ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w93 12/15 ojú ìwé 25-29
  • Jíjẹ́ kí Ojú Wa “Mú Ọ̀nà Kan” nínú Iṣẹ́ Ìjọba

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jíjẹ́ kí Ojú Wa “Mú Ọ̀nà Kan” nínú Iṣẹ́ Ìjọba
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ìsọ̀rí
  • Mímú kí Ojú Wo Ọ̀kánkán Sàn-án
  • Ìgbòkègbodò Ìjọba tí Ó Pọ̀ Síi
  • Ìmọrírì fún Ìwé-Ìkẹ́kọ̀ọ́ Wa
  • Kíkọ́lé fún Ìmúgbòòrò
  • Wọ́n Tẹjúmọ́ Ìjọba Ọlọrun
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
w93 12/15 ojú ìwé 25-29

Jíjẹ́ kí Ojú Wa “Mú Ọ̀nà Kan” nínú Iṣẹ́ Ìjọba

ÌLÚ Aláààrẹ Oníjọba Dẹmọ ti Germany (G.D.R.), tàbí ohun tí a mọ̀ sí East Germany tẹ́lẹ̀, ti fẹ́rẹ̀ẹ́ wọ agbedeméjì sànmánì. Ọdún 41 tí ó ti wà parí ní oṣù October 3, 1990, nígbà tí agbègbè-ìpínlẹ̀ rẹ̀, tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó Liberia tàbí ìpínlẹ̀ Tennessee ní United States, di èyí tí a jápọ̀ mọ́ Ìlú Aláààrẹ ti Ìjọba Àpapọ̀ Germany, èyí tí a ti ń pè ní West Germany.

Ìtúnmúṣọ̀kan àwọn ilú Germany méjèèjì náà ti túmọ̀sí ọ̀pọ̀ iye àwọn àtúnṣe. Ààlà-ilẹ̀ kan tí ó jẹ́ tí àwọn àbá-èrò-orí ni ó ti ya àwọn orílẹ̀-èdè méjèèjì náà sọ́tọ̀, kìí wulẹ̀ ṣe ààlà-ẹnubodè gidi kan lásán. Kí ni gbogbo èyí túmọ̀sí fún àwọn ènìyàn tí wọ́n wà níbẹ̀, báwo sì ni ìgbésí-ayé ṣe yípadà fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa?

Wende, ìyípadà tegbòtigàgá náà tí ó wáyé ní November 1989 tí ó mú kí ìtúnmúṣọ̀kan náà ṣeéṣe, yára tẹ̀lé àwọn ẹ̀wádún mẹ́rin ti ìjọba àjùmọ̀ní aláìláàánú. Ní sáà-àkókò yẹn, ìgbòkègbodò àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni a fòfindè, inúnibíni tí a ṣe sí wọn sì máa ń múná ní àwọn ìgbà mìíràn.a Nígbà tí òmìnira dé fún G.D.R., gbogbo àwọn olùgbé ibẹ̀ nímọ̀lára ayọ̀ jíjinlẹ̀. Ṣùgbọ́n bí ayọ̀ gíga náà ti ń wọ̀ọ̀kùn, ọ̀pọ̀ ní ìdàrúdàpọ̀ ọkàn, ìjákulẹ̀, àní ìrẹ̀wẹ̀sì pàápàá. Iṣẹ́-òpò ti jíjá Germany méjèèjì náà papọ̀ di ọ̀kan níti ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà, ìṣèlú, àti ètò-ọrọ̀-ajé wá ń di àkòtagìrì.

Gẹ́gẹ́ bí àkànṣe ìròyìn náà “162 Tage Deutsche Geschichte” (Àwọn 162 Ọjọ́ Ọ̀rọ̀-Ìtàn Germany) ti sọ nínú Der Spiegel, tẹ̀lé ìtúnmúṣọ̀kan, ìbẹ̀rù wà yíká ibi gbogbo nípa àìgbanisíṣẹ́, ìfòsókè owó-ọjà, àti owó-ilé tí ń ga síi. “Èmi yóò ha ní owó-ìfẹ̀yìntì-lẹ́nu-iṣẹ́ tí ó pọ̀ tó bí?” ni ọ̀pọ̀ ń béèrè ní G.D.R. àtijọ́ náà. Kí ni nípa ti ilé-gbígbé? “Káàkiri ibi gbogbo ní G.D.R., àwọn ilé àtijọ́ ń di ẹgẹrẹmìtì, odidi àdúgbò sì ń di èyí tí kò ṣeé gbé.” Ìsọdèérí ga dé ìwọ̀n tí ń dẹ́rùbani.

Bí irúfẹ́ ìdàrúdàpọ̀ bẹ́ẹ̀ níti ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà àti ìṣúnná-owó ti dojúkọ wọ́n, ọgbọ́n wo ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń dá síi ní G.D.R. àtijọ́?

Mímú kí Ojú Wo Ọ̀kánkán Sàn-án

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kò ní àwọn ààlà-ilẹ̀ kankan níti àbá-èrò-orí. Ìgbàgbọ́ wọn tí a gbékarí Bibeli jẹ́ ọ̀kan náà, yálà ní Ìlà-Oòrùn tàbí Ìwọ̀-Oòrùn. Pẹ̀lú sàkáání-àyíká ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà wọn tí ń yípadà, ọ̀pọ̀ jùlọ àwọn Ẹlẹ́rìí di ìdúródéédéé wọn tẹ̀mí mú nípa títẹ ojú wọn mọ́ góńgó àkọ́kọ́ ti ṣíṣiṣẹ́sin Jehofa. Èéṣe tí èyí fi jẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe?

Nítorí pé “ìrísí ìran ayé yìí ń yípadà.” (1 Korinti 7:31, NW) Kristian alàgbà kan sọ̀rọ̀ àkíyèsí pé wíwàásù lábẹ́ ìfòfindè ṣáájú Wende béèrè ìgboyà; ó kọ́ awọn Ẹlẹ́rìí náà láti gbáralé Jehofa ó sì kọ́ wọn ní bí a ti ń lo Bibeli. Bí ó ti wù kí ó rí, nísinsìnyí, “a níláti túbọ̀ ṣọ́ra kí ìfẹ́-ọrọ̀-àlùmọ́nì àti àwọn àníyàn ìgbésí-ayé máṣe fà wá kúrò lójú ọ̀nà.”

Òmìnira àti ìtẹ̀síwájú ni a sábà máa ń fi ipò nǹkan níti àwọn ohun ti ara díwọ̀n. Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn ní ẹkùn yìí nímọ̀lára àìní láti wá àsanfidípò fún àwọn àkókò tàbí ìgbádùn tí wọ́n ti pàdánù tẹ́lẹ̀. Èyí dí ohun tí ó ṣe kedere nígbà tí ẹnìkan bá ń wakọ̀ lọ lójú títì olókùúta ní àwọn ìlú àti abúlé Thuringia àti Saxony ní gúúsù. Àwọn títì náà lè nílò àtúnṣe, àwọn ibùgbé sì lè wà níwọ̀ntunwọ̀nsì, síbẹ̀ ẹ wo bí àwọn agbada sátẹ́láìtì tẹlifíṣọ̀n ti pọ̀ yamùrá tó! Ó rọrùn fún ẹnìkan láti di ẹni tí a tànjẹ láti gbàgbọ́ pé àìléwu àti ayọ̀ ń wá láti inú níní ohun gbogbo tí ojú lè rí. Ìkẹkùn eléwu wo ni ìyẹn jẹ́!

Nínú Ìwàásù Lórí Òkè, Jesu sọ̀rọ̀ nípa ewu ti fífún àwọn nǹkan ti ara àti àwọn àníyàn ìgbésí-ayé ní àfiyèsí tí kò yẹ. “Ẹ máṣe to ìṣúra jọ fún araayín ní ayé,” ni ó kìlọ̀. Ó fikún un pé: “Ojú ni fìtílà ara: nítorí náà bí ojú rẹ bá [mú ọ̀nà kan, NW], gbogbo araarẹ ni yóò kún fún ìmọ́lẹ̀.” (Matteu 6:19, 22) Kí ni ó nílọ́kàn? Ojú tí ó mú ọ̀nà kan jẹ́ ọ̀kan tí ń wo ọ̀kánkán tí ó sì ń tàtaré àwọn àwòrán ṣíṣekedere síni lọ́kàn. Ojú tẹ̀mí tí ó mú ọ̀nà kan ń pa àwòràn Ìjọba Ọlọrun mọ́ ní kedere. Nítorí náà ìgbèròpinnu Kristian kan láti mú kí ojú òun mú ọ̀nà kan, ní fífojúsun Ìjọba Ọlọrun, kí ó sì ti àwọn àníyàn sí ipò ẹ̀yìn ń ṣèrànlọ́wọ́ láti mú kí ó pa ìwàdéédéé tẹ̀mí mọ́.

Èyí ni a lè fi ìrírí tọkọtaya kan láti Zwickau, Saxony, tí wọ́n fi ọkàn-ìfẹ́ hàn nínú Bibeli nígbà Wende ṣàpèjúwe. Iṣẹ́-ajé wọn ń gba àkókò gidigidi, síbẹ̀ wọ́n fi àwọn àǹfààní-ire tẹ̀mí sí ipò àkọ́kọ́, ní lílọ sí gbogbo àwọn ìpàdé Kristian. “Bí a bá fi ojú ti iṣẹ́-ajé wa wò ó, àwa kò lè yọ̀ǹda àkókò náà,” ni wọ́n jẹ́wọ́, “ṣùgbọ́n nípa tẹ̀mí a nílò rẹ̀.” Ẹ wo ìpinnu ọlọgbọ́n tí èyí jẹ́!

Tún gbé ọ̀ràn ti ìdílé kan ní Plauen, ní Saxony pẹ̀lú yẹ̀wò. Ọkọ ń ṣe aago, ọ̀gá oníṣẹ́-ọnà tí ó ní iṣẹ́-ajé tirẹ̀ sì ni. Tẹ̀lé Wende náà, owó tí ó ń san fún ilé rẹ̀ gásokè lójijì. Kí ni ó níláti ṣe? “Yóò ná mi ní owó púpọ̀ rẹpẹtẹ, mó sì kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ náà láti fi òtítọ́ ṣáájú ohun gbogbo.” Nítorí náà ó ṣílọ sí ilé kan tí ó wà níbi tí kò fi bẹ́ẹ̀ dára tó ṣùgbọ́n tí owó rẹ̀ dínkù. Bẹ́ẹ̀ni, aláago náà yára kẹ́kọ̀ọ́ nípa mímú kí ojú rẹ̀ mú ọ̀nà kan.

Bí ó ti wù kí ó rí, ó ti pẹ́ jù kí àwọn díẹ̀ tó kẹ́kọ̀ọ́. Ní ríronú pé ètò-ọrọ̀-ajé dandawì tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ mú wọlé kún fún àṣeyọrísírere, Kristian alàgbà kan ní ríronú pé ètò-ọrọ̀-ajé dandawì tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ mú wọlé kún fún aṣeyọrísírere, kówọnú iṣẹ́-ajé. Alábòójútó arìnrìn-àjò kan fi inúrere rọ̀ ọ́ láti máṣe jẹ́ kí àwọn ẹ̀jẹ́-àdéhùn iṣẹ́-ajé ṣíji bo ipò tẹ̀mí. Síbẹ̀, ó baninínújẹ́ pé ohun tí ó ṣẹlẹ̀ nìyẹn. Ní oṣù díẹ̀ lẹ́yìn náà arákùnrin náà kọ̀wé fi ipò alàgbà sílẹ̀. Ó kọ̀wé lẹ́yìn náà pé: “Láti inú ìrírí tèmí fúnraàmi, èmi yóò gba arákùnrin èyíkéyìí tí ń nàgà fún àwọn àǹfààní iṣẹ́-ìsìn nímọ̀ràn láti máṣe kówọnú iṣẹ́-ajé àdáṣe.” Èyí kò túmọ̀sí pé iṣẹ́ àdáṣe kò tọ̀nà fún Kristian kan. Ṣùgbọ́n yálà a ní iṣẹ́-ajé tiwa tàbí bẹ́ẹ̀kọ́, fífún àwọn àníyàn ti ètò-ọrọ̀-ajé ní àfiyèsí tí ó pọ̀ jù lè sọ wá di ẹrú ọrọ̀ láìròtẹ́lẹ̀. Jesu fi ìyọrísí rẹ̀ hàn: “Kò sí ẹni tí ó lè sin oluwa méjì: nítorí yálà yóò kórìíra ọ̀kan, yóò sì fẹ́ èkejì; tàbí yóò faramọ́ ọ̀kan, yóò sì yan èkejì ní ìpọ̀sí.” (Matteu 6:24) Akéwì ọmọ ilẹ̀ Germany náà Goethe sọ pé: “Kò sí àwọn tí a túbọ̀ sọdẹrú láìnírètí bíkòṣe àwọn wọnnì tí wọ́n fi èké gbàgbọ́ pé awọn wà lómìnira.”

Bí a bá bá araawa nínú ìjì gidi kan ó lè béèrè pé kí a fojú apákan wo ọ̀nà kí a tó lè ríran tààrà tàbí kí a fọwọ́ dígàgá ojú wa kí a báa lè máa wo góńgó wa níwájú. Nígbà tí ìdàrúdàpọ̀ níti ìṣèlú, ìṣúnná-owó, tàbí ti ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà bá yí wa ká, ìpọkànpọ̀ pọndandan láti máa wo góńgó tẹ̀mí wa níwájú. Kí ni àwọn Kristian kan ń ṣe láti mú kí ojú wọn mú ọ̀nà kan nínú iṣẹ́ Ìjọba?

Ìgbòkègbodò Ìjọba tí Ó Pọ̀ Síi

Jákèjádò gbogbo G.D.R. àtijọ́, àwọn Ẹlẹ́rìí ń yọ̀ǹda àkókò púpọ̀ síi fún wíwàásù ju ti ìgbàkígbà rí lọ. Ní àwọn ọdún méjì tí ó kọjá, ìpíndọ́gba àkókò tí a lò nínú iṣẹ́-ìsìn pápá fi ìpín 21 nínú ọgọ́rùn–ún ròkè. Ìyọrísí náà jẹ́ ìbísí wíwúnilórí ti ìpín 34 nínú ọgọ́rùn-ún nínú àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli inú ilé. Síwájú síi, iye àwọn aṣáájú-ọ̀nà déédéé ti fi ìgbà mẹ́rin ga síi ní lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí ju bí ó ti rí ní kìkì ọdún méjì sẹ́yìn! Nígbà tí àwọn mìíràn ní wàhálà-ọkàn tí wọ́n sì ń ṣàròyé, iye àwọn Kristian tí ó ju 23,000 lọ ní ibi tí a mọ̀ sí G.D.R. nígbà náà ń kojú ipò-ọ̀ràn náà nípa mímú kí ojú wọn mú ọ̀nà kan. Èyí ti fikún ìbísí tí ń ṣeniníkàyééfì nínú ìgbòkègbodò Ìjọba.—Fiwé Joṣua 6:15.

Ìgbòkègbodò tí a mú gbòòrò síi náà túmọ̀sí pé agbègbè-ìpínlẹ̀ náà ni a ń bójútó dáradára ní gúúsù, níbi tí ọ̀pọ̀ jùlọ nínú àwọn Ẹlẹ́rìí ń gbé. Ọ̀pọ̀ nínú orúkọ àwọn ibi wọ̀nyí jámọ́ pàtàkì nínú ọ̀rọ̀-ìtàn a sì mọ̀ wọ́n dunjú. Bí ó bá fẹ́ràn àwọn tánńganran, ìwọ yóò mọ ìlú Meissen, lẹ́bàá Dresden, gẹ́gẹ́ bí ibi tí ọ̀pọ̀ jùlọ lára àwọn awo ẹlẹgẹ́ jùlọ ní ayé ti pilẹ̀ṣẹ̀. Meissen ni ilé nǹkan bíi 130 àwọn akéde Ìjọba náà nísinsìnyí. Tàbí ṣàgbéyẹ̀wò Weimar, “olú-ìlú àtijọ́ fún Germany.” Ohun-Ìrántí Goethe-òun-Schiller ní àárín ìlú náà jẹ́rìí sí àwọn ìsokọ́ra oníyì-ọlá tí Weimar ní pẹ̀lú àwọn òǹkọ̀wé méjì wọnnì ó sì jẹ́ orísun àmúyangàn fún ọ̀pọ̀ tí ń bẹ níbẹ̀. Lónìí Weimar lè fi àwọn akéde ìhìnrere tí wọ́n ju 150 lọ tí wọ́n wà níbẹ̀ yangàn.

Bí ó ti wù kí ó rí, ní àríwá, àwọn nǹkan yàtọ̀ gan-an, pẹ̀lú àwọn akéde tí ó túbọ̀ kéré àti ọ̀nà-jíjìn tùn-ùn-nù-tun-un-nu láti ìjọ kan sí òmíràn. Ó ṣòro ní pàtàkì láti rí iṣẹ́. Ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n ní iṣẹ́ wà lábẹ́ ìkìmọ́lẹ̀ láti ṣiṣẹ́ rékọjá àkókò kí wọ́n má baà pàdánù iṣẹ́ wọn. Arákùnrin kan tí ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí oníwàásù alákòókò kíkún ní àríwá ṣàlàyé pé: “Lábẹ́ ìfòfindè arákùnrin kọ̀ọ̀kan nílò ààbò Jehofa nínú iṣẹ́-ìsìn pápá, ṣùgbọ́n rírí iṣẹ́ kò ṣòro. Nísinsìnyí ipò-ọ̀ràn náà ti yípadà. A ní òmìnira láti wàásù, ṣùgbọ́n a nílò ìtọ́sọ́nà rẹ̀ níti ìgbanisíṣẹ́. Irú ìyípadà bẹ́ẹ̀ kò tètè mọ́nilára.”

Ó ha dùn mọ́ àwọn akéde náà nínú pé wọn lè túbọ̀ wàásù bí? Ojú-ìwòye Wolfgang nìyí: “Ó túbọ̀ sàn jù gidigidi fún akéde kan láti ṣiṣẹ́ léraléra ní agbègbè-ìpínlẹ̀ kan-náà. Àwọn ènìyàn yóò gbẹ́kẹ̀lé e wọn yóò sì túbọ̀ lè finú hàn án.” Ní àfikún sí ìyẹn, àwọn onílé ni “kò tì lójú mọ́ láti sọ̀rọ̀ nípa ìsìn lẹ́nu ilẹ̀kùn, àní bí àwọn tí ń kọjá lọ bá tilẹ̀ lè gbọ́ wọn pàápàá. Ìsìn kìí tún ṣe kókó-ọ̀rọ̀ tí ó jẹ́ èèwọ̀ mọ́.” Ralf àti Martina gbà bẹ́ẹ̀. “A gbádùn ṣíṣiṣẹ́ ní agbègbè-ìpínlẹ̀ wa ní lemọ́lemọ́ síi. A lè mọ àwọn ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ẹnìkọ̀ọ̀kan, ọ̀pọ̀ onírúurú àwọn ìwé-ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó sì tún ru ìmọ̀lára wa sókè.”

Ìmọrírì fún Ìwé-Ìkẹ́kọ̀ọ́ Wa

Ní pàtàkì ni Ralf àti Martina mọrírì ìwé náà Life—How Did It Get Here? By Evolution or by Creation? Fún ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n tẹ́wọ́gba àìgbàgbọ́-nínú-wíwà Ọlọrun ní G.D.R. àtijọ́, ìwé yìí ti ń jásí àgbàyanu àrànṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli. Wọ́n tún fẹ́ ìtẹ̀jáde tí ó túbọ̀ kéré tí ó ní àkójọpọ̀-ọ̀rọ̀ kan-náà. “Ẹ wo bí a ti ru wá sókè tó nípa ìmújáde ìwé-pẹlẹbẹ náà Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi? ní Àpéjọpọ̀ Àgbègbè ‘Àwọn Olùtan Ìmọ́lẹ̀’ ti 1992 ní Dresden. Ó jẹ́ ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wa.”

Ọ̀pọ̀ àwọn tí kìí ṣe Ẹlẹ́rìí ni àwọn ìtẹ̀jáde Watch Tower ti wá jọ lójú. Ní July 1992 tíṣà yunifásítì kan tí ń kọ́ni ní ìmọ̀-ẹ̀kọ́ ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà kọ̀wé láti sọ̀ nípa “ọ̀wọ̀ àti ọpẹ́ ọlọ́yàyà gíga jùlọ” tí òun ní fún àwọn ìtẹ̀jáde náà, èyí tí òun ń lò láti múra àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ sílẹ̀. Ní January 1992 obìnrin kan ní Rostock gba ẹ̀dà kan ìwé Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí méjì tí wọ́n wá sẹ́nu ilẹ̀kùn rẹ̀. Ó kọ̀wé sí ẹ̀ka ọ́fíìsì Germany pé: “Mó jẹ́ mẹ́ḿbà Ṣọ́ọ̀ṣì Lutheran. Mo ní ọ̀wọ̀ gíga jùlọ fún ìgbòkègbodò ètò-àjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Wọn sọ pẹ̀lú ìgbèròpinnu pé ènìyàn kò tún lè wàláàyè mọ́ láìsí ìtọ́sọ́nà Ọlọrun.”

Báwo ni ìtọ́sọ́nà tẹ̀mí tí àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Kristẹndọm ti fún àwọn mẹ́ḿbà rẹ̀ ti pọ̀ tó? Ìwé-akéde-ìròyìn tí ó gbayì náà Die Zeit ṣàlàyé ní December 1991 pé nígbà tí ó jẹ́ pé Ṣọ́ọ̀ṣì Lutheran ti “jọlá ogó fún àkókò kúkúrú gẹ́gẹ́ bí orísun fún ìyípadà tegbòtigaga alálàáfíà, ó dàbí ẹni pé ojú tí àwọn ènìyàn fi ń wò ó ti ń dínkù níti ìjẹ́pàtàkì.” Nítòótọ́, aṣojú Ṣọ́ọ̀ṣì Lutheran kan kédàárò pé: “Àwọn ènìyàn da ìgbésí-ayé nínú ètò-ọrọ̀-ajé dandawì rú pọ̀ mọ́ paradise.” Mẹ́ḿbà ṣọ́ọ̀ṣì kan ní Magdeburg kọ̀wé béèrè fún ìsọfúnni. Èéṣe? “Lẹ́yìn tí mo ti fi àìnígbàgbọ̀ rẹ́rìn-ín músẹ́ fún ọ̀pọ̀ ọdún,” ni ọkùnrin náà kọ̀wé, “mo ní ìdánilójú tí ó fẹsẹ̀múlẹ̀ nísinsìnyí pé ayé yìí ti wà nínú àwọn ọjọ́ ìkẹyìn rẹ̀ àti pé àwa yóò bá ìjàngbọ̀n ńláǹlà pàdé ní ọjọ́-ọ̀la tí kò jìnnà mọ́.”—2 Timoteu 3:1-5.

Kíkọ́lé fún Ìmúgbòòrò

Ṣáájú Wende náà, a kò gba àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba láàyè ní G.D.R. Nísinsìnyí a nílò wọn ní kánjúkánjú; kíkọ́ wọn ní a fi sí ipò kìn-ín-ní. Èyí jẹ́ apá-ẹ̀ka mìíràn nínú ìjọsìn tòótọ́ tí ó ti ní ìyípadà pípẹtẹrí. Ìrírí arákùnrin kan ṣàkàwé bí ìyípadà yìí tí yára gan-an tó.

Ní March 1990, ní kìkì wákàtí díẹ̀ lẹ́yìn tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa rí ìdánimọ̀ lábẹ́ òfin gbà ní G.D.R., a késí arákùnrin kan láti bá àwùjọ àwọn Ẹlẹ́rìí kan sọ̀rọ̀, ní lílo ẹ̀rọ gbohùngbohùn fún ìgbà àkọ́kọ́ nínú ìgbésí-ayé rẹ̀. Ní ọdún méjì àti ààbọ̀ lẹ́yìn náà, ìjọ tí ó ń darapọ̀ mọ́ ya Gbọ̀ngàn Ìjọba titun kan sí mímọ́. Nígbà tí ọdún 1992 fi máa parí, àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba méje ní a ti kọ́ fún àwọn ìjọ 16. Àwọn mìíràn tí iye wọn ju 30 lọ, àti Gbọ̀ngàn Àpéjọ fífanimọ́ra kan, ni a ń wéwèé wọn lọ́wọ́.

Wọ́n Tẹjúmọ́ Ìjọba Ọlọrun

“Ní kété lẹ́yìn Wende náà,” ni ọ̀rọ̀-àkíyèsí tí Kristian alàgbà kan sọ, “ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn kọ Bibeli sílẹ̀. Wọ́n fi ìrètí wọn sínú ìjọba titun náà, èyí tí ó nawọ́ ìlérí fún àwọn ipò sísàn jù jáde nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín.” A ha mú ìrètí wọn ṣẹ bí? “Láàárín ọdún méjì wọ́n yí ọkàn wọn padà. Àwọn ènìyàn gbà pẹ̀lú wa nísinsìnyí pé àwọn ìjọba ènìyàn kò lè mú àlááfíà àti òdodo wá láé.”

Àwọn ògìdìgbó yọ̀ nítorí ìyípadà ìjọba àjùmọ̀ní aláìláàánú ní G.D.R., ní pípolongo ohun tí wọ́n kà sí àkókò ayọ̀ àti aásìkí nínú ìdábàá-èrò-orí Ìwọ̀-Oòrùn Ayé. Ṣùgbọ́n a já wọn kulẹ̀. Láìka ìjọba tí ń ṣàkóso sí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa mú kí ojú wọn jẹ́ èyí tí ó mú ọ̀nà kan àti èyí tí ó tẹjú mọ́ Ìjọba Ọlọrun, tí ń tàn bí ìràwọ̀ kan nínú àwọn ọ̀run. Irúfẹ́ ìrètí bẹ́ẹ̀ kò lè yọrísí ìjákulẹ̀ láé.—Romu 5:5.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo “Jehofa Bojuto Wa Labẹ Ifofinde,” Apá 1 sí 3, nínú àwọn ìtẹ̀jáde Ilé-Ìṣọ́nà ti April 15, May 1, àti May 15, 1992.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Àwọn Ẹlẹ́rìí ní Germany ń lo òmìnira wọn láti túbọ̀ lọ́wọ́ nínú ìgbòkegbodò Ìjọba

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́