May
Thursday, May 1
Ìyàn ńlá máa tó mú.—Ìṣe 11:28.
Àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ wà lára àwọn tí ìyàn ńlá mú “ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé.” Ó dájú pé ìdààmú máa bá àwọn olórí ìdílé torí wọ́n á máa ronú bí wọ́n á ṣe wá oúnjẹ fún ìdílé wọn. Kí lẹ rò pé ó lè ṣẹlẹ̀ sáwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n ti ń ṣètò bí wọ́n ṣe máa ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù? Ṣé wọ́n lè máa ronú pé káwọn dúró dìgbà tí ìyàn náà máa parí káwọn tó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe púpọ̀ sí i? Láìka ipò tí wọ́n bá ara wọn sí, wọ́n ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe. Wọ́n lo gbogbo àǹfààní tí wọ́n ní láti wàásù, inú wọn sì dùn pé àwọn fi nǹkan ránṣẹ́ sáwọn ará ní Jùdíà. (Ìṣe 11:29, 30) Nígbà táwọn Kristẹni yẹn rí oúnjẹ àtàwọn nǹkan míì tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí wọn gbà, wọ́n rí i pé Jèhófà ń ran àwọn lọ́wọ́. (Mát. 6:31-33) Ìrànwọ́ tí wọ́n rí gbà yìí máa jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ mọyì àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó fi nǹkan ránṣẹ́ sí wọn. Àwọn tó mú nǹkan wá àtàwọn tó lọ fi jíṣẹ́ ń láyọ̀ torí wọ́n ran àwọn ará lọ́wọ́.—Ìṣe 20:35. w23.04 16 ¶12-13
Friday, May 2
A mọ̀ pé a máa rí àwọn ohun tí a béèrè gbà, torí pé a béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.—1 Jòh. 5:15.
Nígbà míì, bí Jèhófà ṣe máa ń dáhùn àdúrà wa ni pé ó máa ń lo àwọn tí kì í ṣe ìránṣẹ́ ẹ̀ láti ràn wá lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, ó mú kí Ọba Atasásítà gba Nehemáyà láyè láti lọ sí Jerúsálẹ́mù kó lè tún ìlú náà kọ́. (Neh. 2:3-6) Bákan náà lónìí, Jèhófà lè lo àwọn tí kì í ṣe ìránṣẹ́ ẹ̀ láti ràn wá lọ́wọ́ tá a bá níṣòro. Kì í ṣe gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń dáhùn àdúrà wa lọ́nà àrà ọ̀tọ̀. Àmọ́, tó bá máa dáhùn ẹ̀, ó dájú pé ohun tó máa jẹ́ ká jẹ́ olóòótọ́ sí i ló máa ṣe fún wa. Torí náà, máa kíyè sí bí Jèhófà ṣe ń dáhùn àdúrà ẹ. Látìgbàdégbà, máa ronú jinlẹ̀ nípa bí Jèhófà ṣe ń dáhùn àwọn àdúrà ẹ. (Sm. 66:19, 20) Kì í ṣe àdúrà tá à ń gbà nìkan ló ń fi hàn pé a nígbàgbọ́ nínú Jèhófà. A tún máa fi hàn pé a nígbàgbọ́ tá a bá fara mọ́ bí Jèhófà ṣe dáhùn àdúrà wa.—Héb. 11:6. w23.05 12 ¶13, 15-16
Saturday, May 3
Láti ṣe ìfẹ́ rẹ, Ọlọ́run mi, ni inú mi dùn sí.—Sm. 40:8.
Nígbà tá a ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà, a ṣèlérí pé òun làá máa jọ́sìn, ìfẹ́ ẹ̀ làá sì máa ṣe. Ó yẹ ká mú ẹ̀jẹ́ wa ṣẹ. Ẹ̀jẹ́ tá a jẹ́ pé Jèhófà la máa sìn kì í ṣe nǹkan tó nira láti ṣe. Kí nìdí? Ìdí ni pé Jèhófà dá wa ká lè máa ṣe ìfẹ́ ẹ̀. (Ìfi. 4:11) Ó dá wa ní àwòrán ara ẹ̀ kó lè máa wù wá láti jọ́sìn ẹ̀. Ìyẹn jẹ́ ká lè sún mọ́ ọn, kí inú wa sì máa dùn bá a ṣe ń ṣe ìfẹ́ ẹ̀. Bákan náà, tá a bá ń ṣèfẹ́ Ọlọ́run, tá a sì ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Ọmọ ẹ̀, “ara” máa “tù” wá. (Mát. 11:28-30) Torí náà, máa ṣe ohun táá jẹ́ kí ìfẹ́ tó o ní fún Jèhófà lágbára sí i, o sì lè ṣe bẹ́ẹ̀ tó o bá ń ronú nípa àwọn nǹkan tí Jèhófà ti ṣe fún ẹ àtàwọn ohun rere tó máa ṣe fún ẹ lọ́jọ́ iwájú. Bó o bá ṣe ń nífẹ̀ẹ́ Jèhófà sí i, bẹ́ẹ̀ lá máa rọrùn fún ẹ láti pa àwọn àṣẹ ẹ̀ mọ́. (1 Jòh. 5:3) Ohun tó jẹ́ kí Jésù lè ṣèfẹ́ Ọlọ́run láṣeyọrí ni pé ó máa ń gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ran òun lọ́wọ́, ó sì gbájú mọ́ èrè tó máa gbà lọ́jọ́ iwájú. (Héb. 5:7; 12:2) Bíi ti Jésù, bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ lókun, kó lè túbọ̀ dá ẹ lójú pé wàá rí ìyè àìnípẹ̀kun gbà lọ́jọ́ iwájú. w23.08 27-28 ¶4-5
Sunday, May 4
Ṣé o fojú kéré ọlá inú rere rẹ̀ àti ìmúmọ́ra pẹ̀lú sùúrù rẹ̀, torí o ò mọ̀ pé Ọlọ́run, nínú inú rere rẹ̀, fẹ́ darí rẹ sí ìrònúpìwàdà?—Róòmù 2:4.
Gbogbo wa la mọyì àwọn tó bá jẹ́ onísùúrù. Kí nìdí? Ìdí ni pé wọ́n máa ń fi sùúrù dúró de nǹkan, nǹkan kì í sì í tètè sú wọn. Tá a bá ṣàṣìṣe, a máa ń mọyì ẹ̀ táwọn èèyàn bá ní sùúrù fún wa. Yàtọ̀ síyẹn, a mọyì báwọn tó kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe ní sùúrù fún wa nígbà tí ẹ̀kọ́ tí wọ́n ń kọ́ wa ò tètè yé wa tàbí nígbà tó ṣòro fún wa láti gba àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì kan tàbí tí kò rọrùn láti fi í sílò. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, a máa ń mọyì ẹ̀ pé Jèhófà Ọlọ́run máa ń ní sùúrù fún gbogbo wa! Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a máa ń mọyì àwọn tó bá ní sùúrù, láwọn ìgbà míì, ó lè má rọrùn fún wa láti ní sùúrù. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá wà nínú sún-kẹrẹ-fà-kẹrẹ ọkọ̀, ó lè má rọrùn fún wa láti ní sùúrù pàápàá tá a bá ti ń pẹ́. Táwọn èèyàn bá múnú bí wa, a lè gbaná jẹ dípò ká ní sùúrù. Nígbà míì sì rèé, ó lè má rọrùn fún wa láti máa fi sùúrù dúró de ayé tuntun tí Jèhófà ṣèlérí. Bó ti wù kó rí, ó ṣe pàtàkì ká túbọ̀ máa ní sùúrù. w23.08 20 ¶1-2
Monday, May 5
Ó ní kí gbogbo ọkùnrin Ísírẹ́lì yòókù pa dà sílé, àwọn ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) ọkùnrin náà nìkan ló sì ní kó dúró.—Oníd. 7:8.
Jèhófà sọ fún Gídíónì pé kó dá ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ ogun ẹ̀ pa dà sílé, torí náà àwọn tó kù ò tó nǹkan rárá. Ó ṣeé ṣe kó ronú pé: ‘Ṣé dandan ni kí wọ́n pa dà sílé ni? Ṣé ìwọ̀nba àwọn tó kù yìí máa lè jagun ṣẹ́gun?’ Èyí ó wù ó jẹ́, Gídíónì ṣègbọràn. Lónìí, àwọn alàgbà náà lè fara wé Gídíónì. Tí àyípadà bá dé bá ohun tí ètò Ọlọ́run ní kí wọ́n ṣe, ó yẹ kí wọ́n ṣe é. (Héb. 13:17) Iṣẹ́ tí Jèhófà gbé fún Gídíónì ò rọrùn, ẹ̀rù sì ń bà á, síbẹ̀ ó ṣègbọràn. (Oníd. 9:17) Lẹ́yìn tí Jèhófà sọ fún Gídíónì pé òun máa wà pẹ̀lú ẹ̀, ó dá Gídíónì lójú pé Jèhófà máa ran òun lọ́wọ́ láti dáàbò bo àwọn èèyàn Ọlọ́run. Torí náà, ó yẹ kẹ́yin alàgbà tó ń gbé láwọn ibi tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ wa fara wé Gídíónì. Ẹ sì lè ṣe bẹ́ẹ̀ táwọn ará bá ń rí i tẹ́ ẹ̀ ń bójú tó ìpàdé, tẹ́ ẹ sì ń fìgboyà wàásù pẹ̀lú wọn, bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn aláṣẹ ìjọba lè mú yín, wọ́n lè fọ̀rọ̀ wá yín lẹ́nu wò, iṣẹ́ lè bọ́ lọ́wọ́ yín, wọ́n sì lè gbéjà kò yín. Nígbà ìpọ́njú ńlá, ẹ̀yin alàgbà gbọ́dọ̀ nígboyà tí ètò Ọlọ́run bá ní kẹ́ ẹ ṣe àwọn nǹkan kan, kódà tí nǹkan náà bá léwu. w23.06 5-6 ¶12-13
Tuesday, May 6
Àwọn tó ń bọlá fún mi ni màá bọlá fún.—1 Sám. 2:30.
Jèhófà ní kí wọ́n kọ iṣẹ́ rere tí Àlùfáà Àgbà Jèhóádà ṣe sínú Bíbélì ká lè kẹ́kọ̀ọ́ nínú ẹ̀. (Róòmù 15:4) Yàtọ̀ síyẹn, nígbà tí Jèhóádà kú, wọ́n bọlá fún un lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ torí pé wọ́n sin ín “sí Ìlú Dáfídì níbi tí wọ́n ń sin àwọn ọba sí, nítorí ó ti ṣe dáadáa ní Ísírẹ́lì sí Ọlọ́run tòótọ́ àti sí ilé Rẹ̀.” (2 Kíró. 24:15, 16) Ohun tí Bíbélì sọ nípa Jèhóádà lè ran gbogbo wa lọ́wọ́ ká lè máa bẹ̀rù Jèhófà bó ṣe tọ́. Àwọn alábòójútó nínú ìjọ lè fara wé Jèhóádà tí wọ́n bá ń wà lójúfò, tí wọ́n sì ń dáàbò bo àwọn ará ìjọ. (Ìṣe 20:28) Àwọn àgbàlagbà náà lè kẹ́kọ̀ọ́ lára Jèhóádà pé táwọn bá ń bẹ̀rù Jèhófà, táwọn sì jẹ́ olóòótọ́, Jèhófà lè lo àwọn láti mú ìfẹ́ Rẹ̀ ṣẹ. Ẹ̀yin ọ̀dọ́ náà lè kíyè sí bí Jèhófà ṣe hùwà tó dáa sí Jèhóádà, kẹ́ ẹ sì fara wé e. Ó yẹ kẹ́yin náà máa hùwà tó dáa sáwọn àgbàlagbà, kẹ́ ẹ sì máa bọ̀wọ̀ fún wọn, pàápàá àwọn tó ti ń sin Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ọdún. (Òwe 16:31) Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ‘àwọn tó ń ṣàbójútó’ wa, ká sì máa ṣègbọràn sí wọn.—Héb. 13:17. w23.06 17 ¶14-15
Wednesday, May 7
Ẹnu olódodo ń bọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn.—Òwe 10:21.
Tó o bá wà nípàdé, ó yẹ kó o fòye mọ iye ìgbà tó yẹ kó o nawọ́ láti dáhùn. Tá a bá ń nawọ́ ṣáá, á jẹ́ kí ẹni tó ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà máa rò pé dandan ni kóun pè wá léraléra bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn míì ò tíì dáhùn. Ìyẹn sì lè mú káwọn tí ò tíì dáhùn má nawọ́ mọ́. (Oníw. 3:7) Táwọn ará tó ń nawọ́ láti dáhùn bá pọ̀ nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ kan, a lè má láǹfààní láti dáhùn bá a ṣe fẹ́. Nígbà míì, ẹni tó ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lè má pè wá rárá. Ká sòótọ́, ó lè dùn wá, àmọ́ kò yẹ ká bínú tí wọn ò bá pè wá rárá. (Oníw.7:9) Tó ò bá láǹfààní láti dáhùn bó o ṣe fẹ́, o ò ṣe fetí sílẹ̀ nígbà táwọn ẹlòmíì bá ń dáhùn kó o lè gbóríyìn fún wọn lẹ́yìn tí ìpàdé bá parí. Tá ò bá tiẹ̀ dáhùn nípàdé àmọ́ tá a gbóríyìn fáwọn ará tó dáhùn, àwa náà ti dáhùn nìyẹn, ìyẹn sì máa gbé wọn ró. w23.04 23-24 ¶14-16
Thursday, May 8
Ọkàn mi dúró ṣinṣin, Ọlọ́run.—Sm. 57:7.
Máa dá kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kó o sì máa ṣàṣàrò. Igi kan máa lágbára tí gbòǹgbò ẹ̀ bá fìdí múlẹ̀. Lọ́nà kan náà, ìgbàgbọ́ wa máa lágbára tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Bí igi náà bá ṣe ń dàgbà, bẹ́ẹ̀ náà ni gbòǹgbò ẹ̀ á máa fìdí múlẹ̀, táá sì máa tóbi sí i. Táwa náà bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́, tá a sì ń ṣàṣàrò, ìgbàgbọ́ wa á máa lágbára sí i, á sì túbọ̀ dá wa lójú pé àwọn ìlànà Ọlọ́run ló dáa jù lọ. (Kól. 2:6, 7) Máa ronú nípa bí ìtọ́sọ́nà, ìmọ̀ràn àti ààbò Jèhófà ṣe ran àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ lọ́wọ́ nígbà àtijọ́. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Ìsíkíẹ́lì rí ìran, ó rí áńgẹ́lì kan tó ń wọn tẹ́ńpìlì, ó sì fọkàn sí gbogbo àlàyé tí áńgẹ́lì náà ṣe. Ìran yìí fún Ìsíkíẹ́lì lókun, ó sì jẹ́ káwa náà mọ bá a ṣe lè tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà nínú ìjọsìn mímọ́. (Ìsík. 40:1-4; 43:10-12) Àwa náà máa jàǹfààní tá a bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́, tá a sì ń ṣàṣàrò nípa àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tó jinlẹ̀. Àwa náà lè jẹ́ adúróṣinṣin, ká sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.—Sm. 112:7. w23.07 18 ¶15-16
Friday, May 9
Má ṣe jẹ́ kí làákàyè bọ́ mọ́ ọ lọ́wọ́.—Òwe 3:21.
Ọ̀pọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tí wọ́n fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ ló wà nínú Bíbélì tẹ́yin ọ̀dọ́kùnrin lè fara wé. Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ìgbà àtijọ́ yìí nífẹ̀ẹ́ ẹ̀ gan-an, oríṣiríṣi iṣẹ́ ni wọ́n sì ṣe láti bójú tó àwọn èèyàn Ọlọ́run. O tún lè rí àwọn ọkùnrin Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn tó o lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn nínú ìdílé ẹ àti nínú ìjọ. (Héb. 13:7) O sì tún lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ tó dáa jù lọ tí Jésù fi lélẹ̀. (1 Pét. 2:21) Bó o ṣe ń fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa wọn, kíyè sí àwọn ànímọ́ tí wọ́n ní tó wù ẹ́. (Héb. 12:1, 2) Lẹ́yìn náà kó o wo bó o ṣe lè fara wé wọn. Ẹni tó ní làákàyè máa ń ronú dáadáa kó tó ṣèpinnu. Torí náà, ṣiṣẹ́ kára kó o lè ní ànímọ́ yìí, kó o má sì jẹ́ kó bọ́ mọ́ ẹ lọ́wọ́. Bó o ṣe lè ṣe é ni pé kó o mọ àwọn ìlànà Bíbélì, kó o sì ronú nípa àwọn àǹfààní tó o máa rí tó o bá tẹ̀ lé àwọn ìlànà náà. Lẹ́yìn náà, lo àwọn ìlànà yẹn láti ṣe àwọn ìpinnu tó máa múnú Jèhófà dùn. (Sm. 119:9) Nǹkan pàtàkì tó yẹ kó o ṣe nìyẹn tó o bá fẹ́ di ọkùnrin Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀.—Òwe 2:11, 12; Héb. 5:14. w23.12 24-25 ¶4-5
Saturday, May 10
Ẹ ṣe tán nígbà gbogbo láti gbèjà ara yín níwájú gbogbo ẹni tó bá béèrè ìdí tí ẹ fi ní ìrètí yìí, àmọ́ kí ẹ máa fi ìwà tútù àti ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ ṣe bẹ́ẹ̀.—1 Pét. 3:15.
Ó yẹ kẹ́yin òbí kọ́ àwọn ọmọ yín bí wọ́n ṣe lè dáhùn lọ́nà pẹ̀lẹ́ tí wọ́n bá ní kí wọ́n ṣàlàyé ohun tí wọ́n gbà gbọ́. (Jém. 3:13) Àwọn òbí kan máa ń fi dánra wò nígbà ìjọsìn ìdílé. Wọ́n máa ń jíròrò àwọn ìbéèrè tí wọ́n lè bi àwọn ọmọ wọn nílé ìwé, wọ́n á sọ bí wọ́n ṣe máa dáhùn àwọn ìbéèrè náà àti bí wọ́n ṣe máa sọ̀rọ̀ lọ́nà pẹ̀lẹ́. Táwọn ọ̀dọ́ bá ń ṣe ìdánrawò bí wọ́n ṣe máa ṣàlàyé ohun tí wọ́n gbà gbọ́, ìyẹn á jẹ́ kí ohun tí wọ́n gbà gbọ́ dá wọn lójú. Ìwé àjákọ fún àwọn ọ̀dọ́ wà ní abala “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé” lórí ìkànnì jw.org. Wọ́n ṣe ìwé yẹn lọ́nà táá jẹ́ kí ohun táwọn ọ̀dọ́ gbà gbọ́ dá wọn lójú, wọ́n á sì lè dáhùn ìbéèrè èyíkéyìí. Tí gbogbo àwọn tó wà nínú ìdílé bá jọ lo ìwé àjákọ náà, wọ́n á kọ́ bí wọ́n ṣe lè ṣàlàyé ohun tí wọ́n gbà gbọ́ lọ́nà pẹ̀lẹ́. w23.09 17 ¶10; 18 ¶15-16
Sunday, May 11
Ẹ má ṣe jẹ́ kí a jáwọ́ nínú ṣíṣe rere, torí tí àkókò bá tó, a máa kórè rẹ̀ tí a ò bá jẹ́ kó rẹ̀ wá.—Gál. 6:9.
Ṣé o ti ní àfojúsùn kan nínú ìjọsìn Jèhófà àmọ́ tó ò ń ṣiṣẹ́ kára kọ́wọ́ ẹ lè tẹ̀ ẹ́? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ìwọ nìkan kọ́ nirú ẹ̀ ń ṣẹlẹ̀ sí. Bí àpẹẹrẹ, ó wu Arákùnrin Philip pé kóun máa gbàdúrà déédéé, kí àdúrà òun sì sunwọ̀n sí i, àmọ́ kò rọrùn fún un láti ráyè ṣe bẹ́ẹ̀. Ó wu Arábìnrin Erika náà pé kó máa tètè dé sí ìpàdé iṣẹ́ ìwàásù, àmọ́ ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ìpàdé náà ló máa ń pẹ́ dé. Tó o bá lóhun kan tó o fẹ́ ṣe nínú ìjọsìn Ọlọ́run, àmọ́ tí ọwọ́ ẹ ò tíì tẹ̀ ẹ́, má rẹ̀wẹ̀sì. Ìdí ni pé àwọn nǹkan kéékèèké téèyàn fẹ́ ṣe náà máa ń gba àkókò àti ìsapá. Bó o ṣe ń ṣiṣẹ́ kára kọ́wọ́ ẹ lè tẹ àwọn àfojúsùn ẹ fi hàn pé o mọyì àjọṣe tó o ní pẹ̀lú Jèhófà, o sì fẹ́ ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe nínú ìjọsìn ẹ̀. Jèhófà mọyì gbogbo ohun tó ò ń ṣe torí kò retí pé kó o ṣe ju agbára ẹ lọ. (Sm. 103:14; Míkà 6:8) Torí náà, má ṣe lé ohun tó kọjá agbára ẹ. w23.05 26 ¶1-2
Monday, May 12
Tí Ọlọ́run bá wà lẹ́yìn wa, ta ló lè dènà wa?—Róòmù 8:31.
Ẹ̀rù lè ba ẹni tó nígboyà, àmọ́ ìyẹn ò ní kó má ṣe ohun tó tọ́. Ọ̀dọ́kùnrin tó nígboyà gan-an ni Dáníẹ́lì. Ó kẹ́kọ̀ọ́ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wòlíì Ọlọ́run títí kan àsọtẹ́lẹ̀ wòlíì Jeremáyà. Àwọn ẹ̀kọ́ tí Dáníẹ́lì kọ́ yìí ló jẹ́ kó fòye mọ̀ pé àkókò táwọn Júù máa lò nígbèkùn Bábílónì máa tó pé. (Dán. 9:2) Bí Dáníẹ́lì ṣe ń rí i táwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ń ṣẹ mú kó túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ó sì jẹ́ kó rí i pé àwọn tó bá gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run máa ń nígboyà gan-an. (Fi wé Róòmù 8:32, 37-39.) Ju gbogbo ẹ̀ lọ, Dáníẹ́lì máa ń gbàdúrà sí Bàbá rẹ̀ ọ̀run déédéé. (Dán. 6:10) Ó jẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀ fún Jèhófà, ó sọ bí nǹkan ṣe rí lára ẹ̀ fún un, ó sì ní kó ran òun lọ́wọ́. (Dán. 9:4, 5, 19) Èèyàn bíi tiwa ni Dáníẹ́lì, a ò bí ìgboyà mọ́ ọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló kọ́ béèyàn ṣe ń nígboyà. Ohun tó sì ràn án lọ́wọ́ ni pé ó máa ń dá kẹ́kọ̀ọ́, ó máa ń gbàdúrà, ó sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. w23.08 3 ¶4; 4 ¶7
Tuesday, May 13
Ẹ jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ yín máa tàn níwájú àwọn èèyàn, kí wọ́n lè rí àwọn iṣẹ́ rere yín, kí wọ́n sì fògo fún Baba yín tó wà ní ọ̀run.—Mát. 5:16.
Tá a bá ń ṣègbọràn síjọba, ó máa ṣe àwa àtàwọn míì láǹfààní. Lọ́nà wo? Àǹfààní kan ni pé a ò ní sí lára àwọn tí ìjọba máa fìyà jẹ torí pé wọ́n ṣàìgbọràn. (Róòmù 13:1, 4) Tá a bá ń ṣègbọràn sófin ìjọba, wọ́n á rí i pé èèyàn dáadáa làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti pé a máa ń pa òfin ìjọba mọ́. Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún mélòó kan sẹ́yìn lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, àwọn sójà wọnú Ilé Ìpàdé kan nígbà táwọn ará ń ṣèpàdé lọ́wọ́, wọ́n ń wá àwọn tó ń fẹ̀hónú hàn torí owó orí tí ìjọba ní kí wọ́n san. Àmọ́, ọ̀gá àwọn sójà náà ní kí wọ́n kúrò níbẹ̀. Ó ní: “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń san owó orí wọn.” Torí náà, tó o bá ń pa òfin ìjọba mọ́, ìyẹn ò ní jẹ́ kí orúkọ rere táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní bà jẹ́. Ó sì lè dáàbò bo àwọn ará lọ́jọ́ kan. w23.10 9 ¶13
Wednesday, May 14
Ẹ nílò ìfaradà, pé lẹ́yìn tí ẹ ti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, kí ẹ lè rí ohun tí ó ṣèlérí náà gbà.—Héb. 10:36.
Ọjọ́ pẹ́ tí àwọn kan lára àwa ìránṣẹ́ Jèhófà ti ń dúró de ìgbà tí òpin ayé burúkú yìí máa dé. Àwọn kan rò pé àkókò tí Ọlọ́run dá pé òun máa mú ìlérí òun ṣẹ ti ń pẹ́ jù. Àmọ́ Jèhófà mọ bọ́rọ̀ yìí ṣe rí lára àwa ìránṣẹ́ ẹ̀, ìdí nìyẹn tó fi sọ fún Hábákúkù pé kó má mikàn, ó ní: “Àkókò tí ìran náà máa ṣẹ kò tíì tó, ó ń yára sún mọ́lé, kò sì ní lọ láìṣẹ. Tó bá tiẹ̀ falẹ̀, ṣáà máa retí rẹ̀! Torí yóò ṣẹ láìkùnà. Kò ní pẹ́ rárá!” (Háb. 2:3) Ṣé Hábákúkù nìkan ni Jèhófà sọ̀rọ̀ yìí fún, àbí ọ̀rọ̀ yìí kan àwa náà lónìí? Ẹ̀mí Ọlọ́run darí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti sọ irú ọ̀rọ̀ yìí fún àwọn Kristẹni tó ń retí ayé tuntun. (Héb. 10:37) Torí náà, tó bá dà bíi pé àwọn ìlérí Jèhófà ń pẹ́ lójú ẹ, mọ̀ dájú pé “yóò ṣẹ láìkùnà. Kò ní pẹ́ rárá!” w23.04 30 ¶16
Thursday, May 15
Gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá bẹ̀rẹ̀ sí í kùn sí Mósè.—Nọ́ń. 14:2.
Ó bani nínú jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ni ò gba ẹ̀rí tí Jèhófà ń fi hàn wọ́n pé Mósè ni òun ń lò láti darí wọn. (Nọ́ń. 14:10, 11) Léraléra ni wọ́n ṣe ohun tó fi hàn pé wọn ò gbà pé Jèhófà ń lo Mósè. Torí náà, Jèhófà ò gbà kí ìran àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yẹn wọ Ilẹ̀ Ìlérí. (Nọ́ń. 14:30) Àmọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kan tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà sọ pé: “Kélẹ́bù . . . ń fi gbogbo ọkàn rẹ̀ tẹ̀ lé mi.” (Nọ́ń. 14:24) Jèhófà bù kún Kélẹ́bù, kódà ilẹ̀ tó wù ú ni Jèhófà fún un ní Kénáánì. (Jóṣ. 14:12-14) Ìran àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó tẹ̀ lé ìyẹn náà ṣe ohun tí Jèhófà sọ fún wọn. Nígbà tí Jèhófà fi Jóṣúà rọ́pò Mósè, tó sì ní kó máa darí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọ́n “bọ̀wọ̀ fún un gan-an ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.” (Jóṣ. 4:14) Torí náà, Jèhófà bù kún wọn torí ó jẹ́ kí wọ́n wọ ilẹ̀ tó ṣèlérí fún wọn.—Jóṣ. 21:43, 44. w24.02 21 ¶6-7
Friday, May 16
Ẹnikẹ́ni tó bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ arákùnrin rẹ̀ pẹ̀lú.—1 Jòh. 4:21.
Tí dókítà kan bá fọwọ́ sí ọrùn ọwọ́ wa, ó máa mọ̀ bóyá ọkàn wa ń ṣiṣẹ́ dáadáa. Lọ́nà kan náà, tá a bá wo bá a ṣe nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa tó, a máa mọ bá a ṣe nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tó. Tá a bá kíyè sí i pé a ò fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ àwọn ará mọ́, ìyẹn lè fi hàn pé a ò fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà mọ́. Àmọ́ tá a bá ń fìfẹ́ hàn sáwọn ará ní gbogbo ìgbà, ìyẹn máa jẹ́ ká mọ̀ pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run gan-an. Tá a bá rí i pé a ò fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ àwọn ará mọ́, ó yẹ ká wá nǹkan ṣe sí i. Kí nìdí? Ìdí ni pé tá ò bá ṣe bẹ́ẹ̀, àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà máa bà jẹ́. Àpọ́sítélì Jòhánù jẹ́ ká rí i pé bọ́rọ̀ ṣe rí nìyẹn nígbà tó sọ pé: “Ẹni tí kò nífẹ̀ẹ́ arákùnrin rẹ̀ tó rí, kò lè nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tí kò rí.” (1 Jòh. 4:20) Kí la rí kọ́? Inú Jèhófà máa dùn sí wa tá a bá “nífẹ̀ẹ́ ara wa.”—1 Jòh. 4:7-9, 11. w23.11 8 ¶3; 9 ¶5-6
Saturday, May 17
Bàbá rẹ àti ìyá rẹ yóò máa yọ̀.—Òwe 23:25.
Nígbà tí Ọba Jèhóáṣì ṣì kéré, ó ṣe ìpinnu tó dáa. Torí pé bàbá ẹ̀ ti kú, Àlùfáà Àgbà Jèhóádà tó ń sin Jèhófà tọkàntọkàn ló ń tọ́ ọ sọ́nà, ó sì ń ṣe ohun tó bá sọ. Ńṣe ni Jèhóádà mú Jèhóáṣì bí ọmọ, ó sì ń bójú tó o. Ìyẹn jẹ́ kí Jèhóáṣì pinnu pé òun á fàpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ nínú ìjọsìn mímọ́, òun á sì máa sin Jèhófà. Kódà, Jèhóáṣì ṣètò pé kí wọ́n tún tẹ́ńpìlì Jèhófà ṣe. (2 Kíró. 24:1, 2, 4, 13, 14) Táwọn òbí ẹ bá ti kọ́ ẹ pé kó o nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, kó o sì máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà ẹ̀, ẹ̀bùn tó ṣeyebíye ni wọ́n fún ẹ yẹn. (Òwe 2:1, 10-12) Oríṣiríṣi ọ̀nà làwọn òbí ẹ lè gbà tọ́ ẹ. Tó o bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì táwọn òbí ẹ ń kọ́ ẹ, inú wọn máa dùn. Èyí tó ṣe pàtàkì jù ni pé inú Jèhófà máa dùn sí ẹ, wàá sì di ọ̀rẹ́ ẹ̀ títí láé. (Òwe 22:6; 23:15, 24) Àwọn nǹkan tá a sọ yìí yẹ kó mú kó o fara wé àpẹẹrẹ Jèhóáṣì nígbà tó wà lọ́mọdé. w23.09 8-9 ¶3-5
Sunday, May 18
Màá fetí sí yín.—Jer. 29:12.
Jèhófà ṣèlérí pé òun máa tẹ́tí sáwọn àdúrà wa. Ọlọ́run wa nífẹ̀ẹ́ àwọn tó ń sìn ín tọkàntọkàn, torí náà ó máa ń gbọ́ àdúrà wọn. (Sm. 10:17; 37:28) Àmọ́, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé gbogbo ohun tá a bá béèrè lọ́wọ́ ẹ̀ ló máa ṣe fún wa. Ó dinú ayé tuntun ká tó rí àwọn nǹkan míì tá a béèrè lọ́wọ́ ẹ̀ gbà. Jèhófà máa ń wò ó bóyá ohun tá à ń béèrè bá ìfẹ́ ẹ̀ mu. (Àìsá. 55:8, 9) Ọ̀kan lára ohun tí Jèhófà fẹ́ ni pé káwọn ọkùnrin àtobìnrin kún ayé, kó sì máa ṣàkóso wọn bí wọ́n ṣe ń fayọ̀ jọ́sìn ẹ̀ níṣọ̀kan. Àmọ́ Sátánì sọ pé táwọn èèyàn bá ń ṣàkóso ara wọn ló dáa jù. (Jẹ́n. 3:1-5) Kí Jèhófà lè fi hàn pé irọ́ ni Sátánì ń pa, ó gba àwọn èèyàn láyè láti máa ṣàkóso ara wọn. Torí náà, àkóso àwọn èèyàn ló fa ọ̀pọ̀ ìṣòro tá a ní lónìí. (Oníw. 8:9) A mọ̀ pé kì í ṣe gbogbo ìṣòro náà ni Jèhófà máa mú kúrò báyìí. w23.11 21 ¶4-5
Monday, May 19
Mo ti yàn ọ́ ṣe bàbá ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè.—Róòmù 4:17.
Jèhófà ṣèlérí pé òun máa bù kún ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè nípasẹ̀ Ábúráhámù. Síbẹ̀, nígbà tí Ábúráhámù pé ọgọ́rùn-ún (100) ọdún, tí Sérà sì pé àádọ́rùn-ún (90) ọdún, wọn ò tíì bí ọmọ tá a ṣèlérí náà. Lójú èèyàn, ó jọ pé kò ṣeé ṣe fún Ábúráhámù àti Sérà láti bímọ mọ́. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí máa dán ìgbàgbọ́ Ábúráhámù wò gan-an. “Síbẹ̀ lórí ìrètí, ó ní ìgbàgbọ́ pé òun máa di bàbá ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè.” (Róòmù 4:18, 19) Níkẹyìn, ohun tó ń retí tẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́. Ó bí Ísákì, ọmọ tí wọ́n ti ń retí tipẹ́. (Róòmù 4:20-22) A lè rí ojúure Ọlọ́run, kó kà wá sí olódodo, ká sì di ọ̀rẹ́ ẹ̀ bíi ti Ábúráhámù. Ohun tí Pọ́ọ̀lù fẹ́ ká mọ̀ nìyẹn nígbà tó sọ ọ̀rọ̀ yìí, ó ní: “Ọ̀rọ̀ tí a kọ pé ‘a kà á sí’ kì í ṣe nítorí [Ábúráhámù] nìkan, àmọ́ ó jẹ́ nítorí wa pẹ̀lú, àwa tí a máa kà sí olódodo, nítorí a nígbàgbọ́ nínú Ẹni tó gbé Jésù Olúwa wa dìde.” (Róòmù 4:23, 24) Bíi ti Ábúráhámù, ó yẹ káwa náà nígbàgbọ́, ká máa ṣe àwọn nǹkan tó fi hàn pé a nígbàgbọ́, ká sì tún nírètí. w23.12 7 ¶16-17
Tuesday, May 20
O ti rí ìpọ́njú mi; o mọ ìdààmú ńlá tó bá mi.—Sm. 31:7.
Tó o bá níṣòro tó ń bà ẹ́ lẹ́rù, rántí pé Jèhófà mọ ìṣòro náà, ó sì mọ bó ṣe rí lára ẹ. Bí àpẹẹrẹ, kì í ṣe ìyà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń jẹ ní Íjíbítì nìkan ni Jèhófà rí, ó tún mọ̀ pé “wọ́n ń jẹ̀rora.” (Ẹ́kís. 3:7) Tó o bá níṣòro kan tó ń bà ẹ́ lẹ́rù, o lè má rí bí Jèhófà ṣe ń ràn ẹ́ lọ́wọ́. Kí lo lè ṣe? Bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kó o rí bó ṣe ń ràn ẹ́ lọ́wọ́. (2 Ọba 6:15-17) Lẹ́yìn náà, bi ara ẹ pé: Ṣé àsọyé kan tàbí ìdáhùn kan wà tí mo gbọ́ nípàdé tó fún mi lókun? Ṣé ìwé, fídíò tàbí àwọn orin wa míì wà tó fún mi níṣìírí? Ṣé ẹnì kan ti sọ̀rọ̀ tó fi mí lọ́kàn balẹ̀ tàbí ka ẹsẹ Bíbélì kan tó tù mí nínú? Tá ò bá ṣọ́ra, a lè gbàgbé bí àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tàbí àwọn ìwé pẹ̀lú fídíò ètò Ọlọ́run ṣe ń ràn wá lọ́wọ́. Ẹ̀bùn ńlá làwọn nǹkan yìí sì jẹ́ látọ̀dọ̀ Jèhófà. (Àìsá. 65:13; Máàkù 10:29, 30) Wọ́n jẹ́ kó o mọ̀ pé ó nífẹ̀ẹ́ rẹ. (Àìsá. 49:14-16) Wọ́n sì fi hàn pé ó yẹ kó o gbẹ́kẹ̀ lé e. w24.01 4 ¶9-10
Wednesday, May 21
Kí o sì jẹ́ kí àwa ẹrú rẹ máa sọ ọ̀rọ̀ rẹ nìṣó pẹ̀lú ìgboyà.—Ìṣe 4:29.
Kí Jésù tó pa dà sọ́run, ó rán àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ létí iṣẹ́ pàtàkì tó gbé fún wọn pé wọ́n máa wàásù nípa òun “ní Jerúsálẹ́mù, ní gbogbo Jùdíà àti Samáríà àti títí dé ibi tó jìnnà jù lọ ní ayé.” (Ìṣe 1:8; Lúùkù 24:46-48) Kò pẹ́ sígbà yẹn, àwọn olórí ẹ̀sìn Júù fàṣẹ ọba mú àpọ́sítélì Pétérù àti Jòhánù, wọ́n mú wọn lọ síwájú ìgbìmọ̀ Sàhẹ́ndìrìn, wọ́n sì halẹ̀ mọ́ àwọn ọkùnrin olóòótọ́ yìí pé kí wọ́n má wàásù mọ́. (Ìṣe 4:18, 21) Pétérù àti Jòhánù wá sọ pé: “Ẹ̀yin náà ẹ sọ, tó bá tọ́ lójú Ọlọ́run pé ká fetí sí yín dípò ká fetí sí Ọlọ́run. Àmọ́ ní tiwa, a ò lè ṣàì sọ ohun tí a ti rí tí a sì ti gbọ́.” (Ìṣe 4:19, 20) Nígbà tí wọ́n dá Pétérù àti Jòhánù sílẹ̀, àwọn ọmọ ẹ̀yìn gbé ohùn wọn sókè sí Jèhófà, Jèhófà sì dáhùn àdúrà yẹn.—Ìṣe 4:31. w23.05 5 ¶11-12
Thursday, May 22
Èyí ni Ọmọ mi, àyànfẹ́.—Mát. 17:5.
Àìmọye ọdún ni Jèhófà àti Jésù Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n ti di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́, wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ ara wọn gan-an. Ọ̀rẹ́ àwọn méjèèjì ló pẹ́ jù láyé àtọ̀run. Jèhófà fi bóun ṣe nífẹ̀ẹ́ Jésù tó hàn, bó ṣe wà nínú ẹsẹ ojúmọ́ wa tòní. Nínú ẹsẹ Bíbélì yẹn, Jèhófà ò kàn sọ pé, ‘Ẹni tí mo tẹ́wọ́ gbà rèé.’ Kàkà bẹ́ẹ̀, ó fẹ́ ká mọ bóun ṣe nífẹ̀ẹ́ Jésù tó, ìdí nìyẹn tó fi pè é ní “Ọmọ mi, àyànfẹ́.” Jèhófà mọyì Jésù, pàápàá torí pé ó ṣe tán láti fi ẹ̀mí ẹ̀ lélẹ̀ fún aráyé. (Éfé. 1:7) Jésù ò ṣiyèméjì pé lóòótọ́ ni Bàbá òun nífẹ̀ẹ́ òun. Ó sì dá a lójú háún-háún pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ òun gan-an. Léraléra ni Jésù sọ ọ́ pẹ̀lú ìdánilójú pé Bàbá òun nífẹ̀ẹ́ òun.—Jòh. 3:35; 10:17; 17:24. w24.01 28 ¶8
Friday, May 23
Orúkọ rere ló yẹ kéèyàn yàn dípò ọ̀pọ̀ ọrọ̀.—Òwe 22:1.
Ká sọ pé ọ̀rẹ́ ẹ sọ ohun tí ò dáa nípa ẹ. O mọ̀ pé irọ́ ló pa mọ́ ẹ, àmọ́ àwọn kan gbà á gbọ́. Ohun tó burú jù níbẹ̀ ni pé àwọn kan tún ń tan irọ́ náà kiri, ọ̀pọ̀ èèyàn sì ń gbà á gbọ́. Báwo lọ̀rọ̀ náà ṣe máa rí lára ẹ? Irọ́ yẹn máa bà ẹ́ nínú jẹ́ gan-an torí o nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, o ò sì fẹ́ kí orúkọ rere ẹ bà jẹ́. Àpèjúwe yìí máa jẹ́ ká mọ bó ṣe rí lára Jèhófà nígbà tí áńgẹ́lì kan bà á lórúkọ jẹ́. Ọ̀kan lára àwọn áńgẹ́lì ẹ̀ pa irọ́ mọ́ ọn lọ́dọ̀ Éfà obìnrin àkọ́kọ́. Éfà gba irọ́ náà gbọ́. Irọ́ yẹn sì mú kí àwọn òbí wa àkọ́kọ́ ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà. Báwa èèyàn ṣe di ẹlẹ́ṣẹ̀, tá a sì ń kú nìyẹn. (Jẹ́n. 3:1-6; Róòmù 5:12) Irọ́ tí Sátánì pa ló fa ikú, ogun, ìṣẹ́ àti gbogbo ìṣòro tó wà láyé báyìí. Ṣé gbogbo irọ́ tí wọ́n pa mọ́ Jèhófà àtàwọn nǹkan tí irọ́ náà fà bà á nínú jẹ́? Bẹ́ẹ̀ ni. Ṣùgbọ́n Jèhófà ò torí ìyẹn bínú. Kódà “Ọlọ́run aláyọ̀” ṣì ni.—1 Tím. 1:11. w24.02 8 ¶1-2
Saturday, May 24
Ṣé ó wá yẹ kí n hùwà burúkú tó tó báyìí, kí n sì ṣẹ Ọlọ́run?—Jẹ́n. 39:9.
Báwo lo ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jósẹ́fù, kó o sì kọ ìdẹwò? Ó yẹ kó o ti mọ ohun tó o máa ṣe báyìí kí ìdẹwò tó dé. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni kó o kọ àwọn ohun tínú Jèhófà ò dùn sí, kódà má tiẹ̀ ronú nípa ẹ̀ rárá. (Sm. 97:10; 119:165) Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, o ò ní dẹ́ṣẹ̀. Ó ṣeé ṣe kó o mọ̀ pé o ti rí òtítọ́, kó o sì ti pinnu pé wàá máa sin Jèhófà tọkàntọkàn, àmọ́ káwọn nǹkan kan ṣì máa dí ẹ lọ́wọ́ láti ya ara ẹ sí mímọ́, kó o sì ṣèrìbọmi. Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, àpẹẹrẹ Ọba Dáfídì máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. Bíi ti Dáfídì, o lè bẹ Jèhófà pé: “Yẹ̀ mí wò látòkè délẹ̀, Ọlọ́run, kí o sì mọ ọkàn mi. Ṣàyẹ̀wò mi, kí o sì mọ àwọn ohun tó ń gbé mi lọ́kàn sókè. Wò ó bóyá ìwà burúkú kankan wà nínú mi, kí o sì darí mi sí ọ̀nà ayérayé.” (Sm. 139:23, 24) Jèhófà máa ń bù kún àwọn “tó ń wá a tọkàntọkàn.” Torí náà, bó o ṣe ń ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti ya ara ẹ sí mímọ́, kó o sì ṣèrìbọmi ń jẹ́ kí Jèhófà mọ̀ pé ò ń wá òun tọkàntọkàn.—Héb. 11:6. w24.03 6 ¶13-15
Sunday, May 25
Kò nílò kó máa rúbọ lójoojúmọ́.—Héb. 7:27.
Àlùfáà àgbà ló máa ń ṣojú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Áárónì ni àlùfáà àgbà àkọ́kọ́ tí Jèhófà yàn fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n ya àgọ́ ìjọsìn sí mímọ́. Àmọ́, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé “ó di dandan kí ọ̀pọ̀ di àlùfáà tẹ̀ léra torí pé ikú ò jẹ́ kí wọ́n lè máa bá iṣẹ́ náà lọ.” (Héb. 7:23-26) Torí pé aláìpé làwọn àlùfáà àgbà yẹn, àwọn náà gbọ́dọ̀ máa rú ẹbọ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Ẹ ò rí i pé ìyàtọ̀ ńlá ló wà láàárín àwọn àlùfáà àgbà ti Ísírẹ́lì àti Jésù Kristi tó jẹ́ Àlùfáà Àgbà ńlá! Jésù Kristi Àlùfáà Àgbà wa ni “òjíṣẹ́ . . . àgọ́ tòótọ́, tí Jèhófà gbé kalẹ̀, kì í ṣe èèyàn” ló gbé e kalẹ̀. (Héb. 8:1, 2) Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé “torí pé [Jésù] wà láàyè títí láé, kò sí pé ẹnì kan ń rọ́pò rẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ àlùfáà.” Pọ́ọ̀lù tún sọ pé Jésù jẹ́ “aláìlẹ́gbin, ẹni tí a yà sọ́tọ̀ láàárín àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,” kò sì dà bí àwọn àlùfáà àgbà ti Ísírẹ́lì torí “kò nílò kó máa rúbọ lójoojúmọ́” nítorí pé kì í ṣe ẹlẹ́ṣẹ̀. w23.10 26 ¶8-9
Monday, May 26
Ọ̀run tó wà tẹ́lẹ̀ àti ayé tó wà tẹ́lẹ̀ ti kọjá lọ.—Ìfi. 21:1.
“Ọ̀run tó wà tẹ́lẹ̀” ni àwọn ìjọba ayé tí Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù ń darí. (Mát. 4:8, 9; 1 Jòh. 5:19) Nígbà míì tí Bíbélì bá lo ọ̀rọ̀ náà “ayé,” àwọn èèyàn tó ń gbé inú ẹ̀ ló ń sọ nípa ẹ̀. (Jẹ́n. 11:1; Sm. 96:1) Torí náà, “ayé tó wà tẹ́lẹ̀” ni àwọn èèyàn burúkú tó wà láyé lónìí. Kì í ṣe pé Jèhófà máa dá “ọ̀run” tàbí “ayé” míì, àmọ́ àwọn èèyàn burúkú inú ẹ̀ ló máa pa run. Ọlọ́run máa mú ọ̀run àti ayé tó wà tẹ́lẹ̀ kúrò, á sì fi “ọ̀run tuntun àti ayé tuntun” rọ́pò ẹ̀, ìyẹn ìjọba tuntun tí Ọlọ́run máa gbé kalẹ̀, táá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso àwọn èèyàn olódodo. Jèhófà máa sọ ayé yìí àtàwọn èèyàn tó ń gbé inú ẹ̀ di tuntun, á sì jẹ́ kí wọ́n di pípé. Bí Àìsáyà ṣe sọ tẹ́lẹ̀, gbogbo ayé pátápátá máa di ọgbà ẹlẹ́wà kan bíi ti ọgbà Édẹ́nì. Jèhófà tún máa sọ wá di tuntun torí pé ó máa wo ẹnì kọ̀ọ̀kan wa sàn. Ó máa wo àwọn tó yarọ, àwọn tí ò ríran àtàwọn adití sàn, kódà ó máa jí àwọn tó ti kú dìde.—Àìsá. 25:8; 35:1-7. w23.11 4 ¶9-10
Tuesday, May 27
Kí ẹ̀yin náà múra sílẹ̀.—Mát. 24:44.
Òjijì ni “ìpọ́njú ńlá” máa bẹ̀rẹ̀. (Mát. 24:21) Àwọn àjálù tó ń ṣẹlẹ̀ máa ń dé bá àwọn èèyàn lójijì, àmọ́ ìpọ́njú ńlá ò ní dé bá àwa kan lójijì torí a ti mọ̀ pé ó máa ṣẹlẹ̀. Kódà, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún méjì (2,000) sẹ́yìn ni Jésù ti kìlọ̀ fáwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ pé kí wọ́n máa múra sílẹ̀ de ọjọ́ yẹn. Torí náà, tá a bá múra sílẹ̀, ó máa rọrùn fún wa láti fara da àkókò tó máa nira yẹn, àá sì lè ran àwọn míì lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀. (Lúùkù 21:36) A máa nílò ìfaradà ká tó lè ṣe ohun tí Jèhófà sọ, ká sì gbà pé ó máa dáàbò bò wá. Kí la máa ṣe táwọn ará wa bá pàdánù díẹ̀ tàbí gbogbo nǹkan tí wọ́n ní? (Háb. 3:17, 18) Ó máa gba pé ká jẹ́ aláàánú ká tó lè pèsè àwọn nǹkan tí wọ́n nílò. Nígbà tí àgbájọ àwọn orílẹ̀-èdè bá kọ lu àwa èèyàn Jèhófà, báwo la ṣe máa hùwà sáwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tó bá ṣẹlẹ̀ pé inú ilé kékeré kan ni gbogbo wa jọ máa gbé fúngbà díẹ̀? (Ìsík. 38:10-12) Ó máa gba pé ká fi ìfẹ́ tó lágbára hàn sí wọn kí gbogbo wa lè la àkókò tí nǹkan nira yẹn já. w23.07 2 ¶2-3
Wednesday, May 28
Ẹ máa ṣọ́ra lójú méjèèjì pé bí ẹ ṣe ń rìn kì í ṣe bí aláìlọ́gbọ́n àmọ́ bí ọlọ́gbọ́n, kí ẹ máa lo àkókò yín lọ́nà tó dára jù lọ.—Éfé. 5:15, 16.
Àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ nífẹ̀ẹ́ Ákúílà àti Pírísílà gan-an, ọ̀pọ̀ nǹkan lẹ̀yin tọkọtaya òde òní sì lè kọ́ lára wọn. (Róòmù 16:3, 4) Wọ́n jọ máa ń ṣiṣẹ́ pọ̀, wọ́n jọ máa ń wàásù, wọ́n sì jọ máa ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. (Ìṣe 18:2, 3, 24-26) Kódà, nígbàkigbà tí Bíbélì bá sọ̀rọ̀ nípa Ákúílà àti Pírísílà, àwọn méjèèjì ló máa ń dárúkọ pa pọ̀. Báwo lẹ̀yin tọkọtaya ṣe lè fara wé wọn? Ronú nípa ọ̀pọ̀ nǹkan tí ẹ̀yin méjèèjì fẹ́ ṣe. Ṣé ẹ lè jọ ṣe díẹ̀ lára ẹ̀ dípò kí ìwọ nìkan dá ṣe gbogbo ẹ̀? Bí àpẹẹrẹ, Ákúílà àti Pírísílà jọ máa ń wàásù. Ṣé ẹ̀yin náà máa ń ṣètò àkókò yín kẹ́ ẹ lè jọ máa wàásù? Yàtọ̀ síyẹn, Ákúílà àti Pírísílà jọ máa ń ṣiṣẹ́. Iṣẹ́ tí ẹ̀yin méjèèjì ń ṣe lè yàtọ̀ síra, àmọ́ ṣé ẹ lè jọ máa ṣiṣẹ́ ilé pa pọ̀? (Oníw. 4:9) Tí ẹ bá ń ṣe àwọn iṣẹ́ kan pa pọ̀, ìyẹn máa jẹ́ kẹ́ ẹ túbọ̀ ṣe ara yín lọ́kan, ẹ̀ẹ́ sì tún láǹfààní láti jọ sọ̀rọ̀. w23.05 22-23 ¶10-12
Thursday, May 29
Nígbà tí ẹ̀rù ń bà mí, mo gbẹ́kẹ̀ lé ọ.—Sm. 56:3.
Gbogbo wa lẹ̀rù máa ń bà nígbà míì. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Ọba Sọ́ọ̀lù fẹ́ pa Dáfídì, ó sá lọ sí Gátì nílẹ̀ àwọn Filísínì. Kò pẹ́ tí Ákíṣì ọba Gátì fi mọ̀ pé Dáfídì ni jagunjagun tó lákíkanjú tí wọ́n kọrin yìn pé ó pa “ẹgbẹẹgbàárùn-ún” lára àwọn Filísínì. Ìyẹn mú kí ‘ẹ̀rù bẹ̀rẹ̀ sí í ba Dáfídì gan-an.’ (1 Sám. 21:10-12) Ó ń bẹ̀rù ohun tí Ọba Ákíṣì máa ṣe fóun. Àmọ́, báwo ni Dáfídì ṣe borí ẹ̀rù tó ń bà á yìí? Nínú Sáàmù 56, Dáfídì sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ̀ nígbà tó wà ní Gátì. Sáàmù yẹn sọ ohun tó ń ba Dáfídì lẹ́rù, ó sì tún sọ bó ṣe borí ohun tó ń bà á lẹ́rù. Nígbà tẹ́rù ń ba Dáfídì, ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. (Sm. 56:1-3, 11) Ó fọkàn tán Jèhófà pátápátá. Jèhófà sì ran Dáfídì lọ́wọ́, ó jẹ́ kó rí ọgbọ́n dá sọ́rọ̀ náà, ló bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe bí ẹni tó ń ṣiwèrè! Ohun tí Dáfídì ṣe yìí rí ọba náà lára, torí náà, kò gbà pé ó lè ṣe òun ní jàǹbá, ìyẹn sì jẹ́ kí Dáfídì ráyè sá lọ.—1 Sám. 21:13–22:1. w24.01 2 ¶1-3
Friday, May 30
Àwọn tí a pè tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀, tí wọ́n jẹ́ àyànfẹ́ àti olóòótọ́ máa ṣẹ́gun pẹ̀lú.—Ìfi. 17:14.
Àwọn wo là ń sọ nínú ẹsẹ ojúmọ́ wa tòní? Àwọn ẹni àmì òróró tó ti jíǹde ni! Torí náà, tí èyí tó kẹ́yìn lára àwọn ẹni àmì òróró bá ti lọ sọ́run lápá ìparí ìpọ́njú ńlá, ọ̀kan lára iṣẹ́ tí wọ́n máa kọ́kọ́ ṣe ni pé kí wọ́n jagun. Lẹ́yìn tí wọ́n bá lọ sọ́run, àwọn àti Jésù pẹ̀lú àwọn áńgẹ́lì máa bá àwọn ọ̀tá Ọlọ́run ja ogun ìkẹyìn. Ẹ̀yin náà ẹ wo bí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó ṣì wà láyé ṣe rí báyìí, àwọn kan lára wọn ti dàgbà gan-an. Àmọ́ tí Jèhófà bá ti jí wọn dìde sọ́run, wọ́n á di ẹni ẹ̀mí tó lágbára tí ò lè kú mọ́, wọ́n á sì dara pọ̀ mọ́ Jésù Kristi tó jẹ́ Olórí Ogun wọn láti jagun. Lẹ́yìn tí wọ́n bá jagun Amágẹ́dọ́nì tán, wọ́n á ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Jésù láti sọ àwa èèyàn di pípé. Ó dájú pé nígbà yẹn, ìrànlọ́wọ́ táwọn ẹni àmì òróró máa ṣe fún àwa arákùnrin àtàwọn arábìnrin wọn máa pọ̀ gan-an ju ti ìgbà tí wọ́n ṣì jẹ́ aláìpé láyé! w24.02 6-7 ¶15-16
Saturday, May 31
Ẹ máa rìn nípa ẹ̀mí, ẹ kò sì ní ṣe ìfẹ́ ti ara rárá.—Gál. 5:16.
Àwọn kan tí wọ́n ti ṣe tán láti ya ara wọn sí mímọ́, kí wọ́n sì ṣèrìbọmi ṣì ń lọ́ tìkọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Wọ́n lè máa rò pé, ‘Tí mo bá dá ẹ̀ṣẹ̀ ńlá ńkọ́, tí wọ́n sì yọ mí kúrò nínú ìjọ?’ Tó bá jẹ́ pé ohun tó ń bà ẹ́ lẹ́rù nìyẹn, mọ̀ dájú pé Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o “lè máa rìn lọ́nà tó yẹ [ẹ́] láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀ ní kíkún.” (Kól. 1:10) Jèhófà tún máa fún ẹ lókun kó o lè ṣe ohun tó tọ́. Ó sì dájú pé ó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ torí pé ó ti ṣe bẹ́ẹ̀ fún ọ̀pọ̀ èèyàn. (1 Kọ́r. 10:13) Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé àwọn tí wọ́n máa ń yọ kúrò nínú ìjọ kì í pọ̀. Kò sígbà tí Jèhófà kì í ran àwa èèyàn ẹ̀ lọ́wọ́ ká lè jẹ́ olóòótọ́ sí i. Gbogbo àwa èèyàn aláìpé la máa ń dojú kọ ìdẹwò láti ṣe ohun tí ò dáa. (Jém. 1:14) Àmọ́, ìwọ lo máa pinnu ohun tó o máa ṣe tí ìdẹwò bá dé. Ohun kan tó dájú ni pé ọwọ́ ẹ ló kù sí bóyá wàá jẹ́ kí ìdẹwò borí ẹ àbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Àwọn kan lè sọ pé kò ṣeé ṣe láti kó ara ẹ níjàánu, àmọ́ irọ́ ni, o lè ṣe bẹ́ẹ̀. w24.03 5 ¶11-12