Otitọ Rinlẹ̀ Gbingbin ni Abule Olómi Pupọ
ẸWO bi o ti ṣajeji to! Ilẹ kan ti o lokiki fun ọpọlọpọ omi rẹ̀ di eyi ti a rí ti oungbẹ ń gbẹ! Agbegbe ti omi kun fọ́fọ́ di eyi ti a ri ti o gbẹ ti o si dá táútáú! Ó jẹ́ oungbẹ kan ti a lè pa kiki pẹlu omi otitọ lati inu Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, Bibeli. Ìtàn nipa Rahbeh, abule kekere kan ti o ní 2,200 olugbe, ti o mù saaarin oke ńlá níhà ariwa Lebanon, nǹkan bii 80 ibusọ lati Beirut ni.
Orukọ naa Rahbeh tumọsi “ibi ti ààyè wà” ni ede Larubawa, ó sì wá lati inu gbongbo ti awọn Semite ti o tumọsi “gbigbooro, titankalẹ.” Lọna ti o ṣe wẹku, abule naa tẹ́rẹrẹ sori awọn oke gbigbooro meji ni nǹkan bii 2,000 ẹsẹ bata si isalẹ okun. Nigba otutu ati ìgbà ìrúwé, yìnyín ni a le ri lókèréré lori awọn oke naa ni apa ila-oorun, ni fifi ògo ẹwà kun un. Ṣugbọn, ju gbogbo rẹ̀ lọ, Rahbeh jẹ́ abule olómi pupọ. Awọn orisun omi 360, kekere ati ńlá ni o wà, ni agbegbe naa, ni pipese omi oniyebiye fun awọn ilẹ ọlọraa ti oko alikama, awọn eso apricot, pear, peach, ati àjàrà ní awọn afonifoji ti o yii ká.
Awọn Nǹkan Atijọ ati Ti Iwoyi Parapọ si Rahbeh
Ni ọpọlọpọ ọ̀nà awọn nǹkan ni Rahbeh ti wà bi wọn ṣe wà ni awọn akoko ti a kọ Bibeli. Awọn ile ni abule naa funpọmọra pinpin. Awọn opopona rí tooro, lọ́kọlọ̀kọ, wọn si dí jọjọ fun ìrìnlọrìnbọ̀—awọn kẹtẹkẹtẹ ati maluu. Bi o tilẹ jẹ pe awọn ọkọ̀ diẹ wà, awọn ẹranko naa ní ẹ̀tọ́ oju-ọna nihin-in. Ni ọpọ ìgbà awọn olowo wọn yoo di ẹrù lé wọn lori ninu oko wọn yoo si da wọn pada sile funraawọn. Wọn yoo gba awọn opopona tooro naa, ni wíwá ọ̀nà gbà wọnu ati wíwá ọ̀nà bá jade kuro ninu awọn ibi fifunmọra pinpin naa, ti wọn yoo si pada si ile wọn. Eyi ha le jọra pẹlu ohun ti Isaiah ní lọkan nigba ti o sọ pe: “Maluu mọ oluwa rẹ̀, kẹtẹkẹtẹ si mọ ibujẹ oluwa rẹ̀”?—Isaiah 1:3.
Rahbeh tun jẹ ibi ti a ti lè fi awọn iyatọ wera. Nihin-in ni iwọ yoo ti ri awọn agboyejade ni yunifasiti ati awọn àgbẹ̀-arokojẹ ti wọn kò tii dé inú ilu-nla rí. Awọn ile ti a ṣe ọgba yíká wa, awọn abà kekeke si wà pẹlu awọn ẹran-ọsin ti ń sare kiri. Ó fẹrẹẹ jẹ ninu gbogbo ile kọọkan ni a rí awọn ohun eelo oníná, ṣugbọn iná manamana kìí figba gbogbo si fun lilo. Nitori eyi, ọpọlọpọ ile ní ẹrọ amúnáwá. Awọn ọ̀nà pataki abule naa ni a fi kọnnkere ṣe, bi o tilẹ jẹ pe ọpọ awọn oju ọ̀nà ti o lọ si oko ni a kò fi kọnnkere ṣe ti wọn si ri pagunpagun. Nipa bẹẹ, ọ̀nà kanṣoṣo lati gba kó irè oko wale ni nipasẹ awọn ẹranko agbéléjẹ̀. Iwọ tilẹ le rí kẹtẹkẹtẹ ti o ń ru ẹ̀rọ amúnáwá lọ si oko lati pese agbara iná manamana fun awọn ẹ̀rọ oko, eyi ti a ń lò lẹgbẹẹ awọn ẹranko ti ń fa ẹrù ninu oko.
Bakan naa, igbesi-aye ninu abule naa kò tii yipada tobẹẹ ju bẹẹ lọ. Bi iwọ ba sun mọju ninu abule naa, awọn akukọ ti ń kọ ni agogo meji tabi mẹta ni oru le dá oorun mọ́ ọ loju. Ila iṣẹ ojoojumọ maa ń bẹrẹ ni kutukutu, nitori naa maṣe jẹ ki o yà ọ́ lẹnu bi o bá gbọ ariwo awọn eniyan ti ń kigbe pe ara wọn ninu okunkun bi wọn ti ń mura awọn ẹranko wọn silẹ. Ni ìdájí, iwọ le ri ọpọ awọn ara abule, pẹlu awọn ẹranko wọn ti a ti di ẹrù rù, ti wọn forile oko tabi ọja lati ta awọn ọjà wọn.
Bi oju ọjọ naa ti ń mọ́ sii, awọn ọmọdekunrin ati ọmọdebinrin a bọ́ sita lati ṣeré ni awọn opopona ati ita gbangba. Igbe ati ẹrin wọn a gbòdekan, gan-an gẹgẹ bi o ti ri ni Jerusalemu igbaani gẹgẹ bi wolii Sekariah ti ṣapejuwe rẹ̀: “Igboro ilu yoo si kun fun ọmọdekunrin, ati ọmọdebinrin, ti ń ṣere ni ita wọn.” (Sekariah 8:5) Iwọ yoo tun ri awọn ara abule naa gẹgẹ bi ọ̀rẹ́ ati ọlọfin-in-toto. A reti pe ki o kí gbogbo awọn ara abule ti o bá bá pade, bi wọn yoo ti fẹ lati mọ ẹni ti o jẹ́, ibi ti o ti wá, idi ti o fi wà nibẹ, ati ibi ti o ń lọ. Awọn eniyan a maa mọ araawọn daradara gan-an.
Omi Otitọ Dé Rahbeh
Ninu iru awujọ fifunpọ-mọra bẹẹ, irohin maa ń tete tàn kaakiri. Eyi ni ohun ti o ṣẹlẹ nigba ti Asaad Younis pada si Rahbeh lati United States ni 1923. Ni ṣiṣe kayeefi boya Asaad ti di ọlọrọ ni America, ọ̀rẹ́ rẹ̀ Abdallah Blal lọ sọdọ rẹ̀ lati rii. Dipo sisọrọ nipa owó, Asaad fun un ni ẹ̀dà iwe naa Duru Ọlọrun o si sọ fun un pe: “Ọrọ̀ tootọ niyii.” Abdallah, ti o jẹ́ Protestanti kan tẹlẹri, ka itẹjade ti a gbekari Bibeli yii a si wu u lori gidigidi. Bi o tilẹ jẹ pe Asaad kò ṣe ohun gunmọ kan nipa isọfunni naa, a ru imọlara Abdallah soke nipa ohun ti o ti kẹkọọ rẹ̀ o si jẹwọ ni gbangba pe oun ti rí otitọ.
Akoko kan lẹhin naa, Abdallah ṣí lọ si Tripoli, ilu-nla pataki kan ti o wà ni ariwa Lebanon. Nibẹ, o ṣeeṣe fun un lati ri ọpọ awọn Akẹkọọ Bibeli, gẹgẹ bi a ti mọ awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa si nigba yẹn, ti o si tẹsiwaju sii ninu ikẹkọọ Bibeli rẹ̀. Ó pada si Rahbeh nigba ti o yá lati tan ihinrere ti oun ti kẹkọọ rẹ̀ kalẹ. Oun yoo mú awọn ara abule ẹlẹgbẹ rẹ̀ wọnu ijiroro lori awọn koko ẹ̀kọ́ bii Mẹtalọkan, boya eniyan ni ọkàn aileku, iná hell, oyè alufaa, isin Mass, ati lilo awọn ère, ni ṣiṣajọpin ohun ti Bibeli fi kọni niti gidi pẹlu wọn.
Diẹ lara awọn ará abule naa fi ifẹ hàn. Mẹta tabi mẹrin ninu wọn darapọ mọ Abdallah ninu iṣẹ́ iwaasu naa. Lẹhin naa ni wọn bẹrẹ sii ṣe ipade ọjọ Sunday. Eyi ni ninu fifetisilẹ si awiye ti a ti gbà silẹ sinu ẹ̀rọ ikọrin tabi kíkà Bibeli, ti ijiroro awọn ohun ti wọn ṣẹṣẹ gbọ́ tan yoo si tẹle e. Nigba ti o yá, awọn aranṣe fun ikẹkọọ Bibeli ni a lò, titikan awọn iwe Duru Ọlọrun, Ọrọ, ati “Jẹki Ọlọrun Jẹ Olõtọ.” Iye awọn ti ń wá kò kọja mẹwaa ri, ti ọpọ ninu wọn tubọ jẹ́ atọpinpin dipo ki wọn jẹ́ olufifẹhan. Ó jọ pe awọn kan ń wá kiki nitori ounjẹ ti a maa ń pese lẹhin ipade kọọkan.
Ni awọn ọdun 1940, Abdallah Blal ni a fun ni ẹrù-iṣẹ́ ti bibojuto awujọ ti o wà ni Rahbeh. Ó jásí iranṣẹ Jehofa ti o ni itara ti ó sì ń ṣotitọ, ni fifi apẹẹrẹ rere lelẹ fun awọn ẹlomiiran. Ọ̀kan lara awọn wọnyi, Arakunrin Mattar, ranti bi awọn ṣe maa ń ṣe iṣẹ iwaasu wọn: “Niwọn bi awọn ọkọ̀ ayọkẹlẹ kò ti si ni awọn ọjọ wọnni, emi ati Arakunrin Blal ń fi ẹsẹ rin lọ lati jẹrii ni awọn abule ti o wà nitosi. Emi yoo gbé ẹ̀rọ ikọrin naa, nigba ti Arakunrin Blal ń mu ipo iwaju ninu sisọrọ. A sábà maa ń lọ fun ọjọ meji tabi mẹta ṣaaju pipada wálé.” Arakunrin Blal fi tootọ tootọ ṣiṣẹsin Jehofa titi di ọjọ iku rẹ ni 1979 ni ẹni ọdun 98.
Itẹsiwaju Mu Atako Wá
Bi iṣ naa ti ń tẹsiwaju, awọn ará naa bẹrẹ sii niriiri atako. Ni 1950, lati inu isunnasi awọn alufaa abule naa, igbetasi inunibini lodisi awọn ará wa ni a bẹrẹ ni Rahbeh. Awọn alufaa naa fẹsun kan awọn ará naa fun bíba ṣọọṣi jẹ́ ati sisọ awọn ohun mimọ di alaimọ. Awọn ará abule diẹ kun fun ibinu gbigbona tobẹẹ ti wọn fi sọ awọn ará lokuuta, awọn ará diẹ ni a si fi àṣẹ ọba mú ti a si sọ sẹwọn. Bi o ti wu ki o ri, iwadii lẹhin-o-rẹhin fi ẹ̀rí hàn pe awọn ẹsun naa jẹ́ èké. Ani sibẹ, a fi awọn ará naa silẹ ninu ẹwọn fun ọjọ́ melookan.
Alatako miiran gbiyanju lati mú awọn ará abule naa, awọn diẹ ti o ṣeeṣe ki wọn má mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà daradara, fọwọsi iwe kan ti o fi ọpọlọpọ ẹ̀sùn kan awọn ará, ti o ni ninu yiyọ awọn eniyan lẹnu nipa ṣiṣebẹwo si ile wọn laidẹkun. Lati mu ki ọpọlọpọ sii fọwọsi iwe naa, o wi fun wọn pe o jẹ́ ibeere fun oṣiṣẹ kan ti a fẹ lati gbé wa si abule naa. Nigba ti awọn eniyan naa wa mọ pe o jẹ́ ẹ̀sùn kan niti gidi lodisi awọn Ẹlẹ́rìí, wọn fagile ifọwọsi wọn. Iru awọn iṣẹlẹ bi eyi ṣeranwọ lati fun awọn ẹni jankanjankan ni ijẹrii ti o kunna ni agbegbe naa.
Yatọ si kikoju irú atako gbangba gbàǹgbà bẹẹ, awọn ará dojukọ idiwọ miiran. Ni abule kekere kan ti gbogbo eniyan ti mọ araawọn, “ibẹru eniyan nii mu ikẹkun wá,” gẹgẹ bi Bibeli ti ṣalaye ni Owe 29:25. Ó gba igboya fun awọn ará lati waasu fun awọn aladuugbo, awọn ọ̀rẹ́, ati mọlẹbi, ti wọn ń tako wọn nigba gbogbo ti wọn si ń fi wọn ṣẹlẹ́yà. Itumọ gidi ni ọ̀rọ̀ Jesu ní Matteu 10:36 ni pe: “Ara ile eniyan si ni ọ̀tá rẹ̀.” Sibẹ, gẹgẹ bi owe naa ti ń baa lọ lati sọ, “ṣugbọn ẹnikẹni ti o gbẹkẹ rẹ̀ le Oluwa ni a o gbe leke.” Igbagbọ ati ifarada awọn ará ti mú agbayanu iyọrisi jade.
Otitọ Rinlẹ̀ Gbingbin ni Rahbeh
Bi ọdun ti ń gori ọdun awọn ara abule naa ti wa mọriri iwa rere awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, ti ọpọlọpo si ti tẹwọgba otitọ. Ayọ awọn ará kún akunwọsilẹ ni 1969 nigba ti a dá ijọ keji silẹ ni Rahbeh. Wọn ń baa lọ lati ṣiṣẹ kára. Ọpọlọpọ tẹwọgba iṣẹ-ojiṣẹ alakooko kikun, awọn kan tilẹ ṣí lọ lati ṣiṣẹsin ni awọn ipinlẹ miiran, titikan ilu-nla Beirut. Jehofa bukun iṣẹ́ aṣekara wọn, a si dá ìjọ kẹta silẹ ni Rahbeh ni 1983. Lakooko yii, pupọ awọn ará ṣí lọ lati gbé ni awọn ilu-nla. Sibẹ, idagbasoke naa ń baa lọ, a si dá ijọ kẹrin silẹ ni Rahbeh ni 1989, ti ikarun-un si tẹle e ni 1990.
Ni akoko yii, o fẹrẹẹ jẹ pe gbogbo idile ni abule yẹn ni o ni mọlẹbi tabi ọ̀rẹ́ ti o ti jẹ́ Ẹlẹ́rìí. Ẹtanu ti o ti figbakan wà rí ti lọ silẹ. Awọn eniyan wa dojulumọ awọn Ẹlẹ́rìí naa daradara sii. Nitootọ, awọn gbolohun ọ̀rọ̀ naa, “alagba,” “aṣaaju-ọna,” “alaboojuto ayika,” “apejọ,” ati “Armageddoni” ti di apakan èdè isọrọ awọn ara abule naa. Ni awọn akoko iṣẹlẹ pataki, bii ti ibẹwo alaboojuto ayika tabi Iṣe-iranti, awọn opopona yoo dá páro ti awọn Gbọngan Ijọba yoo si kun fọfọ. Awọn ijọ kan tilẹ maa ń gbé gbohungbohun si ẹhinkule fun irọrun awọn aladuugbo.
Ni lọwọlọwọ bayii iye ti o ju 250 awọn akede Ijọba lọ ni wọn wà ni Rahbeh. Iyẹn tumọsi pe Ẹlẹ́rìí kanṣoṣo ni ó wà fun nǹkan bii ẹni mẹjọ ni abule naa! Ijọ kan ti o ni 51 akede ni ipinlẹ ti o ni ile 76, wọn si ń kari rẹ̀ lọṣọọsẹ. Ronuwoye ohun ti o ṣẹlẹ ni oṣu March ati April ọdun ti o kọja nigba ti 98 lara 250 awọn akede naa gba iṣẹ́ aṣaaju-ọna oluranlọwọ, papọ pẹlu awọn aṣaaju-ọna deedee 13 ti ń bẹ ni Rahbeh. Ipinlẹ naa ni a kari ni ọpọ ìgbà lọsọọsẹ. Kìí ṣe ohun ti kò wọ́pọ̀ fun akede meji tabi mẹta pẹlu awọn alabaaṣiṣẹ wọn lati ṣebẹwo si ile kan-naa ni ọjọ kan-naa tabi ni akoko kan-naa paapaa. Ibẹwo naa ti wa mọ́ ọpọ julọ awọn ará abule naa lara. Ṣugbọn nigba ti ọkunrin kan ṣaroye, akede kan fesipada pe: “Nigba ti iwọ ba tẹwọgba ifilọni wa lati ṣe ikẹkọọ Bibeli, nigba naa a o maa bẹ ọ wò lẹẹkan lọsẹ.” Wọn tun ń ba olukuluku ẹni ti wọn bá bá pade ni oko sọrọ—awọn eniyan ti ń túlẹ̀, gbin irè, bomirin, tabi gun kẹtẹkẹtẹ.
Ni tootọ, otitọ Bibeli ti rinlẹ̀ gbingbin ni Rahbeh, abule olómi pupọ. Kìí ṣe iyẹn nikan. Gan-an gẹgẹ bi Rahbeh ti jẹ́ orisun omi atunilara fun ọpọ awọn abule ti o wà ni ayika, ó tun ti pese omi afunni-ni-iye ti otitọ Bibeli fun wọn. Awọn akede lati Rahbeh a maa ṣebẹwo si ọ̀dọ̀ awọn eniyan ni awọn abule ti o wa nitosi ni fifi ẹsẹ rin ti wọn yoo si ṣeto ọkọ̀-ayọ́kẹ́lẹ́ fun awọn awujọ ti wọn yoo si rinrin-ajo ni ojúmọmọ lati waasu ni awọn abule jijinna réré. Awọn akede diẹ ṣílọ lati ṣiṣẹsin ni awọn ilu-nla miiran. Pẹlu ibukun Jehofa, ibisi siwaju sii yoo wà ti yoo ṣì mu ọpọ iyin sii wa fun Baba ọrun, Jehofa Ọlọrun.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Irisi opopona kan ni Rahbeh