April
Thursday, April 1
Ọ̀rẹ́ tòótọ́ máa ń nífẹ̀ẹ́ ẹni nígbà gbogbo.—Òwe 17:17.
Ọ̀rẹ́ gidi ni Àrísítákọ́sì ará Makedóníà jẹ́ fún Pọ́ọ̀lù. Ìgbà àkọ́kọ́ tí Bíbélì mẹ́nu kan Àrísítákọ́sì nìgbà tí Pọ́ọ̀lù wà lẹ́nu ìrìn àjò míṣọ́nnárì rẹ̀ ẹlẹ́ẹ̀kẹta tó sì ṣèbẹ̀wò sí Éfésù. Lásìkò tí Pọ́ọ̀lù wà ní Éfésù, àwọn èèyàn dá rúgúdù sílẹ̀, wọ́n sì mú Àrísítákọ́sì. (Ìṣe 19:29) Lẹ́yìn tó jàjàbọ́ lọ́wọ́ àwọn èèyànkéèyàn náà, kò wá ibi tó lè forí pa mọ́ sí, kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ló tún ń bá Pọ́ọ̀lù ṣiṣẹ́. Oṣù mélòó kan lẹ́yìn náà, a tún gbọ́ pé Àrísítákọ́sì wà pẹ̀lú Pọ́ọ̀lù nílùú Gíríìsì bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn alátakò ń wá bí wọ́n ṣe máa gbẹ̀mí Pọ́ọ̀lù. (Ìṣe 20:2-4) Nígbà tó fi máa dọdún 58 Sànmánì Kristẹni, wọ́n ní kí Pọ́ọ̀lù lọ ṣẹ̀wọ̀n ní Róòmù. Kò ní yà yín lẹ́nu pé Àrísítákọ́sì wà lára àwọn tó bá Pọ́ọ̀lù rìnrìn àjò tó jìnnà yẹn, òun náà wà ńbẹ̀ nígbà tí ọkọ̀ ojú omi wọn rì. (Ìṣe 27:1, 2, 41) Nígbà tí wọ́n dé Róòmù, kò fi Pọ́ọ̀lù sílẹ̀, kódà ó wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú ẹ̀wọ̀n yẹn fúngbà díẹ̀. (Kól. 4:10) Abájọ tí Pọ́ọ̀lù fi sọ pé orísun ìṣírí ló jẹ́ fún òun, ó jẹ́ ọ̀rẹ́ tí ń dúró tini nígbà ìṣòro! Bíi ti Àrísítákọ́sì, àwa náà lè jẹ́ ọ̀rẹ́ tí ń dúró tini fáwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin nígbà dídùn àti ní “ìgbà wàhálà.” w20.01 9 ¶4-5
Friday, April 2
Aláyọ̀ àti ẹni mímọ́ ni ẹnikẹ́ni tó nípìn-ín nínú àjíǹde àkọ́kọ́.—Ìfi. 20:6.
Ẹnì kan tí Jèhófà fẹ̀mí yàn lè máa ronú pé òun ò yẹ lẹ́ni tí Jèhófà ń fẹ̀mí yàn. Àmọ́, kò jẹ́ ṣiyè méjì láé pé Jèhófà ti fẹ̀mí yan òun. Ṣe ni inú ẹ̀ á máa dùn gan-an, á sì mọyì àǹfààní tó ní pé òun máa gbé lọ́run. (1 Pét. 1:3, 4) Ṣé ohun tá à ń sọ ni pé ó ń wu àwọn ẹni àmì òróró pé kí wọ́n kú? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù dáhùn ìbéèrè yìí nígbà tó ń fi ẹran ara tí wọ́n gbé wọ̀ báyìí wé àgọ́, ó sọ pé: “Kódà, àwa tí a wà nínú àgọ́ yìí ń kérora, ìdààmú bò wá mọ́lẹ̀, torí pé a ò fẹ́ bọ́ èyí kúrò, àmọ́ a fẹ́ gbé èkejì wọ̀, kí ìyè lè gbé èyí tó lè kú mì.” (2 Kọ́r. 5:4) Àwọn Kristẹni yìí ò fẹ́ kú. Wọ́n fẹ́ wà láàyè, kí àwọn àtàwọn èèyàn wọn lè jọ máa sin Jèhófà lójoojúmọ́. Àmọ́ ohun yòówù kí wọ́n máa ṣe, wọn ò jẹ́ gbàgbé ìlérí àgbàyanu tí Ọlọ́run ṣe fún wọn.—1 Kọ́r. 15:53; 2 Pét. 1:4; 1 Jòh. 3:2, 3. w20.01 23 ¶12-13
Saturday, April 3
Àwọn tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ló máa ń bá wí.—Héb. 12:6.
Ká lè kẹ́kọ̀ọ́, Baba wa ọ̀run máa ń bá wa wí nígbà tó bá yẹ. Onírúurú ọ̀nà ló sì máa ń gbà ṣe bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ó lè jẹ́ ohun kan tá a kà nínú Bíbélì tàbí tá a gbọ́ nípàdé ló máa jẹ́ ká ríbi tá a kù sí. Ó sì lè lo àwọn alàgbà láti tọ́ wa sọ́nà. Ọ̀nà yòówù kó jẹ́, ó ṣe kedere pé ìfẹ́ tí Jèhófà ní fún wa ló mú kó máa bá wa wí. (Jer. 30:11) Jèhófà ń ràn wá lọ́wọ́ nígbà ìṣòro. Bí bàbá tó nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ rẹ̀ ṣe máa ń dúró tì wọ́n nígbà ìṣòro, bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà Baba wa ọ̀run ṣe máa ń wà pẹ̀lú wa nígbà ìṣòro. Ó máa ń lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ láti dáàbò bò wá kí ohunkóhun má bàa ba àjọṣe wa pẹ̀lú òun jẹ́. (Lúùkù 11:13) Jèhófà tún máa ń ràn wá lọ́wọ́ tá a bá ní ẹ̀dùn ọkàn. Bí àpẹẹrẹ, ó jẹ́ ká nírètí pé ọ̀la máa dáa. Ìrètí yìí ń mú ká lè máa fara da àwọn ìṣòro wa. Ohun kan tó dájú ni pé ohun yòówù kí ìṣòro tá a ní ti fà fún wa, Jèhófà máa mú gbogbo ẹ̀ kúrò. Torí náà, bó ti wù kí ìṣòro wa lágbára tó, ẹ jẹ́ ká máa rántí pé fúngbà díẹ̀ ni torí pé títí ayé ni Jèhófà á máa rọ̀jò ìbùkún rẹ̀ lé wa lórí.—2 Kọ́r. 4:16-18. w20.02 5 ¶14-15
Sunday, April 4
Ẹ̀mí tó ń gbé inú wa ń mú ká máa jowú ṣáá.—Jém. 4:5.
Ó dájú pé a lè borí ẹ̀mí ìlara! Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ àwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù. Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn tí wọ́n hùwà ìkà sí Jósẹ́fù, wọ́n pàdé ẹ̀ ní Íjíbítì. Kí Jósẹ́fù tó fara hàn wọ́n pé òun ni àbúrò wọn, ó dán wọn wò kó lè mọ̀ bóyá wọ́n ti yí pa dà. Ó ṣètò pé kí wọ́n bá òun jẹun, ó sì fún Bẹ́ńjámínì tó jẹ́ àbígbẹ̀yìn ní oúnjẹ tó pọ̀ ju tàwọn yòókù lọ. (Jẹ́n. 43:33, 34) Àmọ́, kò sí ohunkóhun tó fi hàn pé àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ jowú Bẹ́ńjámínì. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n fi hàn pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ àbúrò wọn gan-an, wọn ò sì fẹ́ ṣe ohun tó máa kó ẹ̀dùn ọkàn bá Jékọ́bù bàbá wọn. (Jẹ́n. 44:30-34) Torí pé àwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù ti yíwà pa dà, tí wọn ò sì ṣe ìlara mọ́, wọ́n mú kí àlàáfíà pa dà jọba nínú ìdílé wọn. (Jẹ́n. 45:4, 15) Lọ́nà kan náà, tá a bá fa ẹ̀mí ìlara tu kúrò lọ́kàn wa, àlàáfíà á jọba nínú ìdílé wa àti nínú ìjọ. Jèhófà fẹ́ ká sapá gan-an ká lè borí ìlara, ká sì jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà. Tá a bá lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, tá a ní ìtẹ́lọ́rùn, tá a sì mọyì àwọn míì, a ò ní jowú, a ò sì ní ṣèlara wọn. w20.02 19 ¶17-18
Monday, April 5
Mo nífẹ̀ẹ́ Jèhófà nítorí ó ń gbọ́ ohùn mi, ẹ̀bẹ̀ mi fún ìrànlọ́wọ́.—Sm. 116:1.
Ọ̀nà kan tó o lè gbà fi hàn pé o mọyì ìfẹ́ Jèhófà ni pé kó o máa gbàdúrà sí i. Wàá túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà bó o ṣe ń sọ ohun tó ń jẹ ẹ́ lọ́kàn fún un tó o sì ń dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ fún gbogbo oore rẹ̀. Bákan náà, bó o ṣe ń kíyè sí bí Jèhófà ṣe ń dáhùn àdúrà rẹ, okùn ọ̀rẹ́ yín á máa lágbára sí i. Á túbọ̀ dá ẹ lójú pé Jèhófà mọ̀ ẹ́, ó sì lóye rẹ. Àmọ́ tó o bá fẹ́ kí àjọṣe ìwọ àti Jèhófà túbọ̀ lágbára, ó ṣe pàtàkì kó o mọ ojú tó fi ń wo nǹkan àti ìdí tó fi ń ṣe àwọn ohun tó ń ṣe. Ó tún ṣe pàtàkì kó o mọ ohun tó fẹ́ kó o ṣe. Ọ̀nà kan ṣoṣo tó o sì lè gbà mọ àwọn nǹkan yìí ni pé kó o kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Torí náà, mọyì Bíbélì. Inú Bíbélì nìkan lo ti lè kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa Jèhófà àtohun tó ní lọ́kàn fún ẹ. O lè fi hàn pé o mọyì Bíbélì tó o bá ń kà á lójoojúmọ́, tó ò ń múra ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ sílẹ̀, tó o sì ń fi ohun tó ò ń kọ́ sílò. (Sm. 119:97, 99; Jòh. 17:17) Ǹjẹ́ o ní ìṣètò láti máa ka Bíbélì lójoojúmọ́? Ṣé o máa ń tẹ̀ lé ìṣètò náà, ṣé o sì ń rí i dájú pé ọjọ́ kan ò lọ láìka Bíbélì? w20.03 5 ¶8-9
Tuesday, April 6
Ó bẹ̀rẹ̀ sí í [fèròwérò] pẹ̀lú àwọn tó bá wà ní àrọ́wọ́tó.—Ìṣe 17:17.
Tí o kò bá lè rìn púpọ̀, o lè wá ibì kan jókòó sí níbi táwọn èèyàn ń gbà kọjá kó o lè wàásù fún wọn. O sì lè wàásù lọ́nà àìjẹ́ bí àṣà, o lè kọ lẹ́tà tàbí kó o wàásù lórí fóònù. Ọ̀pọ̀ àwọn ará tó ní àìlera tàbí tí ara wọn ti dara àgbà ló ń láyọ̀ bí wọ́n ṣe ń lọ́wọ́ nínú àwọn apá míì tí iṣẹ́ ìwàásù pín sí. Ohun yòówù kó mú kó nira fún ẹ, o ṣì lè ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ láṣeyanjú. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Mo ní okun láti ṣe ohun gbogbo nípasẹ̀ ẹni tó ń fún mi lágbára.” (Fílí. 4:13) Pọ́ọ̀lù nílò okun látọ̀dọ̀ Jèhófà torí pé ó ṣàìsàn nígbà kan tó rìnrìn àjò míṣọ́nnárì. Ó sọ fún àwọn ará ní Gálátíà pé: “Àìsàn tó ṣe mí ló jẹ́ kí n kọ́kọ́ láǹfààní láti kéde ìhìn rere fún yín.” (Gál. 4:13) Lọ́nà kan náà, àìlera rẹ lè mú kó o láǹfààní láti wàásù fáwọn dókítà, àwọn nọ́ọ̀sì àtàwọn míì tó ń tọ́jú rẹ. Má gbàgbé pé ibiṣẹ́ lọ̀pọ̀ wọn máa ń wà nígbà táwọn ará bá wàásù dé ilé wọn. w19.04 4-5 ¶10-11
Wednesday, April 7
Gbogbo àwọn tó bá fẹ́ fi ayé wọn sin Ọlọ́run tọkàntọkàn ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi Jésù ni wọ́n máa ṣe inúnibíni sí pẹ̀lú.—2 Tím. 3:12.
Lọ́dún 2018, àwọn akéde tó ju ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún méjì ó lé mẹ́tàlélógún (223,000) ló wà láwọn ilẹ̀ tí wọ́n ti fòfin de ìjọsìn wa, ìyẹn ò sì yà wá lẹ́nu rárá. Àwa Kristẹni tòótọ́ mọ̀ pé a máa kojú inúnibíni. Ibi yòówù ká máa gbé, ìgbàkigbà ni ìjọba lè ṣòfin pé a ò gbọ́dọ̀ jọ́sìn Jèhófà Baba wa onífẹ̀ẹ́ mọ́, ó sì lè bá wa lójijì. Tí ìjọba bá fòfin de ìjọsìn wa, a lè máa ronú pé bóyá Jèhófà ló ń bínú sí wa. Àmọ́ ohun kan wà tó yẹ ká fi sọ́kàn: Kì í ṣe torí pé Jèhófà ń bínú sáwa èèyàn rẹ̀ ló mú kó fàyè gba inúnibíni tí wọ́n ń ṣe sí wa. Àpẹẹrẹ kan tó mú kó túbọ̀ dá wa lójú ni ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Kò sí àní-àní pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ Pọ́ọ̀lù gan-an. Jèhófà mí sí i láti kọ mẹ́rìnlá (14) lára Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, ó sì tún jẹ́ àpọ́sítélì fún àwọn orílẹ̀-èdè. Síbẹ̀, ó dojú kọ inúnibíni tó gbóná janjan. (2 Kọ́r. 11:23-27) Àpẹẹrẹ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jẹ́ ká rí i pé Jèhófà máa ń fàyè gbà á pé káwọn ọ̀tá ṣenúnibíni sáwọn tó ń fòótọ́ ọkàn sìn ín. w19.07 8 ¶1, 3
Thursday, April 8
A ní ìjà kan . . . pẹ̀lú agbo ọmọ ogun àwọn ẹ̀mí burúkú ní àwọn ibi ọ̀run.—Éfé. 6:12.
Ọ̀kan lára ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà fìfẹ́ hàn ni bó ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè borí àwọn ọ̀tá wa. Olórí ọ̀tá wa ni Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀. Jèhófà kìlọ̀ fún wa pé ká ṣọ́ra fún wọn, ó sì tún sọ bá a ṣe lè bá wọn jà, ká sì borí wọn. (Éfé. 6:10-13) Tá a bá jẹ́ kí Jèhófà ràn wá lọ́wọ́, tá a sì gbára lé e pátápátá, àá borí Sátánì Èṣù. Àwa náà lè nírú ìdánilójú tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní nígbà tó sọ pé: “Tí Ọlọ́run bá wà lẹ́yìn wa, ta ló lè dènà wa?” (Róòmù 8:31) Kì í ṣe ọ̀rọ̀ nípa Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ ló gba àwa Kristẹni tòótọ́ lọ́kàn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó jẹ wá lógún ni bá a ṣe máa túbọ̀ mọ Jèhófà ká sì máa jọ́sìn rẹ̀ nìṣó. (Sm. 25:5) Bó ti wù kó rí, ó ṣe pàtàkì ká mọ àwọn ọ̀nà tí Sátánì ń gbà ṣi àwọn èèyàn lọ́nà. Kí nìdí? Ìdí ni pé a ò fẹ́ kó fi ọgbọ́n àyínìke rẹ̀ tàn wá jẹ.—2 Kọ́r. 2:11; àlàyé ìsàlẹ̀. w19.04 20 ¶1-2
Friday, April 9
Ó yẹ kí gbogbo èèyàn yára láti gbọ́rọ̀, kí wọ́n lọ́ra láti sọ̀rọ̀.—Jém. 1:19.
Tá a bá ń bá àwọn ẹni tó ní ẹ̀dùn ọkàn sọ̀rọ̀, ṣé a máa ń fara balẹ̀ tẹ́tí sí wọn? Ó kọjá pé ká kàn dúró ká máa gbọ́ ohun tí wọ́n ń sọ. Tá a bá ń tẹ́tí sí ẹnì kan, a lè sọ ohun tó máa jẹ́ kẹ́ni náà mọ bí ọ̀rọ̀ yẹn ṣe rí lára wa. A lè sọ pé: “Ó dùn mí gan-an pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí ẹ!” O sì lè fọgbọ́n bi í láwọn ìbéèrè kan kí ohun tó ń sọ lè yé ẹ dáadáa. O lè bi í pé, “Ṣé o lè tún àlàyé yẹn ṣe kí n lè mọ̀ bóyá mo gbọ́ ẹ dáadáa?” tàbí “Ṣé ohun tó ò ń sọ ni pé . . . Ṣé bẹ́ẹ̀ ni?” Irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ máa jẹ́ kẹ́ni náà mọ̀ pé lóòótọ́ là ń tẹ́tí sí òun ká lè lóye ọ̀rọ̀ òun. (1 Kọ́r. 13:4, 7) Ó tún ṣe pàtàkì pé ká “lọ́ra láti sọ̀rọ̀.” Má ṣe já lu ọ̀rọ̀ ẹni náà torí pé o fẹ́ fún un nímọ̀ràn tàbí pé o fẹ́ tún èrò rẹ̀ ṣe. Rí i dájú pé o mú sùúrù fún un! Dípò ká máa ronú ohun tá a máa sọ láti yanjú ìṣòro ẹ̀, á dáa ká jẹ́ kó mọ̀ pé a ṣì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ àti pé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i dùn wá.—1 Pét. 3:8. w19.05 17-18 ¶15-17
Saturday, April 10
Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn aya yín, bí Kristi ṣe nífẹ̀ẹ́ ìjọ, tó sì fi ara rẹ̀ lélẹ̀ fún un.—Éfé. 5:25.
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run rọ àwọn ọkọ pé kí wọ́n máa nífẹ̀ẹ́ ìyàwó wọn “bí Kristi ti ń ṣe sí ìjọ.” (Éfé. 5:28, 29) Irú ìfẹ́ tí Kristi ní ló yẹ káwọn ọkọ ní sáwọn ìyàwó wọn, kí wọ́n máa fi ire wọn ṣáájú tiwọn, ohun tí ìyàwó wọn nílò ló sì yẹ kó gbawájú. Àwọn ọkọ kan ò mọ bí wọ́n ṣe lè fìfẹ́ hàn bóyá torí bí wọ́n ṣe tọ́ wọn dàgbà. Ó lè ṣòro fún wọn láti yíwà tó ti mọ́ wọn lára pa dà, àmọ́ ó di dandan kí wọ́n ṣe àwọn ìyípadà tó yẹ tí wọ́n bá máa tẹ̀ lé òfin Kristi. Tí ọkọ kan bá ń fi irú ìfẹ́ tí Kristi ní hàn sí ìyàwó rẹ̀, ìyàwó náà á máa bọ̀wọ̀ fún un. Bàbá tó nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ rẹ̀ dénú kò ní máa sọ̀rọ̀ kòbákùngbé sí wọn, kò sì ní hùwà ìkà sí wọn. (Éfé. 4:31) Kàkà bẹ́ẹ̀, ó yẹ kó máa fìfẹ́ hàn sí wọn, kó sì mọyì wọn. Èyí á mú kí ọkàn àwọn ọmọ náà balẹ̀ kára sì tù wọ́n. Ó dájú pé àwọn ọmọ náà máa nífẹ̀ẹ́ bàbá wọn, wọ́n á sì fọkàn tán an. w19.05 6 ¶21
Sunday, April 11
Jèhófà Ọlọ́run sì máa fún un ní ìtẹ́ Dáfídì bàbá rẹ̀, ó máa jẹ Ọba lórí ilé Jékọ́bù títí láé.—Lúùkù 1:32, 33.
Báwo lọ̀rọ̀ tí Gébúrẹ́lì sọ yìí ṣe rí lára Màríà? Ṣé ó ronú pé Jésù ọmọ òun ló máa gba ipò Ọba Hẹ́rọ́dù tàbí ẹlòmíì tó máa jẹ lẹ́yìn rẹ̀ táá sì wá di ọba Ísírẹ́lì? Tí Jésù bá di ọba, á jẹ́ pé Màríà di ìyá ààfin nìyẹn, gbogbo ìdílé wọn á sì máa gbé láàfin. Síbẹ̀, a ò rí i kà pé Màríà béèrè fún ipò ọlá nínú Ìjọba Ọlọ́run. Èyí jẹ́ ká rí i pé obìnrin tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ gan-an ni Màríà. Ká má gbàgbé pé, ohun tó yẹ kó gbà wá lọ́kàn jù bá a ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àtàwọn ìtẹ̀jáde wa ni pé a fẹ́ túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. A tún fẹ́ fara balẹ̀ kíyè sí “irú ẹni” tá a jẹ́ ká lè ṣe àwọn àtúnṣe tó tọ́ ká bàa lè múnú Jèhófà dùn. (Jém. 1:22-25; 4:8) Torí náà, ká tó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́, ó yẹ ká gbàdúrà fún ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà. Ká sì tún bẹ̀ ẹ́ pé kó jẹ́ ká jàǹfààní ní kíkún nínú ohun tá a fẹ́ kà, ká sì rí àwọn ibi tá a kù sí. w19.05 31 ¶18-19
Monday, April 12
Ìdààmú ńlá ló bá mi.—1 Sám. 1:15.
Nígbà míì, ìṣòro tá a ní lè ju ẹyọ kan lọ. Ẹ jẹ́ ká wo àwọn àpẹẹrẹ tó tẹ̀ lé e yìí. Arákùnrin kan tó ń jẹ́ John ní àrùn multiple sclerosis tó máa ń jẹ́ kí iṣan ara le gbagidi. Àfi bíi pé ìyẹn ò tó, ìyàwó rẹ̀ tún fi í sílẹ̀ lẹ́yìn ọdún mọ́kàndínlógún (19) tí wọ́n ti ṣègbéyàwó. Kò tán síbẹ̀ o, àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ méjèèjì náà tún fi Jèhófà sílẹ̀. Àpẹẹrẹ àwọn míì tó tún kojú ìṣòro ni tọkọtaya kan tó ń jẹ́ Bob àti Linda. Iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ àwọn méjèèjì, bó ṣe di pé wọn ò rówó ilé san mọ́ nìyẹn, tí wọ́n sì kó jáde. Ìyẹn nìkan kọ́ o, àyẹ̀wò tún fi hàn pé Linda ní àrùn ọkàn tó lè ṣekú pa á nígbàkigbà, yàtọ̀ síyẹn àwọn sẹ́ẹ̀lì tó ń gbógun ti àrùn lára rẹ̀ ti daṣẹ́ sílẹ̀. Ó dá wa lójú pé Jèhófà, Baba wa onífẹ̀ẹ́ àti Ẹlẹ́dàá wa mọ bí àwọn ìṣòro wa ṣe ń kó ìdààmú ọkàn bá wa, ó sì fẹ́ ràn wá lọ́wọ́ ká lè fara dà á. (Fílí. 4:6, 7) Bíbélì jẹ́ ká mọ ìṣòro tí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run kan kojú. Ó tún jẹ́ ká mọ bí Jèhófà ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́ láti fara da àwọn ìṣòro náà. w19.06 14 ¶2-3
Tuesday, April 13
Ọ̀rẹ́ tòótọ́ máa ń nífẹ̀ẹ́ ẹni nígbà gbogbo, ó sì jẹ́ ọmọ ìyá tí a bí fún ìgbà wàhálà.—Òwe 17:17.
Tá a bá ṣenúure sáwọn tí kò ní ọkọ tàbí aya mọ́, á jẹ́ kó dá wọn lójú pé a nífẹ̀ẹ́ wọn. Àsìkò yìí gan-an ni wọ́n nílò àwọn ọ̀rẹ́ tó ń dúró tini. Báwo lo ṣe lè jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé o nífẹ̀ẹ́ wọn dénú? O lè ní kí wọ́n wá kí ẹ, kẹ́ ẹ sì jọ jẹun. Bákan náà, ẹ lè jọ ṣeré jáde tàbí kẹ́ ẹ jọ ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí. Ohun míì tó o lè ṣe ni pé kó o ní kí wọ́n dara pọ̀ mọ́ ìdílé rẹ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan tẹ́ ẹ bá fẹ́ ṣe Ìjọsìn Ìdílé. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá mú inú Jèhófà dùn, torí pé Jèhófà “wà nítòsí àwọn tó ní ọgbẹ́ ọkàn,” òun ló sì “ń dáàbò bo àwọn opó.” (Sm. 34:18; 68:5) Nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso, gbogbo ‘wàhálà máa di ohun ìgbàgbé.’ Ẹ wo bí nǹkan ṣe máa rí nígbà tí ‘àwọn ohun àtijọ́ ò ní wá sí ìrántí, tí wọn ò sì ní wá sí ọkàn mọ́.’ (Àìsá. 65:16, 17) Títí dìgbà yẹn, ẹ jẹ́ ká máa ran ara wa lọ́wọ́ ká sì máa fi hàn lọ́rọ̀ àti níṣe pé a nífẹ̀ẹ́ gbogbo àwọn ará wa.—1 Pét. 3:8. w19.06 25 ¶18-19
Wednesday, April 14
Jèhófà ni olùrànlọ́wọ́ mi; mi ò ní bẹ̀rù.—Héb. 13:6.
Lọ́pọ̀ ọdún sẹ́yìn, Ilé Ìṣọ́ kan sọ pé: “Téèyàn bá mọ Ọlọ́run dáadáa, á gbọ́kàn lé e pátápátá nígbà àdánwò.” Òótọ́ pọ́ńbélé lọ̀rọ̀ yẹn! Ká tó lè fara da àtakò láìbọ́hùn, a gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ká gbẹ́kẹ̀ lé e pátápátá, ká má sì ṣiyèméjì pé ó nífẹ̀ẹ́ wa gan-an. (Mát. 22:36-38; Jém. 5:11) Máa ka Bíbélì lójoojúmọ́ lọ́nà táá mú kó o túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. (Jém. 4:8) Bó o ṣe ń kà á, máa ronú nípa àwọn ànímọ́ rere tí Jèhófà ní. Máa kíyè sí bí àwọn ohun tó sọ àtàwọn nǹkan tó ṣe ṣe fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ wa àti pé ó mọyì wa. (Ẹ́kís. 34:6) Kò rọrùn fún àwọn kan láti gbà pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wọn torí pé kò sẹ́ni tó fìfẹ́ hàn sí wọn rí. Tó bá jẹ́ pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ tìẹ náà rí, gbìyànjú kó o fi àbá yìí sílò: Lójoojúmọ́, máa ṣàkọsílẹ̀ àwọn nǹkan rere tí Jèhófà ṣe fún ẹ àti bó ṣe fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ rẹ. (Sm. 78:38, 39; Róòmù 8:32) Bó o ṣe ń kíyè sáwọn nǹkan rere tí Jèhófà ń ṣe fún ẹ, tó o sì ń ronú lórí àwọn nǹkan tó ò ń kà nínú Bíbélì, wàá rí i pé ọ̀pọ̀ nǹkan ni Jèhófà ti ṣe fún ẹ. Bó o ṣe túbọ̀ ń mọyì ohun tí Jèhófà ti ṣe, bẹ́ẹ̀ ni àjọṣe tó wà láàárín yín á máa lágbára sí i.—Sm. 116:1, 2. w19.07 2-3 ¶4-5
Thursday, April 15
Kì í ṣe pé a jẹ́ ọ̀gá lórí ìgbàgbọ́ yín, àmọ́ a jọ ń ṣiṣẹ́ kí ẹ lè máa láyọ̀, torí ìgbàgbọ́ yín ló mú kí ẹ dúró.—2 Kọ́r. 1:24.
Ká fi sọ́kàn pé Jèhófà kò fún ẹnikẹ́ni nínú wa láṣẹ láti ṣèpinnu fún àwọn míì. Ńṣe lẹni tó ń ṣe òfin máṣu mátọ̀ ń sọ ara ẹ̀ di ọ̀gá lórí ìgbàgbọ́ àwọn ará dípò kó dáàbò bò wọ́n. Sátánì Èṣù kò ní dẹ̀yìn lẹ́yìn àwọn tó ń fòótọ́ ọkàn sin Jèhófà. (1 Pét. 5:8; Ìfi. 2:10) Òun àtàwọn ìsọ̀ǹgbè rẹ̀ máa wá gbogbo ọ̀nà láti mú ká ṣíwọ́ jíjọ́sìn Jèhófà. Àmọ́ ẹ má ṣe jẹ́ ká bẹ̀rù! (Diu. 7:21) Jèhófà wà pẹ̀lú wa, kò sì ní fi wá sílẹ̀ láé kódà tí wọ́n bá fòfin de iṣẹ́ wa. (2 Kíró. 32:7, 8) Ẹ jẹ́ káwa náà pinnu bíi tàwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, tí wọ́n sọ fún àwọn aláṣẹ ìgbà yẹn pé: “Ẹ̀yin náà ẹ sọ, tó bá tọ́ lójú Ọlọ́run pé ká fetí sí yín dípò ká fetí sí Ọlọ́run. Àmọ́ ní tiwa, a ò lè ṣàì sọ ohun tí a ti rí tí a sì ti gbọ́.”—Ìṣe 4:19, 20. w19.07 13 ¶18-20
Friday, April 16
Èrò ọkàn èèyàn dà bí omi jíjìn, àmọ́ olóye ló ń fà á jáde.—Òwe 20:5.
Tá a bá ń wàásù, ká rí i pé a lóye ìdí táwọn tá à ń wàásù fún fi ní irú èrò tí wọ́n ní. Júù ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, àárín wọn náà ló sì dàgbà sí. Torí náà, ó máa gba pé kó mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ bá àwọn tí kì í ṣe Júù mu torí pé wọn ò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ nípa Jèhófà àti Ìwé Mímọ́. Káwa náà lè lóye àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa, ó lè gba pé ká ṣèwádìí. (1 Kọ́r. 9:20-23) Ohun tó jẹ wá lógún ni bá a ṣe máa rí àwọn “ẹni yíyẹ.” (Mát. 10:11) Ká lè dá àwọn ẹni yíyẹ mọ̀, a gbọ́dọ̀ jẹ́ kí wọ́n sọ èrò wọn, ká sì tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa. Arákùnrin kan lórílẹ̀-èdè England máa ń ní káwọn èèyàn sọ èrò wọn nípa bá a ṣe lè ní ìdílé aláyọ̀, bá a ṣe lè tọ́ àwọn ọmọ yanjú àti bá a ṣe lè fara da ìwà ìrẹ́jẹ. Lẹ́yìn tó bá ti gbọ́ èrò wọn, á wá sọ pé, “Kí lèrò yín nípa ìmọ̀ràn tí wọ́n kọ sílẹ̀ lóhun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún ọdún méjì (2,000) sẹ́yìn yìí?” Láì mẹ́nu ba Bíbélì, á wá fi àwọn ẹsẹ Bíbélì hàn wọ́n lórí fóònù rẹ̀. w19.07 21-22 ¶7-8
Saturday, April 17
Ọlọ́run dámọ̀ràn ìfẹ́ rẹ̀ fún wa ní ti pé, nígbà tí a ṣì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, Kristi kú fún wa.—Róòmù 5:8.
Báwo ló ṣe yẹ kí ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà jinlẹ̀ tó? Jésù sọ fún Farisí kan pé: “Kí o fi gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo ara rẹ àti gbogbo èrò rẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ.” (Mát. 22:36, 37) Èyí fi hàn pé ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà kò gbọ́dọ̀ jẹ́ ìfẹ́ orí ahọ́n. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló yẹ kó dà bí igi tó ń gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ lójoojúmọ́. Ká tó lè nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, ó ṣe pàtàkì ká mọ̀ ọ́n dáadáa. Bíbélì sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tí kò bá nífẹ̀ẹ́ kò tíì mọ Ọlọ́run, torí Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” (1 Jòh. 4:8) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà á túbọ̀ jinlẹ̀ tá a bá ní “ìmọ̀ tó péye àti òye tó kún rẹ́rẹ́” nípa Jèhófà. (Fílí. 1:9) Nígbà tá a bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, a bẹ̀rẹ̀ sí í nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tá a mọ̀ nípa rẹ̀ kò fi bẹ́ẹ̀ tó nǹkan. Àmọ́, bá a ṣe túbọ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ tá a ní fún un túbọ̀ ń jinlẹ̀. Ìdí nìyẹn tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ká sì máa ṣàṣàrò lórí ẹ̀ lójoojúmọ́.—Fílí. 2:16. w19.08 9 ¶4-5
Sunday, April 18
Ẹni méjì sàn ju ẹnì kan lọ.—Oníw. 4:9.
Tí iṣẹ́ ìsìn rẹ bá yí pa dà, á dáa kó o láwọn ọ̀rẹ́ tuntun níbi tó o wà báyìí. Rántí pé tó o bá fẹ́ lọ́rẹ̀ẹ́, ó yẹ kára tìẹ náà yá mọ́ọ̀yàn. Jẹ́ káwọn ará mọ àwọn ohun rere tí Jèhófà ti ṣe fún ẹ, kí wọ́n lè rí i pé o gbádùn iṣẹ́ ìsìn yẹn gan-an. Tó bá jẹ́ pé àìsàn ọkọ tàbí ìyàwó rẹ ló mú kẹ́ ẹ fiṣẹ́ ìsìn sílẹ̀, má ṣe dá a lẹ́bi. Tó bá sì jẹ́ pé àìlera tìẹ ló mú kẹ́ ẹ fiṣẹ́ náà sílẹ̀, má ṣe máa dá ara ẹ lẹ́bi, má sì ronú pé ìwọ lo fi tìẹ kó bá ẹnì kejì rẹ. Rántí pé “ara kan” ni yín, ẹ sì ti ṣèlérí níwájú Jèhófà pé èkùrọ̀ ni alábàákú ẹ̀wà, pé lábẹ́ dídùn lábẹ́ kíkan, ẹ̀ẹ́ wà fúnra yín. (Mát. 19:5, 6) Tó bá jẹ́ pé oyún ló gbé yín kúrò lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn, ẹ jẹ́ kí ọmọ yín mọ̀ pé ẹ mọyì rẹ̀ ju iṣẹ́ ìsìn yín lọ. Ẹ máa fi dá ọmọ náà lójú nígbà gbogbo pé ìbùkún látọ̀dọ̀ Jèhófà ni. (Sm. 127:3-5) Bákan náà, ẹ máa sọ àwọn ìrírí alárinrin tẹ́ ẹ ní nígbà tẹ́ ẹ wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún fún un. Tẹ́ ẹ bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, á mú kó máa wu ọmọ yín láti fayé rẹ̀ sin Jèhófà bẹ́yin náà ti ṣe. w19.08 22 ¶10-11
Monday, April 19
Màá fi ìdájọ́ aṣẹ́wó ńlá . . . hàn ọ́.—Ìfi. 17:1.
Bábílónì Ńlá ti kó ẹ̀gàn bá orúkọ mímọ́ Jèhófà gan-an. Ó tún ń pa irọ́ fáwọn èèyàn nípa Ọlọ́run. Aṣẹ́wó ni torí pé àwọn alákòóso ayé ló ń tì lẹ́yìn dípò Ìjọba Ọlọ́run. Ó ń mú àwọn ọmọ abẹ́ rẹ̀ sìn, ó sì ń fipá gba tọwọ́ wọn. Ó ti ṣekú pa ọ̀pọ̀ èèyàn títí kan àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run. (Ìfi. 18:24; 19:2) Jèhófà máa lo “ìwo mẹ́wàá” tó wà lórí “ẹranko aláwọ̀ rírẹ̀dòdò” kan láti pa “aṣẹ́wó ńlá” náà run. Ẹranko ẹhànnà yìí ṣàpẹẹrẹ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè. Ìwo mẹ́wàá orí rẹ̀ sì dúró fún àwọn ìjọba tó ń ṣàkóso báyìí tí wọ́n ń ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè lẹ́yìn. Tó bá tó àsìkò lójú Jèhófà, á mú kí àwọn alákòóso yẹn gbéjà ko Bábílónì Ńlá. Wọ́n “máa sọ ọ́ di ahoro, wọ́n á tú u sí ìhòòhò” ní ti pé wọ́n á gba gbogbo ohun àmúṣọrọ̀ rẹ̀, wọ́n á sì tú àṣírí ìwà ìkà tó ń hù. (Ìfi. 17:3, 16) Òjijì ni ìparun yẹn máa ṣẹlẹ̀, bíi pé ní ọjọ́ kan ṣoṣo, kódà ó máa ya àwọn alátìlẹyìn rẹ̀ lẹ́nu. Ó ṣe tán, ọjọ́ pẹ́ tó ti ń fọ́nnu pé: “Mi ò . . . ní ṣọ̀fọ̀ láé.”—Ìfi. 18:7, 8. w19.09 10 ¶10-11
Tuesday, April 20
Ẹ gba àjàgà mi sọ́rùn yín, kí ẹ sì kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi.—Mát. 11:29.
Gbogbo èèyàn ni Jésù pè, kò sì ní lé ẹnikẹ́ni tó bá ṣe tán láti sin Jèhófà tọkàntọkàn pa dà. (Jòh. 6:37, 38) Ojúṣe gbogbo àwa ọmọlẹ́yìn Kristi ni láti lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ tí Jèhófà gbé fún Jésù. Ó sì dá wa lójú pé Jésù á máa wà pẹ̀lú wa lẹ́nu iṣẹ́ náà, kò sì ní dá wa dá a. (Mát. 28:18-20) Àwọn onírẹ̀lẹ̀ fẹ́ràn Jésù gan-an. (Mát. 19:13, 14; Lúùkù 7:37, 38) Kí nìdí? Ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ lára ìyàtọ̀ tó wà láàárín Jésù àtàwọn Farisí. Àwọn Farisí ò lójú àánú, wọ́n sì máa ń gbéra ga. (Mát. 12:9-14) Ẹlẹ́yinjú àánú ni Jésù ní tiẹ̀, ó sì lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. Àwọn Farisí máa ń wá ipò ọlá, wọ́n sì máa ń ṣe fọ́ńté torí ipò wọn láwùjọ. Àmọ́ Jésù dẹ́bi fún wíwá ipò ọlá, ó sì kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, kí wọ́n sì ṣe tán láti ṣiṣẹ́ sin àwọn míì. (Mát. 23:2, 6-11) Àwọn Farisí máa ń jẹ gàba lé àwọn míì lórí, wọ́n sì máa ń lo agbára bó ṣe wù wọ́n káwọn èèyàn lè bẹ̀rù wọn. (Jòh. 9:13, 22) Ọ̀rọ̀ Jésù ní tiẹ̀ máa ń tu àwọn èèyàn lára, ó sì máa ń fìfẹ́ hàn sí wọn. Kí làwọn nǹkan tá a sọ tán yìí kọ́ ẹ? w19.09 20 ¶1; 21 ¶7-8; 23 ¶9
Wednesday, April 21
Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, á sì sún mọ́ yín.—Jém. 4:8.
Àwọn ìpàdé wa máa ń jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Ọwọ́ tá a bá fi mú ìpàdé máa fi hàn bóyá àá lè fara da inúnibíni lọ́jọ́ iwájú. (Héb. 10:24, 25) Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Tí àwọn nǹkan kéékèèké bá ń dí wa lọ́wọ́ àtimáa lọ sípàdé báyìí, kí ló máa ṣẹlẹ̀ tó bá di pé ká fẹ̀mí ara wa wewu ká lè wà pẹ̀lú àwọn ará wa lásìkò tí nǹkan bá ṣòro gan-an? Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, tá a bá pinnu pé a ò ní jẹ́ kí ohunkóhun dí wa lọ́wọ́ àtimáa pésẹ̀ sípàdé, ó dájú pé kò sóhun táwọn alátakò lè ṣe lọ́jọ́ iwájú táá mú ká pa ìpàdé tì. Àkókò yìí gan-an ló yẹ ká túbọ̀ fọwọ́ pàtàkì mú àwọn ìpàdé wa. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ohun yòówù káwọn alátakò ṣe, kódà kí ìjọba fòfin de iṣẹ́ wa, a ò ní dẹwọ́ àtimáa ṣègbọràn sí Ọlọ́run dípò èèyàn. (Ìṣe 5:29) Há àwọn ẹsẹ Bíbélì tó o fẹ́ràn jù sórí. (Mát. 13:52) O lè má rántí gbogbo ẹ̀, àmọ́ Jèhófà lè fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ kó o lè rántí àwọn ẹsẹ Bíbélì náà lásìkò tó o nílò rẹ̀. (Jòh. 14:26) Àwọn ẹsẹ Bíbélì yẹn á jẹ́ kíwọ náà túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, kó o sì fara da inúnibíni láìbọ́hùn. w19.07 3 ¶5; 4 ¶8-9
Thursday, April 22
Kí o mọ èyí pé, àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yóò jẹ́ àkókò tí nǹkan máa le gan-an, tó sì máa nira.—2 Tím. 3:1.
Ṣé ẹ̀yìn ọdún 1914 ni wọ́n bí ẹ? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, á jẹ́ pé “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” lo ti ṣe kékeré, inú ẹ̀ náà lo sì dàgbà sí. Gbogbo wa pátá là ń gbọ́ ìròyìn àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí bí Jésù ṣe sọ tẹ́lẹ̀. Lára wọn ni ogun, àìtó oúnjẹ, ìmìtìtì ilẹ̀, àjàkálẹ̀ àrùn, ìwà tí kò bófin mu tó ń pọ̀ sí i àti inúnibíni tí wọ́n ń ṣe sáwa èèyàn Jèhófà. (Mát. 24:3, 7-9, 12; Lúùkù 21:10-12) Bákan náà là ń rí ìwà abèṣe tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé àwọn èèyàn á máa hù lọ́jọ́ ìkẹyìn yìí. Ó dá àwa ìránṣẹ́ Jèhófà lójú pé “apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́” là ń gbé báyìí. (Míkà 4:1) Torí pé ọ̀pọ̀ ọdún ti kọjá lẹ́yìn 1914, ó dájú pé apá ìgbẹ̀yìn “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” là ń gbé báyìí. Níwọ̀n bí òpin ti sún mọ́lé gan- an, a gbọ́dọ̀ wá ìdáhùn sáwọn ìbéèrè pàtàkì kan: Àwọn nǹkan wo ló máa ṣẹlẹ̀ tí “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” yìí bá dópin? Kí ni Jèhófà sì fẹ́ ká máa ṣe bá a ṣe ń retí àwọn nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀? w19.10 8 ¶1-2
Friday, April 23
Ẹni tó fara dà á dé òpin máa rí ìgbàlà.—Mát. 24:13, àlàyé ìsàlẹ̀.
Nǹkan ò rọrùn fún àwa Kristẹni, Jèhófà ló ń jẹ́ ká lè fara dà á. Tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, á túbọ̀ rọrùn fún wa láti ní ìfaradà. (Róòmù 12:12) Ìlérí tí Jésù ṣe nínú ẹsẹ ojúmọ́ wa tòní fi hàn pé a gbọ́dọ̀ jẹ́ olóòótọ́ láìka àdánwò tó lè dé bá wa. Tá a bá ń fara da àdánwò báyìí, àá túbọ̀ lókun kí ìpọ́njú ńlá tó dé. Bó ṣe jẹ́ pé a gbọ́dọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà ká tó lè ní ìfaradà, ohun kan náà ló máa gbà ká tó lè nígboyà. Kí lá jẹ́ ká túbọ̀ gbára lé Jèhófà? Ká máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́, ká sì máa ṣàṣàrò lórí bí Jèhófà ṣe gba àwọn èèyàn rẹ̀ là nígbà àtijọ́. (Sm. 68:20; 2 Pét. 2:9) Nígbà táwọn orílẹ̀-èdè bá gbéjà kò wá nígbà ìpọ́njú ńlá, ó máa gba pé ká nígboyà ká sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà ju ti ìgbàkigbà rí lọ. (Sm. 112:7, 8; Héb. 13:6) Tó bá ti mọ́ wa lára láti máa gbára lé Jèhófà báyìí, a máa nígboyà láti kojú Gọ́ọ̀gù nígbà tó bá gbéjà kò wá. Jèhófà máa dáàbò bò wá láìka ohun yòówù ká kojú, mìmì kan ò sì ní mì wá.—1 Kọ́r. 13:8. w19.10 18 ¶15-16
Saturday, April 24
Gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.—1 Jòh. 5:19.
Èṣù ló ń darí ayé burúkú yìí, ó sì ń lo àwọn nǹkan tí ọkàn wa sábà máa ń fà sí láti dọdẹ wa. (Éfé. 2:1-3) Ohun tó fẹ́ ni pé ká nífẹ̀ẹ́ àwọn nǹkan míì kí ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà lè dín kù. Lẹ́yìn tí àpọ́sítélì Pétérù sọ̀rọ̀ nípa bí ayé Sátánì yìí ṣe máa dópin àti bí ayé tuntun ṣe máa wọlé wá, ó ní: “Ẹ̀yin ará mi ọ̀wọ́n, bí ẹ ṣe ń retí àwọn nǹkan yìí, ẹ sa gbogbo ipá yín kó lè bá yín nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín láìní èérí àti àbààwọ́n àti ní àlàáfíà.” (2 Pét. 3:14) Tá a bá ń fi ìmọ̀ràn yẹn sílò, tá a sì ń ṣe gbogbo nǹkan tá a lè ṣe láti múnú Jèhófà dùn, a máa fi hàn pé Jèhófà nìkan là ń jọ́sìn. Ojoojúmọ́ ni Sátánì ń wá bó ṣe máa mú káwọn nǹkan míì gba ipò àkọ́kọ́ láyé wa. (Lúùkù 4:13) Àmọ́ ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀, Jèhófà la máa fi sípò àkọ́kọ́, a ò sì ní jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàbí ohunkóhun gba ipò rẹ̀. Torí náà, ẹ jẹ́ ká pinnu pé Jèhófà nìkan làá máa jọ́sìn! w19.10 27 ¶4; 31 ¶18-19
Sunday, April 25
Ẹ̀ṣẹ̀ mi dààmú mi.—Sm. 38:18.
Àwọn àníyàn kan bójú mu, wọ́n sì ṣàǹfààní. Bí àpẹẹrẹ, ó bọ́gbọ́n mu ká ṣàníyàn nípa bá a ṣe máa múnú Jèhófà àti Jésù Ọmọ rẹ̀ dùn. (1 Kọ́r. 7:32) Bákan náà, tá a bá dẹ́ṣẹ̀ tó wúwo, a máa ń ṣàníyàn nípa bá a ṣe máa pa dà ní àjọṣe tó gún régé pẹ̀lú Jèhófà. Yàtọ̀ síyẹn, a máa ń ṣàníyàn nípa bá a ṣe máa múnú ọkọ tàbí aya wa dùn, bá a ṣe máa bójú tó ìdílé wa àti bá a ṣe máa mára tu àwọn ará wa. (1 Kọ́r. 7:33; 2 Kọ́r. 11:28) Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, àníyàn àṣejù lè mú ká máa ṣàníyàn ṣáá nípa bá a ṣe máa rí oúnjẹ tó tó àti aṣọ. (Mát. 6:31, 32) Ìyẹn lè mú ká máa sáré bá a ṣe máa kó ohun ìní rẹpẹtẹ jọ. Tá a bá jẹ́ kírú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí wa, a ò ní fi bẹ́ẹ̀ nígbàgbọ́ nínú Jèhófà mọ́, àárín àwa pẹ̀lú rẹ̀ kò sì ní gún régé mọ́. (Máàkù 4:19; 1 Tím. 6:10) Ó sì lè jẹ́ pé à ń ṣàníyàn nípa bá a ṣe máa rí ojúure àwọn èèyàn. Ìbẹ̀rù pé àwọn èèyàn máa fi wá ṣe yẹ̀yẹ́ tàbí pé wọ́n á ṣenúnibíni sí wa lè mú ká ṣe ohun tí Jèhófà kórìíra. Tá ò bá fẹ́ káwọn nǹkan yìí ṣẹlẹ̀ sí wa, ẹ jẹ́ ká bẹ Jèhófà pé kó fún wa nígbàgbọ́ àti ìgboyà tá a nílò ká lè borí àwọn ìṣòro yìí.—Òwe 29:25; Lúùkù 17:5. w19.11 15 ¶6-7
Monday, April 26
Tí ẹnikẹ́ni nínú yín ò bá ní ọgbọ́n, kó máa béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, ó sì máa fún un, torí ó lawọ́ sí gbogbo èèyàn.—Jém. 1:5.
Àwọn ìpinnu pàtàkì kan wà tá ò ní yí pa dà láé. Bí àpẹẹrẹ, a ti pinnu pé títí láé la máa sin Jèhófà, àwọn tọkọtaya náà sì ti pinnu pé bíná ń jó bíjì ń jà, àwọn ò ní dalẹ̀ ara àwọn. (Mát. 16:24; 19:6) Àmọ́ àwọn ìpinnu míì wà tó lè gba pé ká yí pa dà. Kí nìdí? Ìdí ni pé ipò nǹkan máa ń yí pa dà. Torí náà, kí lá ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu tó dáa jù lọ? Bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ lọ́gbọ́n. Gbogbo wa la nílò “ọgbọ́n.” Torí náà kó o tó ṣèpinnu, bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́, kó o sì tún gbàdúrà tó bá gba pé kó o yí ìpinnu náà pa dà. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà máa mú kó o ṣèpinnu tó bọ́gbọ́n mu. Ṣe ìwádìí tó jinlẹ̀. Wo àwọn ìlànà tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ka àwọn ìtẹ̀jáde ètò Ọlọ́run, kó o sì fọ̀rọ̀ lọ àwọn tó máa gbà ẹ́ nímọ̀ràn tó nítumọ̀. (Òwe 20:18) Ó ṣe pàtàkì kó o ṣe irú ìwádìí yìí kó o tó yí iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ tó ò ń ṣe pa dà, kó o tó kó lọ síbòmíì tàbí kó o tó pinnu irú ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó o máa gbà kó o bàa lè rówó tọ́jú ara rẹ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. w19.11 27 ¶6-8
Tuesday, April 27
Èmi abòṣì èèyàn! Ta ló máa gbà mí lọ́wọ́ ara tó ń kú lọ yìí?—Róòmù 7:24.
A mà dúpẹ́ o pé Jèhófà ti ṣètò láti gbà wá lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀! Jésù sì ni Jèhófà lò láti dá wa sílẹ̀ lómìnira. Ní ohun tó lé lọ́gọ́rùn-ún ọdún méje (700) kí Jésù tó wá sáyé, wòlíì Àìsáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé òmìnira kan máa wáyé lọ́jọ́ iwájú, èyí tó ju òmìnira èyíkéyìí lọ. Ohun tí òmìnira yìí máa ṣàṣeparí ẹ̀ máa ju ti òmìnira táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń gbà lọ́dún Júbílì lọ. Wòlíì náà sọ pé: “Ẹ̀mí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wà lára mi, torí Jèhófà ti yàn mí kí n lè kéde ìhìn rere fún àwọn oníwà pẹ̀lẹ́. Ó rán mi láti di ọgbẹ́ àwọn tó ní ọgbẹ́ ọkàn, láti kéde òmìnira fún àwọn ẹrú.” (Àìsá. 61:1) Ta ló mú àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣẹ? Ìgbà tí Jésù bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ni àsọtẹ́lẹ̀ tí Àìsáyà sọ nípa òmìnira bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ. Nígbà tó lọ sínú sínágọ́gù tó wà ní Násárẹ́tì tó jẹ́ ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀, ó ka àsọtẹ́lẹ̀ Àìsáyà yẹn sétígbọ̀ọ́ àwọn Júù tó wà níbẹ̀. Kódà, Jésù pe àwọn ọ̀rọ̀ inú àsọtẹ́lẹ̀ náà mọ́ ara rẹ̀.—Lúùkù 4:16-19. w19.12 9-10 ¶6-8
Wednesday, April 28
Ọlọ́run wa mú kí a mọ́kàn le kí a lè sọ ìhìn rere Ọlọ́run fún yín lójú ọ̀pọ̀ àtakò.—1 Tẹs. 2:2.
Kó o tó lè kojú inúnibíni láìbọ́hùn, o nílò ìgboyà. Tí ẹ̀rù bá ń bà ẹ́, kí lo lè ṣe? Kì í ṣe béèyàn ṣe tóbi tó, bó ṣe lágbára tó tàbí ẹ̀bùn àbínibí tó ní lá mú kó nígboyà. Rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Dáfídì kojú Gòláyátì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Dáfídì ò ga tó Gòláyátì, kò lágbára, kódà kò ní idà lọ́wọ́. Síbẹ̀, ó nígboyà, ó sì kojú fìrìgbọ̀n náà láìbẹ̀rù. Kí ló mú kí Dáfídì nígboyà? Ó dá a lójú pé Jèhófà wà pẹ̀lú òun. (1 Sám. 17:37, 45-47) Dáfídì ò ronú nípa bí Gòláyátì ṣe tóbi ju òun lọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ronú nípa bí Gòláyátì ṣe kéré ní ìfiwéra pẹ̀lú Jèhófà. Kí la rí kọ́ látinú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí? A máa nígboyà tó bá dá wa lójú pé Jèhófà wà pẹ̀lú wa àti pé àwọn alátakò wa ò ju bíńtín lọ ní ìfiwéra pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run Alágbára ńlá.—2 Kíró. 20:15; Sm. 16:8. w19.07 5 ¶11-13
Thursday, April 29
Àwọn yìí nìkan la jọ ń ṣiṣẹ́ . . . wọ́n sì ti di orísun ìtùnú fún mi gan-an.—Kól. 4:11.
Tíkíkù jẹ́ Kristẹni alábàáṣiṣẹ́ tó ṣeé gbára lé fún àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. (Ìṣe 20:4) Ní nǹkan bí ọdún 55 Sànmánì Kristẹni, Pọ́ọ̀lù ṣètò báwọn Kristẹni tó wà lágbègbè yẹn ṣe máa kówó jọ kí wọ́n sì fi í ránṣẹ́ sáwọn Kristẹni tó wà ní Jùdíà láti dín ìṣòro wọn kù. Ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Tíkíkù ni Pọ́ọ̀lù gbé iṣẹ́ ńlá yẹn fún. (2 Kọ́r. 8:18-20) Ẹ̀yìn ìyẹn ni wọ́n fi Pọ́ọ̀lù sẹ́wọ̀n fúngbà àkọ́kọ́ ní Róòmù, ní gbogbo àsìkò yẹn Tíkíkù wà pẹ̀lú rẹ̀, ó sì ń ràn án lọ́wọ́. Òun náà ló fi àwọn lẹ́tà àti ọ̀rọ̀ ìṣírí tí Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn ìjọ tó wà ní Éṣíà jíṣẹ́. (Kól. 4:7-9) Ọ̀rẹ́ tó ṣeé gbára lé tó sì ṣeé fọkàn tán ni Tíkíkù jẹ́ sí Pọ́ọ̀lù. (Títù 3:12) Àmọ́, kì í ṣe gbogbo àwọn Kristẹni tó wà nígbà yẹn ló dà bíi Tíkíkù. Bí àpẹẹrẹ, ní nǹkan bíi 65 Sànmánì Kristẹni, ìyẹn lásìkò tí Pọ́ọ̀lù ń ṣẹ̀wọ̀n ẹlẹ́ẹ̀kejì nílùú Róòmù, ó sọ pé ńṣe làwọn Kristẹni tó wà lágbègbè Éṣíà pa òun tì, bóyá nítorí ìbẹ̀rù àwọn alátakò. (2 Tím. 1:15) Àmọ́ Tíkíkù ọ̀rẹ́ rẹ̀ kò fi í sílẹ̀, kódà Pọ́ọ̀lù tún gbé iṣẹ́ ńlá míì fún un. (2 Tím. 4:12) Ó dájú pé Pọ́ọ̀lù mọyì Tíkíkù ọ̀rẹ́ rẹ̀ yìí gan-an. w20.01 10 ¶7-8
Friday, April 30
Àwa ni Ọlọ́run ti ṣí wọn payá fún.—1 Kọ́r. 2:10.
Àbí ò ń ronú pé Jèhófà ti yàn ẹ́ láti lọ sọ́run? Tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé Jèhófà ti yàn ẹ́, ronú nípa àwọn ìbéèrè pàtàkì yìí ná: Ṣé kò sí nǹkan míì tó máa ń wù ẹ́ bíi kó o ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́? Ṣó máa ń ṣe ẹ́ bíi pé kò sí iṣẹ́ míì tó o kúndùn bí iṣẹ́ ìwàásù? Ṣé o fẹ́ràn láti máa ka Bíbélì gan-an tó sì máa ń wù ẹ́ láti máa kẹ́kọ̀ọ́ “àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run”? Ṣé ò ń wò ó pé Jèhófà ti mú kó o ṣàṣeyọrí gan-an lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ? Ṣé o nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn dénú tó o sì ń ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè sọ òtítọ́ di tiwọn? Ṣó o ti rí àwọn ọ̀nà pàtó tí Jèhófà ti gbà ràn ẹ́ lọ́wọ́ nígbèésí ayé rẹ? Bí ìdáhùn rẹ bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni sí gbogbo ìbéèrè yìí, ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé Jèhófà ti yàn ẹ́ láti lọ sọ́run? Rárá, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé Jèhófà ti fẹ̀mí yàn ẹ́. Kí nìdí? Ìdí ni pé gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lè dáhùn bẹ́ẹ̀ ni sí gbogbo ìbéèrè yìí. Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, tó o bá ń ṣiyè méjì bóyá o wà lára àwọn tó ń lọ sọ́run, á jẹ́ pé Jèhófà ò tíì yàn ẹ́ nìyẹn. Àwọn tí Jèhófà yàn kì í ṣiyè méjì nípa ẹ̀! Ó dá wọn lójú hán-ún! w20.01 23 ¶14