October
Friday, October 1
Ojú Jèhófà ń lọ káàkiri gbogbo ayé láti fi agbára rẹ̀ hàn nítorí àwọn tí wọ́n ń fi gbogbo ọkàn wọn sìn ín.—2 Kíró. 16:9.
Ọ̀pọ̀ ẹ̀rí ló fi hàn pé Jèhófà ń dáàbò bo àwa èèyàn rẹ̀ lónìí. Jẹ́ ká wò ó báyìí ná: Ibi gbogbo láyé la ti ń wàásù tá a sì ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Mát. 28:19, 20) Nípa bẹ́ẹ̀, à ń tú àṣírí Sátánì, a sì ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé ẹni ibi ni. Ó dájú pé ká ní Sátánì lágbára ẹ̀ ni, ì bá ti dá iṣẹ́ náà dúró, àmọ́ kò lágbára ẹ̀. Torí náà, kò sídìí pé à ń bẹ̀rù Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀. Tá a bá jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà, àwọn ẹ̀mí èṣù kò ní lè ṣe ìpalára ayérayé fún wa. Àmọ́, gbogbo wa la gbọ́dọ̀ kọjú ìjà sáwọn ẹ̀mí èṣù, ká sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ ìbùkún la máa rí gbà, Sátánì ò sì ní lè fi irọ́ burúkú rẹ̀ ṣì wá lọ́nà. Bákan náà, a ò ní máa bẹ̀rù àwọn ẹ̀mí èṣù. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, okùn àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà á túbọ̀ lágbára. Jémíìsì tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn sọ pé: “Ẹ dojú ìjà kọ Èṣù, ó sì máa sá kúrò lọ́dọ̀ yín. Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, á sì sún mọ́ yín.”—Jém. 4:7, 8. w19.04 24 ¶15; 25 ¶18
Saturday, October 2
Èso ikùn jẹ́ èrè.—Sm. 127:3.
Jèhófà ti fi àwọn ọmọ yìí jíǹkí yín, torí pé “ogún láti ọ̀dọ̀ Jèhófà” ni wọ́n. Torí náà, ojúṣe yín ni láti bójú tó àwọn ọmọ yín, kẹ́ ẹ sì dáàbò bò wọ́n. Kí lẹ lè ṣe táwọn ọmọ yín ò fi ní kó sọ́wọ́ àwọn tó ń bọ́mọdé ṣèṣekúṣe? Àkọ́kọ́, ó yẹ kẹ́yin òbí mọ ọgbọ́n táwọn tó ń bọ́mọdé ṣèṣekúṣe máa ń lò. Ẹ ṣèwádìí kẹ́ ẹ lè mọ irú àwọn èèyàn tó sábà máa ń bọ́mọdé ṣèṣekúṣe àti ọgbọ́nkọ́gbọ́n tí wọ́n fi máa ń tan àwọn ọmọdé. Bákan náà, ó yẹ kẹ́ ẹ mọ àwọn ibi àti ipò tó lè mú káwọn ọmọ yín kó sọ́wọ́ àwọn èèyànkéèyàn yìí. (Òwe 22:3; 24:3) Ẹ fi sọ́kàn pé, lọ́pọ̀ ìgbà àwọn tí ọmọ yín mọ̀ dáadáa tó sì fọkàn tán ló sábà máa ń hùwà burúkú yìí. Ìkejì, ẹ máa bá àwọn ọmọ yín sọ̀rọ̀ dáadáa, kẹ́ ẹ sì rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n máa sọ tinú wọn fún yín. (Diu. 6:6, 7; Jém. 1:19) Ẹ fi sọ́kàn pé kì í yá àwọn ọmọ tí wọ́n fipá bá ṣèṣekúṣe lára láti sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn. Ẹ̀rù lè máa bà wọ́n pé kò sẹ́ni tó máa gba àwọn gbọ́, ó sì lè jẹ́ pé ẹni tó bá wọn ṣèṣekúṣe ti halẹ̀ mọ́ wọn pé òun á ṣe wọ́n ní jàǹbá tí wọ́n bá sọ fún ẹnikẹ́ni. Tẹ́yin òbí bá fura pé nǹkan kan ń ṣe ọmọ yín, ẹ fi pẹ̀lẹ́tù bá a sọ̀rọ̀, kẹ́ ẹ lo àwọn ìbéèrè táá jẹ́ kẹ́ ẹ mọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀, kẹ́ ẹ sì fara balẹ̀ dáadáa tó bá ń ṣàlàyé ohun tó ṣe é. Ìkẹta, ẹ kọ́ wọn lóhun tí wọ́n máa sọ àtohun tí wọ́n máa ṣe tẹ́nì kan bá fẹ́ fọwọ́ kàn wọ́n níbi tí kò tọ́ tàbí lọ́nà tí kò yẹ. w19.05 13 ¶19-22
Sunday, October 3
Jèhófà kórìíra gbogbo ẹni tó ń gbéra ga.—Òwe 16:5.
Kí nìdí tí Jèhófà fi kórìíra àwọn agbéraga? Ìdí kan ni pé Sátánì làwọn agbéraga fìwà jọ. Àbí kí ni ká ti gbọ́, pé kí Sátánì máa sọ fún Jésù pé kó forí balẹ̀ fún òun kó sì jọ́sìn òun, tó sì mọ̀ pé Jésù ni Jèhófà lò láti dá gbogbo nǹkan. Ẹ ò rí i pé àrífín gbáà nìyẹn, ìkọjá-àyè sì ni! (Mát. 4:8, 9; Kól. 1:15, 16) Irú ojú táwọn agbéraga fi ń wo ara wọn yìí jẹ́ kó ṣe kedere pé lójú Ọlọ́run, ìwà òmùgọ̀ lohun tí ayé ń gbé lárugẹ. (1 Kọ́r. 3:19) Àmọ́, Bíbélì fún wa láwọn ìmọ̀ràn táá jẹ́ ká lè máa fojú tó tọ́ wo ara wa. Ó jẹ́ ká mọ̀ pé ó yẹ ká nífẹ̀ẹ́ ara wa déwọ̀n àyè kan. Jésù sọ pé ká ‘nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì wa bí ara wa,’ tó fi hàn pé ó yẹ ká máa tọ́jú ara wa. (Mát. 19:19) Àmọ́ Bíbélì ò sọ pé ká máa ronú pé a sàn ju àwọn míì lọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó sọ ni pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí ìbínú tàbí ìgbéraga mú yín ṣe ohunkóhun, àmọ́ ẹ jẹ́ kí ìrẹ̀lẹ̀ máa mú kí ẹ gbà pé àwọn míì sàn jù yín lọ.”—Fílí. 2:3; Róòmù 12:3. w19.05 24 ¶13-14
Monday, October 4
Ẹ má sì jẹ́ kí ètò àwọn nǹkan yìí máa darí yín, àmọ́ ẹ para dà nípa yíyí èrò inú yín pa dà.—Róòmù 12:2.
Ó ṣeé ṣe ká rántí àwọn ìyípadà tá a ṣe nígbà tá a kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, tá a sì ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà. Kíyẹn lè ṣeé ṣe, ọ̀pọ̀ lára wa ló jáwọ́ nínú àwọn ìwà tí kò tọ́. (1 Kọ́r. 6:9-11) A mà dúpẹ́ o pé Jèhófà ràn wá lọ́wọ́ láti borí àwọn ìwà burúkú yẹn! Àmọ́ o, a ò gbọ́dọ̀ dẹra nù. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti jáwọ́ nínú àwọn ìwà burúkú tá à ń hù ká tó ṣèrìbọmi, síbẹ̀ ó yẹ ká túbọ̀ wà lójúfò ká sì yẹra fún ohunkóhun táá mú ká pa dà sẹ́yìn. Ìgbésẹ̀ méjì kan wà tá a gbọ́dọ̀ gbé. Àkọ́kọ́, a gbọ́dọ̀ ṣe ohun tí kò ní jẹ́ kí ayé èṣù yìí “máa darí” wa. Èkejì, a gbọ́dọ̀ “para dà,” ní ti pé ká yí bá a ṣe ń ronú pa dà. Ìyípadà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ kọjá ohun tó kàn hàn sójú táyé. Ó kan gbogbo apá ìgbésí ayé wa. A gbọ́dọ̀ yí èrò inú wa pa dà, ìyẹn ni pé ká ṣe ìyípadà nínú bá a ṣe ń ronú, bí nǹkan ṣe ń rí lára wa títí kan ohun tó ń sún wa ṣe nǹkan. w19.06 9 ¶4-6
Tuesday, October 5
Ìwọ Jèhófà ni olùrànlọ́wọ́ mi àti olùtùnú mi.—Sm. 86:17.
Tá a bá ní ẹ̀dùn ọkàn, a lè jèrè okun pa dà tá a bá ń lọ sáwọn ìpàdé wa. Tá a bá ń pésẹ̀ sípàdé déédéé, ṣe la túbọ̀ ń jẹ́ kí Jèhófà di ‘olùrànlọ́wọ́ àti olùtùnú’ wa. Láwọn ìpàdé wa, Jèhófà máa ń fún wa lókun nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àtàwọn èèyàn rẹ̀. Àwọn ìpàdé wa tún máa ń jẹ́ ká lè “fún ara wa ní ìṣírí” lẹ́nì kìíní kejì. (Róòmù 1:11, 12) Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Sophia sọ pé: “Jèhófà àtàwọn èèyàn rẹ̀ ló ràn mí lọ́wọ́. Mi ò fọ̀rọ̀ lílọ sípàdé ṣeré rárá torí pé mo máa ń rí ìṣírí gbà níbẹ̀. Mo ti rí i pé bí mo ṣe túbọ̀ ń lo ara mi lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù àti nínú ìjọ, bẹ́ẹ̀ ló túbọ̀ ń rọrùn fún mi láti fara da àwọn ìṣòro mi.” Nígbàkigbà tá a bá rẹ̀wẹ̀sì, ẹ jẹ́ ká rántí pé láìpẹ́ Jèhófà máa mú gbogbo ohun tó ń fa ìdààmú ọkàn kúrò. Àmọ́, kì í ṣèyẹn nìkan, ní báyìí ó ń fún wa ní “agbára” táá mú ká borí ìrẹ̀wẹ̀sì àti ìdààmú ọkàn èyíkéyìí tá a bá ní.—Fílí. 2:13. w19.06 19 ¶17-18
Wednesday, October 6
Ẹ lọ ròyìn fún àwọn arákùnrin mi, kí wọ́n lè lọ sí Gálílì, ibẹ̀ ni wọ́n ti máa rí mi.—Mát. 28:10.
Ó dájú pé ìtọ́ni pàtàkì kan wà tí Jésù fẹ́ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ torí pé ìyẹn ni ìpàdé àkọ́kọ́ tó ṣètò lẹ́yìn tó jíǹde. Níbi ìpàdé tí Jésù ṣètò yẹn, ó gbé iṣẹ́ pàtàkì kan fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tí wọ́n máa ṣe jálẹ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, iṣẹ́ yìí kan náà la sì ń ṣe lónìí. Jésù sọ pé: “Torí náà, ẹ lọ, kí ẹ máa sọ àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, . . . ẹ máa kọ́ wọn pé kí wọ́n máa pa gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún yín mọ́.” (Mát. 28:19, 20) Gbogbo àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ni Jésù fẹ́ kó máa wàásù. Kì í ṣe àwọn àpọ́sítélì mọ́kànlá tó jẹ́ olóòótọ́ nìkan làṣẹ yẹn kàn. Báwo la ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀? Ẹ jẹ́ ká wò ó báyìí ná: Ṣé òun àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ nìkan ló wà níbi òkè kan ní Gálílì nígbà tó pàṣẹ pé kí wọ́n sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn? Ẹ rántí pé áńgẹ́lì tó yọ sáwọn obìnrin yẹn sọ fún wọn pé: “Ẹ máa rí i [ní Gálílì].” (Mát. 28:7) Èyí fi hàn pé àwọn obìnrin yẹn wà lára àwọn tó wà níbẹ̀ lọ́jọ́ náà. w20.01 2-3 ¶1-4
Thursday, October 7
Torí pé ẹ kì í ṣe apá kan ayé, àmọ́ mo ti yàn yín látinú ayé, torí èyí ni ayé ṣe kórìíra yín.—Jòh. 15:19.
Jésù ṣàlàyé ìdí táwọn èèyàn fi máa ṣenúnibíni sí wa. Ó sọ pé àwọn èèyàn máa kórìíra wa torí pé a kì í ṣe apá kan ayé. Torí náà, ti pé wọ́n ń ṣenúnibíni sí wa kò túmọ̀ sí pé Jèhófà kẹ̀yìn sí wa. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ̀rí ló jẹ́ pé ohun tó tọ́ là ń ṣe! Ńṣe lọ̀rọ̀ àwọn tó ṣòfin pé a ò gbọ́dọ̀ jọ́sìn Jèhófà dà bí ewúrẹ́ tó ń bínú, tó wá ń fẹsẹ̀ halẹ̀. Ẹ gbọ́ ná, kí lá fi olówó ẹ̀ ṣe? Kí èèyàn lásánlàsàn máa lérí pé òun á pa ìjọsìn Ọlọ́run Olódùmarè rẹ́! Àwọn tó ṣe bẹ́ẹ̀ níjọ̀ọ́sí dà? Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà Ogun Àgbáyé Kejì. Nígbà yẹn, ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ló ń ṣenúnibíni tó gbóná janjan sáwa èèyàn Jèhófà. Wọ́n fòfin de iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lásìkò ìjọba Násì nílẹ̀ Jámánì, kódà wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ lórílẹ̀-èdè Ọsirélíà, Kánádà àtàwọn ilẹ̀ míì. Ǹjẹ́ ẹ mọ ohun tó ṣẹlẹ̀? Lọ́dún 1939 tí ogun yẹn bẹ̀rẹ̀, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjìléláàádọ́rin àtààbọ̀ (72,475) làwọn akéde tó wà kárí ayé. Àmọ́ lẹ́yìn tí ogun náà parí lọ́dún 1945, àwọn akéde ti ju ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́jọ lọ (156,299). Àbẹ́ ò rí nǹkan, láìka gbogbo àtakò wọn sí, ṣe làwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run pọ̀ sí i, kódà wọ́n lé ní ìlọ́po méjì! w19.07 9 ¶4-5
Friday, October 8
Èyí ni gbogbo èèyàn máa fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, tí ìfẹ́ bá wà láàárín yín.—Jòh. 13:35.
Ká tiẹ̀ sọ pé o ò ní àwọn tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì báyìí, o ṣì lè lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn láwọn ọ̀nà míì. Bí àpẹẹrẹ, o lè fi tayọ̀tayọ̀ kí àwọn ẹni tuntun káàbọ̀ sí ìpàdé tàbí kó o bá wọn ṣọ̀rẹ́. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá jẹ́ kí wọ́n rí i pé Kristẹni tòótọ́ ni wá bá a ṣe nífẹ̀ẹ́ ara wa. Tó o bá ń dáhùn nípàdé, bó tiẹ̀ jẹ́ ṣókí, ńṣe lò ń kọ́ àwọn ẹni tuntun bí wọ́n ṣe lè dáhùn lọ́rọ̀ ara wọn, kí wọ́n sì sọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́. O tún lè ṣètò láti lọ sóde ẹ̀rí pẹ̀lú akéde tuntun kan, kó o sì jẹ́ kó rí bó ṣe lè máa fi Ìwé Mímọ́ fèrò wérò pẹ̀lú àwọn èèyàn. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àpẹẹrẹ Kristi lò ń tẹ̀ lé yẹn. (Lúùkù 10:25-28) Ọ̀pọ̀ Kristẹni lọwọ́ wọn máa ń dí torí àwọn ojúṣe tí wọ́n ń bójú tó. Síbẹ̀, wọ́n máa ń wáyè kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìyẹn sì ń fún wọn láyọ̀. w19.07 17 ¶11, 13
Saturday, October 9
Bí mo ṣe ń gbàgbé àwọn ohun tí mo fi sílẹ̀ sẹ́yìn, tí mo sì ń nàgà sí àwọn ohun tó wà níwájú, mò ń sapá kí ọwọ́ mi lè tẹ èrè.—Fílí. 3:13, 14.
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ò jẹ́ kí àwọn àṣeyọrí tàbí àwọn àṣìṣe tó ti ṣe sẹ́yìn pín ọkàn rẹ̀ níyà. Kódà, ó sọ pé òun ní láti ‘gbàgbé àwọn ohun tóun ti fi sílẹ̀ sẹ́yìn’ kóun tó lè “nàgà sí àwọn ohun tó wà níwájú,” ìyẹn kọ́wọ́ òun tó lè tẹ èrè náà. Kí ni díẹ̀ lára àwọn nǹkan tí Pọ́ọ̀lù ò jẹ́ kó pín ọkàn òun níyà? Ohun àkọ́kọ́ ni pé kò jẹ́ kí ọ̀pọ̀ àṣeyọrí tó ṣe nínú ẹ̀sìn àwọn Júù kó sí i lórí. Dípò bẹ́ẹ̀, ó ka gbogbo ẹ̀ sí “ọ̀pọ̀ pàǹtírí.” (Fílí. 3:3-8) Ìkejì, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó máa ń banú jẹ́ torí inúnibíni tó ṣe sáwọn Kristẹni, kò jẹ́ kíyẹn kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá òun. Ìkẹta, kò ronú pé ohun tóun ti ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ti tó. Ká sòótọ́, iṣẹ́ òjíṣẹ́ Pọ́ọ̀lù méso jáde láìka gbogbo ohun tójú ẹ̀ rí. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n jù ú sẹ́wọ̀n, wọ́n lù ú, wọ́n sọ ọ́ lókùúta, ọkọ̀ ojú omi tó wọ̀ rì, bẹ́ẹ̀ sì làwọn ìgbà míì wà tí kò fi bẹ́ẹ̀ ní oúnjẹ àti aṣọ. (2 Kọ́r. 11:23-27) Pẹ̀lú gbogbo ohun tó gbé ṣe àtohun tójú ẹ̀ rí, Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé òun ṣì gbọ́dọ̀ máa bá eré ìje náà lọ. Bọ́rọ̀ sì ṣe rí fáwa náà nìyẹn. w19.08 3 ¶5
Sunday, October 10
Mò ń rán yín jáde bí àgùntàn sáàárín àwọn ìkookò.—Mát. 10:16.
Ọ̀pọ̀ àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin ló ń gbé lórílẹ̀-èdè tí wọn ò ti gbà wá láyè láti wàásù ní fàlàlà tàbí láti ilé dé ilé. Torí náà, ṣe ni wọ́n máa ń wọ́nà míì láti wàásù. (Mát. 10:17-20) Lórílẹ̀-èdè kan, alábòójútó àyíká sọ fáwọn akéde pé kí wọ́n máa wàásù láwọn ibi tá a lè pè ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn, ìyẹn fáwọn ẹbí wọn, àwọn aládùúgbò, ọmọ ilé ìwé, ará ibiṣẹ́ àtàwọn ojúlùmọ̀ míì. Ní nǹkan bí ọdún méjì péré, ìjọ tó wà ní àyíká yẹn pọ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Kí làwa tá à ń gbé nílẹ̀ tí wọn ò ti fòfin de iṣẹ́ wa lè ṣe? A lè kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tí wọ́n ń wàásù lábẹ́ ipò tó nira. Ẹ̀kọ́ náà ni pé ká máa wá gbogbo ọ̀nà tá a lè fi bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kó sì dá wa lójú pé Jèhófà á fún wa lágbára láti borí ìdènà èyíkéyìí. (Fílí. 2:13) Láwọn àkókò òpin yìí, ẹ jẹ́ ká pinnu pé àá máa rí i dájú pé àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì jù là ń ṣe, ká wà láìní àbààwọ́n, ká má ṣe máa mú àwọn míì kọsẹ̀, ká sì máa so èso òdodo. Nípa bẹ́ẹ̀, ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà àtàwọn ará wa á túbọ̀ pọ̀ sí i, àá sì mú ìyìn àti ògo bá Jèhófà, Baba wa onífẹ̀ẹ́. w19.08 13 ¶17-18
Monday, October 11
Mo ti rí àwọn ìránṣẹ́ tó ń gun ẹṣin àmọ́ tí àwọn olórí ń fẹsẹ̀ rìn bí ìránṣẹ́.—Oníw. 10:7.
Ọ̀pọ̀ wa kì í fẹ́ da nǹkan pọ̀ pẹ̀lú àwọn tó máa ń rin kinkin mọ́ èrò wọn tàbí tí kì í gba èrò àwọn míì. Lọ́wọ́ kejì, ó máa ń wù wá láti wà pẹ̀lú ẹni tó máa ń ‘báni kẹ́dùn, tó nífẹ̀ẹ́ àwọn ará, tó lójú àánú, tó sì jẹ́ onírẹ̀lẹ̀.’ (1 Pét. 3:8) Tó bá jẹ́ pé ó máa ń wù wá láti wà pẹ̀lú àwọn onírẹ̀lẹ̀, kò sí àní-àní pé ó máa wu àwọn náà láti wà pẹ̀lú wa tá a bá jẹ́ onírẹ̀lẹ̀. Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ máa ń jẹ́ kí nǹkan túbọ̀ rọrùn fún wa. Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, nígbà míì nǹkan kì í lọ bá a ṣe fẹ́, wọ́n sì lè fi ohun tó tọ́ sí wa dù wá. Nígbà míì, àwọn tó ṣiṣẹ́ kára tàbí tó lẹ́bùn tó ta yọ kì í gbayì lójú àwọn èèyàn. Àmọ́ àwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ lẹ́bùn làwọn èèyàn máa ń gbé gẹ̀gẹ̀. Síbẹ̀, Sólómọ́nì sọ pé á dáa ká má ṣe yọ ara wa lẹ́nu nípa ohun tá ò lè ṣe nǹkan kan nípa ẹ̀. (Oníw. 6:9) Tá a bá lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, a ò ní máa da ara wa láàmú táwọn nǹkan tá ò retí bá tiẹ̀ ṣẹlẹ̀ nígbèésí ayé wa. w19.09 4-5 ¶9-10
Tuesday, October 12
Ẹ̀yin bàbá, . . . ẹ máa tọ́ [àwọn ọmọ yín] dàgbà nínú ìbáwí àti ìmọ̀ràn Jèhófà.—Éfé. 6:4.
Ó yẹ káwọn tó wà nípò àṣẹ irú bí àwọn bàbá máa fi ara wọn sábẹ́ Jèhófà, tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n á ran àwọn mí ì lọ́wọ́. Ẹ̀yin bàbá ni Jèhófà fi ṣe olórí ìdílé, ó sì retí pé kẹ́ ẹ máa kọ́ àwọn ọmọ yín, kẹ́ ẹ máa tọ́ wọn sọ́nà, kẹ́ ẹ sì máa bá wọn wí. (1 Kọ́r. 11:3) Àmọ́, ó níbi tí àṣẹ yín mọ torí pé ẹ máa jíhìn fún Jèhófà tó dá ìdílé sílẹ̀. (Éfé. 3:14, 15) Tí ẹ̀yin bàbá bá ń lo ipò orí yín bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ, ìyẹn á fi hàn pé ẹ̀ ń fi ara yín sábẹ́ Jèhófà. Má ṣi agbára tí Jèhófà fún ẹ lò. Tó o bá ṣàṣìṣe, mọ ẹ̀bi ẹ lẹ́bi, kó o sì gba ìmọ̀ràn táwọn míì bá fún ẹ látinú Bíbélì. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìyàwó àtàwọn ọmọ ẹ máa bọ̀wọ̀ fún ẹ. Tó o bá ń gbàdúrà pẹ̀lú ìdílé ẹ, sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn ẹ fún Jèhófà, jẹ́ kí wọ́n rí i pé Jèhófà lo gbẹ́kẹ̀ lé pátápátá. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, ìjọsìn Jèhófà ni kó o jẹ́ kó gbawájú láyé ẹ. (Diu. 6:6-9) Àpẹẹrẹ rere tó o bá fi lélẹ̀ lẹ̀bùn tó dáa jù tó o lè fún ìdílé ẹ. w19.09 15 ¶8; 17 ¶14; 18 ¶16
Wednesday, October 13
Gba [Máàkù] tọwọ́tẹsẹ̀ tó bá wá sọ́dọ̀ yín.—Kól. 4:10.
Inú Máàkù máa ń dùn láti ṣiṣẹ́ sin àwọn míì. Àwọn ìgbà kan wà tó bá àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àti Pétérù ṣiṣẹ́, tó sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣe àwọn nǹkan, bíi kó bá wọn ra oúnjẹ, kó wá ibi tí wọ́n lè dé sí àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. (Ìṣe 13:2-5; 1 Pét. 5:13) Máàkù wà lára àwọn tí Pọ́ọ̀lù dárúkọ pé àwọn “jọ ń ṣiṣẹ́ fún Ìjọba Ọlọ́run,” ó sì tún sọ pé ó jẹ́ “àrànṣe afúnnilókun” tàbí orísun ìtùnú fún òun. (Kól. 4:11, àlàyé ìsàlẹ̀) Kò sí àní-àní pé Máàkù wà lára àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ tí Pọ́ọ̀lù ní. Bí àpẹẹrẹ, lásìkò tí Pọ́ọ̀lù wà lẹ́wọ̀n fúngbà ìkẹyìn nílùú Róòmù, ìyẹn ní nǹkan bíi 65 Sànmánì Kristẹni, ó kọ lẹ́tà rẹ̀ kejì sí Tímótì. Nínú lẹ́tà yẹn, ó sọ pé kí Tímótì wá bá òun ní Róòmù, kó sì mú Máàkù dání. (2 Tím. 4:11) Ó ṣe kedere pé Pọ́ọ̀lù mọyì àwọn ohun tí Máàkù ti ṣe sẹ́yìn, ó sì fẹ́ kó wà pẹ̀lú òun lásìkò tí nǹkan nira yẹn. Máàkù ṣèrànwọ́ fún Pọ́ọ̀lù lónírúurú ọ̀nà, bóyá kó bá a ra oúnjẹ tàbí àwọn nǹkan tí Pọ́ọ̀lù fi ń kọ̀wé. Ó dájú pé ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n ṣe fún Pọ́ọ̀lù yẹn máa fún un níṣìírí gan-an, á sì jẹ́ kó rọrùn fún un láti fara dà á kí wọ́n tó pa á. w20.01 11 ¶12-13
Thursday, October 14
Ẹ wá sọ́dọ̀ mi.—Mát. 11:28.
A ti pinnu pé a máa fayé wa sin Jèhófà, àá sì yááfì àwọn nǹkan ká lè ṣe iṣẹ́ náà yanjú. Jésù ti sọ fún wa tẹ́lẹ̀ pé wọ́n máa ṣenúnibíni sí wa. Àmọ́ ó dá wa lójú pé Jèhófà máa fún wa lókun ká lè fara da ìṣòro yòówù kó yọjú. Bá a ṣe ń fara dà á, bẹ́ẹ̀ ni ìgbàgbọ́ tá a ní nínú Jèhófà á túbọ̀ máa lágbára sí i. (Jém. 1:2-4) Ó tún dá wa lójú pé Jèhófà máa pèsè àwọn nǹkan tá a nílò, pé Jésù máa darí wa àti pé àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin máa fún wa níṣìírí. (Mát. 6:31-33; Jòh. 10:14; 1 Tẹs. 5:11) Kò sí àní-àní pé ara tu obìnrin tó ní “ìsun ẹ̀jẹ” yẹn lọ́jọ́ tí Jésù wò ó sàn. (Lúùkù 8:43-48) Àmọ́ ohun tó máa jẹ́ kó rí ìtura tó wà pẹ́ títí ni pé kó di ọmọlẹ́yìn Kristi. Kí lo rò pé obìnrin náà ṣe? Tó bá jẹ́ ìpè Jésù, tó sì fi ara rẹ̀ sábẹ́ àjàgà rẹ̀, á ti wà pẹ̀lú Jésù lọ́run báyìí. Ẹ ò rí i pé èrè ńlá nìyẹn! Ohun yòówù kó yááfì kó lè di ọmọlẹ́yìn Kristi tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Yálà ọ̀run là ń lọ tàbí ayé la máa wà títí láé, inú wa dùn pé a jẹ́ ìpè Jésù tó ní: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi!” w19.09 25 ¶21-22
Friday, October 15
Ọgbọ́n la fi ń gbé ilé ró, òye sì la fi ń fìdí rẹ̀ múlẹ̀.—Òwe 24:3.
Dáfídì àtàwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ nílò ìrànlọ́wọ́ lójú méjèèjì, torí náà àwọn èèyàn Dáfídì lọ bá Nábálì, ọmọ Ísírẹ́lì kan tó lówó bíi ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ pé kó wá oúnjẹ díẹ̀ fáwọn, bó ti wù kó kéré mọ. Ojú ò tì wọ́n láti béèrè pé kí Nábálì wá nǹkan fáwọn torí pé àwọn ló ń ṣọ́ agbo ẹran rẹ̀ nínú aginjù. Àmọ́ ahun ni Nábálì, kò sì fún wọn ní nǹkan kan. Dáfídì tutọ́ sókè ó fojú gbà á, ó ní àfi kóun pa Nábálì àti gbogbo ọkùnrin tó wà lágboolé rẹ̀. (1 Sám. 25:3-13, 22) Àmọ́, Ábígẹ́lì ìyàwó Nábálì níwà, ó sì tún lẹ́wà. Ó lo ìgboyà, ó lọ bá Dáfídì ó wólẹ̀ síbi ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì bẹ̀ ẹ́ pé kó má gbẹ̀san torí pé ìyẹn máa jẹ́ kó jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀. Ó fọgbọ́n gba Dáfídì nímọ̀ràn pé kó fọ̀rọ̀ náà sọ́wọ́ Jèhófà. Ọ̀rọ̀ ọlọgbọ́n tó ń tuni lára tí Ábígẹ́lì sọ àti ìwà ìrẹ̀lẹ̀ tó hù mú kí ọkàn Dáfídì rọ̀. Ó gbà pé Jèhófà ló rán an sí òun. (1 Sám. 25:23-28, 32-34) Ábígẹ́lì ní àwọn ànímọ́ tó mú kó wúlò fún Jèhófà. Lọ́nà kan náà, bí ẹ̀yin arábìnrin bá jẹ́ olóye, tẹ́ ẹ sì mọ béèyàn ṣe ń fọgbọ́n báni sọ̀rọ̀, Jèhófà máa lò yín láti fún àwọn míì lókun yálà nínú ìdílé yín tàbí nínú ìjọ.—Títù 2:3-5. w19.10 23 ¶10
Saturday, October 16
Ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀, ẹ̀yin èèyàn mi, tí ẹ kò bá fẹ́ pín nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, tí ẹ kò bá sì fẹ́ gbà lára àwọn ìyọnu rẹ̀.—Ìfi. 18:4.
Gbogbo wa pátá la gbọ́dọ̀ rí i pé a ya ara wa sọ́tọ̀ kúrò nínú Bábílónì Ńlá, ká má sì ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú rẹ̀ bó ti wù kó kéré mọ. Àwọn kan lè ti máa ṣe ẹ̀sìn èké kí wọ́n tó kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n ti máa lọ́wọ́ nínú àwọn àṣà àti ìṣe ẹ̀sìn náà. Ó sì lè jẹ́ pé wọ́n máa ń fowó ṣètìlẹyìn fún irú ẹ̀sìn bẹ́ẹ̀. Àmọ́, káwọn alàgbà tó lè fọwọ́ sí i pé kẹ́nì kan tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi, ó gbọ́dọ̀ jáwọ́ pátápátá nínú ẹ̀sìn èké tó ń dara pọ̀ mọ́ tẹ́lẹ̀. Ó máa ní láti kọ lẹ́tà sí wọn pé òun kì í ṣe ọ̀kan lára wọn mọ́, ó sì tún gbọ́dọ̀ yọwọ́ yọsẹ̀ pátápátá nínú ètò tàbí ẹgbẹ́ èyíkéyìí tó ní nǹkan ṣe pẹ̀lú Bábílónì Ńlá. Ẹnì kọ̀ọ̀kan wa gbọ́dọ̀ rí i dájú pé iṣẹ́ wa kò ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú Bábílónì Ńlá. (2 Kọ́r. 6:14-17) Kí nìdí tọ́rọ̀ yìí fi lágbára tó bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé a ò fẹ́ lọ́wọ́ nínú ohunkóhun tí wọ́n ń ṣe nínú ẹ̀sìn èké, yálà ẹ̀kọ́ tí wọ́n fi ń kọ́ni, orin wọn, ìṣe wọn tàbí àṣà wọn torí pé ohun àìmọ́ ni wọ́n lójú Ọlọ́run.—Àìsá. 52:11. w19.10 12 ¶16-17
Sunday, October 17
Aláàánú ni Jèhófà, ó sì ń gba tẹni rò . . . Kì í fìgbà gbogbo wá àṣìṣe, kì í sì í bínú títí lọ.—Sm. 103:8, 9.
Jeremáyà fúnra ẹ̀ ló kọ ìwé Jeremáyà, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé òun náà ló kọ ìwé Àwọn Ọba Kìíní àti Kejì. Ó dájú pé iṣẹ́ tí Jèhófà gbé fún un yẹn jẹ́ kó túbọ̀ mọ̀ pé Jèhófà máa ń ṣàánú àwa èèyàn aláìpé gan-an. Bí àpẹẹrẹ, Jeremáyà mọ̀ pé nígbà tí Ọba Áhábù ronú pìwà dà, Jèhófà kò jẹ́ kí ìdílé rẹ̀ pa run lójú ẹ̀. (1 Ọba 21:27-29) Bákan náà, Jeremáyà mọ̀ pé ohun tí Ọba Mánásè ṣe burú ju ti Áhábù lọ. Síbẹ̀, Jèhófà dárí ji Mánásè nígbà tó ronú pìwà dà. (2 Ọba 21:16, 17; 2 Kíró. 33:10-13) Ó dájú pé àwọn àpẹẹrẹ yìí máa mú kí Jeremáyà rí ìdí tó fi yẹ kóun náà máa mú sùúrù kóun sì máa ṣàánú. Ẹ jẹ́ ká wo bí Jeremáyà ṣe ran Bárúkù lọ́wọ́ nígbà kan tó ní ìpínyà ọkàn. Dípò kí Jeremáyà gbà pé ọ̀rẹ́ òun ò wúlò mọ́, ṣe ló ràn án lọ́wọ́ tìfẹ́tìfẹ́, kò sì fi ọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ nígbà tó ń sọ ìkìlọ̀ Jèhófà fún un.—Jer. 45:1-5. w19.11 6 ¶14-15
Monday, October 18
Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tó fi máa gbàgbé iṣẹ́ yín àti ìfẹ́ tí ẹ fi hàn fún orúkọ rẹ̀.—Héb. 6:10.
Ìwé Léfítíkù jẹ́ ká rí i pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń rú ẹbọ ìrẹ́pọ̀ “láti fi ṣe ìdúpẹ́.” (Léf. 7:11-13, 16-18) Kò sí òfin tó sọ pé ọmọ Ísírẹ́lì kan gbọ́dọ̀ rú ẹbọ yìí, òun fúnra rẹ̀ ló pinnu láti ṣe bẹ́ẹ̀. Iṣẹ́ ìsìn wa jọ ẹbọ ìrẹ́pọ̀ torí pé àwa fúnra wa la pinnu pé a máa sin Jèhófà. Torí pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ tọkàntọkàn, ohun tó dáa jù là ń fún un. Ẹ wo bí inú Jèhófà ṣe máa dùn tó bó ṣe ń rí ẹgbàágbèje èèyàn tó ń jọ́sìn rẹ̀ torí ìfẹ́ tí wọ́n ní fún un! Kì í ṣe pé Jèhófà mọrírì ohun tá à ń ṣe nínú ìjọsìn rẹ̀ nìkan, ó tún mọyì ohun tó ń sún wa ṣe é. Bí àpẹẹrẹ, bóyá àgbàlagbà ni ẹ́ tó ò sì lè ṣe tó bó o ṣe fẹ́, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà lóye rẹ. Ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé ohun tó ò ń ṣe kò tó nǹkan, àmọ́ ohun tí Jèhófà ń wò ni ìfẹ́ àtọkànwá tó o ní, torí ìfẹ́ yẹn ló jẹ́ kó o máa ṣe gbogbo ohun tágbára rẹ gbé. Inú Jèhófà ń dùn sí ẹ torí pé ohun tó dáa jù lọ lò ń fún un. w19.11 22 ¶9; 23 ¶11-12
Tuesday, October 19
Ẹ máa bọ̀, ẹ wá síbi tó dá . . . kí ẹ sì sinmi díẹ̀.—Máàkù 6:31.
Kò yẹ ká ṣàṣejù tó bá dọ̀rọ̀ iṣẹ́. Ọlọ́run mí sí Ọba Sólómọ́nì láti sọ pé: “Ohun gbogbo ni àkókò wà fún.” Ó mẹ́nu kan ìgbà gbígbìn, ìgbà kíkọ́, ìgbà sísunkún, ìgbà rírẹ́rìn-ín, ìgbà jíjó àtàwọn ìgbòkègbodò míì. (Oníw. 3:1-8) Ó ṣe kedere pé bó ti ṣe pàtàkì pé ká máa ṣiṣẹ́ bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe pàtàkì ká máa wáyè sinmi. Ojú tó tọ́ ni Jésù fi wo iṣẹ́ àti ìsinmi. Bí àpẹẹrẹ, ìgbà kan wà tí Bíbélì ròyìn pé ọwọ́ àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ dí gan-an lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù débi pé “wọn ò . . . ní àkókò kankan tí ọwọ́ wọn dilẹ̀, kódà, wọn ò ráyè jẹun.” Jésù wá sọ ọ̀rọ̀ tó wà nínú ẹsẹ ojúmọ́ wa tòní fún wọn. (Máàkù 6:30-34) Lóòótọ́, kì í ṣe gbogbo ìgbà ni Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ máa ń ráyè sinmi, síbẹ̀ Jésù mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì káwọn sinmi. Nígbà míì, ó lè gba pé ká sinmi tàbí ká ṣe àwọn ìyípadà kan nínú bá a ṣe ń ṣiṣẹ́. Èyí ṣe kedere nínú ètò kan tí Jèhófà ṣe fáwọn èèyàn rẹ̀ nígbà àtijọ́, ìyẹn Sábáàtì táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń pa mọ́ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Òótọ́ ni pé a ò sí lábẹ́ Òfin Mósè, àmọ́ a lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ tá a bá ṣàyẹ̀wò ohun tí òfin yẹn sọ nípa Sábáàtì. w19.12 3 ¶6-7
Wednesday, October 20
Ẹ má ṣàníyàn láé.—Mát. 6:31.
Jèhófà ṣèlérí pé òun á pèsè fáwọn tó ń fi gbogbo ọkàn sin òun, ó sì máa ń rí i dájú pé òun ṣe bẹ́ẹ̀. (Sm. 31:1-3) Yàtọ̀ síyẹn, ara ìdílé Jèhófà ni wá, ó sì mọ̀ pé inú wa ò ní dùn tá ò bá rí ohun tá a nílò. Ẹ má sì gbàgbé ìlérí tó ṣe pé òun máa pèsè ohun tá a nílò nípa tara àti nípa tẹ̀mí, kò sì sí nǹkan tó lè ní kó má ṣe bẹ́ẹ̀! (Mát. 6:30-33; 24:45) Tá a bá ń ronú lórí ìdí tí Jèhófà fi máa ń mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ, a ò ní fòyà tá a bá níṣòro àtijẹ àtimu. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní. Nígbà tí ìjọ tó wà ní Jerúsálẹ́mù dojú kọ inúnibíni tó gbóná janjan, gbogbo àwọn ọmọ ẹ̀yìn ló tú ká àyàfi “àwọn àpọ́sítélì nìkan ni kò tú ká.” (Ìṣe 8:1) Kí lẹ rò pé ó máa ṣẹlẹ̀ sáwọn Kristẹni yẹn? Ó dájú pé àtijẹ àtimu á nira fún wọn gan-an! Ó ṣe tán, ọ̀pọ̀ wọn ti fi ilé àti iṣẹ́ wọn sílẹ̀. Síbẹ̀, Jèhófà ò gbàgbé wọn, bẹ́ẹ̀ làwọn náà sì ń láyọ̀. (Ìṣe 8:4; Héb. 13:5, 6; Jém. 1:2, 3) Ó dájú pé Jèhófà máa tì wá lẹ́yìn bó ṣe ti àwọn Kristẹni yẹn lẹ́yìn.—Sm. 37:18, 19. w20.01 17-18 ¶14-15
Thursday, October 21
Jèhófà . . . ń kíyè sí àwọn onírẹ̀lẹ̀.—Sm. 138:6.
Nígbà tí Dáfídì gba àgùntàn bàbá rẹ̀ lẹ́nu kìnnìún àti bíárì, ó dá a lójú pé Jèhófà ló ran òun lọ́wọ́ tí òun fi lè mú àwọn ẹranko ìgbẹ́ yẹn balẹ̀. Nígbà tó ṣẹ́gun Gòláyátì tó jẹ́ akínkanjú ọmọ ogun, ó dá Dáfídì lójú pé kì í ṣe agbára òun ló jẹ́ kíyẹn ṣeé ṣe bí kò ṣe Jèhófà tó wà pẹ̀lú òun. (1 Sám. 17:37) Nígbà tó bọ́ lọ́wọ́ Ọba Sọ́ọ̀lù tó ń ṣe ìlara rẹ̀, Dáfídì sọ gbangba-gbàǹgbà pé ọpẹ́lọpẹ́ Jèhófà ló jẹ́ kóun wà láàyè. (Sm. 18, àkọlé) Agbéraga èèyàn ò ní sọ ohun tí Dáfídì sọ yẹn, kàkà bẹ́ẹ̀ á sọ pé agbára òun ló jẹ́ kó ṣeé ṣe. Àmọ́ onírẹ̀lẹ̀ èèyàn ni Dáfídì, ìyẹn ló jẹ́ kó rọ́wọ́ Jèhófà láyé rẹ̀. Kí la rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ yìí? Kò yẹ ká kàn máa bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́. Ó tún yẹ ká máa kíyè sí ìgbà tó ń ràn wá lọ́wọ́ àti ọ̀nà tó ń gbà ṣe bẹ́ẹ̀. Tá a bá jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, tá a sì mọ̀wọ̀n ara wa, á rọrùn fún wa láti rí bí Jèhófà ṣe ń ràn wá lọ́wọ́. Tá a bá sì ń fara balẹ̀ kíyè sí bó ṣe ń ràn wá lọ́wọ́, àjọṣe wa pẹ̀lú rẹ̀ á túbọ̀ gún régé. w19.12 20 ¶18-19
Friday, October 22
Àwọn tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ló máa ń bá wí, bí bàbá ṣe máa ń fún ọmọ tí inú rẹ̀ dùn sí ní ìbáwí.—Òwe 3:12.
Ọ̀pọ̀ ìdí ló wà tá a fi gbà pé Jèhófà mọyì wa gan-an. Òun ló fà wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀ nípasẹ̀ ìhìn rere, ó sì kíyè sí i pé a nífẹ̀ẹ́ òtítọ́. (Jòh. 6:44) Bó ṣe di pé a bẹ̀rẹ̀ sí í sún mọ́ Jèhófà nìyẹn, òun náà sì túbọ̀ sún mọ́ wa. (Jém. 4:8) Torí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, ó máa ń lo okun rẹ̀ àti àkókò rẹ̀ láti kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́, ó sì máa ń tọ́ wa sọ́nà. Ó mọ irú ẹni tá a jẹ́ báyìí, ó sì tún mọ̀ pé a lè ṣe dáadáa sí i. Yàtọ̀ síyẹn, ó máa ń bá wa wí torí ìfẹ́ tó ní sí wa. Torí náà, ṣé àsọdùn ni tá a bá sọ pé Jèhófà mọyì wa, ó sì tún nífẹ̀ẹ́ wa gan-an? Kì í ṣe àsọdùn rárá, òótọ́ pọ́ńbélé ni! Ojú ẹni tí kò wúlò lọ̀pọ̀ fi wo Ọba Dáfídì, àmọ́ Dáfídì fúnra ẹ̀ mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ òun, ó sì ń ti òun lẹ́yìn. Èyí ló mú kí Dáfídì máa fojú tó tọ́ wo ìṣòro rẹ̀. (2 Sám. 16:5-7) Tí ìbànújẹ́ bá dorí wa kodò tàbí tá a níṣòro, Jèhófà lè mú ká fojú tó tọ́ wo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí wa, ó sì lè ràn wá lọ́wọ́ láti borí àwọn ìṣòro náà. (Sm. 18:27-29) Lọ́lá ìtìlẹyìn Jèhófà, kò sóhun tó lè ba ayọ̀ wa jẹ́ nínú ìjọsìn rẹ̀.—Róòmù 8:31. w20.01 15 ¶7-8
Saturday, October 23
Ẹ máa kọ́ wọn pé kí wọ́n máa pa gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún yín mọ́.—Mát. 28:20.
Máa fi àdúrà bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lọ́pọ̀ ìgbà, ohun tó dáa jù ni pé ẹ má jẹ́ kó pẹ́ sígbà tẹ́ ẹ bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ kẹ́ ẹ tó máa gbàdúrà níbẹ̀rẹ̀ àti ní ìparí, bóyá lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ mélòó kan tẹ́ ẹ bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Ó yẹ ká jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ wa mọ̀ pé èèyàn ò lè lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láìsí ìrànwọ́ ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà. Ohun táwọn ará kan máa ń ṣe kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà níbi ìkẹ́kọ̀ọ́ wọn ni pé wọ́n á ka Jémíìsì 1:5 tó sọ pé: “Tí ẹnikẹ́ni nínú yín ò bá ní ọgbọ́n, kó máa béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run.” Lẹ́yìn náà, wọ́n á bi akẹ́kọ̀ọ́ wọn pé, “Báwo la ṣe lè rí ọgbọ́n gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run?” Ó ṣeé ṣe kí akẹ́kọ̀ọ́ náà dáhùn pé àfi kéèyàn gbàdúrà. Jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ rẹ mọ bó ṣe lè máa gbàdúrà. Fi dá a lójú pé Jèhófà ṣe tán láti gbọ́ àdúrà àtọkànwá rẹ̀. Jẹ́ kó mọ̀ pé tá a bá ń gbàdúrà, a lè sọ gbogbo bí nǹkan ṣe rí lára wa fún Jèhófà títí kan àwọn ohun téèyàn ò lè sọ fún ẹlòmíì. Ó ṣe tán, kò sóhun tó wà lọ́kàn wa tí Jèhófà ò mọ̀.—Sm. 139:2-4. w20.01 2 ¶3; 5 ¶11-12
Sunday, October 24
Kò sí lọ́wọ́ ẹni tó ń fẹ́ tàbí lọ́wọ́ ìsapá ẹni náà, àmọ́ ọwọ́ Ọlọ́run.—Róòmù 9:16.
Jèhófà ló ń pinnu ìgbà tó máa fẹ̀mí yan ẹnì kan. (Róòmù 8:28-30) Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde ni Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í yan àwọn ẹni àmì òróró. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé gbogbo àwọn Kristẹni tòótọ́ tó wà ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ni ẹni àmì òróró. Láwọn ọdún tó tẹ̀ lé e, èyí tó pọ̀ jù lára àwọn tó pe ara wọn ní Kristẹni ni kò tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù. Síbẹ̀ náà, láàárín àwọn ọdún yẹn, Jèhófà fẹ̀mí yan ìwọ̀nba àwọn tó jẹ́ Kristẹni tòótọ́. Àwọn yẹn ló dà bí àlìkámà tí Jésù sọ pé ó máa wà láàárín àwọn èpò. (Mát. 13:24-30) Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, Jèhófà ṣì ń yan àwọn èèyàn tó máa wà lára àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) náà. Torí náà, bí Ọlọ́run bá pinnu láti yan àwọn kan lára wọn ní àkókò díẹ̀ kí òpin tó dé, ó dájú pé kò sẹ́ni tó lè yẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́ wò. (Róòmù 9:11) A gbọ́dọ̀ ṣọ́ra kí ọ̀rọ̀ wa má bàa dà bíi tàwọn òṣìṣẹ́ tí Jésù sọ nínú àkàwé kan tí wọ́n ń bínú sí ọ̀gá wọn torí iye owó tó san fún àwọn òṣìṣẹ́ tó dé kẹ́yìn.—Mát. 20:8-15. w20.01 30 ¶14
Monday, October 25
Àwọn ìránṣẹ́ mi máa kígbe ayọ̀.—Àìsá. 65:14.
Jèhófà fẹ́ káwọn tó wà nínú ìdílé rẹ̀ máa láyọ̀. Bó ti wù kí ìṣòro tá à ń kojú pọ̀ tó, a ní ìdí tó pọ̀ tó fi yẹ ká máa láyọ̀. Bí àpẹẹrẹ, ó dá wa lójú pé Jèhófà Baba wa ọ̀run nífẹ̀ẹ́ wa gan-an. A tún ní ìmọ̀ tó péye nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀. (Jer. 15:16) Yàtọ̀ síyẹn, a wà lára ìdílé tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, tí wọ́n ń fi àwọn ìlànà rẹ̀ ṣèwà hù, tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ ara wọn. (Sm. 106:4, 5) Ìdí míì tí inú wa fi ń dùn ni pé ó dájú pé ọjọ́ iwájú aláyọ̀ ń dúró dè wá. A mọ̀ pé láìpẹ́ Jèhófà máa pa gbogbo àwọn ẹni burúkú run, Ìjọba rẹ̀ á sì sọ ayé yìí di Párádísè. Yàtọ̀ síyẹn, ó dá wa lójú pé àwọn tó ti kú máa pa dà jíǹde, wọ́n á sì tún pa dà wà pẹ̀lú ìdílé wọn. (Jòh. 5:28, 29) Ẹ wo bí àsìkò yẹn ṣe máa dùn tó! Ohun tó ń fún wa láyọ̀ jù ni pé láìpẹ́ gbogbo ẹ̀dá tó wà láyé àti lọ́run lá máa jọ́sìn Baba wa ọ̀run, wọ́n á sì máa fún un ní ọlá, ìyìn àti ògo tó tọ́ sí i. w20.02 13 ¶15-16
Tuesday, October 26
Ìwọ gan-an ni mo dẹ́ṣẹ̀ sí.—Sm. 51:4.
Tó o bá dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì, má ṣe bò ó mọ́ra. Kàkà bẹ́ẹ̀, yíjú sí Jèhófà kó o sì jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ náà fún un. Wàá rí i pé ara máa tù ẹ́, ọkàn ẹ á sì fúyẹ́. Àmọ́ o, tó o bá fẹ́ kí àjọṣe ìwọ àti Jèhófà túbọ̀ dán mọ́rán, ohun míì wà tó o gbọ́dọ̀ ṣe lẹ́yìn tó o bá gbàdúrà. Ó yẹ kó o jẹ́ kí Jèhófà bá ẹ wí. Nígbà tí Jèhófà rán wòlíì Nátánì sí Ọba Dáfídì pé kó sọ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ fún un, Dáfídì kò wí àwíjàre bẹ́ẹ̀ sì ni kò fojú kéré ẹ̀ṣẹ̀ tó dá. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló gbà pé òun ti ṣẹ ọkọ Bátí-ṣébà, òun sì tún ṣẹ Jèhófà. Dáfídì gbà kí Jèhófà bá òun wí, Jèhófà náà sì dárí jì í. (2 Sám. 12:10-14) Torí náà, tá a bá dẹ́ṣẹ̀ tó wúwo tàbí ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì, ó yẹ ká sọ fún àwọn tí Jèhófà yàn sípò pé kí wọ́n máa bójú tó wa. (Jém. 5:14, 15) Ká má sì wí àwíjàre tí wọ́n bá ń ràn wá lọ́wọ́. Bó bá ṣe yá wa lára tó láti gba ìbáwí tí wọ́n fún wa, tá a sì ṣe àtúnṣe tó yẹ, bẹ́ẹ̀ lá ṣe rọrùn tó láti pa dà ní àlàáfíà àti ìbàlẹ̀ ọkàn. w20.02 24-25 ¶17-18
Wednesday, October 27
Ọkùnrin mẹ́wàá láti inú gbogbo èdè àwọn orílẹ̀-èdè yóò di aṣọ Júù kan mú . . . ṣinṣin, wọ́n á sì sọ pé: “A fẹ́ bá yín lọ, torí a ti gbọ́ pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú yín.”—Sek. 8:23.
Àwọn “ọkùnrin mẹ́wàá” náà dúró fún àwọn tó nírètí àtigbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé. Wọ́n mọ̀ pé Jèhófà ti bù kún àwùjọ àwọn ẹni àmì òróró tí “Júù” yẹn ṣàpẹẹrẹ , wọ́n sì gbà pé àǹfààní ńlá ni báwọn ṣe ń jọ́sìn Jèhófà pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹni àmì òróró. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò ṣeé ṣe láti mọ orúkọ gbogbo àwọn ẹni àmì òróró tó wà lórí ilẹ̀ ayé báyìí, àwọn tó nírètí àtigbé láyé ṣì lè “bá” àwọn ẹni àmì òróró lọ. Lọ́nà wo? Tẹ́ ẹ bá kíyè sí ẹsẹ ojúmọ́ tòní, ẹ̀ẹ́ rí i pé Júù kan péré ni ẹsẹ Bíbélì yìí mẹ́nu kàn. Àmọ́ ọ̀rọ̀ náà “yín” tí wọ́n lò lẹ́ẹ̀mejì nínú ẹsẹ yìí fi hàn pé ó ju ẹnì kan lọ. Èyí túmọ̀ sí pé kì í ṣe ẹnì kan ṣoṣo ni Júù náà ń tọ́ka sí, àmọ́ ó dúró fún àwùjọ àwọn ẹni àmì òróró lápapọ̀. Àwọn tí kì í ṣe ẹni àmì òróró ń sin Jèhófà pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹni àmì òróró. Àmọ́, wọn kì í wo àwọn ẹni àmì òróró bí aṣáájú wọn torí wọ́n mọ̀ pé Jésù nìkan ni Aṣáájú.—Mát. 23:10. w20.01 26 ¶1-2
Thursday, October 28
Èyí ni gbogbo èèyàn máa fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, tí ìfẹ́ bá wà láàárín yín.—Jòh. 13:35.
Jésù sọ pé á ṣeé ṣe fáwọn èèyàn láti dá àwọn Kristẹni tòótọ́ mọ̀ tí wọ́n bá ń fìfẹ́ hàn síra wọn bóun ṣe fi hàn sí wọn. Bó ti ṣe pàtàkì pé káwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní firú ìfẹ́ yìí hàn, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe kókó pé káwa náà fi hàn lónìí. Ẹ ò rí i pé ó bọ́gbọ́n mu gan-an pé ká má ṣe fàyè gba ohunkóhun tí kò ní jẹ́ ká fìfẹ́ hàn sáwọn ará wa! Bi ara ẹ pé: ‘Kí ni mo rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọ́n ń fìfẹ́ hàn bí kò tiẹ̀ rọrùn?’ Torí pé a jẹ́ aláìpé, ó lè ṣòro fún wa láti fi ìfẹ́ tó jinlẹ̀ hàn síra wa látọkàn wá. Bó ti wù kó rí, a gbọ́dọ̀ sapá láti fara wé Jésù Kristi. Jésù jẹ́ ká mọ bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká wá àlàáfíà pẹ̀lú arákùnrin tàbí arábìnrin tó ní ohun kan lòdì sí wa. (Mát. 5:23, 24) Ó jẹ́ kó ṣe kedere pé tá a bá máa rí ojúure Ọlọ́run, a gbọ́dọ̀ wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn míì. Inú Jèhófà máa ń dùn tá a bá ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti jẹ́ kí àlàáfíà jọba láàárín àwa àtàwọn arákùnrin wa. Kò ní tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wa tá a bá ń di ẹlòmíì sínú, tá ò sì wá bá a ṣe máa yanjú ọ̀rọ̀ náà.—1 Jòh. 4:20. w20.03 24 ¶1-4
Friday, October 29
[À] ń fìyàtọ̀ sí ọ̀rọ̀ òtítọ́ tó ní ìmísí àti ọ̀rọ̀ àṣìṣe tó ní ìmísí.—1 Jòh. 4:6.
Ọjọ́ pẹ́ tí Sátánì tó jẹ́ “baba irọ́” ti ń tan àwọn èèyàn jẹ, kódà ọ̀dọ̀ àwọn òbí wa àkọ́kọ́ ló ti bẹ̀rẹ̀. (Jòh. 8:44) Lára ẹ̀kọ́ èké tó fi ń ṣi àwọn èèyàn lọ́nà ni pé ọkàn èèyàn kì í kú. Ẹ̀kọ́ èké yìí ló bí àwọn àṣà tó wọ́pọ̀ lónìí àti ìgbàgbọ́ òdì nípa àwọn òkú. Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi gba irọ́ yìí gbọ́? Sátánì mọ bí ọ̀rọ̀ ikú ṣe máa ń rí lára wa, ìyẹn ló sì ń lò láti tan àwọn èèyàn jẹ. Kò sẹ́ni tó fẹ́ kú nínú wa, ó ṣe tán Ọlọ́run dá wa pé ká máa wà láàyè títí láé. (Oníw. 3:11) Kódà, a kì í fẹ́ gbọ́rọ̀ ikú sétí rárá, torí pé ọ̀tá wa ni. (1 Kọ́r. 15:26) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Sátánì ń sa gbogbo ipá rẹ̀ láti daṣọ bo òtítọ́ nípa àwọn òkú, síbẹ̀ pàbó ni gbogbo ìsapá rẹ̀ já sí. Ju ti ìgbàkígbà rí lọ, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti wá mọ ipò táwọn òkú wà àti ìrètí tí wọ́n ní, wọ́n sì ń sọ ọ́ fáráyé gbọ́. (Oníw. 9:5, 10; Ìṣe 24:15) Òtítọ́ yìí ń tuni nínú, ó sì ń fini lọ́kàn balẹ̀ pé kò sídìí láti máa bẹ̀rù ikú. w19.04 14 ¶1; 15 ¶5-6
Saturday, October 30
Ẹ máa bá ara yín gbé ẹrù tó wúwo, nípa bẹ́ẹ̀, ẹ ó mú òfin Kristi ṣẹ.—Gál. 6:2.
Jèhófà Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ àwọn tó ń jọ́sìn rẹ̀. Àtìgbà tó ti dá àwa èèyàn sáyé ló ti nífẹ̀ẹ́ wa, títí ayé lá sì máa ṣe bẹ́ẹ̀. Bákan náà, ó nífẹ̀ẹ́ ìdájọ́ òdodo. (Sm. 33:5) Torí náà, ohun méjì kan wà tó dá wa lójú: (1) Inú Jèhófà kì í dùn táwọn èèyàn bá fi ẹ̀tọ́ àwọn èèyàn rẹ̀ dù wọ́n. (2) Á rí i dájú pé àwọn ìránṣẹ́ òun rí ìdájọ́ òdodo gbà, ó sì máa fìyà jẹ àwọn tó ń fojú pọ́n wọn. Ìfẹ́ ni Òfin tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dá lé. Bákan náà, Òfin yẹn gbé ìdájọ́ òdodo lárugẹ, ìyẹn ìdájọ́ òdodo fún gbogbo èèyàn títí kan àwọn tí kò ní olùrànlọ́wọ́. (Diu. 10:18) Kò sí àní-àní pé Òfin yẹn jẹ́ kó túbọ̀ dá wa lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn tó ń jọ́sìn rẹ̀ gan-an. Òfin Mósè parí iṣẹ́ lọ́dún 33 Sànmánì Kristẹni nígbà tí ìjọ Kristẹni bẹ̀rẹ̀. Ṣéyẹn túmọ̀ sí pé àwa Kristẹni kò ní máa tẹ̀ lé òfin tá a gbé karí ìfẹ́, tó sì tún gbé ìdájọ́ òdodo lárugẹ? Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá! Àwa Kristẹni ní òfin tuntun tá à ń tẹ̀ lé. “Òfin Kristi” ló ń darí àwa Kristẹni. Ká sòótọ́, Jésù ò ṣe òfin jàn-àn-ràn jan-an-ran fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, àmọ́ ó fún wọn láwọn ìtọ́ni àtàwọn ìlànà tí wọ́n á máa tẹ̀ lé. Torí náà, gbogbo ohun tí Jésù fi kọ́ni ló para pọ̀ jẹ́ “òfin Kristi.” w19.05 2 ¶1-3
Sunday, October 31
Ọlọ́run ìtùnú gbogbo . . . ń tù wá nínú nínú gbogbo àdánwò wa.—2 Kọ́r. 1:3, 4.
Jèhófà dá àwa èèyàn lọ́nà tó ń mú kó máa wù wá pé káwọn míì tù wá nínú, káwa náà sì tù wọ́n nínú. Bí àpẹẹrẹ, ọmọdé kan lè ṣubú níbi tó ti ń ṣeré kó sì fi orúnkún bó, kó wá sunkún lọ bá mọ́mì tàbí dádì ẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn òbí rẹ̀ ò lè mú kí egbò náà jinná lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, síbẹ̀ wọ́n máa tù ú nínú. Wọ́n lè béèrè ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́ ẹ̀ tàbí kí wọ́n rẹ̀ ẹ́ lẹ́kún. Wọ́n tiẹ̀ lè fọwọ́ ra á lórí kára lè tù ú, lẹ́yìn náà wọ́n lè bá a fi nǹkan sójú egbò náà tàbí kí wọ́n fi báńdéèjì wé e. Ká tó ṣẹ́jú pẹ́, ọmọ náà tún lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣeré, tó bá sì yá egbò rẹ̀ á jinná. Àmọ́ nígbà míì, ọgbẹ́ táwọn ọmọdé kan ní máa ń burú ju èyí lọ. Ìdí sì ni pé wọ́n ti bá wọn ṣèṣekúṣe. Ó lè jẹ́ pé ẹ̀ẹ̀kan péré ni ìwà burúkú yìí wáyé tàbí kó tiẹ̀ ṣẹlẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún. Èyí ó wù kó jẹ́, ọgbẹ́ ọkàn tí èyí máa ń fà fún àwọn ọmọ náà kì í ṣe kékeré, ọgbẹ́ náà sì lè má jinná fún ọ̀pọ̀ ọdún. Nígbà míì, ọwọ́ pálábá ọ̀daràn náà lè ségi kí wọ́n sì fìyà tó tọ́ jẹ ẹ́, nígbà míì sì rèé, ó lè dà bíi pé ó mú un jẹ. Ká tiẹ̀ sọ pé wọ́n mú onítọ̀hún tí wọ́n sì fìyà jẹ ẹ́, ọgbẹ́ tó ti dá sọ́mọ náà lọ́kàn lè má jinná títí táá fi dàgbà. w19.05 14 ¶1-2