ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 11/1 ojú ìwé 23-26
  • Ẹ Wo Ohun Tí Jehofa Ti Ṣe fun Wa!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ Wo Ohun Tí Jehofa Ti Ṣe fun Wa!
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ìsọ̀rí
  • Ominira Pupọ sii ni Iwọ-oorun ati Aarin Gbungbun Africa
  • A Tẹwọgba Á Lọna Ofin ni Ìhà Guusu Africa
  • Awọn Ọ̀dọ́ Nipin-in Ninu Jijẹrii
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 11/1 ojú ìwé 23-26

Ẹ Wo Ohun Tí Jehofa Ti Ṣe fun Wa!

“ASÁBÀ maa ń gbadura fun iru akoko bẹẹ,” ni ọkunrin kan sọ. Omiran maa ń jí ni deedee agogo mẹrin òwúrọ̀ lati gbadura. Fun ki ni? “Lati gbadura pe ni ọjọ kan ṣáá a o ní ominira lati jọsin Jehofa ni gbangba,” ni ó sọ. Ni January 1992, nigba ti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni Ethiopia pade papọ ni Addis Ababa fun Apejọpọ Agbegbe “Awọn Olùfẹ́ Ominira” wọn, ó ṣe kedere pe awọn adura onirẹlẹ, olotiitọ-inu yii ni a ti dahun.

Apejọpọ ti Ethiopia yẹn jẹ́ itọka kan nipa bi nǹkan ti ń yipada ni Africa. Ni awọn ọdun ẹnu aipẹ yii awọn eniyan Jehofa ni awọn ilẹ 13 nibẹ ti layọ lati rí ominira ti ofin gbà nibi ti a ti fofinde tabi ká wọn lọ́wọ́kò tẹlẹri. Ni Ethiopia, ìfòfindè ọlọdun 34 ti a faṣẹ si dopin ni November 11, 1991, nigba ti awọn ijoye oṣiṣẹ ijọba yọọda ìdámọ̀ tí ìtún orukọ fi silẹ sì wáyé. Lọ́gán, awọn Ẹlẹ́rìí naa ṣe awọn ètò lati ṣe apejọpọ kan jakejado awọn orilẹ-ede. Sibẹ, lati ri ogunlọgọ ti 7,573 eniyan ti wọn korajọ ni Gbọngan-iṣere Ilu Addis Ababa kọja ironuwoye ti gbogbo eniyan kúndùn julọ. Fun ọpọ julọ awọn wọnni ti wọn wá, ń ṣe ni ó dabii pe wọn ń lálàá. Leralera wọn ń sọ fun ẹnikinni keji pe: “Arakunrin, wo ohun ti Jehofa Ọlọrun wa ti ṣe fun wa!”—Fiwe Orin Dafidi 66:1-5; 126:1.

Wíwà ti wọn wà labẹ ìfòfindè fun ọdun 34 dá awọn iṣoro diẹ ti a kò reti silẹ. Ọpọ julọ ni kò mọ awọn orin Ijọba didunyungba. Bawo ni wọn yoo ṣe kọ́ bi a tií kọ wọn ṣaaju apejọpọ naa? Ogoji orin, papọ pẹlu 17 ti a lò ninu itolẹsẹẹsẹ apejọpọ naa, ni a tumọ si èdè Amharic. Nigba naa, ẹgbẹ́ akọrin kan ni a ṣetojọ lati gba awọn orin naa silẹ lori ẹ̀rọ kasẹẹti. Ijọ kọọkan ni olu-ilu naa gba ẹ̀dà kan teepu naa, gbogbo ijọ yoo sì lo 30 iṣẹju ṣaaju ati lẹhin awọn ipade lati ṣe idanrawo awọn orin naa. Ki ni iyọrisi rẹ̀? Gbọngan-iṣere naa kún fun orin àfitọkàntọkànkọ ati alayọ nigba apejọpọ naa.

Nitori awọn idilọwọ ni apá ila-oorun orilẹ-ede naa, oju-ọna ti ó lọ si olu-ilu naa lati Diredawa ati Harar ni a sépa. Kìkì ọ̀nà ìgbà rinrin-ajo lati ibẹ̀ ni nipasẹ ọkọ̀-òfuurufú. Bi wọn kò ti lè san owó ọkọ̀-òfuurufú, ṣugbọn ti wọn pinnu lati wà ni apejọpọ naa, awọn arakunrin mẹjọ ni Harar lọ sí ọgangan-ìdarí ologun wọn sì beere fun wíwọ ọkọ̀-òfuurufú ologun kọja. Si iyalẹnu wọn ohun ti wọn beere fun naa ni a fọwọsi. A pese irin-ajo ọ̀fẹ́ fun wọn lọ si apejọpọ naa!

Lati rí i ti a dahun adura wọn mú omije ayọ wá si oju awọn arakunrin ni Ethiopia wọnyi, awọn ẹni ti wọn ti farada inira ati inunibini fun ẹwadun mẹta ti ó ti kọja àní ti wọn tilẹ fojuri pipa awọn ọ̀rẹ́ wọn nitori igbagbọ wọn. Àyànṣaṣojú kan sọ pe: “Lati ibẹrẹ apejọpọ naa ni mo ti ń sunkún.” Omiran wi pe: “Bi o bá ni agbara-iṣe lati mọ ọkàn ni, iwọ yoo rí i bi inu mi ti dùn tó.” Bẹẹni, ẹ wo iru ohun agbayanu ti Jehofa ti ṣe fun awọn Ẹlẹ́rìí oluṣotitọ wọnyi!—Orin Dafidi 66:16, 19.

Ominira Pupọ sii ni Iwọ-oorun ati Aarin Gbungbun Africa

Benin jẹ́ ilẹ miiran ti a ti tẹwọgba iṣẹ awọn eniyan Jehofa lọna ofin lẹnu aipẹ yii. Ki ni imọlara awọn Ẹlẹ́rìí naa nipa rẹ̀? Olubanisọrọ ni ikorajọ Kristian kan nibẹ jẹwọ pe: “Ominira ijọsin ni orilẹ-ede yii jẹ́ ẹbun lati ọ̀dọ̀ Jehofa nitootọ.” Bẹẹni, awọn iranṣẹ Jehofa nibẹ kún fun imoore lọna jijinlẹ pe nisinsinyi awọn lè gbadun ominira ti a kò kálọ́wọ́kò lati pade papọ ninu ijọsin ki wọn sì sọrọ nipa Ijọba Jehofa fun awọn aladuugbo wọn—ominira ti ọpọ julọ ninu wa foju lasan wò.

Bawo ni wọn yoo ṣe fi ayọ wọn hàn? Olubanisọrọ ti a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ loke yii tọka si ọ̀nà kan nigba ti ó wi pe: “Ṣiṣajọpin wa ninu iṣẹ iwaasu—ni pataki lilọ wa lati ile de ile pẹlu ihinrere—fi imọriri wa fun isọdominira yii hàn.” Dajudaju bi ọ̀ràn ti rí ni Benin niyẹn. Gẹgẹ bi ẹ̀rí, iwọ wulẹ wo iye awọn aṣaaju-ọna ti a ni. Ni January 1990, ni ọdun ti a mu ifofinde ọlọdun 14 naa kuro, akede 77 ni ọwọ́ wọn dí ninu iṣẹ-isin alakooko kikun. Ni ọdun meji lẹhin naa nọmba yẹn ti ju ilọpo mẹta lọ, ó ti dé 244!

Eyi kò tumọ si pe awọn Ẹlẹ́rìí ni Benin kìí ṣe onitara ṣaaju ki a tó mú ìfòfindè naa kuro. Nitootọ, ifarada wọn ní ipa jijinlẹ lori oṣiṣẹ ologun kan ti a yàn si àgọ́ kan nibi ti a mú wọn wá nigba ti a faṣẹ-ọba mú wọn. Niwọn bi ipinnu wọn lati ṣiṣẹsin Jehofa ti ṣamọna si ifaṣẹ-ọba muni lemọlemọ, ó ń bá araarẹ̀ ni pàdéǹpàdé pẹlu wọn lemọlemọ. Ṣugbọn eyi wulẹ ń ṣiṣẹ lati rán an leti nipa awọn ijiroro Bibeli gbigbadunmọni ti ó ti ní pẹlu wọn ni awọn ọjọ iṣaaju nigba ti wọn ti gbadun ominira ni.

Nikẹhin, igbagbọ wọn lilagbara mú imọlara ebi tẹmi sọji ninu rẹ̀. Ó ṣebẹwo si oniruuru ṣọọṣi ati ẹ̀ya isin ṣugbọn kò rí itẹlọrun fun ebi yẹn lae. Kìkì lẹhin ti a mú ìfòfindè naa kuro ni January 1990 ni ó tó lè jiroro Bibeli falala pẹlu awọn Ẹlẹ́rìí ti ó sì rí idahun si awọn aini tẹmi rẹ̀. A ti baptisi rẹ̀ nisinsinyi ó sì ń ṣiṣẹsin gẹgẹ bi aṣaaju-ọna. Ni èrò itumọ kan, iyipada rẹ̀ rán awọn ará ni Benin leti ohun ti ó ṣẹlẹ si Saulu ará Tarsu: “Ẹni ti o ti ń ṣe inunibini si wa rí, sì ń waasu igbagbọ naa nisinsinyi.”—Galatia 1:23.

Ni December 1991, awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni orilẹ-ede Iwọ-oorun Africa miiran, Niger, ni a forukọ wọn silẹ gẹgẹ bi ajọ ti ó bá ofin mu, ti ìkálọ́wọ́kò lori iṣẹ wọn sì di eyi ti ó dopin. Nihin-in pẹlu ihuwapada alayọ wà. Ẹ̀ka ni Nigeria, ti ń bojuto Niger, rohin idahunpada ni apejọpọ kan. “Lẹhin kókó-ọ̀rọ̀-àwíyé ni apejọpọ ti ó wáyé ni Maradi ni ọjọ Friday, a kede rẹ̀ fun awọn ará pe a ti ní ìdámọ̀ lọna ofin ni Niger nisinsinyi. Ara wọn yá gágá gan-an wọn sì pàtẹ́wọ́ fun ọpọlọpọ iṣẹju. Ni ipari akoko ijokoo naa, awọn ará fi imọlara wọn hàn, ní rírọ̀ mọ́ ẹnikinni keji lọrun ti wọn sì ń yọ̀ nitori iru irohin rere bẹẹ.” A lè finuwoye iru ìran bẹẹ, a sì bá wọn yọ̀.

Bawo ni awọn ará nibẹ yoo ṣe lo ominira wọn ti wọn ṣẹṣẹ rí yii? Arabinrin aṣaaju-ọna kan ni Niger kò ṣiyemeji niti ohun ti idahun si ibeere yẹn jẹ́. Ó kọwe pe: “Awọn otitọ fihàn pe ni ipinlẹ wa ni Niger, awọn wọnni ti wọn yoo jade wá lati inu Babiloni Ńlá ṣaaju ki opin tó dé kò lóǹkà. Gẹgẹ bi ẹ̀rí si eyi, ó ti ṣeeṣe fun mi lati rohin ipadabẹwo lati ori 80 si 85 loṣooṣu ti mo sì ń dari awọn ikẹkọọ Bibeli 13 tabi 14, laika otitọ naa si pe mo ti fa ọpọlọpọ awọn ti mo ń bẹwo lé awọn akede miiran lọwọ.” Arabinrin oluṣotitọ yii fikun un pe: “Nitori iṣoro ilera mi, emi kò lè ṣe pupọ tó bi emi yoo ti fẹ́ lati ṣe ninu iṣẹ-isin pápá, ṣugbọn olukuluku ń ṣe ohun ti ó lè ṣe.”

Ni Rwanda ni Aarin Gbungbun Africa, ipo awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tun ti yipada lọna ti ń múnijígìrì. Ni April 1992 iwe-aṣẹ kan ni a kọ jade pẹlu itumọ pe wọn di eto-ajọ ti ó bófinmu nígbẹ̀hìn-gbẹ́hín. Iwe-aṣẹ naa ni a gbà ni ọsẹ kan-naa ti a ṣe Iṣe-iranti, ti awọn akede 1,526 ni Rwanda sì ní idunnu lati rí 6,228 ti wọn wá sibi iṣẹlẹ yẹn. Awọn arakunrin ọ̀wọ́n wọnyi yoo ha fi ayọ ati imọriri wọn hàn nipa igbokegbodo pupọ sii ninu pipolongo ihinrere bi? Dajudaju! Ni oṣu April kan-naa, awọn akede ijọ ní ipindọgba wakati 27.7 ninu iṣẹ iwaasu ati ipadabẹwo 17, ni didari ipindọgba ikẹkọọ Bibeli 2.4. Nǹkan bii ipin 40 ninu ọgọrun-un ninu wọn sì wà ninu iru iṣẹ-isin alakooko kikun kan.

A Tẹwọgba Á Lọna Ofin ni Ìhà Guusu Africa

Nisalẹ ni ìhà guusu Africa, afẹ́fẹ́ tútù ti ominira fẹ́ la ilẹ meremere meji, Mozambique ati Angola kọja. Ni Mozambique itẹwọgba lọna ofin ni a yọọda ni February 1991. Bi ipo ọ̀ràn naa ti ń dẹrun nibẹ, Watch Tower Bible and Tract Society rán awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun lọ sinu orilẹ-ede naa, eyi ti ogun abẹ́lé ti bajẹ lọna biburujai. Awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun naa rí ilẹ ọlọ́ràá. Iwe ikẹkọọ Bibeli—ni pataki iwe naa Questions Young People Ask—Answers That Work—ni wọn ń beere fun lọpọlọpọ. Ojihin-iṣẹ-Ọlọrun kan rohin fifi iwe 50 sode ni ohun ti ó din si wakati meji ati aabọ.

Awọn olufifẹhan ń dahunpada ní kiamọsa. Ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ṣebẹwo si adirẹsi kan ti a ti fifun Society, ó sì wá di ti ọkunrin kan ninu iṣẹ ologun. Ijiroro rere ni a ṣe pẹlu ọkunrin naa funraarẹ ati meji ninu awọn ibatan rẹ̀. Nigba ipadabẹwo kan, ijiroro amesojade miiran ni a tun ṣe pẹlu ọkunrin naa ati awọn marun-un miiran. Nigba naa wọn tẹwọgba ikesini lati wá si ibi ọ̀rọ̀-àsọyé fun gbogbo eniyan ati Ikẹkọọ Ilé-Ìṣọ́nà—gbogbo rẹ̀ laaarin ọjọ mẹrin.

Ni Angola awọn Ẹlẹ́rìí ti gbadun ominira tí ń pọ sii eyi ti o dé otente rẹ̀ nigba ti a tẹwọgba iṣẹ wọn lọna ofin ni April 1992. Bawo ni wọn ṣe ń lo ominira pupọ sii ti wọn ni? Wọn ń ṣajọpin ninu iṣẹ-isin pápá! Nǹkan bii 17,000 akede ni ó wà ni Angola, awọn akede wọnni sì ń dari iye ti o fẹrẹẹ tó 60,000 ikẹkọọ Bibeli. Ẹ wo iru ireti fun ibisi ọjọ-ọla ti eyi jẹ́!

Awọn Ọ̀dọ́ Nipin-in Ninu Jijẹrii

Ni awọn orilẹ-ede wọnyi nibi ti a ti tẹwọgba iṣẹ iwaasu lọna ofin lẹnu aipẹ yii, àní awọn ọ̀dọ́ ati awọn ti wọn kò tíì ṣe iribọmi paapaa ń fi imọriri wọn hàn nipa igbokegbodo ninu iṣẹ-ojiṣẹ. Ni Cape Verde Republic, nibi ti a ti tẹwọgba awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lọna ofin ni November 1990, ni apejọpọ kan ọdọmọbinrin ọlọdun 17 kan dide duro lati ṣe ìjẹ́wọ́ igbagbọ ni gbangba. Lẹhin iribọmi, olubẹwo kan rí ọpọlọpọ èrò ti ó rọ̀gbà yí i ká. Ó lọ bá a yọ̀ ó sì beere awọn ti ọpọlọpọ èrò naa jẹ́. “Óò,” ni ó fèsì pada, “awọn wọnyi ni awọn akẹkọọ Bibeli mi.” Ó ń dari ikẹkọọ meje, wọn sì wà nibẹ lati bá a yọ̀ nigba iribọmi rẹ̀. Ó ti fi iwe iwọṣẹ silẹ lati sin gẹgẹ bii aṣaaju-ọna oluranlọwọ kan ó sì ń wo iwaju lẹhin-ọ-rẹhin lati tootun gẹgẹ bi aṣaaju-ọna deedee.

Ọdọmọbinrin ọlọdun mẹwaa kan ni Angola ni a beere lọwọ rẹ̀ bi ó bá jẹ́ akede. Ó dahun pe: “Bẹẹni.” Iwọ ha ń dari ikẹkọọ Bibeli kankan bi? “Dajudaju.” Melo ni wọn? “Meje,” ni ọmọ ọlọdun mẹwaa yii dahunpada.

A kà ninu iwe Iṣe pe ni ori kókó kan ni ọrundun kìn-ín-ní, “ijọ wà ni alaafia yi gbogbo Judea ká, ati ni Galili ati ni Samaria, wọn ń fẹsẹmulẹ; wọn ń rin ni ibẹru Oluwa, ati ni itunu ẹmi mimọ, wọn ń pọ̀ sii.” (Iṣe 9:31) A gbadura pe fun awọn arakunrin wa ni Africa, abajade eyi yoo jẹ́ akoko alaafia. A bá wọn yọ̀ niwọn bi a ti gbé wọn ró, a sì gbadura pe ki ẹmi Jehofa lè wà lori wọn bi wọn ti ń lo anfaani ominira wọn lati tan ihinrere kalẹ ki wọn sì maa pọ sii.

[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 24]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

Awọn Ilẹ Nibi Ti A Ti Tẹ́wọ́gbà Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa Lọna Ofin Tabi Mu Ìkálọwọ́kò Kuro Lori Iṣẹ Wọn

1. The Gambia, December 1989

2. Benin, January 1990

3. Cape Verde Republic,  November 1990

4. Mozambique, February 1991

5. Ghana, November 1991

6. Ethiopia, November 1991

7. Congo, November 1991

8. Niger, December 1991

9. Togo, December 1991

10. Chad, January 1992

11. Kenya, March 1992

12. Angola, April 1992

13. Rwanda, April 1992

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Ni Benin akede Ijọba kan fi ìlù gángan rẹ̀ sọ awọn ọ̀rọ̀ inu Matteu 24:14 jade

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Ni ọpọlọpọ ilẹ Africa awọn Kristian tootọ ń lo ominira wọn titun ti wọn ṣẹṣẹ rí lọna rere

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Awọn Ẹlẹ́rìí titun fẹ̀rí iyasimimọ wọn hàn si Jehofa nipa baptism ninu omi

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́