Araadọta Ọkẹ Nlọ. Iwọ Nkọ?
Lọ sibo? Si ayẹyẹ ọdọọdun iku Jesu Kristi. Ni 1990 aropọ yika aye ti 9,950,058 ni wọn pesẹ. Eeṣe ti awọn eniyan fi nlọ? Nitori ohun ti iku Kristi tumọsi fun ẹda araye. O tumọsi itura alaafia ti o sunmọle kuro lọwọ aisan, irora, ati iku. Ani awọn ololufẹ ti wọn ti kú paapaa ni a o ji dide si iye lori ilẹ-aye ti a mu pada bọ sipo di Paradise. Bawo ni iku Jesu ṣe le mu iru awọn ibukun bẹẹ wa? A kesi ọ lati ṣe iwadii lati mọ̀. Awọn Ẹlẹrii Jehofa kesi ọ lati darapọ mọ́ wọn nigba iṣẹlẹ pataki yii. Lọ si Gbọngan Ijọba ti o sunmọ ile rẹ julọ. Ni ọdun yii déètì naa jẹ Saturday, March 30, lẹhin tí oorun bá wọ̀. Wadii lọdọ awọn Ẹlẹrii ti wọn wà ni adugbo rẹ fun akoko naa gan-an.