August
Sunday, August 1
Ẹni tó rán mi wà pẹ̀lú mi; kò pa mí tì.—Jòh. 8:29.
Jésù ní ìbàlẹ̀ ọkàn láìka inúnibíni tí wọ́n ṣe sí i torí ó mọ̀ pé òun ń múnú Baba òun dùn. Ó jẹ́ onígbọràn kódà nígbà tó ṣòro gan-an láti ṣe bẹ́ẹ̀. Bákan náà, Jésù fi gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀ ṣèfẹ́ Jèhófà torí pé ó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an. Kí Jésù tó wá sáyé, òun ni “àgbà òṣìṣẹ́” fún Ọlọ́run. (Òwe 8:30) Nígbà tó sì wà láyé, ó fìtara wàásù nípa Baba rẹ̀ fáwọn míì. (Mát. 6:9; Jòh. 5:17) Ó dájú pé iṣẹ́ yìí fún Jésù láyọ̀ gan-an. (Jòh. 4:34-36) A lè fara wé Jésù tá a bá ń ṣègbọràn sí Jèhófà, tá a sì ń “ní ohun púpọ̀ láti ṣe nínú iṣẹ́ Olúwa nígbà gbogbo.” (1 Kọ́r. 15:58) Tá a bá jẹ́ kí ‘ọwọ́ wa dí gan-an’ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, àwọn ìṣòro wa ò ní gbà wá lọ́kàn ju bó ti yẹ lọ. (Ìṣe 18:5) Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ àwọn tá à ń wàásù fún ló jẹ́ pé ìṣòro wọn ju tiwa lọ. Síbẹ̀, tí wọ́n bá kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí wọ́n ṣe lè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tí wọ́n sì ń fi àwọn ìlànà rẹ̀ sílò, ìgbésí ayé wọn máa ń nítumọ̀, wọ́n sì máa ń láyọ̀. Bá a ṣe ń kíyè sí ayọ̀ tí wọ́n ní, bẹ́ẹ̀ ló túbọ̀ ń dá wa lójú pé Jèhófà máa bójú tó wa, èyí á sì mú kọ́kàn wa balẹ̀. w19.04 10-11 ¶8-9
Monday, August 2
Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ń pidán kó àwọn ìwé wọn jọ, wọ́n sì dáná sun wọ́n níwájú gbogbo èèyàn.—Ìṣe 19:19.
Àwọn tá à ń sọ yìí mọ bó ti ṣe pàtàkì tó pé káwọn yọwọ́yọsẹ̀ nínú ìbẹ́mìílò. Owóbówó làwọn ìwé idán yẹn. Síbẹ̀, ńṣe ni wọ́n dáná sun àwọn ìwé náà, wọn ò fún ẹlòmíì, wọn ò sì tà wọ́n. Bí wọ́n ṣe máa múnú Jèhófà dùn ló jẹ wọ́n lógún, kì í ṣe iye tí wọ́n máa rí ká sọ pé wọ́n ta àwọn ìwé náà. Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní yẹn? Ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé ká kó gbogbo nǹkan tó bá ní í ṣe pẹ̀lú ìbẹ́mìílò jù nù. Lára wọn ni ìfúnpá, bàǹtẹ́, ìgbàdí, àlùwó, ońdè, òkígbẹ́, ìwé idán àtàwọn nǹkan míì táwọn èèyàn máa ń lò láti fi dáàbò bo ara wọn. (1 Kọ́r. 10:21) Fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò irú eré ìnàjú tó ò ń lọ́wọ́ sí. Bi ara rẹ pé: ‘Ṣé àwọn orin tí mò ń gbọ́, àwọn fíìmù àti eré orí tẹlifíṣọ̀n tí mò ń wò, títí kan géèmù tí mò ń gbá kò ní ìbẹ́mìílò nínú?’ Síbẹ̀, nígbàkigbà tó o bá fẹ́ yan eré ìnàjú, rí i dájú pé o yan èyí táá jẹ́ kó o jìnnà pátápátá sóhun tí Jèhófà kórìíra. A gbọ́dọ̀ sa gbogbo ipá wa láti rí i pé ‘ẹ̀rí ọkàn wa mọ́’ níwájú Jèhófà.—Ìṣe 24:16. w19.04 22-23 ¶10-12
Tuesday, August 3
Pe àwọn alàgbà.—Jém. 5:14.
Ọ̀pọ̀ nǹkan làwọn alàgbà máa gbé yẹ̀ wò nígbà tí wọ́n bá gbọ́ pé ẹnì kan dẹ́sẹ̀ tó burú jáì. Ohun tó jẹ wọ́n lógún jù ni bí wọ́n ṣe máa sọ orúkọ Ọlọ́run di mímọ́. (Léf. 22:31, 32; Mát. 6:9) Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n á tún ronú bí wọ́n ṣe lè dáàbò bo àwọn ará nípa tẹ̀mí, kí wọ́n sì ṣèrànwọ́ fún ẹni tí wọ́n hùwà ìkà sí. Láfikún sí i, tí ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì náà bá jẹ́ ará inú ìjọ, àwọn alàgbà á ronú bí wọ́n ṣe lè ràn án lọ́wọ́ kó lè pa dà ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, ìyẹn tó bá ṣeé ṣe. (Jém. 5:14, 15) Ẹni tó gba ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ láyè tó sì dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì ń ṣàìsàn nípa tẹ̀mí. Èyí túmọ̀ sí pé kò ní àjọṣe tó gún régé pẹ̀lú Jèhófà mọ́. Nírú ipò yìí, àwọn alàgbà máa dà bíi dókítà, ní ti pé wọ́n á gbìyànjú láti “mú aláìsàn [ìyẹn ẹni tó hùwà àìtọ́] náà lára dá.” Ìbáwí tí wọ́n bá fún un látinú Ìwé Mímọ́ máa mú kó pa dà ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, ìyẹn tó bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn.—Ìṣe 3:19; 2 Kọ́r. 2:5-10. w19.05 10 ¶10-11
Wednesday, August 4
Ọlọ́run ni ẹni tó ń fún yín lágbára . . . ó ń mú kó wù yín láti gbé ìgbésẹ̀, ó sì ń fún yín ní agbára láti ṣe é.—Fílí. 2:13.
Jèhófà lè mú kó máa wù wá láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀. A lè gbọ́ pé àwọn kan nílò ìrànlọ́wọ́ tàbí kí ohun kan wà tó yẹ ká bójú tó yálà nínú ìjọ tàbí níbòmíì. Nírú ipò yìí, a lè bi ara wa pé, ‘Ṣé mo lè yọ̀ǹda ara mi tàbí àwọn nǹkan wo ni mo lè ṣe láti ṣèrànwọ́?’ Ó sì lè jẹ́ pé wọ́n gbé iṣẹ́ ńlá kan fún wa àmọ́ tá à ń ronú pé a ò ní lè ṣe iṣẹ́ náà. Yàtọ̀ síyẹn, a lè ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan, ká wá máa ronú pé, ‘Báwo ni mo ṣe lè fi ibi tí mo kà yìí ran àwọn míì lọ́wọ́?’ Tí Jèhófà bá kíyè sí i pé à ń ronú bá a ṣe lè ṣe púpọ̀ sí i, á mú kó máa wù wá láti ṣe ohun tó wà lọ́kàn wa, á sì fún wa lágbára láti ṣe é. Jèhófà máa ń fún wa ní agbára láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀. (Àìsá. 40:29) Ó lè fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ láti mú kí ẹ̀bùn àbínibí wa túbọ̀ wúlò. (Ẹ́kís. 35:30-35) Jèhófà tún lè lo ètò rẹ̀ láti dá wa lẹ́kọ̀ọ́ ká bàa lè ṣe iṣẹ́ rẹ̀ láṣeyanjú. Torí náà, tó o bá ń ṣiyèméjì pé bóyá ni wàá lè ṣe iṣẹ́ tí wọ́n gbé fún ẹ, sọ pé káwọn míì ràn ẹ́ lọ́wọ́. Bákan náà, o lè bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ ní “agbára tó kọjá ti ẹ̀dá,” torí pé ọ̀làwọ́ ni Jèhófà Baba wa ọ̀run.—2 Kọ́r. 4:7; Lúùkù 11:13. w19.10 21 ¶3-4
Thursday, August 5
Àwọn èèyàn máa nífẹ̀ẹ́ ara wọn nìkan.—2 Tím. 3:2.
Kò yani lẹ́nu pé ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan layé ń gbé lárugẹ. Ìwé ìwádìí kan sọ pé láwọn ọdún 1970, “àwọn ìwé tó dá lórí béèyàn ṣe lè yọrí ọlá ló kún ìgboro.” Àwọn ìwé kan tiẹ̀ “gba àwọn tó ń kà á níyànjú pé kò yẹ kí wọ́n yí irú ẹni tí wọ́n jẹ́ pa dà bíi pé ìwà wọn ò dáa, pé àfi káwọn èèyàn gbà wọ́n bí wọ́n ṣe rí.” Bí àpẹẹrẹ, ọ̀kan lára àwọn ìwé yẹn sọ pé: “Nífẹ̀ẹ́ ara ẹ, torí pé kò sí ẹlòmíì tó rẹwà tó sì dáa tó ẹ.” Ohun tí ìwé náà ń gbé lárugẹ ni pé “ohunkóhun tó bá wù ẹ́, tó tọ́ lójú ẹ, tó sì bá ẹ lára mu ni kó o máa ṣe.” Ṣé o rántí pé ohun tó jọ bẹ́ẹ̀ ni Sátánì sọ fún Éfà lọ́jọ́ kìíní àná. Ó sọ fún un pé, ó lè ‘dà bí Ọlọ́run, ó sì máa mọ rere àti búburú.’ (Jẹ́n. 3:5) Lónìí, ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń ro ara wọn ju bó ti yẹ lọ, wọ́n gbà pé kò sẹ́ni tó lè pinnu ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́ fáwọn, kódà wọn ò ka ìlànà Ọlọ́run sí rárá. Irú èrò yìí hàn kedere nínú ojú táwọn èèyàn fi ń wo ìgbéyàwó. w19.05 23 ¶10-11
Friday, August 6
Ìdààmú àti ìrẹ̀wẹ̀sì tó lé kenkà bá mi; mò ń rìn kiri nínú ìbànújẹ́ láti àárọ̀ ṣúlẹ̀.—Sm. 38:6.
Àwọn ìgbà kan wà tí Ọba Dáfídì náà ní ìdààmú ọkàn. Ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ lára àwọn ohun tó kó ìdààmú ọkàn bá a. Àkọ́kọ́, ìrẹ̀wẹ̀sì bá a torí àwọn àṣìṣe tó ṣe. (Sm. 40:12) Yàtọ̀ síyẹn, Ábúsálómù ọmọ rẹ̀ ṣọ̀tẹ̀ sí i, ohun tó sì fa ikú Ábúsálómù nìyẹn. (2 Sám. 15:13, 14; 18:33) Kò tán síbẹ̀ o, ọ̀kan lára àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́ dalẹ̀ rẹ̀. (2 Sám. 16:23–17:2; Sm. 55:12-14) Ọ̀pọ̀ lára àwọn sáàmù tí Dáfídì kọ jẹ́ ká rí bí ìrẹ̀wẹ̀sì ṣe bò ó mọ́lẹ̀, síbẹ̀ ó tún jẹ́ ká rí bó ṣe fi gbogbo ọkàn rẹ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. (Sm. 38:5-10; 94:17-19) Láwọn ọdún mélòó kan lẹ́yìn náà, onísáàmù kan bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìlara àwọn èèyàn burúkú. Ó ṣeé ṣe kí onísáàmù yìí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àtọmọdọ́mọ Ásáfù tó wá látinú ẹ̀yà Léfì, tó sì ṣiṣẹ́ sìn nínú “ibi mímọ́ títóbi lọ́lá ti Ọlọ́run.” Bí onísáàmù yìí ṣe rí i tí àwọn ẹni burúkú ń gbádùn tí wọ́n sì wà ní àlàáfíà mú kí nǹkan sú u débi pé kò láyọ̀ mọ́. Kódà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiyèméjì pé bóyá ni èrè wà nínú bóun ṣe ń sin Ọlọ́run.—Sm. 73:2-5, 7, 12-14, 16, 17, 21. w19.06 17 ¶12-13
Saturday, August 7
A mọ àwọn ọgbọ́n [Sátánì].—2 Kọ́r. 2:11.
Sátánì máa ń fi ohun tó wù wá dẹkùn mú wa. Ó máa ń wù wá pé ká níṣẹ́ lọ́wọ́ ká lè pèsè fún ìdílé wa. (1 Tím. 5:8) Lọ́pọ̀ ìgbà, ìyẹn lè gba pé ká lọ sílé ìwé, ká sì fojú sí ẹ̀kọ́ wa dáadáa. Àmọ́ a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra. Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, kì í ṣe iṣẹ́ nìkan ni wọ́n máa ń kọ́ àwọn ọmọ iléèwé, wọ́n tún máa ń kọ́ wọn ní ọgbọ́n orí èèyàn. Wọ́n máa ń sọ fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ pé kò sí Ọlọ́run àti pé ìtàn àròsọ lásán ló wà nínú Bíbélì. Wọ́n tún máa ń kọ́ wọn pé ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n nìkan ni àlàyé tó bọ́gbọ́n mu nípa ibi táwa èèyàn ti wá. (Róòmù 1:21-23) Kò sí àní-àní pé irú àwọn ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ ta ko “ọgbọ́n Ọlọ́run.” (1 Kọ́r. 1:19-21; 3:18-20) Pinnu pé o ò ní jẹ́ kí ayé Sátánì fi “ọgbọ́n orí àti ìtànjẹ lásán” mú ẹ lẹ́rú. (Kól. 2:8) Máa wà lójúfò nígbà gbogbo kí Sátánì má bàa fi ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ rẹ̀ tàn ẹ́ jẹ. (1 Kọ́r. 3:18) Ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe kí Sátánì má bàa mú kó o gbàgbé Jèhófà, kó o sì pinnu pé wàá máa fi àwọn ìlànà Jèhófà sílò lójoojúmọ́. Yàtọ̀ síyẹn, má ṣe jẹ́ kí Sátánì mú kó o ronú pé àwọn ìmọ̀ràn Jèhófà ò wúlò fún ẹ. w19.06 5 ¶13; 7 ¶17
Sunday, August 8
Ẹ máa kọ́ wọn pé kí wọ́n máa pa gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún yín mọ́.—Mát. 28:20.
Ohun yòówù kó o ní lọ́kàn láti bá wọn sọ, á dáa kó o ronú nípa àwọn tó o fẹ́ bá sọ̀rọ̀. Ronú nípa bí wọ́n ṣe máa jàǹfààní látinú ọ̀rọ̀ Bíbélì tó o fẹ́ bá wọn sọ. Tẹ́ ẹ bá ń sọ̀rọ̀, rí i dájú pé o tẹ́tí sí wọn dáadáa, kó o sì bọ̀wọ̀ fún wọn kódà tí èrò wọn bá yàtọ̀ sí tìẹ. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá lóye ohun tí wọ́n ń sọ, àwọn náà á sì fara balẹ̀ tẹ́tí sí ẹ. Nígbà míì, ó máa ń gba ọ̀pọ̀ ìsapá àti àkókò láti ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ ẹnì kan kó tó lè gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kí nìdí? Ìdí ni pé a lè má bá àwọn míì nílé tàbí kí wọ́n má ráyè tá a bá pa dà sọ́dọ̀ wọn. Yàtọ̀ síyẹn, ó lè gba pé kó o lọ lọ́pọ̀ ìgbà kí ọkàn ẹni náà tó balẹ̀ pẹ̀lú rẹ, débi táá fi gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Máa rántí pé, kí irúgbìn tó hù dáadáa, a gbọ́dọ̀ máa bomi rin ín déédéé. Bákan náà, ìfẹ́ tí ẹnì kan ní sí Jèhófà àti Jésù máa pọ̀ sí i tá a bá ń bá a sọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé. w19.07 14 ¶1; 15-16 ¶7-8
Monday, August 9
Aláyọ̀ ni yín nígbàkigbà tí àwọn èèyàn bá kórìíra yín àti nígbàkigbà tí wọ́n bá ta yín nù, tí wọ́n pẹ̀gàn yín, tí wọ́n sì fẹ̀sùn kàn yín pé ẹni burúkú ni yín nítorí Ọmọ èèyàn.—Lúùkù 6:22.
Kí nìdí tí Jésù fi sọ bẹ́ẹ̀? Jésù ò sọ pé inú àwa Kristẹni máa ń dùn táwọn èèyàn bá kórìíra wa. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló ń kìlọ̀ fún wa. Ó jẹ́ ká mọ̀ pé ayé máa kórìíra wa torí pé a kì í ṣe apá kan ayé. Yàtọ̀ síyẹn, à ń wàásù ìhìn rere kan náà tí Jésù wàásù, ìlànà tó sì fi kọ́ni là ń tẹ̀ lé. (Jòh. 15:18-21) A fẹ́ múnú Jèhófà dùn, táwọn èèyàn bá wá tìtorí ìyẹn kórìíra wa, wàhálà tiwọn nìyẹn. Kì í ṣe báwọn èèyàn ṣe gba tiwa tó ló ń pinnu bá a ṣe níyì tó. Ìgbàkigbà ni inúnibíni lè bẹ̀rẹ̀, a ò sì mọ̀gbà tí ìjọba máa fòfin de iṣẹ́ wa. Síbẹ̀, a mọ̀ pé a lè múra sílẹ̀ nísinsìnyí tá a bá mú kí àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà túbọ̀ lágbára, tá a túbọ̀ nígboyà, tá a sì mọ ohun tó yẹ ká ṣe táwọn èèyàn bá kórìíra wa. Tá a bá múra sílẹ̀ nísinsìnyí, àá lè dúró gbọin-in nígbà tí àtakò bá dé lọ́jọ́ iwájú. w19.07 6 ¶17-18; 7 ¶21
Tuesday, August 10
Ẹnikẹ́ni tó bá ń tọ Ọlọ́run wá gbọ́dọ̀ gbà gbọ́ pé ó wà.—Héb. 11:6.
Tá a bá ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú àwọn tí kò ṣe ẹ̀sìn kankan tàbí tí wọn ò gbà pé Ọlọ́run wà, a gbọ́dọ̀ máa jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wọn nínú Ọlọ́run túbọ̀ lágbára. Ó sì yẹ ká tún ràn wọ́n lọ́wọ́ láti fọkàn tán Bíbélì. Èyí lè gba pé ká sọ àwọn kókó kan ní àsọtúnsọ. Ní gbogbo ìgbà tá a bá ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́, ó lè gba pé ká tún jíròrò àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì. A lè tọ́ka sí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tó ti nímùúṣẹ, àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé Bíbélì bá ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì mu àtàwọn ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n tó wà nínú Bíbélì. A lè mú káwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn Kristi tá a bá ń fìfẹ́ hàn sí wọn, yálà wọ́n jẹ́ onísìn tàbí wọn ò tiẹ̀ ṣe ẹ̀sìn kankan. (1 Kọ́r. 13:1) Bá a ṣe ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́, àfojúsùn wa ni pé kí wọ́n mọ̀ pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wọn, ó sì fẹ́ káwọn náà nífẹ̀ẹ́ òun. Ọdọọdún ni ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀sìn máa ń kẹ́kọ̀ọ́, wọ́n ń ṣèrìbọmi, wọ́n sì ń dẹni tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Torí náà, gbà pé wọ́n lè yí pa dà, fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ wọn láìka ibi tí wọ́n ti wá sí. Máa tẹ́tí sí wọn kó o sì gbìyànjú láti lóye wọn. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wàá lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti di ọmọ ẹ̀yìn Kristi. w19.07 24 ¶16-17
Wednesday, August 11
Ẹ má gbàgbé láti máa ṣe rere, kí ẹ sì máa pín ohun tí ẹ ní pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì, torí inú Ọlọ́run máa ń dùn gan-an sí irú àwọn ẹbọ bẹ́ẹ̀.—Héb. 13:16.
Nígbà tí wọ́n fẹ́ tún ògiri Jerúsálẹ́mù kọ́, àwọn ọmọbìnrin Ṣálúmù wà lára àwọn tí Jèhófà lò fún iṣẹ́ náà. (Neh. 2:20; 3:12) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé olórí ni bàbá wọn, àwọn ọmọbìnrin Ṣálúmù ṣe tán láti ṣe iṣẹ́ tó lágbára tó sì léwu yẹn. (Neh. 4:15-18) Bó ṣe rí lónìí náà nìyẹn, inú àwọn arábìnrin tó yọ̀ǹda ara wọn máa ń dùn láti ṣe àwọn àkànṣe iṣẹ́ kan. Lára ẹ̀ ni pé wọ́n máa ń kọ́ àwọn ilé tí ètò Ọlọ́run ń lò, wọ́n sì máa ń tún wọn ṣe. Irú àwọn arábìnrin tó mọṣẹ́, tí wọ́n nítara, tí wọ́n sì jẹ́ adúróṣinṣin yìí ń mú kí iṣẹ́ náà máa tẹ̀ síwájú. Jèhófà mú kí “àwọn iṣẹ́ rere àti ọrẹ àánú” tí Tàbítà ń ṣe pọ̀ gidigidi pàápàá fáwọn opó. (Ìṣe 9:36) Ọ̀pọ̀ ló ṣọ̀fọ̀ rẹ̀ nígbà tó kú torí pé ọ̀làwọ́ ni, ó sì lójú àánú. Àmọ́, ìdùnnú ṣubú layọ̀ wọn nígbà tí àpọ́sítélì Pétérù jí i dìde. (Ìṣe 9:39-41) Kí la rí kọ́ lára Tàbítà? Yálà ọmọdé ni wá tàbí àgbàlagbà, ọkùnrin tàbí obìnrin, ọ̀pọ̀ nǹkan la lè ṣe láti ran àwọn ará wa lọ́wọ́ bó ti wù kó kéré tó. w19.10 23 ¶11-12
Thursday, August 12
Ẹ . . . máa wádìí dájú àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù, kí ẹ lè jẹ́ aláìní àbààwọ́n, kí ẹ má sì máa mú àwọn ẹlòmíì kọsẹ̀.—Fílí. 1:10.
Báwo la ṣe lè mú káwọn míì kọsẹ̀? Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ yìí. Ó pẹ́ tí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan ti ń sapá kó lè jáwọ́ nínú ọtí àmujù, nígbà tó yá ó ṣe bẹ́ẹ̀. Ó pinnu pé òun ò ní fẹnu kan ọtí mọ́ ó sì ṣèrìbọmi. Lọ́jọ́ kan, arákùnrin kan kó àwọn ará lẹ́nu jọ, ó sì pe ẹni tuntun náà síbẹ̀. Arákùnrin yẹn wá ń rọ ẹni tuntun náà pé kó mutí, ó ní: “Kò ní ṣòro fún ẹ láti kó ara ẹ níjàánu. Kó o kàn mu díẹ̀ ni, ló bá tán, wàá gbádùn ara ẹ, kò jù bẹ́ẹ̀ lọ.” Ẹ wo ohun tíyẹn lè fà fún arákùnrin tuntun náà tó bá fetí sí ìmọ̀ràn burúkú yẹn! Àwọn ìpàdé wa ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè fi ìtọ́ni inú ẹsẹ ojúmọ́ wa tòní sílò. Àwọn oúnjẹ tẹ̀mí tó dọ́ṣọ̀ tá à ń rí gbà ń rán wa létí àwọn nǹkan tí Jèhófà kà sí pàtàkì jù àti bá a ṣe lè máa fi ohun tá à ń kọ́ sílò ká bàa lè jẹ́ aláìní àbààwọ́n. Wọ́n tún ń fún wa níṣìírí láti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àtàwọn ará wa. Tá a bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àtàwọn ará wa látọkàn wá, àá ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká má bàa mú ẹnikẹ́ni kọsẹ̀. w19.08 10 ¶9; 11 ¶13-14
Friday, August 13
Èmi ló kéré jù nínú àwọn àpọ́sítélì, mi ò sì yẹ lẹ́ni tí à ń pè ní àpọ́sítélì, torí mo ṣe inúnibíni sí ìjọ Ọlọ́run.—1 Kọ́r. 15:9.
Ti pé ẹnì kan máa ń sọ bí nǹkan ṣe rí lára ẹ̀, tó sì máa ń sojú abẹ níkòó kò túmọ̀ sí pé ó gbéra ga. (Jòh. 1:46, 47) Síbẹ̀, yálà a máa ń sọ bí nǹkan ṣe rí lára wa tàbí a jẹ́ onítìjú èèyàn, gbogbo wa gbọ́dọ̀ sapá láti lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Jèhófà lo Pọ́ọ̀lù gan-an lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀, débi pé ṣe ló ń dá ìjọ sílẹ̀ láti ìlú kan dé òmíì. Ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn nǹkan tó gbéṣe ju tàwọn àpọ́sítélì tó kù lọ. Síbẹ̀, Pọ́ọ̀lù ò gbéra ga kò sì ronú pé òun sàn ju àwọn tó kù lọ. Ó jẹ́ kó ṣe kedere pé inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí Ọlọ́run fi hàn sóun ló mú kóun ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú rẹ̀, kì í ṣe mímọ̀-ọ́n-ṣe òun. (1 Kọ́r. 15:10) Ẹ wo bí Pọ́ọ̀lù ṣe fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ hàn nínú lẹ́tà tó kọ sáwọn ará Kọ́ríńtì. Àpẹẹrẹ àtàtà lèyí jẹ́ torí pé inú ìjọ yẹn kan náà làwọn kan ti ń gbéra ga bíi pé wọ́n sàn ju Pọ́ọ̀lù lọ.—2 Kọ́r. 10:10. w19.09 3 ¶5-6
Saturday, August 14
Ṣé kò wá yẹ kó yá wa lára láti fi ara wa sábẹ́ Baba?—Héb. 12:9.
Ìdí kan tó fi máa ń ṣòro fún wa láti fi ara wa sábẹ́ Jèhófà ni pé a ti jogún ẹ̀ṣẹ̀, aláìpé sì ni wá. Torí náà, kì í fìgbà gbogbo wù wá pé ká ṣègbọràn. Ádámù àti Éfà ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà nígbà tí wọ́n jẹ èso tó ní kí wọ́n má jẹ, èyí sì fi hàn pé tinú wọn ni wọ́n ṣe. (Jẹ́n. 3:22) Bó ṣe rí lónìí náà nìyẹn, ọ̀pọ̀ kì í ka òfin Jèhófà sí torí pé tinú wọn ni wọ́n máa ń fẹ́ ṣe. Kódà kì í rọrùn fáwọn tó mọ Jèhófà tó sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ láti máa ṣègbọràn sí i nígbà gbogbo. Bó ṣe rí fún àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà nìyẹn. (Róòmù 7:21-23) Bíi ti Pọ́ọ̀lù, àwa náà fẹ́ ṣe ohun táá múnú Jèhófà dùn bí kò tiẹ̀ rọrùn. Torí náà, a gbọ́dọ̀ máa sapá nígbà gbogbo láti borí èrò tó lè mú ká ṣe ohun tí kò tọ́. Ohun míì tó lè mú kó ṣòro láti fi ara wa sábẹ́ Jèhófà ni àṣà ìbílẹ̀ wa tàbí ibi tá a gbé dàgbà. Ọ̀pọ̀ nǹkan làwọn èèyàn ń sọ tí wọ́n sì ń ṣe tí kò bá ìlànà Jèhófà mu, kì í sì í rọrùn láti jáwọ́ nínú àwọn àṣà bẹ́ẹ̀. w19.09 15 ¶4-6
Sunday, August 15
Lọ, kí o ta àwọn ohun tí o ní, kí o fún àwọn aláìní, . . . kí o wá máa tẹ̀ lé mi.—Máàkù 10:21.
Ohun kan wà tó yẹ ká fi sọ́kàn. Ohun náà sì ni pé ó níbi tí agbára wa mọ. Torí náà, kò yẹ ká máa ṣe ju agbára wa lọ. Bí àpẹẹrẹ, tá ò bá ṣọ́ra, a lè máa ṣe kìràkìtà nídìí mo fẹ́ dogún mo fẹ́ dọgbọ̀n. Àmọ́ ẹ kíyè sí ohun tí Jésù sọ fún ọ̀dọ́kùnrin ọlọ́rọ̀ kan tó bi í pé: “Kí ni mo gbọ́dọ̀ ṣe kí n lè jogún ìyè àìnípẹ̀kun?” Ọ̀dọ́kùnrin yẹn máa ń pa Òfin Ọlọ́run mọ́. Ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kó jẹ́ èèyàn dáadáa torí pé Ìhìn Rere Máàkù dìídì sọ pé Jésù “nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.” Jésù wá sọ ohun tó máa ṣe kó lè di ọmọ ẹ̀yìn òun. Ó wu ọkùnrin náà pé kó tẹ̀ lé Jésù àmọ́ kò lè ṣe bẹ́ẹ̀ torí “ohun ìní rẹ̀ pọ̀” gan-an. (Máàkù 10:17-22) Bí ò ṣe gba àjàgà Jésù nìyẹn o, tó sì ń bá a lọ láti sìnrú fún “Ọrọ̀.” (Mát. 6:24) Tó bá jẹ́ ìwọ ni, kí lò bá ṣe? Látìgbàdégbà, ó yẹ ká máa yẹ ara wa wò bóyá ohun tó tọ́ la fi sípò àkọ́kọ́ láyé wa. Kí nìdí? Ká lè rí i dájú pé à ń lo okun wa bó ṣe tọ́. w19.09 24 ¶17-18
Monday, August 16
A ní láti kọ́kọ́ wàásù ìhìn rere náà ní gbogbo orílẹ̀-èdè.—Máàkù 13:10.
Àá ṣì máa bá iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run yìí nìṣó títí dìgbà tí Jèhófà fúnra ẹ̀ bá sọ pé ó ti tó. Báwo ni àsìkò táwọn èèyàn ní láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà àti Jésù Kristi ṣe máa pẹ́ tó? (Jòh. 17:3) A ò mọ̀. Ohun kan tó dá wa lójú ni pé “àwọn olóòótọ́ ọkàn tí wọ́n ń fẹ́ ìyè àìnípẹ̀kun” ṣì láǹfààní láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ kí wọ́n sì di ìránṣẹ́ Jèhófà, torí pé tí ìpọ́njú ńlá bá ti bẹ̀rẹ̀, ẹ̀pa ò ní bóró mọ́. (Ìṣe 13:48) Báwo la ṣe lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kó tó pẹ́ jù? Nípasẹ̀ ètò rẹ̀, Jèhófà ń fún wa ní gbogbo nǹkan tá a nílò ká lè kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n máa ń dá wa lẹ́kọ̀ọ́ láwọn ìpàdé àárín ọ̀sẹ̀. Nínú ìpàdé yẹn, wọ́n ń kọ́ wa lóhun tá a máa bá àwọn èèyàn sọ nígbà àkọ́kọ́ àti nígbà ìpadàbẹ̀wò. Tí ẹnì kan bá nífẹ̀ẹ́ sọ́rọ̀ ẹ, o lè fún un ní ìwé àṣàrò kúkúrú tàbí ìwé ìròyìn kan. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, á lè rí ohun táá máa kà kó o tó tún pa dà sọ́dọ̀ rẹ̀. Torí náà, ojúṣe ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ni láti rí i pé à ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run déédéé. w19.10 9 ¶7; 10 ¶9-10
Tuesday, August 17
Ẹ má gbàgbé láti máa ṣe rere, kí ẹ sì máa pín ohun tí ẹ ní pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì, torí inú Ọlọ́run máa ń dùn gan-an sí irú àwọn ẹbọ bẹ́ẹ̀.—Héb. 13:16.
Jèhófà ṣèlérí fún Síméónì, ọkùnrin àgbàlagbà kan ní Jerúsálẹ́mù pé kò ní kú kí Mèsáyà tó dé, á sì fojú ara rẹ̀ rí i. Ìlérí yẹn fún Síméónì níṣìírí gan-an torí pé ọjọ́ pẹ́ tí ọkùnrin olóòótọ́ yìí ti ń dúró de Mèsáyà náà. Jèhófà sì san án lẹ́san torí ìgbàgbọ́ àti ìfaradà rẹ̀. Lọ́jọ́ kan “ẹ̀mí darí rẹ̀,” ó sì wá sínú tẹ́ńpìlì. Nígbà tó débẹ̀, ó rí Jésù ọmọ jòjòló, Jèhófà sì mú kí Síméónì sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ọmọ tó máa di Kristi náà. (Lúùkù 2:25-35) Kò dájú pé Síméónì pẹ́ láyé débi táá fi rí bí Jésù ṣe ṣiṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, síbẹ̀ ó mọyì àǹfààní tí Jèhófà fún un. Àmọ́ o, kékeré nìyẹn lára ìbùkún tó ṣì máa rí gbà! Ìdí ni pé nínú ayé tuntun, á rí bí Jésù ṣe máa rọ̀jò ìbùkún sórí aráyé nígbà ìṣàkóso rẹ̀. (Jẹ́n. 22:18) Ó yẹ káwa náà mọrírì àǹfààní iṣẹ́ ìsìn èyíkéyìí tí Jèhófà bá fún wa nínú ètò rẹ̀. w19.10 22 ¶7; 23 ¶12
Wednesday, August 18
Ju gbogbo ohun mìíràn tí ò ń dáàbò bò, dáàbò bo ọkàn rẹ.—Òwe 4:23.
Yálà a jẹ́ olówó tàbí a ò fi bẹ́ẹ̀ ní lọ́wọ́, gbogbo wa pátá la gbọ́dọ̀ dáàbò bo ọkàn wa. Báwo la ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀? Má ṣe jẹ́ kí ìfẹ́ owó gbà ẹ́ lọ́kàn. Má sì jẹ́ kí iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ gba ipò àkọ́kọ́ láyé rẹ, kí ìjọsìn Jèhófà wá gba ipò kejì. Báwo lo ṣe lè mọ̀ tírú ẹ̀ bá ti ń ṣẹlẹ̀ sí ẹ? O lè bi ara ẹ pé: ‘Ṣé ọ̀rọ̀ iṣẹ́ mi ni mo máa ń rò tí mo bá wà nípàdé tàbí lóde ẹ̀rí? Ṣé ọ̀rọ̀ bí màá ṣe rówó tó pọ̀ kó jọ kí n má bàa jìyà lọ́jọ́ ọ̀la ló máa ń gbà mí lọ́kàn? Ṣé owó àti nǹkan ìní máa ń fa wàhálà láàárín èmi àti ìyàwó tàbí ọkọ mi? Ṣé mo lè ṣe iṣẹ́ tó máa fún mi láyè láti sin Jèhófà tí kò bá tiẹ̀ gbayì?’ (1 Tím. 6:9-12) Bó o ṣe ń ronú lórí àwọn ìbéèrè yìí, fi sọ́kàn pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ rẹ, ó sì ti ṣèlérí fún gbogbo ẹni tó bá ń sìn ín tọkàntọkàn pé: “Mi ò ní fi ọ́ sílẹ̀ láé, mi ò sì ní pa ọ́ tì láé.” Ìdí nìyẹn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi kìlọ̀ pé: “Ẹ yẹra fún ìfẹ́ owó nínú ìgbésí ayé yín.”—Héb. 13:5, 6. w19.10 29 ¶10
Thursday, August 19
Bí irin ṣe ń pọ́n irin, bẹ́ẹ̀ ni èèyàn ṣe ń pọ́n ọ̀rẹ́ rẹ̀.—Òwe 27:17.
Tá a bá ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ará wa, a máa rí àwọn ànímọ́ tó dáa tí wọ́n ní, ìyẹn á mú ká kẹ́kọ̀ọ́ lára wọn, ká sì túbọ̀ sún mọ́ wọn. Bí àpẹẹrẹ, báwo ló ṣe máa ń rí lára rẹ tó o bá wà lóde ẹ̀rí, tó o sì rí bí ọ̀rẹ́ rẹ kan ṣe ń fi ìgboyà sọ ohun tó gbà gbọ́ tàbí tó ń sọ̀rọ̀ látọkàn wá nípa Jèhófà àtohun tó fẹ́ ṣe fáráyé? Ó ṣeé ṣe kíyẹn mú kó o túbọ̀ sún mọ́ ọn, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Arábìnrin Adeline tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàlélógún (23) sọ fún Candice ọ̀rẹ́ rẹ̀ pé káwọn jọ lọ sí ìpínlẹ̀ ìwàásù tí a kì í ṣe déédéé. Ó ní: “A fẹ́ kí ìtara wa lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù pọ̀ sí i, ká sì túbọ̀ gbádùn òde ẹ̀rí. A gbà pé ìyẹn máa jẹ́ ká lè ṣe púpọ̀ sí i.” Àwọn àǹfààní wo ni wọ́n rí bí wọ́n ṣe jọ ṣiṣẹ́? Adeline sọ pé: “Lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan tá a bá ti parí iṣẹ́, gbogbo nǹkan tó wà lọ́kàn wa la máa ń sọ fún ara wa, títí kan ohun tó wọ̀ wá lọ́kàn jù lọ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù lọ́jọ́ yẹn. A sì tún máa ń sọ bá a ṣe rí ọwọ́ Jèhófà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wa. Àwa méjèèjì máa ń gbádùn ìjíròrò yẹn gan-an, ó sì ti jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ra ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.” w19.11 5 ¶10-11
Friday, August 20
Ẹ gbé apata ńlá ti ìgbàgbọ́.—Éfé. 6:16.
Láyé àtijọ́, ìtìjú ńlá ló máa jẹ́ fún ọmọ ogun tó bá sọ apata rẹ̀ nù sójú ogun. Kódà, òpìtàn ará Róòmù kan tó ń jẹ́ Tacitus sọ pé: “Kò sí ohun tó tini lójú tó pé kí ọmọ ogun kan sọ apata rẹ̀ nù sójú ogun.” Ìdí nìyẹn táwọn ọmọ ogun fi máa ń rí i dájú pé àwọn di apata àwọn mú dáadáa. Tá ò bá fẹ́ kí apata ìgbàgbọ́ wa bọ́ mọ́ wa lọ́wọ́, a gbọ́dọ̀ máa lọ sípàdé déédéé, ká sì máa sọ̀rọ̀ Jèhófà àti Ìjọba rẹ̀ fáwọn míì. (Héb. 10:23-25) Yàtọ̀ síyẹn, a tún gbọ́dọ̀ máa ka Bíbélì lójoojúmọ́, ká sì máa gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ràn wá lọ́wọ́ ká lè fi àwọn ìtọ́ni rẹ̀ sílò nígbèésí ayé wa. (2 Tím. 3:16, 17) Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ó dájú pé kò sí ohun ìjà Sátánì tó máa lè ba àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Jèhófà jẹ́. (Àìsá. 54:17) “Apata ńlá ti ìgbàgbọ́” wa máa dáàbò bò wá. Àwa àtàwọn ará wa máa dúró gbọin, a ò sì ní bẹ̀rù. Yàtọ̀ sí pé a máa borí ogun tẹ̀mí tá à ń jà lójoojúmọ́, inú wa máa dùn, ohun iyì ló sì máa jẹ́ pé ọ̀dọ̀ Jésù la wà nígbà tó bá ṣẹ́gun Sátánì àtàwọn alátìlẹ́yìn rẹ̀.—Ìfi. 17:14; 20:10. w19.11 19 ¶18-19
Saturday, August 21
Mi ò . . . ju ẹ̀ṣẹ́ mi kí n lè máa gbá afẹ́fẹ́.—1 Kọ́r. 9:26.
Tó o bá kọ ohun tó o fẹ́ ṣe àti bó o ṣe fẹ́ ṣe é sílẹ̀, á rọrùn fún ẹ láti parí ohun tó o dáwọ́ lé. (1 Kọ́r. 14:40) Bí àpẹẹrẹ, ètò Ọlọ́run ti sọ fáwọn alàgbà pé kí wọ́n yan ẹnì kan láàárín wọn táá máa kọ gbogbo ìpinnu tí wọ́n bá ṣe sílẹ̀, á sì tún kọ orúkọ àwọn tó máa ṣe iṣẹ́ náà àtìgbà tó yẹ kí wọ́n parí ẹ̀. Táwọn alàgbà bá ń tẹ̀ lé ìtọ́ni yìí, á rọrùn fún wọn láti parí gbogbo ohun tí wọ́n bá dáwọ́ lé. Ìwọ náà lè ṣe ohun tó jọ bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, o lè kọ àwọn nǹkan tó o fẹ́ ṣe lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan sílẹ̀ àti bó o ṣe máa ṣe é ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wàá máa parí àwọn nǹkan tó o dáwọ́ lé lásìkò. Àmọ́, o ò gbọ́dọ̀ ṣọ̀lẹ. Èèyàn gbọ́dọ̀ sapá kó tó lè parí ohun tó dáwọ́ lé. (Róòmù 12:11) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fún Tímótì pé kó “tẹra mọ́” àwọn ohun táá jẹ́ kó túbọ̀ já fáfá bó ṣe ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́, kó sì ‘rí i pé òun ò jáwọ́.’ Gbogbo wa pátá la lè fi ìlànà yẹn sílò lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wa sí Jèhófà.—1 Tím. 4:13, 16. w19.11 29-30 ¶15-16
Sunday, August 22
Jèhófà bá Mósè sọ̀rọ̀ ní ojúkojú, bí ìgbà téèyàn méjì ń bá ara wọn sọ̀rọ̀.—Ẹ́kís. 33:11.
Nígbà tí Jèhófà yan Mósè pé kó kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò lóko ẹrú ní Íjíbítì, kò gbà pé òun á lè ṣe iṣẹ́ náà, kódà léraléra ló sọ fún Jèhófà pé ẹ̀mí òun ò gbé e. Ọlọ́run fi àánú hàn sí Mósè, ó sì ràn án lọ́wọ́. (Ẹ́kís. 4:10-16) Ohun tí Jèhófà ṣe yẹn mú kí Mósè nígboyà láti kéde ìdájọ́ Jèhófà fún Fáráò. Mósè wá rí bí Jèhófà ṣe lo agbára rẹ̀ láti dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nídè tó sì pa Fáráò àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ nínú Òkun Pupa. (Ẹ́kís. 14:26-31; Sm. 136:15) Lẹ́yìn táwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò lóko ẹrú, ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n máa ń ráhùn. Dípò kí Jèhófà bínú, Mósè rí i pé ṣe ni Jèhófà mú sùúrù fáwọn èèyàn rẹ̀ tó dá nídè. (Sm. 78:40-43) Yàtọ̀ síyẹn, Mósè kíyè sí ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tí kò láfiwé tí Jèhófà lò nígbà tó gbà láti ṣe ohun tí Mósè rọ̀ ọ́ pé kó ṣe. (Ẹ́kís. 32:9-14) Lẹ́yìn táwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní Íjíbítì, ó ṣe kedere pé àárín Mósè àti Jèhófà wọ̀ gan-an débi tó fi dà bíi pé Mósè ń rí Jèhófà Baba rẹ̀ ọ̀run lójúkojú.—Héb. 11:27. w19.12 17 ¶7-9
Monday, August 23
Ó ń lọ sí Gálílì ṣáájú yín. Ẹ máa rí i níbẹ̀.—Mát. 28:7.
Gálílì lèyí tó pọ̀ jù lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ti wá. Torí náà, òkè kan ní Gálílì ló máa bọ́gbọ́n mu pé kó ti pàdé pẹ̀lú adúrú èèyàn bẹ́ẹ̀ dípò ilé àdáni kan ní Jerúsálẹ́mù. Bákan náà, Jésù ti pàdé pẹ̀lú àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ mọ́kànlá tẹ́lẹ̀ nínú ilé àdáni kan ní Jerúsálẹ́mù. Torí náà, tó bá jẹ́ pé àwọn nìkan ló fẹ́ gbéṣẹ́ ìwàásù àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn fún, ì bá ti ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tó pàdé pẹ̀lú wọn ní Jerúsálẹ́mù dípò táá fi ní kí àwọn, àwọn obìnrin yẹn àtàwọn míì pàdé òun ní Gálílì. (Lúùkù 24:33, 36) Kì í ṣe àwọn Kristẹni tó wà ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní nìkan làṣẹ tí Jésù pa pé ká sọni dọmọ ẹ̀yìn kàn. Báwo la ṣe mọ̀? Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ lẹ́yìn tó pàṣẹ yẹn ló jẹ́ ká mọ̀, ó ní: “Mo wà pẹ̀lú yín ní gbogbo ọjọ́ títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan.” (Mát. 28:19, 20) Lónìí, àwa èèyàn Jèhófà ń ṣe bẹbẹ tó bá di pé ká wàásù ká sì sọni dọmọ ẹ̀yìn. Ẹ̀yin náà ẹ wò ó ná! Àwọn nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300,000) èèyàn ló ń ṣèrìbọmi lọ́dọọdún! w20.01 2 ¶1; 3 ¶5-6
Tuesday, August 24
Ó rántí wa nígbà tí wọ́n rẹ̀ wá sílẹ̀.—Sm. 136:23.
Bóyá ọ̀dọ́ ni ẹ́ tí àyẹ̀wò dókítà sì fi hàn pé o ní àìsàn tó lágbára. Ṣé o ti dàgbà, tó o gbìyànjú gbogbo ohun tó o lè ṣe, síbẹ̀ ti o kò rí iṣẹ́. Àbí kẹ̀, ara tó ń dara àgbà kò jẹ́ kó o lè ṣe tó bó o ti ń ṣe tẹ́lẹ̀ nínú ìjọsìn Jèhófà. Ó ṣeé ṣe kó o máa dojú kọ ọ̀kan lára àwọn ìṣòro tá a sọ tán yìí. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, o lè máa ronú pé o ò wúlò mọ́. Ìdí sì ni pé, àwọn ìṣòro yìí máa ń kó ẹ̀dùn ọkàn báni, ó sì lè mú kéèyàn máa fojú ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan wo ara rẹ̀ tàbí kó tiẹ̀ ba àjọṣe téèyàn ní pẹ̀lú àwọn míì jẹ́. Ojú tí Sátánì fi ń wo ẹ̀mí èèyàn làwọn èèyàn ayé yìí náà fi ń wò ó. Ọjọ́ pẹ́ tí Sátánì ti máa ń fojú àbùkù wò wá, ó gbà pé àwa èèyàn ò já mọ́ nǹkan kan. Bí àpẹẹrẹ, ó ṣèlérí fún Éfà pé nǹkan máa sàn fún wọn tí wọ́n bá ṣàìgbọràn sí Jèhófà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó mọ̀ lọ́kàn ẹ̀ pé wọ́n máa kú. Ẹ ò rí i pé ìwà ìkà gbáà nìyẹn! Torí pé Sátánì ni alákòóso ayé yìí, kò yani lẹ́nu pé ẹ̀mí àwọn èèyàn ò jọ àwọn aláṣẹ lójú, wọn ò sì bìkítà nípa ẹnikẹ́ni. Àmọ́, Ọlọ́run ìfẹ́ ni Jèhófà Baba wa ọ̀run, kò fẹ́ ká máa ronú pé a ò já mọ́ nǹkan kan, kódà ó ń ràn wá lọ́wọ́ tá a bá níṣòro.—Róòmù 12:3. w20.01 14 ¶1-4
Wednesday, August 25
O ò gbọ́dọ̀ sọ tẹ́lẹ̀ ní orúkọ Jèhófà, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀ a ó fi ọwọ́ ara wa pa ọ́.—Jer. 11:21.
Nǹkan bí ogójì (40) ọdún ni Jeremáyà fi gbé láàárín àwọn tó jẹ́ aláìṣòótọ́, àwọn ará àdúgbò rẹ̀ wà lára wọn, ó tún ṣeé ṣe káwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ kan ní Ánátótì ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀ náà wà lára àwọn aláìṣòótọ́ yìí. (Jer. 12:6) Àmọ́ kò torí ìyẹn yara ẹ̀ sọ́tọ̀. Kódà, ó sọ bí nǹkan ṣe rí lára rẹ̀ fún Bárúkù akọ̀wé rẹ̀ tó dúró tì í, gbogbo ẹ̀ sì wà lákọọ́lẹ̀ fún wa lónìí. (Jer. 8:21; 9:1; 20:14-18; 45:1) Kò sí àní-àní pé bí Bárúkù ṣe ń kọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí Jeremáyà ń sọ fún un sílẹ̀, ṣe làwọn méjèèjì á túbọ̀ sún mọ́ra pẹ́kípẹ́kí, wọ́n á sì mọyì ara wọn. (Jer. 20:1, 2; 26:7-11) Ọ̀pọ̀ ọdún ni Jeremáyà fi kìlọ̀ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì tìgboyàtìgboyà nípa nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ sí ìlú Jerúsálẹ́mù. (Jer. 25:3) Àmọ́ torí Jèhófà fẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì yí pa dà, ó tún kìlọ̀ fún wọn, ó sì sọ fún Jeremáyà pé kó ṣàkọsílẹ̀ ìkìlọ̀ náà sínú àkájọ ìwé kan. (Jer. 36:1-4) Ó ṣeé ṣe kí iṣẹ́ tí Jèhófà gbé fún Jeremáyà àti Bárúkù gbà wọ́n ní ọ̀pọ̀ oṣù, bí wọ́n ṣe jọ ń ṣiṣẹ́ yẹn, ó dájú pé àwọn méjèèjì á jọ máa sọ àwọn ọ̀rọ̀ tó gbé ìgbàgbọ́ wọn ró. w19.11 2-3 ¶3-4
Thursday, August 26
Ẹnikẹ́ni tó bá gbé ara rẹ̀ ga, a máa rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀, ẹnikẹ́ni tó bá sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, a máa gbé e ga.—Mát. 23:12.
Ojú wo ló yẹ kó o máa fi wo àwọn ẹni àmì òróró lọ́kùnrin àti lóbìnrin? Kò dáa ká máa fún ẹnì kan láfiyèsí kọjá bó ṣe yẹ, kódà bí ẹni náà tiẹ̀ jẹ́ arákùnrin Kristi. (Mát. 23:8-11) Nígbà tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn alàgbà, ó gbà wá níyànjú pé ká máa “tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ wọn,” àmọ́ kò sọ pé ká sọ èèyàn èyíkéyìí di aṣáájú wa. (Héb. 13:7) Òótọ́ ni pé Bíbélì sọ pé ká fún àwọn kan ní “ọlá ìlọ́po méjì.” Àmọ́ èyí jẹ́ nítorí pé wọ́n “ń ṣe àbójútó lọ́nà tó dáa,” wọ́n sì “ń ṣiṣẹ́ kára nínú ọ̀rọ̀ sísọ àti kíkọ́ni,” kì í ṣe torí pé wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró. (1 Tím. 5:17) A máa dójú ti àwọn ẹni àmì òróró tá a bá ń fún wọn láfiyèsí àrà ọ̀tọ̀ tàbí tá a bá ń yìn wọ́n kọjá bó ṣe yẹ. Èyí tó tiẹ̀ wá burú jù ni pé a lè mú kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í gbéra ga. (Róòmù 12:3) Ó sì dájú pé kò sẹ́nì kankan nínú wa táá fẹ́ kí ọ̀kan nínú àwọn arákùnrin Kristi ṣe irú àṣìṣe ńlá bẹ́ẹ̀!—Lúùkù 17:2. w20.01 29 ¶8
Friday, August 27
Yàtọ̀ sí àwọn nǹkan tó jẹ́ ti òde yìí, nǹkan míì tún wà . . . àníyàn lórí gbogbo ìjọ.—2 Kọ́r. 11:28.
Ọ̀pọ̀ nǹkan ló mú kí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù máa ṣàníyàn. Ìṣòro àwọn ará lọ́kùnrin lóbìnrin máa ń mú kó ṣàníyàn. (2 Kọ́r. 2:4) Àwọn ìgbà kan wà tí àwọn alátakò lù ú tí wọ́n sì jù ú sẹ́wọ̀n. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ìgbà míì tún wà tó bára ẹ̀ “nínú àìní,” ìyẹn sì mú kó ṣàníyàn. (Fílí. 4:12) Tá a bá sì rántí pé ẹ̀ẹ̀mẹta ni ọkọ̀ ojú omi tó wọ̀ rì, ìyẹn á jẹ́ ká lóye ìdí tó fi lè máa bẹ̀rù nígbà tó bá ń rìnrìn àjò lójú omi. (2 Kọ́r. 11:23-27) Kí ló ran Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́ láti borí àníyàn? Pọ́ọ̀lù ṣàníyàn nígbà táwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin rẹ̀ wà nínú ìṣòro, àmọ́ kò gbìyànjú láti dá yanjú àwọn ìṣòro náà. Pọ́ọ̀lù mọ̀wọ̀n ara rẹ̀, ó mọ̀ pé òun ò lè dá ṣe gbogbo nǹkan. Ìyẹn mú kó yan àwọn arákùnrin míì tó ṣeé fọkàn tán bíi Tímótì àti Títù, kí wọ́n lè ran àwọn ará lọ́wọ́. Kò sí àní-àní pé iṣẹ́ táwọn arákùnrin yẹn ṣe dín àníyàn Pọ́ọ̀lù kù.—Fílí. 2:19, 20; Títù 1:1, 4, 5. w20.02 23 ¶11-12
Saturday, August 28
Ẹ̀yin ọmọ, ẹ máa gbọ́ràn sí àwọn òbí yín lẹ́nu.—Éfé. 6:1.
Jèhófà retí pé kí gbogbo wa máa ṣègbọràn sí òun. Ó yẹ ká máa ṣègbọràn sí i torí pé òun ni Ẹlẹ́dàá wa, òun ló sì ń pèsè àwọn nǹkan tó ń gbẹ́mìí wa ró. Yàtọ̀ síyẹn, òun ni Baba tó gbọ́n jù lọ láyé àti lọ́run. Àmọ́, ìdí tó ṣe pàtàkì jù tá a fi ń ṣègbọràn sí Jèhófà ni pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. (1 Jòh. 5:3) Lóòótọ́, ọ̀pọ̀ ìdí ló wà tó fi yẹ ká máa ṣègbọràn sí Jèhófà, síbẹ̀ kì í fipá mú wa láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ó fún wa lómìnira láti yàn bóyá a máa ṣègbọràn sóun tàbí a ò ní ṣe bẹ́ẹ̀, torí náà inú rẹ̀ máa ń dùn tá a bá ṣègbọràn sí i torí pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Àwọn òbí máa ń dáàbò bo àwọn ọmọ wọn. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi máa ń fún wọn láwọn òfin. Táwọn ọmọ bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà táwọn òbí wọn fi lélẹ̀, wọ́n á fi hàn pé àwọn fọkàn tán àwọn òbí wọn, àwọn sì bọ̀wọ̀ fún wọn. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, mélòómélòó ni ti Baba wa ọ̀run, ṣé kò yẹ ká mọ àwọn ìlànà rẹ̀, ká sì máa fi wọ́n sílò nígbèésí ayé wa? Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a máa jẹ́ kí Jèhófà mọ̀ pé a nífẹ̀ẹ́ òun a sì bọ̀wọ̀ fún òun. Yàtọ̀ síyẹn, a tún máa ṣe ara wa láǹfààní. (Àìsá. 48:17, 18) Lọ́wọ́ kejì, àwọn tó kọ ìlànà Jèhófà máa ń kó sínú ìṣòro àti wàhálà.—Gál. 6:7, 8. w20.02 9-10 ¶8-9
Sunday, August 29
Jẹ́ kí ìránṣẹ́bìnrin rẹ bá ọ sọ̀rọ̀, kí o sì fetí sí ọ̀rọ̀ tí ìránṣẹ́bìnrin rẹ fẹ́ sọ.—1 Sám. 25:24.
Bíi ti Ábígẹ́lì, ó lè gba pé káwa náà lo ìgboyà láti tọ́ ẹnì kan sọ́nà kó má bàa ṣi ẹsẹ̀ gbé. (Sm. 141:5) Ká má ṣe kan onítọ̀hún lábùkù, síbẹ̀ ká rí i dájú pé a ò fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ. Tá a bá fìfẹ́ tọ́ ẹnì kan sọ́nà, ṣe là ń fi hàn pé ọ̀rẹ́ tòótọ́ la jẹ́. (Òwe 27:17) Ó ṣe pàtàkì gan-an pé kẹ́yin alàgbà lo ìgboyà kẹ́ ẹ lè tọ́ àwọn ará sọ́nà tí wọ́n bá ṣi ẹsẹ̀ gbé. (Gál. 6:1) Ẹ máa fi sọ́kàn pé aláìpé ni yín àti pé ẹ̀yin náà lè nílò kí ẹlòmíì gbà yín nímọ̀ràn. Àmọ́ ìyẹn ò wá ní kẹ́ ẹ lọ́ tìkọ̀ láti bá àwọn tó bá ṣàṣìṣe wí. (2 Tím. 4:2; Títù 1:9) Tẹ́ ẹ bá ń bá ẹnì kan wí, ẹ rí i dájú pé ẹ mú sùúrù fún un, kẹ́ ẹ sì bá a sọ̀rọ̀ lọ́nà tó ń tuni lára kó lè rí ẹ̀kọ́ kọ́. Ẹ fìfẹ́ hàn sí i, tẹ́ ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, á yá a lára láti ṣàtúnṣe. (Òwe 13:24) Àmọ́, ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé kẹ́ ẹ rọ̀ mọ́ ìlànà òdodo Jèhófà, kẹ́ ẹ sì dáàbò bo ìjọ torí pé ìyẹn ló máa bọlá fún Jèhófà.—Ìṣe 20:28. w20.03 20 ¶8-9
Monday, August 30
Mo ní okun láti ṣe ohun gbogbo nípasẹ̀ ẹni tó ń fún mi lágbára.—Fílí. 4:13.
Jèhófà mú kí Mósè di olùdáǹdè àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Àmọ́ ìgbà wo ni Jèhófà mú kó ṣe bẹ́ẹ̀? Ṣé lẹ́yìn tí wọ́n “kọ́ Mósè ní gbogbo ọgbọ́n àwọn ará Íjíbítì,” tó sì ronú pé òun tóótun láti dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nídè ni? (Ìṣe 7:22-25) Rárá, kàkà bẹ́ẹ̀ ẹ̀yìn tí Jèhófà dá Mósè lẹ́kọ̀ọ́ tó sì di onírẹ̀lẹ̀ àti oníwà tútù ni Jèhófà tó lò ó. (Ìṣe 7:30, 34-36) Jèhófà fún un nígboyà láti kojú Fáráò ọba Íjíbítì. (Ẹ́kís. 9:13-19) Ohun tá a rí kọ́ ni pé àwọn tó fìwà jọ Jèhófà tó sì gbára lé e pátápátá ló máa ń lò. Tipẹ́tipẹ́ ni Jèhófà ti máa ń fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lágbára láti ṣe ohunkóhun tó bá fẹ́. Àmọ́, kí ni Jèhófà máa mú kó o dì? Ó sinmi lórí bí ìwọ fúnra rẹ bá ṣe sapá tó lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. (Kól. 1:29) Tó o bá yọ̀ǹda ara rẹ, Jèhófà lè mú kó o di ajíhìnrere tó nítara, olùkọ́ tó dáńtọ́, ẹni tó mọ bí wọ́n ṣe ń tu àwọn míì nínú, òṣìṣẹ́ tó mọṣẹ́ rẹ̀ níṣẹ́, ọ̀rẹ́ tòótọ́ tàbí ohunkóhun tó máa mú kí ìfẹ́ Jèhófà ṣẹ. w19.10 21 ¶5; 25 ¶14
Tuesday, August 31
Mo pè yín ní ọ̀rẹ́.—Jòh. 15:15.
Àwọn ọ̀rẹ́ gidi máa ń mú kó rọrùn fún wa láti jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. Ọ̀nà kan tá a sì lè gbà ní ọ̀rẹ́ gidi ni pé káwa náà jẹ́ ọ̀rẹ́ gidi sáwọn míì. (Mát. 7:12) Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì rọ̀ wá pé ká lo ara wa fáwọn míì, pàápàá jù lọ fáwọn aláìní. (Éfé. 4:28) Tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti ran àwọn míì lọ́wọ́, ó dájú pé a máa láyọ̀. (Ìṣe 20:35) Àwọn ọ̀rẹ́ gidi máa ń dúró tini nígbà ìṣòro, ìyẹn sì máa ń jẹ́ kọ́kàn wa balẹ̀. Bí Élíhù ṣe fara balẹ̀ tẹ́tí sí Jóòbù nígbà tó ń sọ bí nǹkan ṣe rí lára ẹ̀, àwọn ọ̀rẹ́ gidi máa ń fara balẹ̀ tẹ́tí sí wa nígbà tá a bá ń tú àníyàn wa jáde. (Jóòbù 32:4) Òótọ́ ni pé àwọn ọ̀rẹ́ wa ò lè ṣèpinnu fún wa, síbẹ̀ á dáa ká tẹ́tí sí ìmọ̀ràn Bíbélì tí wọ́n bá fún wa. (Òwe 15:22) Bákan náà, bíi ti Ọba Dáfídì tó gbà káwọn ọ̀rẹ́ òun ran òun lọ́wọ́, ó yẹ káwa náà lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, ká sì tẹ́wọ́ gba ìrànlọ́wọ́ èyíkéyìí táwọn ọ̀rẹ́ wa bá ṣe fún wa. (2 Sám. 17:27-29) Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Jèhófà làwọn ọ̀rẹ́ gidi jẹ́.—Jém. 1:17. w19.04 11 ¶12; 12 ¶14-15