ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w93 7/1 ojú ìwé 32
  • Ẹwà tí Kìí Sá

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹwà tí Kìí Sá
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
w93 7/1 ojú ìwé 32

Ẹwà tí Kìí Sá

“ẸWÀ ń pòórá; ẹwà ń kọja lọ,” ni akéwì Walter De la Mare sọ. Dajudaju bayii ni ọ̀ràn rí pẹlu awọn òdòdó igi ọrọ́ ti a fi aworan rẹ̀ hàn nihin-in. Ògò wọn ń yára ṣá.

Kristian ọmọ-ẹhin naa Jakọbu kọwe pe: “Bí itanna koriko ni [ọkunrin ọlọ́rọ̀] yoo kọja lọ. Nitori oorun là ti oun ti ooru mímú, ó sì gbẹ koriko, itanna rẹ̀ sì rẹ̀ danu, ẹwà oju rẹ̀ si parun: bẹẹ pẹlu ni ọlọ́rọ̀ yoo ṣegbe ni ọ̀nà rẹ̀.”—Jakọbu 1:10, 11.

Ninu ayé ti kò nidaaniloju yii, ọrọ̀ lè pòórá ni ọ̀sán-kan-òru-kan nitootọ. Siwaju sii pẹlu, ọkunrin ọlọ́rọ̀—bii gbogbo eniyan miiran—jẹ́ ‘ọlọ́jọ́ diẹ, bi ìtànná.’ (Jobu 14:1, 2) Jesu pa òwe kan nipa ọkunrin kan ti ọwọ́ rẹ̀ ti dí ninu kíkó ọrọ̀ jọ ki o baa lè fẹhinti ki o sì maa gbáládùn. Ṣugbọn nigba ti ó ronu pe oun ti ní gbogbo ohun ti oun nilo fun igbesi-aye fàájì, ó kú. Jesu kilọ pe: “Bẹẹ ni ẹni ti o to iṣura jọ fun ara rẹ̀, ti kò sì ni ọrọ̀ lọdọ Ọlọrun.”—Luku 12:16-21.

“Ọrọ̀ lọdọ Ọlọrun.” Ki ni ohun ti Jesu ní lọ́kàn nipa iyẹn? Ọkunrin kan ti ó lọ́rọ̀ ni ọ̀nà yii ní “iṣura ni ọrun”—orukọ rere pẹlu Ọlọrun. Iru iṣura bẹẹ kìí ṣá lae. (Matteu 6:20; Heberu 6:10) Dipo dídàbíi òdòdó tí ń rọ, ninu Bibeli iru ọkunrin kan bẹẹ ni a fiwe igi kan, ti ewe rẹ̀ kìí rẹ̀. A sì mú un dá wa loju pe, “ohunkohun ti o ṣe ni yoo maa ṣe deedee.”—Orin Dafidi 1:1-3, 6.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́