Lílọ sí Ọ̀run Tàbí sí Hẹ́ẹ̀lì?
“ÀWỌN ṣíṣeéṣe wo ni ó wà pé kí o lọ sí ọ̀run tàbí hẹ́ẹ̀lì?”
Níti gidi, ìyẹn ni ohun tí a bi ọ̀wọ́ àwọn ará America kan nínú ìwádìíkiri kan lẹ́nu àìpẹ́ yìí. Ibùdó Ìṣèwádìí Ìsìn ti Princeton tẹ àbájáde náà sínú ìwé Religion in America 1992-1993.
Báwo ni ìwọ ìbá ti dáhùn? Àwọn ṣíṣeéṣe wo ni ó wà pé kí alábàáṣègbéyàwó rẹ tàbí àwọn mìíràn tí o nífẹ̀ẹ́ sí lọ sí ọ̀run nígbà tí wọ́n bá kú? Ìwọ ha rò pé ó ṣeéṣe kí ìwọ, tàbí àwọn, lọ sí hẹ́ẹ̀lì níkẹyìn bí?
Ìwádìíkiri náà fihàn pé ìpín 78 nínú ọgọ́rùn-ún ronú pé ṣíṣeéṣe tí wọ́n ní láti lọ sí ọ̀run jẹ́ dáradára tàbí dára jùlọ, iye yìí rékọjá iye tí ó dáhùn lọ́nà bẹ́ẹ̀ ní nǹkan bí 40 ọdún sẹ́yìn. Hẹ́ẹ̀lì ńkọ́? Nǹkan bí ìpín 77 nínú ọgọ́rùn-ún sọ pé kò sí ẹ̀rí tí ó tó pé kí wọ́n lọ síbẹ̀.
Ǹjẹ́ a gbé àwọn ìdáhùn wọn karí ìmọ̀ pípéye nípa Bibeli bí? Ó dára, nǹkan bí 4 nínú 10 gbà pé àwọn kìí lọ sí àwọn ìpàdé ìjọsìn léraléra mọ́ bí ó ti rí ní ọdún márùn-ún sẹ́yìn. Kìkì ìpín 28 nínú ọgọ́rùn-ún ni wọ́n jẹ́wọ́ pé wọ́n ń ṣàjọpín nínú àwùjọ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli tí ìpín 27 nínú ọgọ́rùn-ún sì ń ṣàjọpín nínú àwọn kíláàsì ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ìsìn.
Bí o bá fìṣọ́ra kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, ìwọ yóò rí àwọn òtítọ́ yíyanilẹ́nu. Fún àpẹẹrẹ, Bibeli sọ ní ṣàkó pé Jesu lọ́ sínú “hẹ́ẹ̀lì” nígbà tí ó kú, gẹ́gẹ́ bí a ti túmọ̀ rẹ̀ nínú àwọn ẹ̀dà ìtumọ̀ Bibeli kan. (Iṣe 2:31, King James Version; “Hédíìsì,” New World Translation) Ọ̀rọ̀ Ọlọrun tún jẹ́rìí síi pé Ọba Dafidi tàbí Johannu Baptisi kò lọ sí ọ̀run nígbà tí wọ́n kú. (Matteu 11:11; Iṣe 2:29) Àwọn òtítọ́ nìwọ̀nyẹn, wọn kìí ṣe àwọn èrò lásán tí ó jáde wá láti inú ìwádìíkiri ìsìn.
Àwọn òtítọ́ mìíràn tí wọ́n lè nípa lórí rẹ: Bibeli kọ́ni pé àwọn aposteli Jesu àti iye kéréje kan nínú àwọn mìíràn ni a óò mú lọ sí ọ̀run láti ṣàkóso pẹ̀lú Jesu. Bí ó ti wù kí ó rí, ọ̀pọ̀ jùlọ nínú àwọn ènìyàn tí ó ti kú wulẹ̀ lọ sínú àpapọ̀ sàréè aráyé ni. Ọlọrun yóò jí wọn dìde, ní mímú wọn padà wá sí ìyè lórí ilẹ̀-ayé pẹ̀lú ìfojúsọ́nà fún ìwàláàyè aláyọ̀, kíkún tí kì yóò lópin nínú paradise ilẹ̀-ayé kan tí a múpadàbọ̀sípò.
Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa yóò dùn láti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti fìdí ìpìlẹ̀ tí ó ṣeégbáralé múlẹ̀ fún ìrètí yẹn láti inú Bibeli tìrẹ.