ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • es25 ojú ìwé 26-36
  • March

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • March
  • Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2025
  • Ìsọ̀rí
  • Saturday, March 1
  • Sunday, March 2
  • Monday, March 3
  • Tuesday, March 4
  • Wednesday, March 5
  • Thursday, March 6
  • Friday, March 7
  • Saturday, March 8
  • Sunday, March 9
  • Monday, March 10
  • Tuesday, March 11
  • Wednesday, March 12
  • Thursday, March 13
  • Friday, March 14
  • Saturday, March 15
  • Sunday, March 16
  • Monday, March 17
  • Tuesday, March 18
  • Wednesday, March 19
  • Thursday, March 20
  • Friday, March 21
  • Saturday, March 22
  • Sunday, March 23
  • Monday, March 24
  • Tuesday, March 25
  • Wednesday, March 26
  • Thursday, March 27
  • Friday, March 28
  • Saturday, March 29
  • Sunday, March 30
  • Monday, March 31
Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2025
es25 ojú ìwé 26-36

March

Saturday, March 1

Ìrètí kì í yọrí sí ìjákulẹ̀.—Róòmù 5:5.

Ká sòótọ́, ayé tuntun ò tíì dé báyìí. Àmọ́ kó tó dé, máa kíyè sí àwọn nǹkan tó wà láyìíká ẹ, irú bí ìràwọ̀, igi, ẹranko àtàwọn èèyàn. Kò sẹ́ni tó lè jiyàn pé àwọn nǹkan yìí ò sí, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìgbà kan wà tí wọn ò sí. Àmọ́ à ń rí àwọn nǹkan yẹn torí pé Jèhófà ló dá wọn. (Jẹ́n. 1:​1, 26, 27) Ọlọ́run wa ti ṣèlérí pé òun máa sọ ayé di tuntun, ó sì máa mú ìlérí yẹn ṣẹ. Nínú ayé tuntun, àwọn èèyàn ò ní kú mọ́, wọ́n sì máa ní ìlera tó jí pépé. Torí náà, tó bá tó àkókò lójú Ọlọ́run, ayé tuntun tó ṣèlérí máa dé. (Àìsá. 65:17; Ìfi. 21:​3, 4) Kí ayé tuntun tó dé, máa ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe kí ìgbàgbọ́ ẹ lè túbọ̀ lágbára. Máa dúpẹ́ ní gbogbo ìgbà pé Jèhófà fi Ọmọ ẹ̀ rà wá pa dà. Máa ronú lórí bí agbára Jèhófà ṣe pọ̀ tó. Máa ṣe àwọn ohun táá jẹ́ kó o túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wàá wà lára “àwọn tí ìgbàgbọ́ àti sùúrù mú kí wọ́n jogún àwọn ìlérí” Ọlọ́run.—Héb. 6:​11, 12. w23.04 31 ¶18-19

Sunday, March 2

Ṣebí mo sọ fún ọ pé tí o bá gbà gbọ́, o máa rí ògo Ọlọ́run?—Jòh. 11:40.

Jésù gbé ojú ẹ̀ sókè, ó sì gbàdúrà níṣojú gbogbo èèyàn. Ìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ó fẹ́ káwọn èèyàn yin Ọlọ́run lógo lẹ́yìn tóun bá jí Lásárù dìde. Jésù wá kígbe pé: “Lásárù, jáde wá!” (Jòh. 11:43) Lásárù sì jáde látinú ibojì! Ohun tí Jésù ṣe yìí ya àwọn èèyàn lẹ́nu torí wọ́n rò pé kò lè ṣeé ṣe. Ìtàn yìí jẹ́ kí ìgbàgbọ́ tá a ní pé àwọn òkú máa jíǹde túbọ̀ lágbára. Lọ́nà wo? Ṣẹ́ ẹ rántí ìlérí tí Jésù ṣe fún Màtá. Ó sọ pé: “Arákùnrin rẹ máa dìde.” (Jòh. 11:23) Bíi ti Bàbá ẹ̀, ó wu Jésù pé kó mú ìlérí yìí ṣẹ, ó sì lágbára láti ṣe é. Bí Jésù ṣe sunkún fi hàn pé ó wù ú kó jí àwọn tó ti kú dìde, kó sì mú ìbànújẹ́ tí ikú fà kúrò. Nígbà tí Jésù jí Lásárù dìde, tó sì jáde látinú ibojì, Jésù tún fi hàn lẹ́ẹ̀kan sí i pé òun lágbára láti jí àwọn òkú dìde. Ẹ tún ronú nípa ohun tí Jésù sọ fún Màtá nínú ẹsẹ ojúmọ́ wa tòní. Àwọn nǹkan tí Jésù ṣe yìí jẹ́ ká gbà pé Ọlọ́run máa mú ìlérí ẹ̀ ṣẹ pé òun máa jí àwọn òkú dìde. w23.04 11-12 ¶15-16

Monday, March 3

Jèhófà wà nítòsí gbogbo àwọn tó ń ké pè é, nítòsí gbogbo àwọn tó ń ké pè é ní òtítọ́.—Sm. 145:18.

Nígbà míì, ó lè gba pé ká yí àdúrà wa pa dà torí pé a ti wá mọ ohun tí Jèhófà fẹ́ ká ṣe. Ó yẹ ká máa rántí pé Jèhófà ní nǹkan tó fẹ́ ṣe fún wa, àsìkò tó sì tọ́ lójú ẹ̀ ló máa ṣe é. Lára ohun tí Jèhófà fẹ́ ṣe ni pé ó fẹ́ mú gbogbo ìṣòro tó ń fa ìyà kúrò pátápátá, irú bí àjálù, àìsàn àti ikú. Ìjọba ẹ̀ ló sì máa lò láti ṣe gbogbo nǹkan yìí. (Dán. 2:44; Ìfi. 21:​3, 4) Àmọ́ kó tó dìgbà yẹn, Jèhófà ṣì ń gba Sátánì láyè láti ṣàkóso ayé. (Jòh. 12:31; Ìfi. 12:9) Tí Jèhófà bá yanjú gbogbo ìṣòro àwa èèyàn báyìí, ṣe ló máa dà bíi pé Sátánì ń ṣàkóso ayé dáadáa. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ṣì ń dúró dìgbà tí Jèhófà máa mú àwọn ìlérí kan ṣẹ, ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé kì í ràn wá lọ́wọ́ ni? Rárá o, Jèhófà máa ń ràn wá lọ́wọ́. w23.05 8 ¶4; 9-10 ¶7-8

Tuesday, March 4

Ẹ mọ bó ṣe yẹ kí ẹ dá ẹnì kọ̀ọ̀kan lóhùn.—Kól. 4:6.

Báwo la ṣe lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti jàǹfààní Ìrántí Ikú Kristi? Ohun tó yẹ ká kọ́kọ́ ṣe ni pé ká pè wọ́n wá. Yàtọ̀ sáwọn tá a pàdé lóde ìwàásù, ó yẹ ká tún kọ orúkọ àwọn míì tá a fẹ́ pè wá. Ó lè jẹ́ àwọn mọ̀lẹ́bí wa, àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́, àwọn ọmọ ilé ìwé wa àtàwọn míì tá a mọ̀. Tí ìwé tá a fi ń pe àwọn èèyàn wá sí Ìrántí Ikú Kristi ò bá tiẹ̀ pọ̀ lọ́wọ́ wa, a lè fi ìlujá ẹ̀ ránṣẹ́ sí wọn. A ò lè sọ, ọ̀pọ̀ lára wọn lè wá! (Oníw. 11:6) Rántí pé àwọn tá a pè wá sí Ìrántí Ikú Kristi lè ní ìbéèrè, pàápàá tí wọn ò bá tíì wá sípàdé wa rí. Á dáa ká ti ronú nípa àwọn ìbéèrè tí wọ́n lè bi wá àti bá a ṣe máa dá wọn lóhùn. Kódà, àwọn tó wá sí Ìrántí Ikú Kristi fúngbà àkọ́kọ́ máa ń béèrè àwọn ìbéèrè míì. Torí náà, a fẹ́ ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ṣáájú Ìrántí Ikú Kristi, nígbà Ìrántí Ikú Kristi àti lẹ́yìn náà láti ran “àwọn olóòótọ́ ọkàn” lọ́wọ́ kí wọ́n lè jàǹfààní.—Ìṣe 13:48. w24.01 12 ¶13, 15; 13 ¶16

Wednesday, March 5

Ìkùukùu ni yín, tó máa ń wà fúngbà díẹ̀, lẹ́yìn náà tí á pòórá.—Jém. 4:14.

Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa èèyàn mẹ́jọ tí wọ́n jí dìde nígbà àtijọ́. O ò ṣe fara balẹ̀ ka ìtàn àjíǹde kọ̀ọ̀kan? Bó o ṣe ń ka àwọn ìtàn náà, wo àwọn ẹ̀kọ́ tó o lè rí kọ́ níbẹ̀. Ronú nípa bí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn àjíǹde yẹn ṣe fi hàn pé ó wu Ọlọ́run láti jí àwọn òkú dìde, ó sì lágbára láti ṣe é. Àmọ́ ó tún yẹ kó o ronú nípa àjíǹde tó ṣe pàtàkì jù lọ, ìyẹn àjíǹde Jésù. Rántí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ló rí Jésù lẹ́yìn tó jíǹde, ìyẹn sì jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára pé àwọn òkú máa jíǹde. (1 Kọ́r. 15:​3-6, 20-22) A mà dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà ò torí ìlérí tó ṣe pé òun máa jí àwọn òkú dìde. Ó dá wa lójú pé Jèhófà máa mú ìlérí ẹ̀ ṣẹ torí ó wù ú, ó sì lágbára láti ṣe é. Torí náà, jẹ́ kí ìgbàgbọ́ tó o ní pé àwọn òkú máa jíǹde túbọ̀ máa lágbára. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run tó ṣèlérí fún ẹ pé ‘Àwọn èèyàn ẹ máa jíǹde!’—Jòh. 11:23. w23.04 8 ¶2; 12 ¶17; 13 ¶20

Thursday, March 6

Kí o mọ̀wọ̀n ara rẹ bí o ṣe ń bá Ọlọ́run rẹ rìn!—Míkà 6:8.

Ìrẹ̀lẹ̀ àti ìmọ̀wọ̀n ara ẹni jọra. Tá a bá mọ̀wọ̀n ara wa, a ò ní máa ro ara wa ju bó ṣe yẹ lọ, àá sì gbà pé àwọn nǹkan kan wà tá ò lè ṣe. Tá a bá nírẹ̀lẹ̀, a ò ní máa ṣe bíi pé a mọ nǹkan ṣe ju àwọn míì lọ. (Fílí. 2:3) Ká sòótọ́, ẹni tó mọ̀wọ̀n ara ẹ̀ máa ń nírẹ̀lẹ̀. Gídíónì mọ̀wọ̀n ara ẹ̀, ó sì nírẹ̀lẹ̀. Nígbà tí áńgẹ́lì Jèhófà sọ fún Gídíónì pé òun ni Jèhófà yàn pé kó lọ gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Mídíánì, ìrẹ̀lẹ̀ tó ní mú kó sọ pé: “Agbo ilé mi ló kéré jù ní Mánásè, èmi ló sì kéré jù ní ilé bàbá mi.” (Oníd. 6:15) Ó rò pé òun ò kúnjú ìwọ̀n láti ṣiṣẹ́ náà, àmọ́ Jèhófà mọ̀ pé ó lè ṣe é. Torí náà, Jèhófà ràn án lọ́wọ́, Gídíónì sì ṣe iṣẹ́ náà láṣeyọrí. Ó yẹ kẹ́yin alàgbà máa fi hàn pé ẹ mọ̀wọ̀n ara yín, ẹ sì nírẹ̀lẹ̀ nínú gbogbo ohun tẹ́ ẹ bá ń ṣe. (Ìṣe 20:​18, 19) Wọn kì í fọ́nnu torí àwọn nǹkan tí wọ́n gbé ṣe, wọn kì í sì í ro ara wọn pin tí wọ́n bá ṣàṣìṣe. w23.06 3 ¶4-5

Friday, March 7

Òun yóò fọ́ orí rẹ.—Jẹ́n. 3:15.

Ẹgbẹ̀rún ọdún (1,000) ṣì máa kọjá kí Jèhófà tó lo Jésù láti fọ́ orí Sátánì. (Ìfi. 20:​7-10) Àmọ́ kíyẹn tó ṣẹlẹ̀, àwọn nǹkan àgbàyanu tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé ó máa ṣẹlẹ̀ máa wáyé. Ohun àkọ́kọ́ ni pé àwọn orílẹ̀-èdè máa kéde “àlàáfíà àti ààbò!” (1 Tẹs. 5:​2, 3) Ìpọ́njú ńlá máa bẹ̀rẹ̀ nígbà táwọn orílẹ̀-èdè bá bẹ̀rẹ̀ sí í pa gbogbo ìsìn èké run, ó sì máa ṣẹlẹ̀ ‘lójijì.’ (Ìfi. 17:16) Lẹ́yìn ìyẹn, Jésù máa dá àwọn èèyàn lẹ́jọ́, á sì ya àwọn tó dà bí àgùntàn sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn tó dà bí ewúrẹ́. (Mát. 25:​31-33, 46) Síbẹ̀, Sátánì ò ní káwọ́ gbera. Torí inú ń bí i burúkú burúkú, ó máa mú kí àgbájọ àwọn orílẹ̀-èdè tí Bíbélì pè ní Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù gbéjà ko àwa èèyàn Jèhófà. (Ìsík. 38:​2, 10, 11) Láàárín àkókò kan nígbà ìpọ́njú ńlá, àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn ẹni àmì òróró máa lọ bá Kristi àtàwọn ọmọ ogun ọ̀run lọ́run kí wọ́n lè jọ ja ogun Amágẹ́dọ́nì, ìyẹn ló sì máa fòpin sí ìpọ́njú ńlá náà. (Mát. 24:31; Ìfi. 16:​14, 16) Lẹ́yìn náà, Jésù máa bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso lé ayé lórí fún ẹgbẹ̀rún ọdún kan.—Ìfi. 20:6. w23.10 20-21 ¶9-10

Saturday, March 8

Ìránṣẹ́ rẹ ti ń bẹ̀rù Jèhófà láti ìgbà èwe rẹ̀ wá.—1 Ọba 18:12.

Lónìí, ọ̀pọ̀ àwa ìránṣẹ́ Jèhófà ló ń gbé láwọn ilẹ̀ tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ wa. Síbẹ̀, a máa ń bọ̀wọ̀ fáwọn aláṣẹ ìjọba, àmọ́ bíi ti Ọbadáyà, àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa ọ̀wọ́n yìí ò fi Jèhófà sílẹ̀. (Mát. 22:21) Wọ́n fi hàn pé Ọlọ́run làwọn bẹ̀rù torí pé wọ́n ń ṣègbọràn sí i dípò èèyàn. (Ìṣe 5:29) Bí wọ́n ṣe ń ṣe é ni pé wọ́n ń wàásù, wọ́n sì ń ṣèpàdé níkọ̀kọ̀. (Mát. 10:​16, 28) Àwọn ará ń rí i dájú pé àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wọn ń rí ìwé ètò Ọlọ́run gbà torí ìyẹn máa jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Arákùnrin Henri tó ń gbé lórílẹ̀-èdè kan ní Áfíríkà, níbi tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ wa láwọn àkókò kan. Lásìkò yẹn, Henri yọ̀ǹda ara ẹ̀ kó lè máa pín àwọn ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì fáwọn ará. Ó sọ pé: “Mo máa ń tijú. Àmọ́, Jèhófà . . . jẹ́ kí n nígboyà tí mo fi ṣiṣẹ́ náà.” Ṣé ìwọ náà lè nígboyà bíi ti Henri? Bẹ́ẹ̀ ni, o lè nígboyà tó o bá ń bẹ̀rù Ọlọ́run lọ́nà tó tọ́. w23.06 16 ¶9, 11

Sunday, March 9

Ẹ̀ṣẹ̀ tipasẹ̀ ẹnì kan wọ ayé.—Róòmù 5:12.

Nígbà tí Ádámù àti Éfà ṣọ̀tẹ̀, ó lè dà bíi pé Sátánì ti dí Jèhófà lọ́wọ́ láti mú ìlérí tó ṣe fún aráyé ṣẹ, ìyẹn ni pé káwọn èèyàn pípé táá máa ṣègbọràn kún ayé. Ó ṣeé ṣe kí Sátánì máa rò pé Jèhófà ò lè rí ojúùtú ọ̀rọ̀ náà mọ́. Ọ̀kan lára ohun tó lè máa rò ni pé kí Jèhófà pa Ádámù àti Éfà, kó sì dá tọkọtaya míì tó jẹ́ pípé, kó lè ṣe ohun tó ní lọ́kàn fún aráyé. Àmọ́ ká ní ohun tí Jèhófà ṣe nìyẹn, ńṣe ni Èṣù máa sọ pé òpùrọ́ ni Jèhófà. Kí nìdí? Ìdí ni pé nínú Jẹ́nẹ́sísì 1:​28, Jèhófà ti sọ fún Ádámù àti Éfà pé àtọmọdọ́mọ wọn máa kún ayé. Ó tún ṣeé ṣe kí Sátánì máa rò pé Jèhófà máa fàyè gba Ádámù àti Éfà kí wọ́n bí àwọn ọmọ aláìpé tí wọn ò ní lè di ẹni pípé láé. (Oníw. 7:20; Róòmù 3:23) Ká sọ pé bọ́rọ̀ ṣe rí nìyẹn ni, kò sí àní-àní pé ńṣe ni Sátánì máa fẹ̀sùn kan Jèhófà pé kò mú ìlérí ẹ̀ ṣẹ. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé tí Jèhófà bá ṣe bẹ́ẹ̀, kò ní lè mú ohun tó ní lọ́kàn ṣẹ, ìyẹn ni pé káwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù àti Éfà tí wọ́n jẹ́ pípé, tí wọ́n sì jẹ́ onígbọràn kún ayé. w23.11 6 ¶15-16

Monday, March 10

Má ṣe kọjá àwọn ohun tó wà lákọsílẹ̀.—1 Kọ́r. 4:6.

Lónìí, Jèhófà ń tọ́ àwa náà sọ́nà nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti ètò rẹ̀. Kò yẹ ká fi kún ohun tí Jèhófà ń sọ fún wa. (Òwe 3:​5-7) Torí náà, kò yẹ ká kọjá ohun tó wà lákọsílẹ̀ nínú Bíbélì, kò sì yẹ ká máa ṣòfin fáwọn ará wa lórí ọ̀rọ̀ tí Bíbélì ò sọ nǹkan kan nípa ẹ̀. Sátánì máa ń lo “ìtànjẹ” àti “àwọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀ ayé” láti ṣi àwọn èèyàn lọ́nà, kó sì dá ìyapa sáàárín wọn. (Kól. 2:8) Nígbà ayé àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀, lára ohun tí Sátánì máa ń lò láti tan àwọn èèyàn jẹ ni ọgbọ́n orí tí wọ́n fi ń kọ́ àwọn èèyàn, ẹ̀kọ́ àwọn Júù tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu àti pé dandan ni káwọn Kristẹni máa pa Òfin Mósè mọ́. Ìtànjẹ ni gbogbo ẹ̀ torí àwọn nǹkan yìí kì í jẹ́ káwọn èèyàn ṣe ìfẹ́ Jèhófà, ẹni tí ọgbọ́n tòótọ́ wá látọ̀dọ̀ ẹ̀. Lónìí, Sátánì máa ń lo ilé iṣẹ́ ìròyìn àti ìkànnì àjọlò láti tan irọ́ kálẹ̀, ó sì tún máa ń lo ìròyìn tí ò jóòótọ́ táwọn olórí olóṣèlú máa ń gbé jáde nílé iṣẹ́ ìròyìn. Ọ̀pọ̀ irú àwọn ìròyìn báyìí la sì ń rí. w23.07 16 ¶11-12

Tuesday, March 11

Àwọn iṣẹ́ rẹ mà tóbi o, Jèhófà! Èrò rẹ jinlẹ̀ gidigidi!—Sm. 92:5.

Nígbà tí Sátánì, Ádámù àti Éfà ṣọ̀tẹ̀, Jèhófà yanjú ẹ̀ lọ́nà tí Sátánì ò lérò. Jèhófà mú ìlérí ẹ̀ ṣẹ nígbà tó jẹ́ kí Ádámù àti Éfà bímọ, ìyẹn sì fi hàn pé kì í ṣe òpùrọ́. Jèhófà ti fi hàn pé òun kì í ṣe aláṣetì torí gbogbo ohun tó bá sọ pé òun máa ṣe ló máa ń ṣe. Ó ṣe ohun tó jẹ́ kí ìlérí ẹ̀ ṣẹ, ìyẹn bó ṣe pèsè “ọmọ” tó máa gba àwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù àti Éfà tó jẹ́ onígbọràn là. (Jẹ́n. 3:15; 22:18) Bí Jèhófà ṣe gbà kí ọmọ ẹ̀ kú láti ra aráyé pa dà ya Sátánì lẹ́nu gan-an torí ibi tó fojú sí, ọ̀nà ò gbabẹ̀! Kí nìdí? Ìdí ni pé ìràpadà jẹ́ ẹ̀rí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, kò sì mọ tara ẹ̀ nìkan. (Mát. 20:28; Jòh. 3:16) Àmọ́ Sátánì ò nífẹ̀ẹ́ wa torí onímọ-tara-ẹni-nìkan ni. Torí náà, kí ló máa jẹ́ àbájáde ìràpadà tí Jèhófà pèsè yìí? Tó bá fi máa di òpin Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi, àwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù àti Éfà tí wọ́n jẹ́ onígbọràn á ti di pípé, wọ́n á sì máa gbé ayé nínú Párádísè bí Jèhófà ṣe fẹ́ kó rí níbẹ̀rẹ̀. w23.11 6 ¶17

Wednesday, March 12

Ọlọ́run máa dájọ́.—Héb. 13:4.

A máa ń ṣègbọràn sí òfin Jèhófà tó sọ pé ohun mímọ́ ni ẹ̀mí àti ẹ̀jẹ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé Jèhófà sọ pé ẹ̀jẹ̀ ni ẹ̀mí, òun ló sì fún wa ní ẹ̀bùn pàtàkì náà. (Léf. 17:14) Nígbà tí Jèhófà kọ́kọ́ sọ fáwọn èèyàn pé wọ́n lè jẹ ẹran, ó ní wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀. (Jẹ́n. 9:4) Ó tún sọ òfin yìí fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì nínú Òfin Mósè. (Léf. 17:10) Bákan náà, ẹ̀mí mímọ́ darí ìgbìmọ̀ olùdarí ìgbà ayé àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ láti sọ fáwọn Kristẹni pé kí wọ́n “ta kété sí ẹ̀jẹ̀.” (Ìṣe 15:​28, 29) Torí náà, ó yẹ ká ṣègbọràn sí òfin yìí tó bá kan irú ìtọ́jú tá a máa gbà nílé ìwòsàn. A tún máa ń ṣègbọràn sí òfin Ọlọ́run tó sọ pé ìṣekúṣe ò dáa. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lo àfiwé kan tó fi gbà wá níyànjú pé ká sọ àwọn ẹ̀yà ara wa “di òkú,” ìyẹn ni pé ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti mú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ kúrò lọ́kàn wa. A ò ní máa wo ohunkóhun tàbí ṣe ohunkóhun tó lè mú ká ṣèṣekúṣe.—Kól. 3:5; Jóòbù 31:1. w23.07 15 ¶5-6

Thursday, March 13

Níkẹyìn, ó sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ fún un.—Oníd. 16:17.

Ṣé ó ṣeé ṣe kí ìfẹ́ Dẹ̀lílà ti kó sí Sámúsìn lórí débi pé kò fura pé ó fẹ́ dalẹ̀ òun? Èyí ó wù ó jẹ́, ńṣe ni Dẹ̀lílà fúngun mọ́ Sámúsìn kó lè sọ ibi tí agbára ẹ̀ wà, nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín ó sọ fún un. Ó mà ṣe o! Àṣìṣe tí Sámúsìn ṣe yìí ló jẹ́ kó pàdánù agbára ẹ̀, ó sì tún pàdánù ojúure Jèhófà fáwọn àkókò kan. (Oníd. 16:​16-20) Torí pé Sámúsìn fọkàn tán Dẹ̀lílà dípò Jèhófà, ó jìyà ẹ̀. Àwọn Filísínì mú Sámúsìn, wọ́n sì fọ́ ojú ẹ̀. Wọ́n fi sẹ́wọ̀n nílùú Gásà, ó sì ń bá wọn lọ ọkà nínú ẹ̀wọ̀n. Lẹ́yìn ìyẹn, nígbà táwọn Filísínì ń ṣe àjọyọ̀ kan, wọ́n mú Sámúsìn wá síbẹ̀. Wọ́n rú ẹbọ ńlá kan sí ọlọ́run èké wọn tó ń jẹ́ Dágónì torí wọ́n gbà pé òun ló jẹ́ káwọn rí Sámúsìn mú. Torí náà, wọ́n mú Sámúsìn jáde látinú ẹ̀wọ̀n wá síbi àjọyọ̀ náà kó lè “dá wọn lára yá,” kí wọ́n sì fi í ṣe yẹ̀yẹ́.—Oníd. 16:​21-25. w23.09 5-6 ¶13-14

Friday, March 14

Ẹ jẹ́ kí ìrònú yín dá lé ohun tó dára lójú gbogbo èèyàn.—Róòmù 12:17.

Ó ṣeé ṣe kẹ́ni tá a jọ ń ṣiṣẹ́ tàbí ọmọ ilé ìwé wa bi wá pé kí nìdí tá a fi ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì kan? A máa ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti jẹ́ kẹ́ni náà rí i pé ohun tí Bíbélì sọ ló tọ̀nà, bá a sì ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀, ó yẹ ká bọ̀wọ̀ fún ẹni náà. (1 Pét. 3:15) Dípò ká máa ronú pé ẹni náà ń ta kò wá, ṣe ló yẹ ká rí i bí àǹfààní láti dáhùn ìbéèrè tó ń jẹ ẹ́ lọ́kàn. Ohun yòówù kó mú kẹ́nì kan béèrè ìbéèrè, ó yẹ ká fara balẹ̀ dá a lóhùn lọ́nà pẹ̀lẹ́. Ohun tá a bá sọ lè mú kó yí èrò ẹ̀ pa dà. Bí àpẹẹrẹ, ẹnì kan tá a jọ ń ṣiṣẹ́ lè bi wá pé kí nìdí tó fi jẹ́ pé a kì í ṣe ọjọ́ ìbí? Ṣé ó ṣeé ṣe kó máa ronú pé ẹ̀sìn wa ò gbà wá láyè láti gbádùn ara wa? Tó bá jẹ́ bọ́rọ̀ ṣe rí nìyẹn, ọkàn ẹ̀ máa balẹ̀ tá a bá jẹ́ kó mọ̀ pé a mọyì bó ṣe ń sapá láti jẹ́ kára tu àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó ṣeé ṣe ká láǹfààní láti ṣàlàyé ohun tí Bíbélì sọ nípa ọjọ́ ìbí fún un. w23.09 17 ¶10-11

Saturday, March 15

Ẹ máa ṣọ́ra yín kí àṣìṣe àwọn arúfin má bàa ṣì yín lọ́nà pẹ̀lú wọn, tí ẹ ò sì ní dúró ṣinṣin mọ́.—2 Pét. 3:17.

Ẹ jẹ́ ká fi àkókò tó kù yìí wàásù fún gbogbo èèyàn. Àpọ́sítélì Pétérù rọ̀ wá pé ká máa ‘fi ọjọ́ Jèhófà sọ́kàn.’ (2 Pét. 3:​11, 12) Báwo la ṣe lè ṣe é? A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń ronú lójoojúmọ́ nípa àwọn ohun rere tá a máa gbádùn nínú ayé tuntun. Fojú inú wò ó pé ò ń mí afẹ́fẹ́ tó mọ́ símú, ò ń jẹ oúnjẹ aṣaralóore, ò ń kí àwọn èèyàn ẹ tó jíǹde káàbọ̀, o sì ń ṣàlàyé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tó ti ṣẹ fáwọn tó ti gbé ayé ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn. Tó o bá ń ronú nípa irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀, wàá máa fayọ̀ retí àkókò yẹn, á sì dá ẹ lójú pé òpin ò ní pẹ́ dé mọ́. Tá a bá “mọ àwọn nǹkan yìí tẹ́lẹ̀,” àwọn olùkọ́ èké ò ní ‘ṣì wá lọ́nà.’ w23.09 27 ¶5-6

Sunday, March 16

Ẹ máa gbọ́ràn sí àwọn òbí yín lẹ́nu nínú Olúwa, nítorí èyí jẹ́ òdodo.—Éfé. 6:1.

Àwọn ọ̀dọ́ sábà máa ń wà pẹ̀lú àwọn ọ̀dọ́ míì tó máa ń ‘ṣàìgbọràn sí òbí’ wọn. (2 Tím. 3:​1, 2) Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ lára wọn fi ń ṣàìgbọràn? Àwọn ọ̀dọ́ kan gbà pé alágàbàgebè ni òbí àwọn torí wọn kì í ṣe ohun tí wọ́n sọ pé káwọn máa ṣe. Àwọn ọ̀dọ́ míì sì gbà pé ìmọ̀ràn òbí àwọn ò bágbà mu mọ́, kò bọ́gbọ́n mu, ó sì ti le jù. Tó o bá jẹ́ ọ̀dọ́, ṣé ìwọ náà ti ronú bẹ́ẹ̀ rí? Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ló máa ń nira fún láti tẹ̀ lé àṣẹ Jèhófà bó ṣe wà nínú ẹsẹ ojúmọ́ tòní. Kí ló máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti máa gbọ́ràn sáwọn òbí ẹ lẹ́nu? Ẹ̀yin ọ̀dọ́ lè kẹ́kọ̀ọ́ lára àpẹẹrẹ rere Jésù nípa bó ṣe yẹ kẹ́ ẹ jẹ́ onígbọràn. (1 Pét. 2:​21-24) Ẹni pípé ni Jésù, àmọ́ aláìpé làwọn òbí ẹ̀. Síbẹ̀, Jésù máa ń bọ̀wọ̀ fáwọn òbí ẹ̀, kódà tí wọ́n bá ṣàṣìṣe tàbí tí wọ́n bá ṣì í lóye nígbà míì.—Ẹ́kís. 20:12. w23.10 7 ¶4-5

Monday, March 17

A pa àṣẹ ti tẹ́lẹ̀ tì torí pé kò lágbára, kò sì gbéṣẹ́ mọ́.—Héb. 7:18.

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé àwọn ẹbọ tí Òfin náà sọ pé kí wọ́n máa rú kò lè mú ẹ̀ṣẹ̀ kúrò pátápátá. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ‘pa Òfin náà tì.’ Torí náà, Pọ́ọ̀lù bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wọn láwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó jinlẹ̀. Ó rán àwọn Kristẹni yẹn létí pé ẹbọ tí Jésù fi ara ẹ̀ rú ni “ìrètí tó dáa jù,” òun ló sì lè mú kí wọ́n “sún mọ́ Ọlọ́run.” (Héb. 7:19) Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé fáwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù nípa bí ẹ̀sìn Kristẹni tí wọ́n ń ṣe báyìí ṣe dáa gan-an ju ìjọsìn àwọn Júù tí wọ́n ń ṣe tẹ́lẹ̀ lọ. Ohun tí wọ́n ń ṣe nínú ìjọsìn àwọn Júù jẹ́ “òjìji àwọn ohun tó ń bọ̀, àmọ́ Kristi ni ohun gidi náà.” (Kól. 2:17) Òjìji ni àwòrán tó máa ń jẹ́ ká mọ bí ohun kan ṣe rí. Lọ́nà kan náà, ọ̀nà táwọn Júù ń gbà jọ́sìn láyé àtijọ́ jẹ́ ká mọ bí ìjọsìn tòótọ́ ṣe máa rí lọ́jọ́ iwájú. Torí náà, ó yẹ ká lóye ètò tí Jèhófà ṣe láti dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá ká lè jọ́sìn ẹ̀ bó ṣe fẹ́. w23.10 25 ¶4-5

Tuesday, March 18

Ní àkókò òpin, ọba gúúsù máa kọ lù ú, ọba àríwá sì máa rọ́ lù ú.—Dán. 11:40.

Dáníẹ́lì orí 11 sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọba méjì kan tí wọ́n ń bá ara wọn jìjàkadì, kí wọ́n lè mọ ẹni tó máa ṣàkóso ayé. Tá a bá fi àsọtẹ́lẹ̀ yìí wé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ míì nínú Bíbélì, a máa rí i pé ìjọba Rọ́ṣíà àtàwọn tó ń tì í lẹ́yìn ni “ọba àríwá,” ìjọba Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà sì ni “ọba gúúsù.” Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó ń gbé láwọn ìlú tí “ọba àríwá” ti ń ṣàkóso ń fara da inúnibíni tí ọba yìí ń ṣe sí wọn. Ọba yìí ti fìyà jẹ àwọn ará wa kan, ó sì jù wọ́n sẹ́wọ̀n nítorí ohun tí wọ́n gbà gbọ́. Dípò kí ohun tí “ọba àríwá” ṣe yìí dẹ́rù ba àwọn ará wa, ṣe ló túbọ̀ jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wọn lágbára. Kí nìdí tí wọn ò fi bẹ̀rù? Ìdí ni pé àwọn ará wa mọ̀ pé inúnibíni tí wọ́n ń ṣe sáwọn ń jẹ́ kí àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì ṣẹ. (Dán. 11:41) Ohun tá a mọ̀ yìí mú kó dá àwa náà lójú pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa, á sì mú ká jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. w23.08 11-12 ¶15-16

Wednesday, March 19

Ẹni tó bá fọwọ́ kàn yín ń fọwọ́ kan ẹyinjú mi.—Sek. 2:8.

Torí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, ó mọ bí nǹkan ṣe rí lára wa, ó sì ṣe tán láti dáàbò bò wá. Tí inú wa ò bá dùn, inú Jèhófà náà kì í dùn. Torí náà, tá a bá bẹ̀ ẹ́ pé kó ‘dáàbò bò wá bí ọmọlójú ẹ̀,’ ó dájú pé ó máa gbọ́ tiwa. (Sm. 17:8) Ẹ̀yà ara tó gbẹgẹ́, tó sì ṣeyebíye gan-an ni ojú wa. Torí náà, bí Jèhófà ṣe fi wá wé ẹyinjú ẹ̀ dà bí ìgbà tó ń sọ pé, ‘Ẹni tó bá hùwà ìkà sí ẹ̀yin èèyàn mi ń hùwà ìkà sóhun tó ṣeyebíye sí mi.’ Jèhófà fẹ́ kó dá ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lójú pé òun nífẹ̀ẹ́ wa lóòótọ́. Àmọ́ ó mọ̀ pé nítorí àwọn nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ sí wa sẹ́yìn, ó lè máa ṣe wá bíi pé bóyá ló nífẹ̀ẹ́ wa. Àwọn nǹkan kan sì lè máa ṣẹlẹ̀ sí wa báyìí tó lè mú ká rò pé bóyá ni Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa. Kí ló máa jẹ́ ká mọ̀ pé lóòótọ́ ni Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa? Ohun tó máa jẹ́ ká mọ̀ ni tá a bá kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí Jèhófà ṣe fìfẹ́ hàn sí Jésù, àwọn ẹni àmì òróró àti gbogbo wa lápapọ̀. w24.01 27 ¶6-7

Thursday, March 20

Ọwọ́ Ọlọ́run wa sì wà lára wa, ó gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá.—Ẹ́sírà 8:31.

Ẹ́sírà ti rí bí Jèhófà ṣe ran àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ lọ́wọ́ nígbà àdánwò. Ní ọdún díẹ̀ ṣáájú 484 Ṣ.S.K., ó jọ pé Bábílónì ni Ẹ́sírà ń gbé nígbà tí Ọba Ahasuérúsì pàṣẹ pé kí wọ́n pa àwọn Júù tó wà ní Ilẹ̀ Páṣíà run. (Ẹ́sít. 3:​7, 13-15) Ó dájú pé ẹ̀mí Ẹ́sírà wà nínú ewu! Nígbà tí àwọn Júù “tó wà ní gbogbo ìpínlẹ̀” náà gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, wọ́n gbààwẹ̀, wọ́n ṣọ̀fọ̀, ó sì dájú pé wọ́n máa gbàdúrà sí Jèhófà pé kó tọ́ àwọn sọ́nà. (Ẹ́sít. 4:3) Ẹ wo bó ṣe máa rí lára Ẹ́sírà àtàwọn Júù yòókù nígbà tí ọ̀rọ̀ náà yí dà sórí àwọn ọlọ̀tẹ̀ tí wọ́n gbìmọ̀ pọ̀ láti pa àwọn Júù! (Ẹ́sít. 9:​1, 2) Àwọn nǹkan tójú Ẹ́sírà rí nígbà àdánwò yẹn máa jẹ́ kó múra sílẹ̀ de àwọn ìṣòro ọjọ́ iwájú, á sì jẹ́ kó túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé ó máa dáàbò bo àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀. w23.11 17 ¶12-13

Friday, March 21

Ọlọ́run ka [èèyàn] sí olódodo láìka àwọn iṣẹ́ rẹ̀ sí.—Róòmù 4:6.

Ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù dìídì ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ ni “àwọn iṣẹ́ òfin,” ìyẹn òfin tí Jèhófà fún Mósè lórí Òkè Sínáì. (Róòmù 3:​21, 28) Ó jọ pé nígbà ayé Pọ́ọ̀lù, àwọn Júù kan tí wọ́n jẹ́ Kristẹni ń sọ pé àwọn gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé Òfin Mósè. Torí náà, Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa Ábúráhámù láti fi hàn pé kì í ṣe “àwọn iṣẹ́ òfin” ló ń mú kẹ́nì kan jẹ́ olódodo lójú Ọlọ́run, ìgbàgbọ́ ni. Ìyẹn múnú wa dùn torí ó jẹ́ kó dá wa lójú pé a lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run. Á ṣeé ṣe fún wa láti nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run àti Kristi, á sì jẹ́ ká rí ojú rere Jèhófà. “Àwọn iṣẹ́” tí Jémíìsì orí kejì sọ yàtọ̀ sí “àwọn iṣẹ́ òfin” tí Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀. Iṣẹ́ tí Jémíìsì ń sọ ni àwọn nǹkan táwa Kristẹni máa ń ṣe déédéé. (Jém. 2:24) Irú àwọn iṣẹ́ yìí máa ń jẹ́ ká mọ̀ bóyá Kristẹni kan nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run lóòótọ́ tàbí kò ní. w23.12 3 ¶8; 4-5 ¶10-11

Saturday, March 22

Ọkọ ni orí aya rẹ̀.—Éfé. 5:23.

Tó o bá jẹ́ arábìnrin, tó o sì ń ronú láti lọ́kọ, ó yẹ kó o fara balẹ̀ yan ẹni tó o máa fẹ́. Rántí pé ọkọ tó o bá fẹ́ ni Ọlọ́run sọ pé ó máa jẹ́ orí ẹ. (Róòmù 7:2; Éfé. 5:33) Torí náà, bi ara ẹ pé: ‘Ṣé Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀ ni? Ṣé ìjọsìn Jèhófà gbawájú láyé ẹ̀? Ṣé ó máa ń ṣe ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu? Ṣé ó máa ń gbà pé òun ṣàṣìṣe? Ṣé ó máa ń bọ̀wọ̀ fáwọn obìnrin? Ṣé á jẹ́ kí n túbọ̀ ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, ṣé á lè pèsè àwọn nǹkan tí mo nílò, tá á sì dúró tì mí nígbà ìṣòro?’ Ká sòótọ́, tó o bá fẹ́ rí ọkọ rere, ìwọ náà gbọ́dọ̀ máa ṣe àwọn nǹkan tó fi hàn pé o máa jẹ́ aya rere. Aya rere gbọ́dọ̀ jẹ́ “olùrànlọ́wọ́” ọkọ àti “ẹnì kejì” rẹ̀. (Jẹ́n. 2:18) Torí pé ó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, á máa ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe kí orúkọ rere tí ọkọ ẹ̀ ní má bàa bà jẹ́. (Òwe 31:​11, 12; 1 Tím. 3:11) Torí náà, tó o bá fẹ́ ṣe ojúṣe tó o máa ní dáadáa, jẹ́ kí ìfẹ́ tó o ní fún Jèhófà túbọ̀ lágbára, kó o sì máa ran àwọn tó wà nínú ìdílé ẹ àtàwọn ará ìjọ lọ́wọ́. w23.12 22-23 ¶18-19

Sunday, March 23

Tí ẹnikẹ́ni nínú yín ò bá ní ọgbọ́n, kó máa béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run.—Jém. 1:5.

Jèhófà ṣèlérí pé òun máa fún wa lọ́gbọ́n táá jẹ́ ká máa ṣèpinnu tó dáa. Ó ṣe pàtàkì pé kí Jèhófà fún wa lọ́gbọ́n tá a bá fẹ́ ṣe ìpinnu pàtàkì láyé wa. Jèhófà tún máa ń fún wa lágbára láti fara da àwọn ìṣòro wa bó ṣe fún àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lókun. (Fílí. 4:13) Ọ̀kan lára ọ̀nà tó ń gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ó máa ń lo àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa. Jésù gbàdúrà gan-an lálẹ́ tó ṣáájú ikú ẹ̀. Ó bẹ Jèhófà pé kó má jẹ́ káwọn èèyàn ka òun sí asọ̀rọ̀ òdì. Dípò kí Jèhófà ṣe ohun tó sọ yẹn, ṣe ló rán ọ̀kan lára àwọn áńgẹ́lì tó jẹ́ arákùnrin Jésù pé kó wá fún un lókun. (Lúùkù 22:​42, 43) Bákan náà, Jèhófà lè mú kí ọ̀kan lára àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa pè wá lórí fóònù tàbí kí wọ́n wá sọ́dọ̀ wa láti fún wa níṣìírí. Torí náà, gbogbo wa ló yẹ ká máa wá bá a ṣe máa sọ “ọ̀rọ̀ rere” fáwọn tá a jọ ń sin Jèhófà.—Òwe 12:25. w23.05 10-11 ¶9-11

Monday, March 24

Ẹ máa fún ara yín níṣìírí, kí ẹ sì máa gbé ara yín ró.—1 Tẹs. 5:11.

Ó ṣeé ṣe kẹ́rù máa ba àwọn aláìṣiṣẹ́mọ́ tó wá sí Ìrántí Ikú Kristi pé àwọn ará máa fojú tí ò dáa wo àwọn. Torí náà, má bi wọ́n ní ìbéèrè tó máa kó ìtìjú bá wọn, má sì sọ ohunkóhun tó máa dùn wọ́n. Ó ṣe tán, arákùnrin àti arábìnrin wa ni wọ́n. Inú wa sì dùn pé a ti fẹ́ jọ máa sin Jèhófà pa pọ̀ báyìí! (Sm. 119:176; Ìṣe 20:35) Inú wa dùn pé Jésù ní ká máa rántí ikú òun lọ́dọọdún, a sì mọ ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa ṣe bẹ́ẹ̀. Tá a bá lọ síbi Ìrántí Ikú Kristi, àwa àtàwọn tó bá lọ máa jàǹfààní. (Àìsá. 48:​17, 18) Á jẹ́ ká túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti Jésù. Ó tún máa ń jẹ́ ká fi hàn pé a mọyì ohun tí wọ́n ṣe fún wa. Yàtọ̀ síyẹn, ó máa ń jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ àwọn tá a jọ ń sin Jèhófà. A tún lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ àwọn ohun rere tí wọ́n máa gbádùn nítorí ìràpadà tí Jésù san. Torí náà, ẹ jẹ́ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti múra sílẹ̀ de Ìrántí Ikú Kristi tọdún yìí torí ọjọ́ yẹn ló ṣe pàtàkì jù lọ́dún! w24.01 14 ¶18-19

Tuesday, March 25

Èmi, Jèhófà, ni . . . Ẹni tó ń jẹ́ kí o mọ ọ̀nà tó yẹ kí o máa rìn.—Àìsá. 48:17.

Báwo ni Jèhófà ṣe ń tọ́ wa sọ́nà? Ohun àkọ́kọ́ tó máa ń lò ni Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Àmọ́ ó tún máa ń lo àwọn èèyàn láti tọ́ wa sọ́nà. Bí àpẹẹrẹ, ó máa ń lo “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” láti fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ bọ́ wa, ká lè máa ṣe àwọn ìpinnu tó tọ́. (Mát. 24:45) Jèhófà tún máa ń lo àwọn arákùnrin tó kúnjú ìwọ̀n láti tọ́ wa sọ́nà. Bí àpẹẹrẹ, àwọn alábòójútó àyíká àtàwọn alàgbà ìjọ máa ń fún wa níṣìírí, wọ́n sì máa ń tọ́ wa sọ́nà nígbà ìṣòro. A mà mọyì bí Jèhófà ṣe ń tọ́ wa sọ́nà láwọn ọjọ́ ìkẹyìn tí nǹkan nira yìí o! Àwọn ìtọ́sọ́nà yìí máa ń jẹ́ ká rójú rere Jèhófà, ó sì ń jẹ́ ká máa rìn nìṣó lójú ọ̀nà ìyè àìnípẹ̀kun. Síbẹ̀, ó lè má rọrùn láti ṣe ohun tí Jèhófà sọ pàápàá tó bá jẹ́ pé àwọn èèyàn aláìpé bíi tiwa ló sọ pé ká ṣe nǹkan náà. Irú àwọn àsìkò yẹn gan-an ló yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé òun ló ń darí àwọn èèyàn ẹ̀, tá a bá sì ń tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà ẹ̀, a máa jàǹfààní gan-an. w24.02 20 ¶2-3

Wednesday, March 26

Kò yẹ kí ìfẹ́ wa jẹ́ ọ̀rọ̀ ẹnu tàbí ti ahọ́n, àmọ́ ó yẹ kó jẹ́ ní ìṣe àti òtítọ́.—1 Jòh. 3:18.

Tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé, ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà á túbọ̀ lágbára. Bó o ṣe ń ka Bíbélì, ronú jinlẹ̀ nípa ibi tó ò ń kà, kó o lè rí nǹkan kọ́ nípa Jèhófà. Bi ara ẹ pé: ‘Báwo lohun tí mo kà yìí ṣe jẹ́ kí n mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ mi? Báwo lohun tí mo kà yìí ṣe jẹ́ kí n rí i pé ó yẹ kí n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà?’ Ohun míì tó máa jẹ́ ká túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ni pé ká máa sọ ohun tó wà lọ́kàn wa fún un tá a bá ń gbàdúrà. (Sm. 25:​4, 5) Ó sì dájú pé Jèhófà máa gbọ́ wa. (1 Jòh. 3:​21, 22) A gbọ́dọ̀ máa ṣe ohun táá jẹ́ ká túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn. Lẹ́yìn ọdún díẹ̀ tí Pọ́ọ̀lù di Kristẹni, ó pàdé ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Tímótì. Tímótì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àtàwọn ará. Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn ará Fílípì pé: “Mi ò ní ẹlòmíì tó níwà bíi [Tímótì] tó máa fi òótọ́ inú bójú tó ọ̀rọ̀ yín.” (Fílí. 2:20) Ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ nínú ẹsẹ Bíbélì yìí ni bí Tímótì ṣe ń fìfẹ́ hàn sáwọn ará. Torí náà, ó dájú pé inú àwọn ará ìjọ máa ń dùn gan-an tí wọ́n bá gbọ́ pé Tímótì ń bọ̀ wá bẹ àwọn wò.—1 Kọ́r. 4:17. w23.07 9 ¶7-10

Thursday, March 27

Mi ò ní pa ọ́ tì láé.—Héb. 13:5.

Mósè ti kú káwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wọ Ilẹ̀ Ìlérí. Ṣé torí pé ọkùnrin olóòótọ́ yìí kú, Jèhófà ò wá ran àwọn èèyàn ẹ̀ lọ́wọ́ mọ́? Rárá o. Ní gbogbo ìgbà tí wọ́n fi jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà, ó ń bójú tó wọn. Kí Mósè tó kú, Jèhófà sọ fún un pé kó yan Jóṣúà kó lè máa darí àwọn èèyàn òun. Ọ̀pọ̀ ọdún sì ni Mósè ti fi dá Jóṣúà lẹ́kọ̀ọ́. (Ẹ́kís. 33:11; Diu. 34:9) Yàtọ̀ síyẹn, ó tún yan ọ̀pọ̀ ọkùnrin tó kúnjú ìwọ̀n láti jẹ́ olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún, olórí ọgọ́rọ̀ọ̀rún, olórí àràádọ́ta àti olórí àwọn mẹ́wàá-mẹ́wàá. (Diu. 1:15) Ohun tó ṣe yìí jẹ́ kí wọ́n lè bójú tó àwọn èèyàn Ọlọ́run dáadáa. Èlíjà náà ṣe ohun tó jọ ìyẹn. Ọ̀pọ̀ ọdún ló fi ṣiṣẹ́ kára láti ran àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa jọ́sìn Jèhófà. Àmọ́ nígbà tó yá, Jèhófà yan iṣẹ́ míì fún un ní apá gúúsù ilẹ̀ Júdà. (2 Ọba 2:1; 2 Kíró. 21:12) Ṣé Jèhófà wá pa ẹ̀yà mẹ́wàá ìjọba Ísírẹ́lì tó wà ní apá àríwá tì? Rárá o. Ọ̀pọ̀ ọdún ni Èlíjà ti fi ń dá Èlíṣà lẹ́kọ̀ọ́. Jèhófà ò ṣíwọ́ láti mú ohun tó ní lọ́kàn ṣẹ, ó ń rí i dájú pé òun bójú tó àwọn tó ń fi òótọ́ sin òun. w24.02 5 ¶12

Friday, March 28

Ẹ máa rìn gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìmọ́lẹ̀.—Éfé. 5:8.

Àwọn Kristẹni tó wà ní Éfésù ti kẹ́kọ̀ọ́, wọ́n sì ti lóye òtítọ́ inú Ìwé Mímọ́. (Sm. 119:105) Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n ti pa ẹ̀sìn èké àti ìṣekúṣe tì. Wọ́n ti wá ń “fara wé Ọlọ́run,” wọ́n sì ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti sin Jèhófà, kí wọ́n sì múnú ẹ̀ dùn. (Éfé. 5:1) Bíi tàwọn ará Éfésù yẹn, ká tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, ẹ̀sìn èké làwa náà ń ṣe tẹ́lẹ̀, a sì máa ń hùwàkiwà. Àwọn kan lára wa máa ń ṣe àwọn ayẹyẹ tí wọ́n ń ṣe nínú ẹ̀sìn èké, àwọn kan sì máa ń ṣèṣekúṣe. Àmọ́ nígbà tá a kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tí Jèhófà fẹ́ àtohun tí kò fẹ́, a ṣàtúnṣe. A bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ìgbé ayé wa lọ́nà tó bá ìfẹ́ ẹ̀ mu, ìyẹn sì ṣe wá láǹfààní gan-an. (Àìsá. 48:17) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a máa ń ní ìṣòro, ó ṣe pàtàkì pé ká sá fún òkùnkùn tá a ti fi sílẹ̀, ká sì “máa rìn gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìmọ́lẹ̀.” w24.03 21 ¶6-7

Saturday, March 29

Níbi tí a tẹ̀ síwájú dé, ẹ jẹ́ kí a máa rìn létòlétò ní ọ̀nà kan náà.—Fílí. 3:16.

Ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé o ò tíì ṣe tán láti ya ara ẹ sí mímọ́, kó o sì ṣèrìbọmi. Bóyá ó ṣì yẹ kó o ṣe àwọn àyípadà kan nígbèésí ayé ẹ kó o lè máa tẹ̀ lé gbogbo ìlànà Jèhófà tàbí kó o máa wò ó pé ó yẹ kó o ṣì ní sùúrù kígbàgbọ́ ẹ lè túbọ̀ lágbára. (Kól. 2:​6, 7) Ká sòótọ́, bí ẹnì kan tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe máa yára tẹ̀ síwájú, tó sì máa nífẹ̀ẹ́ Jèhófà máa yàtọ̀ sí ti ẹlòmíì, kì í sì í ṣe ọjọ́ orí kan náà ni gbogbo àwọn ọ̀dọ́ máa ń ṣe tán láti ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà, kí wọ́n sì ṣèrìbọmi. Torí náà bó o ṣe ń tẹ̀ síwájú, gbìyànjú láti mọ àwọn nǹkan tó kù tó yẹ kó o ṣe, kó o sì rí i pé o ṣe àwọn nǹkan náà, àmọ́ má ṣe fi ara ẹ wé àwọn ẹlòmíì. (Gál. 6:​4, 5) Kódà, tó o bá rí i pé o ò tíì ṣe tán láti ya ara ẹ sí mímọ́ fún Jèhófà, fi ṣe àfojúsùn ẹ pé o máa ṣe bẹ́ẹ̀. Gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè ṣe àwọn àtúnṣe tó bá yẹ nígbèésí ayé ẹ. (Fílí. 2:13) Torí náà, mọ̀ dájú pé ó máa gbọ́ àdúrà ẹ, á sì ràn ẹ́ lọ́wọ́.—1 Jòh. 5:14. w24.03 5 ¶9-10

Sunday, March 30

Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa fi òye bá [ìyàwó yín] gbé.—1 Pét. 3:7.

Ìgbà kan wà tí nǹkan tojú sú Sérà, ó sì bínú sí Ábúráhámù, kódà ó di ẹ̀bi ọ̀rọ̀ náà ru Ábúráhámù pàápàá. Ábúráhámù mọ̀ pé aya rere ni Sérà, ó máa ń tẹrí ba fún òun, ó sì máa ń ti òun lẹ́yìn. Torí náà, Ábúráhámù gbọ́ ohun tó sọ, ó sì ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti yanjú ọ̀rọ̀ náà. (Jẹ́n. 16:​5, 6) Kí lẹ̀yin ọkọ rí kọ́ lára Ábúráhámù? Ẹ̀yin ọkọ, òótọ́ ni pé ẹ̀yin lẹ láṣẹ láti ṣèpinnu fún ìdílé yín. (1 Kọ́r. 11:3) Síbẹ̀, ohun tó dáa jù ni pé kẹ́ ẹ fara balẹ̀ tẹ́tí sí ìyàwó yín kẹ́ ẹ tó ṣèpinnu, pàápàá tó bá jẹ́ pé ìpinnu yẹn máa kàn án. (1 Kọ́r. 13:​4, 5) Ìgbà kan tún wà tí àwọn èèyàn kan tí Ábúráhámù ò retí wá sọ́dọ̀ ẹ̀, ó sì fẹ́ ṣe wọ́n lálejò. Torí náà ó ní kí Sérà fi ohun tó ń ṣe sílẹ̀, kó sì lọ ṣe búrẹ́dì rẹpẹtẹ fáwọn àlejò náà. (Jẹ́n. 18:6) Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Sérà lọ ṣe ohun tí Ábúráhámù ní kó ṣe, ó sì fi hàn pé òun fara mọ́ ìpinnu tí ọkọ òun ṣe. Ẹ̀yin aya, ẹ̀yin náà lè fara wé Sérà, kẹ́ ẹ sì fi hàn pé ẹ̀ ń fara mọ́ ìpinnu tí ọkọ yín bá ṣe. Tẹ́ ẹ bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àárín yín á túbọ̀ gún régé.—1 Pét. 3:​5, 6. w23.05 24-25 ¶16-17

Monday, March 31

Ọgbọ́n tó wá láti òkè . . . ṣe tán láti ṣègbọràn.—Jém. 3:17.

Lẹ́yìn tí Gídíónì di onídàájọ́, Jèhófà gbé iṣẹ́ kan fún un tó máa gba pé kó jẹ́ onígbọràn àti onígboyà. Jèhófà ní kó lọ wó pẹpẹ Báálì bàbá rẹ̀ lulẹ̀. (Oníd. 6:​25, 26) Lẹ́yìn ìyẹn, Gídíónì lọ kó àwọn ọmọ ogun jọ, àmọ́ ẹ̀ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Jèhófà ní kó dín iye àwọn ọmọ ogun náà kù. (Oníd. 7:​2-7) Níkẹyìn, Jèhófà sọ fún un pé ọ̀gànjọ́ òru ni kó lọ gbéjà ko àwọn ọ̀tá ní ibùdó wọn. (Oníd. 7:​9-11) Ẹ̀yin alàgbà gbọ́dọ̀ “ṣe tán láti ṣègbọràn.” Alàgbà tó jẹ́ onígbọràn máa ń ṣe ohun tí Ìwé Mímọ́ àti ètò Ọlọ́run sọ. Tó bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àpẹẹrẹ rere ló máa jẹ́ fáwọn ará. Síbẹ̀, àwọn nǹkan kan lè mú kó ṣòro fún un láti jẹ́ onígbọràn. Bí àpẹẹrẹ, ètò Ọlọ́run lè sọ pé ká ṣe àwọn nǹkan kan, àwọn nǹkan náà sì lè yí pa dà léraléra, kó sì nira fún alàgbà náà láti ṣe ohun tí ètò Ọlọ́run sọ. Àwọn ìgbà míì wà tó lè máa wò ó pé ohun tí ètò Ọlọ́run ní ká ṣe ò bọ́gbọ́n mu. Wọ́n sì lè ní kó lọ ṣiṣẹ́ kan tó lè jẹ́ káwọn aláṣẹ ìjọba sọ pé kí wọ́n lọ mú un. Torí náà, báwo lẹ̀yin alàgbà ṣe lè jẹ́ onígbọràn bíi ti Gídíónì tírú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀? Máa fara balẹ̀ tẹ́tí sí ohun tí ètò Ọlọ́run sọ, kó o sì ṣe é. w23.06 4-5 ¶9-11

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́