Ilé-ẹjọ́ Giga Julọ ni Nigeria Ṣetilẹhin fun Ominira Isin
AWỌN ará abule jí irè-oko àgbẹ̀ kan. Awọn miiran sì ya wọnú ile bíríkìlà kan wọn sì fipa gba awọn irinṣẹ rẹ̀. Sibẹ awọn miiran dena obinrin kan lati maṣe lọwọ ninu káràkátà. Eredi awọn iwakiwa yii? O jẹ nitori tí awọn ojiya wọnyi, ti gbogbo wọn jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jehofa, ki yoo darapọ mọ ẹgbẹ́ ojúgbà. ‘Mọ́ kí ni?’ ni ó lè ṣe ọ́ ní kayefi.
Ẹgbẹ́ ojúgbà ní awọn eniyan, ti wọn sábà maa ń jẹ ọkunrin ninu, ti a bí ni nǹkan bii akoko kan-naa ati ni abule kan-naa. Awọn ẹgbẹ́ ojúgbà ni wọn wọ́pọ̀ ni ila-oorun Nigeria. Wọn le ṣe onigbọwọ iṣẹ́ ilu, ṣugbọn wọn tun ń lọwọ ninu ijọsin ibọriṣa ti wọn sì ń ṣe awọn ààtò ibẹmiilo lati fihàn pe awọn ọmọ ẹgbẹ́ rẹ̀ ti de ipo àgbà. Nitori pe Bibeli fagile iru awọn aṣa bẹẹ fun awọn Kristian tootọ, awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kìí nipin-in ninu iru awọn ẹgbẹ́ bẹẹ.—1 Korinti 10:20, 21; 1 Johannu 5:21.
Samuel Okogbue ń ṣiṣẹ bii aranṣọ ni Aba, Nigeria. Ni ibẹrẹ 1978, awọn mẹmba Ẹgbẹ́ Ojúgbà ti Umunkalu ni Alayi beere pe ki o san “owo-abufunni” lati fi ṣeranwọ fun kikọ ibudo ilera kan. Gẹgẹ bii Kristian tootọ kan, Samuel a maa sa gbogbo ipa rẹ̀ lati ran awọn ẹlomiran lọwọ, ṣugbọn pẹlu igbatẹri-ọkan rò o kọ̀ lati ni nǹkan ṣe pẹlu ẹgbẹ́ ojúgbà naa. Ni April 22 ọdun yẹn, mẹfa ninu mẹmba ẹgbẹ́ naa jáwọ́ ṣọọbu rẹ̀ wọn sì fipa gbe maṣíìnì iranṣọ rẹ̀, eyi ti wọn sọ pe wọn yoo gbe pamọ titi di ìgbà ti o bá san owo naa. Samuel fẹ̀hónú hàn pe oun kò si labẹ aigbọdọmaṣe lati san ohunkohun niwọn bi oun kìí tii ṣe mẹmba ẹgbẹ́ wọn. Nigba ti kò le gba maṣíìnì iranṣọ rẹ̀ pada, Samuel gbe ọ̀ràn naa lọ si ile-ẹjọ.
Lati Ilé-ẹjọ́ de Ilé-ẹjọ́
Ni Ile-ẹjọ Majisireti Àgbà, ẹgbẹ́ ojúgbà yii ṣalaye pe nitori ọjọ ori rẹ̀, láìdéènà-pẹnu Samuel ti di ọ̀kan ninu mẹmba wọn, ti o ní ẹrù-iṣẹ́ lati san owo-abufunni eyikeyii ti wọn bá bù le araawọn lori. Siwaju sii, aṣa-iṣẹdalẹ si sọ pe bi mẹmba kan kò bá san owo-abufunni kan, dúkìá rẹ̀ ni a o fipa gbà titi di ìgbà ti yoo fi ṣe bẹẹ.
Ile-ẹjọ naa kò faramọ́-ọn. Ni February 28, 1980, o ṣedajọ pe a kò lè fipa mú Samuel lati di mẹmba ẹgbẹ́ ojúgbà. Majisireti Àgbà naa sọ pe: “Aṣa-iṣẹdalẹ kan ti o ba du araalu kan ni ominira yiyan ẹgbẹ́ ti o bá fẹ tako A[pa] 37 ninu Akojọ-ofin ti Ijọba Apapọ Ilẹ Nigeria ti eyi nigba naa kò si lè ri itilẹhin agbara Ofin.”
Ẹgbẹ́ ojúgbà naa pe ẹjọ kotẹmilọrun lori idajọ yii si Ile-ẹjọ Giga wọn si bori. Nibẹ ni adajọ ti paṣẹ pe ki Samuel san owo-abufunni naa, ni sisọ pe o wulẹ jẹ ọ̀nà lati ṣetilẹhin fun idagbasoke awọn eniyan ti wọn jẹ́ ara ilu rẹ̀ ni.
Lẹhin naa Samuel pe ẹjọ kotẹmilọrun lori ohun ti o ri bii aiṣedajọ-ododo. Ile-ẹjọ Kọtẹmilọrun yí idajọ Ile-ẹjọ Giga pada, o sì ṣedajọ gbe Samuel lẹhin. Nitori ti wọn kò muratan lati gba ìfìdírẹmi, ẹgbẹ́ ojúgbà naa gbé ọ̀ràn naa lọ si Ile-ẹjọ Giga Julọ ti ilẹ Nigeria.
Laaarin akoko yii, awọn mẹmba ẹgbẹ́ naa ni wọn ti ń ṣiṣẹ kára ni abule Samuel. Wọn ń ṣalaye pe awọn Ẹlẹ́rìí ni wọn lodisi gbogbo awọn iṣẹ idawọle ilu, wọn yí baalẹ abule naa leropada lati fofinde igbokegbodo awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni agbegbe naa. Alagogo-ọba kede pe ẹnikẹni ti o ba ni ajọṣepọ pẹlu awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni a o bu owo-itanran le. Awọn Ẹlẹ́rìí lati awọn ilu ti o wà laduugbo dásí ọ̀ràn naa wọn sì fi ọ̀ràn yé awọn àgbà abule naa yekeyeke. Wọn ṣalaye pe awọn eniyan Ọlọrun ni kò tako idagbasoke ilu lọna kankan. Niti gidi, Samuel ti pese awọn iwe-ẹri isanwo ni ile-ẹjọ lati ṣẹri pe oun ti ṣetilẹhin fun awọn iṣẹ idawọle ilu ti kìí ṣe awọn ẹgbẹ́ ojúgbà yii ni wọn ṣonígbọ̀wọ́ rẹ̀. Awọn àgbà abule naa wa ṣe iyipada ipinnu wọn lati ta awọn Ẹlẹ́rìí naa nù lawujọ.
Ominira Isin Lékè
Ni October 21, 1991, awọn adajọ marun-un ni Ile-ẹjọ Giga Julọ ni Ilẹ Nigeria fohunṣọkan lati ṣedajọ gbe Samuel lẹhin. Ni ṣiṣalaye siwaju sii lori idajọ awọn ti o pọ julọ eyi ti Adajọ Paul Nwokedi gbẹnusọ fun, Adajọ Abubakar Wali sọ pe: “Kìí ṣe owó-àbùlé [owo-abufunni ti a faṣẹ gbekanilori] naa ni olùjẹ́jọ́ [Samuel] ń tako lati san bikoṣe jijẹ mẹmba kan ninu ẹgbẹ́, ọrẹdẹgbẹ tabi ẹgbẹ́ ojúgbà eyikeyii, niwọn bi eyi ti lodisi igbagbọ isin rẹ̀, nitori ti oun jẹ́ ọ̀kan lara [awọn] Ẹlẹ́rìí Jehofa.”
Adajọ naa ń baa lọ pe: “Akojọ-ofin ti 1963, apa 24(1) fi dá gbogbo ọmọ ilẹ Nigeria loju pe wọn ni ominira lilo ẹri-ọkan, ironu, ati isin. Olùjẹ́jọ́ naa ni ẹ̀tọ́ lati dirọ mọ igbagbọ isin rẹ̀, ironu ati ẹri-ọkan ti o kaaleewọ fun-un lati darapọ mọ ẹgbẹ́ Ojúgbà naa. De iwọn ti aṣa-iṣẹdalẹ eyikeyii bá fi gbé ohun ti o yatọ si eyi kanilori ni o fi tako Akojọ-ofin ti o sì tipa bẹẹ dalailagbara labẹ ofin.”
Ni kukuru, ile-ẹjọ naa dajọ pe kò sí ẹnikẹni ti a lè fi agbara mu labẹ ofin lati darapọ mọ ẹgbẹ ojúgbà kan bi o tilẹ jẹ pe didi ọmọ ẹgbẹ lè jẹ aṣa-iṣẹdalẹ ilu kan. O tun ṣedajọ pe kò si ẹnikẹni ti a lè fagbara mú labẹ ofin lati san owo nipasẹ ẹgbẹ́ kan ti ẹni naa kìí ṣe mẹmba rẹ̀, koda nigba ti owo naa bá wà fun idagbasoke ilu. Nitori naa ninu ohun ti o dabi iṣẹlẹ kekere yii, ominira isin fun gbogbo ọmọ ilẹ Nigeria ni a ṣetilẹhin fun.