jẹ́ kí n túbọ̀ sunwọ̀n sí i. Mo rí i pé bí mo ṣe ń fowó ṣètìlẹ́yìn ti jẹ́ kí n túbọ̀ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn. Mo túbọ̀ ń dárí jini, mo túbọ̀ ń ní sùúrù, mo túbọ̀ mọ béèyàn ṣe ń mú nǹkan mọ́ra, mo sì máa ń gbàmọ̀ràn.” w17.07 9 ¶9-10
Wednesday, December 25
Jèhófà sọ fún Sátánì pé: “Wò ó! Ohun gbogbo tí ó ní wà ní ọwọ́ rẹ.”—Jóòbù 1:12.
Ká tiẹ̀ sọ pé ó wá pàpà lóye ẹni tó wà lẹ́yìn ìyà tó jẹ ẹ́, ó lè máa rò ó pé kí nìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gbà á pé kóun jẹ adúrú ìyà yẹn. Èyí ó wù kó máa rò, ó dájú pé tó bá ń ronú lórí ìbáwí tí Ọlọ́run fún un, á jẹ́ kó máa fojú tó tọ́ wo ọ̀rọ̀ tó ṣẹlẹ̀ náà, ìyẹn á sì tù ú nínú. (Sm. 94:19) Tá a bá ń ronú lórí ìtàn Jóòbù, àwa náà máa ní èrò tó tọ́, àá sì tipa bẹ́ẹ̀ rí ìtùnú. Ó ṣe tán, Jèhófà mú kí wọ́n ṣàkọsílẹ̀ ìtàn náà “fún ìtọ́ni wa, pé nípasẹ̀ ìfaradà wa àti nípasẹ̀ ìtùnú láti inú Ìwé Mímọ́, kí a lè ní ìrètí.” (Róòmù 15:4) Kí la rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jóòbù? Kókó pàtàkì ibẹ̀ ni pé: Ká má jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ara wa gbà wá lọ́kàn débi tá a fi máa gbàgbé ọ̀rọ̀ tó ṣe pàtàkì jù náà, ìyẹn bí Jèhófà ṣe máa fi hàn pé òun lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso ayé àtọ̀run. Ká sì máa rántí pé gbogbo wa pátá lọ̀rọ̀ náà kàn ní ti pé a gbọ́dọ̀ jẹ́ olóòótọ́ lójú àdánwò bíi ti Jóòbù. w17.06 24 ¶9; 25 ¶13-14
Thursday, December 26
Ẹ máa bọ̀, ẹ̀yin fúnra yín, ní ẹ̀yin nìkan sí ibi tí ó dá, kí ẹ sì sinmi díẹ̀.—Máàkù 6:31.
Jésù náà máa ń wáyè sinmi. Nígbà kan tóun àtàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ti wàásù gan-an, ó sọ ọ̀rọ̀ tí a kọ sókè yìí fún wọn. Òótọ́ ni pé ó dáa kéèyàn máa gbafẹ́, kéèyàn sì wáyè fún eré ìnàjú. Síbẹ̀ tá ò bá ṣọ́ra, àwọn nǹkan yìí lè gbà wá lọ́kàn ju bó ṣe yẹ lọ. Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, ọ̀pọ̀ ló ní èrò náà pé, “Ẹ jẹ́ kí a máa jẹ, kí a sì máa mu, nítorí ọ̀la ni àwa yóò kú.” (1 Kọ́r. 15:32) Irú èrò yìí lọ̀pọ̀ èèyàn náà ní lónìí. Báwo la ṣe máa mọ̀ bóyá a ti ń ṣàṣejù nídìí eré ìnàjú? A lè yan ọ̀sẹ̀ kan, ká ṣàkọsílẹ̀ iye wákàtí tá a lò fún àwọn nǹkan tẹ̀mí bí lílọ sí ìpàdé, òde ẹ̀rí, ìdákẹ́kọ̀ọ́ àti ìjọsìn ìdílé. Lẹ́yìn náà, ká wá fi wéra pẹ̀lú iye wákàtí tá a lò lọ́sẹ̀ kan náà nídìí eré ìnàjú, bí eré ìmárale, eré ọwọ́ dilẹ̀, tẹlifíṣọ̀n àtàwọn géèmù orí fóònù tàbí kọ̀ǹpútà. Tá a bá fi wéra, èwo nínú méjèèjì là ń ṣe jù? Ǹjẹ́ kò ní gba pé ká dín iye àkókò tá à ń lò nídìí eré ìnàjú àti ìgbafẹ́ kù?—Éfé. 5:15, 16. w17.05 24-25 ¶11-13
Friday, December 27
Ìjọba ọ̀run dà bí olówò arìnrìn-àjò kan tí ń wá àwọn péálì àtàtà.—Mát. 13:45.
Nínú àkàwé Jésù, oníṣòwò náà rí péálì kan tó ṣeyebíye gan-an. Àmọ́ tó bá máa rí péálì náà rà, ó máa ní láti ta gbogbo ohun tó ní. Ṣé ìwọ náà rí bí péálì tí ọkùnrin yẹn rí ti ṣeyebíye sí i tó? Òtítọ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run ló dà bíi péálì tó ṣeyebíye yẹn. Tá a bá nífẹ̀ẹ́ Ìjọba Ọlọ́run bí oníṣòwò náà ṣe fẹ́ràn péálì yẹn, a ò ní gbà kí ohunkóhun dí wa lọ́wọ́ àtidi ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, a ò sì ní kúrò lábẹ́ Ìjọba náà. (Máàkù 10:28-30) Bí àpẹẹrẹ, Sákéù lówó gan-an torí pé ó máa ń rẹ́ àwọn èèyàn jẹ. (Lúùkù 19:1-9) Síbẹ̀, nígbà tí ọkùnrin aláìṣòótọ́ yẹn gbọ́ ìwàásù Jésù nípa Ìjọba Ọlọ́run, ó mọyì ohun tó gbọ́ gan-an, ó sì gbé ìgbésẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Ó sọ pé: “Wò ó! Olúwa, ìdajì nǹkan ìní mi ni èmi yóò fi fún àwọn òtòṣì, ohun yòówù tí mo sì lọ́ ẹnikẹ́ni lọ́wọ́ gbà nípasẹ̀ ẹ̀sùn èké ni èmi yóò dá padà ní ìlọ́po mẹ́rin.” Gbogbo nǹkan tó fèrú kó jọ ló fínnúfíndọ̀ yọ̀ǹda, ó sì jáwọ́ nínú ìgbésí ayé oníwọra tó ń gbé. w17.06 10 ¶3-5
Saturday, December 28
Èmi kò ní ìdí kankan tí ó tóbi ju nǹkan wọ̀nyí lọ fún ṣíṣọpẹ́, pé kí n máa gbọ́ pé àwọn ọmọ mi ń bá a lọ ní rírìn nínú òtítọ́.—3 Jòh. 4.
Ẹni táwọn òbí bá yàn pé kó ran ọmọ wọn lọ́wọ́ gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ọmọ náà mọ̀ pé ó yẹ kó máa bọ̀wọ̀ fáwọn òbí rẹ̀. Ẹni náà lè ṣe bẹ́ẹ̀ tó bá ń sọ̀rọ̀ tó dáa nípa àwọn òbí ọmọ náà, tí kò sì gba ojúṣe àwọn òbí náà ṣe. Yàtọ̀ síyẹn, kò yẹ kó máa bá ọmọ náà ṣe àwọn eré táwọn èèyàn á máa kọminú sí, yálà nínú ìjọ àbí lójú àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí. (1 Pét. 2:12) Kì í ṣe pé káwọn òbí kàn fa ọmọ wọn lé ẹnì kan lọ́wọ́, wọ́n gbọ́dọ̀ mọ bí ẹni náà ṣe ń ran ọmọ náà lọ́wọ́. Ó yẹ káwọn òbí rántí pé àwọn gbọ́dọ̀ máa kọ́ àwọn ọmọ wọn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ fúnra wọn. Ẹ̀yin òbí, ẹ bẹ Jèhófà pé kó ràn yín lọ́wọ́, kẹ́ ẹ sì ṣe gbogbo ohun tẹ́ ẹ lè ṣe. (2 Kíró. 15:7) Kì í ṣe ohun tó wù yín ló yẹ kẹ́ ẹ kà sí pàtàkì jù bí kò ṣe báwọn ọmọ yín ṣe máa sún mọ́ Jèhófà. Ẹ sapá láti rí i pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dọ́kàn àwọn ọmọ yín. Ẹ má ṣe ronú láé pé àwọn ọmọ yín ò ní sin Jèhófà. w17.05 12 ¶19-20
Sunday, December 29
Kò ṣeé ronú kàn níhà ọ̀dọ̀ mi, ní ojú ìwòye Jèhófà, pé kí n fi ohun ìní àjogúnbá àwọn baba ńlá mi fún ọ.—1 Ọba 21:3.
Fojú inú wo ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí. Wọ́n parọ́ mọ́ ọkùnrin kan pé ó dẹ́ṣẹ̀ kan tó burú jáì. Àwọn ọkùnrin tí kò dára fún ohunkóhun ló fi ẹ̀sùn èké kàn án, wọ́n sì dájọ́ ikú fún un. Èyí ya tẹbí tọ̀rẹ́ lẹ́nu gan-an. Yàtọ̀ síyẹn, inú àwọn tí kò nífẹ̀ẹ́ ká máa rẹ́ni jẹ kò dùn nígbà tí wọ́n rí bí wọ́n ṣe pa aláìmọwọ́mẹsẹ̀ yẹn àtàwọn ọmọkùnrin rẹ̀. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí kì í ṣe ìtàn àròsọ rárá. Ìránṣẹ́ Ọlọ́run kan tó ń jẹ́ Nábótì ló ṣẹlẹ̀ sí, ìgbà ayé Áhábù ọba Ísírẹ́lì ló sì ṣẹlẹ̀. (1 Ọba 21:11-13; 2 Ọba 9:26) Ọba Áhábù sọ fún Nábótì pé kó ta ọgbà àjàrà rẹ̀ fún òun tàbí kó jẹ́ kóun fún un ní òmíì tó dáa jùyẹn lọ, àmọ́ Nábótì kò gbà. Kí nìdí tí Nábótì fi kọ̀? Ìdí ni pé nínú òfin tí Jèhófà fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó sọ pé wọn ò gbọ́dọ̀ ta ogún ìdílé wọn títí lọ fáàbàdà. (Léf. 25:23; Núm. 36:7) Ó ṣe kedere pé ojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan ni Nábótì náà fi ń wò ó. w17.04 23 ¶1; 24 ¶4
Monday, December 30
Ní ìgbà díẹ̀ sí i, ẹni burúkú kì yóò sì sí mọ́; dájúdájú, ìwọ yóò sì fiyè sí ipò rẹ̀, òun kì yóò sì sí.—Sm. 37:10.
Àwọn wo ló máa rọ́pò àwọn ẹni burúkú? Jèhófà ṣèlérí tó ń múnú ẹni dùn yìí: “Àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.” Ní ẹsẹ míì nínú sáàmù kan náà, ó sọ pé: “Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.” (Sm. 37:11, 29) Àwọn wo ni “ọlọ́kàn tútù” àti “olódodo”? Ọlọ́kàn tútù làwọn tó fìrẹ̀lẹ̀ gba ìtọ́ni àti ìlànà Jèhófà, olódodo sì làwọn tó ń ṣe ohun tó tọ́ lójú Jèhófà Ọlọ́run. Nínú ayé tá a wà yìí, àwọn ẹni ibi pọ̀ ju àwọn olódodo lọ fíìfíì. Àmọ́ nínú ayé tuntun tó ń bọ̀, kì í ṣe ọ̀rọ̀ bóyá àwọn ọlọ́kàn tútù àtàwọn olódodo ló máa pọ̀ jù tàbí ló máa kéré jù, àwọn nìkan ṣoṣo ló máa wà láyé nígbà yẹn, wọ́n á sì sọ ayé di Párádísè. w17.04 10-11 ¶5-6
Tuesday, December 31
Má fawọ́ ohun rere sẹ́yìn . . . nígbà tí ó bá wà ní agbára ọwọ́ rẹ láti ṣe é.—Òwe 3:27.
Bíbélì sọ pé “ìfẹ́ fún Ọlọ́run” mú kó pọn dandan fún wa láti nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa pàápàá àwọn tó níṣòro. (1 Jòh. 3:17, 18) Nígbà tí ìyàn mú nílẹ̀ Jùdíà ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, àwọn ará ṣètò ìrànwọ́ fáwọn Kristẹni tó wà níbẹ̀. (Ìṣe 11:28, 29) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àti àpọ́sítélì Pétérù náà gba àwọn ará níyànjú pé kí wọ́n lẹ́mìí aájò àlejò. (Róòmù 12:13; 1 Pét. 4:9) Torí náà, tó bá yẹ káwọn Kristẹni máa gba àwọn tó bẹ̀ wọ́n wò lálejò, ṣé kò wá yẹ kí wọ́n máa ran àwọn ará tí ẹ̀mí wọn wà nínú ewu lọ́wọ́ tàbí àwọn tí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí torí ìgbàgbọ́ wọn? Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ogun abẹ́lé bẹ̀rẹ̀ ní ìlà oòrùn Ukraine, ọ̀pọ̀ àwọn ará ló ní láti sá kúrò lágbègbè yẹn torí inúnibíni. Ó dunni pé wọ́n pa àwọn kan lára wọn. Àmọ́ àwọn ará ní Rọ́ṣíà àti láwọn apá ibòmíì ní Ukraine gba àwọn ará náà sílé. Ibi yòówù káwọn ará yìí wà lórílẹ̀-èdè méjèèjì, wọn ò dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú torí pé wọn “kì í ṣe apá kan ayé.” Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n ń fìtara “polongo ìhìn rere ọ̀rọ̀ náà.”—Jòh. 15:19; Ìṣe 8:4. w17.05 4 ¶6-7