ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 7/1 ojú ìwé 32
  • Awọn Ìtàn Bibeli Tí Wọn Fàfẹ́ Awọn Ọmọde Mọ́ra

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Awọn Ìtàn Bibeli Tí Wọn Fàfẹ́ Awọn Ọmọde Mọ́ra
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 7/1 ojú ìwé 32

Awọn Ìtàn Bibeli Tí Wọn Fàfẹ́ Awọn Ọmọde Mọ́ra

Mẹmba ijọ Protẹstant kan ní Puerto Rico kọ̀wé sí Watch Tower Society: “Mo jẹ́ olùkọ́ awọn ọmọdé ní ilé-ẹ̀kọ́ Bibeli kan. Láàárín ọdun tí ó kọjá, ohun tí ó tẹle e yii ṣẹlẹ̀ sí mi.

“Ìwé tí mo ńlò lati kọ́ awọn ọmọde naa lẹ́kọ̀ọ́ ọ̀rọ̀ Bibeli ni a ti parí-pátápátá, nitorinaa mo bi araami leere: ‘Ki ni emi yoo ṣe nisinsinyi?’ Gẹgẹbi mo ti wò awọn pẹpẹ-ìwé inú yàrá mi níbití mo ti ní nǹkan bí ọgọ́rùn ún ìwé, mo rí ọ̀kan tí ó láwọ̀ òfefèé tí o ni àkòrí naa Iwe Itan Bibeli Mi. Mo pinnu lati lo ìwé yii.

“Mo gbọn ekuru ara rẹ̀ kúrò mo sì bẹrẹsii lò ó ní ọjọ́ Sunday kọọkan ninu ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ mi. Awọn ọmọde ní ìdùnnú pẹlu ìwé naa, a sì fẹrẹẹ má tíì parí orí-ìwé kan nigba ti wọn ńfẹ́ lati bẹ̀rẹ̀ òmíràn. Ìyọrísí rẹ̀ nìyí: Ọdun naa parí, a sì ti kárí gbogbo ìwé naa pátá. Awọn ọmọde naa láyọ̀ gan an, mo sì kún fun imoore gan an. Ó jẹ́ ìwé ẹlẹ́wà nítòótọ́, ó ṣe kedere ó sì ṣe ṣókí.”

Awa nímọ̀lára pe iwọ pẹlu yoo ka ìwé-àtẹ̀jáde aláwòrán-àpèjúwe rèterète tí a tẹ̀ gàdàgbàgàdàgbà yii sí ìṣúra. Awọn 116 ìròhìn-ìṣẹ̀lẹ̀ inú Bibeli rẹ̀ fun onkawe ní èrò ohun tí Bibeli dá lé lórí. Awọn ìtàn wọnyi farahàn lọna ètò tí awọn ìṣẹ̀lẹ̀ naa gbà wáyé. Iwọ yoo rí eyi pe ó kún fun iranlọwọ ninu kíkẹ́kọ̀ọ́ niti-gidi nigba ti, ní ìbátan sí awọn ìṣẹ̀lẹ̀ miiran, awọn nǹkan ṣẹlẹ̀. Bí iwọ yoo bá fẹ́ lati gbà ìwé olójú-ìwé 256 aṣeyebíye yii, jọwọ kọ̀ ọ̀rọ̀ kún àlàfo tí ó wà níhìn-ín kí o sì firánṣẹ́.

Emi yoo fẹ́ lati gba ìwé ẹlẹ́hìn-líle naa Iwe Itan Bibeli Mi. (Kọwe sí adirẹsi tí nbẹ nísàlẹ̀ yii fun ìsọfúnni.)

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́