December
Wednesday, December 1
Ohun gbogbo ni àkókò wà fún . . . ìgbà dídákẹ́.—Oníw. 3:1, 7.
Tá ò bá kó ahọ́n wa níjàánu, ó lè kó wa síyọnu, ó sì lè ṣe jàǹbá fáwọn míì. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé o pàdé ẹnì kan tó ń gbé nílẹ̀ tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ wa, ṣé wàá fẹ́ kó sọ fún ẹ nípa ọgbọ́n tí wọ́n fi ń ṣèpàdé tí wọ́n sì fi ń wàásù? Kò sí àní-àní pé ohun tó dáa lo ní lọ́kàn. Ó ṣe tán a nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa, a sì máa ń fẹ́ mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí wọn. Yàtọ̀ síyẹn, a máa ń fẹ́ sọ ohun pàtó tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́ tá a bá ń gbàdúrà fún wọn. Àmọ́, irú àsìkò yìí ló yẹ ká ṣọ́ra, ká má bàá bi wọ́n nírú ìbéèrè bẹ́ẹ̀. Tá a bá ṣe ohun táá mú kí wọ́n sọ̀rọ̀ àṣírí bẹ́ẹ̀ fún wa, a ò fìfẹ́ hàn sí onítọ̀hún, a ò sì fìfẹ́ hàn sáwọn ará tó fọkàn tán ẹni náà pé kò ní sọ ọ́ fáwọn míì. Ó dájú pé kò sẹ́nì kankan nínú wa tó máa fẹ́ kí nǹkan túbọ̀ nira fáwọn ará tó ń gbé láwọn ilẹ̀ tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ wa. Bákan náà, kò sí ìkankan nínú àwọn ará tó wà nírú ilẹ̀ bẹ́ẹ̀ tó máa fẹ́ sọ ọgbọ́n tí wọ́n fi ń ṣèpàdé tí wọ́n sì fi ń wàásù fún ẹlòmíì. w20.03 21 ¶11-12
Thursday, December 2
Ó dájú pé ẹ ò ní kú.—Jẹ́n. 3:4.
Ọlọ́run ò fẹ́ káwa èèyàn máa kú. Àmọ́ tí Ádámù àti Éfà bá máa wà láàyè títí láé, wọ́n gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Jèhófà. Òfin tó fún wọn ò sì nira, ó ní: ‘Ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ èso igi ìmọ̀ rere àti búburú, torí ó dájú pé ọjọ́ tí ẹ bá jẹ ẹ́ lẹ máa kú.’ (Jẹ́n. 2:16, 17) Nígbà tí Sátánì máa gbé ìṣe ẹ̀ dé, ó fi ejò bojú, ó sì sọ ọ̀rọ̀ tó wà nínú ẹsẹ ojúmọ́ wa tòní fún Éfà. Ó bani nínú jẹ́ pé Éfà gba irọ́ yẹn gbọ́, ó sì jẹ èso náà. Nígbà tó yá, ọkọ rẹ̀ náà jẹ èso yẹn. (Jẹ́n. 3:6) Bó ṣe di pé aráyé ń dẹ́ṣẹ̀ tá a sì ń kú nìyẹn. (Róòmù 5:12) Ádámù àti Éfà kú bí Ọlọ́run ṣe sọ. Àmọ́ Sátánì ò ṣíwọ́ irọ́ pípa. Nígbà tó yá, ó tún pa àwọn irọ́ míì nípa ipò táwọn òkú wà. Lára irọ́ náà ni pé téèyàn bá kú, ohun kan wà tó máa ń jáde lára ẹ̀ táá sì máa rìn káàkiri. Onírúurú ọ̀nà ni wọ́n ti gbà tan irọ́ yìí kálẹ̀, ó sì ń ṣi ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́nà títí dòní olónìí.—1 Tím. 4:1. w19.04 14-15 ¶3-4
Friday, December 3
Nígbà tí mo wà lọ́mọdé, mo máa ń sọ̀rọ̀ bí ọmọdé, mò ń ronú bí ọmọdé, mo sì ń gbèrò bí ọmọdé.—1 Kọ́r. 13:11.
Àwọn ọmọdé ò tíì gbọ́n, wọn ò sì lè ronú jinlẹ̀ débi tí wọ́n á fi mọ ohun tó lè wu wọ́n léwu tàbí bí wọ́n ṣe lè yẹra fún un. Torí náà, ó rọrùn gan-an fáwọn èèyànkéèyàn láti tan àwọn ọmọdé jẹ. Oríṣiríṣi irọ́ burúkú làwọn tó ń bọ́mọdé ṣèṣekúṣe máa ń pa fún wọn. Wọ́n lè sọ pé ẹ̀bi ọmọ náà lohun tó ṣẹlẹ̀ tàbí pé kò gbọ́dọ̀ sọ fún ẹnikẹ́ni torí tó bá sọ, kò sẹ́ni tó máa gbà á gbọ́. Wọ́n tún lè parọ́ fún un pé ọ̀nà tí àgbàlagbà máa ń gbà fìfẹ́ hàn sọ́mọdé nìyẹn. Irú àwọn irọ́ bẹ́ẹ̀ máa ń jẹ́ káwọn ọmọdé ní èrò òdì, ó sì lè gba ọ̀pọ̀ ọdún kí wọ́n tó mọ̀ pé irọ́ ni gbogbo ohun tẹ́ni náà sọ. Bí ọmọ náà ṣe ń dàgbà, ó lè máa ronú pé ayé òun ti bà jẹ́, òun ò wúlò, kò sẹ́ni tó máa fìfẹ́ hàn sóun, òun ò sì lè rí ìtùnú. Ó ṣe kedere pé ọgbẹ́ ọkàn tí kì í jinná bọ̀rọ̀ làwọn tí wọ́n ti bá ṣèṣekúṣe lọ́mọdé máa ń ní. Bí ìwà burúkú yìí ṣe gbòde kan jẹ́ kó hàn gbangba pé àwọn ọjọ́ ìkẹyìn la wà, ìyẹn àsìkò tí ọ̀pọ̀ “kò ní ìfẹ́ àdámọ́ni,” tí ‘àwọn èèyàn burúkú àti àwọn afàwọ̀rajà sì ń burú sí i.’—2 Tím. 3:1-5, 13. w19.05 15 ¶7-8
Saturday, December 4
Ẹ ó mú òfin Kristi ṣẹ.—Gál. 6:2.
Ọ̀nà wo ni Jésù gbà kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́? Lákọ̀ọ́kọ́, ó kọ́ wọn nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹnu. Àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ lágbára torí pé òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló fi kọ́ni, ó jẹ́ káwọn èèyàn mọ ohun tí wọ́n lè fayé wọn ṣe, ó sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló máa fòpin sí ìyà tó ń jẹ aráyé. (Lúùkù 24:19) Jésù tún kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ nípasẹ̀ àpẹẹrẹ tó fi lélẹ̀. Àpẹẹrẹ rẹ̀ mú káwọn ọmọlẹ́yìn náà rí bó ṣe yẹ kí wọ́n gbé ìgbé ayé wọn. (Jòh. 13:15) Ìgbà wo ni Jésù kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́? Ó ṣe bẹ́ẹ̀ ní gbogbo àsìkò tó fi ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ láyé. (Mát. 4:23) Ó tún kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ kété lẹ́yìn tó jíǹde. Bí àpẹẹrẹ, ìgbà kan wà tó fara han àwọn ọmọlẹ́yìn tó lé lọ́gọ́rùn-ún márùn-ún (500), ó sì pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n máa ‘sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn.’ (Mát. 28:19, 20; 1 Kọ́r. 15:6) Torí pé Jésù ni orí ìjọ, ó ṣì ń fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ní ìtọ́ni kódà lẹ́yìn tó pa dà sí ọ̀run. Àpẹẹrẹ kan lohun tó ṣe ní nǹkan bí ọdún 96 Sànmánì Kristẹni. Ó rán àpọ́sítélì Jòhánù pé kó fún àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró níṣìírí, kó sì tún fún wọn nímọ̀ràn.—Kól. 1:18; Ìfi. 1:1. w19.05 3 ¶4-5
Sunday, December 5
Máa wádìí dájú àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù.—Fílí. 1:10.
Àtijẹ-àtimu ò rọrùn rárá láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí. Ọ̀pọ̀ àwọn ará wa ló ń fi ọ̀pọ̀ wákàtí ṣiṣẹ́ kí wọ́n tó lè pèsè àwọn nǹkan kòṣeémáàní fún ìdílé wọn. Ọ̀pọ̀ wákàtí sì làwọn míì máa ń lò lójú ọ̀nà ibi iṣẹ́ wọn lójoojúmọ́. Iṣẹ́ àṣelàágùn làwọn kan ń ṣe, tí wọ́n bá sì máa fi délé á ti rẹ̀ wọ́n tẹnutẹnu. Tó bá wá di pé kí wọ́n gbé ìwé láti kà, kò ní rọrùn. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé a gbọ́dọ̀ wáyè láti máa dá kẹ́kọ̀ọ́. Èyí kọjá pé ká kàn ka ìwé, a gbọ́dọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àtàwọn ìtẹ̀jáde ètò Ọlọ́run. Tá a bá fẹ́ ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà tá a sì fẹ́ jogún ìyè àìnípẹ̀kun, ó ṣe pàtàkì gan-an ká máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (1 Tím. 4:15) Àárọ̀ kùtùkùtù làwọn kan máa ń jí kí wọ́n lè kẹ́kọ̀ọ́ torí pé ilé máa ń pa rọ́rọ́ lásìkò yẹn, wọ́n á sì lè pọkàn pọ̀. Àwọn míì máa ń lo àkókò díẹ̀ lálẹ́ kí wọ́n tó lọ sùn láti kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n sì máa ń ṣàṣàrò lé e lórí. w19.05 26 ¶1-2
Monday, December 6
Ẹ má sì jẹ́ kí ètò àwọn nǹkan yìí máa darí yín, àmọ́ ẹ para dà nípa yíyí èrò inú yín pa dà.—Róòmù 12:2.
A ò lè ṣe àwọn ìyípadà yìí ní ọ̀sán kan òru kan, bẹ́ẹ̀ sì ni kì í ṣàdédé wáyé. Ó gba pé ká sapá gan-an fún ọ̀pọ̀ ọdún. (2 Pét. 1:5) Ó yẹ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti yí irú ẹni tá a jẹ́ nínú pa dà. Àdúrà ni ohun àkọ́kọ́ tó ṣe pàtàkì. Ó ṣe pàtàkì pé ká gbàdúrà bíi ti onísáàmù pé: “Dá ọkàn mímọ́ sí inú mi, Ọlọ́run, kí o sì fi ẹ̀mí tuntun sí inú mi, èyí tó fìdí múlẹ̀.” (Sm. 51:10) Àwa fúnra wa gbọ́dọ̀ gbà pé ó yẹ ká yí ìrònú wa pa dà ká sì bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́. Ohun pàtàkì kejì ni pé ká máa ṣàṣàrò. Ó yẹ ká máa fara balẹ̀ ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́, ká sì rí i pé à ń ṣàṣàrò ká lè mọ àwọn ìyípadà tó yẹ ká ṣe nínú èrò àti ìṣe wa. (Sm. 119:59; Héb. 4:12; Jém. 1:25) Ó yẹ ká kíyè sí i bóyá a ti bẹ̀rẹ̀ sí í nífẹ̀ẹ́ sí ohun táwọn èèyàn ń gbé lárugẹ. Ó ṣe pàtàkì ká mọ ibi tá a kù sí, ká gbà pé lóòótọ́ la kù síbẹ̀, ká sì sapá gidigidi láti borí àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ wa. w19.06 8 ¶1; 10 ¶10; 12 ¶11-12
Tuesday, December 7
Ẹ máa lo àkókò yín lọ́nà tó dára jù lọ.—Éfé. 5:16.
Tó o bá fẹ́ ṣèpinnu, yan àkókò tó o fẹ́ ṣe ohun tó o pinnu, kó o sì rí i pé àkókò náà lò ń ṣe é. Má ronú pé àsìkò kan ń bọ̀ tó máa túbọ̀ rọ̀ ẹ́ lọ́rùn láti ṣe ohun tó o fẹ́ ṣe, òótọ́ ibẹ̀ ni pé àsìkò yẹn lè má dé láé. (Oníw. 11:4) Má ṣe jẹ́ káwọn nǹkan tí kò fi bẹ́ẹ̀ pọn dandan gbà ẹ́ lákòókò débi pé o ò wá ní lágbára láti ṣe àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì. (Fílí. 1:10) Tó bá ṣeé ṣe, fi sí àkókò táwọn èèyàn ò ti ní dà ẹ́ láàmú púpọ̀. Jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé àwọn ìgbà kan wà tí wọn ò ní lè rí ẹ bá sọ̀rọ̀. Nírú àwọn àkókò bẹ́ẹ̀, o lè pa fóònù ẹ, kó o sì fi wíwo àwọn àtẹ̀jíṣẹ́ tàbí ìkànnì àjọlò sígbà míì. A lè fi ìpinnu tá à ń ṣe wé ìrìn àjò, ibi tí ìpinnu náà máa yọrí sí ló sì dà bí ibi téèyàn ń lọ. Tó o bá fẹ́ dé ibi tó ò ń lọ, o ò ní jẹ́ kí ohunkóhun dá ẹ dúró. Tí wọ́n bá tiẹ̀ dí ọ̀nà, wàá lọ gba ibòmíì kó o lè dé ibi tó ò ń lọ. Lọ́nà kan náà, tó o bá pọkàn pọ̀ sórí àǹfààní tí wàá rí, wàá dúró lórí ìpinnu rẹ tó o bá tiẹ̀ kojú ìṣòro tàbí ìpèníjà.—Gál. 6:9. w19.11 30 ¶17-18
Wednesday, December 8
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run . . . lè mọ ìrònú àti ohun tí ọkàn ń gbèrò.—Héb. 4:12.
Kí nìdí tó ṣe pàtàkì jù tó fi yẹ kó o pinnu pé wàá ṣèrìbọmi? Torí pé o fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ọ̀pọ̀ nǹkan lo ti mọ̀ nípa Jèhófà, o mọ àwọn ànímọ́ rẹ̀, àwọn ohun tó fẹ́ àtohun tí kò fẹ́. Àwọn ohun tó o kọ́ yìí múnú rẹ dùn, ó sì mú kó o nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an. Torí náà, ìfẹ́ tó o ní fún Jèhófà ni ìdí tó ṣe pàtàkì jù tó fi yẹ kó o pinnu pé wàá ṣèrìbọmi. Ìdí míì tó fi yẹ kó o pinnu pé wàá ṣèrìbọmi ni pé o kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, o sì gba àwọn ẹ̀kọ́ náà gbọ́. Àpẹẹrẹ kan lohun tí Jésù sọ nígbà tó pàṣẹ pé ká máa sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn. (Mát. 28:19, 20) Bí Jésù ṣe sọ, àwọn tó fẹ́ ṣèrìbọmi gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ “ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́.” Kí ni èyí túmọ̀ sí? Ohun tó ń sọ ni pé o gbọ́dọ̀ gba ohun tí Bíbélì sọ nípa Jèhófà, Jésù Ọmọ rẹ̀ àti ẹ̀mí mímọ́ gbọ́ láìsí-tàbí-ṣùgbọ́n. Ẹ̀kọ́ òtítọ́ yìí lágbára gan-an, ó sì lè mú kéèyàn pinnu àtiṣe ohun tó tọ́. w20.03 9 ¶8-9
Thursday, December 9
Ẹ máa kìlọ̀ fún àwọn tó ń ṣe ségesège, . . . ẹ máa ran àwọn aláìlera lọ́wọ́, ẹ máa mú sùúrù fún gbogbo èèyàn.—1 Tẹs. 5:14.
Jèhófà rán àwọn áńgẹ́lì sí Lọ́ọ̀tì kí wọ́n lè kìlọ̀ fún un, àmọ́ ó tún fẹ́ kí wọ́n ràn án lọ́wọ́ kó lè la ìparun Sódómù já. (Jẹ́n. 19:12-14, 17) Lọ́nà kan náà, ó yẹ ká kìlọ̀ fún arákùnrin tàbí arábìnrin kan tá a bá rí i pé ohun tó fẹ́ ṣe lè kó o síṣòro. Àmọ́, tá a bá rí i pé kò tètè fi àwọn ìmọ̀ràn Bíbélì sílò, ó yẹ ká mú sùúrù fún un, ká ṣe bíi tàwọn áńgẹ́lì méjì yẹn. Dípò tá a fi máa pa á tì, ṣe ló yẹ ká ronú ohun pàtó tá a lè ṣe fún un. (1 Jòh. 3:18) A lè gbá ọwọ́ rẹ̀ mú lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, ká sì ràn án lọ́wọ́ kó lè fi àwọn ìmọ̀ràn tí wọ́n fún un sílò. Kì í ṣe àwọn àṣìṣe Lọ́ọ̀tì ni Jèhófà gbájú mọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, nínú lẹ́tà tí Ọlọ́run mí sí àpọ́sítélì Pétérù láti kọ, ó pe Lọ́ọ̀tì ní olódodo. (Sm. 130:3) Báwo làwa náà ṣe lè fara wé Jèhófà? Tó bá jẹ́ pé ibi táwọn ará wa dáa sí là ń wò, ìyẹn á jẹ́ ká túbọ̀ máa mú sùúrù fún wọn. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, á túbọ̀ yá wọn lára láti fi ìmọ̀ràn wa sílò. w19.06 21 ¶6-7
Friday, December 10
Kálukú ló máa ru ẹrù ara rẹ̀.—Gál. 6:5.
Tí ìjọba bá fòfin de ìjọsìn wa lórílẹ̀-èdè tó ò ń gbé, o lè máa ronú pé kó o ṣí lọ sórílẹ̀-èdè míì níbi tí wàá ti lè jọ́sìn Jèhófà bó o ṣe fẹ́. Ìwọ fúnra rẹ lo máa pinnu bóyá kó o ṣe bẹ́ẹ̀ tàbí kó o má ṣe bẹ́ẹ̀. Àwọn kan lè ronú nípa ohun táwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ṣe nígbà tí wọ́n ṣenúnibíni sí wọn. Àwọn kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó wà ní Jerúsálẹ́mù ṣí lọ sáwọn agbègbè Jùdíà àti Samáríà. Kódà, àwọn kan lọ sí Foníṣíà, Sápírọ́sì àti Áńtíókù. (Mát. 10:23; Ìṣe 8:1; 11:19) Nígbà tí wọ́n ṣenúnibíni sáwọn Kristẹni lẹ́yìn ìgbà yẹn, Pọ́ọ̀lù pinnu láti dúró lágbègbè tí wọ́n ti ń ṣenúnibíni yẹn. (Ìṣe 14:19-23) Kí la rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ méjèèjì yìí? Ẹ̀kọ́ náà ni pé olórí ìdílé kọ̀ọ̀kan ló máa pinnu ohun tí ìdílé rẹ̀ máa ṣe. Kó tó ṣèpinnu bóyá káwọn lọ síbòmíì tàbí káwọn dúró, ó ṣe pàtàkì kó gbàdúrà, kó sì fara balẹ̀ gbé ipò ìdílé rẹ̀ yẹ̀ wò. Á dáa kó ronú nípa àǹfààní tí ṣíṣí lọ máa ṣe wọ́n àti ewu tó lè fà fún wọn. A ò gbọ́dọ̀ dá ẹnikẹ́ni lẹ́jọ́ fún ìpinnu èyíkéyìí tó bá ṣe. w19.07 10 ¶8-9
Saturday, December 11
Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, pé kí wọ́n wá mọ ìwọ Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo àti Jésù Kristi, ẹni tí o rán.—Jòh. 17:3.
Jésù sọ fún wa pé “ẹ lọ, kí ẹ máa sọ àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.” (Mát. 28:19) Yàtọ̀ sí pé ká jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ kan mọ àwọn ìlànà tí Jésù fi lélẹ̀ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, a tún gbọ́dọ̀ jẹ́ kí wọ́n mọ bí wọ́n ṣe lè máa fi àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ ṣèwà hù nígbèésí ayé wọn. Èyí máa gba pé ká ní sùúrù fún wọn bí wọ́n ṣe ń gbìyànjú láti fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò. Kì í pẹ́ táwọn kan fi máa ń yí ìgbésí ayé wọn pa dà, àmọ́ ó máa ń pẹ́ káwọn míì tó lè ṣe bẹ́ẹ̀. Míṣọ́nnárì kan lórílẹ̀-èdè Peru sọ ìrírí kan tó jẹ́ ká rí ìdí tó fi yẹ ká máa ní sùúrù. Arákùnrin náà sọ pé: “A ti parí ìwé méjèèjì tá a fi ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú Raúl, àmọ́ ó ṣì ń nira fún un láti ṣe àwọn àtúnṣe kan. Bí àpẹẹrẹ, àárín òun àti ìyàwó rẹ̀ ò gún, ó máa ń bú èébú, àwọn ọmọ rẹ̀ sì máa ń gbó o lẹ́nu. Torí pé ó máa ń wá sípàdé déédéé, mi ò ṣíwọ́ lílọ sọ́dọ̀ rẹ̀ kí n lè ran òun àti ìdílé rẹ̀ lọ́wọ́. Ẹ̀yìn ọdún mẹ́ta tá a ti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ ló tó ṣèrìbọmi.” w19.07 15 ¶3; 19 ¶15-17
Sunday, December 12
Ẹ sa gbogbo ipá yín.—Lúùkù 13:24.
Báwo ni nǹkan ṣe rí fún Pọ́ọ̀lù lásìkò tó kọ̀wé sí àwọn ará Fílípì? Àtìmọ́lé ló wà nílùú Róòmù, kò sì láǹfààní láti jáde lọ wàásù. Àmọ́, ó máa ń wàásù fáwọn tó bá wá kí i, ó sì ń kọ lẹ́tà sáwọn ìjọ tó wà káàkiri. Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé bíi ti Kristi, òun gbọ́dọ̀ sa gbogbo ipá òun títí dópin. Ìdí nìyẹn tó fi fi àwa Kristẹni wé àwọn tó ń sá eré ìje. (1 Kọ́r. 9:24-27) Kí sárésáré kan tó lè sáré dópin, ó gbọ́dọ̀ gbájú mọ́ ibi tó ń lọ, kí ohunkóhun má sì pín ọkàn rẹ̀ níyà. Bí àpẹẹrẹ, àwọn tó ń sáré lónìí lè gba ojú ọ̀nà táwọn èèyàn ti ń tajà tàbí tí wọ́n ti ń ṣe nǹkan míì tó ń gbàfiyèsí. Ǹjẹ́ ẹ ronú pé sárésáré kan máa dúró, á sì máa yẹ àwọn ọjà tí wọ́n ń tà ní ṣọ́ọ̀bù kan wò? Ó dájú pé kò ní ṣe bẹ́ẹ̀ tó bá fẹ́ gbégbá orókè! Bákan náà, nínú eré ìje ìyè, a gbọ́dọ̀ yẹra fún gbogbo nǹkan tó lè pín ọkàn wa níyà. Tá a bá gbájú mọ́ èrè tó wà níwájú wa, tá a sì ń sapá gan-an bíi ti Pọ́ọ̀lù, a máa gba èrè náà! w19.08 3 ¶4; 4 ¶7
Monday, December 13
Máa kíyè sí ara rẹ àti ẹ̀kọ́ rẹ nígbà gbogbo. . . . Tí o bá ń ṣe é, wàá lè gba ara rẹ àti àwọn tó ń fetí sí ọ là.—1 Tím. 4:16.
Nígbà tá a di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó lè má rọrùn fáwọn mọ̀lẹ́bí wa láti fara mọ́ ohun tuntun tá a gbà gbọ́. Lọ́pọ̀ ìgbà, ohun tí wọ́n máa ń kọ́kọ́ kíyè sí ni pé a ò bá wọn ṣọdún mọ́, a ò sì dá sọ́rọ̀ òṣèlú. Ìyẹn lè mú káwọn kan lára wọn máa bínú sí wa. (Mát. 10:35, 36) Àmọ́, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kọ́rọ̀ wọn sú wa. Tá a bá jẹ́ kọ́rọ̀ wọn sú wa, tá ò sì wàásù fún wọn mọ́, ṣe ló dà bíi pé a ti dá wọn lẹ́jọ́ pé wọn ò yẹ lẹ́ni tó ń jèrè ìyè àìnípẹ̀kun. Kì í ṣe àwa ni Jèhófà yàn láti dá àwọn èèyàn lẹ́jọ́, Jésù ló gbéṣẹ́ náà fún. (Jòh. 5:22) Tá a bá ṣe sùúrù, ó ṣeé ṣe káwọn mọ̀lẹ́bí wa pa dà fetí sí wa. Ó yẹ ká sòótọ́ fún àwọn mọ̀lẹ́bí wa, síbẹ̀ ká fi ọgbọ́n ṣe é bí wọ́n tiẹ̀ ń ṣe inúnibíni sí wa. (1 Kọ́r. 4:12b) Àwọn mọ̀lẹ́bí wa lè má tètè lóye pé ìjọsìn Jèhófà ṣe pàtàkì sí wa gan-an. w19.08 17 ¶10, 13; 18 ¶14
Tuesday, December 14
Mo ní okun láti ṣe ohun gbogbo nípasẹ̀ ẹni tó ń fún mi lágbára.—Fílí. 4:13.
Táwọn kan bá ń ronú nípa ohun tí wọ́n ti fara dà, wọ́n máa ń sọ pé Jèhófà ló ran àwọn lọ́wọ́, kì í ṣe agbára àwọn. Ṣé ìwọ náà ti sọ bẹ́ẹ̀ rí, bóyá lẹ́yìn tó o fara da àìsàn tó le gan-an tàbí lẹ́yìn ikú ẹnì kan tó o fẹ́ràn? Nígbà tó o wá ń ronú nípa àwọn nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn, o rí i pé Jèhófà ló fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ràn ẹ́ lọ́wọ́ tó o fi ní “agbára tó kọjá ti ẹ̀dá.” (2 Kọ́r. 4:7-9) Yàtọ̀ síyẹn, a tún nílò ẹ̀mí mímọ́ kí ayé yìí má bàa kéèràn ràn wá. (1 Jòh. 5:19) Bákan náà, a nílò ẹ̀mí mímọ́ ká lè bá àwọn “ẹ̀mí burúkú” wọ̀yá ìjà. (Éfé. 6:12) Ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà máa ń ràn wá lọ́wọ́ ní ti pé ó máa ń fún wa lágbára tàbí okun ká lè ṣe gbogbo ohun tó yẹ láìka ìṣòro wa sí. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbà pé “agbára Kristi” ló ran òun lọ́wọ́ láti máa fara dà á kóun sì ṣiṣẹ́ òjíṣẹ́ òun yanjú.—2 Kọ́r. 12:9. w19.11 8 ¶1-3
Wednesday, December 15
Ẹnikẹ́ni tó bá ti rí mi ti rí Baba náà.—Jòh. 14:9.
Bíbélì nìkan ló sọ ohun tó péye nípa Jésù àtohun tó ṣe fún ẹ. Nífẹ̀ẹ́ Jésù kó o lè túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Kí nìdí? Ìdí ni pé Jésù gbé àwọn ànímọ́ Jèhófà yọ lọ́nà tó pé pérépéré. Torí náà, bó o ṣe túbọ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jésù, bẹ́ẹ̀ ni wàá túbọ̀ lóye ẹni tí Jèhófà jẹ́, wàá sì mọyì rẹ̀. Ronú nípa bí Jésù ṣe fi àánú hàn sáwọn tí aráyé kò kà sí, ìyẹn àwọn tálákà, àwọn tó ń ṣàìsàn àtàwọn tí kò ní olùrànlọ́wọ́. Tún ronú nípa àwọn ìmọ̀ràn tí Jésù fún ẹ nínú ìwàásù rẹ̀ àti àǹfààní tó ò ń rí bó o ṣe ń fi ẹ̀kọ́ rẹ̀ sílò láyé rẹ. (Mát. 5:1-11; 7:24-27) Wàá túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jésù bó o ṣe ń ronú nípa bó ṣe fẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ kí Ọlọ́run lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá. (Mát. 20:28) Tó bá yé ẹ pé torí tìẹ ni Jésù ṣe fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀, wàá ronú pìwà dà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ, wàá sì bẹ Jèhófà pé kó dárí jì ẹ́. (Ìṣe 3:19, 20; 1 Jòh. 1:9) Bó o ṣe túbọ̀ ń nífẹ̀ẹ́ Jésù àti Jèhófà, bẹ́ẹ̀ lá máa wù ẹ́ láti wà pẹ̀lú àwọn tó ti ṣe bẹ́ẹ̀. w20.03 5-6 ¶10-12
Thursday, December 16
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ga, ó ń kíyè sí àwọn onírẹ̀lẹ̀.—Sm. 138:6.
Arákùnrin kan lè bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé òun lòun tóótun fún àǹfààní iṣẹ́ ìsìn kan. Arábìnrin kan sì lè máa sọ lọ́kàn ẹ̀ pé, ‘Ọkọ mi tóótun ju ẹni tí wọ́n fún láǹfààní iṣẹ́ ìsìn yẹn lọ.’ Àmọ́ tá a bá lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ lóòótọ́, a ò ní fàyè gba irú èrò bẹ́ẹ̀. A lè kẹ́kọ̀ọ́ látinú ohun tí Mósè ṣe nígbà táwọn míì gba àǹfààní iṣẹ́ ìsìn. Mósè mọyì àǹfààní tó ní láti jẹ́ aṣáájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Ṣùgbọ́n nígbà tí Jèhófà yan àwọn míì láti bá Mósè ṣiṣẹ́, ṣé Mósè jowú wọn? Rárá, kò ṣe bẹ́ẹ̀. (Nọ́ń. 11:24- 29) Mósè lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, ó sì gbà káwọn míì máa ṣèdájọ́ àwọn èèyàn náà. (Ẹ́kís. 18:13- 24) Èyí mú kó rọrùn fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti tètè yanjú àwọn ẹjọ́ wọn torí pé Mósè nìkan kọ́ ló ń ṣèdájọ́. Ìyẹn jẹ́ ká rí i pé ire àwọn èèyàn ló jẹ Mósè lọ́kàn kì í ṣe àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tó ní. Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ àtàtà nìyẹn jẹ́ fáwa náà lónìí! Ká rántí pé ká tó lè wúlò fún Jèhófà, ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ wa gbọ́dọ̀ ju ẹ̀bùn èyíkéyìí tá a ní lọ. w19.09 5-6 ¶13-14
Friday, December 17
Jèhófà ń dáàbò bo àwọn olóòótọ́.—Sm. 31:23.
A ò mọ ohun táwọn orílẹ̀-èdè máa sọ pé àwọn fẹ́ tìtorí ẹ̀ pa Bábílónì Ńlá run. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n sọ pé àwọn ẹ̀sìn ni kò jẹ́ kí ìlú fara rọ àti pé ìgbà gbogbo ni wọ́n máa ń tojú bọ ọ̀rọ̀ òṣèlú. Wọ́n sì lè sọ pé ọrọ̀ àti dúkìá tí wọ́n kó jọ ti pọ̀ jù. (Ìfi. 18:3, 7) Àmọ́ ti pé wọ́n máa pa ẹ̀sìn èké run kò túmọ̀ sí pé gbogbo àwọn tó ń ṣe ẹ̀sìn èké ló máa pa run. Dípò bẹ́ẹ̀, ètò ẹ̀sìn lápapọ̀ ni wọ́n máa pa run. Tí gbogbo ẹ̀sìn èké bá ti pa run, àwọn tó ń ṣe ẹ̀sìn yẹn tẹ́lẹ̀ á wá rí i pé ńṣe làwọn olórí ẹ̀sìn kàn tan àwọn jẹ, wọ́n sì lè sọ pé àwọn ò ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú ẹ̀sìn. Kò ní pẹ́ tí Bábílónì Ńlá fi máa pa run, kò ní pẹ́ rárá. (Ìfi. 18:10, 21) Jèhófà ti ṣèlérí pé òun máa “dín àwọn ọjọ́ náà kù,” ìyẹn àsìkò tí ìpọ́njú ńlá máa gbà kí ìsìn tòótọ́ àti “àwọn àyànfẹ́” lè là á já.—Máàkù 13:19, 20. w19.10 15 ¶4-5
Saturday, December 18
Gba àwọn ọ̀dọ́bìnrin níyànjú . . . láti nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ wọn.—Títù 2:4.
Ẹ̀yin ìyá, ó lè jẹ́ pé àwọn òbí tó máa ń tètè bínú ló tọ́ yín dàgbà, wọ́n sì máa ń fìbínú sọ̀rọ̀ sí yín. Torí náà, ẹ lè ronú pé bó ṣe yẹ kẹ́ ẹ tọ́ àwọn ọmọ yín nìyẹn. Ní báyìí tẹ́ ẹ ti mọ ohun tí Jèhófà fẹ́ kẹ́ ẹ ṣe, ó lè má rọrùn láti fi pẹ̀lẹ́tù sọ̀rọ̀ pàápàá táwọn ọmọ yín bá ṣẹ̀ lásìkò tó ti rẹ̀ yín tẹnutẹnu. (Éfé. 4:31) Nírú àsìkò bẹ́ẹ̀, ó ṣe pàtàkì gan-an pé kẹ́ ẹ gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn yín lọ́wọ́. (Sm. 37:5) Ìṣòro táwọn ìyá kan ní ni pé wọn ò mọ bí wọ́n ṣe lè fìfẹ́ hàn sáwọn ọmọ wọn. Ìdí sì ni pé inú ilé tí wọn ò ti mọ bí wọ́n ṣe ń fìfẹ́ hàn sáwọn ọmọ ni wọ́n ti tọ́ àwọn míì dàgbà. Tó bá jẹ́ pé irú ilé bẹ́ẹ̀ lo dàgbà sí, kò di dandan pé kó o ṣe irú àṣìṣe táwọn òbí ẹ ṣe. Ìyá kan tó fi ara ẹ̀ sábẹ́ Jèhófà máa kọ́ béèyàn ṣe ń fìfẹ́ hàn sáwọn ọmọ rẹ̀. Ó lè má rọrùn láti yí bó o ṣe ń ronú pa dà lóòótọ́, àmọ́ ó ṣeé ṣe. Tó o bá sapá, wàá ṣe ara ẹ àti ìdílé rẹ láǹfààní. w19.09 18-19 ¶19-20
Sunday, December 19
Kò sí ẹni tó lè sin ọ̀gá méjì.—Mát. 6:24.
Tẹ́nì kan bá ń sin Jèhófà tó sì tún ń lo ọ̀pọ̀ àkókò lẹ́nu bó ṣe máa kó ọrọ̀ jọ, ṣe lẹni náà ń sin ọ̀gá méjì. Ìdí sì ni pé Jèhófà nìkan kọ́ ló ń jọ́sìn mọ́. Nígbà tó ku díẹ̀ kí ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní Sànmánì Kristẹni parí, àwọn kan nínú ìjọ Laodíkíà ń fọ́nnu pé: “Ọlọ́rọ̀ ni mí, mo ti kó ọrọ̀ jọ, mi ò sì nílò nǹkan kan.” Àmọ́ lójú Jèhófà àti Jésù, “akúṣẹ̀ẹ́ ni [wọ́n], ẹni téèyàn ń káàánú, òtòṣì, afọ́jú àti ẹni tó wà ní ìhòòhò.” Kì í ṣe torí pé wọ́n lówó lọ́wọ́ ni Jésù ṣe bá wọn wí, àmọ́ torí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ owó, ìyẹn ò sì jẹ́ kí wọ́n ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. (Ìfi. 3:14-17) Táwa náà bá kíyè sí i pé gbogbo àkókò wa la fi ń wá bá a ṣe máa di olówó, a gbọ́dọ̀ tètè wá nǹkan ṣe sí i kó tó pẹ́ jù. (1 Tím. 6:7, 8) Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, a ò ní lè sin Jèhófà tọkàntọkàn mọ́, Jèhófà ò sì ní tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wa, torí pé “òun nìkan ṣoṣo” ló fẹ́ ká máa jọ́sìn.—Diu. 4:24. w19.10 27 ¶5-6
Monday, December 20
Àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run bí ẹ̀mí mímọ́ ṣe darí wọn.—2 Pét. 1:21.
Ní tààràtà, ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n tú sí “darí” túmọ̀ sí “sún wọn; mú kí wọ́n gba ìmísí.” Lúùkù tó kọ ìwé Ìṣe náà lo ọ̀rọ̀ Gíríìkì tó jọ èyí nígbà tó ń sọ bí ‘ìjì ṣe ń gbá ọkọ̀ kan lọ.’ (Ìṣe 27:15) Kódà, ọ̀mọ̀wé Bíbélì kan sọ pé nígbà tí àpọ́sítélì Pétérù ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó kọ Bíbélì, ó lo ọ̀rọ̀ náà “sún wọn,” ọ̀rọ̀ yìí jọ bí atẹ́gùn ṣe máa ń sún ọkọ̀ ojú omi síwájú. Ohun tí Pétérù ń sọ ni pé bí atẹ́gùn ṣe ń sún ọkọ̀ ojú omi kan dé ibi tó ń lọ, bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ̀mí mímọ́ ṣe darí àwọn wòlíì àtàwọn tó kọ Bíbélì kí wọ́n lè ṣiṣẹ́ tí Jèhófà gbé fún wọn. Ọ̀mọ̀wé kan náà yẹn sọ pé: “A lè sọ pé àwọn wòlíì yẹn ta ìgbòkun ọkọ̀ wọn, [ìyẹn aṣọ tó máa ń wà lórí ọkọ̀].” Jèhófà ṣe ipa tirẹ̀ torí òun ló pèsè “ìjì” tàbí atẹ́gùn, ìyẹn ẹ̀mí mímọ́. Àwọn tó kọ Bíbélì náà sì ṣe ipa tiwọn torí wọ́n jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ darí wọn. Lónìí, bí ìjì tí kò le tàbí atẹ́gùn ṣe máa ń rọra darí ọkọ̀ ojú omi lọ síbi tí ọkọ̀ náà fẹ́ lọ, bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ̀mí mímọ́ ṣe máa ń ràn wá lọ́wọ́, tó sì máa ń tì wá lẹ́yìn ká lè jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà títí wọnú ayé tuntun láìka àwọn ìṣòro wa sí. w19.11 9 ¶7-9
Tuesday, December 21
Tí o bá rẹ̀wẹ̀sì ní ọjọ́ wàhálà, agbára rẹ ò ní tó nǹkan.—Òwe 24:10.
Ìṣòro lè mú ká rẹ̀wẹ̀sì. Síbẹ̀, kò yẹ ká jẹ́ káwọn ìṣòro yẹn gbà wá lọ́kàn débi pé òun làá máa rò ṣáá. Tó bá jẹ́ pé ìṣòro wa ló gbà wá lọ́kàn, a lè má fọkàn sí àwọn ìlérí Jèhófà mọ́, ó sì lè mú ká sọ̀rètí nù. (Ìfi. 21:3, 4) Ńṣe ni ìrẹ̀wẹ̀sì máa ń tánni lókun, kódà ó máa ń mú kéèyàn bọ́hùn. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí arábìnrin kan lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ṣe tó fún un lókun lásìkò tí ọkọ rẹ̀ ń ṣàìsàn tó le gan-an. Arábìnrin yìí sọ pé: “Àwọn ìgbà kan wà tí ìṣòro yìí tán wa lókun tó sì mú ká rẹ̀wẹ̀sì, síbẹ̀ a ò sọ̀rètí nù. A mọyì ìtọ́ni tá à ń rí gbà gan-an torí pé òun ló ń fún ìgbàgbọ́ wa lókun, tó sì ń gbé wa ró. Ó bọ́ sákòókò tá a nílò rẹ̀, ó ń fún wa lókun láti máa sin Jèhófà nìṣó.” Ó dájú pé ohun tí arábìnrin yìí sọ jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè borí ìrẹ̀wẹ̀sì. Torí náà, nígbàkigbà tó o bá níṣòro, gbà pé àǹfààní ló ṣí sílẹ̀ yẹn láti kọjú ìjà sí Sátánì. Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, fi sọ́kàn pé Jèhófà ni Orísun ìtùnú, á sì tù ẹ́ nínú. Bákan náà, rí i pé o mọyì oúnjẹ tẹ̀mí tó ń fún wa. w19.11 16 ¶9-10
Wednesday, December 22
Ẹni tó ṣeé fọkàn tán máa ń pa àṣírí mọ́.—Òwe 11:13.
Ó ṣe pàtàkì kẹ́yin alàgbà máa pa àṣírí mọ́. Ẹ̀yin alàgbà mọ̀ pé ẹ ò gbọ́dọ̀ sọ “ọ̀rọ̀ àṣírí” àwọn ará fún ìyàwó yín. Tí alàgbà kan bá sọ̀rọ̀ àṣírí síta, àwọn ará ò ní fọkàn tán an mọ́, á sì ba orúkọ rere tó ní jẹ́. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ kó ṣe kedere pé àwọn tá a yàn sípò nínú ìjọ kì í ṣe “ẹlẹ́nu méjì,” wọn kì í sì í tanni jẹ. (1 Tím. 3:8; àlàyé ìsàlẹ̀) Lédè míì, a ò gbọ́dọ̀ bá alàgbà èyíkéyìí nídìí òfófó tàbí kó máa sọ̀rọ̀ ọlọ́rọ̀ kiri. Alàgbà tó nífẹ̀ẹ́ ìyàwó rẹ̀ kò ní sọ ohun tí ò lẹ́tọ̀ọ́ láti gbọ́ fún un torí pé ńṣe nìyẹn máa fa ìnira fún obìnrin náà. Báwo ni ìyàwó alàgbà kan ṣe lè mú kí ọkọ rẹ̀ túbọ̀ jẹ́ ẹni iyì lójú àwọn ará? Ó lè ṣe bẹ́ẹ̀ tí kì í bá fúngun mọ́ ọkọ rẹ̀ tàbí dọ́gbọ́n mú kó sọ̀rọ̀ àṣírí fún òun. Tí ìyàwó kan bá mọ̀wọ̀n ara ẹ̀, tó sì fìmọ̀ràn yìí sílò, ṣe ló máa jẹ́ alátìlẹ́yìn gidi fún ọkọ ẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, ṣe ló ń fi hàn pé òun bọ̀wọ̀ fáwọn tó fọkàn tán ọkọ rẹ̀ tí wọ́n sì sọ̀rọ̀ àṣírí fún un. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, irú ìyàwó bẹ́ẹ̀ ń múnú Jèhófà dùn torí pé bó ṣe mọ̀wọ̀n ara ẹ̀ yìí ń mú kí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan túbọ̀ gbilẹ̀ nínú ìjọ.—Róòmù 14:19. w20.03 22 ¶13-14
Thursday, December 23
Jèhófà yóò fara hàn yín.—Léf. 9:4.
Lọ́dún 1512 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni nígbà tí wọ́n to àgọ́ ìjọsìn sí ọwọ́ ìsàlẹ̀ Òkè Sínáì. Mósè ló bójú tó bí wọ́n ṣe yan Áárónì àtàwọn ọmọ rẹ̀ sípò àlùfáà. (Ẹ́kís. 40:17; Léf. 9:1-5) Kí ni Jèhófà ṣe tó fi hàn pé ó tẹ́wọ́ gba àwọn àlùfáà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn sípò? Bí Áárónì àti Mósè ṣe súre fún àwọn èèyàn náà tán, Jèhófà jẹ́ kí iná bọ́ látọ̀run, ó sì jó ẹbọ tó wà lórí pẹpẹ. (Léf. 9:23, 24) Kí ló ṣe kedere pẹ̀lú bí iná ṣe wá látọ̀run tó sì jó ẹbọ yẹn run lọ́jọ́ tí wọ́n yan àlùfáà àgbà sípò? Ó ṣe kedere pé Jèhófà tẹ́wọ́ gba bí wọ́n ṣe yan Áárónì àtàwọn ọmọ rẹ̀ sípò. Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì rí i pé Jèhófà wà lẹ́yìn àwọn àlùfáà náà, ó túbọ̀ ṣe kedere sí wọn pé ó yẹ kí àwọn tì wọ́n lẹ́yìn. Ǹjẹ́ ohun tá a sọ yìí kàn wá lónìí? Bẹ́ẹ̀ ni! Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn àlùfáà Ísírẹ́lì ṣàpẹẹrẹ àwọn àlùfáà míì tó jùyẹn lọ. Ìyẹn àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) tí wọ́n máa ṣàkóso pẹ̀lú Kristi ní ọ̀run. (Héb. 4:14; 8:3-5; 10:1) Kò sí àní-àní pé Jèhófà ló ń darí ètò rẹ̀, ó sì ń rọ̀jò ìbùkún lé e lórí. w19.11 23 ¶13; 24 ¶14, 16
Friday, December 24
À ń ṣiṣẹ́ tọ̀sántòru kí a má bàa gbé ẹrù tó wúwo wọ ìkankan nínú yín lọ́rùn.—2 Tẹs. 3:8.
Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wà ní Kọ́ríńtì, ilé Ákúílà àti Pírísílà ló dé sí, ó sì “ń bá wọn ṣiṣẹ́ torí iṣẹ́ àgọ́ pípa ni wọ́n ń ṣe.” Ti pé Pọ́ọ̀lù ń “ṣiṣẹ́ tọ̀sántòru” kò túmọ̀ sí pé ó ń ṣiṣẹ́ bí aago. Bí àpẹẹrẹ, ó máa ń wáyè sinmi lọ́jọ́ Sábáàtì. Ọjọ́ yẹn ló fi máa ń bá àwọn Júù sọ̀rọ̀ Ọlọ́run torí pé àwọn náà kì í ṣiṣẹ́ lọ́jọ́ Sábáàtì. (Ìṣe 13:14-16, 42-44; 16:13; 18:1-4) Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé ó yẹ kóun ṣiṣẹ́ kóun lè gbọ́ bùkátà ara òun, ó sì tún máa ń ṣe “iṣẹ́ mímọ́ ti ìhìn rere Ọlọ́run” déédéé. (Róòmù 15:16; 2 Kọ́r. 11:23) Kódà, ó gba àwọn míì níyànjú pé kí wọ́n fara wé òun. Ìyẹn jẹ́ ká rídìí tí Bíbélì fi sọ pé Ákúílà àti Pírísílà jẹ́ alábàáṣiṣẹ́ Pọ́ọ̀lù tí wọ́n “jọ ń ṣiṣẹ́ Kristi Jésù.” (Róòmù 12:11; 16:3) Pọ́ọ̀lù rọ àwọn ará Kọ́ríńtì pé kí wọ́n “máa ní ohun púpọ̀ láti ṣe nínú iṣẹ́ Olúwa.” (1 Kọ́r. 15:58; 2 Kọ́r. 9:8) Kódà Jèhófà mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti sọ pé: “Tí ẹnikẹ́ni ò bá fẹ́ ṣiṣẹ́, kó má jẹun.”—2 Tẹs. 3:10. w19.12 5 ¶12-13
Saturday, December 25
Àwọn ọmọ jẹ́ ogún láti ọ̀dọ̀ Jèhófà.—Sm. 127:3.
Jèhófà dá ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́, ó sì mú kó máa wù wọ́n láti bímọ. Ta ló yẹ kó pinnu bóyá kí tọkọtaya kan bímọ tàbí kí wọ́n má bímọ àtìgbà tó yẹ kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀? Láwọn ilẹ̀ kan, àwọn èèyàn máa ń retí pé gbàrà tí tọkọtaya bá ti ṣègbéyàwó ló yẹ kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í bímọ. Kódà àwọn mọ̀lẹ́bí àtàwọn míì lè máa fúngun mọ́ wọn pé kí wọ́n tètè bímọ. Arákùnrin Jethro tó ń gbé nílẹ̀ Éṣíà sọ pé: “Nínú ìjọ, àwọn tọkọtaya tó ti lọ́mọ máa ń sọ fún àwọn tí kò tíì bímọ pé kí ni wọ́n ń dúró dè tí wọn ò fi tíì bímọ.” Arákùnrin Jeffrey, tóun náà ń gbé nílẹ̀ Éṣíà sọ pé: “Àwọn míì máa ń sọ pé á dáa káwọn tọkọtaya tí kò tíì bímọ ṣe bẹ́ẹ̀ torí pé ọmọ ló máa tọ́jú wọn lọ́jọ́ ogbó, òun náà ló sì máa sin wọ́n tí wọ́n bá kú.” Bó ti wù kó rí, tọkọtaya kọ̀ọ̀kan ló máa dá pinnu bóyá wọ́n á bímọ tàbí wọn ò ní bímọ. Ọwọ́ wọn ni ìpinnu yẹn wà, ojúṣe wọn sì ni. (Gál. 6:5, àlàyé ìsàlẹ̀) Lóòótọ́, ire tọkọtaya làwọn ẹbí àtàwọn ọ̀rẹ́ náà ń wá, àmọ́ ó yẹ kí wọ́n fi sọ́kàn pé ọwọ́ tọkọtaya náà ló wà láti pinnu bóyá àwọn máa bímọ tàbí àwọn ò ní bí.—1 Tẹs. 4:11. w19.12 22 ¶1-3
Sunday, December 26
Torí náà, ẹ máa gbàdúrà lọ́nà yìí: “Baba wa.”—Mát. 6:9.
Ṣó máa ń ṣòro fún ẹ láti ka Jèhófà sí Baba rẹ? Àwọn kan máa ń ronú pé kí làwọn já mọ́ níwájú Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run, kódà àwọn ò ju bíńtín bí orí abẹ́rẹ́ lọ ní ìfiwéra. Wọ́n gbà pé tí Ọlọ́run Olódùmarè bá tiẹ̀ máa ráyè fún gbogbo èèyàn, kì í ṣe bíi tàwọn. Àmọ́, Baba wa ọ̀run ò fẹ́ ká ronú bẹ́ẹ̀. Òun ló dá wa, ó sì fẹ́ ká sún mọ́ òun. Lẹ́yìn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé kókó yìí fáwọn tó ń gbọ́rọ̀ rẹ̀ nílùú Áténì, ó fi kún un pé Jèhófà “kò jìnnà sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa.” (Ìṣe 17:24-29) Jèhófà fẹ́ kẹ́nì kọ̀ọ̀kan wa máa wá sọ́dọ̀ òun láìbẹ̀rù bí ọmọ kan ṣe máa ń ṣe sí òbí tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ó ṣòro fáwọn míì láti ka Jèhófà sí Baba torí pé bàbá tó bí wọn lọ́mọ kò rí tiwọn rò ká má tíì sọ pé kó fìfẹ́ hàn sí wọn. Arábìnrin kan sọ pé: “Bàbá mi máa ń bú mi gan-an, wọ́n sì máa ń ṣépè fún mi. Torí náà, nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó ṣòro fún mi láti gbà pé Jèhófà jẹ́ Bàbá mi ọ̀run.” Ṣé bọ́rọ̀ tìẹ náà ṣe rí nìyẹn? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé ìwọ náà lè mọ Jèhófà débi tí wàá fi gbà pé kò sí bàbá tó dà bíi Jèhófà. w20.02 3 ¶4-5
Monday, December 27
Má pa mí tì nígbà tí mi ò bá lágbára mọ́.—Sm. 71:9.
Jésù jẹ́ ká mọ̀ pé bó ti wù kí agbára wa mọ tàbí bí ohun tá à ń ṣe nínú ìjọsìn Jèhófà ṣe kéré tó lójú wa ní báyìí tí ara ti ń dara àgbà, Jèhófà mọyì rẹ̀. (Sm. 92:12-15; Lúùkù 21:2-4) Torí náà, ohun tí agbára rẹ ká ni kó o máa ṣe. Bí àpẹẹrẹ, o lè sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà fáwọn èèyàn, o lè gbàdúrà fáwọn ará, o sì lè fún àwọn míì níṣìírí kí wọ́n lè jẹ́ adúróṣinṣin. Jèhófà gbà pé alábàáṣiṣẹ́ òun lo jẹ́. Kì í ṣe nítorí bí agbára rẹ ṣe tó, àmọ́ torí pé ò ń ṣègbọràn sí i. (1 Kọ́r. 3:5-9) A mà dúpẹ́ o pé Jèhófà ni Ọlọ́run wa, torí pé ó mọyì ohun tá à ń ṣe nínú ìjọsìn rẹ̀! Torí ká lè ṣe ìfẹ́ rẹ̀ ló ṣe dá wa, ó ṣe tán kò sóhun míì tó ń mú kí ìgbésí ayé ẹni nítumọ̀ ju pé kéèyàn máa jọ́sìn Jèhófà. (Ìfi. 4:11) Bí Èṣù àti ayé yìí bá tiẹ̀ ń fojú ẹni tí kò wúlò wò wá, ọkàn wa balẹ̀ pé Jèhófà ò fi irú ojú bẹ́ẹ̀ wò wá. (Héb. 11:16, 38) Torí náà, nígbàkigbà tó o bá rẹ̀wẹ̀sì torí àìsàn, ìṣòro àtijẹ àtimu tàbí torí ara tó ń dara àgbà, máa rántí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ rẹ gan-an, kò sì sóhun tó lè yà ọ́ ya ìfẹ́ Jèhófà, Baba rẹ ọ̀run.—Róòmù 8:38, 39. w20.01 18 ¶16; 19 ¶18-19
Tuesday, December 28
Dá ọkàn mímọ́ sí inú mi, Ọlọ́run, kí o sì fi ẹ̀mí tuntun sí inú mi, èyí tó fìdí múlẹ̀.—Sm. 51:10.
A lè fa ẹ̀mí burúkú yìí tu lọ́kàn wa tá a bá lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ tá a sì ní ìtẹ́lọ́rùn. Àwọn ànímọ́ yìí ò ní jẹ́ kí ìlara ta gbòǹgbò lọ́kàn wa. Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ kò ní jẹ́ ká máa ro ara wa ju bó ti yẹ lọ. Ẹni tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ kò ní máa ronú pé òun ni gbogbo nǹkan tọ́ sí. (Gál. 6:3, 4) Ẹni tó ní ìtẹ́lọ́rùn máa ń mọyì ohun tó ní, kì í sì í fi ara rẹ̀ wé àwọn míì. (1 Tím. 6:7, 8) Inú ẹni tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn máa ń dùn nígbà táwọn míì bá ní àǹfààní tóun ò ní. A nílò ẹ̀mí mímọ́ ká bàa lè borí ìlara ká sì tún ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn. (Gál. 5:16; Fílí. 2:3, 4) Ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà máa jẹ́ ká mọ ohun tó wà lọ́kàn wa àti ohun tó ń mú wa ṣe nǹkan. Lọ́lá ìtìlẹyìn Jèhófà, a lè fa èròkerò àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ yìí tu lọ́kàn wa ká sì fi èyí tó dáa rọ́pò rẹ̀.—Sm. 26:2. w20.02 15 ¶8-9
Wednesday, December 29
Máa kíyè sí ara rẹ àti ẹ̀kọ́ rẹ nígbà gbogbo.—1 Tím. 4:16.
Ńṣe lo jẹ́jẹ̀ẹ́ fún Jèhófà nígbà tó o ya ara ẹ sí mímọ́, Jèhófà sì retí pé kó o mú ẹ̀jẹ́ náà ṣẹ. Torí náà, má jìnnà sáwọn ará. Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tẹ́ ẹ jọ wà nínú ìjọ máa mú ẹ bí ọmọ ìyá. Tó o bá ń lọ sípàdé déédéé, àárín yín á túbọ̀ gún régé. Máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́, kó o sì máa ṣàṣàrò lórí ẹ̀. (Sm. 1:1, 2) Rí i pé o lo àkókò díẹ̀ láti ronú lórí ohun tó o kà. Ìgbà yẹn lohun tó o kà máa tó wọnú ọkàn rẹ. Bíbélì rọ̀ ẹ́ pé kó o “máa gbàdúrà nígbà gbogbo.” (Mát. 26:41) Àdúrà àtọkànwá tó ò ń gbà máa mú kó o túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Bákan náà, “máa wá Ìjọba náà . . . lákọ̀ọ́kọ́.” (Mát. 6:33) O lè ṣe bẹ́ẹ̀ tó o bá ń jẹ́ kí iṣẹ́ ìwàásù gbawájú nígbèésí ayé ẹ. Tó o bá ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù déédéé, ìgbàgbọ́ ẹ á túbọ̀ lágbára. Ìṣòro yòówù kó o máa kojú nínú ayé èṣù yìí, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé ‘fún ìgbà díẹ̀ ni, kò sì lágbára.’ (2 Kọ́r. 4:17) Àmọ́ tó o bá ya ara ẹ sí mímọ́ tó o sì ṣèrìbọmi, ayé ẹ á ládùn á sì lóyin nísinsìnyí, wàá sì tún ní “ìyè tòótọ” lọ́jọ́ iwájú. Ṣé ìrìbọmi tó bẹ́ẹ̀? Bẹ́ẹ̀ ni, ó tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ!—1 Tím. 6:19. w20.03 13 ¶19-21
Thursday, December 30
Àkókò tó ṣẹ́ kù ti dín kù.—1 Kọ́r. 7:29.
Bí akẹ́kọ̀ọ́ rẹ kò bá tẹ̀ síwájú bó ṣe yẹ, ó lè gba pé kó o pinnu bóyá kó o dá ìkẹ́kọ̀ọ́ náà dúró. Fún ìdí yìí, á dáa kó o bi ara ẹ pé: ‘Ṣé akẹ́kọ̀ọ́ mi ń tẹ̀ síwájú débi tí agbára rẹ̀ gbé e dé?’ ‘Ṣé ó ti ń fi ohun tó ń kọ́ sílò?’ (Mát. 28:20) Ó ṣeni láàánú pé ọ̀rọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan dà bíi tàwọn ọmọ Ísírẹ́lì ayé ìgbà Ìsíkíẹ́lì. Jèhófà sọ fún Ìsíkíẹ́lì nípa àwọn èèyàn náà pé: “Wò ó! Lójú wọn, o dà bí orin ìfẹ́, tí wọ́n fi ohùn dídùn kọ, tí wọ́n sì fi ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín kọ lọ́nà tó já fáfá. Wọ́n á gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ, àmọ́ wọn ò ní tẹ̀ lé e.” (Ìsík. 33:32) Ó lè ṣòro fún wa láti sọ fún ẹni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ pé a máa dá ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ dúró. Àmọ́, a ò rọ́jọ́ mú so lókùn torí pé “àkókò tó ṣẹ́ kù ti dín kù.” Dípò ká máa fi àkókò ṣòfò nídìí ìkẹ́kọ̀ọ́ tí kò méso jáde, ẹ jẹ́ ká wá àwọn míì lọ, ìyẹn “àwọn olóòótọ́ ọkàn tí wọ́n ń fẹ́ ìyè àìnípẹ̀kun.”—Ìṣe 13:48. w20.01 6 ¶17; 7 ¶20
Friday, December 31
Kí Ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ ní ayé, bíi ti ọ̀run.—Mát. 6:10.
Àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì kì í fi òtítọ́ Bíbélì kọ́ni pé ìgbà kan ń bọ̀ tí àwọn èèyàn onígbọràn máa gbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé. (2 Kọ́r. 4:3, 4) Ọ̀pọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì ló ń kọ́ni pé ọ̀run ni gbogbo èèyàn rere ń lọ lẹ́yìn tí wọ́n bá kú. Àmọ́ ohun táwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kéréje tó ń tẹ ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ láti ọdún 1879 fi ń kọ́ni yàtọ̀ síyẹn. Wọ́n nígbàgbọ́ pé Ọlọ́run máa sọ ayé yìí di Párádísè, inú ẹ̀ sì ni ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn onígbọràn máa gbé títí láé, kì í ṣe ọ̀run. Síbẹ̀, òye wọn ò fi bẹ́ẹ̀ ṣe kedere nípa àwọn tó máa gbé lórí ilẹ̀ ayé. Ìwádìí táwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe nínú Ìwé Mímọ́ jẹ́ kí wọ́n lóye pé àwọn kan tí Jèhófà “rà látinú ayé” máa jọba pẹ̀lú Jésù lọ́run. (Ìfi. 14:3) Ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) làwọn Kristẹni yìí, wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́, wọ́n sì fìtara ṣiṣẹ́ Jèhófà nígbà tí wọ́n wà láyé. w19.09 27 ¶4-5