ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 1/1 ojú ìwé 25-29
  • Ìfaradà Aláyọ̀ Ní Agbedeméjì Ìlà-oòrùn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìfaradà Aláyọ̀ Ní Agbedeméjì Ìlà-oòrùn
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìsọ̀rí
  • “Ìhà Dídára”
  • “Orukọ Jehofa Gba Ẹmi Mi Là”
  • “Ìtọ́jú Jehofa Yí Wa Ká”
  • Iranlọwọ Pàjáwìrì Wà Lẹnu Iṣẹ!
  • “Irú Ènìyàn Wo Ni Ẹyin Jẹ́?”
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 1/1 ojú ìwé 25-29

Ìfaradà Aláyọ̀ Ní Agbedeméjì Ìlà-oòrùn

Ìròhìn ajínipẹ́pẹ́ yii wá lati ọ̀dọ̀ awọn Ẹlẹrii Jehofa ní Lebanon

ỌDUN iṣẹ́-ìsìn wa 1990 bẹ̀rẹ̀ pẹlu ìfagagbága ti fífọ́n àfọ̀njá oníwà-ipá ní Beirut. Lẹhin naa ìparọ́rọ́ wà lati ìparí September 1989 títí di January 1990.

Láàárín awọn oṣu wọnni góńgó titun ti 2,659 awọn akéde ni a ròhìn (ní November), ni ìfiwéra pẹlu 2,467 ní ọdun iṣẹ́-ìsìn 1989. Awọn ènìyàn mẹrinlelogoji ni a baptisi, ati loṣooṣu ipindọgba 65 ṣàjọpín ninu iṣẹ́-ìsìn aṣaaju-ọna oluranlọwọ. Fun ìgbà àkọ́kọ́, awọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli tí wọn ju 2,000 ni a ròhìn, awa sì bẹrẹsii fojúlọ́nà fun ohun tí a lè ṣàṣeparí ní ọjọ-iwaju.

Ṣugbọn ogun búgbàù lẹẹkan síi ní Ìlà-oòrùn Beirut, níbití ọ̀pọ̀jùlọ awọn ijọ wà, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ iye awọn arakunrin wa sì nilati sálọ sí awọn apá miiran ni orílẹ̀-èdè naa. Fun ọpọlọpọ ọjọ awa kò ní ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ pẹlu awọn ijọ tí wọn wà ní àgbègbè ibi tí ọ̀ràn kàn, awọn ìròhìn iṣẹ́-ìsìn pápá kò sì pé perepere. Bí ó tilẹ rí bẹẹ, awọn arakunrin tí wọn ti fọ́nká darapọ̀ mọ́ awọn ijọ ní àgbègbè ibi tí wọn sálọ, iṣẹ́ ilé-dé-ilé sì nbaalọ pẹlu awọn ìyọrísírere jákèjádò ilẹ̀ orílẹ̀-èdè naa. Láàárín àkókò naa, ọ̀pọ̀ ilé awọn arakunrin wa ni a jó tabi bàjẹ́ nipa awọn bọmbu jíjù naa. Arabinrin kan pàdánù ẹ̀mí rẹ̀.

Pẹlu ìgbọ́kànlé awa wo Jehofa fun iranlọwọ ati ìtọ́sọ́nà. Awọn aṣaaju-ọna onígboyà yọnda araawọn lati mú awọn ìpèsè tẹ̀mí, papọ̀ pẹlu ounjẹ ati omi, lọ fun awọn arakunrin wa ní awọn àyíká tí wọn wà lábẹ́ ìkọlù naa. Bi a ti sún wọn nipa ìfẹ́ fun Jehofa ati fun awọn arakunrin naa wọn tilẹ dágbále ewu sísọdá awọn ojú-ọ̀nà tí a ri ohun-ọṣẹ́ abúgbàù mọ́lẹ̀ sí. Ìjẹ́rìí rere ni a fifúnni gẹgẹbi awọn ènìyàn ti rí ẹrù iranlọwọ tí ńwá sọ́dọ̀ awọn idile arakunrin wa. Wọn rí ohun tí ìfẹ́ tootọ lè ṣe nigbati a bá so gbogbo ènìyàn pọ̀ṣọ̀kan ninu ìjọsìn Ọlọrun tootọ kanṣoṣo naa, Jehofa.—Johanu 13:34, 35; 15:13.

Láàárín ọdun iṣẹ́-ìsìn naa, awọn arakunrin kò padanu ìtẹ̀jáde kanṣoṣo ninu awọn ìwé-ìròhìn wa. Gẹgẹ bi ó ti rí tẹlẹ pẹlu Ilé-ìṣọ́nà, ìwé-ìròhìn Ji! ní Arabic ni a bẹrẹsii tẹ̀jáde nigba kan naa pẹlu Gẹẹsi, bẹ̀rẹ̀ pẹlu itẹjade January 8, 1990. Awọn Ẹlẹrii ati awọn olufifẹhan láyọ̀ pupọ. Ó tún dùnmọ́ni lati rí awọn ìtẹ̀jáde titun ní Arabic irú bíi ìwé-pẹlẹbẹ naa Should You Believe in the Trinity? ati awọn ìwé naa The Bible—God’s Word or Man’s? ati Iwe Itan Bibeli Mi.

Awọn ẹ̀bùn tẹ̀mí wọnyi ni a pèsè láìka títìpa ọpọlọpọ ilé-iṣẹ́ ẹ̀rọ ati awọn ile-iṣẹ iṣowo miiran ní Beirut sí. Ipò ìṣúnná owó burú jákèjádò orílẹ̀-èdè naa. Ọpọlọpọ ibi ni kò ní iná mànàmáná, kò sí omi, kò sí ìpèsè tẹlifoonu. Nisinsinyi, jẹ́ kí diẹ ninu awọn arakunrin wa sọ bí wọn ti rí ayọ̀ àní nigbati wọn ńwọ̀jákadì pẹlu awọn iyọrisi ìrunbàjẹ́ ogun tí ó ti nbaalọ fun 15 ọdun.

“Ìhà Dídára”

Arakunrin kan ní Beirut kọ̀wé pe: “Lákọ̀ọ́kọ́, mo fi ọpẹ́ àtọkànwá fun Jehofa nitori pe oun pa wá mọ́ láìséwu ninu ètò-àjọ ti ìjọsìn mímọ́gaara rẹ̀ láìka gbogbo awọn ipò ìṣòro tí a ti dojúkọ sí. Láàárín awọn ìṣẹ̀lẹ̀ lẹ́nu àìpẹ́ yìí, mo ní awọn ìrírí diẹ tí wọn mú ayọ̀ wá fun mi, mo sì kà wọn sí ìhà dídára ti ogun naa.

“Láàárín àkókò rirọjo bọmbu naa, awa jókòó pẹlu awọn aládùúgbò lórí àtẹ̀gùn pẹ̀tẹ́ẹ̀sì niwọnbi iyẹn ti jẹ́ ibi aabo julọ nigba fífọ́n àfọ̀njá. A ńsọ̀rọ̀ pẹlu wọn ní ìgbà gbogbo nipa Ijọba Ọlọrun gẹgẹbi ojútùú kanṣoṣo fun awọn ìṣòro aráyé. Awa sì gbàdúrà lemọ́lemọ́ sí Ọlọrun wa, Jehofa. Eyi di mímọ̀ fun gbogbo ènìyàn.

“Nigba miiran fífọ́n àfọ̀njá naa wà pẹ́ títí fun ọpọlọpọ ọjọ́, awa kò sì lè lọ sí awọn ipade. Nitori naa mo mú ìwé-ìròhìn Ilé-ìṣọ́nà wà pẹlu mi mo sì kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ nigba ti mo jókòó lórí awọn àtẹ̀gùn pẹ̀tẹ́ẹ̀sì. Iyẹn ru ìfẹ́ awọn aládùúgbò wa sókè. Diẹ ninu wọn kìí ba wa sọ̀rọ̀ nitori pe a jẹ́ Ẹlẹrii Jehofa. Ṣugbọn nigbati a ju àfọ̀njá kan lu ilé wa, kàyéfì ṣe wọn sí ìfẹ́ tí awọn arakunrin wa fihàn. Nisinsinyi wọn fẹ́ lati ba wa sọ̀rọ̀. Iyẹn mu ki a le gba awọn àsansílẹ̀-owó diẹ fun Ji! lọdọ wọn.

“Awọn ìrírí wọnyi mú mi pinnu lati maa sọ̀rọ̀ nipa otitọ naa niṣo. Jehofa lẹ́tọ̀ọ́sí gbogbo ìjọsìn wa ati gbogbo ìgbéníyì ati gbogbo ògo wa.”

“Orukọ Jehofa Gba Ẹmi Mi Là”

Arakunrin kan lati Ijọ Ras Beirut ròhìn: “Aya mi, awọn ọmọkunrin wa kekere meji, ati emi bẹ̀rẹ̀ ọjọ́ wa ninu iṣẹ́-òjíṣẹ́ ilé-dé-ilé ní ẹ̀ka-ìpín ìwọ̀-oòrùn Beirut. Ní ọsan, awa ṣe ipade elédè Gẹẹsi ní ilé mi. Ní agogo mẹfa aabọ ìrọ̀lẹ́ òkùnkùn ṣú. Kìkì awọn ènìyàn tí wọn wà lójú òpópó jẹ awọn ọkunrin adìhámọ́ra. Awọn bọmbu ńrọ̀jò silẹ. Ọ̀pọ̀ jùlọ awọn olùgbé ilé wa ti sá. Kò sí yálà omi tabi iná mànàmáná. Lẹhin naa awa gbọ́ ìró ilẹ̀kùn kíkàn.

“Ríronú pe ó lè jẹ́ ọ̀kan lára awọn aládùúgbò tí ó nílò omi tabi burẹdi, aya mi ṣí ilẹ̀kùn naa. Awọn ọkunrin adìhámọ́ra mẹrin ni wọn dúró nibẹ. Wọn na ìbọn wọn sí aya mi wọn sì fi orukọ beere mi. Ní ọsẹ yẹn awọn ọkunrin mẹ́sàn-án ni a ti mú kúrò ninu ilé wọn ní ọ̀nà yii tí a sì pa lẹsẹkẹsẹ. Nigbati awọn ọkunrin adìhámọ́ra naa rí mi, wọn na awọn ìbọn wọn ti nda ṣiṣẹ sí orí mi wọn sì fun mi láṣẹ lati lọ pẹlu wọn. Mo sọ fun wọn pe: ‘Emi yoo lọ pẹlu yin. Ṣugbọn lákọ̀ọ́kọ́ ẹ jẹ́ kí nwọṣọ.’ Mo gbàdúrà sí Jehofa pẹlu gbogbo ọkàn-àyà mi, ní bibeere fun iranlọwọ rẹ̀. Bi mo ti parí àdúrà gbígbà, mo nímọ̀lára ìdẹ̀ra mo sì bẹrẹsii wo awọn ọkunrin adìhámọ́ra ati akó-jìnnìjìnnì-báni wọnyi bí awọn ènìyàn àìṣàrà ọ̀tọ̀. Mo lè ba wọn sọ̀rọ̀ láìbẹ̀rù.

“Mo beere lọwọ wọn pe: ‘Kinni ẹyin ńfẹ́ lati ọwọ́ mi? Ẹ jẹ́ kí a sọ̀rọ̀ diẹ ninu ilé ṣaaju kí á tó kúrò.’ Nigbati a ti wà ninu iyara inaju, olórí wọn beere lọwọ mi: ‘Ẹ̀tọ́ wo ni o ní lati wọ awọn ilé kí o sì waasu fun awọn ènìyàn?’ Mo fèsìpadà: ‘Ẹyin gbé ìbọn lati fi ipá mú ìfẹ́-inú yin ṣẹ, kò sì sí ẹni tí ó dí yin lọwọ. Emi gbé ihinrere ti alaafia tí Jesu pàṣẹ rẹ̀ fun wa lati waasu.’ Lẹhin naa mo ṣàlàyé awọn ìgbàgbọ́ ati iṣẹ́ awọn Ẹlẹrii Jehofa. Nigba ti mo mẹnukan orukọ Jehofa, wọn wipe: ‘Yoo tẹ́ wa lọ́rùn lati fìbéèrè wádìí lẹ́nu rẹ níhìn-ín. Kò sí ìdí lati mú ọ lọ pẹlu wa.’ O ṣe kedere pe, ọ̀kan lára wọn jẹ́ ojúlùmọ̀ pẹlu arakunrin kan. Oun wipe: ‘Ẹni yii dabi Jarjoura.’

“A jẹ́rìí fun awọn ọkunrin oníbọn wọnni a sì dáhùn awọn ibeere wọn fun wakati kan ati aabọ. Lẹhin naa, dípò gbigbe mi lọ ninu ibi ikẹrusi ọkọ wọn gẹgẹbi wọn ti ṣe pẹlu awọn miiran, wọn tọrọ àforíjì, wọn fi ẹnu kò mi ní ẹnu, wọn ṣèlérí lati pèsè iranlọwọ wọn bí mo bá nílò rẹ̀ nigbakigba, wọn sì lọ. Ní gbogbo àkókò yii, mo nímọ̀lára ààbò Jehofa. Ṣíṣàjọpín ninu iṣẹ́ ilé-dé-ilé ní òwúrọ̀ yẹn ati lilọ sí ipade ní ọ̀sán naa ti fun mi lókun lati dúró gbọnyingbọnyin. Nitootọ, orukọ Jehofa gba ẹmi mi là.”—Owe 18:10.

“Ìtọ́jú Jehofa Yí Wa Ká”

Arakunrin miiran lati Beirut kọ̀wé: “Ó jẹ́ ọjọ́ Wednesday, January 31, 1990. Nigbati mo ńrìn lọ pẹlu arakunrin mi ní ilé arabinrin kan, ìjà naa bẹ̀rẹ̀ lẹẹkan síi. Awọn bọmbu ńbúgbàù níbigbogbo. Nitori ìjà yíyewèlè naa, awa kò lè padà sí ilé. Arabinrin naa jẹ́ olùfẹ́ àlejò ṣíṣe àní bí ó tilẹ jẹ́ pe oun ní kìkì iwọnba ègé burẹdi diẹ.

“Mo dààmú gan-an nipa aya mi nitoripe oun jẹ́ ọmọ Philippines, ìwà-ipá ati ogun kò sì mọ́ ọn lára. Ní ọjọ́ keji, bí ó ti wù kí ó rí, mo le fi ibẹ silẹ lọ sí ilé mi. Awọn ìkòjọ pelemọ ohun ọ̀ṣọ́ ilé dí awọn ojú-pópó, ṣugbọn ọpẹ́ ni fun Jehofa, idile mi wà láìséwu. Lẹhin ìparọ́rọ́ ṣókí, fífọ́n àfọ̀njá lọna rẹpẹtẹ bẹ̀rẹ̀ lẹẹkan síi. Awa sápamọ́ sínú ilé arakunrin kan lẹ́bàá tiwa. Awa márùn-ún ni a wà níbẹ̀—aya mi, ọmọkunrin mi ọlọ́dún meji, emi, arakunrin mi, ati aya rẹ̀. Awọn bọmbu, àfọ̀njá, ati rọ́kẹ́ẹ̀tì ńjábọ́ kaakiri, ṣugbọn ìtọ́jú Jehofa yí wa ká. Fífọ́n àfọ̀njá ọlọ́jọ́ meji kọjá, nigbati awa nbaalọ lati dọ̀bálẹ̀ pẹlu èéfín awọn bọmbu naa ninu awọn ihò imú wa.

“Bi a ti nfetisilẹ sí awọn ìbúgbàù, awa ranti awọn ọ̀rọ̀ Dafidi ní Saamu 18:1-9, 16-22, 29, 30. Ní awọn àkókò ìṣòro wọnni, ati láìka gbogbo ohun tí ńṣẹlẹ̀ sí, awa láyọ̀ a sì lè rẹ́rìn-ín músẹ́ sibẹ. Awa gbadura sí Jehofa pe bí awa bá nilati kú, kí awa kú pẹlu ìrọ̀rùn, láìjìyà. Ireti wa ninu ajinde lágbára.

“Ọjọ́ tí ó tẹle e kò ṣeé gbàgbọ́. Nǹkan bíi bọmbu 25 jábọ́ nítòsí ilé naa níbití a farapamọ́ si, ṣugbọn kò sí ọ̀kan ninu wa tí ó farapa. Iwọ ha lè ronú ki o si wòye ìmọ̀lára wa bi awa ti ri ọwọ ààbò Jehofa? Ní òwúrọ̀ tí ó tẹle e, awa pinnu lati sá lẹsẹkẹsẹ. Ọkọ̀-ayọ́kẹ́lẹ́ mi nikanṣoṣo ni ó wà lórí títì tí kò tíì jó. Mo wakọ̀ kọjá láàárín awọn ohun-ọṣẹ́ ti a rì mọ́lẹ̀ ati awọn bọmbu, ọpẹ́ sì ni fun Jehofa, awa lè sá àsálà lọ sí ibìkan tí ó parọ́rọ́ diẹ ju tiwa. Nibẹ, awọn arakunrin pèsè awọn aṣọ, ounjẹ, ati owó fun wa pẹlu ìfẹ́.

“Láìka gbogbo awọn ìṣòro naa sí, awa nímọ̀lára ayọ̀ nitoripe Jehofa wà pẹlu wa. Ó fẹrẹẹ dabi ẹnipe ṣe ni ó rán awọn angeli rẹ̀ lati pa awọn bọmbu naa mọ́ kúrò lọ́dọ̀ wa. (Saamu 34:7) Bẹẹni, ayọ̀ wa pọ̀ pupọ. Ṣugbọn ayọ̀ wa yoo di pupọ sii lẹhin líla Armageddon já.”

Iranlọwọ Pàjáwìrì Wà Lẹnu Iṣẹ!

Awọn àgbègbè Beirut diẹ dabi pe ìsẹ̀lẹ̀ ti ṣẹlẹ nibẹ. Ọpọlọpọ ilé awọn arakunrin wa ni a bàjẹ́ tabi parun. Nigba ti yánpọnyánrin aipẹ yii dìde, Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka ṣètò igbimọ iranlọwọ pàjáwìrì lati bójútó àìní awọn arakunrin. Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ ní February 16, 1990, gan-an ní nǹkan bíi àkókò naa nigba ti awa lè ṣí lọ sí awọn àgbègbè tí a pọ́nlójú naa. Ète ìgbìmọ̀ yii jẹ́ alápá mẹta: lati fi ìṣírí tẹ̀mí fun awọn ara; lati bójútó awọn àìní wọn fun owó, ounjẹ, ati omi; ati lati ràn wọn lọwọ lati ṣàtúnṣe tabi tún awọn ilé wọn kọ́.

Kò sí ìdí fun pípè awọn olùyọ̀nda-ara-ẹni. Ní ọjọ́ kọọkan ọpọlọpọ farahàn ní kùtùkùtù òwúrọ̀ lati ṣèrànlọ́wọ́. Níhìn-ín ni diẹ lára awọn ọ̀rọ̀ ti awọn wọnni tí a ṣèrànwọ́ fun sọ:

Bi a ti nsọ ilé arabinrin kan di mímọ́tónítóní tí a sì nmú un padàbọ̀sípò, oun wipe: “Mo ńgbọ́ nipa iranlọwọ tí awọn arakunrin ńfifúnni nigba ti àjálù bá ṣẹlẹ. Nisinsinyi mo rí i mo sì nímọ̀lára rẹ̀.” Àní aládùúgbò rẹ̀ pàápàá, obinrin Musulumi kan, sọ fun arabinrin yii pe: “Ẹyin nífẹ̀ẹ́ araayin nitootọ. Tiyín ni ìsìn títọ̀nà. Nisinsinyi emi yoo sáré lọ sí abúlé mi emi yoo sì sọ fun olukuluku ohun tí ẹyin ṣe níhìn-ín.” Aládùúgbò yii mú ounjẹ diẹ wá fun awọn òṣìṣẹ́ olùyọ̀nda-ara-ẹni.

Arabinrin àgbàlagbà kan sọ̀rọ̀ pe: “Mo fojúsọ́nà pe ẹyin yoo wá lati bẹ̀ mi wò, ṣugbọn emi kò fojúsọ́nà pe Society yoo rán ẹnikan lati bu omi wá fun mi.” Oun sọkún gẹgẹbi ó ti ńfẹnuko arakunrin naa tí ó wá lati ràn án lọwọ lẹnu.

Idile ẹlẹ́ni mẹta kan—ọkọ ati aya tí wọn jẹ́ akéde aláìṣèrìbọmi ati ọmọkunrin wọn kekere—ni a bẹ̀wò tí a sì fun ní àpótí wàrà nla kan, burẹdi diẹ, omi mímu, ati owó. Nigba naa a sọ fun wọn pe awọn Ẹlẹrii Jehofa ni wọn ṣètò yii, ọkọ naa wipe: “Mo wà ninu Ṣọọṣi Evangelical fun 11 ọdun mo sì jẹ́ alákitiyan iṣẹ́ gan-an. Ṣugbọn fun ọdun 15 ninu ogun yii ní Lebanon, wọn kò tíì ronú lati ṣe ohunkohun bí eyi fun awọn mẹmba wọn.” Oun nbaalọ: “Eyi niti-tootọ jẹ ètò-àjọ kanṣoṣo ti Ọlọrun.” Ọkọ naa ati aya rẹ̀ ni a baptisi ní apejọ kan ní May 1990.

Alàgbà kan sọ pe: “Ẹnu wa kò gbọpẹ́ fun awọn iṣẹ́ ìfẹ́ tí ẹyin ṣe fun awọn arakunrin tí a pọ́nlójú. A ṣí mi lórí tobẹẹ tí mo fi da omijé pòròpòrò nigbati mo rí àwùjọ awọn ọ̀dọ́ arakunrin, awọn oluyọnda ara-ẹni, tí wọn ńtún ilé awọn òbí mi kọ́. Àní awọn aládùúgbò wa pàápàá tí wọn kii ṣe Ẹlẹrii sọ ìmọrírì wọn jáde. Awa nitootọ ṣọpẹ́ fun Jehofa ati ètò-àjọ rẹ̀ fun ìtìlẹhìn gbígbéṣẹ́ tí a ti fifúnni. Bawo ni awọn ọ̀rọ̀ onisaamu naa ti jóòótọ́ tó ní Saamu 144:15 (NW): ‘Aláyọ̀ ni awọn ènìyàn naa tí Ọlọrun wọn jẹ́ Jehofa.’”

“Irú Ènìyàn Wo Ni Ẹyin Jẹ́?”

Arabinrin kan pẹlu idile rẹ̀ kọ̀wé: “Mo fẹ́ lati sọ ìmọrírì jíjinlẹ̀ mi fun ìfẹ́ tí Jehofa ati ètò-àjọ rẹ̀ fihàn jáde. Ọpọlọpọ àfọ̀njá bọ lù ilé mi ó sì jóná. Ọpọlọpọ sọ fun wa pe a kò lè kọ́ ọ. Bí ó ti wù kí ó rí, níhìn-ín ni ó dúró tí a ti ṣàtúnṣe rẹ̀ látòkèdélẹ̀ bi ẹni pe ohunkohun kò tíì ṣẹlẹ̀ sí i, tí a yí i ka nipasẹ ọgọrọọrun awọn ilé ní ojú-pópó wa tí a ti jó tabi parun.

“Àní awọn aládùúgbò wa pàápàá, tí wọn kii ṣe Ẹlẹrii Jehofa, nbeere pe: ‘Lati ibo ni ìfẹ́ yii ti wá? Irú ènìyàn wo ni ẹyin jẹ́? Awọn wo ni awọn ẹni wọnyi tí wọn ńṣiṣẹ́ pẹlu irú ìtara bẹẹ tí wọn ṣe jẹ́jẹ́ ti wọn sì mọ̀wàáhù? Ibukun ni fun Ọlọrun tí ó ti fun yin ní ìfẹ́ ati ẹ̀mí ìfara-ẹni rúbọ yii.’ Bawo ni awọn ọ̀rọ̀ Saamu 84:11, 12 ti ba a mu rẹ́gí tó: ‘Nitori Oluwa [“Jehofa,” NW] Ọlọrun ni oòrùn ati asà: Oluwa [“Jehofa,” NW] yoo fúnni ni oore-ọ̀fẹ́ ati ògo: kò sí ohun rere tí yoo fàsẹ́hìn lọwọ awọn tí ńrìn déédéé. Oluwa [“Jehofa,” NW] awọn ọmọ-ogun, ibukun ni fun olúwa rẹ̀ naa tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ.’”

Ọkunrin kan ẹni tí aya ati awọn ọmọ rẹ̀ jẹ́ Ẹlẹrii Jehofa kọ̀wé: “Emi yoo fẹ́ lati dupẹ lọwọ yin fun iranlọwọ yin ninu ṣíṣàtúnṣe ilé wa. Iṣẹ́ yin fi ìfẹ́ Kristian olóòótọ́-inú hàn eyi tí ó ṣọ̀wọ́n pupọ ní awọn ọjọ́ wọnyi. Kí Ọlọrun fi ibukun sí awọn ìsapá yin.”

Lẹhin tí a mú ilé alàgbà kan padàbọ̀sípò, oun wipe: “Ẹnu wa kò lè sọ ohun tí ó wà ninu ọkàn-àyà wa jáde tán. Awa kò lè rí ọ̀rọ̀ tó lati sọ ìmọrírì wa fun Jehofa ati ètò-àjọ rẹ̀ fun yin. Awa nímọ̀lára ìsúnmọ́ra tímọ́tímọ́ Jehofa ninu àjálù ti o de ba wa. Ìfẹ́ yin ti fun gbogbo mẹmba idile mi níṣìírí lati ṣàjọpín ninu ríran awọn ẹlomiran ninu àìní lọwọ.”

Ní April, awọn ènìyàn 194 ní Lebanon gbádùn iṣẹ́ aṣaaju-ọna oluranlọwọ. Alẹ́ Iṣe-iranti parọ́rọ́ ju awọn alẹ́ miiran, a sì ṣe Iṣe-iranti naa pẹlu àpapọ̀ iye awọn ènìyàn tí wọn pesẹ ti o jẹ 5,034. Gbogbo awọn apejọ tí a wéwèé ni a ṣe, àpapọ̀ iye awọn ènìyàn tí a baptisi fun ọdun naa sì jẹ́ 121, laika rudurudu ti nbẹ ni orilẹ-ede naa si. Ọpọlọpọ idile ninu awọn ijọ naa fi orílẹ̀-èdè naa silẹ laipada mọ. Ṣugbọn awọn olufifẹhan titun ńtẹ̀síwájú siha baptism, 2,726 àròpọ̀ awọn olùpòkìkí Ijọba naa sì ńpọ̀síi. Láàárín ọdun iṣẹ́-ìsìn 1990, gbogbo awọn ènìyàn Jehofa ní Lebanon nírìírí ìṣòtítọ́ Jehofa gẹgẹbi oun ti ṣètọ́jú wọn daradara tí ó sì tọ́ wọn sọ́nà la awọn àkókò onírọ̀ọ́kẹ̀kẹ̀ kọjá.—Saamu 33:4, 5; 34:1-5.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́