Awọn Olupokiki Ijọba Rohin
Wọn Nigbẹkẹle Ninu Jehofa
AWỌN Ẹlẹ́rìí Jehofa ni Jehofa paṣẹ fun lati waasu ihinrere Ijọba naa ni gbogbo aye ki awọn eniyan gbogbo orilẹ-ede ba le ni anfaani lati mọ nipa aye titun ti Ọlọrun. Ni awọn orilẹ-ede kan, niye igba pẹlu ìdẹsí awujọ alufaa Kristẹndọm, iṣẹ wa ni a fofin dè. Bẹẹ ni ọran ri ni orilẹ-ede kan ni Africa. Ṣugbọn awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa nibẹ ṣe gẹgẹ bi Ọba Dafidi ti ṣe. Oun wipe: “Ọlọrun ni emi gbẹkẹ mi le, emi ki yoo bẹru.” (Saamu 56:11) Iriri awọn arakunrin wa ni ilẹ naa fihan pe wọn nigbẹkẹle ninu Jehofa wọn si nbaa lọ pẹlu iṣẹ pataki rẹ.
Ẹlẹrii kan ti nṣiṣẹ gẹgẹ bi olori ile-ẹkọ ni ile-ẹkọ kan tẹpẹlẹ mọ gbigbọ “ti Ọlọrun ju ti eniyan lọ,” ni sisọ ipo aidasi tọtun tosi rẹ si awọn àlámọ̀rí Orilẹ-ede fayegbọ. (Iṣe 5:29) Oun ni a nà jalajala ti a si reti pe yoo gba idajọ gẹgẹ bi ọdalẹ. Gbogbo eniyan ronu pe pipa ni a o pa á. Bi o ti wu ki o ri, Ẹlẹrii naa nigbẹkẹle ninu Jehofa. O nba iṣotitọ rẹ lọ o si ṣalaye awọn idi ti a gbekari ẹri ọkan fun iduro rẹ. Iyọrisi rẹ? A dá a silẹ laijẹbi a si dá a pada si ilu rẹ, nibi ti awọn aṣoju ijọba naa ti wọn nà á ti tọrọ aforiji. Ẹlẹrii oluṣotitọ yii ni a gba pada sẹnu iṣẹ ikọnilẹkọọ ti a si gbe e ga si ipo olubẹwo awọn ile-ẹkọ!
Olùṣekòkáárí ile-ẹkọ kan dá olukọ Ẹlẹrii kan duro. Ni oṣu kan lẹhin naa oluṣekokaari yii gba iwe naa Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ile Aye lọwọ aṣaaju-ọna akanṣe kan o si fohunṣọkan fun ikẹkọọ Bibeli. Lẹhin pipari ori 6, o kọwe ifiṣẹ silẹ gẹgẹ bi oluṣekokaari ile-ẹkọ naa, oun ati aya rẹ si bẹrẹ sii lọ si gbogbo ipade awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Ni owurọ ọjọ Sunday kan olukọ ti a lé kuro naa ni a yàlẹ́nu tayọtayọ lati pade ọkunrin naa ti o ti le e kuro ati lati rii pe ó wa ni oju ọna si didi arakunrin tẹmi kan.
Iriri miiran lati orile-ede kan naa yii ṣakawe bi awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ṣe ngbin ọwọ fun awọn iṣeto Jehofa sini lọ́kàn ti wọn si nṣiṣẹ lati mu ki eto-ajọ naa wa ni mimọ. Aṣaaju-ọna akanṣe kan ti o nṣiṣẹ ni ipilẹ adado ni iriri atako pupọ. Niwọn bi oun ti wá lati ẹ̀yà ati agbegbe miiran, awọn ọta otitọ fẹ lati le e lọ kuro ni abule naa. Bi o ti wu ki o ri, olóyè abule naa tọka si iwa rere rẹ ati awọn iyọrisi rere iṣẹ-ojiṣẹ rẹ ko si yọnda ki a le e lọ. Oloye naa ti ṣakiyesi pe lati igba dide aṣaaju-ọna akanṣe naa, awọn eniyan nbọla fun alaṣẹ ti nṣakoso nipa sisan awọn owo ori wọn ati ṣiṣe iṣẹ oju ọna awujọ lẹẹkan lọsẹ.—Roomu 13:1, 7.
Lẹhin naa, ni alẹ kan Ẹlẹrii miiran ni a ká mọ inu iwa panṣaga pẹlu obinrin kan ti kii ṣe Ẹlẹrii. Ibanilorukọjẹ waye, aṣaaju-ọna akanṣe naa ni a si pe wa siwaju oloye naa, ẹni ti o fi ibinu sọrọ sii ni wiwipe: “Arakunrin rẹ ni a ka mọ iwa paṣanga yii. Ẹyin Ẹlẹ́rìí Jehofa ko yatọ si awọn isin miiran.” Bi o ti wu ki o ri, aṣaaju-ọna naa ṣalaye pe: “Bi o tilẹ jẹ pe a jẹ alaipe, awa yatọ si awọn isin miiran nitori pe awa ko faye gba awọn iṣe awọn wọnni ti wọn da ẹṣẹ wiwuwo.”
Ẹlẹrii naa ti o ṣe panṣaga lo akoko kan ninu ẹwọn o si san owo itanran. Siwaju sii, a yọ ọ́ lẹgbẹ kuro ninu ijọ gẹgẹ bi oluṣe buburu alaironupiwada. Igbesẹ yii wu oloye naa lori o si pa awọn wọnni ti wọn nfi awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ṣẹlẹya lẹnumo. Oloye naa sọ pe: “Ẹ maṣe sọrọ awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni buburu. Wọn ni otitọ. Iru igbesẹ yẹn ni awọn isin miiran kii gbe.”
Awọn Ẹlẹrii oluṣotitọ ni ilẹ yẹn tẹle ìṣínilétí Saamu 37:3 pe: “Gbẹkẹle Oluwa [“Jehofa,” NW], ki o si maa ṣe rere; maa gbe ilẹ naa, ki o si maa nhuwa otitọ.” Awa yoo ha gbẹkẹle Jehofa gẹgẹ bi awọn Kristian wọnyi ti ṣe bi?