Wọn Ń Rí Ayọ Tootọ Ninu “Paradise”
PARADISE! Ọ̀rọ̀ yẹn sábà maa ń wá sọkan nigba ti awọn eniyan ba ronu nipa Hawaii—ati fun awọn idi rere. Apọto awọn ipese bii ipo oju-ọjọ ti o wadeede, awọsanma mímọ kedere, awọn igi ọpẹ ti ń fẹ́ rìyẹ̀, afẹfẹ titunilara, ati awọn bebe okun oniyanrin ni o wà nihin-in—awọn ohun ti ọpọ lè kà si ipo oniparadise.
Irisi wọnyi ti fa awọn eniyan lati itòsí ati ibi jijinna mọra. Wọn ti wá lati Asia, awọn ilẹ okun Pacific, America, ati awọn erekuṣu bii ti Caribbean ati Europe paapaa. Ọpọ ni wọn ti ṣí wá sihin-in nitori ipo oju-ọjọ rirọnilara ti o maa ń wà yipo ọdun. Dajudaju, awọn miiran ń wá lati wá aabo nipa eto ìṣúnná-owó—ati ayọ. Abajade rẹ̀ ni didi ibi ikorijọpọ fun ẹgbẹ awọn eniyan orilẹ-ede ati ti ẹ̀yà-ìran yiyatọsira, pẹlu oniruuru awọn àṣà-ìṣẹ̀dálẹ̀ ati awọn ero igbagbọ isin ọlọ́kan-kò-jọ̀kan.
Bi o ti wu ki o ri, apá ìhá miiran wà fun aworan naa. Bi ọpọ awọn ibi rirẹwa lori ilẹ̀-ayé, Hawaii ni a ń yọlẹnu pẹlu iwa-ọdaran, oogun, ìya-pòókì, biba ayika jẹ́, ati ọpọ awọn iṣoro miiran ti ń rọ́lu awọn idile eniyan mọ́lẹ̀ laika ibi yoowu ti ẹnikan lè maa gbe si. Nipasẹ aibikita eniyan ati imọtara-ẹni-nikan, awọn erekuṣu Hawaii ni a ń fi diẹdiẹ jà lólè awọn ẹwà adanida wọn. Awọn eniyan ń fẹ paradise, ṣugbọn kìí ṣe gbogbo awọn ti ń gbé nibẹ ni wọn bikita tó lati sọ ọ́ di paradise tabi pa awọn erekuṣu wọnyi mọ́ gẹgẹ bii paradise kan ó kerepin. Ó gbà ju ayika adanida rirẹwa ati ipo oju-ọjọ kan ti o banilaramu lati ṣe paradise kan.
Bi o ti wu ki o ri, ẹgbẹ awọn eniyan ti ń pọ sii kan wà ti ń gbe nihin-in ti wọn ń gbadun ayọ tootọ ninu igbekalẹ onipo paradise yii. Wọn jẹ ẹnikọọkan ti ń tẹwọgba otitọ Bibeli ti wọn si ń fi ileri Ọlọrun yiyanilẹnu sọkan: “Emi o da ọrun titun ati ayé titun: a kì yoo si ranti awọn ti iṣaaju, bẹẹni wọn ki yoo wá si àyà.” Awọn eniyan wọnyi ń fi tayọtayọ wo ọjọ́ iwaju pẹlu awọn ọrọ aposteli Peteru naa lọkan: “Ṣugbọn gẹgẹ bi ileri rẹ̀, awa ń reti awọn ọrun titun ati ayé titun, ninu eyi ti ododo ń gbé.” (Isaiah 65:17; 2 Peteru 3:13) Awọn wo ni awọn eniyan wọnyi? Bawo ni wọn ṣe wá kẹkọọ ireti agbayanu naa ti a gbekalẹ ninu Bibeli? Awọn iyipada wo ni a ti mu wá ba igbesi-aye wọn?
A Bori Ibẹru Iku
Isabel ati ọkọ rẹ̀, George, jẹ ọmọ ibilẹ Philippines. Oun ni a tọ́ dàgbà lati tẹle isin Roman Katoliki ti awọn obi rẹ̀ ń ṣe, bi o tilẹ jẹ pe oun kò tii figbakanri wo inu Bibeli. Isabel ni a ti kọ́ pe ọkàn eniyan jẹ alaileeku. Bawo ni o ṣe huwapada si ẹ̀kọ́ èké yii? O dara, oun bẹru ironu kíkú nitori pe o ni ero didi ẹni ti a sin laaye titilae ninu pósí kan, ti ọkàn rẹ̀ bi o ti gbagbọ ki yoo si lè jadelọ. Ni 1973, bi o ti wu ki o ri, Isabel bẹrẹ sii kẹkọọ Bibeli pẹlu Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Nigba ti o kẹkọọ pe ọkàn eniyan kìí ṣe alaileeku ati pe Ọlọrun yoo mú iku kuro nipasẹ ajinde, oun ni idunnu rẹ̀ kun akunwọsilẹ ti o sì nimọlara itura lọna pipọjọjọ. (Esekieli 18:4, 20; Johannu 5:28, 29) Otitọ Bibeli wọ̀ ọ́ lọ́kàn tobẹẹ ti o fi tẹsiwaju lọna yiyarakankan.
Kí ni nipa George? Oun pẹlu ń jokoo nibẹ ni awọn akoko ijiroro Bibeli ṣugbọn kiki pẹlu ero jíjá Awọn Ẹlẹ́rìí naa níkoro. Bi o ti wu ki o ri, oun kò lè ri ohunkohun ti o gbòdì ninu ohun ti wọn ń kọ́ oun ati iyawo rẹ̀. Niti tootọ, laipẹ laijinna lẹhin ti wọn bẹrẹ sii kẹkọọ, koko ẹ̀kọ́ nipa ọran ẹ̀jẹ̀ dide. Titi di igba yẹn, George ni o ti kúndùn lati maa jẹ awọn ounjẹ ti a fi ẹ̀jẹ̀ ṣe. Ṣugbọn nigba ti o rii pe ni kedere ni Bibeli dẹbi fun jijẹ ẹ̀jẹ̀, o jáwọ́ ninu rẹ̀. (Genesisi 9:3, 4; Lefitiku 17:10-12; Iṣe 15:28, 29) O ń baa niṣo lati nipin-in ninu ikẹkọọ Bibeli inu rẹ̀ si dun pe nigbẹhin-gbẹhin oun ti ri otitọ. Lonii, George, Isabel, ati awọn ọmọ wọn mẹrẹẹrin ni wọn ń gbadun ayọ tootọ ni gbigbe ni ibamu pẹlu ọ̀pá-ìdiwọ̀n Ọlọrun.
Isin Kristian Tootọ Fa Wọn Mọra
Ọkunrin ọmọ ilẹ Japan kan, ti orukọ rẹ̀ ń jẹ George ati iyawo rẹ̀ Lillian, ọmọ ilẹ Potogi, ni wọn ti lé ni 60 ọdun. Awọn mejeeji ni a bí ti a si tọ́ dàgbà ni Hawaii. Niwọn bi awọn obi rẹ̀ kò ti fun George ni itọni isin eyikeyii, oun kò figbakanri fi ọwọ́ pataki mu isin. Sibẹ, oun ti fi igba gbogbo ni igbagbọ ninu Ọlọrun. Ni ọwọ́ keji ẹ̀wẹ̀, awọn obi Lillian tọ̀ ọ dàgbà ninu isin wọn, gẹgẹ bi Roman Katoliki kan.
Bi o tilẹ jẹ pe George kò ní ìháragàgà fun kika Bibeli, oun ti ń ka iwe-irohin Ilé-Ìsọ́nà ati Ji! fun nǹkan bii 30 ọdun. Oun ti tipa bẹẹ kẹkọọ ohun ti o pọ̀ nipa Bibeli. Ni jijẹ amusiga ati ọmuti paraku, bi o ti wu ki o ri, o ń falẹ̀ lati ṣe iyipada ninu igbesi-aye rẹ̀. Bi ọdun ti ń gori ọdun, George ń baa niṣo lati ka awọn iwe-irohin ti o si ń wa si awọn ipade Kristian ni Gbọngan Ijọba lẹẹkọọkan. Eeṣe? Nitori pe, gẹgẹ bi o ti sọ ọ, “awọn isin yooku jẹ alagabagebe pupọ jù” ni fifaayegba ọpọ awọn nǹkan buburu ti Bibeli dalẹbi. Oun lè rii pe Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa yatọ.
Kí ni ohun ti o fa Lillian, iyawo aduroṣinṣin fun George, sinu otitọ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun bi o tilẹ jẹ pe isin awọn obi rẹ̀ ti nipa lori rẹ̀ gidigidi? O dara, arabinrin rẹ̀ tii ṣe ọmọ iya rẹ̀ késí i wá si awọn ipade ni Gbọngan Ijọba. “Mo gbadun ipo ayika idile alayọ ati awọn ẹrin muṣẹ ti ẹni bi ọrẹ wọnni,” ni Lillian pada ranti. Ojulowo ifẹ ti o ri ti a fihàn laaarin awọn eniyan Jehofa mu un gbagbọdaju pe eyi ni otitọ. (Johannu 13:34, 35) Ó tẹwọgba ikẹkọọ Bibeli, ó si ya igbesi-aye rẹ̀ si mimọ fun Jehofa Ọlọrun nígbẹ̀hìn-gbẹ́hín, a si baptisi rẹ̀ ni oṣu melookan lẹhin ti ọkọ rẹ̀ ti ṣe tirẹ̀.
George kò tun mu siga tabi mutiyo mọ́, Lillian si ti sọ gbogbo awọn ère isin rẹ̀ nù. Pẹlu ọkan-aya ti o kun fun ifẹ, wọn ń ṣajọpin ohun ti wọn kẹkọọ pẹlu awọn ẹlomiran, titikan awọn ọmọ-ọmọ wọn 25 ati ọmọ ọmọ-ọmọ wọn 4. Ṣaa wo oju wọn, ki o sì rí i bi George ati Lillian ti alayọ tó!
Ọwọ́ Wọn Tẹ Alaafia ati Ayọ
Patrick, ọmọ ilẹ Irish ti o ti lé ni ogoji ọdun, ati iyawo rẹ̀ ti ó jẹ́ Ju, Nina, ni awọn mejeeji ṣí lọ si Hawaii lati gúúsù iwọ-oorun United States. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, wọn ti gbe igbesi-aye ti a fẹnu lasan pe ni ti olominira òògùn lílò, ṣiṣewadii isin, ati ti iwarere alainijaanu. Wọn tun lo ọpọ ọdun pẹlu gẹgẹ bii mẹmba ẹgbẹ awo kan, ni sisakun lati de ipo iwalojufo giga nipasẹ òògùn, ṣiṣaṣaro lọna àṣà isin, ati guru (olukọ) adani wọn. Nigba ti o ṣe Patrick ni a mu nǹkan sú pẹlu ilara, asọ̀, ati aáwọ̀ igba gbogbo laaarin awọn mẹmba ẹgbẹ awo ti wọn ń sọ pe awọn ti nawọ gan ‘ipele ipo iwalojufo giga kan.’ O fi ẹgbẹ naa silẹ ó si pada si Hawaii, nibi ti o ti gbe lẹẹkan ri, ni rireti lati ri alaafia ọkàn. Lẹhin naa, Patrick mu un da Nina, ọrẹbinrin rẹ̀ nigba naa loju, lati ṣebẹwo sọdọ rẹ̀. Nígbẹ̀hìn-gbẹ́hín, wọn ṣegbeyawo wọn si tẹ̀dó si Hawaii.
Patrick ati Nina kò mọ pe iwakiri wọn fun alaafia ati ayọ yoo ṣamọna nígbẹ̀hìn-gbẹ́hín si ikẹkọọ Bibeli pẹlu Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Nina ẹni ti a mọ dunju gẹgẹ bi alaigbọlọrungbọ fun gbogbo igbesi-aye rẹ̀, bẹrẹ si ri awọn idahun Bibeli titẹnilọrun si iru awọn ibeere riruniloju bii idi ti ibi fi wà ati idi ti awọn nǹkan buburu fi ń ṣẹlẹ si awọn eniyan rere. Bakan-naa ni iwakiri ọlọdun mẹwaa ti Patrick ṣe fun otitọ ni abajade alayọ. Laipẹ, ohun ti oun ati Nina ń kẹkọọ lati inu Bibeli bẹrẹ sii yí oju-iwoye wọn nipa iwarere pada. Lẹhin ijakadi alakooko gigun ti o si nira, Patrick ni o ṣeeṣe fun lati bori àṣà baraku ti taba mímu ti o ti wọ̀ ọ́ lẹ́wù ṣinṣin. Fun eyi ti o fẹrẹẹ tó ẹwadun nisinsinyi, oun ati iyawo rẹ̀ ti gbe igbesi-aye mímọ́, igbesi-aye oniwarere ni ibamu pẹlu awọn ọ̀pá-ìdiwọ̀n Ọlọrun. Pẹlu ọkan-àyà funfun ati ẹri-ọkan mimọ, wọn ti ń gbadun alaafia ti wọn ti ń wakiri.
Awọn Irubọ ati Èrè
“Ẹ lakaka lati wọ oju-ọna koto: nitori mo wi fun yin, eniyan pupọ ni yoo wá ọ̀nà ati wọ ọ, wọn ki yoo si lè wọle.” (Luku 13:24) Awọn ọrọ Jesu Kristi wọnni fihàn kedere pe kò rọrun lati sin Ọlọrun ki a si gbé ni ibamu pẹlu ọ̀pá-ìdiwọ̀n Iwe Mimọ. Kìí ṣe pe olukuluku ti ń daniyan lati ṣe bẹẹ gbọdọ sa gbogbo ipa ti a nilo nikan ni ṣugbọn o tun gbọdọ ṣe awọn irubọ ti o pọndandan pẹlu. Eyi ti jẹ bi ọran naa ti ri dajudaju pẹlu awọn ẹnikọọkan ti a mẹnukan ninu akọsilẹ yii. Ṣugbọn ẹ wo bi a ti ṣe san èrè fun wọn lọna yiyanilẹnu tó!
Fun apẹẹrẹ, gbe ọran ti Patrick ati Nina, ti a ṣẹṣẹ mẹnukan tan yii yẹwo. Wọn ṣe iyipada patapata lati inu ọ̀nà igbesi-aye kan ninu eyi ti wọn ti ń ri owó tabua si ọkan ti o jẹ ti iṣẹ-ojiṣẹ Kristian alakooko kikun ti a ń ti lẹhin pẹlu iṣẹ àbọ̀ṣẹ́ nipa ti ara. Sibẹ, awọn ni o daloju pe awọn èrè tẹmi naa fi pupọpupọ tayọ irubọ eyikeyii nipa ti ara ti wọn ti ṣe. Wọn si layọ niti tootọ.
Nitori ọjọ ori wọn, awọn iyipada ni kò ṣe bẹẹ rọrun fun George ati Lillian. Ṣiṣajọpin ninu awọn ipade Kristian ati iṣẹ ojiṣẹ ń beere akoko, afiyesi, ati isapa nipa ti ara. Si idunnu wọn giga julọ, bi o ti wu ki o ri, ilera wọn ti sunwọn sii, a si lè ṣakawe igbesi-aye ti wọn ń gbe nisinsinyi bi ọkan ti o rọ̀ṣọ̀mù, ti o kunrẹrẹ, ti o si jẹ alayọ.
Niti George ati Isabel, ipenija wọn titobi julọ jẹ ti dida awọn ọmọ wọn lẹkọọ ni ríràn wọn lọwọ lati fi ẹsẹ wọn lé oju ọ̀nà iye. Ọpọ akoko ati isapa ni wọn nilo lati mu ki awọn ògowẹẹrẹ mẹrẹẹrin naa wà ni imurasilẹ fun awọn ipade Kristian tabi lati mu wọn lọwọ ninu iṣẹ-ojiṣẹ Kristian. Ni akoko kan ikimọlẹ igba gbogbo naa mú ki George ati Isabel jorẹhin ninu awọn ẹru-iṣẹ wọn gẹgẹ bi obi. Ṣugbọn asọye Bibeli kan ti o ni akori naa: “Sisọ Ẹmi Ifara-ẹni-rubọ Rẹ Dọtun” sun wọn lati tun sọ isapa wọn di onilọọpo meji lati fun awọn ọmọ wọn mẹrẹẹrin ni gbogbo afiyesi ati idanilẹkọọ ti wọn nilo lati ‘tọ́ wọn dàgbà ninu ìbáwí-ẹ̀kọ́ ati ilana-ero-ori Jehofa.’ Laitun ni ṣẹṣẹ sọ eyi, iru isapa bẹẹ ni a ti san èrè jìngbìnnì fun lọna dìdọ́ṣọ́.—Efesu 6:4.
Kìí ṣe ayika adanida rirẹwa, ipo oju-ọjọ bibanilaramu naa, tabi itẹsiwaju ninu igbesi-aye ní gbẹdẹmukẹ ni o mu ayọ tootọ wa fun awọn ẹnikọọkan wọnyi ati ọpọ awọn miiran pẹlu. Kaka bẹẹ, o jẹ imọ naa pe wọn ń lo igbesi-aye wọn ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun ti wọn si ń gbe ni ibamu pẹlu awọn ọ̀pá-ìdiwọ̀n Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Bibeli. (Oniwasu 12:13) Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ayọ tootọ ń ru soke ninu ọkan-aya wọn bi wọn ṣe ń ronu jinlẹ nipa akoko alayọ naa nigba ti a o dá paradise ti ori ilẹ-ayé pada yika gbogbo ayé.—Luku 23:43.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
George, Isabel, ati awọn ọmọ wọn ń rí igbadun ninu kíka Bibeli
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
George ati Lillian rí ayọ ninu iṣẹ-ojiṣẹ Kristian
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
Patrick ati Nina ń gbadun alaafia tootọ ninu iṣẹ-isin Jehofa