Iwọ Ha Dabi Ọ̀kan Ninu awọn Wọnyi Bi?
‘ÓSÀN ju lati jẹ́ kinniun fun ọjọ kan ju lati jẹ ọdọ-agutan kan fun ọgọrun-un ọdun lọ.’ Awọn ọ̀rọ̀ wọnni ni a ti a kà sí ti Benito Mussolini, oluṣakoso boofẹ-bookọ Italy nigbakanri.
Gẹgẹ bii Mussolini ọpọlọpọ eniyan yoo kọ̀ lati jẹ́ ki a kà wọn si ọdọ-agutan ati agutan. Bi o ti wu ki o ri, ọba ati olorin Israeli igbaani Dafidi kede pe: “Oluwa ni oluṣọ agutan mi: . . . O mu mi lọ si ìhà omi didakẹ rọ́rọ́.” (Orin Dafidi 23:1, 2) Bẹẹni, Jehofa Ọlọrun jẹ́ Oluṣọ-agutan Ńlá kan, ẹni ti ń fun awọn eniyan rẹ̀ ni itọju onijẹlẹnkẹ bi ẹni pe wọn jẹ agutan ti kò lè panilara.
Awọn eniyan Ọlọrun ni a sọrọ wọn lọna iṣapẹẹrẹ gẹgẹ bi agutan ninu Orin Dafidi 95:7, nibi ti a ti kà pe: “Nitori [Jehofa] ni Ọlọrun wa; awa sì ni eniyan pápá rẹ̀, ati agutan ọwọ́ rẹ̀.” Awọn miiran ti lè reti pe ki olorin naa sọrọ nipa “agutan pápá rẹ̀” ati “eniyan ọwọ́ rẹ̀.” Ṣugbọn nihin-in yii ipo ọ̀ràn ni a yipada, awọn eniyan Jehofa funraawọn ni a sì wá mọ̀ yàtọ̀ gẹgẹ bi agutan rẹ̀. Wọn ń gbadun awọn anfaani papa-oko tútù Ọlọrun a si ń ṣamọna wọn nipasẹ ọwọ́ onifẹẹ rẹ̀.
Ọmọkunrin Jehofa, Jesu Kristi, jẹ́ Oluṣọ-agutan Rere. O sábà maa ń tọka si awọn eniyan gẹgẹ bi agutan. Fun apẹẹrẹ, Jesu sọrọ nipa “agbo kekere” kan ati nipa “awọn agutan miiran” rẹ̀. (Luku 12:32; Johannu 10:14-16) Niti awọn ọmọlẹhin rẹ̀ onirẹlẹ ẹni-bi-agutan, Jesu sọ pe: “Awọn agutan mi ń gbọ ohùn mi, emi sì mọ̀ wọn, wọn a si maa tọ̀ mi lẹhin: emi sì fun wọn ni ìyè ainipẹkun; wọn ki ó sì ṣegbe laelae, kò sì sí ẹni ti ó lè já wọn kuro ni ọwọ́ mi.” (Johannu 10:27, 28) Ni ọwọ́ oluṣakoso aṣenilanfaani kan, awọn ọmọ-abẹ ń janfaani lati inu agbara, ojurere, itọsọna, ati aabo rẹ̀.—Ìfihàn 1:16, 20; 2:1.
Kò si ẹni ti ó le já awọn eniyan bi agutan nitootọ gbà kuro lọwọ adaaboboni Jesu. Lonii, oun ń ya awọn eniyan sọtọ yala gẹgẹ bi “ewurẹ” ti wọn ṣaini ojurere rẹ̀ tabi gẹgẹ bi “agutan” ti wọn yoo gbadun ìyè ayeraye labẹ iṣakoso Ijọba ọrun ti Ọlọrun. (Matteu 25:31-46) Iwọ yoo ha fẹri hàn pe o jẹ́ ọ̀kan ninu awọn agutan ti a bukun fun wọnyẹn bi?
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 32]
Garo Nalbandian