Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Ojoojúmọ́ Fún Ọdún 1994
MARCH
1. Awọn eniyan tí ń rìn ní òkùnkùn rí ìmọ́lẹ̀ ńlá: awọn tí ń gbé ilẹ̀ òjìji ikú, lara wọn ni ìmọ́lẹ̀ mọ́ sí.—Isa. 9:2. w-YR 4/1/93 11, 12
2. Maa sá fun ifẹkufẹẹ èwe: sì maa lépa òdodo, igbagbọ, ifẹ, alaafia, pẹlu awọn ti ń ké pe Oluwa lati inu ọkàn funfun wá.—2 Tim. 2:22. w-YR 4/15/93 6, 10, 11
3. Ọ̀rọ̀ wọnyi, ti mo palaṣẹ fun ọ ni oni, ki o maa wà ni àyà rẹ.—Deut. 6:6. w-YR 11/1/92 7, 8
4. Wèrè eniyan yi ọ̀nà rẹ̀ po: nigba naa ni àyà rẹ̀ binu si Oluwa.—Owe 19:3. w-YR 11/15/92 9, 10a
5. Kò sí ọ̀kankan tí ó dàbí rẹ laaarin awọn ọlọrun, óò Jehofa, bẹẹ ni kò sí awọn iṣẹ eyikeyii tí ó dàbí tìrẹ.—Orin Da. 86:8, NW. w-YR 12/15/92 14, 15
6. Emi ni ìmọ́lẹ̀ ayé; ẹni tí ó bá tọ̀ mi lẹ́yìn ki yoo rìn ninu òkùnkùn, ṣugbọn yoo ní ìmọ́lẹ̀ ìyè.—Joh. 8:12. w-YR 1/15/93 8, 10, 11
7. Oluwa ni onidaajọ wa, Oluwa ni olofin wa, Oluwa ni ọba wa; oun o gbà wa là.—Isa. 33:22. w-YR 2/1/93 6, 8
8. Simoni, iwọ ti rò ó sí? lọwọ ta ni awọn ọba ayé ti maa ń gba owóòde? lọwọ awọn ọmọ wọn, tabi lọwọ awọn alejo?—Matt. 17:25. w-YR 10/15/92 15, 16a
9. Ẹ ma si ṣe mu ẹmi mimọ Ọlọrun binu, [eyi ti] a fi ṣe edidi yin de ọjọ idande.—Efe. 4:30. w-YR 9/15/92 15, 17, 18a
10. Ta ni ó dàbí Jehofa Ọlọrun wa, ẹni tí ó fi ibi gíga lókèlókè ṣe ibugbe rẹ̀? Ó ń rẹ araarẹ̀ sílẹ̀ lati wo ọ̀run ati ilẹ̀-ayé.—Orin Da. 113:5, 6, NW. w-YR 11/15/92 8, 9
11. Ẹ̀yin gbọ́dọ̀ pè é padà sí ọkàn-àyà yín [àlàyé etí-ìwé, “gbọ́dọ̀ pè padà sí èrò-inú yìn”] pé Jehofa ni Ọlọrun tòótọ́.—Deut. 4:39, NW. w-YR 3/1/93 1-3
12. Emi ni [Jehofa, NW]: eyi ni orukọ mi: ògo mi ni emi kì yoo fi fún ẹlòmíràn, bẹẹni emi kì yoo fi iyin mi fún ère gbígbẹ́.—Isa. 42:8. w-YR 1/15/93 7, 8, 10a
13. Gbogbo awọn orílẹ̀-èdè tí iwọ ti ṣe yoo fúnraawọn wá, wọn yoo sì tẹríba niwaju rẹ, óò Jehofa, wọn yoo sì fi ògo fún orukọ rẹ.—Orin Da. 86:9, NW. w-YR 12/15/92 17
14. Oluwa, iwọ ni ó yẹ lati gba ògo ati ọlá ati agbara: Nitori pe iwọ ni o dá ohun gbogbo, ati nitori ifẹ-inu rẹ ni wọn fi wà ti a sì dá wọn.—Ìfi. 4:11. w-YR 2/1/93 9-11
15. Emi gbìn, Apollo bomirin; ṣugbọn Ọlọrun ni ń mú ibisi wá. Ǹjẹ́ kì í ṣe ẹni tí ó ń gbìn nǹkankan, bẹẹ ni kì í ṣe ẹni ti ń bomirin; bikoṣe Ọlọrun tí ó ń mú ibisi wá.—1 Kor. 3:6, 7. w-YR 9/1/92 11, 12a
16. Adura igbagbọ yoo si gba alaisan naa là, Oluwa yoo si gbe e dide; bí ó bá sì ṣe pe o ti dẹṣẹ, a o dáríjì í.—Jak. 5:15. w-YR 9/15/92 17, 18
17. Kí aya ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún ọkọ rẹ̀.—Efe. 5:33, NW. w-YR 10/15/92 12, 13
18. Ọlọrun, ṣaanu fun mi, gẹgẹ bi iṣeun ifẹ rẹ̀: gẹgẹ bi irọnu ọpọ aanu rẹ, nu irekọja mi nù kuro.—Orin Da. 51:1. w-YR 3/15/93 10, 11
19. Nitori naa ẹ lọ, ki ẹ maa sọ gbogbo eniyan orilẹ-ede di ọmọ-ẹ̀yìn.—Matt. 28:19. w-YR 1/15/93 11, 12
20. Yoo si ṣe ni ọjọ ìkẹyìn, a o fi oke ile Oluwa kalẹ lori awọn oke nla, . . . gbogbo orilẹ-ede ni yoo si wọ́ si inu rẹ̀.—Isa. 2:2. w-YR 4/1/93 5, 6
21. Ìmọ̀ a maa fẹ̀, ṣugbọn ifẹ ni gbéniró.—1 Kor. 8:1. w-YR 11/15/92 16, 17b
22. Dẹtí rẹ silẹ, óò Jehofa. Dá mi lóhùn, nitori tí mo jẹ́ ẹni ti a pọ́nlójú ati òtòṣì. Óò dákun daabobo ọkàn mi, nitori ti mo jẹ́ aduroṣinṣin. Gba iranṣẹ rẹ—ti ń ní igbẹkẹle ninu rẹ là—iwọ ni Ọlọrun mi.—Orin Da. 86:1, 2, NW. w-YR 12/15/92 3, 4
23. Ẹyin ọmọ mi, ẹ pa araayin mọ́ kuro ninu oriṣa.—1 Joh. 5:21. w-YR 1/15/93 19, 21-23a
24. Iwọ sọ̀rọ̀ bi ọ̀kan ninu awọn obinrin alaimoye ti i sọ̀rọ̀; kinla! awa o ha gba ire lọwọ Ọlọrun, ki a má si gba ibi!—Jobu 2:10. w-YR 2/1/93 19
25. Kí ẹ di titun ninu ipá tí ń mú èrò-inú yín ṣiṣẹ́.—Efe. 4:23, NW. w-YR 3/1/93 11, 12a
26. Iwọ tobi o sì ń ṣe awọn ohun àgbàyànu; iwọ ni Ọlọrun, iwọ nìkan.—Orin Da. 86:10, NW. w-YR 12/15/92 18-20
27. Ṣugbọn nigba ti ó rí ọpọ eniyan, àánú wọn ṣe é, nitori ti àárẹ̀ mú wọn, wọ́n sì túka kiri bi awọn agutan ti kò ni oluṣọ.—Matt. 9:36. w-YR 4/1/93 8a
28. Ifẹ kii yẹ̀ lae.—1 Kor. 13:8. w-YR 2/15/93 15, 16
29. [Ki sì ni, NW] ohun tí Oluwa beere lọwọ rẹ, bikoṣe ki o ṣe otitọ, ki o sì fẹ àànú, ati ki o rìn ní ìrẹ̀lẹ̀ pẹlu Ọlọrun rẹ?—Mika 6:8. w-YR 4/15/93 18, 19
30. Ta ni o lè mọ iṣina rẹ̀? Wẹ̀ mi mọ́ kuro ninu ìṣìṣe ikọkọ mi. Fa iranṣẹ rẹ sẹ́yìn pẹlu kuro ninu ẹ̀ṣẹ̀ ìkùgbù: maṣe jẹ ki wọn ki o jọba lori mi: nigba naa ni emi o duro ṣinṣin, emi o si ṣe alaijẹbi kuro ninu ẹ̀ṣẹ̀ nla nì. Jẹ ki ọ̀rọ̀ ẹnu mi, ati ìṣàrò ọkan mi, ki o ṣe itẹwọgba ni oju rẹ, Oluwa, agbara mi, ati oludande mi.—Orin Da. 19:12-14. w-YR 11/15/92 5a
31. Ẹyin ọmọ, ẹ maa gbọ ti awọn obi yin ninu Oluwa: nitori pe eyi ni o tọ́. Bọwọ fun baba ati iya rẹ eyi ti iṣe ofin ikinni pẹlu ileri, Ki o lè dara fun ọ, ati ki iwọ ki o lè wà pẹ ni ayé.—Efe. 6:1-3. w-YR 10/15/92 17, 18