Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Ojoojúmọ́ Fún Ọdún 1994
APRIL
1. Ẹ máa gbọ́ ti awọn ti ń ṣe olori yin, ki ẹ si maa tẹriba fun wọn: nitori wọn ń ṣọ ẹṣọ nitori ọkàn yin, bi awọn ti yoo ṣe iṣiro.—Heb. 13:17. w-YR 9/1/92 8
2. Ijọba rẹ̀ yoo sì jẹ́ lati òkun dé òkun, ati lati odò titi de opin ayé.—Sek. 9:10. w-YR 9/15/92 8, 9b
3. Kristi [Messia], Ọmọ Ọlọrun alaaye ni iwọ ń ṣe.—Matt. 16:16. w-YR 10/1/92 1, 2
4. Oluwa ni i fi ọgbọ́n funni: lati ẹnu rẹ̀ jade ni ìmọ̀ ati oye ti i wá.—Owe 2:6. w-YR 11/1/92 10, 11
5. Ẹ mu gbogbo idamẹwaa wá si ile iṣura, ki ounjẹ baa le wà ni ile mi, ẹ si fi eyi dan mi wò nisinsinyi, bi emi ki yoo ba . . . sí tú ibukun jade fun yin, tobẹẹ ti ki yoo si àyè tó lati gbà á.—Mal. 3:10. w-YR 12/1/92 10, 15, 16a
6. Nigba ti Israeli jade kuro ni Egipti, ti ara-ile Jakobu kuro ninu ajeji ede eniyan; Juda ni ibi mimọ rẹ̀, Israeli ni ijọba rẹ̀.—Orin Da. 114:1, 2. w-YR 11/15/92 12, 13
7. Ẹ̀yin baba, ẹ máṣe máa sún awọn ọmọ yín bínú, ṣugbọn ẹ máa báa lọ ní títọ́ wọn dàgbà ninu ìbáwí ati ìlànà èrò-orí Jehofa.—Efe. 6:4, NW. w-YR 10/15/92 9, 10a
8. Dafidi sì tẹ́síwájú lati fi aworan ìkọ́lé naa fún Solomoni ọmọkùnrin rẹ̀ . . . èyí tí oun ti ní nípasẹ̀ ìmísí.—1 Kron. 28:11, 12, NW. w-YR 1/1/93 17, 18
9. Dide, tàn ìmọ́lẹ́: nitori ìmọ́lẹ̀ rẹ dé, ogo Oluwa si yọ lara rẹ. Nitori kiyesi i, . . . Oluwa yoo yọ lara rẹ, a ó sì rí ogo rẹ̀ lara rẹ.—Isa. 60:1, 2. w-YR 1/15/93 15, 16
10. Ọlọrun, gbà mi lọwọ ẹbi ẹ̀jẹ̀, iwọ Ọlọrun igbala mi: ahọ́n mi yoo sì maa kọrin òdodo rẹ kíkan.—Orin Da. 51:14. w-YR 3/15/93 12a
11. Ará, bi a tilẹ mú eniyan ninu ìṣubú kan, kí ẹyin tí iṣe ti ẹmi kí ó mú iru ẹni bẹẹ bọ̀ sípò ní ẹmi ìwà tútù; kí iwọ tikaraarẹ maa kiyesara, kí a má ba dan iwọ naa wò pẹlu.—Gal. 6:1. w-YR 2/1/93 9, 10a
12. Ṣaanu fun mi, Oluwa: nitori iwọ ni emi ń képè lojoojumọ. Mu ọkàn iranṣẹ rẹ yọ̀: Oluwa, nitori iwọ ni mo gbé ọkàn mi sókè sí.—Orin Da. 86:3, 4. w-YR 12/15/92 6, 7
13. A fi ofin de obinrin niwọn ìgbà ti ọkọ rẹ̀ bá wà laaye; ṣugbọn bi ọkọ rẹ̀ ba kú, o di ominira lati ba ẹnikẹni tÍ ó wù ú gbeyawo; kiki ninu Oluwa.—1 Kor. 7:39. w-YR 2/15/93 3, 4a
14. Kí ẹ bọ́ àkópọ̀-ànímọ́-ìwá ogbologboo sílẹ̀ èyí tí ó bá ìlà ipa-ọ̀nà ìwà yín ti àtijọ́ ṣe déédéé tí a sì ń sọ di ìbàjẹ́ ní ìbámu pẹlu awọn ìfẹ́-ọkàn rẹ̀ atannijẹ.—Efe. 4:22, NW. w-YR 3/1/93 8, 9a
15. Ẹ wá, ẹ jẹ ki a yipada si Oluwa: . . . awa o . . . tẹramọ ati mọ Oluwa.—Hos. 6:1-3. w-YR 4/15/93 13, 14
16. Awọn eniyan ti ń rin ni òkùnkùn ri ìmọ́lẹ̀ nla: awọn ti ń gbe ilẹ̀ ojiji ikú, lara wọn ni ìmọ́lẹ̀ mọ́ sí.—Isa. 9:2. w-YR 4/1/93 12-14
17. Ọsan kan ati oru kan ni mo wà ninu ibú. Ni irin-ajo nigbakuugba, ninu ewu omi, . . . ninu ewu ni aginju, ninu ewu loju òkun.—2 Kor. 11:25, 26. w-YR 9/1/92 9
18. Nitori orukọ rẹ, Oluwa, dárí ẹ̀ṣẹ̀ mi jì, nitori tí ó tobi.—Orin Da. 25:11. w-YR 9/15/92 11, 12
19. Kí ni yoo sì jẹ́ àmì wíwàníhìn-ín rẹ ati ti ìparí ètò-ìgbékalẹ̀ awọn nǹkan?—Matt. 24:3, NW. w-YR 10/1/92 9, 10a
20. Emi ó pa ọgbọ́n awọn ọlọ́gbọ́n run, emi ó si sọ òye awọn olóye di asan.—1 Kor. 1:19. w-YR 11/1/92 13-15a
21. Ẹ̀yin baba, ẹ máṣe máa sún awọn ọmọ yín bínú, ṣugbọn ẹ máa báa lọ ní títọ́ wọn dàgbà ninu ìbáwí ati ìlànà èrò-orí ti Jehofa.—Efe. 6:4, NW. w-YR 10/15/92 9, 13, 14a
22. Oun kìí ṣe si wa gẹgẹ bi ẹ̀ṣẹ̀ wa; bẹẹ ni kìí san án fun wa gẹgẹ bi aiṣedeedee wa.—Orin Da. 103:10. w-YR 11/15/92 6a
23. Ẹ mu gbogbo idamẹwaa wá si ile iṣura, . . . ẹ sì fi eyi dán mi wò nisinsinyi, bi emi ki yoo ba . . . tú ibukun jade fun yin, tobẹẹ ti ki yoo si àyè tó lati gbà á.—Mal. 3:10. w-YR 12/1/92 10-12a
24. Ẹyin ó gba agbara, nigba ti ẹmi mimọ bá bà le yin: ẹ o sì maa ṣe ẹlẹ́rìí mi . . . titi de opin ilẹ̀-ayé.—Iṣe 1:8. w-YR 1/1/93 6, 7a
25. [Jehofa, NW] Ọlọrun rẹ ajonirun iná ni, Ọlọrun owú.—Deut. 4:24. w-YR 1/15/93 5, 13b
26. Nitori naa gbogbo ohunkohun ti ẹyin ba ń fẹ ki eniyan ki o ṣe si yin, bẹẹ ni ki ẹyin ki o sì ṣe sí wọn gẹgẹ; nitori eyi ni ofin ati awọn wolii.—Matt. 7:12. w-YR 2/1/93 4, 5a
27. O sàn lati jokoo ni igun oke àjà, ju pẹlu onija obinrin lọ ninu ile ajumọgbe.—Owe 21:9. w-YR 2/15/93 1, 2a
28. Nitori naa, èyí ni mo ń wí tí mo sì ń jẹ́rìí sí ninu Oluwa, pé kí ẹ máṣe máa bá a lọ mọ́ ní rírìn gan-an gẹ́gẹ́ bí awọn orílẹ̀-èdè pẹlu ti ń rìn ninu àìlérè èrò-inú wọn.—Efe. 4:17, NW. w-YR 3/1/93 7, 8
29. Emi jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi fun ọ, ati ẹ̀ṣẹ̀ mi ni emi kò si fi pamọ. Emi wi pe, emi o jẹ́wọ́ irekọja mi fun Oluwa: iwọ sì dari ẹbi ẹ̀ṣẹ̀ mi jì.—Orin Da. 32:5. w-YR 3/15/93 1, 8
30. Oluwa yoo yọ lara rẹ, a o sì rí ogo rẹ̀ lara rẹ. Awọn Keferi yoo wá sí ìmọ́lẹ̀ rẹ.—Isa. 60:2, 3. w-YR 4/1/93 9, 10