ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w93 7/1 ojú ìwé 31
  • Ó Rí Ète kan Ninu Igbesi-Aye

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ó Rí Ète kan Ninu Igbesi-Aye
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bíbélì Máa Ń yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Bíbélì Máa Ń Sọni Dèèyàn Rere
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
w93 7/1 ojú ìwé 31

Awọn Olupokiki Ijọba Rohin

Ó Rí Ète kan Ninu Igbesi-Aye

JESU sọ pe oun mọ awọn agutan oun. (Johannu 10:14) Bí ẹnikan bá ni ọkan-aya rere ati ifẹ fun alaafia ati òdodo, ẹni yẹn ni a o fà sunmọ awọn ọmọlẹhin Jesu. Iru ẹni bẹẹ yoo rí ète kan ninu igbesi-aye, bi obinrin kan ti ṣe ní Belgium. Ìtàn rẹ̀ niyii:

“Nigba ti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kan ilẹ̀kùn mi, mo ni isorikọ gidigidi mo sì ń ronu lati fi opin si iwalaaye mi. Mo nifẹẹ ohun ti awọn Ẹlẹ́rìí naa sọ nipa ojutuu si awọn iṣoro ayé alaisan yii ṣugbọn n kò fẹ́ èrò naa pe Ọlọrun ní ipa kan lati kó. Mo ti dawọ lilọ si ṣọọṣi duro ni ọdun mẹjọ ṣaaju, niwọn bi mo ti koriira agabagebe ti mo rí nibẹ. Bi o ti wu ki o ri, niti awọn Ẹlẹ́rìí naa, mo rí otitọ ti o wà ninu ohun ti wọn sọ mo sì wá mọ̀ pe, o ṣetan, o ṣoro lati walaaye laisi Ọlọrun.

“Lọna ti kò munilayọ, lẹhin awọn ibẹwo bii melookan, ń kò ní ifarakanra pẹlu awọn Ẹlẹ́rìí naa mọ́. Araami kò lélẹ̀ mọ́. Mo ń mu siga paali meji lóòjọ́ mo sì tilẹ bẹrẹ sii lo awọn oogun lile. Bi mo ti ń fẹ́ lati bá baba-baba mi ti o ti kú sọrọ pọ, mo kowọnu ibẹmiilo. Ẹ sì wo bi ẹ̀rù ti maa ń bà mi tó ni emi nikan lóru nigba ti mo bá ń niriiri igbogunti awọn ẹmi-eṣu gẹgẹ bi abajade rẹ̀! Eyi gba oṣu pupọ. Ní gbogbo irọlẹ ni ẹ̀rù maa ń bà mi nigba ti mo bá ronu nipa wíwà ni emi nikan.

“Nigba ti o di ọjọ kan, mo nasẹ̀ jade lọ, ni gbigba ọ̀nà kan ti o yatọ si eyi ti mo sábà maa ń gbà, mo dé ibi ilẹ ile nla kan ti wọn ń kọ́ lọwọ. Si iyalẹnu mi mo ri ogunlọgọ awọn eniyan nibẹ. Bi mo ti ń sunmọ ibẹ, mo rii pe awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni tí wọn wà lẹnu kíkọ́ Gbọngan Ijọba kan. Mo ranti ibẹwo ti awọn Ẹlẹ́rìí ti ṣe si ile mi, mo si ronu bi yoo ti jẹ́ iyalẹnu tó bi gbogbo ayé bá lè gbé bi awọn eniyan wọnyi ti ń ṣe.

“Mo daniyan niti gidi pe awọn Ẹlẹ́rìí naa yoo pada wá si ile mi, nitori naa mo bá diẹ ninu awọn ti wọn ń ṣiṣẹ lori gbọngan naa sọrọ. Mo gbadura si Ọlọrun, ní ọjọ mẹwaa lẹhin naa, ọkunrin ti o ti wá sọdọ mi lakọọkọ dé ẹnu-ọna mi. Ó dabaa pe ki a tẹsiwaju ninu ikẹkọọ Bibeli naa, mo sì fi tayọtayọ gbà. Lẹsẹkẹsẹ o kesi mi lọ si awọn ipade ni Gbọngan Ijọba. Mo gbà. Emi kò tíì ri iru ìran bẹẹ rí! Tipẹtipẹ ni mo ti ń wá awọn eniyan ti wọn nifẹẹ ẹnikinni keji ti wọn si layọ. Awọn sì niyii nikẹhin!

“Lẹhin ìgbà naa mo lọ si gbogbo awọn ipade. Lẹhin nǹkan bii ọsẹ mẹta, mo dáwọ́ aṣa buruku ti siga mimu duro. Mo kó awọn iwe mi lori ìkíyèsí-ìgbà ati awọn àwo orin mi ti wọn ni awọn orin elèṣù ninu dànù, mo sì nimọlara pe awọn ẹmi-eṣu ń padanu ipá wọn lori mi. Mo fi eto si igbesi-aye mi ni ibamu pẹlu awọn ọpa-idiwọn Jehofa ninu Bibeli, lẹhin oṣu mẹta mo sì bẹrẹ sii waasu ihinrere. Lẹhin oṣu mẹfa mo ṣe iribọmi. Ọjọ meji lẹhin iribọmi mi, mo bẹrẹ iṣẹ aṣaaju-ọna oluranlọwọ.

“Mo dupẹ lọwọ Jehofa fun gbogbo ohun daradara tí o ti ṣe fun mi. Igbesi-aye mi ní ète nikẹhin. Bẹẹni, orukọ Jehofa jẹ́ ilé-ìṣọ́ agbara ninu eyi ti mo ti rí ìsádi ati idaabobo. (Owe 18:10) Mo nimọlara niti gidi gẹgẹ bi olorin naa ti ṣe nigba ti o kọwe ni Orin Dafidi 84:10 pe: ‘Ọjọ kan ninu agbala rẹ sàn ju ẹgbẹrun ọjọ lọ. Mo fẹ́ ki n kúkú maa ṣe adènà ni ilé Ọlọrun mi, ju lati maa gbé àgọ́ iwa buburu.’”

Obinrin ọlọkan rirẹlẹ yii rí ète kan ninu igbesi-aye. Bẹẹ pẹlu ni ẹnikẹni ti o ń wá Jehofa pẹlu ọkan-aya rere lè ṣe.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́