Awọn Olupokiki Ijọba Rohin
Jehofa Pese Itura
LẸNU aipẹ yii, awọn Ẹlẹrii Jehofa ni Guusu Africa gba ọrọ nipa ipo iṣoro lilekoko ti awọn arakunrin wọn nipa tẹmi ni orilẹ ede kan nitosi wọn nibi ti a ti fofinde iṣẹ iwaasu wọn. A rohin rẹ fun wọn pe nitori ọgbẹlẹ ti o lekenka, awọn arakunrin wọn nwalaaye niṣo nipa jijẹ awọn gbòǹgbò igi kan bayii. Awọn pẹlu ṣalaini aṣọ wiwọ ti o bojumu, eyi ti o mu ki awọn Ẹlẹrii diẹ lọtikọ lati ṣalabaapin ninu iṣẹ ojiṣẹ pápá.
Loju ẹsẹ awọn arakunrin ti wọn wa ni Guusu Africa dahunpada. Ipe ni a ran jade si awọn ijọ adugbo ni agbegbe Johannesburg nipa aini fun aṣọ wiwọ. Laarin awọn ọjọ melookan, iwọn tọọnu mẹta ohun wiwọ ni a ti fi tọọrẹ. Awọn ohun eelo naa ni a pín sọtọọtọ nipasẹ awọn oṣiṣẹ oluyọnda ara ẹni. Awọn iṣeto ni a ṣe lati ko iwọn tọọnu 3 ẹ̀wà, iwọn tọọnu 1 epo, iwọn tọọnu 1 ọṣẹ, iwọn tọọnu 17 ounjẹ agbado. Nigba ti ile-iṣẹ ti o ko ounjẹ agbado naa wa gbọ nipa ipo iṣoro awọn Ẹlẹrii ninu ilẹ ti ọgbẹlẹ ti ṣe lọ́ṣẹ́ naa, wọn fi eyi ti o ju idaji iwọn tọọnu ounjẹ ti a nilo gidigidi yii tọrẹ.
Ni ọjọ Mọnday, April 16, 1990, ọkọ akẹru pẹlu iwọn tọọnu 25 ẹru awọn ipese itura fi Guusu Africa silẹ ninu irin ajo rẹ ti 3,400 ibusọ. Ṣugbọn nisinsinyi iyọnda ni a nilati gba lati ọdọ awọn alaṣẹ ki o ba le ṣeeṣe lati gbe awọn ipese wọnyi kọja sinu orilẹ ede wọn ti ogun ti ya pẹrẹpẹrẹ.
Awọn alaṣẹ naa ti o wa ni ile aṣoju ijọba ilẹ okeere sọ pe bi o tilẹ jẹ pe awọn Ẹlẹrii Jehofa ni a ko mọ labẹ ofin ní orilẹ ede wọn, wiwa nibẹ wọn ni a mọ daradara. Ko ni si ikọfun eyikeyi lati mu awọn ipese itura ranṣẹ si awọn arakunrin wa. Iyọnda ni a fọwọsi. Awọn iwe-aṣẹ ti o pọndandan ni a kọ jade, ni ọjọ Friday, April 20, awọn Ẹlẹrii naa sọda ibode naa laisi iṣoro. Bi o ti wu ki o ri, wọn ṣalabaapade eyi ti o ju 30 awọn ibi idọkọduro, nibiti a ti nbeere lọwọ wọn lọpọ igba lati fi awọn iwe-aṣẹ wọn han. Kiki nigba naa ni wọn mọ ni amọdunju bi awọn iwe-aṣẹ wọnyẹn ti pọndandan to.
Lẹhin ti wọn ti rin nnkan bii 90 ibusọ sinu orilẹ ede naa, itẹsiwaju wọn ni a di lọwọ nipasẹ odo nla kan ti o kun akunya. Afara ipilẹṣẹ ni a ti bajẹ, afárá onigba diẹ ti o wa ni ipo rẹ ni ko si rọgbọ fun ọkọ-ẹru nla lati gba kọja. Bi o ti wu ki o ri, wọn ṣawari pe ọkọ-irinna kekere naa ti o nba ẹru naa lọ le kọja lori afara ti omi ti kun bo naa laisewu. Nigba naa ni a pinnu lati pin si ẹgbẹ meji. Àgọ́ kan ni a pa sẹba odo ti o kún ya naa fun ẹgbẹ kan, nigba ti ẹgbẹ keji nbaa lọ ni oju ọna wọn lati pade awọn ara ni nnkan bi 160 ibusọ ni ọna jijin si apa ariwa. Bawo ni wọn ti layọ to nigbẹhingbẹhin lati ṣalabaapade awọn ara! Wọn ko le da ẹrin, wiwa mọra, bibọwọ duro. Laipẹ awọn ọkọ-akẹru adugbo meji bọ si oju ọna wọn lati pade ẹgbẹ awọn ara keji ti wọn nduro ni ẹba odo naa. Nibẹ, awọn ipese itura naa ni a ṣi nipo pada lati inu ọkọ-akẹru nla naa sinu awọn kekere meji naa.
Awọn irohin ti a gba fi awọn imọriri jijinlẹ fun ipese Jehofa ti ohun ipese itura naa han. Sibẹsibẹ, laika ipo iṣoro wọn nipa ti ara si, igbe awọn arakunrin naa fun ounjẹ tẹmi ni o tubọ jẹ ti kanjukanju jù. Ijọ kan ni anfaani si kiki Ilé-ìṣọ́nà kanṣoṣo, eyi ti a nilati tun kọ fun olukuluku idile. Ọpẹ ni fun Jehofa, awọn iṣeto ti ntẹsiwaju bayii lati pese iṣanwọle alaidawọduro ounjẹ tẹmi fun awọn ara ni orilẹ ede yẹn.