Wíwàásù Láti Abúlé dé Abúlé ní Spain
JESU KRISTI rìnrìn-àjò “láti ìlú-ńlá dé ìlú-ńlá àti láti abúlé dé abúlé, ó ń kọ́ni ó sì ń bá ìrìn-àjò rẹ̀ lọ sí Jerusalemu.” (Luku 13:22, NW) Láti ṣàṣeparí iṣẹ́-òjíṣẹ́ náà, Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wàásù kìí ṣe “láti ìlú-ńlá dé ìlú-ńlá” nìkan ṣùgbọ́n “láti abúlé dé abúlé” pẹ̀lú. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tí ìbá ti rọrùn jù ni pé kí wọ́n kó àfiyèsí jọ sórí àwọn ìlú-ńlá, wọn kò gba ọ̀nà ẹ̀bùrú yẹ àwọn abúlé tí ń bẹ ní agbègbè ìgbèríko sílẹ̀.a
Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní Spain dojúkọ ìpèníjà kan tí ó dàbí ọ̀kan tí Jesu dojúkọ. Tipẹ́tipẹ́ sẹ́yìn láti ọdún 1970, ni àwọn agbègbè ìpínlẹ̀ àrọ́ko púpọ̀ jaburata tí ọwọ́ kò tíì kàn rí ti wà nílẹ̀ fún ìkórè. (Matteu 9:37, 38) Ọgọọgọ́rùn-ún àwọn abúlé tí ń bẹ ní àwọn ibi òkè-ńlá olójò ti àríwá, níbi pẹ̀tẹ́lẹ̀ gbígbẹ táútáú tí ó wà ní àárín gbùngbùn, àti lójú ọ̀nà bèbè-etíkun ni a kò tíì mú ìhìn-iṣẹ́ Ìjọba náà dé.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní Spain pinnu láti lo ìsapá ńláǹlà kí wọ́n baà lè mú ìhìnrere náà dé àwọn ẹkùn wọ̀nyí. Ṣùgbọ́n èéṣe tí àwọn ènìyàn ní agbègbè wọ̀nyí fi níláti dúró pẹ́ tóbẹ́ẹ̀ láti gbọ́ ìhìn-iṣẹ́ Ìjọba náà? Báwo ni wọ́n sì ṣe dáhùnpadà?
Ìdámọ̀ Lábẹ́ Òfin Ru Ìjẹ́rìí ní Àrọ́ko Sókè
Iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní Spain ti wà lábẹ́ ìfòfindè láti ìgbà tí ogun abẹ́lé ti parí ní 1939. Ní àwọn ọdún 1950 àti 1960, àwọn Ẹlẹ́rìí onítara wàásù pẹ̀lú ìṣọ́ra ní àwọn ìlú-ńlá, níbi ti a kìí tètè pé àfiyèsí sí wíwàníbẹ̀ wọn. Níkẹyìn nígbà tí a tẹ́wọ́gba iṣẹ́ wọn lábẹ́ òfin ní 1970, nǹkan bíi ìdajì ọ̀kẹ́ akéde Ìjọba ni ó wà ní Spain. Ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ pé gbogbo wọn pátá ni wọ́n ń gbé nínú àwọn ìlú-ńlá àti ìlú fífẹ̀, ṣùgbọ́n ó yẹ kí àwọn abúlé Spain pẹ̀lú gbọ́ ìhìn-iṣẹ́ Ìjọba náà. Ta ni yóò kojú ìpèníjà náà?
Ní àwọn ọdún 1970 ìgbétáásì kan ni a filọ́lẹ̀ pé kí a mú ìhìnrere náà dé gbogbo agbègbè tí ó wà ní ilẹ̀ tí omi fẹ́rẹ̀ẹ́ yíká náà. Ní èyí tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo oṣù láti 1973 títí fi di 1979, àwọn àkànṣe àkíyèsí tí ń ṣètòlẹ́sẹẹsẹ àìní tí ń bẹ ní ẹkùn kọ̀ọ̀kan nínú orílẹ̀-èdè náà farahàn nínú Iṣẹ́-Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa, ìtẹ̀jáde iṣẹ́-ìsìn olóṣooṣù fún ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Ọ̀pọ̀ àwọn ìdílé tí wọ́n múratán tí wọ́n sì fìfẹ́ dáhùnpadà jẹ́ ìpè ìkésíni náà wọ́n sí fi tinútinú yọ̀ǹda araawọn láti ṣiṣẹ́sìn níbi tí àìní gbé pọ̀ jù.
Àpẹẹrẹ irú èyí ni ti Rosendo àti aya rẹ̀, Luci. A rán wọn lọ gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe (àwọn oníwàásù Ìjọba alákòókò kíkún) sí abúlé kan tí a ti ń pẹja ní àríwá ìwọ̀-oòrùn Spain tí wọ́n sì wá pinnu láti dúró sí àyíká náà nígba tí wọ́n di òbí. “Mo níláti gbà pé a la àwọn àkókò lílekoko gan-an kọjá,” ni Rosendo jẹ́wọ́. “Ó ṣòro láti rí iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́, ṣùgbọ́n a gbáralé ìrànlọ́wọ́ Jehofa ebi kò sì pa wá rí bẹ́ẹ̀ ni a kò sì ṣàìní ibùgbé. Ó pé wa bẹ́ẹ̀ níti tòótọ́.” Láti àwọn ọdún wọ̀nyí wá, ó ti ṣeéṣe fún wọn láti ṣèrànlọ́wọ́ nínú dídá àwọn ìjọ mẹ́rin sílẹ̀ ní ẹkùn yìí ní Spain.
‘Ẹ Wa Ẹni tí Ó Bá Yẹ Rí’
Jesu sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ láti “wá” ẹni tí ó bá yẹ “rí” nínú ìlú-ńlá tàbí abúlé kọ̀ọ̀kan. (Matteu 10:11) Ní àwọn agbègbè àrọ́ko ní Spain, ìwákiri náà béèrè fún aápọn àti ìdánúṣe, gẹ́gẹ́ bí Ángel, arákùnrin kan láti Alcoy (Alicante) ti ṣàwárí. Ó ṣẹ̀ṣẹ̀ parí ṣíṣe ìkésíni sí àwọn ilé kan tán ní abúlé Masías ni nígbà tí ó gbọ́ igbe àkùkọ kan tí ń kọ. Ó rò ó nínú araarẹ̀ pé, “Bí àkùkọ bá wà, ilé kan níláti wà níbìkan—ilé kan tí a ti gbójúfòdá.” Lẹ́yìn tí ó ti wò káàkiri, Ángel rí ipa ọ̀nà kan tí ó gba orí gegele ẹ̀bá òkè-kékeré kan kọjá lọ́ jásí ibi ilé àdádó kan.
Níbi ìdèko yìí ni José àti Dolores ń gbé, arákùnrin àti arábìnrin ọmọ-ìyá kan-náà tí wọ́n ti lé ní ẹni ọgọ́ta ọdún. Wọ́n tẹ́tísílẹ̀ pẹ̀lú ìfarabalẹ̀ wọ́n sì tẹ́wọ́gba ìfilọni ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli lójú-ẹsẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, kò rọrùn láti kẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú àwọn ènìyàn onírẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí, níwọ̀n bí wọn kò ti lè kà tí wọn kò sì lè kọ, gbogbo nǹkan ni a sì níláti túmọ̀ fún wọn láti Spanish sí èdè Valencia, èdè kanṣoṣo tí wọ́n gbọ́. Síwájú síi, wọ́n dojúkọ àtakò tí kìí ṣe kékeré láti ọ̀dọ̀ àwọn aládùúgbò wọn. Lójú àwọn ohun ìdínà wọ̀nyí, José àti Dolores tẹ̀síwájú nínú òtítọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé lílọ sí ìpàdé túmọ̀ sí ìrìn-àjò gígùn lórí àwọn òkè-ńlá. Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, wọ́n tóótun fún ìrìbọmi, àwọn méjèèjì sì ń báa lọ láti máa fi ìṣòtítọ́ ṣiṣẹ́sin Jehofa.
Rosendo àti Luci, tí a mẹ́nukàn ṣáájú, rántí bí alárùn ẹ̀gbà kan nínú ilé àdádó kan lẹ́bàá Moaña, ní àríwá ìwọ̀-oòrùn Spain, ṣe tẹ́wọ́gba òtítọ́. María ni orúkọ rẹ̀. Nígbà tí ó kọ́kọ́ bá àwọn Ẹlẹ́rìí sọ̀rọ̀, kò lè kà kò sì lè kọ ó sì ti wà lórí ibùsùn láìlè dìde fún ọ̀pọ̀ ọdún nítorí pé láti kékeré ni ó ti kó àrùn polio. Ilé rẹ̀ jìnnà ju kìlómítà kan àti ààbọ̀ lọ sí ọ̀nà tí ó súnmọ́tòsí jù. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ó ní ìháragàgà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, kò sì pẹ́ tí ìpinnu rẹ̀ láti ṣiṣẹ́sin Jehofa fi farahàn kedere. María kẹ́kọ̀ọ́ láti kà àti láti kọ ó sì bẹ̀rẹ̀ síí lọ sí àwọn ìpàdé, ọpẹ́lọpẹ́ ìsapá onífọkànsìn ti ìjọ. Àwọn ará ń gbé e rìn fún igba mítà láti ilé rẹ̀ wá sí ọ̀nà tóóró kan tí wọn kò da ọ̀dà sí níbi tí wọn yóò ti fẹ̀sọ̀ gbé e sínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́. Láìka àtakò láti ọ̀dọ̀ ìdílé rẹ̀ sí lákọ̀ọ́kọ́, ó tẹ̀síwájú títí tí ó fi ṣèrìbọmi. Nítorí ìgboyà tí ìtẹ̀síwájú rẹ̀ nípa tẹ̀mí fifún un, ó ti kọ́ láti wa ọkọ̀ kan tí a dìídì ṣe fún ìlò rẹ̀ nísinsìnyí ó sì ti parí ọ̀wọ́ àwọn ẹ̀kọ́-ìwé ìpìlẹ̀ kan. “Lílè ran irú àwọn ènìyàn bíi María lọ́wọ́ mú kí ìrúbọ èyíkéyìí jẹ́ ohun yíyẹ,” ni Rosendo ṣàlàyé.
Àwọn tí Ń Ka Bibeli Fìmúratán Dáhùnpadà
Ní àwọn ọdún 1970 Bibeli wà lárọ̀ọ́wọ́tó fún àwọn aráàlú ní gbogbogbòò fún ìgbà àkọ́kọ́ ní Spain. Ọ̀pọ̀ àwọn ará Spain ra ẹ̀dà kan, àwọn díẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ síí ka Ìwé Mímọ́. Pilar, láti Medina del Campo (Valladolid), tilẹ̀ ti ń ka Bibeli nígbà tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kọ́kọ́ lọ sí ìlú rẹ̀ ní 1973. Bí ó ti jẹ́ Katoliki kan, ẹ̀rù ń bà á láti gba ìwé-ìkẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí, ṣùgbọ́n ó fẹ́ láti lóye Bibeli. Nítorí náà, ó gbà láti máa ni ìjíròrò ọ̀sọ̀ọ̀ṣẹ̀ láti dáhùn àwọn ìbéèrè Bibeli rẹ̀.
Nípa lílo àwọn ìwé-ìkẹ́kọ̀ọ́ tí Watch Tower Society tẹ̀jáde lọ́nà rere, ó ṣeéṣe fún arábìnrin aṣáájú-ọ̀nà tí ó bẹ Pilar wò láti dáhùn ọ̀pọ̀ àwọn ìbéèrè rẹ̀. Bí ohun tí ó ń kọ́ ti wú u lórí, lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ mélòókan Pilar gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli nípa lílo ìwé náà Otitọ ti Nsinni Lọ si Iye Aiyeraiye. Ṣáájú kí ó tó parí ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ nínú ìwé Otitọ, ó ti ka Bibeli tán lódiidi ó sì dá a lójú pé òun ti rí òtítọ́. Ó di Ẹlẹ́rìí àkọ́kọ́ ní Medina del Campo, èyí tí ó ní Gbọ̀ngàn Ìjọba dídára kan àti ìjọ tí ó ní akéde mẹ́tàlélọ́gọ́ta nísinsìnyí.
Àwọn Ẹlẹ́rìí ní Spain ṣì ń rí àwọn ènìyàn tí ‘àìní wọn nípa tẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn’ tí wọ́n sì ń ka Bibeli déédéé nínú ìsapá láti lóye ìfẹ́-inú Ọlọrun. (Matteu 5:3) Pepi, Katoliki kan tẹ́lẹ̀rí tí ó ti fìgbà kan rí kọ́ni ní katikísìmù ní ṣọ́ọ̀ṣì agbègbè ti Zumaia (àríwá Spain), ń wàásù ní abúlé itòsí kan nígbà tí ó bá àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì agbègbè náà pàdé.
“Pepi, ó ń fi àkókò rẹ ṣòfò,” ni àlùfáà náà sọ fún un. “Ní abúlé Itziar yìí, ènìyàn méjì péré ni ó wà—tọkọ-taya alájọṣègbéyàwó kan—tí wọ́n ní ìtẹ̀sí fún ohun tẹ̀mí. Àwọn yòókù wulẹ̀ ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì gẹ́gẹ́ bí àṣà ni.”
“Ó dára,” ní Pepi fèsì, “bí àwọn ènìyàn méjì tí wọ́n ní ìtẹ̀sí fún ohun tẹ̀mí bá wà, wọ́n yóò di Ẹlẹ́rìí Jehofa.”
Pepi ń bá iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé rẹ̀ lọ pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí yòókù títí tí wọ́n fi kárí abúlé náà. Ó sì bọ́sí i gẹ́lẹ́ pé, nínú ilé àdádó kan, àwọn ará rí tọ́kọtaya náà gan-an tí àlùfáà náà ti mẹ́nukàn. Wọ́n ń ka Bibeli ṣùgbọ́n wọn kò lóye rẹ̀. Pẹ̀lú ìháragàgà ni wọ́n fi tẹ́wọ́gba ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, wọ́n tẹ̀síwájú lọ́nà tí ó yárakánkán, a sì baptisi wọn ní April 1991.
Àwọn ènìyàn olótìítọ́-ọkàn kan ti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa wíwulẹ̀ ka ìwé-ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a tẹ̀jáde láti ọwọ́ Watch Tower Society tí a sì gbékarí Bibeli fúnraawọn. Fún àpẹẹrẹ, àwọn Ẹlẹ́rìí láti Almadén (Ciudad Real) ń wàásù nínú ìlú Ciruelas kékeré (Badajoz) nígbà tí wọ́n rí obìnrin kan tí ó tẹ́tísílẹ̀ sí ìhìn-iṣẹ́ wọn pẹ̀lú ìfọkànsí. Nítorí tí ó ṣe kedere pé ó ní ọkàn-ìfẹ́, wọ́n fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli inú ilé kan lọ̀ ọ́. Bí ó ti wù kí ó rí, ó kọ̀, ní sísọ pé ọkùnrin àgbàlagbà kan ti ń kọ́ òun ní ẹ̀kọ́ Bibeli ṣáájú ìgbà náà. Àwọn ènìyàn mélòókan mìíràn ní agbègbè náà tún mẹ́nukan ohun kan-náà. Bí a ti ru ìfẹ́-ìtọpinpin wọn sókè, àwọn ará béèrè nípa ọkùnrin àgbàlagbà náà. Wọ́n gba àdírẹ́sì rẹ̀ wọ́n sì lọ bẹ̀ ẹ́ wò.
Sí ìyàlẹ́nu wọn wọ́n ṣàwárí pé ní Madrid ọkùnrin yìí, tí ń jẹ́ Felipe, ti gba ìwé náà Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye. Lẹ́yìn tí ó ti kà á jálẹ̀, ó lóye pé ó jẹ́ ẹrù-iṣẹ́ òun láti ṣàjọpín ìhìnrere pẹ̀lú àwọn aládùúgbò òun. Fún ìdí yìí, ó ti ń lo ìwé náà láti kọ́ wọn ní ẹ̀kọ́ Bibeli. Àwọn ará ṣètò láti bá a kẹ́kọ̀ọ́. Obìnrin kan tí ó ti bá kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú tẹ́wọ́gba ìkẹ́kọ̀ọ́. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ ẹni ọgọ́rin ọdún tí kò sì gbádùn ìlera dídára, Felipe ń tẹ̀síwájú dáradára nínú òtítọ́.
Wọ́n Borí Ẹ̀tanú
Àwọn ìpínlẹ̀ tí ó wà ní àrọ́ko gbé àwọn ìṣòro aláìlẹ́gbẹ́ kan kalẹ̀. Àwọn àṣà-àtọwọ́dọ́wọ́ àti ìgbàgbọ́ nínú àwọn ohun asán máa ń fìgbà gbogbo ní ipa alágbára nínú irú àwọn agbègbè bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn tí wọ́n sì ń gbé ní àrọ́ko ní ìfura kan tí ó ti wọ̀ wọ́n lára nípa “ìsìn titun.” Àwọn ará abúlé kan ní pàtàkì ní ẹ̀mí ìmọ̀lára nípa ohun tí yóò jẹ́ èrò àwọn aládùúgbò àti ìbátan wọn bí wọ́n bá yí ìsìn wọn padà. Ṣùgbọ́n agbára Ọ̀rọ̀ Ọlọrun lè borí irú àwọn ìṣòro bẹ́ẹ̀ kí ó sì yí ìgbésí-ayé ẹnìkan padà. Bí ọ̀ràn ti rí nìyí ní abúlé Cangas de Morrazo tí wọ́n ti ń pẹja ní àríwá ìwọ̀-oòrùn Spain.
Roberto, ọmọ abúlé yìí, bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ atukọ̀-òkun ní ẹni ọdún mẹ́rìnlá nítorí pé ó yánhànhàn fún ìsọdòmìnira. Ìgbésí-ayé rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òṣìṣẹ́ nínú ọkọ̀-òkun oníṣòwò mú un wọnú ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀dọ́ awakọ̀-òkun mìíràn tí wọ́n ń mutíyó bìnàkò tí wọ́n sì ń lo oògùn títí àkókò ìdánìkanwà tí wọn ń lò lójú òkun yóò fi kọjá lọ. Kò pẹ́ kò jìnnà, Roberto pẹ̀lú di ọ̀mu àti ajòògùnyó.
Nígbà tí ó ṣe Roberto padà wálé ṣùgbọ́n kò ṣeéṣe fún un bẹ́ẹ̀ ni kò múratán láti jáwọ́ nínú àṣà búburú rẹ̀. Láti rí owó lò fún ìjòògùnyó rẹ̀, ó di olè ó sì bá ara rẹ̀ nínú ẹ̀wọ̀n ní ìgbà mẹ́fà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Nígbà tí ó di ẹni ọdún méjìdínlógún, ó gbé àdàlù wáìnì àti oògùn amúnilárabalẹ̀ tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ lè ṣekúpani mu. Àwọn dókítà gba ẹ̀mí rẹ̀ là, ṣùgbọ́n ó pàdánù ìlò apá àti ẹsẹ̀ rẹ̀. Ó fi ilé-ìwòsàn sílẹ̀ pẹ̀lú apá àti ẹsẹ̀ tí ó rọ. Pé ó di ẹni tí a sémọ́ orí aga alágbàá-kẹ̀kẹ́ kò tilẹ̀ mú kí ó dáwọ́ àṣà oògùn jíjẹ náà dúró. Ìrẹ̀wẹ̀sì ti dé bá a nípa ìsìn, ó sì dàbí ẹni pé oògùn nìkan ni ó lè mú kí ayé yẹ ní gbígbé fún un—títí ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa fi bẹ̀ẹ́ wo ní ọdún mẹ́ta lẹ́yìn náà.
Kíkẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bibeli tí ó ní ìmúṣẹ ran Roberto lọ́wọ́ láti borí ẹ̀mí-tàbítàbí rẹ̀. Ìkínikáàbọ̀ ọlọ́yàyà tí ó rígbà ní Gbọ̀ngàn Ìjọba mú kí ó gbàgbọ́ dájú pé ìsìn tòótọ́ a máa mú kí ìgbèsí-ayé àwọn ènìyàn túbọ̀ nítumọ̀. Láàárín oṣù mẹ́sàn-án, Roberto ti borí ìjòògùnyó rẹ̀ a sì baptisi rẹ̀. Láìka àìlera ti ara rẹ̀ tí ó gbópọn sí, ó ti ń siṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà fún ọdún mẹ́jọ. Ó sì ti jẹ́ alàgbà ìjọ láti ọdún méjì tí ó ti kọjá. Francisco, ọ̀kan lára àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ tẹ́lẹ̀rí, ni àwọn ìyípadà nínú ìgbésí-ayé Roberto wú lórí tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí òun pẹ̀lú fi di Ẹlẹ́rìí tí ó sì jẹ́ ìránṣẹ́ iṣẹ́-òjíṣẹ́ nísinsìnyí. Ìyípadà pípẹtẹrí náà níti ajòògùnyó tí ó dàbí ẹni tí kò ṣeéwòsàn yìí ran àwọn ènìyàn ní àdúgbò yẹn lọ́wọ́ láti túbọ̀ mọrírì bí iṣẹ́ wa ti rí. Obìnrin kan tilẹ̀ mú ọmọkùnrin rẹ̀ ọ̀dọ́ tí ó jẹ́ ajòògùnyó wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba láti ríi bí àwọn Ẹlẹ́rìí náà bá lè wò ó sàn.
Wíwá Inú Bibeli Kiri fún Òtítọ́
Ní gbogbogbòò, àwọn olùgbé ní àrọ́ko ní irú ìmọrírì bẹ́ẹ̀ fún òtítọ́ débi tí wọ́n fi máa ń dójúti àwọn ọlọ́gbọ́n ayé. (1 Korinti 1:26, 27) Adelina, onítìjú obìnrin àgbàlagbà kan, jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn onímọrírì wọ̀nyí. Ó sábà máa ń fi ọwọ́ pàtàkì mú ìgbàgbọ́ Katoliki rẹ̀. Lóròòwúrọ̀ láìpasé òun yóò kúnlẹ̀ láti gbàdúrà, ní Kíka Àdúrà Oluwa àti Mo Kí Ọ Maria fún ìgbà mélòókan. Òun yóò darí àdúrà rẹ̀ sí “ẹni mímọ́” ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan nínú ọ̀sẹ̀—kìkì láti rí síi pé díẹ̀ nínú àwọn àdúrà rẹ̀ gbà.
Nígbà tí Adelina bẹ̀rẹ̀ síí kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, ó darí ìtara ìsìn kan-náà yìí sí ìgbàgbọ́ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ rí ní titun. Kódà ìtìjú rẹ̀ kó tilẹ̀ dí i lọ́wọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ní ìgbà àkọ́kọ́ tí òun àti ọkọ rẹ̀ lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba, ó gbà wọ́n ní ìṣẹ́jú mẹ́wàá láti pa ìtìjú tì kí wọ́n tó lè wọlé. Bí ó ti wù kí ó rí, lẹ́yìn tí wọ́n ti wọlé tán, ó fetísílẹ̀ pẹ̀lú ìfọkànsí. Ní àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ kan, ó kẹ́kọ̀ọ́ nípa Àkóso-Ìjọba Ẹlẹ́gbẹ̀rún Ọdún ti Kristi. Kókó-ẹ̀kọ́ yìí fà á lọ́kàn mọ́ra, nígbà tí ó sì padà sílé, ó fẹ́ láti ka púpọ̀ síi nípa rẹ̀ nínú Bibeli tirẹ̀. Ṣùgbọ́n yálà òun tàbí ọkọ rẹ̀ kò mọ ibi tí wọ́n ti lè rí ìsọfúnni náà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ronú pé a mẹ́nukàn án níbìkan nínú ìwé Ìfihàn. Nítorí náà Adelina bẹ̀rẹ̀ síí ka ìwé Ìfihàn ní alẹ́ ọjọ́ náà ó sì ń bá kíkà náà lọ títí tí ó fi dé orí 20 nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín ní ọwọ́ ìdájí.
Ní àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ mìíràn, Adelina kẹ́kọ̀ọ́ pé ohun yíyẹ ni fún ọkọ kan láti ṣojú fún aya rẹ̀ nínú àdúrà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun múratán láti gbàdúrà, ọkọ rẹ̀ kò mọ ohun tí ìbá sọ nínú àdúrà. Ní alẹ́ ọjọ́ yẹn gan-an, Adelina pinnu láti wá àwọn ìtọ́ni rí nínú Bibeli. Ní agogo méjì òru, ó jí ọkọ rẹ̀ dìde láti sọ fún un pé òun ti rí Matteu orí 6, tí ó gbé kúlẹ̀kúlẹ̀ kókó-ẹ̀kọ́ nípa àdúrà yẹ̀wò. Lẹ́yìn kíka àwọn ìtọ́ni Jesu, ọkọ rẹ̀ gbàdúrà fún àwọn méjèèjì nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín. Nísinsìnyí Adelina àti ọkọ rẹ̀ jẹ́ Ẹlẹ́rìí fún Jehofa.
Ìkórè Rere Kan
Lẹ́yìn èyí tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ti ìjẹ́rìí ní àrọ́ko nípasẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ Jehofa onítara, apá ibi gbogbo ní Spain ti gbọ́ ìhìnrere náà. Gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ òtítọ́ nípa Asia Kékeré ní ọ̀rúndún kìn-ín-ní, ‘a ti tan ọ̀rọ̀ Jehofa ká gbogbo ẹkùn náà.’ (Iṣe 13:49) Nítorí náà, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ará abúlé ti dáhùnpadà lọ́nà tí ó dùnmọ́ni.
Ní Spain àti níbòmíràn, wíwàásù ní àwàjálẹ̀ ní àwọn agbègbè àrọ́ko a máa béèrè fún sùúrù àti ìfara-ẹni-rúbọ. Ṣùgbọ́n níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé ìfẹ́-inú Ọlọrun ni pé “kí gbogbo ènìyàn ní ìgbàlà,” àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa láyọ̀ láti wá àwọn onímọrírì rí. (1 Timoteu 2:4) Bí àwọn ìrírí tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ mẹ́nukàn tán yìí sì ti fihàn, Jehofa ti san èrè dídọ́sọ̀ fún ìsapá tí a fi sílò láti wàásù láti abúlé dé abúlé ní Spain.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Josephus ṣírò rẹ̀ pé àròpọ̀ 204 “ìlú-ńlá àti abúlé” ní ń bẹ ní Galili, ó sì ṣàpèjúwe ẹkùn náà bí èyí tí ó ní “abúlé tí ó pọ̀ gan-an.”
[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 23]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
FRANCE
PORTUGAL
SPAIN
ERÉKÙṢÙ BALEARIC
ERÉKÙṢÙ CANARY
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 24]
Vilac, Lérida
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 24]
Puebla de Sanabria, Zamora
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 25]
Casarabonela, Málaga
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 25]
Sinués, Huesca
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 26]
Lekeitio, Vizcaya