Wíwàásù ní Ilẹ̀ Onírúurú Ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀
ÀWỌN ẹranko kangaroo, koala, wombat, ati platypus, Àpáta Ayers ati Òkè Barrier Ńlá—ìwọ̀nyí ni àwọn orúkọ tí ó máa ń wá sọ́kàn nígbà tí àwọn ènìyàn bá ronú nípa Australia. Ṣùgbọ́n bí ó ti lè yanilẹ́nu tó, ọ̀pọ̀ jùlọ nínú àwọn ará Australia ni ó ṣeéṣe kí wọ́n má tíì ṣèbẹ̀wò síbi Àpáta Ayers tàbí Òkè Barrier Ńlá tàbí rí ẹranko koala, wombat, tàbí platypus rí lẹ́yìn òde ọgbà ẹranko. Ìdí ni pé ìgboro ìlú ni ìpín márùndínláàádọ́rùn-ún iye àwọn ènìyàn million mẹ́tàdínlógún lé ẹ̀sún mẹ́ta tí ń gbé ìlú náà wà, ní gbígbé nínú àwọn ìlú-ńlá pàtàkì márùn-ún lẹ́bàá ìlà etíkun.
Ní fífi bèbè etíkun sílẹ̀ àti rírìnrìn-àjò nǹkan bíi igba kìlómítà lọ sáàárín gbùngbùn ìlú, ẹnìkan lè bá araarẹ̀ ní orílẹ̀-èdè àrọ́ko tí ó lókìkí ní ilẹ̀ náà. Ìrísí ojú-ilẹ̀ a máa yípadà láti èyí tí ó jẹ́ ti ìgbó ẹgàn dídí kìjikìji àti ilẹ̀-oko tí ó lọ́ràá sí àárín ìlú gbayawu, tí ó móoru, tí ó sì gbẹ, níbi tí kìkì igi wíwẹ́ àti koríko gátagàta ti ń dàgbà. Bí ó ti wù kí ó rí, ohun alààyè wà ní orílẹ̀-èdè àrọ́ko náà. Ibi ìtọ́jú àwọn àgùtàn àti màlúù ńlá, tàbí ọgbà ẹran ọ̀sìn gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ń pè é, gbòòrò yíká ọgọ́rọ̀ọ̀rún kìlómítà ilẹ̀ níbùú lóròó. Aṣálẹ̀ gbígbẹ háú-háú wà ni àwọn ilẹ̀ tí wọ́n túbọ̀ wà ní àárín gbùngbùn ìlú, nibi tí àwọn ènìyàn máa ń kú sí nígbà tí wọn kò bá lo àwọn ìṣọ́ratẹ́lẹ̀ tí ó yẹ.
Ìhìnrere Gbilẹ̀
Nínú irú ipò àyíká bẹ́ẹ̀ ni a ti wàásù ìhìnrere Ìjọba Ọlọrun ní ilẹ̀ Australia. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́dọọdún ń dáhùnpadà sí ìlérí Jehofa nípa ayé titun òdodo kan. Ní ọdún iṣẹ́-ìsìn tí ó kọjá, iye àwọn akéde Ìjọba dé góńgó tí ó rékọjá ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlọ́gọ́ta, èyí tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìlọ́po méjì ti ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn. Nígbà tí ó jẹ́ pe ọ̀pọ̀ jùlọ nínú àwọn akéde, bíi ti apá tí ó pọ̀ jùlọ nínú àwọn olùgbé ìlú, ni wọ́n pọ̀ ní awọ́n ìlú-ńlá tí ó wà lágbègbè etíkun, ìhìnrere náà gbilẹ̀ dé àwọn àgbègbè ìgbèríko pẹ̀lú.
Láti rí ìwòfìrí ohun tí ó jọ láti wàásù ní ilẹ̀ gbígbòòrò onírúurú ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ yìí, ẹ jẹ́ kí á darapọ̀ mọ́ ọ̀kan lára àwọn alábòójútó àgbègbè wa márùn-ún àti aya rẹ̀ bí wọ́n ṣe ń bẹ díẹ̀ lára àwọn ìjọ tí ó wà ní àwọn agbègbè orílẹ̀-èdè àrọ́ko jíjìnnà-réré wò. Ìrìn-àjò wọn kárí ìpínlẹ̀ Western Australia, ìdajì ìpínlẹ̀ Queensland, àti Northern Territory, ààyè ilẹ̀ tí ó ju million mẹ́rin àti ẹ̀sún méje kìlómítà níbùú lóòró lọ. Ìyẹn jẹ́ ohun tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìtóbi Europe, láìka ohun tí ó jẹ́ Soviet Union tẹ́lẹ̀rí mọ́ ọn.
Ìrìn-àjò wa bẹ̀rẹ̀ ní Perth, olú-ìlú Western Australia. Ní ìlú-ńlá tí ó jẹ́ ọlọ́làjú jálẹ̀jálẹ̀ yìí ti ó ní milion kan àti ẹ̀sun méjì ènìyàn nínú, ni ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa mọ́kàndínláàádọ́ta wà nísinsìnyí. Ní àfikún sí ìjọ elédè Gẹ̀ẹ́sì, a ní àwọn ìjọ tí ń sọ èdè Griki, Italian, Portuguese, àti Spanish, bákan náà sì ni àwọn àwùjọ kéékèèke ní àwọn èdè mìíràn. Ìjọ kan tún wà tí ó ní kìkì àwọn arákùnrin àti arábìnrin tí wọ́n jẹ́ Aborigine nìkan nínú, tí wọ́n darí àwọn ìsapá ìwàásù wọ́n sí àárín àwọn ọmọ ilẹ̀ náà gan-an. Púpọ̀ lára àwọn ènìyàn onírẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí ni wọ́n ń dáhùnpadà sí ìhìn-iṣẹ́ Ìjọba náà nísinsìnyí. Ṣugbọn bawo ni àwọn ǹnkan ṣe rí lọ́hùn-ún ní òde àwọn ìlú-ńlá náà?
Láti Perth a rìnrìn-àjò ẹgbẹ̀sán kìlómítà gba ìhà àríwá lọ sí Port Hedland, níbi tí a ó ti ṣe àpéjọ àyíká kan. Ọ̀pọ̀ lára àwọn 289 tí wọ́n pésẹ̀ ni wọ́n ti rìnrìn-àjò láàárín nǹkan bíi igba sí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin kìlómítà láti dé ìhín. Wọ́n wá láti àwọn àgbègbè àdádó níbi tí ìjọ tí ó súnmọ́tòsí jùlọ ti lè fi 250 kìlómítà jìnnà sí wọn ní ojú-ọ̀nà gbágungbàgun tí a da àwọn òkúta ẹlẹ́nu ṣóńṣó sí tí ó sì sábà máa ń gún àwọn táyà ọkọ̀-ayọ́kẹ́lẹ́. Àwọn ìjọ mẹ́ta ní agbègbè yìí ti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba láìpẹ́ yìí, ní lílo ọ̀nà ìkọ́lé ayárakọ́.
Àwọn Gbọ̀ngàn Àyárakọ́ ní Àwọn Àgbègbè Àdádó
Ẹ wo irú ìyàtọ̀ tí ó wà láàárín kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba kan ní àwọn àgbègbè wọ̀nyí àti kíkọ́ ọ̀kan ní àwọn ìlú-ńlá àti àwọn ìlú títóbi jù! Ọ̀pọ̀ jùlọ àwọn ohun-èèlò ìkọ́lé náà ni a gbọ́dọ̀ fi ọkọ̀-ẹrù kówọlé láti Perth, ẹgbẹ̀jọ kìlómítà sí ìhà gúúsù. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn arákùnrin àti arábìnrin rin ọ̀nà jíjìn yìí àti àwọn púpọ̀ síi ní àwọn òpin-ọ̀sẹ̀ tí a fètò sí láti wá kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba náà nínú ooru tí ìwọ̀n ìgbóná rẹ̀ tó 105 sí 115 lóri ìwọn Fahrenheit. Irú ìrọ́wọlé sínú àwọn àgbègbè àdádó kékeré bẹ́ẹ̀ jẹ́ ẹ̀rí dídúró gedegbe kan nínú araarẹ̀. Nígbà tí a kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba kan ní Tom Price, ìlú kékeré kan tí wọ́n ti ń wakùsà irin, abala iwájú ìwé-ìròyìn àdúgbò polongo pe: “Ìkínikáàbọ̀ ọlọ́yàyà fún àwọn òṣìṣẹ́ olùyọ̀ǹda ara-ẹni àti àwọn olùrànlọ́wọ́ tí wọ́n lọ́wọ́ nínú ‘ilé àyárakọ́’ ọlọ́jọ́ mẹ́ta ti Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní Tom Price.”
Ó jọ pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo ẹni tí ó wà nínú ìlú náà ni ó dàníyàn láti fọwọ́sowọ́pọ̀. Dípò ẹgbẹ̀rún mọ́kànlá owó dollar ti Australia tí yóò náni láti kó àádọ́ta tọ́ọ̀nù àwọn ohun-èèlò, ọkùnrin onínúure kan tí ó ní ọkọ̀ akẹ́rù kan wulẹ̀ béèrè pé kí àwọn arákùnrin mówó epo ọkọ̀ wá ni. Àwọn kunlékunlé àdúgbò fi gálọ́ọ̀nù ọ̀dà mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n tọrẹ. Àwọn walẹ̀walẹ̀ pèsè àwọn ẹ̀rọ-ìṣiṣẹ́, ilé-iṣẹ́ ìwakùsà sì pèsè ẹ̀rọ agbẹ́rùrókè kan lọ́fẹ̀ẹ́. Wíwá ilé gbígbé fún ọ̀ọ́dúnrún àlejò gbé ìṣòro kan dìde, ṣùgbọ́n ìfọwọ́sowọ́pọ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn ará ìlú jẹ́ àrà-ọ̀tọ̀. Àwọn kan fóònù wọ́n sì pèsè àwọn bẹ́ẹ̀dì. Ọkùnrin kan tẹ̀ wá láago láti sọ pé òun kì yóò sí nílé ní òpin-ọ̀sẹ̀ ṣùgbọ́n pé òun kì yóò ti ilẹ̀kùn ẹ̀yìnkùlé. Ó sọ pé: “Ẹ̀yin ni ẹ ni ilé fún gbogbo àkókò tí iṣẹ́ ìkọ́lé náà yóò gbà.”
Ìṣẹ̀lẹ̀ apanilẹ́rìn-ín kan wáyé nígbà tí a fún àwọn arákùnrin kan ni àdírẹ́sì ibi kan tí wọn yóò ti lọ gbé ọkọ̀ akẹ́rù kan tí ó jẹ́ ti ìpínlẹ̀ ìṣiṣẹ́ àdúgbò naa. Ẹnu yà wọ́n láti rí àmì kan lẹ́nu géètì tí ó kà pe, “Kò Sí Ààyè fún Ìkésíni Láti Ọ̀dọ̀ Àwọn Onísìn.” Ọkọ̀ akẹ́rù náà ni ó sì wà nídúró yìí. Nítorí náà wọ́n sọ fún obìnrin onílé náà pé àwọn fẹ́ láti gbé ọkọ̀ akẹ́rù náà, tí ó kún fún ìdọ̀tí. Bí wọ́n ti ń gbá inú rẹ̀ lọ́wọ́, wọ́n mọ̀ lójijì pé kìí ṣe ọkọ̀ akẹ́rù ìpínlẹ̀ ìṣiṣẹ́ àdúgbò náà! Nígbà tí ẹni tí ó ni ọkọ̀ akẹ́rù náà darí sílé, aya rẹ̀ sọ fún un pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti wá gbé ọkọ̀ akẹ́rù rẹ̀. Àwọn arákùnrin náà padà wá láìpẹ́ pẹ̀lú ọkọ̀ akẹ́rù náà tí ó ti ṣófo nísinsìnyí, wọ́n sì ṣàlàyé àṣìṣe naa. Ìjíròrò dáradára kan tẹ̀lé e, àwọn alátakò tẹ́lẹ̀rí wọ̀nyí sì ní ọ̀pọ̀ ìbéèrè láti béèrè nípa àwa àti iṣẹ́ wa. Wọ́n ń ṣàníyàn nísinsìnyí láti wá wo Gbọ́ngàn Ìjọba titun náà.
Làti wàásù ìhìnrere náà ní àyíká yìí béèrè fún ìforítì. Lákọ̀ọ́kọ́, nínú rẹ̀ ni àwọn ọ̀nà tí ó jìn síra wà. Arábìnrin aṣáájú-ọ̀nà kan àti ọkọ rẹ̀ máa ń wakọ̀ déédéé ní àwàyípo la nǹkan tí ó ju 350 kìlómítà kọjá lórí àwọn ojú-ọ̀nà eléruku, tí ó rí gbágungbàgun, láti Port Hedland sí Marble Bar, láti ṣe ìpadàbẹ̀wò kí wọ́n sì darí àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli. Marble Bar wà lára àwọn ibi tí ó gbóná jùlọ ní Australia, tí ìwọ̀n ìgbóná sì sábà máa ń ga kọjá 120 lórí ìwọ̀n Fahrenheit láti October sí March.
Lọ Sí “Ìpẹ̀kun Òkè”
Darwin, tí ó jìnnà ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀tàlá kìlómítà síhà àríwá, ni ìlú tí ó kàn fún àpéjọ àyíká. Alábòójútó àgbègbè àti aya rẹ̀ lo wákàtí gígùn ọkọ̀ wíwà láti ṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́. Lákọ̀ọ́kọ́ wọ́n yóò kà ẹsẹ ojoojúmọ́ wọn a sì ṣàyẹ̀wò rẹ̀. Lẹ́yìn náà wọ́n a tẹ́tísílẹ̀ sí Bibeli kíkà tí a gba ohùn rẹ̀ sílẹ̀ sínú téèpù. Bí wọ́n ti ń pín ọkọ̀ náà wà níkọ̀ọ̀kan, wọ́n tún ń pín àwọn ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ láti inú Ilé-Ìsọ́nà àti Jí! kà níkọ̀ọ̀kan.
Àmì ojú-ọ̀nà kan ṣèkìlọ̀ fún wọn láti wà lójúfò fún “àwọn ọkọ̀ akẹ́rù alákànpọ̀.” Ìwọ̀nyẹn ni àwọn ọkọ̀ akẹ́rù gígùn tí wọ́n máa ń sáré gan-an tí wọ́n máa ń fa àwọn ọkọ̀ eléjò mẹ́ta tàbi mẹ́rin tí wọ́n sì máa ń tó mítà márùnléláàádọ́ta ní gígùn. Nítorí náà ààyè púpọ̀ ni a nílò nígbà tí a bá ń kọ́já lára wọn. Wọ́n ń lò wọ́n láti kó àwọn màlúù àti àwọn ẹrù mìíràn lọ sí àwọn ìlú àdádó.
Ojú-ọjọ́ sábà máa ń gbóná tí àrọ́ko sì máa ń gbẹ ṣáá ní gbogbo ìgbà. Ilẹ̀ gbígbẹ tí a túnṣe náà ni ó ṣeéṣe kí a ṣìmú fún ibi ìsìnkú gbígbòòrò kan nítorí pé ilẹ̀ náà kún fún àwọn òkìtì-èèrà tí ó tò tẹ̀léra lọ́wọ̀ọ̀wọ́. Àwọ̀ àwọn òkìtì-èèrà wọ̀nyí yàtọ̀ síra, ní sísinmilórí erùpẹ̀ tí àwọn èèrà náà lò, wọ́n lè ga tó mítà kan sí méjì àti ààbọ̀. Wàyí o, bí àwọn arìnrìn-àjò wa ṣe ń sọdá Odò Victoria, ọ̀pọ̀ àwọn àmì tí ó jẹ́ ti ìbílẹ̀ a máa gba àfiyèsí wọn. “Ewu: A Kò Gba Ìlúwẹ̀ẹ́ Láàyè. Àwọn Ọ̀nì tí Ń Jẹ Ènìyàn Wà Nínú Àwọn Odò Wọ̀nyí!” ni ọ̀kan wí. Pẹ̀lú ọgbọ́n, wọ́n pinnu láti wá àwọn ọ̀nà mìíràn láti wẹ̀ kí ara wọn sì silé!
Níkẹyìn, wọ́n dé ìkángun orí ìhà àríwá Australia, èyí ti gbogbo ènìyàn mọ̀ sí “Ìpẹ̀kun Òkè.” Darwin, olú-ìlu Northern Territory, ni ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa méjì wà. Onírúurú àṣà ìbílẹ̀ Darwin ni a lè tètè rí nígbà tí a bá ń lọ sí àpéjọ àyíká. Ẹ gbọ́ nípa Charles ẹni ọgbọ̀n ọdún, ẹni tí ó ti wá láti East Timor tí ogun ti fọ́ bàjẹ́ ní Indonesia. Àwọn òbí rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ọmọ-ilẹ̀ China kọ́ ọ láti kówọnú ìjọsìn àwọn bàbáńlá. Ó tún ti kówọnú àwọn eré ìdárayá ọnà ìjà panipani. Jíjáwọ́ níbẹ̀ kò rọ̀rùn nítorí ìdè lílágbárá pẹ̀lú ìbẹ́mìílò. Bí ó ti wù kí ó rí, nípa fífi ìmọ̀ràn Jesu sọ́kàn pe “òtítọ́ yóò sì sọ yín di òmìnira,” ó jáwọ́ kúrò nínú ọ̀nà ìgbésí-ayé yìí. (Johannu 8:32) “Lónìí,” ni ó sọ, “mo ní ẹ̀rí-ọkàn mímọ́gaara níwájú Jehofa, mo sì ń ṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ iṣẹ́-òjíṣẹ́ ní báyìí. Góńgó ìlépa mi ni láti lọ sí Ilé-Ẹ̀kọ́ Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Iṣẹ́-Òjíṣẹ́.”
Lẹ́yìn náà, ẹ gbọ́ nípa Beverly láti Papua New Guinea. “Lákọ̀ọ́kọ́ èmi kò ní ìgboyà tí ó pọ̀ tó láti wàásù fún àwọn ènìyàn aláwọ̀ funfun,” ni Beverly jẹ́wọ́, “nítorí pé èdè Gẹ̀ẹ́sì ni èdè mi kejì àwọn èdè ìsọ̀rọ̀ kan báyìí, papọ̀ pẹ̀lú àwọn àmì ohùn ọ̀rọ̀ èdè Australia, sì mú kí ó ṣòro fún mi láti lóye. Ṣùgbọ́n ní rírántí pé Bibeli sọ fún wa láti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jehofa àti láti tọ́ ọ wò kí á sì ríi pé rere ni òun, mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́-òjíṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà alákòókò kíkún ní January 1991. Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli mi àkọ́kọ́ jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà nísinsìnyí. Méjì lára àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ pẹ̀lú ti tẹ́wọ́gba òtítọ́, ọ̀kan nínú wọn ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà, papọ̀ pẹ̀lú ọkọ rẹ̀.”
Kí a tó mẹ́nu kúrò lórí ọ̀rọ̀ ti Darwin, ẹ jẹ́ kí a yára rìnrìn-àjò ránpẹ́ kan tí ó jẹ́ 250 kìlómítà sí ìhà ìlà-oòrùn lọ sí Ọgbà Ìtura Orílẹ̀-Èdè Kakadu, tí a mọ̀ dunjú fún kíkún tí ó kún fún àwọn ẹ̀dá ẹyẹ. Níbí ni a ti lè rí Debbie, oníwàásù ìhìnrere kanṣoṣo ní ibi àdádó ní gbogbo àyíká náà. A béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ bí ó ti ṣe ń dọ́gbọ́n báa nìṣó ní jíjẹ́ alágbára nípa tẹ̀mí nínú irú ipò àdádó bẹ́ẹ̀. Ó dáhùnpadà pé: “Lákọ̀ọ́kọ́, nípa àdúrà. . . . Mo sì ń rí ìtùnú láti inú àwọn ìwé mímọ́ bíi Isaiah 41:10, tí ó sọ pé: ‘Má bẹ̀rù; nítorí mo wà pẹ̀lú rẹ; má fòyà; nítorí èmi ni Ọlọrun rẹ; èmi óò fun ọ ní okun; nítòótọ́, èmi ó ràn ọ́ lọ́wọ́; nítòótọ́, èmi ó fi ọwọ́ ọ̀tún òdodo mi gbé ọ sókè.’”
Ní Jilkmingan, 450 kìlómítà sí ìhà gúúsù Darwin, a pàdé àwùjọ kékeré ti àwọn Aborigine. Fun ọ̀pọ̀ ọdún, àpapọ̀-àwùjọ àwọn Aborigine yìí ni a kà sí àpapọ̀-àwùjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa nítorí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni wọ́n máa ń wá sí àwọn àpéjọpọ̀ àti àpéjọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí èyíkéyìí nínú wọn tí a ti baptisi. A mọ àwùjọ náà fún ìmọ́tótó rẹ̀. Ó dùn mọ́ wa nínú pé, àwọn kan ti mú ìdúró alágbára fún òtítọ́ a sì ti baptisi wọn. Wọ́n wà lára àwọn Aborigine tí kìí gbé àárín-ìlú tí wọ́n kọ́kọ́ ṣe bẹ́ẹ̀. Ó gba ìgboyà àti ìgbọ́kànlé gidi nínú ẹ̀mí mímọ́ Jehofa fún àwọn ènìyàn rírẹlẹ̀ láwùjọ wọ̀nyí láti já araawọn gbà kúrò lọ́wọ́ àwọn ẹ̀kọ́ àtọwọ́dọ́wọ́ àti àwọn àṣà ìbẹ́mìílò ti àwọn ènìyàn ẹ̀yà wọn tí ó ti wà fún ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún.
A Fi Orílẹ̀-Èdè Àrọ́ko Sílẹ̀ Lọ Sí Alice Springs
Ó ti tó àkókò báyìí láti fi “Ìpẹ̀kun Òkè” sílẹ̀ kí á sì forílé ẹgbẹ̀jọ kìlómítà níhà gúúsù sí Alice Springs, ní “Red Centre” tí ó wà ní kọ́ńtínẹ́ǹtì naa, nítòsí Àpáta Ayers tí ó lókìkí naa. Níhìn-ín nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba tí ó ní ẹ̀rọ amúlétutù, àwọn ìjókòó dídẹrùn ni a pèsè fún àpéjọ kan, pẹ̀lú àwọn 130 tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ tí wọ́n wá láti inú àwọn ìjọ méjì tí ó wà ní agbègbè yìí. Lẹ́ẹ̀kan síi, a rí ìran aláyọ̀ ti àwọn ará ilẹ̀ Polynesia, Europe, àti àwọn Aborigine tí wọ́n ń jùmọ̀kẹ́gbẹ́pọ̀ nínú ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ Kristian.
Níkẹyìn a fi ibi Alice Springs sílẹ̀ tí a sì bẹ̀rẹ̀ apá tí ó kẹ́yìn nínú ìrìn-àjò náà pẹ̀lú alábòójútó àgbègbè wa arìnrìn-àjò láti ìlú dé ìlú àti aya rẹ̀. Ìrìn-àjò yìí gbà wá ní ẹgbàá kìlómítà la kọ́ńtínẹ́ǹtì náà já, ó sì lọ láti ìhà àríwá dé ìlà-oòrùn. Bí a ti ṣe bẹ́ẹ̀, a dágbére fún orílẹ̀-èdè àrọ́ko naa, nítóri lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn a dé igbó ẹgàn dídí kìjikìji ti ilẹ̀ olóoru ní Queensland. Níhìn-ín, ní bèbè àríwá Queensland—ilẹ̀ Òkè Barrier Ńlá—àwọn ìjọ púpọ̀ wà tí wọ́n ní ìwọ̀n ìpíndọ́gba gíga ti àwọn Ẹlẹ́rìí sí àwọn olùgbé ilẹ̀ naa.
A kò tíì parí ìrìn-àjò, bí ó ti wù kí ó rí, kí á tó lọ sí àpéjọ àyíká kan síi. Bí a ti wọ ọkọ̀ òfuurufú kan ní Cairns—ìlú ilẹ̀ olóoru Queensland tí ó ní Òkè Barrier olókìkí—a fi ilẹ̀ Australia náà sílẹ̀ lọ nínu ọkọ̀ òfuurufú sọdá lórí ṣóńṣó òkè ìhà àríwá Cape York Peninsula, sọdá sí Torres Strait, lọ sí Thursday Island. Ìjọ kékeré kan wà níhìn-ín tí ó ní àwọn akéde mẹ́tàlélógún péré nínú. Ẹ wo bí ó ti jẹ́ ohun ayọ̀ tó láti rí àwọn mẹ́tàlélọ́gọ́ta níjokòó ní àpéjọ wa tí ó kẹ́yìn nínú ìrìn-àjò yìí!
A lérò pé ẹ ti gbádùn ìwòfìrí iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà tí a ti ṣe ní ilẹ̀ onírúurú ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ yìí. Bóyá ní ọjọ́ kan yóò lè ṣeéṣe fún yín láti bẹ̀ wá wò ní ilẹ̀ arunilọ́kàn-ìfẹ́ sókè yìí ní Australia kí ẹ sì rí àwọn arákùnrin àti aràbìnrin tí wọn ń fi ìṣòtítọ́ ṣe iṣẹ́-òjíṣẹ́ wọn ní ibi àyànfuńni aláìlẹ́gbẹ́ yìí ní tààràtà.
[Àwòrán ilẹ̀/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Port Hedland
Canberra
Tom Price
Marble Bar
Newman
Darwin
Katherine
Alice Springs
Àpáta Ayers
Thursday Island
Cairns
Adelaide
Melbourne
Hobart
Sydney
Brisbane
Perth
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Perth, olú-ìlú Western Australia
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Ìjẹ́rìí òpópónà ń mú àwọn ìyọrísí rere wá