Ipenija Wiwaasu Ni Ọ̀kan Lara Èbúté Titobi Julọ Ni Ayé
ROTTERDAM, ti ó wà nibi ti Rhine, odò ti a ń lò julọ ni Europe wà, wọnu North Sea, ó sì ní anfaani ti jíjẹ́ ọ̀kan lara awọn èbúté òkun titobi julọ ni ayé. Pẹlu ohun ti o tó nǹkan bii 500 ile-iṣẹ ọkọ oju-omi ti ń wá sihin-in, Rotterdam ni isopọ taarata pẹlu iye ti ó ju 800 ibi ti a ń lọ yika ayé. Èbúté agbaye kan ni nitootọ.
Bi o ti wu ki o ri, èbúté Dutch ọlọdun 650 yii ju ọgangan ipade awọn ile-iṣẹ ọkọ oju-omi lọ. Ó tun jẹ́ ibi ipade awọn eniyan. Ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ awọn awakọ oju-omi ń dé ni gbogbo ọ̀sán ati òru lati gbogbo igun ayé. Awọn ọ̀jáfáfá awakọ oju-omi wọnyi kò tii bọ́ lọwọ afiyesi Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni Netherlands. Bii Awọn Ẹlẹ́rìí nibikibi miiran, wọn wá ọ̀nà lati waasu ìhìn didara julọ ni ayé—pe Ijọba Ọlọrun yoo yí ilẹ̀-ayé pada si Paradise kan laipẹ—fun awọn eniyan oniruuru gbogbo, ti ó ní awọn awakọ̀ òkun ninu.—Daniẹli 2:44; Luuku 23:43; 1 Timoti 4:10.
“Iṣẹ Ayanfunni Ojihin-Iṣẹ Ọlọrun ní Àyídà”
Ni awọn ọdun diẹ sẹhin, Watch Tower Society ni Netherlands sọ fun awọn oniwaasu alakooko kikun mẹfa, tabi awọn aṣaaju-ọna, lati ṣiṣẹ lati inu ọkọ oju-omi de inu ọkọ oju-omi ni gbogbo èbúté Rotterdam yẹn. Awọn aṣaaju-ọna bẹ́ mọ́ anfaani naa. Wọn gba isọfunni lọdọ awọn alaṣẹ èbúté, ṣayẹwo ibùdó ọkọ̀ òkun naa, wọn sì mọ laipẹ pe awọn ní iṣẹ ayanfunni kan ti ń peni níjà.
“Ńṣe ni ó dabi iṣẹ ayanfunni ojihin-iṣẹ Ọlọrun ní àyídà,” ni Meinard, ẹni ti ń ṣe kòkáárí iwaasu ibùdó ọkọ̀ òkun naa sọ. Ki ni ó ní lọ́kàn? “Bí ó ti sábà maa ń rí ojihin-iṣẹ Ọlọrun kan yoo rin irin-ajo jíjìn lati lọ sọdọ awọn eniyan, ṣugbọn ninu ọ̀ràn tiwa awọn eniyan naa ń rin irin-ajo jíjìn lati wa sọdọ wa.” Ó fikun un pe, “ó ṣeeṣe ki boya ipinlẹ iwaasu wa jẹ́ jakejado awọn orilẹ-ede gẹgẹ bi o ti lè lóye rẹ̀ tó.” Iwe ọdọọdun naa Rotterdam Europoort ti 1985 sọ pe ní 1983, ọdun naa ti awọn aṣaaju-ọna naa bẹrẹ iṣẹ akanṣe yii, 30,820 awọn ọkọ tí ń rìn loju omi lati awọn orilẹ-ede 71 ọtọọtọ wá sí èbúté Rotterdam. Iyẹn jẹ́ jakejado awọn orilẹ-ede!
Lọna tí ó ṣe wẹ́kú, “awọn ojihin-iṣẹ Ọlọrun ni èbúté” naa—bi awọn awakọ̀ oju-omi ti bẹrẹ sii pe awọn aṣaaju-ọna naa laipẹ—tún gbé animọ ti jíjẹ́ jakejado awọn orilẹ-ede yọ. Geert, Peter, ati aya rẹ̀, Karin, jẹ́ ará Dutch; Daniël ati Meinard wá lati Indonesia; Solomon sì jẹ́ ará Ethiopia. Orírun wọn tí ó jẹ́ ti Europe, Asia, ati Africa mú wọn rekọja iṣoro èdè mẹjọ, ṣugbọn lati ṣaṣeyọri ninu iṣẹ yii, wọn ní awọn iṣoro miiran lati bojuto.
“Ṣọọṣi Agunkẹ̀kẹ́”
“Iwọ kò lè ṣàdédé rìn lọ sí ibudo ọkọ̀, kí o gun àkàsọ̀ ọkọ oju-omi, ki o sì wọ ọkọ oju-omi,” ni Peter ẹni ọdun 32, atukọ̀ òkun tẹlẹri kan sọ. “Iwọ nilo iwe-aṣẹ ayika-ilẹ.” Iyẹn tumọ si iwe-aṣẹ lati wọnu awọn èbúté ati iwe-aṣẹ lati wọ ọkọ̀ oju-omi. Peter pè é pada sọkan pe, “ó kún fun àìmọye àyẹ̀wò kínníkínní, ṣugbọn lẹhin ti a ti gba iwe-aṣẹ mẹjọ, ti ó ní aworan wa ati òǹtẹ̀ ijọba ninu, a ṣetan lati fi itara jade.” Wọn pín awọn ibudo ọkọ̀ èbúté naa ti ó jẹ́ ibusọ 23 sí ìpín mẹta, tí awọn aṣaaju-ọna meji sì ń bojuto ọkọọkan.
Bi o ti wu ki o ri, bawo ni ẹ ṣe ń koju ọpọlọpọ èdè ti awọn atukọ̀ òkun lati ọpọlọpọ orilẹ-ede tobẹẹ ń sọ? Ani bi o tilẹ jẹ pe awọn aṣaaju-ọna ní awọn iwe ikẹkọọ Bibeli ni 30 èdè sọ́wọ́ ti wọn sì ń kó ọpọlọpọ bi o ti le ṣeeṣe tó sori kẹ̀kẹ́ wọn, ó sábà jọ bi ẹni pe kò sí eyi ti ó pọ̀ tó. “Iwọ kò mọ awọn èdè ti iwọ yoo nilo daju,” ni Solomon ẹni 30 ọdun rohin pẹlu ẹ̀rín músẹ́. “Ó ń ṣẹlẹ niye ìgbà pe awọn atukọ̀ òkun maa ń fẹ awọn iwe ni èdè ti iwọ kò mú dání gan-an, wọn yoo sì sọ fun ọ pe ọkọ̀ awọn yoo ṣí ni iwọn wakati mẹta sii tabi ki ó sunmọ ọn.” Láìfẹ́ lati já awọn atukọ̀ òkun kulẹ̀, ọ̀kan lara awọn aṣaaju-ọna naa yára lọ, ó mú awọn iwe ti o yẹ, ó sáré pada, ó sì fi wọn lé awọn atukọ̀ òkun ti ń yánhànhàn naa lọwọ. “Nigba ti iṣoro kan naa dide nigba ti a ń waasu ni awọn apakan èbúté naa ti ó wà ni ibi ti ó jinna tó irin-ajo wakati mẹta lori kẹ̀kẹ́,” ni Peter sọ, “o hàn kedere pe a nilo ọ̀nà ìgbàbójútó miiran.”
Ni ọjọ kan Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kan ti wọn ń gbé ni agbegbe èbúté naa ya awọn aṣaaju-ọna lẹnu pẹlu ọmọlanke meji ti kẹ̀kẹ́ lè fà, ti ọkọọkan jẹ́ ìwọ̀n ọpọ́n-ìfọṣọ oyinbo kan. Awọn aṣaaju-ọna naa fi iwe ikẹkọọ ni gbogbo èdè ti ó wà larọọwọto kún ọmọlanke ti kẹ̀kẹ́ lè fà naa, wọn so ó mọ́ kẹ̀kẹ́ wọn, wọn sì forile èbúté. Laipẹ awọn ọmọlanke naa di ohun ti a ń rí nigba gbogbo. “Wọn ti di àmì ìkésíni wa,” ni ọ̀kan ninu awọn aṣaaju-ọna naa wí. “Nigba ti adènà kan bá rí wa ti a ń bọ̀, yoo ṣí ọ̀nà àbáwọlé, yoo juwọ sí wa pe ki a kọja, yoo sì pariwo pe: ‘Sọọṣi agunkẹ̀kẹ́ ni ó ń lọ yẹn o!’” Ni awọn ìgbà miiran, nigba ti oluṣọ kan bá ṣakiyesi “ṣọọṣi agunkẹ̀kẹ́” ti ń bọ̀ lọdọ rẹ̀, yoo ṣí ọ̀nà yoo sì ké jade pe: “Polish meji ati Chinese kan!” Iru ìtanilólobó ti ń ranni lọwọ bẹẹ jẹ ki ó ṣeeṣe fun awọn aṣaaju-ọna lati lọ sinu ọkọ̀ oju-omi pẹlu iwe ikẹkọọ ni awọn èdè ti ó yẹ. Ṣugbọn wọn tún gbọdọ lọ ni akoko ti ó bojumu. Eeṣe?
Awọn Ibẹwo Tí Ó Bọ́ Si Akoko Pẹlu Ihin-Iṣẹ Tí Ó Bọ́ Si Akoko
Awọn aṣaaju-ọna lè bá awọn oṣiṣẹ inu ọkọ̀ oju-omi sọrọ kìkì ni akoko isinmi ráńpẹ́ ní àárọ̀ ati ni ọ̀sán tabi ni wakati ounjẹ ọ̀sán wọn. Bi o ti wu ki o ri, awọn ti ń se ounjẹ ní awọn wakati iṣiṣẹ ti o yatọ, adarí ọkọ̀ òkun ati awọn oṣiṣẹ miiran ni a sì lè ri ni gbogbo ọjọ ṣúlẹ̀. Ju bẹẹ lọ, awọn aṣaaju-ọna mọ̀ pe awọn ọkọ oju-omi ti Britain ti a fi gúnlẹ̀ si Rotterdam faramọ́ akoko awọn Britain (ti o fi wakati kan yatọ si akoko awọn Dutch), ki awọn oṣiṣẹ inu ọkọ̀ oju-omi wọn ba a lè forílé yàrá ounjẹ nigba ti awọn oṣiṣẹ inu ọkọ̀ ti kì í ṣe ti Britain bá pada sẹnu iṣẹ. Lọna ti ó hàn gbangba, fun aṣaaju-ọna èbúté kan, aago ọrùn ọwọ ti ó ṣee gbarale jẹ́ kòṣeémánìí.
Bi o ti wu ki o ri, awọn atukọ̀ òkun ha ń muratan lati lo sáà akoko isinmi wọn fun awọn ijiroro Bibeli bi? “Lọpọ ìgbà julọ, mo rii pe wọn jẹ́ awọn ti wọn ni ọkàn ṣíṣípayá siha ihin-iṣẹ Ijọba naa,” ni Geert ẹni ọdun 31 sọ. “Boya iyẹn jẹ́ nitori pe wọn rí ìkùnà awọn ijọba eniyan ní taarata.” Fun apẹẹrẹ, awọn atukọ̀ òkun kan sọ fun Geert pe awọn àkójọ ọkà ti wọn ti já fun awọn ará Ethiopia ti ebi ń pa ṣì wà nilẹ nibẹ ni ọpọlọpọ oṣù lẹhin naa nigba ti wọn tun lọ sibẹ, kìkì pe nigba naa ọkà naa ti rà ti awọn eku sì ti fi inu rẹ̀ ṣe ile. “Kò sí iyemeji pe ọpọlọpọ awọn atukọ̀ òkun ti padanu ireti ninu iṣelu,” ni Geert ṣalaye. “Nitori naa ileri Bibeli ti ijọba kan fun gbogbo araye fà wọn mọra.”
Peter fohunṣọkan. “Olùṣàbójútó ọkọ̀ òkun ara Germany kan sọ pe ni ọdun mẹwaa sẹhin awọn oṣiṣẹ inu ọkọ̀ òkun rẹ̀ ìbá ti lé mi kuro ninu ọkọ̀ oju-omi naa, ṣugbọn awọn ipo ayé ti ń yipada lonii ti ru ifẹ wọn soke ninu ihin-iṣẹ Bibeli ti ó bọ́ sí akoko.” Olùṣoúnjẹ inu ọkọ̀ Korea kan sọ pe lakooko ogun Iran-oun-Iraq, ọkọ̀ elépo ńlá tí oun fi ń ṣiṣẹ ni rọ́kẹ́ẹ̀tì kan kọlù ti o sì gbiná ni Gulf ti Paṣia. Ó jẹ́jẹ̀ẹ́ pe bi oun bá wà láàyè, oun yoo wá Ọlọrun. Ó làájá nitootọ. Nigba tí awọn aṣaaju-ọna pade rẹ̀ lẹhin naa ni Rotterdam, ó fẹ́ gbogbo iwe ikẹkọọ ti wọn lè mú wá fun un ni èdè Korea.
Ọpọ julọ awọn ọkọ̀ oju-omi naa duro ni èbúté naa fun ọpọlọpọ ọjọ. Eyi fun awọn aṣaaju-ọna naa lanfaani lati pada ní ìgbà meji, mẹta, tabi ni ìgbà pupọ sii lati maa bá ijiroro Bibeli wọn lọ lẹhin awọn wakati iṣiṣẹ. Sibẹ, nigba ti ọkọ̀ oju-omi kan bá ní iṣoro ẹnjinni, ó lè wà lori ìso nibẹ fun ọ̀sẹ̀ mẹta. “Iyẹn kò dara fun ile-iṣẹ naa,” ni aṣaaju-ọna kan dọgbọn sọ tẹ̀ríntẹ̀rín, “ṣugbọn ó dara fun iṣẹ wa.” Lẹhin naa, yatọ si bíbá awọn ijiroro Bibeli naa lọ, awọn aṣaaju-ọna naa tun ṣeto lati fi ọ̀kan han lara awọn itolẹsẹẹsẹ aworan slide ti Society, “Bibeli—Iwe Kan fun Ìran Yii,” ninu iyàrá ounjẹ. Awọn atukọ̀ òkun kan tún wá sí ipade Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni Rotterdam ti ó wà fun ọpọlọpọ awujọ elédè àjèjì. Eyi a maa wà titi di ìgbà ti ẹnjinni ọkọ̀ bá tó tun ṣiṣẹ. Nigba naa ni Bibeli tó gbọdọ padé. Okùn ti a fi de ọkọ̀ oju-omi naa mọ́lẹ̀ ni a o tú, ti ọkọ naa yoo sì lọ kuro ni èbúté—ṣugbọn kì í ṣe kuro ninu ọkàn awọn aṣaaju-ọna naa.
Ìtàn Afunni Niṣiiri Ti Awọn Atukọ̀ Òkun
Nipasẹ akọsilẹ lẹsẹẹsẹ awọn iwe irohin tabi eto igbekalẹ kọmputa gbogbogboo ti awọn olùṣàbójútó èbúté, awọn aṣaaju-ọna èbúté naa pa iwọle ati ijade awọn ọkọ̀ oju-omi ti wọn ti ṣebẹwo sí mọ́. Gbàrà tí ọ̀kan ninu wọn bá ti wọle lẹẹkan sii, awọn aṣaaju-ọna naa ni ìháragàgà lati ké sí awọn atukọ̀ òkun naa lati wadii ohun ti ó ti ṣẹlẹ lati ìgbà ibẹwo tí ó kẹhin. Iru ìtàn afunni niṣiiri wo ni awọn atukọ̀ òkun naa maa ń sọ!
Atukọ̀ òkun kan fi awọn ẹ̀dà iwe naa Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye fun marun-un lara awọn atukọ̀ òkun ẹlẹgbẹ rẹ̀ lẹhin ti ó ti ṣíkọ̀ bọ́ sójú òkun, awọn mẹfẹẹfa sì ṣe ikẹkọọ Bibeli. Oun tun ka akori nipa igbesi-aye idile sori ẹ̀rọ kasẹẹti afetigbọ ó sì tẹ̀ ẹ́ fun gbígbọ́ ni iyàrá ounjẹ fun anfaani gbogbo awọn oṣiṣẹ inu ọkọ̀ oju-omi. Ninu ọkọ̀ oju-omi miiran, atukọ̀ òkun kan ti ó ti lọ si Gbọngan Ijọba kan ni èbúté Antwerp ti ó sunmọ tòsí gbé ọ̀págun kan ti ó ni awọn ọrọ naa ti a kọ gàdàgbàgàdàgbà “Gbọngan Ijọba Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa” sara ogiri iyàrá ounjẹ naa. Lẹhin naa ó ké sí awọn mẹmba oṣiṣẹ inu ọkọ̀ oju-omi lati wá si ibẹ nigba ti ó dari ipade Bibeli kan. Ṣaaju ki ó tó gbé ọ̀págun naa kuro, ó ké sí awọn oṣiṣẹ inu ọkọ̀ oju-omi naa wá si ipade ti ó tẹle e. Ni ọsẹ ti ó tẹle e, ọpagùn ati awọn oṣiṣẹ inu ọkọ̀ oju-omi naa wà nibẹ lẹẹkan sii.
Awọn aṣaaju-ọna naa tun rí pe awọn atukọ̀ òkun kan kò fi iwe wọn pamọ. “Nigba ti a wọnu iyàrá inu ọkọ̀ oju-omi Isaac, oṣiṣẹ ile redio Iwọ-oorun Africa kan, ó ṣoro lati rí ijokoo,” ni Meinard rohin. “Awọn iwe irohin, iwe ńlá, ati concordance ti Society wà nibi gbogbo—ní ṣíṣí silẹ.” Isaac tun ni iwe akọsilẹ awọn ibeere Bibeli ni sẹpẹ́, gẹgẹ bi oun ti ń duro de ipadabẹwo awọn aṣaaju-ọna naa.
Bi o ti wu ki o ri, awọn atukọ̀ òkun melookan, kò duro de awọn aṣaaju-ọna lati wá sọdọ wọn. Ni alẹ́ ọjọ kan foonu Geert dún ganranran lẹhin ti ó ti lọ sun.
“Ta ni onítọ̀hùn yẹn ìbá jẹ́ o?” ni Geert fi ìkùnsínú sọ bi o ti ń táràrà lati lọ gbé gbohùngbohùn foonu.
“Pẹ̀lẹ́ o, ọ̀rẹ́ rẹ niyii!” ni ohùn ọlọyaya kan sọ.
Geert gbiyanju lati ronu ẹni ti ó lè jẹ́.
“Ọ̀rẹ́ rẹ lati inu ọkọ oju-omi ni,” ni ohùn naa sọ lẹẹkan sii.
“Agogo mẹta òru niyii!” ni Geert sọ.
“Bẹẹni, ṣugbọn o sọ fun mi pe kí n ké sí ọ ni gbàrà ti ọkọ̀ mi bá ti gunlẹ si Rotterdam lẹẹkan sii. Ó dara, mo wà nihin-in!” Laipẹ lẹhin naa, Geert ti wà ni oju-ọna rẹ̀ lati pade ọ̀rẹ́ ti o nifẹẹ ninu Ọrọ Ọlọrun yii.
‘Fún Ounjẹ Rẹ Jade’
Imọriri fun iwe ikẹkọọ Bibeli wa ni a tun fihan ninu awọn lẹta lati ọdọ awọn atukọ̀ si ọdọ awọn aṣaaju-ọna naa. Eyi ti o tẹle e ni awọn àyọkà diẹ:
‘Mo ti bẹrẹ sii ka iwe naa Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye . . . Nisinsinyi mo wá loye ọpọlọpọ awọn nǹkan ti emi kò loye tẹlẹ. Mo nireti pe ọkọ̀ oju-omi wa yoo pada si Rotterdam.’—Angelo.
‘Mo ka iwe naa, mo sì ń fi awọn ibeere ranṣẹ si ọ ki o lè dahun wọn ninu awọn lẹta rẹ.’—Alberta.
‘Mo ń ka Bibeli lojoojumọ nisinsinyi. Inu mi dùn lati jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ. Rírí awọn ọ̀rẹ́ ti o dari mi sọdọ Ọlọrun ni ohun didara julọ ti ó ti ṣẹlẹ ninu igbesi-aye mi.’—Nickey.
Iru awọn lẹta amọ́kànyọ̀ bẹẹ rán awọn aṣaaju-ọna naa létí ohun ti Bibeli sọ ni Oniwaasu 11:1 pe: “Fún ounjẹ rẹ si oju-omi; nitori ti iwọ o rí i lẹhin ọjọ pupọ.” Wọn yọ̀ ni pataki nigba ti wọn gbọ́ pe awọn atukọ̀ òkun kan ti mú iduro wọn fun Jehofa.
Stanislav atukọ̀ òkun ará Poland kan, ní tirẹ, ni ohun ti ó kẹkọọ rẹ̀ lati inu iwe ikẹkọọ Society dùn mọ lọ́kàn. Ó yára ṣe ibi ikoweesi kekere kan ti iwe ikẹkọọ Bibeli, nigba ti ó bá sì wà loju òkun, a ka gbogbo rẹ̀ patapata. “Nigba ti a tún gbúròó rẹ̀,” ni Meinard sọ, “ó kọwe pe oun ti ṣe iribọmi.”
Folkert, balogun ọkọ̀ oju-omi aarin ilu kan, kọ́kọ́ gbọ́ ihin-iṣẹ Ijọba naa ni Rotterdam. Ni gbogbo oṣu meji-meji ni ó maa ń pada wá si èbúté fun ọ̀sẹ̀ kan ti yoo sì kẹkọọ Bibeli fun ọjọ meje tẹlera tẹlera. Lẹhin naa, ṣaaju ki ó tó lọ fun irin-ajo oloṣu meji miiran, awọn aṣaaju-ọna naa fun un ni itolẹsẹẹsẹ akọsilẹ awọn adirẹsi Gbọngan Ijọba loju ọ̀nà ọkọ̀ rẹ̀. Folkert ṣebẹwo si awọn gbọngan naa a sì mú ori rẹ̀ wú nipa itẹwọgba ọlọyaya ti ó rigba. Laipẹ jù, balogun ọkọ̀ oju-omi yii gba iribọmi ó sì ń fi taapọntaapọn ṣiṣẹsin Jehofa nisinsinyi.
Mike, Jagunjagun Oju-Omi ọlọ́lá àṣẹ ara Britain, ti rí ifarakanra diẹ rí pẹlu Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ó sì ti ń kẹkọọ Bibeli nigba ti ó wà loju òkun. Lẹẹkanri, nigba ti ọkọ̀ ologun oju-omi ti ó ṣiṣẹ ninu rẹ̀ dákọ̀ró ní Rotterdam, ó lo kẹ̀kẹ́ alátòpọ̀ rẹ̀ lati lọ si Gbọngan Ijọba kan. A mú ori rẹ̀ wú nipa ifẹ ati iṣọkan ti ó rí ó sì sọ fun awọn ọ̀rẹ́ pe oun ti pinnu lati kuro lẹnu iṣẹ oun. Bi o tilẹ jẹ pe ó ku ọdun mẹrin ki ó gba owó gọbọi fun ifẹhinti lẹnu iṣẹ, ó dirọ mọ́ ipinnu rẹ̀ a sì bamtisi rẹ̀ lẹhin naa.
Meinard sọ pe: “Ìháragàgà Mike, Stanislav, Folkert, ati awọn miiran lati ṣiṣẹsin Jehofa sún wa lati maa baa lọ ni wiwa awọn atukọ̀ òkun bii wọn kaakiri èbúté naa.”
Iwọ Ha Lè Ṣajọpin Bi?
Ni wíwẹ̀hìn wò fun ohun ti ó fẹrẹẹ tó ẹwadun kan ti wiwaasu ninu ọ̀kan lara awọn èbúté titobi julọ ni ayé, “awọn ojihin-isẹ Ọlọrun ti èbúté” mẹfa naa fi tọkantọkan gbà pe—iṣẹ ayanfunni naa ti jẹ́ apeninija ṣugbọn ó mú èrè wá. “Lẹhin ọjọ iwaasu kọọkan,” ni Meinard sọ ni àkópọ̀, awa “a maa gun kẹ̀kẹ́ pada lọ si ile pẹlu imọlara naa pe diẹ lara awọn atukọ̀ òkun wọnni ń duro fun ibẹwo wa.”
Awọn atukọ̀ òkun ha lè wà ti wọn ń duro fun ibẹwo ni ebute kan ni agbegbe rẹ bi? Boya awọn alagba ninu ìjọ rẹ lè ṣe awọn ètò ki o baa lè ni ipin ninu iṣẹ ti ń peni nija ṣugbọn ti ń mú èrè wá yii.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 20]
NINASẸ JADE WỌNU AWỌN IPINLẸ TI A TI FOFINDE
Ni ọdun ẹnu aipẹ yii kan, awọn ọkọ̀ oju-omi ti iye wọn ju 2,500 lọ lati awọn orilẹ-ede nibi ti igbokegbodo Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti wà labẹ ifofinde duro létíkun ni Rotterdam. Awọn aṣaaju-ọna èbúté naa sì rí iyẹn gẹgẹ bi anfaani kan lati nasẹ ihin-iṣẹ Bibeli wọnu awọn ipinlẹ wọnyi.
Ninu ọ̀kan lara awọn ọkọ oju-omi Asia akọkọ ti wọn bẹwo, awọn aṣaaju-ọna fi gbogbo iwe 23 ti wọn ni lọwọ sode, ni fifi awọn mẹmba oṣiṣẹ inu ọkọ̀ oju-omi kan silẹ pẹlu idaamu ọkàn nitori pe wọn tàsé rírí ẹ̀dà kan gbà. Ọdọmọkunrin kan ti ń ṣiṣẹ ninu ile idana ninu ọkọ̀ oju-omi Asia miiran tubọ jẹ́ oniṣọọra. Lẹhin gbigba iwe kan lọwọ aṣaaju-ọna kan, ó dá a pada ní pípọ́n ọn sinu bébà pẹlu adirẹsi ti a kọ sara rẹ̀. Aṣaaju-ọna naa loye kókó naa. Ó lewu pupọ fun ọmọkunrin naa lati mú iwe naa lọ pẹlu rẹ̀. Ni ọjọ yẹn kan naa aṣaaju-ọna naa fi ranṣẹ sí Far East.
Lati inu ọkọ̀ oju-omi kan ti ó wá lati Africa ni atukọ̀ òkun kan ti wá pẹlu akọsilẹ lẹsẹẹsẹ awọn iwe tí Awọn Ẹlẹ́rìí ni ilu rẹ̀ fẹ́. Lati ìgbà naa lọ, ìgbà kọọkan tí atukọ̀ òkun naa bá ti pada si ile, apoti ìfàlọ́wọ́ rẹ̀ a maa kun fun iwe ikẹkọọ. Atukọ̀ òkun kan lati orilẹ-ede Africa miiran ni a já kulẹ gidigidi nigba ti aṣaaju-ọna ti ń bá a ṣekẹkọọ lè fun un ni kìkì ẹ̀dà mẹta pere ninu iwe naa Mimu Ki Igbesi Ayé Idile Rẹ Jẹ Alayọ. “Iyẹn kò tó nǹkankan!” ni atukọ̀ òkun naa kigbe, ní fifi ibinu ju ọwọ́ rẹ̀. “Awọn ará ni ile nilo 1,000!” Fun aabo araarẹ̀, aṣaaju-ọna naa yí i lero pada lati gba kìkì 20 ẹ̀dà lakooko kan.
Boya eyi ti o mú àánú ṣeni julọ ni akoko naa nigba ti awọn aṣaaju-ọna naa gbọ́ pe ọkọ̀ oju-omi kan ti dé lati orilẹ-ede kan nibi ti a ti ṣenunibini si Awọn Ẹlẹ́rìí nitori awọn igbagbọ wọn, ti ọpọlọpọ sì ti padanu iṣẹ ati ohun ìní wọn. Nigba ti wọn wadii rí i pe iriju ti ó wà ninu ọkọ̀ jẹ́ Ẹlẹ́rìí kan, wọn lọ sọdọ olùṣàbójútó ọkọ̀ wọn sì beere fun iyọnda lati fi iranlọwọ itura ranṣẹ ninu ọkọ̀ oju-omi rẹ̀. Olùṣàbójútó ọkọ̀ naa gbà, ati niwọnba ọjọ diẹ lẹhin naa, ọgọrun-un kan àpò ńlá ti ó kún fun aṣọ, bata, ati awọn ọjà miiran wà loju ọ̀nà wọn si ọdọ Awọn Ẹlẹ́rìí ni orilẹ-ede yẹn.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 21]
WIWAASU LATI INU ỌKỌ̀ OJU-OMI DÉ INU ỌKỌ̀ OJU-OMI—OJU-IWOYE OBINRIN KAN
Karin, obinrin kanṣoṣo ti ó wà laaarin awọn aṣaaju-ọna naa ranti pe, “lakọọkọ, mo lọ́tìkọ̀ lati tẹle Peter, nitori pe mo ti gbọ́ awọn ìtàn pe awọn atukọ̀ òkun kò dara wọn sì jẹ́ ọ̀mùtí. Bi o ti wu ki o ri, mo ti rí i pe ọpọ julọ ninu wọn jẹ ọmọluwabi. Niye igba, lẹhin ti atukọ̀ òkun bá ti mọ̀ pe a jẹ́ tọkọtaya ti ó ti ṣegbeyawo, yoo fa aworan iyawo ati awọn ọmọ rẹ̀ yọ yoo sì bẹrẹ sii ṣawada nipa idile rẹ̀. Ni ọ̀nà yẹn, a ti fi ọpọlọpọ ẹ̀dà iwe Mimu Ki Igbesi Ayé Idile Rẹ Jẹ Alayọ sode.”
Ṣiṣebẹwo sinu awọn ọkọ̀ oju-omi gẹgẹ bi tọkọtaya tun mú un rọrun lati dé ọdọ aya awọn mẹmba oṣiṣẹ inu ọkọ oju-omi ati awọn obinrin miiran ti wọn maa ń ṣiṣẹ nigba miiran gẹgẹ bii nọọsi. “Gẹgẹ bi ó ti sábà maa ń rí, wọn ki i sọ tinú wọn jade fun awọn ajeji,” ni Karin sọ, “ṣugbọn nigba ti wọn bá rí mi, wọn a maa ní ìtẹ̀sí lọpọlọpọ sii lati lọwọ ninu ijumọsọrọpọ.”
Ki ni ipenija titobi julọ ninu iṣẹ ayanfunni rẹ̀? Karin dahun pe, “Àkàbà olókùn ni.” “Mo koriira awọn nǹkan tẹẹrẹtẹẹrẹ wọnyẹn.” Ǹjẹ́ oun ha bori ẹ̀rù rẹ̀ bi? “Bẹẹni. Nigba kan ti mo lọ́tìkọ̀ lati gun ọ̀kan, awujọ awọn atukọ̀ òkun kan lati Paraguay wò mi wọn sì pariwo pe: ‘Iwọ lè gùn ún. Ṣá ti nigbẹkẹle ninu Ọlọrun.’ Nitootọ,” ni Karin sọ pẹlu ẹ̀rín, “lẹhin ọrọ yẹn, emi kò ni yíyàn bikoṣe lati goke.” Ọkọ rẹ̀ tí ó rọra ń wò ó sọ pe: “Ọdun mẹrin ati ọpọlọpọ àkàbà olókùn lẹhin naa, oun ń gùn wọn bii atukọ̀ òkun kan nisinsinyi.”
Karin ati ọkọ rẹ̀, Peter, lọ si kilaasi 89 ti Watchtower Bible School of Gilead ni United States. Ni September 28, 1990, wọn lọ sẹnu iṣẹ ayanfunni wọn titun, ni Ecuador, orilẹ-ede kan ti ó ni èbúté. Wọn gbọdọ nimọlara wíwà ni ile.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 22]
IWỌ HA JẸ́ ATUKỌ̀ ÒKUN KAN BI?
Iwọ ha fẹ́ lati lọ si ipade elédè gẹẹsi ti Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa nigba ti ọkọ̀ rẹ bá gúnlẹ̀ sí ọ̀kan lara awọn èbúté titobi ni ayé bi? Nigba naa pa akọsilẹ leṣẹẹsẹ ti adirẹsi Gbọngan Ijọba ati awọn akoko ipade ni lọwọlọwọ yii mọ́ sọ́wọ́:
Hamburg, Schellingstr. 7-9; Saturday, 4:00 ìrọ̀lẹ́; foonu: 040-4208413
Hong Kong, 26 Leighton Road; Sunday, 9:00 owurọ; foonu: 5774159
Marseilles, 5 Bis, rue Antoine Maille; Sunday, 10:00 owurọ; foonu: 91 79 27 89
Naples, Castel Volturno (40 km ariwa Naples), Via Napoli, corner of Via Salerno, Parco Campania; Sunday, 2:45 ọ̀sán; foonu: 081/5097292
New York, 512 W. 20 Street; Sunday, 10:00 owurọ; foonu: 212-627-2873
Rotterdam, Putsestraat 20; Sunday, 10:00 owurọ; foonu: 010-41 65 653 Tokyo, 5-5-8 Mita, Minato-ku; Sunday, 4:00 ìrọ̀lẹ́; foonu: 03-3453-0404
Vancouver, 1526 Robson Street; Sunday, 10:00 owurọ; foonu: 604-689-9796