O Sunmọ Ju Bi Wọn Ti Rò Lọ!
ỌDUN naa ni 609 B.C.E. Ibi iṣẹlẹ naa jẹ́ Jerusalẹmu. Olubanisọrọ naa ni, Jeremaya wolii. O sọ aṣọtẹlẹ iparun fun ilu rẹ̀ mímọ́ ti ó nifẹẹ julọ, Jerusalẹmu, iparun ti yoo wá nitori pe awọn Juu ti kọ̀ ẹyin wọn sí Jehofa wọn sì ti ri ara wọn bọ inu ijọsin awọn ọlọrun èké. Wọn nlọwọ ninu ijọsin oniṣekuṣe takọtabo lori awọn ibi giga, wọn npese awọn ẹbọ ohun mimu sí awọn ọlọrun oriṣa, wọn njọsin oorun ati oṣupa ati awọn irawọ, wọn ńjó tùràrí sí Baali, wọn si fi awọn ọmọ wọn rubọ sí Moleki.—1 Ọba 14:23, 24; Jeremaya 6:15; 7:31; 8:2; 32:29, 34, 35; Esekiẹli 8:7-17.
Ni oju wọn Jeremaya jẹ́ olùkébòsí ìjábá, agbawèrè mẹ́sìn, alainitẹẹlọrun si ohun gbogbo ati sí olukuluku eniyan. Fun 38 ọdún Jeremaya ti nkilọ fun wọn; fun 38 ọdún awọn olugbe Jerusalẹmu ti ńfi í ṣẹlẹya. Titi di akoko yii, awọn eniyan naa ti ńpa Jehofa tì sapakan, ni wiwi pe oun kìí ṣe ipá kan ti a nilati daniyan lé lórí. Wọn wipe: “Oluwa [“Jehofa,” NW] kì yoo ṣe rere, bẹẹ ni kì yoo ṣe buburu” ati “Oluwa [“Jehofa,” NW] ti kọ aye silẹ, Oluwa [“Jehofa,” NW] kò riran.”—Sefanaya 1:12; Esekiẹli 9:9.
Wolii Jeremaya ati Esekiẹli ti nwaasu iparun Jerusalẹmu, ṣugbọn kò sí ohunkohun tí o tíì ṣẹlẹ. Nitori naa awọn ọmọ Israẹli fagile imuṣẹ irú iran bẹẹ ní ọjọ́ wọn, ni wiwi pe: “A fa ọjọ́ gùn, gbogbo iran di asán.” Ṣugbọn èsì Jehofa sí eyi ni pe: “Ọjọ́ kù sí dẹ̀dẹ̀, . . . nitori emi ni Oluwa [“Jehofa,” NW]: emi yoo sọrọ, ọ̀rọ̀ tí emi yoo sọ yoo sì ṣẹ, a kì yoo fà á gun mọ́; nitori ni ọjọ́ yin, ọlọtẹ ile, ni emi yoo sọ ọ̀rọ̀ naa, emi yoo sì ṣe é.”—Esekiẹli 12:22-25.
Ni 609 B.C.E., akoko tó fun Jehofa lati mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ. Lẹhin ti Jeremaya ti nkede ikilọ naa fun nǹkan tí o sunmọ ẹwadun mẹrin, ilu Jerusalẹmu ni a sagati lati ọwọ awọn ọmọ-ogun Babiloni. Oṣu mejidinlogun lẹhin naa awọn ogiri naa ni a ya lulẹ, tẹmpili ni a jó níná, ọpọ julọ awọn eniyan naa sì ni a kó lọ sí igbekun ni Babiloni. Gẹgẹ bi a ti sọ ọ́ tẹlẹ, nipa idà ati ìyàn ati ajakalẹ arun ni a pa ilu naa run.—2 Ọba 25:7-17; 2 Kironika 36:17-20; Jeremaya 32:36; 52:12-20.
Jeremaya tọ̀na, awọn eniyan naa kò tọ̀nà. O ti sunmọle ju bí wọn ti rò lọ! Ìran naa kìí ṣe fun awọn ọdún tí ó jinna réré. Ó wà fun ọjọ́ wọn.
Eyi kìí ṣe itan kan ṣáá. Ohun tí o ṣẹlẹ sí Jerusalẹmu jẹ́ alasọtẹlẹ. Ó jẹ́ ojiji iṣaaju fun ohun kan tí nbọ. Kristẹndọm ode oni gba orukọ Kristi ó si fi idaniloju sọ pe oun wà ninu ibatan onimajẹmu pẹlu Ọlọrun; sibẹ oun ntọ ipasẹ awọn olugbe Jerusalẹmu atijọ. Ni gbogbogboo awọn ṣọọṣi Kristẹndọm maa nkọni ní awọn ẹkọ igbagbọ oloriṣa, awọn ni a sọdibajẹ pẹlu iwa palapala takọtabo, wọn nṣagbatẹru ipetepero oṣelu, wọn nti awọn ogun aye lẹhin, wọn tẹwọgba ẹkọ ẹfoluṣọn wọn si ṣaifiyesi Ọlọrun gẹgẹ bi Ẹlẹdaa, wọn mọ́jú sí ifirubọ araadọta ọkẹ awọn ọmọ ti a kò tíì bí lori pẹpẹ irọrun, ati ni gbogbogboo wọn gbà awọn ọgbọn ìmọ̀-ọ̀ràn ẹda eniyan lò ni sisọ pe Bibeli jẹ́ àlọ́ ati itan arosọ.
Gẹgẹ bi awọn eniyan Jerusalẹmu ti fi Jeremaya rẹrin-in ẹlẹya, bẹẹ ni Kristẹndọm ṣe nfi awọn Ẹlẹrii Jehofa rẹrin-in ẹlẹya lonii. Ikilọ iparun tí nbọ ni Amagẹdọni tí awọn Ẹlẹrii nṣe ni a patì ṣegbẹẹkan gẹgẹ bi eyi ti kò wulo. Kristẹndọm wipe, ‘Ọlọrun ko ni ifẹ si ilẹ aye. Ẹ jẹ́ kí o maa bojuto ọrun; awa yoo maa bojuto ilẹ-aye. Bi Amagẹdọni ba si maa dé, ko ni jẹ ni iran tiwa. Awa ti gbọ itan yẹn rí tẹlẹ. Awa ko ni jẹ́ kí a fi iyẹn tan wa jẹ!’
Eyi yoo ha jẹ atunsọ itan bí? Yoo ha jẹ akoko miiran nigba ti araadọta ọkẹ yoo wá rii pe o ti sunmọle ju bi wọn ti ro lọ bí?